-
Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | June 15
-
-
17. Ní ọ̀rọ̀ tìrẹ, ṣàlàyé òwe àkàwé tálẹ́ńtì ní kúkúrú.
17 Gbé òwe àkàwé Jesu nípa tálẹ́ńtì yẹ̀wò, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ ní Matteu 25:14-30. Ọkùnrin kan tí ó máa tó rín ìrìn-àjò lọ sí ìdálẹ̀ fi ọlá-àṣẹ pé àwọn ẹrú rẹ̀ ó sì fi àwọn nǹkan ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́. “Ó sì fi talẹnti márùn-ún fún ọ̀kan, méjì fún òmíràn, ati ẹyọkan fún òmíràn síbẹ̀, fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹlu agbára ìlèṣe nǹkan tirẹ̀.” Nígbà tí ọ̀gá náà padà dé láti yanjú ìṣirò owó pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀, kí ni ó rí? Ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì márùn-ún jèrè márùn-ún síi. Bákan náà, ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì méjì jèrè méjì síi. Ẹrú tí a ti fún ní tálẹ́ńtì kan bò ó mọ́ inú ilẹ̀ kò sì ṣe ohunkóhun láti sọ ọrọ̀ ọ̀gá rẹ̀ di púpọ̀. Báwo ni ọ̀gá náà ṣe gbé ipò náà yẹ̀wò?
18, 19. (a) Èéṣe tí ọ̀gá náà kò ṣe fi ẹrú tí a fún ní tálẹ́ńtì méjì wé ẹrú tí a fún ní tálẹ́ńtì márùn-ún? (b) Kí ni òwe àkàwé tálẹ́ńtì kọ́ wa nípa ìgbóríyìn àti ṣíṣe ìfiwéra? (d) Èéṣe tí a fi ṣèdájọ́ ẹrú kẹta lọ́nà tí kò báradé?
18 Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kí a gbé àwọn ẹrú tí a fún ní tálẹ́ńtì márùn-ún àti méjì yẹ̀wò níkọ̀ọ̀kan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹrú wọ̀nyí, ni ọ̀gá náà wí fún pé: “O káre láé, ẹrú rere ati olùṣòtítọ́!” Ohun yóò ha ti sọ èyí fún ẹrú náà tí ó ní tálẹ́ńtì márùn-ún bí ó bá jẹ́ pé méjì péré ni òun jèrè? Kò dájú! Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, òun kò sọ fún ẹrú náà tí ó jèrè tálẹ́ńtì méjì pé: ‘Èéṣe tí o kò fi jèrè márùn-ún? Họ́wù, wo ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ sì wo iye tí ó jèrè fún mi!’ Rárá, ọ̀gá oníyọ̀ọ́nú náà, tí ó ṣàpẹẹrẹ Jesu, kò ṣe ìfiwéra. Ó yan tálẹ́ńtì “fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹlu agbára ìlèṣe nǹkan tirẹ̀,” kò sì retí ohunkóhun padà ju ohun tí olúkúlùkù bá lè fúnni. Àwọn ẹrú méjèèjì gba oríyìn kan náà, nítorí pé àwọn méjèèjì fi tọkàn tọkàn ṣiṣẹ́ fún ọ̀gá wọn. Gbogbo wa lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú èyí.
-
-
Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?Ilé-Ìṣọ́nà—1995 | June 15
-
-
20. Báwo ni Jehofa ṣe ń wo àwọn ààlà wa?
20 Jehofa retí pé kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nífẹ̀ẹ́ òun pẹ̀lú gbogbo okun wa, síbẹ̀ ẹ wo bí ó ti múni lọ́kàn yọ̀ tó pé “ó mọ ẹ̀dá wa; ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá”! (Orin Dafidi 103:14) Owe 21:2 (NW) sọ pé “Jehofa ń ṣe ìfojú díwọ̀n ọkàn-àyà”—kì í ṣe àkójọ ìsọfúnni oníṣirò. Ó lóye ààlà èyíkéyìí tí a kò ní agbára lé lórí, yálà wọ́n jẹ́ ti ìṣúnná owó, ti ará, ti èrò-ìmọ̀lára, tàbí lọ́nà mìíràn. (Isaiah 63:9) Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ó ń retí pé kí a lo èyí tí ó dára jù nínú gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ wa tí a lè ní. Jehofa jẹ́ ẹni pípé, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ń bá àwọn olùjọsìn rẹ̀ aláìpé lò, òun kì í ṣe olójú-ìwòye pé ohunkóhun tí ó bá dínkù sí ìjẹ́pípé kò yẹ ní títẹ́wọ́gbà. Kì í ṣe aláìlọ́gbọ́n nínú, nínú àwọn ìbálò rẹ̀ tàbí aláìlóye nínú àwọn ìfojúsọ́nà rẹ̀.
-