‘Ẹrú Olóòótọ́’ Náà Yege Nígbà Àbẹ̀wò!
“Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti tó fún ìdájọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run.”—1 Pétérù 4:17.
1. Kí ni Jésù rí nígbà tó bẹ “ẹrú” náà wò?
NÍ ỌJỌ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù yan “ẹrú” kan láti máa pèsè oúnjẹ fún “àwọn ará ilé” rẹ̀ ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mú. Ní ọdún 1914 a fi Jésù jẹ Ọba, kété lẹ́yìn náà ni àkókò tó láti bẹ “ẹrú” náà wò. Ó rí i pé àwọn tó pọ̀ jù lára “ẹrú” náà ló jẹ́ “olóòótọ́ àti olóye.” Nítorí náà, ó yàn án sípò “lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Mátíù 24:45-47) Àmọ́ ṣá o, ẹrú “búburú” kan wà tí kò jẹ́ olóòótọ́ àti olóye.
“Ẹrú Búburú Yẹn”
2, 3. Ibo ni “ẹrú búburú yẹn” ti wá, báwo ló sì ṣe di ẹni burúkú?
2 Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹrú búburú náà kété lẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Ó sọ pé: “Bí ẹrú búburú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pẹ́nrẹ́n pé, ‘Ọ̀gá mi ń pẹ́,’ tí ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó sì ń jẹ, tí ó sì ń mu pẹ̀lú àwọn ọ̀mùtí paraku, ọ̀gá ẹrú yẹn yóò dé ní ọjọ́ tí kò fojú sọ́nà fún àti ní wákàtí tí kò mọ̀, yóò sì fi ìyà mímúná jù lọ jẹ ẹ́, yóò sì yan ipa tirẹ̀ fún un pẹ̀lú àwọn alágàbàgebè. Níbẹ̀ ni ẹkún rẹ̀ àti ìpayínkeke rẹ̀ yóò wà.” (Mátíù 24:48-51) Gbólóhùn náà “ẹrú búburú yẹn” pe àfiyèsí wa sí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣáájú nípa ẹrú olóòótọ́ àti olóye. Ó dájú pé “ẹrú búburú” náà jẹ́ ara ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà nígbà kan rí.a Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
3 Ṣáájú ọdún 1914, ọ̀pọ̀ lára ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ yẹn ló ní in lọ́kàn pé àwọn máa pàdé Ọkọ ìyàwó ní ọ̀run lọ́dún yẹn, ṣùgbọ́n ìrètí wọ́n ṣákìí. Nítorí ìdí yẹn àtàwọn nǹkan mìíràn tó ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ sọ̀rètí nù, èyí sì bà wọ́n lọ́kàn jẹ́. Àwọn kan lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí fi ọ̀rọ̀ “lu” àwọn tí wọ́n jẹ́ arákùnrin wọn tẹ́lẹ̀, wọ́n wá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú “àwọn ọ̀mùtí paraku,” ìyẹn ẹgbẹ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì.—Aísáyà 28:1-3; 32:6
4. Kí ni Jésù ṣe fún “ẹrú búburú” náà àti fún gbogbo àwọn tó fi irú ẹ̀mí bíi ti ẹrú náà hàn?
4 Àwọn Kristẹni tẹ́lẹ̀ rí yìí la wá mọ̀ sí “ẹrú búburú” náà, Jésù sì “fi ìyà mímúná jù lọ jẹ” wọ́n. Báwo ló ṣe ṣe é? Ó kọ̀ wọ́n sílẹ̀, wọ́n sì pàdánù ìrètí wọn ti ọ̀run. Àmọ́ ṣá o, a kò pa wọn run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Wọ́n kọ́kọ́ fara da sáà ẹkún àti ìpayínkeke nínú “òkùnkùn lóde” ìjọ Kristẹni. (Mátíù 8: 12) Láti àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn wa, àwọn ẹni àmì òróró mélòó kan ti fi irú ẹ̀mí búburú kan náà hàn, wọ́n sì sọ ara wọn di “ẹrú búburú.” Àwọn kan lára “àwọn àgùntàn mìíràn” fara wé ìwà àìṣòótọ́ wọn. (Jòhánù 10:16) Gbogbo irú àwọn ọ̀tá Kristi bẹ́ẹ̀ ló máa ń bá ara wọn nínú ‘òkùnkùn tẹ̀mí lóde.’
5. Báwo ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye ṣe ṣe, tó mú kó yàtọ̀ sí “ẹrú búburú” náà?
5 Pẹ̀lú gbogbo èyí, ẹrú olóòótọ́ àti olóye dojú kọ ìdánwò kan náà tó dojú kọ “ẹrú búburú yẹn.” Àmọ́ kàkà kí ìdánwò náà bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ ńṣe ni wọ́n mú ara wọn bá ipò náà mu. (2 Kọ́ríńtì 13:11) Èyí mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà àti sí àwọn arákùnrin wọn túbọ̀ lágbára sí i. Ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni pé, wọ́n di “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́” ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” oníyánpọnyánrin yìí.—1 Tímótì 3:15; 2 Tímótì 3:1.
Àwọn Wúńdíá Olóye àti Òmùgọ̀
6. (a) Báwo ni Jésù ṣe ṣàpèjúwe òye tí ẹgbẹ́ ẹrú rẹ̀ olóòótọ́ ní? (b) Ṣáájú ọdún 1914, ìhìn wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń polongo rẹ̀?
6 Lẹ́yìn tí Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa “ẹrú búburú yẹn,” ó sọ àkàwé méjì láti fi ṣàlàyé ìdí tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan yóò fi jẹ́ olóòótọ́ àti olóye nígbà tí àwọn mìíràn kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.b Ó ṣàpèjúwe ohun tí òye jẹ́, o ní: “Ìjọba ọ̀run yóò wá dà bí wúńdíá mẹ́wàá tí wọ́n mú fìtílà wọn, tí wọ́n sì jáde lọ láti pàdé ọkọ ìyàwó. Márùn-ún nínú wọn jẹ́ òmùgọ̀, márùn-ún sì jẹ́ olóye. Nítorí àwọn òmùgọ̀ mú fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú òróró pẹ̀lú wọn, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn olóye mú òróró sínú kòlòbó wọn pẹ̀lú fìtílà wọn.” (Mátíù 25:1-4) Àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà rán wa létí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n wà ṣáájú ọdún 1914. Wọ́n fọkàn ṣírò rẹ̀ pé ọkọ ìyàwó náà, Jésù Kristi, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. Nítorí náà, wọ́n “jáde lọ” láti pàdé rẹ̀, wọ́n ń fìgboyà wàásù pé “àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” yóò dópin ní ọdún 1914.—Lúùkù 21:24.
7. Nígbà wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ‘sùn lọ’ nípa tẹ̀mí, kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀?
7 Èrò wọn tọ̀nà. Àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè dópin lóòótọ́ ni ọdún 1914, Ìjọba Ọlọ́run tá a fi síkàáwọ́ Kristi Jésù sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àmọ́, inú ọ̀run tí a kò lè fojú rí nìyẹn ti ṣẹlẹ̀ o. Lórí ilẹ̀ ayé níbí, “ègbé” tá a sọ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá aráyé. (Ìṣípayá 12: 10, 12) Àkókò ìdánwò dé. Nítorí àìlóye nǹkan wọ̀nyí dáadáa, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró rò pé “ọkọ ìyàwó ń pẹ́.” Nítorí ọkàn wọn tó pòrúurùu tí ayé sì gbógun tì wọ́n, wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù ìta gbangba tá a ṣètò dúró. Bíi ti àwọn wúńdíá inú àkàwé náà, wọn “tòògbé, wọ́n sì sùn lọ” nípa tẹ̀mí, àní bí àwọn Kristẹni aláìṣòótọ́ ti ṣe lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì Jésù.—Mátíù 25:5; Ìṣípayá 11:7, 8; 12:17.
8. Kí ló fa igbe náà pé: “Ọkọ ìyàwó ti dé!” kí sì ní àkókò tó fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró láti ṣe?
8 Ẹ̀yìn ìyẹn ni ohun kan wá ṣẹlẹ̀ lójijì ní ọdún 1919. A kà á pé: “Ní àárín òru gan-an, igbe ta, ‘Ọkọ ìyàwó ti dé! Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n láti pàdé rẹ̀.’ Nígbà náà ni gbogbo wúńdíá wọnnì dìde, wọ́n sì mú fìtílà wọn wà létòletò.” (Mátíù 25:6, 7) Nígbà tí gbogbo ìrètí tí wọ́n ní ti pòórá, ni ìpè kan jáde pé kí iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹu! Ní ọdún 1918, Jésù tó jẹ́ “ońṣẹ́ májẹ̀mú náà” wá sínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà láti bẹ̀ ìjọ Ọlọ́run wò, kí ó sì fọ̀ ọ́ mọ́. (Málákì 3:1) Nísinsìnyí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní láti lọ pàdé rẹ̀ nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì yẹn lórí ilẹ̀ ayé. Ó tó àkókò fún wọn láti “tan ìmọ́lẹ̀ jáde.”—Aísáyà 60:1; Fílípì 2:14, 15.
9, 10. Ní ọdún 1919, kí ló mú kí àwọn Kristẹni kan jẹ́ “olóye” tí àwọn kan sì jẹ́ “òmùgọ̀”?
9 Àmọ́, dúró ná! Nínú àkàwé náà, àwọn kan lára àwọn ọ̀dọ́bìnrin yẹn ní ìṣòro kan. Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Àwọn òmùgọ̀ sọ fún àwọn olóye pé, ‘Ẹ fún wa ní díẹ̀ nínú òróró yín, nítorí pé àwọn fìtílà wa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.’” (Mátíù 25:8) Láìsí òróró, fìtílà kò lè tan ìmọ́lẹ̀. Òróró fìtílà rán wa létí Ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, èyí tó ń fún àwọn olùjọsìn tòótọ́ lágbára láti jẹ́ olùtan ìmọ́lẹ̀. (Sáàmù 119:130; Dáníẹ́lì 5:14) Ṣáájú ọdún 1919, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ olóye fi aápọn wá ọ̀nà láti lóye ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ fún wọn, láìka ipò àìlera tí wọ́n wà sí. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìpè náà pé kí wọ́n tan ìmọ́lẹ̀ jáde, wọ́n gbára dì.—2 Tímótì 4:2; Hébérù 10:24, 25.
10 Àmọ́, àwọn ẹni àmì òróró kan kò gbára dì láti fi gbogbo ara wọn ṣiṣẹ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fọkàn fẹ́ láti wà lọ́dọ̀ Ọkọ ìyàwó. Nítorí náà, wọn ò múra sílẹ̀ nígbà tí àkókò tó fún wọn láti wàásù ìhìn rere. (Mátíù 24:14) Kódà wọ́n ń gbìyànjú láti fa àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó jẹ́ onítara sẹ́yìn, wọ́n ń sọ pé kí wọ́n bù nínú òróró wọn fún àwọn. Nínú àkàwé Jésù, kí ni àwọn wúńdíá olóye náà ṣe? Wọ́n sọ pé: “Bóyá ó lè má tó rárá fún àwa àti ẹ̀yin. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń tà á, kí ẹ sì ra tiyín.” (Mátíù 25:9) Lọ́nà kan náà, àwọn adúróṣinṣin Kristẹni ẹni àmì òróró ní ọdún 1919 kò ṣe ohunkóhun tí yóò dín agbára wọn láti tan ìmọ́lẹ̀ kù. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n yege nígbà àbẹ̀wò náà.
11. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn òmùgọ̀ wúńdíá?
11 Jésù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí [àwọn òmùgọ̀ wúńdíá] tí ń lọ láti rà á, ọkọ ìyàwó dé, àwọn wúńdíá tí wọ́n sì ti gbára dì wọlé pẹ̀lú rẹ̀ síbi àsè ìgbéyàwó náà; a sì ti ilẹ̀kùn. Lẹ́yìn ìgbà náà, ìyókù àwọn wúńdíá náà pẹ̀lú dé, wọ́n wí pé, ‘Ọ̀gá, ọ̀gá, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ní ìdáhùn, ó wí pé, ‘Mo sọ òtítọ́ fún yín, èmi kò mọ̀ yín.’” (Mátíù 25:10-12) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn kan kò múra sílẹ̀ de Ọkọ ìyàwó. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò yege nígbà àbẹ̀wò, wọ́n sì pàdánù àǹfààní láti wà níbi àsè ìgbéyàwó ti ọ̀run. Èyí mà bani nínú jẹ́ o!
Àkàwé Tálẹ́ńtì
12. (a) Kí ni Jésù fi ṣe àkàwé ohun tí ìṣòtítọ́ jẹ́? (b) Ta ni ọkùnrin tó “lọ sí ìdálẹ̀”?
12 Lẹ́yìn tí Jésù ṣe àkàwé ohun tí òye jẹ́, ó wá ṣe àkàwé ohun tí ìṣòtítọ́ jẹ́. Ó sọ pé: “Ó rí gan-an bí ìgbà tí ọkùnrin kan, tí ó máa tó rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀, fi ọlá àṣẹ pe àwọn ẹrú rẹ̀, tí ó sì fi àwọn nǹkan ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́. Ó sì fi tálẹ́ńtì márùn-ún fún ọ̀kan, méjì fún òmíràn, àti ẹyọ kan fún òmíràn síbẹ̀, fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìlèṣe-nǹkan tirẹ̀, ó sì lọ sí ìdálẹ̀.” (Mátíù 25:14, 15) Jésù fúnra rẹ̀ ni ọkùnrin tó “lọ sí ìdálẹ̀,” nígbà tó gòkè re ọ̀run ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Àmọ́, kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó fi “àwọn nǹkan ìní rẹ” síkàáwọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́. Báwo ló ṣe ṣe é?
13. Báwo ni Jésù ṣe múra ìgbòkègbodò ńlá sílẹ̀, tó sì pàṣẹ fún “àwọn ẹrú” rẹ̀ láti ṣòwò?
13 Ní ìgbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò ìgbòkègbodò ńlá ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà káàkiri ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (Mátíù 9:35-38) Ṣáájú kó tó “lọ sí ìdálẹ̀,” ó fi iṣẹ́ yẹn síkàáwọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́, ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ.” (Mátíù 28:18-20) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jésù fi pa àṣẹ fún “àwọn ẹrú” rẹ̀ láti ṣòwò títí òun á fi padà dé, ‘gẹ́gẹ́ bí agbára olúkálukú ti lè gbé e.’
14. Kí nìdí tá ò fi retí pé kí gbogbo wọn ṣòwò bá kan náà?
14 Gbólóhùn yẹn fi hàn pé ipò tí gbogbo àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wà kò rí bákan náà. Àwọn kan bíi Pọ́ọ̀lù àti Tímótì láǹfààní kíkúnrẹ́rẹ́ láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Ipò tí àwọn yòókù wà lè máà jẹ́ kí wọ́n ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹrú làwọn Kristẹni kan, àwọn mìíràn jẹ́ aláìlera, àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí làwọn kan, àwọn kan sì ní ẹrù ìdílé tí wọ́n ń gbé. Ó dájú pé àwọn àǹfààní kan wà nínú ìjọ tí kò tẹ gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́wọ́. Àwọn obìnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró àtàwọn kan lára àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró kì í kọ́ni nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 14:34; 1 Tímótì 3:1; Jákọ́bù 3:1) Síbẹ̀, láìka ipò tí àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi wà sí, gbogbo wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ni a yàn láti ṣòwò, ìyẹn láti lo àwọn àǹfààní àti ipò wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tòde òní ń ṣe ohun kan náà.
Àkókò Àbẹ̀wò Bẹ̀rẹ̀!
15, 16. (a) Ìgbà wo ni àkókò tó láti ṣèṣirò? (b) Àkọ̀tun àǹfààní wo ni a fún àwọn olóòótọ́ láti “ṣòwò”?
15 Àkàwé náà ń bá a lọ pé: “Lẹ́yìn àkókò gígùn, ọ̀gá ẹrú wọnnì dé, ó sì yanjú ìṣírò owó pẹ̀lú wọn.” (Mátíù 25:19) Ní ọdún 1914, ìyẹn àkókò gígùn lẹ́yìn ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ni wíwà níhìn-ín Jésù Kristi nínú ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn náà, ní ọdún 1918, ó wá sí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Ọlọ́run láti mú ọ̀rọ̀ Pétérù ṣẹ pé: “Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti tó fún ìdájọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run.” (1 Pétérù 4:17; Málákì 3:1) Àkókò ti tó láti ṣèṣirò.
16 Kí ni àwọn ẹrú náà, ìyẹn àwọn arákùnrin Jésù fi “àwọn tálẹ́ńtì” Ọba náà ṣe? Láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa síwájú títí dé ọdún 1914 ni ọ̀pọ̀ ti ń ṣiṣẹ́ kára nínú ‘òwò’ Jésù. (Mátíù 25:16) Àní nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n nífẹ̀ẹ́ tó lágbára láti sin Ọ̀gá náà. Nísinsìnyí, ó yẹ láti fún àwọn olóòótọ́ náà ni àkọ̀tun àǹfààní láti “ṣòwò.” Àkókò òpin ètò nǹkan yìí ti dé. A ní láti wàásù ìhìn rere náà kárí ayé. A sì ní láti ṣe “ìkórè ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 14:6, 7, 14-16) A tún ní láti wá àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ àlìkámà tó kẹ́yìn rí, a sì gbọ́dọ̀ kó “àgùntàn mìíràn” wọlé.—Ìṣípayá 7:9; Mátíù 13:24-30.
17. Báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe ‘wọnú ìdùnnú ọ̀gá wọn’?
17 Àkókò ìkórè jẹ́ àkókò ìdùnnú. (Sáàmù 126:6) Nígbà náà, ó bá a mu pé ní ọdún 1919 Jésù fi ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀ síkàáwọ́ àwọn olóòótọ́ arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró, ó sọ pé: “Ìwọ jẹ́ olùṣòtítọ́ lórí ìwọ̀nba àwọn ohun díẹ̀. Dájúdájú, èmi yóò yàn ọ́ sípò lórí ohun púpọ̀. Bọ́ sínú ìdùnnú ọ̀gá rẹ.” (Mátíù 25:21, 23) Síwájú sí i, ìdùnnú Ọ̀gá náà gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run tá a gbé gorí ìtẹ́ pọ̀ ré kọjá ibi tá a lè ronú dé. (Sáàmù 45:1, 2, 6, 7) Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ń ṣàjọpín ìdùnnú yẹn nípa ṣíṣojú fún Ọba náà àti nípa mímú kí ire rẹ̀ máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé. (2 Kọ́ríńtì 5:20) A rí ìdùnnú wọn nínú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 61:10 pé: “Láìkùnà, èmi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà. Ọkàn mi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run mi. Nítorí pé ó ti fi ẹ̀wù ìgbàlà wọ̀ mí.”
18. Kí nìdí tí àwọn kan ò fi yege nígbà àbẹ̀wò, kí ni èyí sì yọrí sí?
18 Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn kan kò yege nígbà ìbẹ̀wò. A kà á pé: “Ẹni tí ó gba tálẹ́ńtì kan wá síwájú, ó sì wí pé, ‘Ọ̀gá, mo mọ̀ pé afipámúni ni ọ́, tí o ń ká irúgbìn níbi tí o kò ti fúnrúgbìn, tí o sì ń kó jọ níbi tí o kò ti fẹ́kà. Nítorí náà, àyà fò mí, mo sì lọ, mo sì fi tálẹ́ńtì rẹ pa mọ́ sínú ilẹ̀. Ohun tí í ṣe tìrẹ nìyí.’” (Mátíù 25:24, 25) Bákan náà, àwọn kan lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kò “ṣòwò.” Ṣáájú ọdún 1914 wọ́n kò fi ìtara sọ̀rọ̀ nípa ìrètí wọn fáwọn ẹlòmíràn, wọn ò sì fẹ́ bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 1919. Kí ni Jésù wá ṣe nítorí ìwà ọ̀yájú wọn yìí? Ó gba gbogbo àǹfààní náà kúrò lọ́wọ́ wọn. Ó ‘ju wọ́n síta nínú òkùnkùn lóde níbi tí ẹkún àti ìpayínkeke wọn yóò wà.’—Mátíù 25:28, 30.
Àbẹ̀wò Náà Ń Bá A Nìṣó
19. Ọ̀nà wo ni àbẹ̀wò náà fi ń bá a nìṣó, kí sì ní gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pinnu láti ṣe?
19 Dájúdájú, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó di ẹni àmì òróró ẹrú Kristi ní àkókò òpin ni kò tíì máa sìn Jèhófà nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àbẹ̀wò ní ọdún 1918. Ǹjẹ́ àbẹ̀wò náà kan àwọn náà? Ó kàn wọ́n. Àbẹ̀wò yẹn bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1918 sí ọdún 1919, nígbà tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye yege gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan nígbà àbẹ̀wò. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣì ń bá a lọ láti wà lábẹ́ àbẹ̀wò títí dìgbà tí wọ́n máa fi èdìdì dì wọ́n. (Ìṣípayá 7:1-3) Mímọ̀ táwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi mọ èyí ni wọ́n ṣe pinnu pé àwọn yóò máa fi ìṣòtítọ́ ‘ṣòwò’ náà nìṣó. Wọ́n pinnu láti máa jẹ́ olóye, tí wọ́n ní òróró rẹpẹtẹ lọ́wọ́ kí ìmọ́lẹ̀ lè máa tàn rekete. Wọ́n mọ̀ pé nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bá fi ìṣòtítọ́ parí ìgbésí ayé rẹ̀, Jésù yóò gba onítọ̀hún sí ibùgbé ní ọ̀run.—Mátíù 24:13; Jòhánù 14:2-4; 1 Kọ́ríńtì 15:50, 51.
20. (a) Kí ni àwọn àgùntàn mìíràn pinnu láti ṣe lóde òní? (b) Kí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ̀?
20 Ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn ti fara wé àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró. Wọ́n mọ̀ pé ìmọ̀ tí wọ́n ní nípa ète Ọlọ́run ń mú iṣẹ́ wọn pọ̀ sí i. (Ìsíkíẹ́lì 3:17-21) Nítorí náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti ẹ̀mí mímọ́, àwọn pẹ̀lú mú òróró wọn pọ̀ sí i nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìbákẹ́gbẹ́ ní àwọn ìpàdé Kristẹni. Wọ́n ń mú kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn sí i, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, nípa bẹ́ẹ̀ wọn ń bá àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró “ṣòwò” pọ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ̀ dáadáa pé a fi àwọn tálẹ́ńtì síkàáwọ́ wọn. Wọn gbọ́dọ̀ jíhìn nípa bí wọn ṣe lo àwọn nǹkan ìní Olúwa tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ kéré níye pàápàá, wọn ò lè gbé iṣẹ́ wọn lé ogunlọ́gọ̀ ńlá náà lọ́wọ́. Bí ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti mọ èyí dáadáa, ó ń bá a nìṣó láti máa mú ipò iwájú nínú bíbójútó òwò Ọba náà, wọ́n sì mọyì ìtìlẹ́yìn tí àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó jẹ́ olùfọkànsìn ń ṣe. Àwọn náà pẹ̀lú mọyì iṣẹ́ tí àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró ń ṣe, wọ́n sì kà á sí àǹfààní ńlá láti máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ àbójútó wọn.
21. Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ló kan gbogbo Kristẹni ṣáájú ọdún 1919 títí di ọjọ́ wa?
21 Nípa báyìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkàwé méjèèjì yìí là wá lóye nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ọdún 1919 tàbí ní lákòókò tí kò jìnnà sígbà yẹn, síbẹ̀ àwọn ìlànà inú rẹ̀ wúlò fún gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Bákan náà, bí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Jésù fúnni ní ìparí àkàwé wúńdíá mẹ́wàá náà tiẹ̀ kọ́kọ́ wà fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ṣáájú ọdún 1919, síbẹ̀ ìlànà tó wà nínú rẹ̀ kan gbogbo Kristẹni. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—Mátíù 25:13.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, ohun tó jọ ọ́ ṣẹlẹ̀, “àwọn aninilára ìkookò” wá látinú ẹgbẹ́ àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró.—Ìṣe 20:29, 30.
b Fún àlàyé síwájú sí i nípa àkàwé Jésù, wo orí 5 àti 6 nínú ìwé Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ìgbà wo ni Jésù bẹ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wò, kí ló sì rí?
• Kí nìdí táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan fi fi irú ẹ̀mí bíi ti “ẹrú búburú yẹn” hàn?
• Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olóye nípa tẹ̀mí?
• Ní àfarawé àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ arákùnrin Jésù, ọ̀nà wo ni a lè gbà máa “ṣòwò”?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
ÌGBÀ WO NI JÉSÙ DÉ?
Nínú Mátíù orí 24 àti 25, ọ̀rọ̀ náà “dé” ni a lò fún Jésù ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà tó gbéra láti ibì kan wá kí a tó sọ pé ó “dé.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó “dé” ní ìtumọ̀ pé ó yí àfiyèsí rẹ̀ sí aráyé tàbí sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà láti ṣèdájọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ọdún 1914, ó “dé” láti bẹ̀rẹ̀ wíwà níhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba tá a gbé gorí ìtẹ́. (Mátíù 16:28; 17:1; Ìṣe 1:11) Ní ọdún 1918, ó “dé” gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ májẹ̀mú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèdájọ́ àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Jèhófà. (Málákì 3:1-3; 1 Pétérù 4:17) Ní Amágẹ́dọ́nì, Jésù yóò “dé” láti dá àwọn ọ̀tá Jèhófà lẹ́jọ́.—Ìṣípayá 19:11-16.
Bíbọ̀ (tàbí, dídé) tá a tọ́ka sí nígbà mélòó kan nínú Mátíù 24:29-44 àti 25:31-46 jẹ́ nígbà “ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣípayá 7:14) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, dídé tá a tọ́ka sí nígbà mélòó kan nínú Mátíù 24:45 sí 25:30 wé mọ́ ṣíṣe tó ti ń ṣèdájọ́ àwọn tó pera wọn ni ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ọdún 1918 síwájú. Bí àpẹẹrẹ, kò ní bọ́gbọ́n mu láti sọ pé, fífún ẹrú olóòótọ́ ní èrè, ṣíṣèdájọ́ àwọn òmùgọ̀ wúńdíá, àti ṣíṣèdájọ́ ẹrú onílọ̀ọ́ra tó fi tálẹ́ńtì Ọ̀gá náà pa mọ́ yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá “dé” nígbà ìpọ́njú ńlá. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, á túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró ní yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá, tí a ó sì fi ẹlòmíràn rọ́pò wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìṣípayá 7:3 fi hàn pé gbogbo ẹrú Kristi tó jẹ́ ẹni àmì òróró ni a ó ti fi “èdìdì dì” tán nígbà yẹn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
“Ẹrú búburú” náà kò gba ìbùkún kankan ní ọdún 1919
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Wúńdíá tó jẹ́ ọlọgbọ́n gbára dì nígbà tí ọkọ ìyàwó dé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹrú olóòótọ́ náà ti “ṣòwò”
Ẹrú onílọ̀ọ́ra náà kò ṣòwò
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn ẹni àmì òróró àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ń bá a lọ láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn