A Óò Ha Gbà Ọ́ Là Nígbà Tí Ọlọ́run Bá Gbégbèésẹ̀ Bí?
“Láìjẹ́ pé a ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là; ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́ a óò ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú.”—MÁTÍÙ 24:22.
1, 2. (a) Èé ṣe tí ó fi bá ìwà ẹ̀dá mu láti lọ́kàn ìfẹ́ nínú ọjọ́ ọ̀la? (b) Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ni àwọn ohun tí a lọ́kàn ìfẹ́ sí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá lè ní nínú?
BÁWO ni o ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ tó? Ọ̀pọ̀ lónìí ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn ju bí ó ti yẹ lọ, ní jíjẹ́ olùgbéra-ẹni-lárugẹ. Síbẹ̀, Bíbélì kò dẹ́bi fún níní ọkàn-ìfẹ́ tí ó tọ́ nínú ohun tí ó bá kàn wá. (Éfésù 5:33) Ìyẹn ní níní ọkàn-ìfẹ́ nínú ọjọ́ ọ̀la wa nínú. Nítorí náà, kì í ṣe ohun tí ó ṣàjèjì láti fẹ́ẹ́ mọ ohun tí ọjọ́ ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún ọ. Ìwọ ha fẹ́ láti mọ̀ ọ́n bí?
2 A lè ní ìdánilójú pé àwọn àpọ́sítélì Jésù ní irú ọkàn-ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ọjọ́ ọ̀la wọn. (Mátíù 19:27) Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn ti jẹ́ kókó abájọ tí ó mú kí àwọn mẹ́rin nínú wọn béèrè ìbéèrè kan nígbà tí wọ́n wà pẹ̀lú Jésù lórí Òkè Ólífì. Wọ́n béèrè pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì ìgbà tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá sí ìparí?” (Máàkù 13:4) Jésù kò pa ọkàn-ìfẹ́ tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu nínú ọjọ́ ọ̀la tì—ọkàn ìfẹ́ tiwọn àti tiwa. Léraléra, ó tẹnu mọ́ bí yóò ṣe kan àwọn ọmọlẹ́yìn òun àti ohun tí àbájáde ìkẹyìn yóò jẹ́.
3. Èé ṣe tí a fi so èsì Jésù pọ̀ mọ́ àkókò wa?
3 Èsi Jésù gbé àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ó ní ìmúṣẹ pàtàkì ní àkókò wa kalẹ̀. A lè rí èyí nínú àwọn ogun àgbáyé àti àwọn ìforígbárí mìíràn ní ọ̀rúndún wa, ìmìtìtì ilẹ̀ tí ń gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn, àìtó oúnjẹ tí ń fa àìsàn àti ikú, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn—láti orí àrùn gágá ilẹ̀ Sípéènì tí ó jà kárí ayé ní 1918 títí dórí àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí AIDS tí ń jà lọ́wọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ nínú èsì Jésù tún ní ìmúṣẹ tí ó yọrí sí ìparun Jerúsálẹ́mù láti ọwọ́ àwọn ará Róòmù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa nínú. Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra yín; àwọn ènìyàn yóò fà yín lé àwọn kóòtù àdúgbò lọ́wọ́, wọ́n yóò sì lù yín nínú àwọn sínágọ́gù a óò sì fi yín sórí àpótí ìdúró rojọ́ níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn.”—Máàkù 13:9.
Ohun Tí Jésù Sọ Tẹ́lẹ̀, àti Ohun Tí Ó Ṣẹlẹ̀
4. Àwọn ìkìlọ̀ wo ni èsì Jésù ní nínú?
4 Kì í ṣe kìkì àsọtẹ́lẹ̀ bí àwọn ẹlòmíràn yóò ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò ni Jésù sọ. Ó ta wọ́n lólobó nípa bí ó ṣe yẹ kí àwọn fúnra wọ́n hùwà. Fún àpẹẹrẹ: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro tí ó dúró níbi tí kò yẹ (kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀), nígbà náà ni kí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Máàkù 13:14) Àkọsílẹ̀ tí ó fara jọ ọ́ nínú Lúùkù 21:20 sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká.” Báwo ni ìyẹn ṣe já sí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ nínú ìmúṣẹ àkọ́kọ́?
5. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Júù ní Jùdíà ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa?
5 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopedia (1982), sọ fún wa pé: “Àwọn Júù túbọ̀ ń ya olórí kunkun lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù, àwọn ìjòyè òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Róòmù sì túbọ̀ ń di oníwà ipá, òǹrorò, àti alábòsí. Ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba wálíà wáyé ní ọdún 66 Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa. . . . Ogun náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn Onítara Ìsìn gba Màsádà àti lẹ́yìn náà, lábẹ́ ìdarí Menahem, tí wọ́n sì kọlu Jerúsálẹ́mù. Lọ́wọ́ kan náà, a pa àwọn Júù tí ń bẹ nínú ìlú Kesaríà tí gómìnà ń gbé nípakúpa, ìròyìn ìwà ìkà búburú jáì yìí sì tàn kálẹ̀ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. A gbẹ́ Ọdún 1 títí dé Ọdún 5 ọ̀tẹ̀ náà sí àwọn owó tuntun lára.”
6. Ìwà wo ni ọ̀tẹ̀ àwọn Júù mú kí àwọn ará Róòmù hù?
6 Lígíónì Kejìlá ti Róòmù lábẹ́ Cestius Gallus yan wá láti Síríà, wọ́n fọ́ Gálílì àti Jùdíà túútúú, lẹ́yìn náà wọ́n kọlu olú ìlú náà, kódà wọ́n gba apá òkè “Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́.” (Nehemáyà 11:1; Mátíù 4:5; 5:35; 27:53) Ní ṣíṣàkópọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìdìpọ̀ ìwé náà, The Roman Siege of Jerusalem, sọ pé: “Fún ọjọ́ márùn-ún àwọn ará Róòmù gbìdánwò láti gun ògiri náà, a sì ń ké ìsapá náà nígbèrí léraléra. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n jáwọ́ gbígbèjà ara wọn, nígbà tí àwọn ohun ìjà tí àwọn tọ̀ún ń lò borí tiwọn. Nípa ṣíṣe testudo—ọgbọ́n dída apata wọn borí wọn kí wọ́n baà lè dáàbò bo ara wọn—àwọn ọmọ ogun Róòmù gbẹ́ abẹ́ ògiri náà, wọ́n sì gbìdánwò láti sọ iná sí ẹnu ọ̀nà àbáwọ̀lú. Jìnnìjìnnì ńláǹlà bò wọ́n.” Àwọn Kristẹni tí ń bẹ nínú ìlú ńlá náà yóò ti rántí ọ̀rọ̀ Jésù, wọn yóò sì ti fòye mọ ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro tí ó dúró sí ibi mímọ́.a Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí a ti yí ìlú náà ká, báwo ni àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn yóò ṣe sá, gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí Jésù fún wọn?
7. Nígbà tí ìṣẹ́gun ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wọn lọ́wọ́ ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, kí ni àwọn ará Róòmù ṣe?
7 Òpìtàn, Flavius Josephus, sọ pé: “Cestius [Gallus], láìmọ ipò àìnírètí tí àwọn tí a sàga tì náà wà tàbí ìmọ̀lára tí wọ́n ní, pàṣẹ lójijì pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ dá ìsàgatì náà dúró, ó pa ìrètí rẹ̀ tì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò sẹ́gun rẹ̀, ní híhùwà lọ́nà tí kò bá ọgbọ́n ìrònú mu, ó fi Ìlú Ńlá náà sílẹ̀.” (The Jewish War, II, 540 [xix, 7]) Èé ṣe tí Gallus fi fà sẹ́yìn? Ohun yòó wù kí ó fà á, fífà tí ó fà sẹ́yìn yọ̀ọ̀da fún àwọn Kristẹni láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù kí wọ́n sì sá lọ sí orí òkè àti sí ibi ààbò.
8. Kí ni apá kejì ìsapá àwọn ará Róòmù lòdì sí Jerúsálẹ́mù, kí sì ni àwọn olùlàájá nírìírí rẹ̀?
8 Ìgbọràn ń gbẹ̀mí là. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn ará Róòmù gbéra láti paná ọ̀tẹ̀ náà. Ìgbétásì lábẹ́ Ọ̀gágun Titus dé òtéńté nínú ìsàgatì Jerúsálẹ́mù láti April títí di August ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Kíka àpèjúwe Josephus nípa bí ìyà ṣe jẹ́ àwọn Júù lè kó ìpayà báni. Yàtọ̀ sí àwọn tí a pa nígbà tí wọ́n ń bá àwọn ará Róòmù jà, ẹgbẹ́ àwọn Júù abánidíje pa àwọn Júù míràn nípakúpa, ebi sì yọrí sí pípa ara wọn jẹ. Nígbà tí àwọn ará Róòmù yóò fi ṣẹ́gun, 1,100,000 Júù ti kú.b Nínú 97,000 tí wọ́n là á já, a pa àwọn kan ní kánmọ́kánmọ́; a sì kó àwọn mìíràn lẹ́rú. Josephus sọ pé: “Àwọn tí wọ́n ti lé ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni a fi ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n dè mọ́ra wọn, tí a sì rán lọ fún iṣẹ́ àṣekára ní Íjíbítì, nígbà tí Titus sì rán ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ lọ sí àwọn ẹkùn ìpínlẹ̀, kí wọ́n lè tipa idà tàbí ẹranko ẹhànnà ṣègbé lórí pápá ìṣeré.” Àní bí pípinnu àtúbọ̀tán wọn ti ń wáyé, ebí pa 11,000 ẹlẹ́wọ̀n kú.
9. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni kò fi nírìírí àbájáde tí àwọn Júù ní, ṣùgbọ́n ìbéèrè wo ni ó ń fẹ́ ìdáhùn?
9 Àwọn Kristẹni lè dúpẹ́ pé wọ́n ti ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Olúwa, wọ́n sì ti sá kúrò nínú ìlú ńlá náà kí àwọn ọmọ ogun Róòmù tó padà dé. A tipa báyìí gbà wọ́n là kúrò nínú apá kan ohun tí Jésù pè ní ‘ìpọ́njú ńlá tí irúfẹ́ rẹ̀ kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, tí kì yóò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́’ sórí Jerúsálẹ́mù. (Mátíù 24:21) Jésù fi kún un pé: “Ní tòótọ́, láìjẹ́ pé a ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là; ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́ a óò ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú.” (Mátíù 24:22) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí nígbà náà lọ́hùn-ún, kí sì ni ó túmọ̀ sí nísinsìnyí?
10. Báwo ni a ṣe ṣàlàyé Mátíù 24:22 tẹ́lẹ̀?
10 Ní àtijọ́ a ṣàlàyé pé ‘ẹran ara tí a óò gbà là’ tọ́ka sí àwọn Júù tí wọ́n la ìpọ́njú tí ó dé sórí Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa já. Àwọn Kristẹni ti sá, nítorí náà Ọlọ́run lè yọ̀ọ̀da fún àwọn ará Róòmù láti mú ìparun yíyára kánkán wá. Ní èdè míràn, nítorí òkodoro òtítọ́ náà pé “àwọn àyànfẹ́” ti kúrò nínú ewu, a lè ké ọjọ́ ìpọ́njú náà kúrú, ní yíyọ̀ǹda fún gbígba “ẹran ara” àwọn Júù díẹ̀ là. Nígbà náà lọ́hùn-ún a rò pé àwọn Júù tí wọ́n là á já ṣàpẹẹrẹ àwọn tí yóò la ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀ ní ọjọ́ wa já.—Ìṣípayá 7:14.
11. Èé ṣe tí ó fi dà bíi pé ó yẹ kí a tún àlàyé Mátíù 24:22 gbé yẹ̀ wò?
11 Ṣùgbọ́n àlàyé yẹn ha bá ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa mu bí? Jésù wí pé “ẹran ara” ẹ̀dá ènìyàn ni a óò “gbà là” láti inú ìpọ́njú náà. Ìwọ yóò ha lo ọ̀rọ̀ náà “gbà là” láti ṣàpèjúwe àwọn 97,000 olùlàájá náà bí, lójú ìwòye òkodoro òtítọ́ náà pé, kò pẹ́ tí ebi fi pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn kú tàbí tí a pa wọ́n ní ìpakúpa lórí pápá ìṣeré? Josephus sọ nípa pápá ìṣeré kan, ní Kesaríà pé: “Iye àwọn tí wọ́n kú nínú bíbá àwọn ẹranko ẹhànnà jà tàbí nínú bíbá ẹnì kíní kejì jà tàbí tí a dáná sun láàyè lé ní 2,500.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kò kú nígbà ìsàgatì, ekukáká ni a fi “gbà” wọ́n “là.” Jésù yóò ha sì fojú kan náà wo àwọn àti àwọn aláyọ̀ tí yóò la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ já bí?
A Gba Ẹran Ara Là—Báwo?
12. Àwọn wo ni “àwọn àyànfẹ́” ní ọ̀rúndún kìíní tí Ọlọ́run ní ọkàn-ìfẹ́ sí?
12 Nígbà tí yóò fi di ọdún 70 Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run kò ka àwọn Júù àbínibí sí àwọn tí ó jẹ́ àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́. Jésù fi hàn pé Ọlọ́run ti kọ orílẹ̀-èdè yẹn sílẹ̀, yóò sì jẹ́ kí olú ìlú rẹ̀, tẹ́ḿpìlì rẹ̀, àti ètò ìgbékalẹ̀ ìjọsìn rẹ̀ wá sí òpin. (Mátíù 23:37–24:2) Ọlọ́run yan orílẹ̀-èdè tuntun, Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Ìṣe 15:14; Róòmù 2:28, 29; Gálátíà 6:16) Ó ní àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí a yàn láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo nínú, tí a sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn. (Mátíù 22:14; Jòhánù 15:19; Ìṣe 10:1, 2, 34, 35, 44, 45) Ọdún díẹ̀ ṣáájú kí Cestius Gallus tó kọlù ú, Pétérù kọ̀wé sí “àwọn ẹni tí a yàn ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Bàbá, pẹ̀lú ìsọdimímọ́ nípa ẹ̀mí.” Irú àwọn tí a fi ẹ̀mí yàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ẹ̀yà ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Pétérù Kìíní 1:1, 2; 2:9) Ọlọ́run yóò mú irú àwọn àyànfẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ sí ọ̀run láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù.—Kólósè 1:1, 2; 3:12; Títù 1:1; Ìṣípayá 17:14.
13. Ìtumọ̀ wo ni àwọn ọ̀rọ̀ Jésù nínú Mátíù 24:22 ní?
13 Dídá tí a dá àwọn àyànfẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ ṣèrànwọ́, níwọ̀n bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò ké àwọn ọjọ́ ìpọ́njú kúrú “ní tìtorí àwọn àyànfẹ́.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “ní tìtorí” ni a tún lé túmọ̀ sí “nítorí” tàbí “tìtorí.” (Máàkù 2:27; Jòhánù 12:30; Kọ́ríńtì Kìíní 8:11; 9:10, 23; 11:9; Tímótì Kejì 2:10; Ìṣípayá 2:3) Nítorí náà Jésù ti lè máa sọ pé, ‘Láìjẹ́ pé a ké àwọn ọjọ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara tí a óò lè gbà là; ṣùgbọ́n nítorí àwọn àyànfẹ́ a óò ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú.’c (Mátíù 24:22) Ohun kan ha ṣẹlẹ̀ tí ó ṣàǹfààní fún àwọn Kristẹni àyànfẹ́ tí a ká mọ́ Jerúsálẹ́mù tàbí tí ó jẹ́ ‘nítorí’ wọn bí?
14. Báwo ni a ṣe gba “ẹran ara” là nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù fà sẹ́yìn kúrò ní Jerúsálẹ́mù lójijì ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa?
14 Rántí pé ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa, àwọn ará Róòmù gba orí ilẹ̀, wọ́n gba apá òkè Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ abẹ́ ògiri náà. Josephus sọ pé: “Ká ní ó túbọ̀ tẹra mọ́ ìsàgatì náà díẹ̀ sí i ni, ì bá ti ṣẹ́gun Ìlú Ńlá náà lẹ́ẹ̀kan.” Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Èé ṣe tí ẹgbẹ ọmọ ogun Róòmù alágbára yóò fi pa ìgbétásì náà tì lójijì, tí yóò sì fà sẹ́yìn “ní híhùwà lọ́nà tí kò bá ọgbọ́n ìrònú rẹ̀ mu?’ Rupert Furneaux, ògbóǹkangí nínú ìtumọ̀ ìtàn ológun, sọ pé: “Kò tí ì sí òpìtàn kan tí ó kẹ́sẹ járí nínú sísọ ìdí tí ó tóótun fún ìpinnu àjèjì àti oníjàm̀bá tí Gallus ṣe.” Ohun yòó wù kí ìdí náà jẹ́, ìyọrísí rẹ̀ ni pé a ké ìpọ́njú náà kúrú. Àwọn ará Róòmù fà sẹ́yìn, tí àwọn Júù sì ń kọ lù wọ́n bí wọ́n ṣe ń padà. Àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró “àwọn àyànfẹ́” tí a ti ká mọ́ ńkọ́? Àìsàgatì wọ́n mọ́ túmọ̀ sí pé a ti gbà wọ́n là kúrò nínú ìpakúpa tí ń wuni léwu nígbà ìpọ́njú náà. Nítorí náà, àwọn Kristẹni tí wọ́n jàǹfààní láti inú ìkékúrú ìpọ́njú náà ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa ni “ẹran ara” tí a gbà là, tí a mẹ́nu kàn nínu Mátíù 24:22.
Kí Ni Ọjọ́ Ọ̀la Ní Ní Ìpamọ́ fún Ọ?
15. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé ó yẹ kí a ní ọkàn-ìfẹ́ pàtàkì sí Mátíù orí 24 ní ọjọ́ wa?
15 Ẹnì kan lè béèrè pé, ‘Èé ṣe tí mo fi ní láti ní ọkàn-ìfẹ́ pàtàkì nínú òye tí a túbọ̀ mú ṣe kedere nípa ọ̀rọ Jésù?’ Tóò, ìdí púpọ̀ ń bẹ láti dórí ìparí èrò náà pé, àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yóò ní ìmúṣẹ títóbi jù, ré kọjá ohun tí ó ṣẹlẹ̀ títí di ọdún 70 Sànmánì Tiwa àti ní ọdún náà gan-an.d (Fi wé Mátíù 24:7; Lúùkù 21:10, 11; Ìṣípayá 6:2-8.) Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wàásù pé, ìmúṣẹ pàtàkì tí ń ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa fi hàn pé a lè retí “ìpọ́njú ńlá” gbígbòòrò, gẹ́rẹ́ níwájú wa. Nígbà tí yóò bá ṣẹlẹ̀, báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Mátíù 24:22 yóò ṣe ní ìmúṣẹ?
16. Òkodoro òtítọ́ afúnni níṣìírí wo ni Ìṣípayá fúnni nípa ìpọ́njú ńlá tí ń sún mọ́lé?
16 Nǹkan bí ẹ̀wádún méjì lẹ́yìn ìpọ́njú náà lórí Jerúsálẹ́mù, àpọ́sítélì Jòhánù kọ ìwé Ìṣípayá. Ó jẹ́rìí sí i pé ìpọ́njú ńlá ń bẹ níwájú. Níwọ̀n bí a sì ti lọ́kàn ìfẹ́ nínú ohun tí ó kàn wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó lè tù wá lára láti mọ̀ pé Ìṣípayá mú un dá wa lójú lọ́nà alásọtẹ́lẹ̀ pé, ẹran ara ẹ̀dá ènìyàn yóò wà láàyè la ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀ já. Jòhánù sọ tẹ́lẹ̀ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Ta ni wọ́n? Ohùn kan láti ọ̀run dáhùn pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.” (Ìṣípayá 7:9, 14) Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóò jẹ́ olùlàájá! Ìṣípayá tún fún wa ní òye inú nípa bí àwọn nǹkan yóò ṣe ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀ àti bí Mátíù 24:22 yóò ṣe ní ìmúṣẹ.
17. Kí ni ìpele ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà yóò ní nínú?
17 Apá àkọ́kọ́ nínú ìpọ́njú yìí yóò jẹ́ kíkọlu aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ náà tí a pè ní “Bábílónì Ńlá.” (Ìṣípayá 14:8; 17:1, 2) Ó dúró fún ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, tí Kirisẹ́ńdọ̀mù jẹ́ apá tí ó yẹ ní dídá lẹ́bi jù lọ nínú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ Ìṣípayá 17:16-18 ṣe sọ, Ọlọ́run yóò fi í sínú ọkàn-àyà ètò ìṣèlú láti kọlu aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ yìí.e Ronú lórí bí yóò ṣe rí lójú àwọn ẹni-àmì-òróró Ọlọ́run “àwọn àyànfẹ́” àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, “ogunlọ́gọ̀ ńlá.” Bí ìkọlù ìsọdahoro yìí lórí ìsìn ti ń tẹ̀ síwájú, ó lè dà bíi pé yóò gbá gbogbo ètò àjọ ìsìn kúrò, títí kan àwọn ènìyàn Jèhófà.
18. Èé ṣe tí ó fi lè dà bíi pé kò sí “ẹran ara” kankan tí a óò ‘gbà là’ jálẹ̀ apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá náà?
18 Níhìn-ín yìí ni ọ̀rọ̀ Jésù tí a rí nínú Mátíù 24:22 yóò ti ní ìmúṣẹ lọ́nà gbígbòòrò. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àyànfẹ́ ní Jerúsálẹ́mù ṣe dà bí ẹni wà nínú ewu, ó lè dà bíi pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wà nínú ewu mímú wọn kúrò lákòókò ìkọlù ìsìn, bí ẹni pé ìkọlù yẹn yóò gbá gbogbo “ẹran ara” ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run kúrò. Síbẹ̀, ẹ jẹ́ kí a fi ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa sọ́kàn. A ké ìpọ́njú náà tí àwọn ará Róòmù ṣokùnfà kúrú, ní yíyọ̀ǹda fún àwọn àyànfẹ́ ẹni-àmì-òróró Ọlọ́run láti ní àǹfààní tí ó pọ̀ tó láti sá àsálà, kí wọ́n sì wà láàyè. Nípa báyìí, a lè ní ìdánilójú pé, a kì yóò yọ̀ọ̀da fún ìkọlù ìṣèparun tí yóò dé sórí ìsìn láti pa ìjọ àwọn olùjọsìn tòótọ́ kárí ayé run. Yóò ṣẹlẹ̀ ní kánmọ́kánmọ́, bí ẹni pé “ní ọjọ́ kan ṣoṣo.” Ṣùgbọ́n, lọ́nà kan ṣá, a óò ké e kúrú, a kì yóò yọ̀ọ̀da fún un láti mú ète rẹ̀ ṣẹ, kí a baà lè “gba” àwọn ènìyàn Ọlọ́run “là.”—Ìṣípayá 18:8.
19. (a) Lẹ́yìn apá àkọ́kọ́ ìpọ́njú ńlá náà, kí ni yóò hàn kedere? (b) Kí ni èyí yóò yọrí sí?
19 Àwọn apá tí ó ṣẹ́ kù nínú ètò àjọ Sátánì Èṣù lórí ilẹ̀ ayé yóò máa bá a nìṣó fún àkókò kan, ní ṣíṣọ̀fọ̀ ìpàdánù ìbálò wọn pẹ̀lú àlè wọn àtijọ́ ní ti ìsìn. (Ìṣípayá 18:9-19) Ní àkókò kan, wọn yóò ṣàkíyèsí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣì wà, “tí wọ́n ń gbé láìbẹ̀rù, tí gbogbo wọn ń gbé láìsí odi” tí wọ́n sì dà bí ohun ọdẹ tí ó rọrùn láti pa jẹ. Ẹ wo irú ohun ìyanu tí ó wà ní ìpamọ́! Ní dídáhùn padà sí ìkannú gidi tàbí èyí tí ó jẹ́ ìhàlẹ̀ mọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, Ọlọ́run yóò dìde ní ṣíṣèdájọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ ní apá ìkẹyìn ìpọ́njú ńlá náà.—Ìṣíkẹ́ẹ̀lì 38:10-12, 14, 18-23.
20. Èé ṣe tí ìpele kejì ìpọ́njú ńlá náà kì yóò fi fi àwọn ènìyàn Ọlọ́run sínú ewu?
20 Apá kejì nínú ìpọ́njú ńlá náà yóò bá ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù àti àwọn olùgbé rẹ̀ nígbà ìkọlù ẹ̀ẹ̀kejì tí àwọn ará Róòmù ṣe ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa dọ́gba. Yóò jẹ́ ‘ìpọ́njú ńlá irúfẹ́ èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé títí di [ìgbà yẹn], rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.’ (Mátíù 24:21) Ṣùgbọ́n, a lè ní ìdánilójú pé àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn kì yóò sí ní agbègbè eléwu, ní wíwà nínú ewu pípa wọ́n. Kò sí àní-àní pé, wọn kì yóò ní láti sá lọ sí ọ̀gangan kan pàtó. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Jerúsálẹ́mù lè sá láti ìlú ńlá yẹn lọ sí àwọn ẹkùn olókè gíga, irú bíi ti Pélà ní ìkọjá Jọ́dánì. Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ ọ̀la, àwọn olùṣòtítọ́ Ẹlẹ́rìí Ọlọ́run yóò wà káàkiri àgbáyé, nítorí náà àìléwu àti ààbò kì yóò sinmi lórí ọ̀gangan kan pàtó.
21. Ta ni yóò jagun náà nínú ogun àjàkẹ́yìn náà, kí sì ni yóò yọrí sí?
21 Ìparun náà kì yóò jẹ́ láti ọwọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù tàbí aṣojú ẹ̀dá ènìyàn kankan. Dípò bẹ́ẹ̀, ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe ẹgbẹ́ ọmọ ogun amúdàájọ́ ṣẹ náà bí èyí tí ó wá láti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni, a óò mú apá ìkẹyìn yẹn ti ìpọ́njú ńlá náà ṣẹ, kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀dá ènìyàn, bí kò ṣe nípasẹ̀ “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” Jésù Kristi Ọba, pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn ‘àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run,’ títí kan àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró tí a jíǹde. “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa” yóò mú ìdájọ́ ṣẹ jálẹ̀jálẹ̀ ju bí àwọn ará Róòmù ti ṣe ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa lọ. Yóò mú gbogbo ẹ̀dá ènìyàn alátakò Ọlọ́run kúrò—àwọn ọba, àwọn olórí ogun, àwọn òmìnira àti ẹrú, àwọn ẹni kékeré àti ẹni ńlá. Kódà àwọn ètò àjọ ẹ̀dá ènìyàn ti ayé Sátánì pàápàá yóò lọ sópin.—Ìṣípayá 2:26, 27; 17:14; 19:11-21; Jòhánù Kìíní 5:19.
22. Ọ̀nà míràn wo ni a óò fi gba “ẹran ara” là?
22 Rántí pé a óò ti gba “ẹran ara” ti àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá” là, nígbà tí Bábílónì Ńlá bá yára kánkán parun pátápátá nínú apá àkọ́kọ́ ìpọ́njú ńlá náà. Bákan náà nínú apá ìkẹyìn ìpọ́njú náà, a óò gba “ẹran ara” tí ó ti sá lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà là. Ẹ wo bí èyí yóò ṣe yàtọ̀ tó sí àbájáde àwọn Júù ọlọ̀tẹ̀ ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa!
23. Kí ni “ẹran ara” tí ó bá fẹ́ là á já lè máa wọ̀nà fún?
23 Ní ríronú lórí ṣíṣeé ṣe ọjọ́ ọ̀la rẹ àti ti àwọn olólùfẹ́ rẹ, kíyè sí ohun tí a ṣèlérí nínú Ìṣípayá 7:16, 17 pé: “Ebi kì yóò pa wọ́n mọ́ bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọ́n tàbí ooru èyíkéyìí tí ń jóni gbẹ, nítorí Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí ó wà ní àárín ìtẹ́ náà, yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, yóò sì máa fi wọ́n mọ̀nà lọ sí àwọn ìsun omi ìyè. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” Dájúdájú, ìyẹn gan-an ni ‘gbígbani là’ lọ́nà àgbàyanu, tí yóò wà pẹ́ títí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Josephus sọ pé: “Nígbà tí Titus wọlé, okun ìlú náà mú kí háà ṣe é . . . Ó kígbe ní ohùn rara pé: ‘Ọlọ́run wà ní ìhà ọ̀dọ̀ wa; Ọlọ́run ni ó sọ àwọn Júù kalẹ̀ láti orí àwọn odi agbára wọ̀nyí; àbí kí ni ọwọ́ tàbí irin iṣẹ́ ẹ̀dá ènìyàn lè ṣe fún irú àwọn ilé ìṣọ́ wọ̀nyí?’”
c Ó dùn mọ́ni pé, ẹsẹ ìwé mímọ́ Shem-Tob ti Mátíù 24:22 lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà ʽa·vurʹ, èyí tí ó túmọ̀ sí “nítorí, ní tìtorí, kí a baà lè.”—Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, ojú ìwé 13.
d Wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1994, ojú ìwé 11 àti 12, àti ṣáàtì tí ó wà ní ojú ìwé 14 àti 15, èyí tí ó to èsì alásọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ, tí a rí nínú Mátíù orí 24, Máàkù orí 13, àti Lúùkù orí 21, sí òpó ìlà tí ó fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.
e Wo Revelation—Its Grand Climax At Hand!, ojú ìwé 235 sí 258, tí a tẹ̀ jáde ní 1988 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Apá méjì wo ni ìkọlù tí àwọn ará Róòmù ṣe sórí Jerúsálẹ́mù ní?
◻ Èé ṣe tí kò fi lè jẹ́ pé 97,000 Júù olùlàájá ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa ni ó para pọ̀ jẹ́ “ẹran ara” tí a mẹ́nu kàn nínú Mátíù 24:22?
◻ Báwo ni a ṣe ké ọjọ́ ìpọ́njú Jerúsálẹ́mù kúrú, báwo sì ni a ṣe tipa bẹ́ẹ̀ gba “ẹran ara” là?
◻ Nínú ìpọ́njú ńlá tí ń sún mọ́lé, báwo ni a óò ṣe ké àwọn ọjọ́ náà kúrú tí a óò sì gba “ẹran ara” là?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Owó tí àwọn Júù rọ lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ náà. Àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà sọ pé “Ọdún kejì,” tí ó túmọ̀ sí ọdún 67 Sànmánì Tiwa, ọdún kejì òmìnira wọn
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Owó tí àwọn ará Róòmù rọ ní ọdún 71 Sànmánì Tiwa. Ará Róòmù kan tí ó dira ogun ni ó wà ní apá òsì; obìnrin Júù kan tí ń ṣọ̀fọ̀ ni ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún. Ọ̀rọ̀ náà IVDAEA CAPTA túmọ̀ sí “Ìgbèkùn Jùdíà”
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.