‘Bíi Ti Ọ̀run Bẹ́ẹ̀ Ni ní Ayé’
“Ìjọ Kátólíìkì gbà gbọ́ pé ohun mẹ́rin ló jẹ́ àtúbọ̀tán ọmọ èèyàn: Ikú, Ìdájọ́, Ọ̀run Àpáàdì, Ọ̀run Rere.”—Ìwé Catholicism tí George Brantl ṣe.
ṢÀKÍYÈSÍ pé kò sí ilẹ̀ ayé lára àwọn nǹkan mẹ́rin tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ àtúbọ̀tán ọmọ èèyàn yìí o. Èyí ò sì yani lẹ́nu rárá nítorí pé ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sìn gbà gbọ́ náà ni ìjọ Kátólíìkì gbà gbọ́, ìyẹn ni pé ilẹ̀ ayé ń bọ̀ wá pa rẹ́ lọ́jọ́ kan. Ìwé atúmọ̀ èdè Dictionnaire de Théologie Catholique sọ lábẹ́ àkòrí náà, “Òpin Ayé,” pé: “Ohun tí ìjọ Kátólíìkì gbà gbọ́ tí wọ́n sì fi ń kọ́ni ni pé ilé ayé yìí, bí Ọlọ́run ṣe dá a àti bó ṣe wà yìí, kò ní wà títí láé.” Ìwé katikísìmù ìjọ Kátólíìkì kan tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí sì sọ pé: “Ńṣe ni ayé wa yìí yóò pa rẹ́ pátápátá.” Ṣùgbọ́n o, tí ilé ayé wa yìí bá máa pa rẹ́ pátápátá, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé ayé yóò di Párádísè?
Kedere kèdèrè ni Bíbélì sọ ọ́ pé ilẹ̀ ayé ń bọ̀ wá di Párádísè. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí wòlíì Aísáyà sọ nípa ayé àtàwọn tó máa gbé inú rẹ̀ ni pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Aísáyà 65:21, 22) Ó dá àwọn Júù tí Ọlọ́run ṣe ìlérí yìí fún lójú pé lọ́jọ́ kan ilẹ̀ wọn, ìyẹn Ilẹ̀ Ìlérí, àti gbogbo ayé pàápàá, yóò di Párádísè tí aráyé yóò ti máa jẹ̀gbádùn títí láé.
Sáàmù kẹtàdínlógójì sọ ohun tó ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn, ó ní: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:11) Kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà sí Ilẹ̀ Ìlérí fúngbà díẹ̀ nibí yìí ń wí o. Sáàmù yìí kan náà sọ ọ́ ní pàtó pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29)a Ṣàkíyèsí pé ohun tí Sáàmù yìí ń sọ ni pé “àwọn ọlọ́kàn tútù” yóò fi ìwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ṣe èrè jẹ. Nínú Bíbélì èdè Faransé kan, àlàyé tí wọ́n ṣe lórí ẹsẹ Bíbélì yìí ni pé ọ̀rọ̀ tá a tú sí “ọlọ́kàn tútù” “ní ìtumọ̀ tó gbòòrò ju bí àwọn olùtumọ̀ ṣe máa ń túmọ̀ rẹ̀; ọ̀rọ̀ náà lè túmọ̀ sí àwọn tí nǹkan ò lọ déédéé fún, àwọn tí ìyà ń jẹ tàbí tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí nítorí ti Yáwè [Jèhófà], àtàwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.”
Ṣé Orí Ilẹ̀ Ayé Ni Tàbí Ọ̀run?
Nígbà tí Jésù ń wàásù lórí òkè, ó ṣe ìlérí kan tó rán wa létí ẹsẹ Bíbélì tá a fà yọ lókè yìí. Ó ní: “Alabukun-fun ni awọn ọlọ́kàn-tútù: nitori ti wọn o jogun ayé.” (Mátíù 5:5, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Lẹ́ẹ̀kan sí i, a rí i níhìn-ín pé àwọn olóòótọ́ yóò fi ilẹ̀ ayé ṣe èrè jẹ, títí gbére sì ni. Àmọ́ o, Jésù jẹ́ kó yé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun fẹ́ lọ pèsè ayé sílẹ̀ fún wọn “nínú ilé Baba [òun]” àti pé wọn á wà lọ́run pẹ̀lú òun. (Jòhánù 14:1, 2; Lúùkù 12:32; 1 Pétérù 1:3, 4) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìbùkún tí Bíbélì sọ pé a máa rí gbà lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Ǹjẹ́ a ṣì lè máa retí àwọn ìbùkún wọ̀nyẹn lónìí, àwọn wo ni yóò sì rí wọn gbà?
Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé àpèjúwe lásán ni Jésù fi “ayé” tó mẹ́nu kàn nínú Ìwàásù Lórí Òkè ṣe, wọ́n sì tún sọ pé àpèjúwe lásán ni “ilẹ̀ ayé” tí Sáàmù kẹtàdínlógójì sọ jẹ́. Nínú àlàyé tí ọ̀gbẹ́ni F. Vigouroux ṣe nínú ìwé Bible de Glaire, ó ní “ọ̀run àti Ìjọ àwọn ẹni mímọ́” ni ọ̀rọ̀ ẹsẹ wọ̀nyẹn dúró fún lójú tòun. Ọ̀gbẹ́ni M. Lagrange, ọmọ ilẹ̀ Faransé tó ń ṣèwádìí lórí Bíbélì, sọ pé àwọn ìbùkún wọ̀nyí “kì í ṣe ìlérí tó fi hàn pé ilẹ̀ ayé táwọn ọlọ́kàn tútù ń gbé yìí yóò di tiwọn, yálà nínú ayé ìsinsìnyí tàbí nínú ayé kan tó dára jù báyìí lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí kàn ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ọlọ́kàn tútù ṣe máa gba èrè wọn níbikíbi tí ì báà jẹ́, inú ìjọba ọ̀run sì ni wọ́n ti máa gbà á.” Ẹlòmíì tó ń ṣèwádìí lórí Bíbélì sọ pé lójú tòun, “ńṣe ni wọ́n kàn lo àwọn nǹkan inú ayé láti fi ṣàkàwé ọ̀run.” Bẹ́ẹ̀ làwọn míì náà tún sọ pé: “Nǹkan tẹ̀mí ni wọ́n fi ilẹ̀ ìlérí, ìyẹn ilẹ̀ Kénáánì ṣàpèjúwe, ó sì dúró fún ilé wa lọ́run, ìyẹn ìjọba Ọlọ́run, èyí tó dájú pé ó máa jẹ́ tàwọn ọlọ́kàn tútù. Ohun kan náà ni irú ọ̀rọ̀ yìí tó wà nínú Sáàmù kẹtàdínlógójì àtàwọn ibòmíì túmọ̀ sí.” Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó yẹ ká kàn gbà pé ayé ò lè sí lára àwọn ibi tí ìlérí Ọlọ́run ti máa ṣẹ?
Ọlọ́run Ti Pinnu Pé Ilẹ̀ Ayé Yóò Di Párádísè Títí Láé
Látìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti ní ìdí pàtàkì kan tó fi dá èèyàn sórí ilẹ̀ ayé. Onísáàmù kan sọ pé: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sáàmù 115:16) Nítorí náà, ńṣe ni Ọlọ́run dìídì dá ọmọ èèyàn sí orí ilẹ̀ ayé, kò dá wọn láti lọ sọ́run. Iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún tọkọtaya kìíní ni pé kí wọ́n mú kí ọgbà Édẹ́nì fẹ̀ dé ibi gbogbo ní ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ìgbà kúkúrú kọ́ ni Ọlọ́run fẹ́ kí ètò tóun ṣe nípa ayé yìí fi wà bẹ́ẹ̀ o. Jèhófà fi hàn nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ayé máa wà títí láé ni. Bíbélì sọ pé: “Ìran kan ń lọ, ìran kan sì ń bọ̀; ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé dúró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Oníwàásù 1:4; 1 Kíróníkà 16:30; Aísáyà 45:18.
Àwọn ìlérí Ọlọ́run ò lè ṣaláì ṣẹ nítorí pé òun ni Ẹni Gíga Jù Lọ, yóò rí sí i pé wọ́n ṣẹ ṣáá ni. Bíbélì fi lílọ tí omi máa ń lọ sójú sánmà tí yóò sì padà rọ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjò ṣe àpèjúwe bó ṣe dájú tó pé àwọn ìlérí Ọlọ́run yóò ṣẹ láìyẹ̀, ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde, . . . bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi [ìyẹn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run] tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” (Aísáyà 55:10, 11) Ọlọ́run ti ṣe àwọn ìlérí kan fún aráyé. Ó lè pẹ́ díẹ̀ kí àwọn ìlérí yẹn tó ṣẹ o, àmọ́ ó dájú pé wọ́n á ṣẹ. Gbogbo ohun tí Ọlọ́run bá sọ ni yóò ṣẹ gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ kó tó “padà” sọ́dọ̀ rẹ̀.
Láìsí àní-àní, Jèhófà “ní inú dídùn sí” dídá tó dá ilẹ̀ ayé fún àwa ọmọ èèyàn. Ní òpin ọjọ́ ìṣẹ̀dá kẹfà, Ọlọ́run sọ pé gbogbo ohun tí òun dá “dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Lára ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun fẹ́ ṣe tí kò tíì ṣẹlẹ̀ ni pé ilẹ̀ ayé máa di Párádísè títí láé. Ṣùgbọ́n ó dájú pé ìlérí Ọlọ́run ‘kì yóò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ láìní ìyọrísí.’ Gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe pé ọmọ èèyàn yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé níbi tí gbogbo nǹkan yóò ti máa dùn yùngbà, pé àlàáfíà yóò padà jọba láàárín ọmọ èèyàn àti pé ààbò yóò wà, ni yóò ṣẹ pátá láìkùnà.—Sáàmù 135:6; Aísáyà 46:10.
Ìpinnu Ọlọ́run Yóò Ṣẹ Láìkùnà
Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ni kò jẹ́ kí ayé tíì di Párádísè gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí látìbẹ̀rẹ̀, àmọ́ fúngbà díẹ̀ ni. Lílé ni Ọlọ́run lé àwọn òbí méjèèjì náà jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì lẹ́yìn àìgbọràn wọn. Bí wọn ò ṣe sí lára àwọn tó máa mú kí ìpinnu Ọlọ́run pé kí ẹ̀dá èèyàn pípé máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ṣẹ mọ́ nìyẹn. Síbẹ̀, Ọlọ́run ṣe ètò tó máa jẹ́ kí ìpinnu rẹ̀ lè ṣẹ. Báwo ló ṣe ṣe é?—Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19, 23.
Ọ̀rọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Édẹ́nì dà bí ìgbà tí ọkùnrin kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé sórí ilẹ̀ kan tó dáa. Gbàrà tó fi ìpìlẹ̀ ilé náà lélẹ̀ ni ẹnì kan wá ba ìpìlẹ̀ náà jẹ́. Àmọ́ ọkùnrin yìí ò torí ìyẹn pa iṣẹ́ ilé náà tì. Ńṣe ló wá ọgbọ́n dá kó lè kọ́ ilé náà parí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ilé ọ̀hún tí ọkùnrin náà padà bẹ̀rẹ̀ kó o sí ìnáwó míì, síbẹ̀ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò lè parí ohun tó dáwọ́ lé níbẹ̀rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe ṣe ètò tí yóò jẹ́ kó parí ohun tó ti pinnu láti ṣe. Kété lẹ́yìn táwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣẹ̀ ni Ọlọ́run ti sọ ọ̀nà táwọn àtọmọdọ́mọ wọn yóò fi lè nírètí, ó ní “irú-ọmọ” kan ń bọ̀ wá tún ohun tí wọ́n ti bà jẹ́ ṣe. Ohun tí Ọlọ́run sọ yìí ló ń ṣẹ nígbà tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ olórí irú-ọmọ náà wá sáyé, tó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti fi ṣe ìràpadà aráyé. (Gálátíà 3:16; Mátíù 20:28) Nígbà tí Ọlọ́run sì jí Jésù dìde sí ọ̀run ó di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ní pàtàkì, Jésù yìí ni ọlọ́kàn tútù tó jogún ayé, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ kéréje kan tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run kí wọ́n lè bá Jésù ṣe Ìjọba yìí. (Sáàmù 2:6-9) Nígbà tó bá yá, ìjọba yìí yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé láti lè mú ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ni pé kí ilẹ̀ ayé di Párádísè. Ọ̀kẹ́ àìmọye ọlọ́kàn tútù yóò wá “jogún ayé” ní ti pé wọn yóò jàǹfààní púpọ̀ gan-an nínú Ìjọba tí Jésù àtàwọn tí yóò bá a ṣèjọba yóò ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣe 2:32, 33; Ìṣípayá 20:5, 6.
‘Bíi Ti Ọ̀run Bẹ́ẹ̀ Ni ní Ayé’
Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan tí wọ́n ti mẹ́nu kan ìgbàlà tó pín sọ́nà méjì yìí, ìyẹn ni pé àwọn kan yóò lọ sọ́run àwọn míì yóò sì wà ní ayé. Ó rí àwọn ọba kan lórí ìtẹ́ ní ọ̀run, ara àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi olóòótọ́ ni wọ́n sì ti yàn wọ́n. Bíbélì sọ ní pàtó pé àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú Kristi lọ́run yìí yóò “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Ṣàkíyèsí pé nǹkan méjì ló ṣẹlẹ̀ láti mú ìpinnu Ọlọ́run ṣẹ. Àkọ́kọ́, Jésù Kristi àtàwọn ajùmọ̀jogún rẹ̀ yóò ṣe Ìjọba kan ní ọ̀run, lẹ́yìn náà, Ìjọba náà yóò mú àyípadà bá ilẹ̀ ayé. Gbogbo ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí ni yóò jẹ́ kí ilẹ̀ ayé padà di Párádísè bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà, ó ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ “gẹ́gẹ́ bi ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Ǹjẹ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀ máa bọ́gbọ́n mu tó bá ṣe pé ayé máa pa rẹ́ pátápátá tàbí pé ọ̀run ni ayé tí Jésù sọ nínú àdúrà yẹn dúró fún? Yàtọ̀ síyẹn, ṣé ọ̀rọ̀ yẹn máa bọ́gbọ́n mu tó bá jẹ́ pé ọ̀run ni gbogbo olódodo ń lọ? Ìwé Mímọ́ fi ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ hàn kedere, bẹ̀rẹ̀ látorí ìtàn bí Ọlọ́run ṣe ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan títí lọ dórí ìran inú ìwé Ìṣípayá tó gbẹ́yìn Bíbélì. Ńṣe ni Ọlọ́run pinnu pé ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè. Ìyẹn gan-an ni ìfẹ́ Ọlọ́run, èyí tó ṣèlérí pé ó máa ṣẹ láìyẹ̀. Ìfẹ́ rẹ̀ yìí sì làwọn olóòótọ́ èèyàn lórí ilẹ̀ ayé ń gbàdúrà pé kó ṣẹ.
Ohun tí Ẹlẹ́dàá, Ọlọ́run tí “kò yí padà” ti pinnu láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni pé kí èèyàn wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Málákì 3:6; Jòhánù 17:3; Jákọ́bù 1:17) Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti ń ṣàlàyé nípa nǹkan méjì yẹn tí yóò ṣẹlẹ̀ láti mú ìpinnu Ọlọ́run ṣẹ. Èyí ló jẹ́ ká lè lóye àwọn ìlérí inú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ayé yóò padà di Párádísè. A rọ̀ ọ́ pé kó o túbọ̀ ṣèwádìí sí i lórí ọ̀rọ̀ yìí, yálà kó o pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀ tàbí kó o kàn sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lóòótọ́ àwọn Bíbélì kan tú ọ̀rọ̀ Hébérù náà ‘eʹrets sí “ilẹ̀ náà” dípò “ayé,” àmọ́ kò yẹ ká rò pé kìkì ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan ni ọ̀rọ̀ náà ‘eʹrets tí Bíbélì lò nínú Sáàmù 37:11, 29 túmọ̀ sí. Ìwé Old Testament Word Studies tí William Wilson ṣe sọ pé ọ̀rọ̀ náà ‘eʹrets túmọ̀ sí “ilẹ̀ ayé ní ìtumọ̀ rẹ̀ tó gbòòrò, èyí sì kan àwọn ibi táwọn èèyàn ń gbé àti ibi tí kò ṣeé gbé; àmọ́ tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí ìtumọ̀ rẹ̀ kò gbòòrò, yóò túmọ̀ sí apá ibì kan láyé, ilẹ̀ kan tàbí orílẹ̀-èdè kan.” Nítorí náà, ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí túmọ̀ sí ní pàtàkì ni ilẹ̀ ayé.—Wo Ilé-ìṣọ́nà, May 1, 1986, ojú ìwé 31.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Kedere kèdèrè ni Bíbélì sọ ọ́ pé ilẹ̀ ayé ń bọ̀ wá di Párádísè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ǹjẹ́ àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà máa bọ́gbọ́n mu tó bá ṣe pé ayé máa pa rẹ́ pátápátá?