A Gbà Wọ́n Là Láti Inú “Ìran Burúkú”
“Óò ìran aláìnígbàgbọ́ ati onímàgòmágó, bawo ni emi yoo ti máa bá a lọ pẹlu yín pẹ́ tó tí emi yoo sì máa faradà fún yín?”—LUKU 9:41.
1. (a) Kí ni àkókò alájàálù ibi jẹ́ àmì fún? (b) Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn olùlàájá?
ÀKÓKÒ alájàálù ibi ni a ń gbé. Ìmìtìtì ilẹ̀, omíyalé, ìyàn, àrùn, ìwà àìlófin, bọ́m̀bù jíjù, ogun akópayàbáni—àwọn wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ sí i ti bo aráyé mọ́lẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún wa yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, àjálù kíkàmàmà jù lọ tí ó tí ì ṣẹlẹ̀ rí ṣú dẹ̀dẹ̀ nínú ọjọ́ ọ̀la tí kò jìnnà mọ́. Kí nìyẹn? Ó jẹ́ “ìpọ́njú ńlá . . . irúfẹ́ èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ lati ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni [tí irú rẹ̀] kì yoo tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Matteu 24:21) Síbẹ̀, púpọ̀ lára wa lè máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀! Èé ṣe? Nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnra rẹ̀ júwe “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹni kankan kò lè kà, lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n . . . ‘Awọn wọnyi ni awọn tí wọ́n jáde wá lati inú ìpọ́njú ńlá naa . . . Ebi kì yoo pa wọ́n mọ́ bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yoo gbẹ wọ́n mọ́ . . . Ọlọrun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.’”—Ìṣípayá 7:1, 9, 14-17.
2. Ìmúṣẹ alásọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ wo ni àwọn ẹsẹ ìbẹ̀rẹ̀ Matteu 24, Marku 13, àti Luku 21 ní?
2 Àkọsílẹ̀ onímìísí ní Matteu 24:3-22, Marku 13:3-20, àti Luku 21:7-24 nasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ alápèjúwe tí Jesu sọ nípa “òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.”a Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́ lórí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan oníwà ìbàjẹ́ ti àwọn Júù ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, tí ó dé òtéńté rẹ̀ nínú “ìpọ́njú ńlá” aláìláfiwé, lórí àwọn Júù. A bi àpapọ̀ ètò ìsìn àti ìṣèlú ti ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù, tí a gbè kalẹ̀ sí tẹ́ḿpìlì Jerusalemu wó, tí a kì yóò sì mú un padà bọ̀ sípò láé.
3. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ kánjúkánjú pé ki a kọbi ara sí àsọtẹ́lẹ̀ Jesu lónìí?
3 Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ipò tí ó yí ìmúṣẹ àkọ́kọ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ká yẹ̀ wò. Èyí yóò túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìmúṣẹ tí ó bá a mu lónìí. Yóò fi hàn wá, bí ó ti jẹ́ kánjúkánjú tó, láti gbé ìgbésẹ̀ tí ó gbéṣẹ́ nísinsìnyí láti lè la ìpọ́njú kíkàmàmà jù lọ tí ó ṣú dẹ̀dẹ̀ sórí aráyé já.—Romu 10:9-13; 15:4; 1 Korinti 10:11; 15:58.
“Òpin”—Nígbà Wo?
4, 5. (a) Èé ṣe tí àwọn Júù olùbẹ̀rù Ọlọrun ní ọ̀rúndún kìíní C.E. fi lọ́kàn-ìfẹ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli 9:24-27? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ní ìmúṣẹ?
4 Ní nǹkan bí 539 B.C.E., a fi ìran àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò ṣẹlẹ̀ ní òpin “ọ̀sẹ̀” sáà “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” ọdún han Danieli, wòlíì Ọlọrun. (Danieli 9:24-27) “Àwọn ọ̀sẹ̀” wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ ní 455 B.C.E., nígbà tí Ọba Artasasta ti Persia pàṣẹ títún ìlú ńlá Jerusalemu kọ́. Òpin “ọ̀sẹ̀” náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfarahàn Messia, Jesu Kristi, nígbà batisí àti ìfòróróyàn rẹ̀ ní 29 C.E.b Àwọn Júù olùbẹ̀rù Ọlọrun ní ọ̀rúndún kìíní C.E., mọ apá àkókò yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli dunjú. Fún àpẹẹrẹ, Luku 3:15 sọ nípa ogunlọ́gọ̀ tí ń wọ́ tẹ̀ lé Johannu Oníbatisí ní 29 C.E., láti gbọ́ ìwàásù rẹ̀ pé: “Awọn ènìyàn naa ti wà ninu ìfojúsọ́nà tí gbogbo wọ́n sì ń gbèrò ninu ọkàn-àyà wọn nipa Johannu pé: ‘Àbí oun ni Kristi naa ni?’”
5 “Ọ̀sẹ̀” àádọ́rin náà ní láti jẹ́ ọdún méje ti ojú rere àkànṣe tí a nawọ́ rẹ̀ sí àwọn Júù. Ó bẹ̀rẹ̀ ní 29 C.E., ó ní batisí Jesu àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ikú ìrúbọ rẹ̀ “ní ìlàjì ọ̀sẹ̀ náà” ní 33 C.E., àti ‘ìlàjì ọ̀sẹ̀’ mìíràn tí ó parí sí 36 C.E nínú. Nínú “ọ̀sẹ̀” yìí, a nawọ́ àǹfààní dídi ẹni-àmì-òróró ọmọ ẹ̀yìn Jesu sí kìkì àwọn Júù olùbẹ̀rù Ọlọrun àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù. Lẹ́yìn náà, ní 70 C.E., àkókò kan tí a kò mọ̀ tẹ́lẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ogun Romu, lábẹ́ Titus, pa ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù apẹ̀yìndà run pátápátá.—Danieli 9:26, 27.
6. (a) Báwo ni “ìpọ́njú” tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 66 C.E., ṣe jẹ́ runlérùnnà tó? (b) Àwọn wo ni ó làájá, nítorí ìgbésẹ̀ kánjúkánjú wo sì ni?
6 A tipa báyìí pa ẹgbẹ́ àlùfáà àwọn Júù, tí ó ti sọ tẹ́ḿpìlì Jerusalemu di aláìmọ́, tí ó sì dìtẹ̀ nínú pípa Ọmọkùnrin Ọlọrun fúnra rẹ̀, run. A pa àwọn àkọsílẹ̀ orílẹ̀-èdè àti ti ẹ̀yà ìran run pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kò sí Júù kankan tí ó lè sọ lọ́nà tí ó bófin mu pé òun wá láti ìdílé àlùfáà tàbí ti ọba. Ṣùgbọ́n, a láyọ̀ pé a ti ya àwọn ẹni àmì òróró, àwọn Júù nípa tẹ̀mí sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àlùfáà aládé láti “polongo káàkiri awọn ìtayọlọ́lá” Jehofa Ọlọrun. (1 Peteru 2:9) Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Romu kọ́kọ́ sàga ti Jerusalemu, kódà wọ́n wa yàrà yí agbègbè tẹ́ḿpìlì náà ká ní 66 C.E., àwọn Kristian mọ ẹgbẹ́ ológun náà gẹ́gẹ́ bí “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nípasẹ̀ Danieli wòlíì.” Ní ṣíṣègbọràn sí àṣẹ alásọtẹ́lẹ̀ Jesu, àwọn Kristian ní Jerusalemu àti Judea sá lọ sí àwọn ẹkùn olókè fún ààbò.—Matteu 24:15, 16; Luku 21:20, 21.
7, 8. “Àmì” wo ni àwọn Kristian kíyè sí, ṣùgbọ́n kí ni wọn kò mọ̀?
7 Àwọn Júù Kristian olùṣòtítọ́ wọ̀nyẹn kíyè sí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Danieli, wọ́n sì fojú rí ogun bíbani lẹ́rù, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, ìmìtìtì ilẹ̀, àti ìwà àìlófin tí Jesu sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan “àmì . . . òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” (Matteu 24:3) Ṣùgbọ́n, Jesu ha sọ ìgbà tí Jehofa yóò múdàájọ́ ṣẹ lórí ètò ìgbékalẹ̀ oníwà ìbàjẹ́ náà gan-an fún wọn bí? Rárá o. Dájúdájú, ohun tí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa òtéńté wíwà níhìn-ín rẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la gẹ́gẹ́ bí ọba ní í ṣe pẹ̀lú “ìpọ́njú ńlá” ti ọ̀rúndún kìíní pé: “Níti ọjọ́ ati wákàtí yẹn kò sí ẹni kan tí ó mọ̀, kì í ṣe awọn áńgẹ́lì awọn ọ̀run tabi Ọmọkùnrin, bíkòṣe Baba nìkan.”—Matteu 24:36.
8 Láti inú àsọtẹ́lẹ̀ Danieli, àwọn Júù ti lè ṣírò àkókò ìfarahàn Jesu gẹ́gẹ́ bíi Messia. (Danieli 9:25) Síbẹ̀ a kò fún wọn ní àkókò kankan fún “ìpọ́njú ńlá” tí ó sọ ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù apẹ̀yìndà dahoro nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Kìkì lẹ́yìn ìparun Jerusalemu àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ ni wọ́n tó mọ̀ pé 70 C.E. ni àkókò náà. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n ti mọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jesu pé: “Ìran yii kì yoo kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹlẹ̀.” (Matteu 24:34) Ó hàn gbangba pé, ìlò “ìran” níhìn-ín yàtọ̀ sí èyí tí ó wà ní Oniwasu 1:4, tí ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìran títẹ̀léra, tí ń lọ, tí ń bọ̀, jálẹ̀ sáà àkókò kan.
“Ìran Yìí”—Kí Ni?
9. Báwo ni àwọn ìwé atúmọ̀ èdè ṣe túmọ̀ ọ̀rọ̀ Griki náà, ge·ne·aʹ?
9 Nígbà tí àwọn aposteli mẹ́rin tí wọ́n jókòó sọ́dọ̀ Jesu lórí Òkè Olifi gbọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí nípa “òpin ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan,” kí ni wọn yóò lóye gbólóhùn náà “ìran yìí” sí? Nínú Ìhìn Rere, a túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìran,” láti inú ọ̀rọ̀ Griki náà, ge·ne·aʹ, tí àwọn ìwé atúmọ̀ èdè tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe túmọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ní òwuuru àwọn tí ó wá láti ọ̀dọ̀ babańlá kan náà.” (Greek-English Lexicon of the New Testament ti Walter Bauer) “Èyí tí a ti sọ dọmọ, ìdílé kan; . . . àwọn mẹ́ḿbà àtẹ̀lé ìran kan . . . tàbí ẹ̀yà ìran àwọn ènìyàn kan . . . tàbí ti gbogbo ògìdìgbó ènìyàn tí ń gbé ní àkókò kan náà, Matt. 24:34; Marku 13:30; Luku 1:48; 21:32; Fil. 2:15, àti ní pàtàkì, ti àwọn ẹ̀yà Júù tí ń gbé ní sáà àkókò kan náà.” (Expository Dictionary of New Testament Words ti W. E. Vine) “Èyí tí a ti sọ dọmọ, àwọn ènìyàn irú kan náà, ìdílé kan; . . . gbogbo ògìdìgbó ènìyàn tí ń gbé ní àkókò kan náà: Mt. xxiv. 34; Mk. xiii. 30; Lk. i. 48 . . . a ń lò ó ní pàtàkì fún ẹ̀yà ìran àwọn Júù tí ń gbé ní sáà kan náà.”—Greek-English Lexicon of the New Testament ti J. H. Thayer.
10. (a) Ìtumọ̀ méjì tí ó jọra wo ni àwọn aláṣẹ méjì fúnni ní Matteu 24:34? (b) Báwo ni ìwé atúmọ̀ èdè ẹ̀kọ́ ìsìn kan àti àwọn ìtumọ̀ Bibeli kan ṣe ti ìtumọ̀ yìí lẹ́yìn?
10 Nípa báyìí, Vine àti Thayer tọ́ka sí Matteu 24:34 ní títúmọ̀ “ìran yìí” (he ge·ne·aʹ hauʹte) gẹ́gẹ́ bíi “gbogbo ògìdìgbó ènìyàn tí ń gbé ní àkókò kan náà.” Ìwé atúmọ̀ èdè Theological Dictionary of the New Testament (1964) kín ìtumọ̀ yìí lẹ́yìn, ní sísọ pé: “Bí Jesu ṣe lo ‘ìran’ fi ète gbígbòòrò rẹ̀ hàn: ó ní gbogbo ènìyàn náà lọ́kàn, àti pé, ó mọ ẹ̀ṣẹ̀ àjùmọ̀dá wọn dunjú.” Ní tòótọ́, “ẹ̀ṣẹ̀ àjùmọ̀dá” hàn gbangba ní orílẹ̀-èdè Júù nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀ ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sàmì sí ètò ìgbékalẹ̀ ayé lónìí.c
11. (a) Ní pàtàkì, ọlá àṣẹ wo ni ó yẹ kí ó ṣamọ̀nà wa láti pinnu bí a ṣe ní láti lo he ge·ne·aʹ hauʹte? (b) Báwo ni ọlá àṣẹ yìí ṣe lo ọ̀rọ̀ náà?
11 Àmọ́ ṣáá o, bí àwọn òǹkọ̀wé Ìròyìn Rere tí a mí sí ṣe lo gbólóhùn Griki náà he ge·ne·aʹ hauʹte, tàbí “ìran yìí,” ní ríròyìn àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ni àwọn Kristian tí ń kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí ní pàtàkì ní láti darí ìrònú wọn sí. Ó lò gbólóhùn náà déédéé lọ́nà tí kò bára dé. Nípa bẹ́ẹ̀, Jesu pe àwọn aṣáájú ìsìn Júù ní “ejò, àmújáde-ọmọ paramọ́lẹ̀,” ó sì ń bá a lọ láti sọ pé, a óò múdàájọ́ Gẹ̀hẹ́nà ṣẹ sórí “ìran yìí.” (Matteu 23:33, 36) Bí ó ti wù kí ó rí, a ha fi ìdájọ́ yìí mọ sórí àwùjọ àlùfáà alágàbàgebè bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu gbọ́ tí ń sọ̀rọ̀ nípa “ìran yìí,” ní lílo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà kan náà, lọ́nà gbígbòòrò sí i. Kí nìyẹn?
“Ìran Burúkú Yìí”
12. Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀, báwo ni Jesu ṣe so “ogunlọ́gọ̀ naa” pọ̀ mọ́ “ìran yii”?
12 Ní 31 C.E., nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ kíkàmàmà tí Jesu ṣe ní Galili àti kété lẹ́yìn Àjọ Ìrékọjá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ tí ó sọ fún “ogunlọ́gọ̀ naa” pé: “Ta ni emi yoo fi ìran yii wé? Ó dàbí awọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó ní awọn ibi-ọjà tí wọ́n ń ké jáde sí awọn alájùmọ̀-ṣeré wọn, wí pé, ‘Awa fọn fèrè fún yín, ṣugbọn ẹ̀yin kò jó; awa pohùnréré ẹkún, ṣugbọn ẹ̀yin kò lu ara yín ninu ẹ̀dùn ọkàn.’ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Johannu [Oníbatisí] wá kò jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, síbẹ̀ awọn ènìyàn wí pé, ‘Ó ní ẹ̀mí-èṣù’; Ọmọkùnrin ènìyàn [Jesu] wá lóòótọ́ ó ń jẹ ó sì ń mu, síbẹ̀ awọn ènìyàn wí pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alájẹkì tí ó sì fi ara rẹ̀ fún mímu ọtí wáìnì, ọ̀rẹ́ awọn agbowó-orí ati awọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’” Kò sí títẹ́ “ogunlọ́gọ̀” aláìnílànà náà lọ́rùn!—Matteu 11:7, 16-19.
13. Níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ta ni Jesu pè ní “ìran burúkú yii” tí ó sì dẹ́bi fún?
13 Lẹ́yìn náà ní 31 C.E., bí Jesu àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ìwàásù wọn kejì yíká Galili, “awọn kan lára awọn akọ̀wé òfin ati awọn Farisi” béèrè àmì lọ́wọ́ Jesu. Ó sọ fún àwọn àti “ogunlọ́gọ̀ naa” tí ó pésẹ̀ pé: “Ìran burúkú ati panṣágà tẹramọ́ wíwá àmì, ṣugbọn a kì yoo fi àmì kankan fún un àyàfi àmì Jona wòlíì. Nitori gan-an gẹ́gẹ́ bí Jona ti wà ninu ikùn ẹja mùmùrara naa fún ọ̀sán mẹ́ta ati òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ naa ni Ọmọkùnrin ènìyàn yoo wà ninu ọkàn-àyà ilẹ̀-ayé fún ọ̀sán mẹ́ta ati òru mẹ́ta. . . . Bẹ́ẹ̀ ni yoo rí pẹlu fún ìran burúkú yii.” (Matteu 12:38-46) Ó ṣe kedere pé, “ìran burúkú yìí” ní àwọn aṣáájú ìsìn àti “ogunlọ́gọ̀ naa,” tí kò lóye àmì náà tí ó ní ìmúṣẹ nínú ikú àti àjíǹde Jesu nínú.d
14. Ẹ̀bi wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu gbọ́ tí ó dá fún àwọn Sadusi àti Farisi?
14 Lẹ́yìn Àjọ Ìrékọjá 32 C.E., bí Jesu àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe wọ ẹkùn Galili ti Magadan, àwọn Sadusi àti Farisi tún béèrè àmì lọ́wọ́ Jesu. Ó tún sọ fún wọn pé: “Ìran burúkú ati panṣágà ń bá a nìṣó ní wíwá àmì kan, ṣugbọn a kì yoo fi àmì kankan fún un àyàfi àmì Jona. Pẹlu ìyẹn oun lọ kúrò, ó fi wọ́n sílẹ̀ sẹ́yìn.” (Matteu 16:1-4) Àwọn alágàbàgebè onísìn wọ̀nyẹn ní ti gidi yẹ ní bíbá wí jù lọ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú láàárín “ogunlọ́gọ̀” aláìṣòótọ́ tí Jesu dẹ́bi fún gẹ́gẹ́ bí “ìran burúkú yìí.”
15. Kété ṣáájú àti gbàrà lẹ́yìn ìyípadà ológo náà, ìforígbárí wo ni Jesu àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní pẹ̀lú ‘ìran yìí’?
15 Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Galili ṣe ń lọ sí òpin, Jesu pe ogunlọ́gọ̀ náà àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì wí pé: “Nitori ẹni yòówù tí ó bá tijú emi ati awọn ọ̀rọ̀ mi ninu ìran panṣágà ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yii, Ọmọkùnrin ènìyàn pẹlu yoo tijú rẹ̀.” (Marku 8:34, 38) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé, àwùjọ àwọn Júù aláìronúpìwàdà ti ìgbà yẹn para pọ̀ jẹ́ “ìran panṣaga ati ẹlẹ́ṣẹ̀ yii.” Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ìparadà ológo Jesu, Jesu àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “wá sọ́dọ̀ ogunlọ́gọ̀ naa,” ọkùnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá pé, kí ó wo ọmọkùnrin òun sàn. Jesu dáhùn pé: “Óò ìran aláìnígbàgbọ́ ati onímàgòmágó, bawo ni emi yoo ti máa bá a lọ pẹlu yín pẹ́ tó? Bawo ni emi yoo ti máa faradà fún yín pẹ́ tó?”—Matteu 17:14-17; Luku 9:37-41.
16. (a) Ẹ̀bi wo tí Jesu dá “awọn ogunlọ́gọ̀,” ni ó tún sọ ní Judea? (b) Báwo ni “ìran yii” ṣe hùwà tí ó burú jù lọ nínú gbogbo ìwà ọ̀daràn?
16 Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Judea ni Jesu ti tún ìdálẹ́bi rẹ̀ fún wọn sọ, lẹ́yìn Àjọ̀dún Àtíbàbà ní 32 C.E., “nígbà tí awọn ogunlọ́gọ̀ ń wọ́jọpọ̀,” sọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó sì sọ pé: “Ìran burúkú kan ni ìran yii; ó ń wá àmì kan. Ṣugbọn a kì yoo fún un ní àmì kankan àyàfi àmì Jona.” (Luku 11:29) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nígbà tí àwọn aṣáájú ìsìn mú Jesu wá sí ìgbẹ́jọ́, Pilatu fẹ́ dá a sílẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Awọn olórí àlùfáà ati awọn àgbà ọkùnrin yí awọn ogunlọ́gọ̀ naa lérò padà lati béèrè fún Barabba, ṣugbọn kí wọ́n pa Jesu run. . . . Pilatu wí fún wọn pé: ‘Kí wá ni kí emi ti ṣe Jesu tí gbogbo ènìyàn ń pè ní Kristi?’ Gbogbo wọ́n wí pé: ‘Kí a kàn án mọ́gi!’ Ó wí pé: ‘Họ́wù, ohun búburú wo ni ó ṣe?’ Síbẹ̀ wọ́n túbọ̀ ń ké jáde ṣáá pé: ‘Kí a kàn án mọ́gi!’” “Ìran burúkú” yẹn ń fi torítọrùn wá ikú Jesu!—Matteu 27:20-25.
17. Báwo ni àwọn kan lára “ìran oníwà wíwọ́ yii” ṣe dáhùn padà sí ìwàásù Peteru ní Pẹntikọsti?
17 “Ìran aláìnígbàgbọ́ ati onímàgòmágó” kan, tí àwọn aṣáájú ìsìn rẹ̀ sún, tipa báyìí kó ipa pàtàkì nínú ṣíṣekúpa Jesu Kristi Oluwa. Àádọ́ta ọjọ́ lẹ́yìn náà, ní Pẹntikọsti 33 C.E., àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà rí ẹ̀mí mímọ́ gbà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi onírúurú èdè sọ̀rọ̀. Bí wọ́n ṣe gbọ́ ìró náà, “ògìdìgbó naa kórajọ papọ̀,” aposteli Peteru sì pè wọ́n ní “ẹ̀yin ènìyàn Judea ati gbogbo ẹ̀yin olùgbé Jerusalemu,” ní sísọ pé: “Ọkùnrin yii [Jesu] . . . ni ẹ ti ọwọ́ awọn ènìyàn aláìlófin kàn gbọn-in-gbọn-in mọ́ òpó igi tí ẹ sì pa.” Báwo ni àwọn kan lára àwọn olùgbọ́ wọ̀nyẹn ṣe hùwà padà? “Ó gún wọn dé ọkàn-àyà.” Nígbà náà ni Peteru rọ̀ wọ́n láti ronú pìwà dà. Ó “jẹ́rìí kúnnákúnná ó sì ń gbà wọ́n níyànjú ṣáá, wí pé: ‘Ẹ gba ara yín là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yii.’” Ní ìdáhùnpadà, nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún “fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ [a sì] batisí [wọn].”—Ìṣe 2:6, 14, 23, 37, 40, 41.
A Dá “Ìran Yìí” Mọ̀
18. Kí ni bí Jesu ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìran yii” ń tọ́ka sí déédéé?
18 Lẹ́yìn náà, kí ni “ìran” tí Jesu tọka sí léraléra níṣojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Báwo ni wọ́n ṣe lóye ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà sí pé: “Ìran yii kì yoo kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹlẹ̀”? Ó dájú pé, Jesu kò yí ìlò ọ̀rọ̀ náà “ìran yìí” tí ó ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ padà, tí ó lò léraléra fún àwùjọ àwọn alájọgbáyé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn “afọ́jú afinimọ̀nà” wọn, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè Júù. (Matteu 15:14) “Ìran yìí” nírìírí gbogbo másùnmáwo tí Jesu sọ tẹ́lẹ̀, ó sì kọjá lọ nínú “ìpọ́njú ńlá” aláìláfiwé lórí Jerusalemu.—Matteu 24:21, 34.
19. Báwo àti nígbà wo ni “ọ̀run ati ilẹ̀-ayé” ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù ṣe kọjá lọ?
19 Ní ọ̀rúndún kìíní, Jehofa ṣèdájọ́ àwọn Júù. Àwọn tí wọ́n ronú pìwà dà, tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè aláàánú tí Jehofa tipasẹ̀ Kristi pèsè, ni a gbà là kúrò nínú “ìpọ́njú ńlá” yẹn. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jesu ṣe sọ tẹ́lẹ̀, gbogbo ohun tí a sọ tẹ́lẹ̀ ṣẹ, lẹ́yìn náà, “ọ̀run ati ilẹ̀-ayé” ti ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù—orílẹ̀-èdè náà látòkèdélẹ̀, pẹ̀lú àwọn aṣáájú ìsìn rẹ̀ àti àwùjọ àwọn ènìyàn burúkú rẹ̀—kọjá lọ. Jehofa ti múdàájọ́ ṣẹ!—Matteu 24:35; fi wé 2 Peteru 3:7.
20. Ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó bọ́ sákòókò wo ni ó kan gbogbo Kristian pẹ̀lú kánjúkánjú?
20 Àwọn Júù tí wọ́n tí fiyè sí àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jesu mọ̀ pé ìgbàlà wọn kò sinmi lé, gbígbìyànjú láti ṣírò bí “ìran” kan tàbí “awọn àkókò tàbí àsìkò” ti gùn tó, ṣùgbọ́n bíbá a nìṣó ní yíya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ìran abèṣù ti àwọn alájọgbáyé wọn, àti fífi tìtaratìtara ṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ àsọgbẹ̀yìn ti àsọtẹ́lẹ̀ Jesu ní í ṣe pẹ̀lú ìmúṣẹ pàtàkì ní ọjọ́ wa, àwọn Júù Kristian ọ̀rúndún kìíní tún ní láti kọbi ara sí ìyànjú náà pé: “Ẹ máa wà lójúfò, nígbà naa, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà kí ẹ lè kẹ́sẹjárí ní yíyèbọ́ ninu gbogbo nǹkan wọnyi tí a ti yàntẹ́lẹ̀ lati ṣẹlẹ̀, ati ní dídúró níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn.”—Luku 21:32-36; Ìṣe 1:6-8.
21. Ìṣẹ̀lẹ̀ òjijì wo ni a lè máa wọ̀nà fún ní ọjọ́ ọ̀la tí kò jìn mọ́?
21 Lónìí, “ọjọ́ ńlá Oluwa . . . kù sí dẹ̀dẹ̀, ó sì ń yára kánkán.” (Sefaniah 1:14-18; Isaiah 13:9, 13) Lójijì, ní “ọjọ́ ati wákàtí” tí Jehofa fúnra rẹ̀ ti yàn tẹ́lẹ̀, a óò tú ìbínú rẹ̀ dà sórí ètò ìsìn, ìṣèlú, àti ìṣòwò ayé, tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ àwọn alájọgbáyé ènìyàn oníwà wíwọ́ ti “ìran burúkú ati panṣágà,” yìí. (Matteu 12:39; 24:36; Ìṣípayá 7:1-3, 9, 14) Báwo ni o ṣe lè rí ìgbàlà nínú “ìpọ́njú ńlá naa”? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wa tí yóò tẹ̀ lé e yóò dáhùn, yóò sì sọ fún wa nípa ìrètí kíkọyọyọ fún ọjọ́ ọ̀la.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àsọtẹ́lẹ̀ yìí, jọ̀wọ́ wo ṣáàtì tí ó wà ní ojú ìwé 14, 15 nínú Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1994.
b Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí “àwọn ọ̀sẹ̀” ọdún, wo ojú ìwé 130 sí 132 nínú ìwé The Bible—God’s Word or Man’s?, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
c Àwọn Bibeli kan túmọ̀ he ge·ne·aʹ hauʹte nínú Matteu 24:34 báyìí: “àwọn ènìyàn wọ̀nyí” (The Holy Bible in the Language of Today [1976], láti ọwọ́ W. F. Beck); “orílẹ̀-èdè yìí” (The New Testament—An Expanded Translation [1961], láti ọwọ́ K. S. Wuest); “àwọn ènìyàn yìí” (Jewish New Testament [1979], by D. H. Stern).
d A kò ní láti fi ojú kan náà wo “ogunlọ́gọ̀” aláìṣòtítọ́ wọ̀nyí àti àwọn ʽam-ha·ʼaʹret, tàbí “àwọn ènìyàn ilẹ̀,” tí àwọn agbéraga aṣáájú ìsìn kọ̀ láti bá kẹ́gbẹ́, ṣùgbọ́n tí “àánú wọ́n ṣe” Jesu.—Matteu 9:36; Johannu 7:49.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni a rí kọ́ láti inú ìmúṣẹ Danieli 9:24-27?
◻ Báwo ni àwọn ìwé atúmọ̀ èdè ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ṣe túmọ̀ “ìran yii” gẹ́gẹ́ bí Bibeli ṣe lò ó?
◻ Báwo ni Jesu ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìran” déédéé?
◻ Báwo ni Matteu 24:34, 35 ṣe ní ìmúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Jesu fi “ìran yii” wé ogunlọ́gọ̀ àwọn ewèlè ọmọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jehofa nìkan ni ó mọ wákàtí náà ṣáájú, láti múdàájọ́ ṣẹ sórí ètò ìgbékalẹ̀ burúkú ti àwọn Júù