Ori 7
Ṣiṣe Iṣiro Lori Ìlò Owó-Àkànlò Kristi
1. Ijọba wo ni kò ní awọn iṣoro iṣunna owo kankan, awọn wo nisinsinyi ni wọn si gbọdọ ṣe iṣiro pẹlu ijọba yii?
KÒ SI ijọba eyikeyii ti kò ní awọn iṣoro iṣunna owo, ayafi ọkanṣoṣo. Awọn ijọba ti ó pọ̀ julọ ni ẹrù gbèsè ń wọ̀ lọrun. Ijọba kanṣoṣo naa ti ó dá yatọ yii ni “ijọba ọ̀run” ti a ń polongo rẹ̀ lọna gbigbooro nisinsinyi. (Matteu 25:1) Awọn mẹmba-lọla ti Ijọba ọ̀run naa ti wọn wà lẹnu iṣẹ-isin ijọba yẹn ṣì wà lori ilẹ̀-ayé. Ní ìgbà oniyanpọnyanrin julọ yii ní gbogbo itan iran eniyan, awọn iranṣẹ “ijọba ọ̀run” wọnyi ni a ń kesi lati wá ṣe iṣiro. Wọn gbọdọ yanju araawọn lọdọ ijọba naa niti bi wọn ṣe lo awọn ohun-ìní iyebiye ti a fi si ìkáwọ́ wọn.
2. Eeṣe ti a fi gbọdọ ní ifẹ-ọkan si owe kan bayii ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa pa?
2 Lati ṣe akawe ọran yii, òléwájú aṣoju “ijọba ọ̀run” yẹn pa owe, tabi ṣe akawe kan tipẹtipẹ sẹhin. Eyi yẹ ki ó gba afiyesi wa lonii, nitori “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa fi i kún asọtẹlẹ rẹ̀ ọlọjọ gbọọrọ nipa “ami” ti yoo samisi “wiwanihin-in” rẹ̀ ninu Ijọba pẹlu ẹkunrẹrẹ aṣẹ lati ṣakoso. (Matteu 24:3, NW) Abajade ti ó tẹ̀lé imuṣẹ owe alasọtẹlẹ naa kàn wá lonii láìlè ja àjàbọ́ niwọn bi igbesi-aye wa, ati wiwalaaye wa niṣo ti wemọ ọ. Nitori naa bayii ni ọna ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa gbà pa owe naa fun awọn aposteli rẹ̀ ní ọjọ diẹ ṣaaju iku irubọ rẹ̀ lori Kalfari.
Owe Awọn Talenti
3. Bawo ni awọn ẹrú ti wọn gba talenti lọwọ oluwa naa ki o tó lọ si ìrìn àjò rẹ̀ ṣe lò wọn nigba ti kò si nile?
3 “Nitori naa, ẹ maa ṣọna, bi ẹyin ko ti mọ ọjọ, tabi wakati ti ọmọ eniyan yoo dé. Nitori ijọba ọ̀run dabi ọkunrin kan ti ó ń lọ si àjò, ẹni ti ó pe awọn ọmọ-ọ̀dọ̀ [“ẹrú,” NW] rẹ̀, ó sì ko ẹrù rẹ̀ fun wọn. O si fi talentia marun-un fun ọkan, o sì fi meji fun ẹnikeji, ati ọkan fun ẹnikẹta; o fi fun olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti ri; lẹsẹkan naa o mu ọna àjò rẹ̀ pọ̀n. Nigba naa ni eyi ti ó gba talenti marun-un lọ, o fi tirẹ ṣowo, o si jere talenti marun-un miiran. Gẹgẹ bẹẹ ni eyi ti ó gba meji, oun pẹlu si jere meji miiran. Ṣugbọn eyi ti ó gba talenti kan lọ, o wa ilẹ̀, o si ri owo oluwa rẹ̀.
4. Ki ni ohun ti oluwa naa wi fun awọn ẹrú ti wọn mu ki talenti wọn lé sii?
4 “Lẹhin igba ti ó pẹ titi, oluwa awọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọnni de, ó ba wọn ṣiro. Eyi ti ó gba talenti marun-un si wá, o si mu talenti marun-un miiran wá pẹlu, o wi pe, Oluwa, iwọ fi talenti marun-un fun mi: si wò ó, mo jere talenti marun-un miiran. Oluwa rẹ̀ wi fun un pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere ati oloootọ; iwọ ṣe oloootọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pupọ: iwọ bọ sinu ayọ̀ oluwa rẹ. Eyi ti ó gba talenti meji pẹlu si wá, o wi pe, Oluwa, iwọ fi talenti meji fun mi: wò ó, mo jere talenti meji miiran. Oluwa rẹ̀ si wi fun un pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere ati oloootọ; iwọ ṣe oloootọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pupọ: iwọ bọ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.
5, 6. Awawi wo ni ẹrú kẹta ṣe fun fifi talenti naa pamọ, ki ni oluwa naa si ṣe fun un?
5 “Eyi ti ó gba talenti kan si wá, o ni, Oluwa, mo mọ̀ ọ́ pe onroro eniyan ni iwọ ń ṣe, iwọ ń kore nibi ti iwọ kò gbe funrugbin si, iwọ sì ń ṣà nibi ti iwọ kò fẹ́ká si: Emi si bẹru, mo si lọ pa talenti rẹ mọ́ ninu ilẹ̀: wò ó, nǹkan rẹ niyii. Oluwa rẹ̀ si dahun, ó wi fun un pe, Iwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi ń kore nibi ti emi kò funrugbin si, emi sì ń ṣà nibi ti emi kò fẹ́ká si. Nitori naa iwọ ìbá fi owo mi si ọwọ awọn ti ń powódà, nigba ti emi ba de, emi ìbá si gba nǹkan mi ti oun ti èlé.
6 “Nitori naa ẹ gba talenti naa ní ọwọ rẹ̀, ẹ si fi fun ẹni ti ó ní talenti mẹwaa. Nitori ẹnikẹni ti ó ba ni, ni a o fifun, yoo sì ní lọpọlọpọ: ṣugbọn ní ọwọ́ ẹni ti kò ní ni a o tilẹ gba eyi ti ó ni. Ẹ si gbe alailere ọmọ-ọ̀dọ̀ naa sọ sinu okunkun lode: nibẹ ni ẹkun oun ipahinkeke yoo gbé wà.”—Matteu 25:13-30.
7. Ki ni awọn talenti naa duro fun?
7 Ninu owe yii, ki ni awọn talenti naa duro fun? Ohun kan ti ó niyelori gidigidi, kii ṣe niti owó ṣugbọn loju iwoye tẹmi. Awọn talenti naa duro fun iṣẹ aṣẹ naa lati sọ awọn eniyan di ọmọ-ẹhin Kristi. Papọ pẹlu iṣẹ aṣẹ yii ni akanṣe ojurere gigalọla naa ti anfaani jijẹ ikọ̀ fun Kristi, Ọba, lati ṣoju fun Ijọba naa ní gbogbo orilẹ-ede ayé.—Efesu 6:19, 20; 2 Korinti 5:20.
8. (a) Inu okunkun wo ni a ju ẹgbẹ ẹrú “onilọra” naa si laaarin “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” yii? (b) Eeṣe ti ayé araye ko fi gbadun imọlẹ ojurere ati ibukun Ọlọrun?
8 Rekọja iyemeji eyikeyii, awa lonii ti de ògógóró imuṣẹ owe alasọtẹlẹ yii! Akoko ti ó ṣú dùdù julọ ninu itan iran eniyan ti jalu iran yii! Nitootọ, okunkun ti ó baamu gẹẹ wà lẹhin ode apa ti ó ṣeefojuri ti ètò-àjọ Jehofa ninu eyi ti a lè ju ẹgbẹ ẹrú “onilọra” ati “alailere” naa si bi Oluwa naa ba ti pa a laṣẹ. Iru “okunkun lode” naa ṣapejuwe ipo araye ti ó ṣokunkun, paapaa ní pataki ní oju iwoye ti isin. Ayé araye kò gbadun imọlẹ ojurere ati ibukun Ọlọrun. Kò si ninu imọlẹ imoye Ijọba Ọlọrun. O wà labẹ “ọlọrun ayé yii,” ẹni ti ó ti “sọ ọkan awọn ti kò gbagbọ di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti ó logo, ẹni ti ń ṣe aworan Ọlọrun, ki ó maṣe mọlẹ ninu wọn.”—2 Korinti 4:4.
9. (a) Ní imuṣẹ owe naa, ta ni “ọkunrin” naa ṣapẹẹrẹ rẹ̀, bawo si ni ìrìn àjò rẹ̀ ti jinna tó? (b) Ẹri wo ni o si fi ipadabọ rẹ̀ hàn?
9 Lonii ẹri naa bonimọlẹ pe ẹni ti “ọkunrin” naa ṣapẹẹrẹ rẹ̀, ti ó ni ó keretan awọn talenti fadaka mẹjọ ninu ìní rẹ̀, ti dé lati ìrìn àjò rẹ̀ si ilu okeere. “Ọkunrin” yẹn ni Kristi Jesu. Ìrìn àjò rẹ̀ si ilu okeere mú un dé iwaju Ẹlẹ́dàá oorun, oṣupa, ati awọn irawọ agbaye wa yii. Lati samisi ipadabọ rẹ̀, ogun meji ti ó jà kari gbogbo ayé, ti ọpọ awọn ogun keekeeke miiran ní ifiwera sì ń ba wọn rin nisinsinyi, ti fi ẹ̀jẹ̀ wẹ ilẹ̀-ayé wa. Bi a ti sọ ọ tẹ́lẹ̀, awọn wọnyi ni ìyàn, ajakalẹ arun, ati isẹlẹ, ati iwa aibofinmu ti ó tubọ ń pọ sii pẹlu wiwaasu “ihinrere ijọba yii” ní ibi gbogbo ti eniyan ń gbe lori ilẹ̀-ayé ti bá rìn. Eyi ti mu awọn ohun ti Jesu sọ pe yoo jẹ́ “ami wiwanihin-in [rẹ̀] ati ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” ṣẹ ní kinnikinni.—Matteu 24:3-15, NW.
10. (a) Eeṣe ti ọkunrin naa fi rin ìrìn àjò lọ si ilu okeere? (b) Eeṣe ti ó si fi jẹ́ pe ayé araye kò ri ipadabọ rẹ̀ niti gidi?
10 Bi o tilẹ jẹ pe a kò fihan ni pato ninu owe Jesu, ọkunrin naa ti ó ń rinrin àjò lọ si ilu okeere, ti ko ní si nile fun igba pipẹ, niti gidi mu ọna rẹ̀ pọ̀n lati gba “ijọba ọ̀run,” eyi ti a tọkasi ṣaaju ninu Matteu 25:1. Laika ibẹsilẹ Ogun Agbaye I sí, Jehofa Ọlọrun, ẹni ti a bi ijọba rẹ̀ lori Israeli ṣubu ní 607 B.C.E., gbe Àròlé ti ó lẹ́tọ̀ọ́ si Ijọba naa gun ori itẹ ní 1914 C.E., nigba ti akoko tó lati dá itẹmọlẹ naa duro. Rara, awọn orilẹ-ede Keferi kò fi ojuyooju wọn ri gigun ori itẹ Ẹni naa ti Ọba Dafidi pè ní “Oluwa mi.” (Orin Dafidi 110:1) Kò ṣeeṣe fun wọn lati ṣe bẹẹ nitori pe ọkunrin inu owe naa, Jesu Kristi, ti sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ṣaaju rírin ìrìn àjò lọ si ilu okeere pe: “Nigba diẹ sii, ayé ki o si ri mi mọ́.”—Johannu 14:19.
11. (a) Ki ni yoo jẹ́ apakan ohun ti yoo samisi ipadabọ ati wiwanihin-in rẹ̀? (b) Nigba wo ni eyi yoo sì ṣẹlẹ?
11 Niwọn bi wíwá Kristi sinu agbara Ijọba ọ̀run ti jẹ́ alaiṣee fi oju eniyan ri, oun nilati mu ki wiwanihin-in rẹ̀ ninu agbara Ijọba ọ̀run hàn kedere nipasẹ àmì ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ beere lọwọ rẹ̀ ní ọjọ mẹta ṣaaju iku ajẹriiku rẹ̀. Apakan àmì didaju naa yoo jẹ́ pe ọkunrin naa yoo padabọ lati ìrìn àjò ilu okeere rẹ̀ yoo si ṣe iṣiro pẹlu awọn ẹrú ti ó fi awọn talenti oniyebiye gidigidi nì lé lọwọ. Bi ọran ba ri bayii, ṣiṣe iṣiro yẹn pẹlu awọn ti a ṣe ojurere si lati lo awọn talenti yẹn yẹ ki ó ti ṣẹlẹ lẹhin 1914.
12. (a) Ta ni iṣẹ aigbọdọmaṣe naa já lé lejika lati mu ipo iwaju ninu jijẹrii Ijọba naa? (b) Igbala wọn nikẹhin sinmi lori ki ni?
12 Eyi yoo tumọsi ṣiṣe iṣiro pẹlu awọn wọnni ti wọn jẹ́ ajogun “ijọba ọ̀run” naa. Eyi yoo tọkasi ṣiṣe iṣiro pẹlu àṣẹ́kù ẹgbẹ Kristian naa, ti a ti fi ẹmi Ọlọrun bi lati ọjọ Pentekosti ọdun 33 C.E. (Iṣe, ori 2) Àṣẹ́kù awọn wọnyi ni yoo ṣi wà lori ilẹ̀-ayé laaarin “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” isinsinyi lati 1914 siwaju. Awọn wọnyi ni iṣẹ aigbọdọmaṣe naa yoo já lé lejika lati mu ipo iwaju ninu mimu asọtẹlẹ Jesu fun akoko yẹn ṣẹ: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ní gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo si de.” (Matteu 24:14; Marku 13:10) Lori wọn ni ẹru-iṣẹ naa lati jẹ́ oluṣotitọ titi de opin sinmi le, lati lè ri igbala sinu Ijọba ọ̀run. (Matteu 24:13) Pẹlu ète ti gbigba wọn là ní igbẹhin, Ọlọrun Olodumare ti fun wọn lokun lati farada a titi di isinsinyi, laika inunibini kárí-ayé si. Otitọ yii jẹ́ ẹri pe oun tẹwọgba wọn!
Awọn Ti Wọn Fi Eke Sọ Pe Wọn ní Awọn Talenti naa Ní Ìkáwọ́
13. (a) Ta ni sọ pe oun ti gba awọn talenti naa? (b) Opin ero wo ni a wa dé nipa rẹ̀?
13 Kristẹndọm sọ pe a ti dá oun lọla ní fifi awọn talenti ọkunrin ọlọrọ inu owe Jesu naa si ìkáwọ́ oun. Ṣugbọn nigba ti a ba gbé itolẹsẹẹsẹ ipa ọna rẹ̀ lati 1914 yẹwo, opin ero wo ni a wá dé? Eyi: Kò tii gbe ní ibamu pẹlu awọn ohun ti ó sọ pe oun jẹ́. Laijẹ oluṣotitọ si ọkunrin inu owe naa, oun ti wọnu ajọṣepọ pẹlu awọn ijọba ayé yii; awọn oloṣelu awọn ijọba ayé yẹn ni àlè rẹ̀. Oun sì ń ti Iparapọ Awọn Orilẹ-Ede lẹhin, eyi ti ó jẹ́ arọpo Imulẹ Awọn Orilẹ-Ede ti ó ti di oku nisinsinyi.
14. Nibo ni a ti ri Kristẹndọm lonii?
14 Kò tilẹ bá ẹrú onitalenti kan mu paapaa, ẹni ti ó lọra ti kò sì fikun ohun-ìní oluwa rẹ̀. Nitori naa ní akoko yii lati ìgbà ògógóró Ogun Agbaye I ní 1918, a ti tudii Kristẹndọm patapata gẹgẹ bi ẹni ti ó ti fi ìgbà gbogbo wà ninu okunkun lẹhin ode ile Oluwa naa ti a tan imọlẹ si daradara. Ni ààjìn oru nita nibẹ ninu ayé, ki a sọ ọ lọna apejuwe, ni ẹkun pẹlu ipahinkeke rẹ̀ ti bẹrẹsii ṣẹlẹ bayii. Pupọ sii yoo si tun ṣẹlẹ nigba ti awọn àlè rẹ̀ oloṣelu ba yijupada ní idojuuja kọ ọ ti wọn sì tu u si ihoho gẹgẹ bi apa ti ó lẹgan julọ ninu gbogbo Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye.
A Gbé Ẹgbẹ “Ẹru Buburu” naa Jù Sode
15. Awọn wo ni wọn ti mu apejuwe ti ẹrú onilọra naa ṣẹ, nibo ni wọn sì ti ba araawọn nisinsinyi?
15 Awọn wọnni ti wọn jẹ́ apakan àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo ti a fi ẹmi yàn naa tẹlẹri niti tootọ ti a si ti fi ohun iyebiye Ijọba naa si ìkáwọ́ wọn, ṣugbọn ti wọn ti dawọ ṣiṣe isapa ti mimu ki ire Oluwa naa ti ó ti padabọ bisii duro, ni a ti jù sode kuro ninu iṣẹ-isin ọba ti Oluwa naa. (Matteu 24:48-51) A kò tun rii ki ẹgbẹ “ẹrú buburu” onilọra naa maa waasu “ihinrere ijọba yii” mọ́. Kàkà bẹẹ, igbala ti araawọn ni wọn gbajumọ dipo ire Ijọba Ọlọrun. Wọn wa ba araawọn ninu “okunkun lode,” nibi ti ayé araye wà. A ti gba talenti iṣapẹẹrẹ wọn lọwọ wọn a sì ti fi i fun ẹgbẹ naa ti ó ti fi ifinnufindọ hàn lati lo talenti naa laaarin apa ti ó ṣẹku ti “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” yii.
16. (a) Fun ìlò awọn talenti iṣapẹẹrẹ wo ni eyi jẹ́ akoko ti ó wọ̀ julọ fun? (b) Iṣẹ aigbọdọmaṣe wo ni o já lé “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” lejika nisinsinyi?
16 Kò tii si ìgbà kan ri lae ti ó wọ̀ ju eyi lọ fun pipolongo “ihinrere ijọba naa” nipa lilo “talenti” naa, iyẹn ni, akanṣe ojurere àrà-ọ̀tọ̀ naa, anfaani, jijẹ “ikọ̀ fun Kristi,” Ọba naa ti ń jọba, ati sisọ awọn eniyan di ọmọ-ẹhin rẹ̀. (2 Korinti 5:20) Bi opin si ti ń sunmọle kiakia, ohun ti ó yẹ ki “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ṣe ni lati ṣeranwọ fun àṣẹ́kù awọn ikọ̀ ti a fi ẹmi bi naa bi wọn ti ń fi pẹlu itara lo “talenti” iyebiye ti a fi si ikawọ wọn lẹkun-unrẹrẹ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Talenti fadaka ti Griki kan ń wọn 654 iwọn ounce ninu iwọn troy (20.4 kg).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 59]
Awọn wọnni ti wọn fi animọ ìwà bi ti ẹrú buburu naa hàn ni a gbé jù sode kuro ninu iṣẹ-isin Oluwa naa sinu okunkun