‘Ẹ Máa Ṣọ́nà’—Wákàtí Ìdájọ́ Ti dé!
Ohun tó wà nínú ìwe pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! tá a mú jáde ní àpéjọ àgbègbè tá a ṣe yíká ayé lọ́dún 2004 sí 2005 la gbé àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí kà.
“Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.”—MÁTÍÙ 24:42.
1, 2. Àpèjúwe wo ni Jésù lò tó bá bíbọ̀ rẹ̀ mu wẹ́kú?
KÍ LO máa ṣe bó o bá gbọ́ pé olè kan ń yọ kẹ́lẹ́ kíri àdúgbò rẹ tó sì ń wọlé onílé? Wàá wà lójúfò kó o bàa lè dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ àtohun ìní rẹ. Ìdí ni pé olè kì í kọ lẹ́tà láti fi sọ ìgbà tóun ń bọ̀. Ńṣe ló máa ń rọra yọ́ wọlé lójijì.
2 Láwọn ìgbà bíi mélòó kan, Jésù lo àpèjúwe bí olè ṣe máa ń jà. (Lúùkù 10:30; Jòhánù 10:10) Jésù sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa wáyé lákòókò òpin yìí àtèyí tó máa ṣẹlẹ̀ kó tó wá ṣèdájọ́. Ó kìlọ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ mọ ohun kan, pé ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, ì bá wà lójúfò, kì bá sì [tí] yọ̀ǹda kí a fọ́ ilé rẹ̀.” (Mátíù 24:42, 43) Nítorí náà, Jésù fi bíbọ̀ rẹ̀ wé ìgbà tí olè bá dé lójijì.
3, 4. (a) Kí la óò máa ṣe tí yóò fi hàn pé à ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jésù nípa dídé rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
3 Àpèjúwe náà bá a mu gan-an nítorí pé a kò mọ ọjọ́ náà gan-an tí Jésù máa dé. Kí Jésù tó sọ̀rọ̀ yẹn, ó ti kọ́kọ́ sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan náà yẹn pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Nítorí ìdí yìí, Jésù wá rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ wà ní ìmúratán.” (Mátíù 24:44) Àwọn tó ń kọbí ara sí ìkìlọ̀ Jésù yóò wà ní ìmúratán, wọ́n a máa hùwà tó dára, títí di ìgbàkígbà tí Jésù á fi dé láti wá mu ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ.
4 Àwọn ìbéèrè pàtàkì kan rèé: Ṣé àwọn èèyàn ayé nìkan ni ìkìlọ̀ Jésù wà fún ni àbí ó yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ pẹ̀lú ‘máa ṣọ́nà’? Kí nìdí tó fi yẹ ‘ká máa ṣọ́nà’ lójú méjèèjì, báwo la ó sì ṣe máa ṣọ́nà?
Ta Ni Ìkìlọ̀ Náà Wà Fún?
5. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ la kìlọ̀ fún pé ‘kí wọ́n máa ṣọ́nà’?
5 Òótọ́ tó dájú ni pé bíbọ̀ Olúwa yóò bá àwọn èèyàn ayé lójijì bí ìgbà tí olè bá dé, ìyẹn àwọn tó kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ nípa àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ yìí. (2 Pétérù 3:3-7) Àmọ́ ṣá o, ṣé bí ìgbà tí olè bá dé náà ni bíbọ̀ Olúwa yóò ṣe rí fún àwọn Kristẹni tòótọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru.” (1 Tẹsalóníkà 5:2) A kò ṣiyèméjì rara pé “ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀.” Àmọ́, ṣó wá yẹ ká tìtorí ìyẹn dẹwọ́ nínú bá a ṣe ń ṣọ́nà? Ṣàkíyèsí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mátíù 24:44) Ṣáájú àkókò yẹn, nígbà tí Jésù ń rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa wá Ìjọba náà nígbà gbogbo, ó kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Lúùkù 12:31, 40) Ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ni Jésù ń darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí nígbà tó kìlọ̀ pé, ‘Ẹ máa ṣọ́nà’?
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká ‘máa ṣọ́nà’?
6 Kí nìdí tó fi yẹ ká ‘máa ṣọ́nà’ ká sì “wà ní ìmúratán”? Jésù ṣàlàyé pé: “Àwọn ọkùnrin méjì yóò wà nínú pápá: a óò mú ọ̀kan lọ, a ó sì pa èkejì tì; àwọn obìnrin méjì yóò máa lọ nǹkan lórí ọlọ ọlọ́wọ́: a óò mú ọ̀kan lọ, a ó sì pa èkejì tì.” (Mátíù 24:40, 41) Àwọn tí ‘a óò mú lọ’ tàbí àwọn tí a óò gbà là yẹn làwọn tó wà ní ìmúratán nígbà tí Ọlọ́run bá pa ayé tí kò ṣèfẹ́ rẹ̀ yìí run. A óò pa àwọn tó kù run nítorí pé wọn kò kọbi ara sí ìkìlọ̀, wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé ìmọtara-ẹni-nìkan lọ ràì. Àwọn tó ti fìgbà kan rí mọ òtítọ́ ṣùgbọ́n tí wọn ò ṣọ́nà mọ́ lè wà lára àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.
7. Kí ni bí a kò ṣe mọ ìgbá tí òpin máa dé fún wa láǹfààní láti ṣe?
7 Bá ò ṣe mọ ọjọ́ náà gan-an tí òpin ètò ògbólógbòó yìí yóò dé fún wa láǹfààní láti fi hàn pé ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run ló ń mú wa sìn ín. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó lè jọ pé òpin ètò ògbólógbòó yìí ti ń pẹ́ jù, pé kò tètè dé. Ó ṣeni láàánú pé àwọn Kristẹni kan tí wọ́n níru èrò yìí ti jẹ́ kí ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun tí ìyàsímímọ́ wa fi hàn ni pé a ti fi ara wa fún Jèhófà pátápátá láti máa sìn ín. Àwọn tó mọ Jèhófà dáadáa mọ̀ pé kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa forí ṣe fọrùn ṣe nígbà tí nǹkan ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sórí tán kò lè jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Ó mọ ohun tó wà lọ́kàn wa gan-an.—1 Sámúẹ́lì 16:7.
8. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe ń sún wa láti máa ṣọ́nà?
8 Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tinútinú, ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ ló máa ń múnú wa dùn jù lọ. (Sáàmù 40:8; Mátíù 26:39) A sì fẹ́ láti máa sin Jèhófà títí láé. Bá a bá tiẹ̀ ní láti dúró pẹ́ díẹ̀ sí i ju bá a ṣe rò lọ, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ìrètí tá a ní láti sìn ín títi láé yìí kò ṣeyebíye mọ́. Olórí ohun tá a fi ń ṣọ́nà lójú méjèèjì ni pé a mọ̀ pé ọjọ́ Jèhófà yóò túmọ̀ sí mímú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Nítorí pé ó wù wá gan-an láti máa múnú Ọlọ́run dùn la ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń fún wa, tá a sì ń fi Ìjọba rẹ̀ sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. (Mátíù 6:33; 1 Jòhánù 5:3) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí ṣíṣọ́nà ṣe yẹ ko nípa lórí ìpinnu tá à ń ṣe àti bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́.
Ibo Ni Ìgbésí Ayé Rẹ Forí Lé?
9. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn ayé tètè mọ ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àkókò wa yìí túmọ̀ sí?
9 Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí mọ̀ pé àwọn ìṣòro ńlá àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù ti wọ́pọ̀ gan-an. Ibi tí ìgbésí ayé wọn forí lé tiẹ̀ lè máà tẹ́ wọn lọ́rùn. Àmọ́, ǹjẹ́ wọ́n mọ ìtumọ̀ gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí? Ǹjẹ́ wọ́n mọ̀ pé a ti ń gbé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan”? (Mátíù 24:3) Ǹjẹ́ wọ́n mọ̀ pé bí ìmọtara-ẹni-nìkan, ìwà ipá, kódà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run ṣe gbòde kan lónìí ń fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí? (2 Tímótì 3:1-5) Ó yẹ kí wọ́n tètè mọ ohun pàtàkì táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí kí wọ́n sì ronú nípa ibi tí ìgbésí ayé wọn dorí kọ.
10. Kí ló yẹ ká máa ṣe kó lè dá wa lójú pé à ń ṣọ́nà?
10 Àwa náà ńkọ́, ojú wo la fi ń wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí? Ojoojúmọ́ là ń ṣe àwọn ìpinnu tó kan iṣẹ́ wa, ìlera wa, ìdílé wa àti ìjọsìn wa. A mọ ohun tí Bíbélì sọ, a sì ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé e. Nítorí ìdí yìí, á dára ká béèrè lọ́wọ́ ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mi ò ti jẹ́ kí àníyàn ayé yìí pín ọkàn mi níyà? Ṣé kì í ṣe báyé ṣe ń ronú ló ń pinnu ohun tí mò ń ṣe?’ (Lúùkù 21:34-36; Kólósè 2:8) Ó yẹ ká máa fi hàn nígbà gbogbo pé a fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a kò sì gbára lé òye tiwa. (Òwe 3:5) Nípa bẹ́ẹ̀, a ó lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìyè tí kò nípẹ̀kun nínú ayé tuntun Ọlọ́run.—1 Tímótì 6:12, 19.
11-13. Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ (a) nígbà ayé Nóà? (b) nígbà ayé Lọ́ọ̀tì?
11 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tó jẹ́ ìkìlọ̀ ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣọ́nà. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Nóà yẹ̀ wò. Ọlọ́run ti fún wọn ní ìkìlọ̀ tipẹ́tipẹ́ kó tó mú ìparun náà wá. Àmọ́ àwọn èèyàn náà kò fiyè sí i àyàfi Nóà àti agbo ilé rẹ̀ nìkan. (2 Pétérù 2:5) Jésù sọ̀rọ̀ nípa èyí, ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:37-39) Kí la lè rí kọ́ látinú èyí? Bá a bá rí ẹnikẹ́ni nínú wa tó ń fi àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì dí ara rẹ̀ lọ́wọ́, táwọn ohun náà wá ń ṣèdíwọ́ fún àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tí Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká fi sí ipò kìíní, kódà bí àwọn nǹkan tó ń ṣèdíwọ́ náà bá tiẹ̀ jẹ́ àwọn ohun tó yẹ kéèyàn ṣe láyé, ó yẹ ká tún inú wa rò.—Róòmù 14:17.
12 Tún ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Lọ́ọ̀tì. Ìlú Sódómù, níbi tí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ ń gbé jẹ́ ìlú tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù, ṣùgbọ́n ìṣekúṣe àwọn ará ìlú ọ̀hún yọyẹ́. Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ pé kí wọ́n lọ run ìlú náà. Àwọn áńgẹ́lì náà ní kí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ sá kúrò ní ìlú Sódómù láìbojúwẹ̀yìn. Nígbà táwọn áńgẹ́lì náà rọ̀ wọ́n, wọ́n fìlú náà sílẹ̀. Àmọ́ ọkàn ìyàwó Lọ́ọ̀tì ò kúrò lára ilé rẹ̀ ní Sódómù. Ó ṣàìgbọràn, ó sì bojú wẹ̀yìn. Bó ṣe pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 19:15-26) Jésù sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ wa, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.” Ǹjẹ́ à ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ yẹn?—Lúùkù 17:32.
13 Àwọn tó kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run láyé ọjọ́un yè bọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti Nóà àti ìdílé rẹ̀, àpẹẹrẹ Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (2 Pétérù 2:9) Bá a ṣe ń fi ìkìlọ̀ tó wà nínú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí sọ́kàn, ìhìn rere ìgbàlà táwọn olùfẹ́ òdodo lè rí nínú rẹ̀ tún ń mọ́kàn wa yọ̀. Èyí ń mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa ‘ayé tuntun àti ọ̀run tuntun, níbi tí òdodo yóò máa gbé,’ yóò nímùúṣẹ.—2 Pétérù 3:13.
‘Wákàtí Ìdájọ́ ti Dé’!
14, 15. (a) Kí ni “wákàtí” ìdájọ́ náà? (b) Kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe láti fi hàn pé à ‘ń bẹ̀rù Ọlọ́run, a sì ń fi ògo fún un’?
14 Bá a ti ń ṣọ́nà, kí la lè máa retí? Ìwé Ìṣípayá ṣàlàyé bí àwọn nǹkan yóò ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra nígbà tí Ọlọ́run bá ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Ó pọn dandan ká máa ṣe ohun tí ìwé yìí sọ tá a bá fẹ́ fi hàn pé a wà ní ìmúratán. Kedere ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣàpèjúwe àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́ Olúwa,” èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Kristi gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914. (Ìṣípayá 1:10) Ìwé Ìṣípayá sọ fún wa nípa áńgẹ́lì kan tí Ọlọ́run fún ní “ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo.” Ó polongo ní ohùn rara pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.” (Ìṣípayá 14:6, 7) “Wákàtí” ìdájọ́ yẹn jẹ́ àkókò kúkúrú, tó wà fún kíkéde ìdájọ́ náà àti mímú un ṣẹ gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ. Àkókò náà là ń gbé nísinsìnyí.
15 Wàyí o, kó tó di pé wákàtí ìdájọ́ náà parí, a rọ̀ wá pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un.” Kí lèyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé ó yẹ kí ìbẹ̀rù tó tọ́ tá a ní fún Ọlọ́run mú wa fi ìwà burúkú sílẹ̀. (Òwe 8:13) Bá a bá ń bọlá fún Ọlọ́run, a ó máa tẹ́tí sílẹ̀ sí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àwọn nǹkan mìíràn kò ní dí wa lọ́wọ́ tá ò fi ní ráyè ka Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé. A ò ní fojú kéré ìmọ̀ràn rẹ̀ pé ká máa pésẹ̀ sáwọn ìpàdé Kristẹni. (Hébérù 10:24, 25) A óò ṣìkẹ́ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tá a ní láti máa fi ìtara pòkìkí ìhìn rere ti Ìjọba Mèsáyà Ọlọ́run. A óò máa fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní gbogbo ìgbà. (Sáàmù 62:8) Nítorí a mọ̀ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, à ń bọlá fún un nípa títẹríba fún un látọkànwá gẹ́gẹ́ bí Ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti máa darí ìgbésí ayé wa. Ṣé lóòótọ́ lò ń bẹ̀rù Ọlọ́run tó o sì ń fi ògo fún un ní gbogbo ọ̀nà yẹn?
16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìdájọ́ lórí Bábílónì Ńlá tí Ìṣípayá 14:8 sọ ti ní ìmúṣẹ?
16 Orí kẹrìnlá ìwé Ìṣípayá tún ń bá a lọ láti ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tó tún máa ṣẹlẹ̀ ní wákàtí ìdájọ́. Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, la kọ́kọ́ mẹ́nu kàn lọ́nà yìí pé: “Òmíràn, áńgẹ́lì kejì, tẹ̀ lé e, ó ń wí pé: ‘Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú!’” (Ìṣípayá 14:8) Bẹ́ẹ̀ ni, lójú Ọlọ́run, Bábílónì Ńlá ti ṣubú. Ọdún 1919 ni Jèhófà tú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró sílẹ̀ kúrò nínú ìdè àwọn ẹ̀kọ́ àti ìṣe Bábílonì tó ti jẹ gàba lórí àwọn èèyàn àtàwọn orílẹ̀-èdè fún ẹgbẹẹgbẹ̀run ọdún. (Ìṣípaya 17:1, 15) Látìgbà yẹn ni wọ́n ti gbájú mọ́ gbígbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Látìgbà yẹn ni ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé sì ti bẹ̀rẹ̀.—Mátíù 24:14.
17. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá?
17 Ìdájọ́ Ọlọ́run lórí Bábílónì Ńlá kò mọ síbẹ̀ yẹn o. Ó máa tó pa run pátápátá. (Ìṣípayá 18:21) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ àwọn èèyàn níbi gbogbo pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ [Bábílónì Ńlá] . . . bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 18:4, 5) Báwo la ṣe máa fi hàn pé a ti jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá? Jíjáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá kì í kàn ṣe kéèyàn jáwọ́ nínú ìsìn èké nìkan. Ipa tí Bábílónì ní ń hàn nínú ọ̀pọ̀ àwọn ayẹyẹ àtàwọn àṣà tó lókìkí, ó ń hàn nínú bí aráyé ṣe ń ní ìbálòpọ̀ láìsí ìkóra-ẹni-níjàánu àti nínú bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn eré ìnàjú tó ní ìbẹ́mìílò lárugẹ, ó sì tún ń hàn nínú ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan mìíràn. Ká lè máa ṣọ́nà nìṣó, ó ṣe pàtàkì pé ká máa fi hàn nínú ìṣe wa àti nínú ìfẹ́ ọkàn wa pé lóòótọ́ la ti kúrò nínú Bábílónì Ńlá ní gbogbo ọ̀nà.
18. Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 14:9, 10 ṣe sọ, kí làwọn Kristẹni tó wà lójúfò gbọ́dọ̀ yẹra fun?
18 Ìṣípayá orí kẹrìnlá ẹsẹ kẹsàn-án àti ìkẹwàá, tún sọ ohun mìíràn nípa ‘wákàtí ìdájọ́.’ Áńgẹ́lì mìíràn wí pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀, tí ó sì gba àmì kan sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀, òun yóò mu pẹ̀lú nínú wáìnì ìbínú Ọlọ́run.” Kí nìdí? Nítorí pé “ẹranko ẹhànnà náà àti ère rẹ̀” dúró fún ìṣàkóso èèyàn tí kò gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àwọn Kristẹni tó wà lójúfò máa ń ṣọ́ra gan-an kí ìwà àti ìṣe wọn má bàa fi hàn pé wọ́n wà lára àwọn tí kò gbà pé Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àwọn Kristẹni yìí mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run, àti pé Ìjọba yẹn yóò fòpin sí gbogbo ìṣàkóso èèyàn, ṣùgbọ́n òun yóò wà títí láé.—Dáníẹ́lì 2:44.
Má Ṣe Dẹra Nù!
19, 20. (a) Bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ ìparí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, kí ló dá wa lójú pé Sátánì á fẹ́ láti ṣe? (b) Kí la gbọ́dọ̀ pinnu láti ṣe?
19 Bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ ìparí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, ìṣòro àti ìdẹwò á máa pọ̀ sí i. Níwọ̀n bí a ṣì ti ń gbé nínú ètò ògbólógbòó yìí, tí àìpé àwa fúnra wa sì ń kó ìdààmú bá wa, a óò máa ní àwọn ìṣòro kan, irú bíi: àìlera, ọjọ́ ogbó, kéèyàn ẹni kú, káwọn èèyàn múnú bíni, ìjákulẹ̀ tá a máa ń ní nígbà táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá à ń wàásù rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ìṣòro mìíràn. Má ṣe gbàgbé pé kò sóhun tó wu Sátánì ju pé kó mú káwọn ìṣòro tá à ń dojú kọ mú wa juwọ́ sílẹ̀ nínú wíwàásù ìhìn rere tàbí kó mú wa jáwọ́ nínú títẹ̀lé ìlànà Ọlọ́run. (Éfésù 6:11-13) Àkókò tá a wà yìí kọ́ ló yẹ ká dẹra nù láìṣe nǹkan kan!
20 Jésù mọ̀ pé a máa wà nínú ìṣòro tó lè mú ká fẹ́ juwọ́ sílẹ̀, nítorí náà ó gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mátíù 24:42) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa wà lójúfò nígbà gbogbo ká lè mọ bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó. Ẹ jẹ́ ká yẹra fáwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì tó lè mú ká dẹwọ́ tàbí ká jáwọ́ nínú rírìn ní ọ̀nà òtítọ́. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti túbọ̀ máa fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àní sẹ́, ní gbogbo ọ̀nà, ẹ jẹ́ ká máa wà lójúfò bá a ṣe ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí Jésù fún wa pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” Tá a bá ṣe èyí, a óò fi ọlá fún Jèhófà a óò sì wà lára àwọn tí yóò gba ìbùkún ayérayé.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo la ṣe mọ̀ pé ìkìlọ̀ Jésù pé ‘ká máa ṣọ́nà’ kan àwọn Kristẹni tòótọ́?
• Àwọn àpẹẹrẹ tó jẹ́ ìkìlọ̀ wo ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ‘máa sọ́nà’?
• Kí ni wàkatí ìdájọ́ jẹ́, kí la sì rọ̀ wá pé ká ṣe kó tó parí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jésù fi bíbọ̀ rẹ̀ we ìgbà tí olè bá dé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìparun Bábílónì Ńlá ti sún mọ́lé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ẹ jẹ́ ká pinnu láti túbọ̀ máa fi ìtara wàásù