ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 33
Jẹ́ Kí Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó O Ní Máa Múnú Rẹ Dùn
“Ó sàn kéèyàn máa gbádùn ohun tí ojú rẹ̀ rí ju kó máa dààmú lórí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́.”—ONÍW. 6:9.
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni ọ̀pọ̀ ń ṣe kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
IṢẸ́ tá à ń ṣe nínú ètò Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i bí ayé yìí ṣe ń lọ sópin. (Mát. 24:14; Lúùkù 10:2; 1 Pét. 5:2) Gbogbo wa ló wù pé ká ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wu àwọn kan láti di aṣáájú-ọ̀nà, ó wu àwọn míì láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ń sapá kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. (1 Tím. 3:1, 8) Ẹ wo bínú Jèhófà ṣe ń dùn tó bó ṣe ń rí ẹ̀mí tó dáa táwọn èèyàn ẹ̀ ní!—Sm. 110:3; Àìsá. 6:8.
2. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí ọwọ́ wa ò bá tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tó wù wá?
2 Àmọ́ o, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì tó bá jẹ́ pé lẹ́yìn gbogbo ìsapá wa, ọwọ́ wa ò tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù wá. Inú wa sì lè má dùn tó bá jẹ́ pé a ò lè ní àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ tàbí nínú ètò Jèhófà torí ọjọ́ orí wa tàbí torí àwọn nǹkan míì. (Òwe 13:12) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Melissa nìyẹn.b Ó wù ú pé kó sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí kó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ ó sọ pé: “Ọjọ́ orí mi ti kọjá ohun tí wọ́n béèrè. Torí náà, mi ò lè ní àwọn àǹfààní yẹn mọ́, ìyẹn sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.”
3. Kí ló gba pé kí àwọn kan ṣe kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan?
3 Ó máa gba pé kí àwọn kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tí ara wọn sì le túbọ̀ sapá láti ní àwọn ànímọ́ kan kí wọ́n tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan. Irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ lè gbọ́n, kí wọ́n mọ béèyàn ṣe ń ṣèpinnu, kí wọ́n sì nítara. Àmọ́, ó lè gba pé kí wọ́n túbọ̀ máa mú sùúrù, kí wọ́n máa fara balẹ̀ ṣe nǹkan, kí wọ́n sì túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fúnni. Tó o bá sapá láti ní àwọn ànímọ́ tó yẹ kó o ní, ọwọ́ rẹ lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́ nígbà tó ò retí ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Nick. Nígbà tó wà lọ́mọ ogún (20) ọdún, inú ẹ̀ ò dùn pé òun ò di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó sọ pé: “Mo ronú pé ó ní láti jẹ́ pé mo níṣòro.” Síbẹ̀, Nick ò sọ̀rètí nù. Ṣe ló túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ohun tó ń ṣe nínú ìjọ, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ní báyìí, ó ti di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Ṣé o ò ti máa rẹ̀wẹ̀sì torí pé o ò tíì ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, sọ bó ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà. (Sm. 37:5-7) Bákan náà, o lè ní kí àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn sọ ohun tó o lè ṣe kí ọwọ́ ẹ lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́, kó o sì rí i pé o fi ìmọ̀ràn wọn sílò. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ lè tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn náà. Àmọ́ bíi ti Melissa tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, ọwọ́ ẹ lè má tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́ báyìí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe? Kí lá jẹ́ kó o máa láyọ̀ bó ò tiẹ̀ tíì ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́? Ká lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, a máa jíròrò (1) ohun tó lè mú kó o láyọ̀, (2) ohun tó o lè ṣe tí wàá fi túbọ̀ láyọ̀ àti (3) àwọn àfojúsùn táá jẹ́ kó o túbọ̀ láyọ̀.
OHUN TÓ LÈ MÚ KÓ O LÁYỌ̀
5. Kí ló yẹ kó gbà wá lọ́kàn tá a bá fẹ́ láyọ̀? (Oníwàásù 6:9)
5 Oníwàásù 6:9 sọ ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ láyọ̀. (Kà á.) Ẹni tó ń gbádùn “ohun tí ojú rẹ̀ rí” mọyì ohun tó ní báyìí. Àmọ́ ẹni tó ń dààmú lórí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ kò ní ní ìtẹ́lọ́rùn, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó láyọ̀. Kí nìyẹn kọ́ wa? Tá a bá fẹ́ láyọ̀, á dáa ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tá a ní báyìí dípò ká máa da ara wa láàmú lórí ohun tí ọwọ́ wa ò lè tẹ̀.
6. Àpèjúwe wo la máa jíròrò báyìí, kí la sì máa rí kọ́ nínú ẹ̀?
6 Ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tó ní báyìí? Àwọn kan gbà pé kò ṣeé ṣe, ó ṣe tán bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ó máa ń wù wá pé ká ní àwọn nǹkan míì. Bó ti wù kó rí, ó ṣeé ṣe kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn. A lè gbádùn ohun tí ‘ojú wa rí,’ kì í kàn ṣe ká gba kámú pẹ̀lú ẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ká lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe tálẹ́ńtì tí Jésù ṣe nínú Mátíù 25:14-30. A máa rí ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ kí àwọn àǹfààní tá a ní báyìí máa fún wa láyọ̀ àti ohun táá jẹ́ kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i.
OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ WÀÁ FI TÚBỌ̀ LÁYỌ̀
7. Ní ṣókí, sọ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa tálẹ́ńtì.
7 Jésù sọ nínú àpèjúwe yẹn pé ọkùnrin kan fẹ́ rìnrìn àjò. Àmọ́ kó tó lọ, ó pe àwọn ẹrú rẹ̀, ó sì fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní tálẹ́ńtì pé kí wọ́n fi ṣòwò.c Ọkùnrin náà fún wọn ní owó bí agbára ẹrú kọ̀ọ̀kan ṣe mọ. Ó fún ọ̀kan ní tálẹ́ńtì márùn-ún, ó fún èkejì ní tálẹ́ńtì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ní tálẹ́ńtì kan. Àwọn ẹrú méjì àkọ́kọ́ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè jèrè owó púpọ̀ sí i fún ọ̀gá wọn. Àmọ́ ẹrú kẹta ò fi tálẹ́ńtì tí ọ̀gá rẹ̀ fún un ṣòwò, ìyẹn sì mú kí ọ̀gá rẹ̀ lé e dà nù.
8. Kí ló mú kí ẹrú àkọ́kọ́ láyọ̀?
8 Ó dájú pé inú ẹrú àkọ́kọ́ yẹn máa dùn pé ọ̀gá òun fún òun ní tálẹ́ńtì márùn-ún pé kóun fi ṣòwò. Owó yẹn pọ̀ gan-an, ìyẹn sì fi hàn pé ọ̀gá rẹ̀ fọkàn tán an. Àmọ́ ẹrú kejì ńkọ́? Inú ẹ̀ lè má dùn pé owó tí wọ́n fún òun ò tó ti ẹrú àkọ́kọ́. Síbẹ̀, kí ló ṣe?
9. Kí ni Jésù ò sọ pé ẹrú kejì náà ṣe? (Mátíù 25:22, 23)
9 Ka Mátíù 25:22, 23. Jésù ò sọ pé ẹrú kejì yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í bínú tàbí fapá jánú nítorí pé tálẹ́ńtì méjì péré ni ọ̀gá ẹ̀ fún un. Jésù ò sì sọ pé ó ń ráhùn pé: ‘Ṣé gbogbo ohun tó kàn mí nìyí? Kí ni ẹrú àkọ́kọ́ ṣe tí èmi ò lè ṣe tó fi jẹ́ pé tálẹ́ńtì márùn-ún ni ọ̀gá wa fún un? Tó bá jẹ́ pé ohun tí ọ̀gá mi ń rò ni pé mi ò kì í ṣiṣẹ́ kára, màá kúkú lọ ri owó náà mọ́lẹ̀, màá sì fi àkókò mi ṣe nǹkan míì tó máa ṣe mí láǹfààní.’
10. Kí ni ẹrú kejì fi tálẹ́ńtì rẹ̀ ṣe?
10 Bíi ti ẹrú àkọ́kọ́, ẹrú kejì náà gbà pé iṣẹ́ pàtàkì ni ọ̀gá òun gbé fún òun, torí náà ó ṣiṣẹ́ kára, ó jèrè tálẹ́ńtì méjì sí i, inú ọ̀gá ẹ̀ sì dùn sí i. Láfikún síyẹn, ọ̀gá ẹ̀ yìn ín, ó sì fún un láwọn ojúṣe míì.
11. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ máa láyọ̀?
11 Bíi ti ẹrú kejì yẹn, àwa náà lè túbọ̀ láyọ̀ tá a bá sa gbogbo ipá wa lẹ́nu iṣẹ́ tá à ń ṣe báyìí nínú ìjọsìn Jèhófà. Jẹ́ kí ‘ọwọ́ rẹ dí gan-an’ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọ. (Ìṣe 18:5; Héb. 10:24, 25) Rí i pé ò ń múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, kó o lè dáhùn lọ́nà tó máa gbé àwọn ará ró. Fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí wọ́n bá fún ẹ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀. Tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ èyíkéyìí fún ẹ nínú ìjọ, rí i pé o tètè ṣe é, kó o sì jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Má fojú kéré ohunkóhun tí wọ́n bá fún ẹ nínú ìjọ. Ṣe ni kó o máa sapá láti sunwọ̀n sí i. (Òwe 22:29) Bó o bá ṣe ń sapá tó, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú, ayọ̀ ẹ á sì máa pọ̀ sí i. (Gál. 6:4) Yàtọ̀ síyẹn, táwọn míì bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́, á rọrùn fún ẹ láti bá wọn yọ̀.—Róòmù 12:15; Gál. 5:26.
12. Kí ni àwọn ará méjì tá a sọ̀rọ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan ṣe kí wọ́n lè túbọ̀ láyọ̀?
12 Ṣé ẹ rántí Melissa tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tó fẹ́ lọ sí Bẹ́tẹ́lì tàbí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ẹ̀ ò tẹ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn, ó sọ pé: “Mo máa ń sa gbogbo ipá mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà tí mò ń ṣe, mo sì máa ń wàásù lónírúurú ọ̀nà. Èyí ti mú kí n túbọ̀ láyọ̀.” Kí ni Nick ṣe tí ò fi rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí wọn ò sọ ọ́ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? Ó sọ pé: “Mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, mo sì máa ń dáhùn lọ́nà tó ń gbé àwọn ará ró nípàdé. Yàtọ̀ síyẹn, mo gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì pè mí lọ́dún tó tẹ̀ lé e.”
13. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń sa gbogbo ipá rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tó ò ń ṣe báyìí? (Oníwàásù 2:24)
13 Ṣé ó dájú pé wàá rí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì gbà tó o bá sa gbogbo ipá rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tó ò ń ṣe báyìí? Bíi ti Nick, o lè rí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn míì gbà. Àmọ́ nígbà míì bíi ti Melissa, ó lè má rí bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, wàá láyọ̀, ọkàn ẹ á sì balẹ̀ pé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe fún Jèhófà. (Ka Oníwàásù 2:24.) Bákan náà, kò sí àní-àní pé inú ẹ máa dùn pé Jésù Ọ̀gá ẹ ń kíyè sí gbogbo ìsapá ẹ, inú rẹ̀ sì ń dùn sí ẹ.
ÀWỌN ÀFOJÚSÙN TÁÁ JẸ́ KÓ O TÚBỌ̀ LÁYỌ̀
14. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa àwọn àfojúsùn tá a ní?
14 Tá a bá ti ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò lè ṣe púpọ̀ sí i? Rárá o! Ó yẹ ká ṣì ní àwọn àfojúsùn táá jẹ́ ká lè máa ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, táá sì jẹ́ ká lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. Ọwọ́ wa máa tẹ àwọn àfojúsùn yìí tá a bá pọkàn pọ̀ sórí bá a ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ dípò kó jẹ́ pé tara wa nìkan làá máa rò.—Òwe 11:2; Ìṣe 20:35.
15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àfojúsùn táá jẹ́ kó o túbọ̀ láyọ̀?
15 Àwọn àfojúsùn wo lo lè ní? Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ ẹ lè bà. (Òwe 16:3; Jém. 1:5) Ṣé o lè fi ọ̀kan lára àwọn ohun tá a sọ nínú ìpínrọ̀ kìíní ṣe àfojúsùn rẹ? Bí àpẹẹrẹ, ṣé o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Ṣé o lè lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí kó o bá àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run ṣiṣẹ́? Ṣé o lè kọ́ èdè míì àbí kó o lọ sìn níbi tí àìní wà? Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó o lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn yìí, o lè ka orí 10 nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, kó o sì bá àwọn alàgbà ìjọ rẹ sọ̀rọ̀.d Tó o bá ń sapá kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn yìí, ìtẹ̀síwájú ẹ á túbọ̀ hàn kedere, wàá sì túbọ̀ láyọ̀.
16. Kí lo lè ṣe tọ́wọ́ ẹ ò bá lè tẹ àwọn àfojúsùn kan báyìí?
16 Kí lo lè ṣe tọ́wọ́ ẹ ò bá lè tẹ ọ̀kan lára àwọn àfojúsùn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí? Ohun tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o wá àfojúsùn míì tọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí.
17. Kí ni 1 Tímótì 4:13, 15 sọ tó lè jẹ́ kí arákùnrin kan túbọ̀ di olùkọ́ tó já fáfá?
17 Ka 1 Tímótì 4:13, 15. Tó o bá jẹ́ arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, ó yẹ kó o sapá kó o lè sunwọ̀n sí i nínú bó o ṣe ń kọ́ni nínú ìjọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé tó o bá túbọ̀ já fáfá nínú bó o ṣe ń kàwé àti bó o ṣe ń kọ́ni nínú ìjọ, ìyẹn á ṣe àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ láǹfààní. Fi ṣe àfojúsùn ẹ pé wàá ka gbogbo ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni, wàá sì fi àwọn àbá tó wà nínú ẹ̀ sílò. Tó o bá ka ẹ̀kọ́ kan tán, fi dánra wò dáadáa nílé, kó o wá lo àwọn àbá inú ẹ̀ tó o bá níṣẹ́ nípàdé. Yàtọ̀ síyẹn, o lè gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn tàbí lọ́wọ́ àwọn alàgbà míì tí wọ́n “ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.”e (1 Tím. 5:17) Àmọ́ o, kì í ṣe bá a ṣe máa fi àwọn àbá náà sílò nìkan ló yẹ kó jẹ wá lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró, kó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi tí wọ́n á fi gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ àtàwọn tó ń tẹ́tí sí ẹ á túbọ̀ láyọ̀.
18. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
18 Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ máa wàásù ká sì máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; Róòmù 10:14) Ṣé wàá fẹ́ túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ pàtàkì yìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o lè fi ṣe àfojúsùn ẹ láti ka àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé Kíkọ́ni, kó o sì fi àwọn àbá inú ẹ̀ sílò. Yàtọ̀ síyẹn, o tún lè rí àwọn àbá míì nínú Ìwé Ìpàdé—Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni àti nínú àwọn fídíò ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. Lo onírúurú àbá tó wà níbẹ̀ kó o lè mọ èyí tó gbéṣẹ́ jù. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìwọ náà á rí ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀.—2 Tím. 4:5.
19. Kí lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí?
19 Fi sọ́kàn pé ọ̀kan lára àwọn àfojúsùn tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kó o ní ni pé kó o túbọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí kó o lè máa múnú Jèhófà dùn. (Gál. 5:22, 23; Kól. 3:12; 2 Pét. 1:5-8) Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ká sọ pé ó wù ẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára, o lè ka àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ àwọn nǹkan pàtó tó o lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. Yàtọ̀ síyẹn, o lè wo àwọn fídíò lórí JW Broadcasting® tó jẹ́ ká rí ìgbàgbọ́ táwọn ará wa ní àti bí wọ́n ṣe jẹ́ adúróṣinṣin lójú àdánwò. Lẹ́yìn náà, ronú lórí bó o ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.
20. Kí lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ láyọ̀ kó o má sì rẹ̀wẹ̀sì?
20 Ó dájú pé gbogbo wa ló wù ká ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà ju ohun tá à ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Nínú ayé tuntun, gbogbo wa pátápátá la máa lè sin Jèhófà dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Àmọ́ ní báyìí tá a bá ń fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ojúṣe tá a ní nínú ìjọsìn Jèhófà, àá láyọ̀, a ò sì ní rẹ̀wẹ̀sì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àá mú ìyìn àti ògo bá Jèhófà “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tím. 1:11) Torí náà, jẹ́ kí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ní báyìí máa múnú ẹ dùn!
ORIN 82 “Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”
a A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, a sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Ìyẹn lè mú kó wù wá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tàbí ká máa sapá láti ní ojúṣe míì nínú ìjọ. Àmọ́, tí ọwọ́ wa ò bá tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn náà pẹ̀lú gbogbo ìsapá wa ńkọ́? Kí la lè ṣe tá ò fi ní dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa tí àá sì máa láyọ̀ nìṣó? A máa rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àpèjúwe tálẹ́ńtì tí Jésù ṣe.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Tálẹ́ńtì kan ni owó tí òṣìṣẹ́ kan máa gbà tó bá ṣiṣẹ́ fún nǹkan bí ogún (20) ọdún.
d Ó yẹ káwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi sapá láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ohun tó o lè ṣe kó o lè kúnjú ìwọ̀n fún àwọn àǹfààní yìí, wo orí 5 àti 6 nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà.
e ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló máa ń yan alàgbà kan láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Ojúṣe rẹ̀ ni láti máa fún àwọn alàgbà tàbí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó bójú tó iṣẹ́ èyíkéyìí nímọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ tó bá yẹ bẹ́ẹ̀.
f ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa kó lè di olùkọ́ tó túbọ̀ já fáfá.
g ÀWÒRÁN:Lẹ́yìn tí arábìnrin kan pinnu láti máa wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, ó fún obìnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ nílé oúnjẹ ní káàdì ìkànnì jw.org.
h ÀWÒRÁN:Ó wu arábìnrin kan láti túbọ̀ jẹ́ ọ̀làwọ́, torí náà ó gbé oúnjẹ lọ fún arábìnrin míì.