“Nǹkan Wọ̀nyí Gbọ́dọ̀ Ṣẹlẹ̀”
“Jésù wí fún wọn pé: ‘. . . Nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe ìsinsìnyí.’”—MÁTÍÙ 24:4-6.
1. Kókó ẹ̀kọ́ wo ló yẹ kó gba àfiyèsí wa?
ÓDÁJÚ pé ọ̀ràn ìgbésí ayé rẹ àti ọjọ́ ọ̀la rẹ jẹ ẹ́ lọ́kàn. Nígbà náà, ó yẹ kóo nífẹ̀ẹ́ nínú kókó ẹ̀kọ́ kan tó gba àfiyèsí C. T. Russell nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lọ́dún 1877. Russell, tó wá dá ẹgbẹ́ Watch Tower Society sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ló kọ ìwé náà, The Object and Manner of Our Lord’s Return. Ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta yìí dá lórí ìpadàbọ̀ Jésù, tàbí bíbọ̀ Jésù ní ọjọ́ iwájú. (Jòhánù 14:3) Nígbà kan tí Jésù wà lórí Òkè Ólífì, àwọn àpọ́sítélì lọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ìpadàbọ̀ náà, wọ́n bi í pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ [tàbí, “wíwá,” King James Version] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”—Mátíù 24:3.
2. Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ èrò tó ta kora fi wà nípa ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀?
2 Ǹjẹ́ o mọ ìdáhùn Jésù, ǹjẹ́ ìdáhùn náà yé ọ? A lè rí i nínú mẹ́ta lára àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ọ̀jọ̀gbọ́n D. A. Carson sọ pé: “Gbogbo àwọn orí Bíbélì tó fa awuyewuye láàárín àwọn alálàyé Bíbélì kò tó nǹkan kan rárá táa bá fi wọ́n wé awuyewuye tí Mátíù orí kẹrìnlélógún, Máàkù orí kẹtàlá àti Lúùkù orí kọkànlélógún fà.” Lẹ́yìn náà, ọ̀jọ̀gbọ́n yìí wá sọ èrò tirẹ̀—tó tún jẹ́ òmíràn nínú àwọn èrò èèyàn tó máa ń takora. Ní ọ̀rúndún tó kọjá yìí, ọ̀pọ̀ irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ ló ti fi àìnígbàgbọ́ hàn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní irú èrò bẹ́ẹ̀ ló gbà pé Jésù kò fìgbà kankan sọ ohun táa kà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere, wọ́n ní lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn la yí ohun tó sọ padà, wọ́n ní tàbí kó jẹ́ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kò ṣẹ—àwọn aṣelámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ ló gbé àwọn èrò wọ̀nyí kalẹ̀. Alálàyé kan tilẹ̀ wo ìwé Ìhìn Rere Máàkù ‘lọ́nà tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn ẹlẹ́sìn Mahayanaa, tó jẹ́ ẹ̀ya ẹ̀sìn Búdà gbà wò ó’!
3. Ojú wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo àsọtẹ́lẹ̀ Jésù?
3 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka Bíbélì sí ìwé tó kún fún òótọ́, tó sì ṣeé gbára lé, títí kan ohun tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Òkè Ólífì nígbà tó ku ọjọ́ mẹ́ta tí yóò kú. Láti ìgbà ayé C. T. Russell, òye àwọn ènìyàn Ọlọ́run nípa àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ níbẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti mú kí òye wọn nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí túbọ̀ ṣe kedere sí i. Ǹjẹ́ ìsọfúnni wọ̀nyẹn ti wọnú ọpọlọ rẹ dáadáa, tóo sì ti rí ipa rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ?a Ẹ jẹ́ a gbé e yẹ̀ wò nígbà náà.
Ìmúṣẹ Kíkàmàmà Kan Tí Yóò Ṣẹlẹ̀ Láìpẹ́
4. Èé ṣe tí àwọn àpọ́sítélì fi lè béèrè ìbéèrè nípa ọjọ́ ọ̀la lọ́wọ́ Jésù?
4 Àwọn àpọ́sítélì mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà náà. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbọ́ tó ń sọ nípa ikú rẹ̀, àjíǹde rẹ̀, àti ìpadàbọ̀ rẹ̀, wọ́n ti lè máa kọminú pé, ‘Bí Jésù bá ní láti kú, kó tún padà lọ, báwo ni yóò ṣe wá ṣe àwọn nǹkan àgbàyanu táa ń retí pé kí Mèsáyà ṣe?’ Ní àfikún sí i, Jésù sọ nípa òpin Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀. Àwọn àpọ́sítélì náà ti lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ìgbà wo nìyẹn máa ṣẹlẹ̀, báwo ló sì ṣe máa ṣẹlẹ̀?’ Níbi tí àwọn àpọ́sítélì ti ń gbìyànjú àtilóye èyí ni wọ́n ti béèrè pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì ìgbà tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá sí ìparí?”—Máàkù 13:4; Mátíù 16:21, 27, 28; 23:37–24:2.
5. Báwo ni ohun tí Jésù sọ ṣe nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?
5 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun yóò jà, ìyàn yóò mú, àjàkálẹ̀ àrùn, ìsẹ̀lẹ̀, ìkórìíra yóò wà, àwọn èèyàn yóò máa ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni, àwọn mèsáyà èké yóò lọ bí rẹ́rẹ, iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà yóò sì tàn kálẹ̀. Nígbà náà ni òpin yóò sì dé. (Mátíù 24:4-14; Máàkù 13:5-13; Lúùkù 21:8-19) Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni Jésù sọ nǹkan wọ̀nyí. Ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún tó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n wà lójúfò lè rí i pé àwọn ohun tó sọ ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó pàfiyèsí gan-an. Àní, ìtàn jẹ́rìí sí i pé àmì náà nímùúṣẹ lákòókò yẹn, èyí tó sì yọrí sí òpin ètò àwọn nǹkan àwọn Júù látọwọ́ àwọn ará Róòmù lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Tiwa. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?
6. Kí ló ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ará Róòmù àti àwọn Júù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa?
6 Lákòókò tí ọ̀gbẹlẹ̀ ń jà gan-an lágbègbè Jùdíà lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, Àwọn Júù Onítara Ẹ̀sìn kọ lu àwọn ọmọ ogun ẹ̀ṣọ́ Róòmù tí wọ́n wà lágọ̀ọ́ wọn tó wà nítòsí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, ni rògbòdìyàn bá bẹ́ sílẹ̀ láwọn àgbègbè kan nílẹ̀ náà. Nínú ìwé náà, History of the Jews, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Heinrich Graetz ṣe, ó ròyìn pé: “Cestius Gallus tó jẹ́ pé òun ni Gómìnà Síríà, tó sì ní láti gbé agbára Róòmù lárugẹ, . . . kò lè fọwọ́ lẹ́rán mọ́ kò máa wo bí ọ̀tẹ̀ ṣe ń tàn kálẹ̀ lágbègbè rẹ̀ láìwá nǹkan ṣe sí i. Ó pe àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jọ, àwọn alákòóso àgbègbè tó wà nítòsí sì fi àwọn ọmọ ogun wọn ránṣẹ́ sí i.” Ni ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun [30,000] bá yí Jerúsálẹ́mù ká. Lẹ́yìn ìjà díẹ̀, làwọn Júù bá sá padà sẹ́yìn ògiri tó wà nítòsí tẹ́ńpìlì. “Láàárín ọjọ́ márùn-ún tó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ ogun Róòmù gbẹ́ ògiri náà, ṣùgbọ́n ohun ìjà tí àwọn ará Jùdíà ń jù sí wọn mú kí wọ́n máa sá sẹ́yìn. Ọjọ́ kẹfà nìkan ṣoṣo ni wọ́n tó kẹ́sẹ járí láti dá àlàfo lu sára ògiri ìhà àríwá tó wà níwájú Tẹ́ńpìlì.”
7. Èé ṣe tí èrò àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi yàtọ̀ pátápátá sí ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù?
7 Tiẹ̀ ronú nípa bí ọkàn àwọn Júù yóò ti dàrú tó, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n ti ń rò ó lọ́kàn tipẹ́tipẹ́ pé Ọlọ́run yóò dáàbò bò wọ́n, tí yóò tún dáàbò bo ìlú mímọ́ wọn! Ṣùgbọ́n, a ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pé àjálù ńlá yóò já lu Jerúsálẹ́mù. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé bá ọ, nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ ká, wọn yóò sì ká ọ mọ́, wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo, wọn yóò sì fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tí ń bẹ nínú rẹ mọ́lẹ̀, wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ.” (Lúùkù 19:43, 44.) Ṣùgbọ́n, ṣé ìyẹn yóò mú ikú wá sórí àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa ni?
8. Ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá wo ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀, àwọn wo sì ni “àwọn àyànfẹ́” táa tìtorí wọn ké àwọn ọjọ́ wọnnì kúrú?
8 Nígbà tí Jésù ń fèsì ìbéèrè àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lórí Òkè Ólífì, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọjọ́ wọnnì yóò jẹ́ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú irúfẹ́ èyí ti kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá tí Ọlọ́run dá títí di àkókò yẹn, kì yóò sì tún ṣẹlẹ̀ mọ́. Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé Jèhófà ké àwọn ọjọ́ náà kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là. Ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́ tí ó ti yàn, ó ti ké àwọn ọjọ́ náà kúrú.” (Máàkù 13:19, 20; Mátíù 24:21, 22) Nítorí náà, a óò ké àwọn ọjọ́ náà kúrú, a óò sì gba “àwọn àyànfẹ́” là. Àwọn wo làyànfẹ́? Dájúdájú, kì í ṣe àwọn Júù ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n sọ páwọn ń jọ́sìn Jèhófà ṣùgbọ́n tí wọ́n kọ Ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. (Jòhánù 19:1-7; Ìṣe 2:22, 23, 36) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn àyànfẹ́ ni àwọn Júù àti àwọn tí kì í ṣe Júù tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà àti Olùgbàlà. Ọlọ́run yan irú àwọn bẹ́ẹ̀, nígbà tó sì di ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, ó sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè tuntun nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 6:16; Lúùkù 18:7; Ìṣe 10:34-45; 1 Pétérù 2:9.
9, 10. Báwo la ṣe “ké” àwọn ọjọ́ tí àwọn ará Róòmù fi kọ lu Jerúsálẹ́mù “kúrú,” kí ló sì yọrí sí?
9 Ǹjẹ́ a “ké àwọn ọjọ́ náà kúrú,” tí a sì gba àwọn àyànfẹ́ tó wà ní Jerúsálẹ́mù là? Ọ̀jọ̀gbọ́n Graetz sọ pé: “[Cestius Gallus] rí i pé pẹ̀lú bójú ọjọ́ ti rí nígbà yẹn kò bọ́gbọ́n mu láti máa bá ìjà táwọn ń bá àwọn tó ti gbékútà jà nìṣó, torí pé ìgbà òjò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé . . . tí kò sì ní ṣáǹfààní láti máa kó ohun táwọn ọmọ ogun nílò fún wọn. Ó ní láti jẹ́ pé tìtorí ìyẹn ló fi ronú pé ó kúkú sàn jù káwọn padà sílé.” Ohun yòówù tó lè wà lọ́kàn Cestius Gallus, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kógun wọn kúrò nílùú náà, àwọn Júù tí ń lépa wọn sì ṣe wọ́n bọ́ṣẹ́ ṣe ń ṣojú.
10 Kíkógun tí àwọn ará Róòmù kógun wọn lọ lọ́nà yíyani lẹ́nu fàyè gba “ẹran ara”—ìyẹn ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n ti há sí Jerúsálẹ́mù—láti rí ìgbàlà. Ìtàn fi yéni pé bí ilẹ̀kùn àǹfààní yìí ti ṣí sílẹ̀, làwọn Kristẹni ti sá kúrò lágbègbè náà. Ẹ wo bí agbára Ọlọ́run láti mọ ọjọ́ ọ̀la ti pọ̀ tó, ẹ sì wo bó ti lágbára tó láti rí i pé àwọn tí ń jọ́sìn òun rí ìgbàlà! Síbẹ̀, kí ni nípa àwọn Júù aláìgbàgbọ́ tí wọ́n ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà?
Àwọn Alájọgbáyé Yóò Rí I
11. Kí ni Jésù sọ nípa “ìran yìí”?
11 Ọ̀pọ̀ Júù ló gbà gbọ́ pé ọ̀nà ìgbàjọ́sìn wọn, èyí tí wọ́n gbé ka lílọ sí tẹ́ńpìlì, yóò máa bá a lọ títí ayé. Ṣùgbọ́n Jésù wí pé: “Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ . . . yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ . . . pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ìran yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀. Ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà.”—Mátíù 24:32-35.
12, 13. Kí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn lóye pé ó jẹ́ “ìran yìí” tí Jésù sọ nípa rẹ̀?
12 Ní àwọn ọdún tó ṣáájú ọdún 66 Sànmánì Tiwa, ó dájú pé àwọn Kristẹni yóò ti rí ìmúṣẹ ọ̀pọ̀ ẹ̀ka àmì alápá púpọ̀ náà—ogun, ìyàn, àní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà lọ́nà gbígbòòrò pàápàá. (Ìṣe 11:28; Kólósè 1:23) Ṣùgbọ́n, nígbà wo ni òpin náà yóò dé? Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: ‘Ìran yìí [ge·ne·aʹ lédè Gíríìkì] kì yóò kọjá lọ’? Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti pe àwọn Júù alátakò tí wọ́n jẹ́ alájọgbáyé rẹ̀, títí kan àwọn aṣáájú ìsìn, ní ‘ìran burúkú onípanṣágà.’ (Mátíù 11:16; 12:39, 45; 16:4; 17:17; 23:36) Nítorí náà, nígbà tó wà lórí Òkè Ólífì, tó tún sọ nípa “ìran yìí,” ó dájú pé kì í ṣe gbogbo ìran àwọn Júù jálẹ̀ ìtàn ló ní lọ́kàn; kì í sì í ṣe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ “ẹ̀yà àyànfẹ́.” (1 Pétérù 2:9) Jésù kò sì tún sọ pé “ìran yìí” jẹ́ àkókò kan pàtó.
13 Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Júù alátakò ni Jésù ní lọ́kàn, àwọn tó jẹ́ pé nígbà náà lọ́hùn-ún wọ́n rí ìmúṣẹ àmì tó fún wọn. Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Joel B. Green ń sọ̀rọ̀ nípa ìtọ́kasí tó wà lórí “ìran yìí” nínú Lúùkù 21:32, ó sọ pé: “Nínú ìwé Ìhìn Rere Kẹta, ‘ìran yìí’ (àti àwọn ọ̀rọ̀ tó tan mọ́ ọn) sábà máa ń dúró fún àwùjọ èèyàn kan tí wọ́n lòdì sí ète Ọlọ́run. . . . [Ó ń tọ́ka] sáwọn èèyàn tí oríkunkun mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí ète Ọlọ́run.”b
14. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí “ìran” yẹn, ṣùgbọ́n kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni?
14 Ìran búburú, ìran àwọn Júù alátakò tí wọ́n rí àmì náà tó nímùúṣẹ ni yóò tún rí òpin náà. (Mátíù 24:6, 13, 14) Wọ́n sì rí i lóòótọ́! Lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ogun Róòmù padà wá, Titus, ọmọ Olu Ọba Vespasian, ló kó wọn wá. Ìyà tó jẹ àwọn Júù tí wọ́n ká mọ́nú ìlú náà kò ṣeé fẹnu sọ.c Flavius Josephus tó fojú ara rẹ̀ rí ohun tó ṣẹlẹ̀ ròyìn pé nígbà tí àwọn ará Róòmù fi máa pa ìlú náà run, nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùndínlọ́gọ́ta Júù [1,100,000] ló ti kú, wọ́n sì ti kó nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] nígbèkùn, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn lebi máa tó pa kú tàbí kí wọ́n kú sínú gbọ̀ngàn ìwòran àwọn ará Róòmù. Lóòótọ́, ìpọ́njú tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 66 sí 70 Sànmánì Tiwa ni èyí tó burú jù lọ nínú ìtàn Jerúsálẹ́mù àti ètò àwọn Júù, kò sì tún sírú ẹ̀ mọ́ nínú ìtàn wọn. Ẹ wá wo bí ìyọrísí rẹ̀ ti yàtọ̀ tó fáwọn Kristẹni tí wọ́n ti kọbi ara sí ìkìlọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jésù, tí wọ́n sì sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Róòmù kógun wọn lọ lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa! Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “àwọn àyànfẹ́” ni a “gbà là,” tàbí ni a pa mọ́, lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa.—Mátíù 24:16, 22.
Ìmúṣẹ Mìíràn Tí Ń Bọ̀ Lọ́nà
15. Báwo la ṣe lè ní ìdánilójú pé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù yóò nímùúṣẹ tó tóbi ju ti ọdún 70 Sànmánì Tiwa?
15 Ṣùgbọ́n, kò pin síbẹ̀ yẹn. Ṣáájú, Jésù ti fi hàn pé lẹ́yìn tí a bá ti pa ìlú náà run, òun yóò wá lórúkọ Jèhófà. (Mátíù 23:38, 39; 24:2) Ó túbọ̀ mú èyí ṣe kedere nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tó sọ lórí Òkè Ólífì. Lẹ́yìn tó ti mẹ́nu kan “ìpọ́njú ńlá,” ó wí pé lẹ́yìn náà àwọn èké Kristi yóò fara hàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀ fún àkókò gígùn. (Mátíù 24:21, 23-28; Lúùkù 21:24) Ó ha lè jẹ́ pé, ìmúṣẹ mìíràn, tó tún tóbi ju ti ìṣáájú lọ ṣì ń bọ̀? Àwọn kókó táa rí fi hàn pé bẹ́ẹ̀ ni. Báa bá fi Ìṣípayá 6:2-8 (tí a kọ lẹ́yìn ìpọ́njú tó dé bá Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa) wé Mátíù 24:6-8 àti Lúùkù 21:10, 11, a óò rí i pé ogun, ọ̀wọ́n oúnjẹ, àti àjàkálẹ̀ àrùn yóò ṣì ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lọ́nà tó pọ̀ ju ti ìṣáájú. Ìmúṣẹ títóbi jù yìí tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ti ń ṣẹlẹ̀ láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní tó jà lọ́dún 1914.
16-18. Kí là ń retí pé kó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́?
16 Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún báyìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ni pé ìmúṣẹ àmì náà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ń fi hàn pé “ìpọ́njú ńlá” kò tí ì dé. “Ìran” búburú ti ìsinsìnyí yóò rí ìpọ́njú yẹn. Ó jọ pé ìpọ́njú náà yóò ní bí yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ (kíkọlu gbogbo ìsìn èké), gẹ́gẹ́ bí Gallus ṣe kọ lu Jerúsálẹ́mù lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, tí ìyẹn sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú lórí ìlú ńlá náà.d Lẹ́yìn náà, nígbà tí àkókò kan tí a kò sọ bí yóò ti gùn tó bá parí, òpin náà yóò dé—ìparun jákèjádò ayé, tí yóò jọ ti ọdún 70 Sànmánì Tiwa.
17 Nígbà tí Jésù ń tọ́ka sí ìpọ́njú tó wà gẹ́rẹ́ níwájú wa, ó wí pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọnnì [ìparun ìsìn èké], oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára ọ̀run ni a ó sì mì. Nígbà náà sì ni àmì Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.”—Mátíù 24:29, 30.
18 Abájọ́ tí Jésù fúnra rẹ̀ fi sọ pé “lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọnnì,” onírúurú ohun mérìíyìírí ti ojú ọ̀run yóò máa ṣẹlẹ̀. (Fi wé Jóẹ́lì 2:28-32; 3:15.) Èyí yóò mú àwọn aláìgbọràn ta gìrì, yóò sì kó jìnnìjìnnì bá wọn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn yóò fi “lu ara wọn nínú ìdárò.” Ọ̀pọ̀ yóò sì “kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti ìfojúsọ́nà fún àwọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” Ṣùgbọ́n kò ní rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn Kristẹni tòótọ́! Àwọn wọ̀nyí ‘yóò gbé orí wọn sókè, nítorí pé ìdáǹdè wọn ń sún mọ́lé.’—Lúùkù 21:25, 26, 28.
Ìdájọ́ Wà Níwájú!
19. Báwo la ṣe lè fìdí ìgbà tí àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò nímùúṣẹ múlẹ̀?
19 Ṣàkíyèsí pé Mátíù 24:29-31 sọ tẹ́lẹ̀ pé (1) Ọmọ ènìyàn yóò wá, (2) wíwá yìí yóò jẹ́ pẹ̀lú ògo ńlá, (3) àwọn áńgẹ́lì yóò bá a wá, àti pé (4) gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé ni yóò rí i. Jésù tún àwọn nǹkan wọ̀nyí sọ nínú àkàwé tó ṣe nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́. (Mátíù 25:31-46) Nítorí náà, a lè parí èrò sí pé àkàwé yìí ní í ṣe pẹ̀lú àkókò náà, ìyẹn ni lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ́ sílẹ̀, nígbà tí Jésù yóò wá pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, tí yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́. (Jòhánù 5:22; Ìṣe 17:31; fi wé 1 Àwọn Ọba 7:7; Dáníẹ́lì 7:10, 13, 14, 22, 26; Mátíù 19:28.) Àwọn wo la ó dá lẹ́jọ́, kí ni yóò sì yọrí sí? Àkàwé náà fi hàn pé Jésù yóò darí àfiyèsí sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, bí ẹni pé wọ́n pé jọ síwájú ìtẹ́ rẹ̀ lókè ọ̀run.
20, 21. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn àgùntàn inú àkàwé Jésù? (b) Kí ni ojú àwọn ewúrẹ́ yóò rí lọ́jọ́ iwájú?
20 Jésù yóò ya àwọn ẹni bí àgùntàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sọ́tọ̀ sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, yóò fojú rere hàn sí wọn. Èé ṣe? Nítorí tí wọ́n ti lo àwọn àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣoore fún àwọn arákùnrin rẹ̀—àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọn yóò nípìn-ín nínú Ìjọba Kristi lókè ọ̀run. (Dáníẹ́lì 7:27; Hébérù 2:9–3:1) Ní ìbámu pẹ̀lú àkàwé náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni ẹni bí àgùntàn ti mọ ipò tí àwọn arákùnrin Jésù nípa tẹ̀mí wà, wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ní ìrètí tí a gbé ka Bíbélì, ìyẹn ni ti líla “ìpọ́njú ńlá náà” já, àti ìrètí wíwà láàyè títí láé nínú Párádísè, àgbègbè àkóso Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 7:9, 14; 21:3, 4; Jòhánù 10:16.
21 Ohun tó máa yọrí sí fáwọn ewúrẹ́ yóò mà yàtọ̀ pátápátá o! A ṣàpèjúwe wọn nínú Mátíù 24:30 pé nígbà tí Jésù dé, ṣe ni ‘wọ́n ń lu ara wọn nínú ìdárò.’ Bó ṣe yẹ kó rí fún wọn nìyẹn, nítorí yóò ti wà lákọọ́lẹ̀ pé wọ́n kọ etí ikún sí ìhìn rere Ìjọba náà, pé wọ́n ṣàtakò sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àti pé wọ́n fẹ́ràn ayé tó ń kọjá lọ ju Kristi. (Mátíù 10:16-18; 1 Jòhánù 2:15-17) Jésù ló mọ ẹni tó jẹ́ ewúrẹ́ o, kò sí ìkankan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé tó mọ̀ wọ́n. Nípa àwọn ewúrẹ́, ó sọ pé: “Àwọn wọ̀nyí yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:46.
22. Apá wo nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ló yẹ ká túbọ̀ gbé yẹ̀ wò?
22 Ìtẹ̀síwájú wa nínú lílóye àsọtẹ́lẹ̀ inú Mátíù orí kẹrìnlélógún àti ìkarùndínlọ́gbọ̀n ti mú inú wa dùn jọjọ. Ṣùgbọ́n, apá kan tún wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó yẹ ká fiyè sí gidigidi—“ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́.” Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti fòye mọ èyí, kí wọ́n sì múra tán láti gbégbèésẹ̀. (Mátíù 24:15, 16) Kí ni “ohun ìríra” yìí? Ìgbà wo ló dúró ní ibi mímọ́? Báwo ló sì ṣe kan ìgbésí ayé wa nísinsìnyí àti ìrètí wa ọjọ́ ọ̀la? Àpilẹ̀kọ tó tẹ lé e yóò la ọ̀rọ̀ yìí lẹ́sẹẹsẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwọn àpilẹ̀kọ táa ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti February 15, 1994; October 15 àti November 1, 1995; pẹ̀lú ti August 15, 1996.
b Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, G. R. Beasley-Murray, sọ pé: “Kò yẹ kí ọ̀rọ̀ náà “ìran yìí” fa ìṣòro fún àwọn alálàyé Bíbélì rárá. Níwọ̀n ìgbà táa ti gbà pé nínú ìtumọ̀ Gíríìkì ìgbàanì genea túmọ̀ sí ìbímọ, irú-ọmọ, tó sì lè wá túmọ̀ sí ìran, . . . nínú ìtumọ̀ [ti Gíríìkì Septuagint] a sábà ń túmọ̀ rẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Hébérù náà, dôr, tó túmọ̀ sí sànmánì, sànmánì ìran ènìyàn, tàbí ìran ní ìtumọ̀ ti àwọn alájọgbáyé. . . . Nínú àwọn ọ̀rọ̀ táa sọ pé Jésù sọ, ó dà bí ẹni pé ọ̀rọ̀ náà nítumọ̀ méjì: lọ́nà kan ó máa ń tọ́ka sí àwọn alájọgbáyé rẹ̀, lọ́nà kejì ẹ̀wẹ̀ ó sábà máa ń túmọ̀ sí ọ̀rọ̀ ìbániwí.”
c Nínú ìwé náà, History of the Jews, Ọ̀jọ̀gbọ́n Graetz sọ pé àwọn ará Róòmù nígbà mìíràn máa ń kan ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ẹlẹ́wọ̀n mọ́gi lọ́jọ́ kan ṣoṣo. Wọ́n gé ọwọ́ àwọn Júù mìíràn tí wọ́n kó lẹ́rú sọnù, wọ́n sì dá wọn padà sínú ìlú. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ìlú? “Owó wọn kò nìyí mọ́, nítorí kò tóó ra búrẹ́dì lásán. Àwọn ọkùnrin ǹ ja ìjà àjàkú akátá lójú pópó nítorí oúnjẹ ẹ̀gbin, tó ń ríni lára, ẹ̀kúnwọ́ koríko gbígbẹ, awọ pélébé, tàbí ìjàǹjá ẹran tí wọ́n jù fún ajá. . . . Àwọn òkú tí wọn kò rẹ́ni sin tí ń pọ̀ sí i ṣáá ń mú kí atẹ́gùn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn máa tan àrùn kálẹ̀, àìsàn dá àwọn èèyàn wólẹ̀, ìyàn mú, wọ́n sì ti ipa idà ṣubú.”
d Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e jíròrò apá yìí nípa ìpọ́njú tí ń bọ̀ náà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Ìmúṣẹ wo ni Mátíù 24:4-14 ní lọ́rùn-úndún kìíní?
◻ Nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, báwo la ṣe ké àwọn ọjọ́ kúrú tí a sì gba ẹran ara là, gẹ́gẹ́ bí Mátíù 24:21, 22 ṣe sọ tẹ́lẹ̀?
◻ Báwo la ṣe lè dá “ìran” tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Mátíù 24:34 mọ̀?
◻ Báwo la ṣe mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ táa sọ lórí Òkè Ólífì yóò tún ní ìmúṣẹ mìíràn, tó tóbi ju ti ìṣáájú lọ?
◻ Nígbà wo ni àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ yóò nímùúṣẹ, báwo ni yóò sì ṣe nímùúṣẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwòrán tó wà lára Òbíríkítí Titus ní Róòmù, tó ń fi àwọn ohun ìfiṣèjẹ tó la ìparun Jerúsálẹ́mù já hàn
[Credit Line]
Soprintendenza Archeologica di Roma