Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Ń Sin “Ọlọ́run Aláyọ̀”
“Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—SM. 144:15.
1. Kí nìdí táwa èèyàn Jèhófà fi ń láyọ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
Ó DÁJÚ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń láyọ̀. Tá a bá wà nípàdé, láwọn àpéjọ tàbí níbi àpèjẹ èyíkéyìí, ayọ̀ máa ń kún ọkàn wa, a sì máa ń bá ara wa sọ̀rọ̀ tẹ̀rín-tọ̀yàyà. Àmọ́, kí nìdí tá a fi ń láyọ̀? Ìdí pàtàkì tá a fi ń láyọ̀ ni pé a mọ Jèhófà “Ọlọ́run aláyọ̀,” à ń sìn ín, a sì ń sapá láti fara wé e. (1 Tím. 1:11; Sm. 16:11) Jèhófà ni Ọlọ́run tó ń fúnni láyọ̀, ó sì fẹ́ ká láyọ̀, ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa jẹ́ ká láyọ̀.—Diu. 12:7; Oníw. 3:12, 13.
2, 3. (a) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan láyọ̀? (b) Kí nìdí tí kò fi rọrùn láti jẹ́ aláyọ̀?
2 Ìwọ ńkọ́? Ṣé ò ń láyọ̀? Kí lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ láyọ̀? Téèyàn bá láyọ̀, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀, á ní ìtẹ́lọ́rùn, inú rẹ̀ á sì máa dùn. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹni tí Jèhófà bá bù kún ló máa ń ní ayọ̀ tòótọ́. Ká sòótọ́, kò rọrùn láti jẹ́ aláyọ̀ nínú ayé yìí. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?
3 Kò rọrùn láti jẹ́ aláyọ̀ nígbà tá a bá ń kojú àwọn ipò tó le koko. Bí àpẹẹrẹ, inú wa kì í dùn téèyàn ẹni bá kú tàbí tí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, tí tọkọtaya ò bá gbọ́ ara wọn yé tàbí tí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń fà kì í ṣe kékeré. Nígbà míì sì rèé, ẹnì kan lè rẹ̀wẹ̀sì torí pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣòro táwọn míì tún máa ń kojú ni káwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé wọn máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn míì sì máa ń kojú inúnibíni tàbí kí wọ́n tiẹ̀ sọ wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí òtítọ́. Ìlera àwọn kan túbọ̀ ń burú sí i, ó sì lè jẹ́ àìsàn tó le koko tàbí ìsoríkọ́ ló ń kó ìdààmú bá àwọn míì. Àmọ́, Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jésù Kristi máa ń tu àwọn èèyàn nínú, ó sì fẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Kódà Bíbélì pe Jésù ní “aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà.” (1 Tím. 6:15; Mát. 11:28-30) Nínú ìwàásù Jésù lórí òkè, ó mẹ́nu ba àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì tó yẹ ká ní tá a bá fẹ́ láyọ̀ láìka àwọn ìṣòro tá à ń kojú nínú ayé Sátánì sí.
Ó ṢE PÀTÀKÌ KÁ JẸ́ ẸNI TẸ̀MÍ KÁ TÓ LÈ LÁYỌ̀
4, 5. Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ láyọ̀, kí ayọ̀ náà sì wà pẹ́ títí?
4 Ohun àkọ́kọ́ tí Jésù sọ ṣe pàtàkì gan-an, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mát. 5:3) Báwo la ṣe lè fi hàn pé àìní nípa ti ẹ̀mí ń jẹ wá lọ́kàn? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí, tá a sì ń fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa láyọ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Bákan náà, “ìrètí aláyọ̀” tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú.—Títù 2:13.
5 Tá a bá fẹ́ ní ayọ̀ tó máa wà pẹ́ títí, ó ṣe pàtàkì ká ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú [Jèhófà] Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!” (Fílí. 4:4) Torí náà, tá ò bá fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́, a gbọ́dọ̀ máa fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù. Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí, àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀. Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.”—Òwe 3:13, 18.
6. Kí ló tún yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ ní ayọ̀ tó máa wà pẹ́ títí?
6 Tá ò bá fẹ́ kí ohunkóhun ba ayọ̀ wa jẹ́, kì í ṣe pé ká kàn ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan, ó tún ṣe pàtàkì ká fi í sílò. Jésù tẹnu mọ́ bí èyí ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó sọ pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.” (Jòh. 13:17; ka Jákọ́bù 1:25.) Tá a bá ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò, a máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ayọ̀ wa sì máa wà pẹ́ títí. Ṣùgbọ́n, báwo la ṣe lè máa láyọ̀ láìka onírúurú ìṣòro tó kúnnú ayé yìí sí? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù sọ tẹ̀ lé e nínú Ìwàásù Lórí Òkè.
ÀWỌN ÀNÍMỌ́ TÓ MÁA JẸ́ KÁ LÁYỌ̀
7. Báwo lẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ ṣe lè láyọ̀?
7 “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, níwọ̀n bí a ó ti tù wọ́n nínú.” (Mát. 5:4) A lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kéèyàn máa ṣọ̀fọ̀ kó tún máa láyọ̀?’ Kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ni Jésù ní lọ́kàn. Ìdí ni pé àwọn èèyàn burúkú pàápàá máa ń ṣọ̀fọ̀, inú wọn sì máa ń bà jẹ́ torí pé nǹkan ò rọrùn ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” tá à ń gbé yìí. (2 Tím. 3:1) Àmọ́, àwọn èèyàn burúkú kì í ronú nípa Jèhófà rárá, tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, tí nǹkan ò bá sì lọ dáadáa fún wọn ni wọ́n máa ń banú jẹ́. Ìdí nìyẹn tí wọn ò fi ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, tí wọn ò sì láyọ̀. Àmọ́, àwọn tí Jésù ní lọ́kàn ni àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí inú wọn ò sì dùn bí wọ́n ṣe ń rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò rí ti Ọlọ́run rò, tí wọn ò sì ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn, ó sì máa ń dùn wọ́n bí wọ́n ṣe ń rí àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ ti fà fọ́mọ aráyé. Jèhófà máa ń kíyè sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ó máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù wọ́n nínú kọ́kàn wọn lè balẹ̀ pé wọ́n máa nírètí ìyè àìnípẹ̀kun, ìyẹn sì máa ń fún wọn láyọ̀.—Ka Ìsíkíẹ́lì 5:11; 9:4.
8. Téèyàn bá jẹ́ onínú tútù, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó láyọ̀?
8 “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mát. 5:5) Téèyàn bá jẹ́ onínú tútù, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó láyọ̀? Àwọn kan ti fìgbà kan rí jẹ́ oníjàgídíjàgan, wọ́n sì máa ń fa wàhálà gan-an. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n yíwà pa dà. Ní báyìí, wọ́n ti gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, wọ́n sì ti láwọn ànímọ́ àtàtà bí “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra.” (Kól. 3:9-12) Torí náà, wọ́n ní àlàáfíà, wọ́n sì ń láyọ̀ torí pé wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Yàtọ̀ síyẹn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa “jogún ilẹ̀ ayé.”—Sm. 37:8-10, 29.
9. (a) Ọ̀nà wo làwọn onínú tútù máa gbà “jogún ilẹ̀ ayé”? (b) Kí nìdí táwọn tí “ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo” fi máa láyọ̀?
9 Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn onínú tútù máa “jogún ilẹ̀ ayé”? Àwọn ẹni àmì òróró máa jogún ilẹ̀ ayé nígbà tí wọ́n bá di ọba àti àlùfáà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba lórí ayé. (Ìṣí. 20:6) Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olóòótọ́ yòókù tí kò lọ sọ́run máa jogún ilẹ̀ ayé ní ti pé Jèhófà máa jẹ́ kí wọ́n máa gbé títí láé lórí rẹ̀. Nígbà yẹn, Jèhófà máa sọ wọ́n di pípé, wọ́n á sì máa gbádùn ayọ̀ àti àlàáfíà títí lọ kánrin kése. Àwọn yìí náà làwọn tí Jésù sọ pé wọ́n ń láyọ̀ torí pé ‘ebi ń pa wọ́n, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n fún òdodo.’ (Mát. 5:6) Jèhófà máa bọ́ wọn yó nípa tẹ̀mí nínú ayé tuntun, á sì jẹ́ kọ́wọ́ wọn tẹ òdodo tí wọ́n ń yán hànhàn fún. (2 Pét. 3:13) Tó bá dìgbà yẹn, Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn ẹni ibi run, èyí á mú káwọn olódodo láyọ̀, wọn ò sì ní ṣọ̀fọ̀ tàbí banú jẹ́ mọ́ nítorí ìwà burúkú táwọn ẹni ibi ń hù.—Sm. 37:17.
10. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ aláàánú?
10 “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.” (Mát. 5:7) Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí àánú túmọ̀ sí “kéèyàn máa ṣìkẹ́ àwọn míì, kó sì wù ú láti ràn wọ́n lọ́wọ́.” Bákan náà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò fún àánú túmọ̀ sí pé kó wu èèyàn látọkàn wá láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Àmọ́ àánú kọjá kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ èèyàn lọ́kàn. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé kéèyàn láàánú gba pé kó ṣe nǹkan kan láti ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́.
11. Kí ni àpèjúwe ọkùnrin ará Samáríà kọ́ wa nípa jíjẹ́ aláàánú?
11 Ka Lúùkù 10:30-37. Àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin ará Samáríà jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ aláàánú. Àánú tí ọkùnrin ará Samáríà náà ní ló mú kó ran ẹni tí wọ́n ṣe léṣe náà lọ́wọ́. Lẹ́yìn tí Jésù sọ àpèjúwe yìí, ó ní: “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ, kí ìwọ alára sì máa ṣe bákan náà.” Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé èmi náà máa ń fàánú hàn sáwọn èèyàn bíi ti ọkùnrin ará Samáríà yìí? Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ máa fàánú hàn sáwọn tó ń jìyà? Bí àpẹẹrẹ, ṣé mo lè ṣèrànwọ́ fáwọn àgbàlagbà, àwọn opó tó fi mọ́ àwọn ọmọ táwọn òbí wọn ò sí nínú òtítọ́? Ṣé mo máa ń kíyè sáwọn “tí ó soríkọ́,” kí n sì wá ọ̀nà láti “sọ̀rọ̀ ìtùnú” fún wọn?—1 Tẹs. 5:14; Ják. 1:27.
12. Tá a bá ń fàánú hàn sáwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká láyọ̀?
12 Tá a bá ń fàánú hàn sáwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká láyọ̀? Tá a bá ń ṣàánú àwọn míì, à ń fún wọn ní nǹkan nìyẹn, Jésù sì sọ pé a máa láyọ̀ tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, tá a bá ń fàánú hàn sáwọn èèyàn, a máa múnú Jèhófà dùn. (Ìṣe 20:35; ka Hébérù 13:16.) Ọba Dáfídì sọ ohun tí Jèhófà máa ṣe fún ẹni tó bá ń ṣàánú àwọn míì, ó sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ, yóò sì pa á mọ́ láàyè. A óò máa pè é ní aláyọ̀ ní ilẹ̀ ayé.” (Sm. 41:1, 2) Tá ò bá jẹ́ kó sú wa láti máa ṣàánú, Jèhófà máa fàánú hàn sáwa náà, ìyẹn sì máa jẹ́ ká láyọ̀ títí láé.—Ják. 2:13.
ÌDÍ TÍ ÀWỌN TÓ MỌ́ “GAARA NÍ ỌKÀN-ÀYÀ” FI Ń LÁYỌ̀
13, 14. Kí nìdí téèyàn fi máa láyọ̀ tí ọkàn rẹ̀ bá mọ́ gaara?
13 Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.” (Mát. 5:8) Kí ọkàn-àyà wa tó lè mọ́ gaara, a ò gbọ́dọ̀ máa ro èròkerò, àwọn nǹkan rere ló sì yẹ kó gbà wá lọ́kàn. Èyí ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.—Ka 2 Kọ́ríńtì 4:2; 1 Tím. 1:5.
14 Àwọn tí ọkàn wọn bá mọ́ gaara máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Jèhófà sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ó fọ aṣọ wọn.” (Ìṣí. 22:14) Ọ̀nà wo làwọn tá à ń sọ yìí gbà “fọ aṣọ wọn”? Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “fọ aṣọ wọn” ní ti pé Jèhófà kà wọ́n sí ẹni tó mọ́ lójú rẹ̀ àti pé ó máa fún wọn ní àìleèkú ní ọ̀run níbi tí wọ́n á ti máa láyọ̀ títí láé. Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé máa di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, Jèhófà sì máa kà wọ́n sí olódodo. Ní báyìí, ‘wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’—Ìṣí. 7:9, 13, 14
15, 16. Báwo làwọn tí ọkàn wọn mọ́ gaara ṣe ń “rí Ọlọ́run”?
15 Báwo làwọn tí ọkàn wọn mọ́ gaara ṣe ń “rí Ọlọ́run,” nígbà tó jẹ́ pé “kò sí ènìyàn tí ó lè rí [Ọlọ́run] kí ó sì wà láàyè síbẹ̀”? (Ẹ́kís. 33:20) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “rí” lè túmọ̀ sí kéèyàn “mọ ohun kan, kó fojú inú wo nǹkan tàbí kó fòye mọ ohun kan.” Torí náà, àwọn tó bá fi “ojú ọkàn-àyà” wọn rí Ọlọ́run làwọn tó mọ irú Ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ tí wọ́n sì mọyì àwọn ànímọ́ rẹ̀. (Éfé. 1:18) Bí àpẹẹrẹ, Jésù gbé ànímọ́ Jèhófà yọ lọ́nà tó ta yọ gan-an, ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.”—Jòh. 14:7-9.
16 Bákan náà, a tún lè “rí Ọlọ́run” tá a bá ń kíyè sí bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. (Jóòbù 42:5) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń fọkàn yàwòrán àwọn ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí fáwọn tí ọkàn wọn mọ́ gaara tí wọ́n sì ń fòótọ́ inú sìn ín. Ó sì dájú pé àwọn ẹni àmì òróró máa rí Jèhófà nígbà tí wọ́n bá gba èrè wọn ní ọ̀run.—1 Jòh. 3:2.
A LÈ LÁYỌ̀ BÁ A TIẸ̀ Ń KOJÚ ÌṢÒRO
17. Kí nìdí táwọn tó lẹ́mìí àlàáfíà fi máa ń láyọ̀?
17 Jésù tún sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” (Mát. 5:9) Àwọn tó bá ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì máa ń láyọ̀. Jákọ́bù sọ pé: “Èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn tí ń wá àlàáfíà.” (Ják. 3:18) Tí àárín àwa àti ẹnì kan nínú ìjọ tàbí nínú ìdílé wa kò bá gún régé, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa fi àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣèwà hù, a sì máa láyọ̀. Jésù sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa wá àlàáfíà nígbà tó sọ pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mát. 5:23, 24.
18, 19. Kí ló ń mú káwa Kristẹni máa láyọ̀ láìka inúnibíni sí?
18 Jésù tún sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi.” Kí nìdí tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó fi kún un pé: “Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.” (Mát. 5:11, 12) Nígbà tí wọ́n na àwọn àpọ́sítélì, tí wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, wọ́n “bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀.” Kì í ṣe pé ó wù wọ́n láti jìyà, àmọ́ wọ́n ń láyọ̀ “nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ [Jésù].”—Ìṣe 5:41.
19 Bákan náà lónìí, àwa èèyàn Jèhófà ń fara da onírúurú àtakò nítorí orúkọ Jésù, síbẹ̀ à ń láyọ̀. (Ka Jákọ́bù 1:2-4.) Bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù, inú wa kì í dùn nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣenúnibíni sí wa, àmọ́ ó dá wa lójú pé tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin, Jèhófà máa fún wa nígboyà ká lè fara dà á. Bí àpẹẹrẹ, ní August 1944, àwọn aláṣẹ ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ rán Arákùnrin Henryk Dornik àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Nígbà tó yá, àwọn alátakò yẹn sọ pé: “Kò sọ́gbọ́n tá a lè fi yí wọn lọ́kàn pa dà láti ṣe ohunkóhun. Ńṣe ni inú wọn máa ń dùn láti kú nítorí ẹ̀sìn wọn.” Arákùnrin Dornik wá sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wù mí láti kú nítorí ẹ̀sìn, mo láyọ̀ láti fara da ìyà láìbẹ̀rù, ojú kò sì tì mí, nítorí pé mo jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. . . . Gbígbàdúrà látọkànwá jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, òun náà sì fi hàn pé Olùrànlọ́wọ́ tó ṣeé gbára lé lòun.”
20. Kí nìdí tá a fi ń láyọ̀ bá a ṣe ń sin “Ọlọ́run aláyọ̀”?
20 Tí inú Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀” bá ń dùn sí wa, a máa láyọ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa tàbí táwọn mọ̀lẹ́bí wa ń takò wá torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Kódà a máa láyọ̀ tá a bá ń ṣàìsàn tàbí tí ara wa bá ń dara àgbà. (1 Tím. 1:11) Yàtọ̀ síyẹn, à ń láyọ̀ torí ó dá wa lójú háún-háún pé Ọlọ́run wa, “ẹni tí kò lè purọ́” máa mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Títù 1:2) Nígbà táwọn ìlérí Jèhófà bá ṣẹ, a máa láyọ̀ débi pé a ò ní rántí àwọn ìṣòro tá a ní lásìkò yìí mọ́. Kódà, ó dìgbà yẹn ká tó mọ bí ìbùkún tá a máa gbádùn nínú Párádísè ṣe máa dùn tó. Kò sí àní-àní pé ayọ̀ tá a máa ní nígbà yẹn máa kọjá àfẹnusọ! Ó dájú pé a máa “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sm. 37:11.