Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Ti Àwọn Olùjọsìn Tòótọ́—Níbo ni Wọ́n Ti Wá?
“Sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, . . . lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ ati níwájú Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa.”—ÌṢÍPAYÁ 7:9, NW.
1. Èéṣe tí a fi ní ọkàn-ìfẹ́ ńláǹlà nínú àwọn ìran alásọtẹ́lẹ̀ inú Ìṣípayá lónìí?
NÍ APÁ ìparí ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., aposteli Johannu rí ìran àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu tí ó níí ṣe pẹ̀lú ète Jehofa. Díẹ̀ lára àwọn ohun tí ó rí nínú ìran ti ń ní ìmúṣẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Àwọn yòókù yóò ní ìmúṣẹ láìpẹ́ ní ọjọ́-ọ̀la. Gbogbo èyí wépọ̀ mọ́ mímú ète títóbilọ́lá ti Jehofa láti sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ níwájú gbogbo ẹ̀dá wá sí ògógóró òpin tí ń múnijígìrì. (Esekieli 38:23; Ìṣípayá 4:11; 5:13) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n wémọ́ ìwàláàyè tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ń fojúsọ́nà fún. Báwo ni ìyẹn ṣe rí bẹ́ẹ̀?
2. (a) Kí ni aposteli Johannu rí nínú ìran rẹ̀ kẹrin? (b) Àwọn ìbéèrè wo nípa ìran yìí ni a óò gbé yẹ̀wò?
2 Nínú ìkẹrin nínú ọ̀wọ́ àwọn ìran ti Ìṣípayá, Johannu rí àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n di afẹ́fẹ́ apanirun mú pinpin títí tí a bá tó fi èdìdì dí “awọn ẹrú Ọlọrun wa” níwájú orí wọn. Lẹ́yìn náà ni ó rí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ru ìmọ̀lára sókè jùlọ—“ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, tí ẹni kankan kò lè kà, lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n,” tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan ní jíjọ́sìn Jehofa àti bíbọlá fún Ọmọkùnrin rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí, ni a sọ fún Johannu pé, wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí yóò ti inú ìpọ́njú ńlá jáde wá. (Ìṣípayá 7:1-17, NW) Àwọn wo ni àwọn tí a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “awọn ẹrú Ọlọrun wa”? Àwọn wo ni yóò sì parapọ̀ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn olùla ìpọ́njú já? Ìwọ yóò ha jẹ́ ọ̀kan lára wọn bí?
Àwọn Wo Ni “Awọn Ẹrú Ọlọrun Wa”?
3. (a) Nínú Johannu 10:1-18, báwo ni Jesu ṣe ṣàkàwé ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Kí ni Jesu mú kí ó ṣeé ṣe fun àwọn àgùtàn rẹ̀ nípa ikú ìfara-ẹni-rúbọ rẹ̀?
3 Ní nǹkan bí oṣù mẹ́rin ṣáájú ikú rẹ̀, Jesu sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “olùṣọ́ àgùtàn àtàtà” àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “awọn àgùtàn” tí òun yóò fi ìwàláàyè òun lélẹ̀ fún. Ó sọ̀rọ̀ lọ́nà àkànṣe nípa àwọn àgùtàn tí òun rí láàárín agbo àgùtàn ìṣàpẹẹrẹ tí òun sì fún ní ìtọ́jú àkànṣe lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Johannu 10:1-18, NW)a Lọ́nà tí ó fi ìfẹ́ hàn, Jesu jọ̀wọ́ ìwàláàyè rẹ̀ nítorí àwọn àgùtàn rẹ̀, ní pípèsè iye owó ìràpadà tí wọ́n nílò kí wọ́n lè di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
4. Àwọn wo ni a kọ́kọ́ kó jọ gẹ́gẹ́ bí àgùtàn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jesu sọ níhìn-ín?
4 Ṣùgbọ́n, ṣáájú ṣíṣe ìyẹn, Jesu gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùtàn Àtàtà fúnra rẹ̀ kó àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ. Johannu Oníbatisí, ẹni tí ó jẹ́ “aṣọ́nà” nínú àkàwé Jesu, ni ó fi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́ hàn án. Jesu ń wá àwọn ènìyàn tí wọn yóò dáhùnpadà lọ́nà rere sí àǹfààní náà láti di apákan ‘irú-ọmọ’ ẹlẹ́ni púpọ̀ ‘ti Abrahamu.’ (Genesisi 22:18; Galatia 3:16, 29) Ó gbin ìmọrírì fún Ìjọba ọ̀run sí wọn lọ́kàn, ó sì mú un dá wọn lójú pé òun ń lọ láti lọ pèsè àyè sílẹ̀ fún wọn nínú ilé Bàbá òun tí ń bẹ ní ọ̀run. (Matteu 13:44-46; Johannu 14:2, 3) Lọ́nà tí ó bá a mu ó wí pé: “Lati awọn ọjọ́ Johannu Oníbatisí títí di ìsinsìnyí ìjọba awọn ọ̀run ni góńgó naa tí awọn ènìyàn ń fi ìsapá lépa, awọn wọnnì tí ń fi ìsapá tẹ̀síwájú sì ń gbá a mú.” (Matteu 11:12, NW) Àwọn tí ń tẹ̀lé e kí ọwọ́ wọn baà lè tẹ góńgó yẹn fihàn pé àwọn wà nínú agbo àgùtàn tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
5. (a) Àwọn wo ni “awọn ẹrú Ọlọrun wa” tí a tọ́ka sí ní Ìṣípayá 7:3-8? (b) Kí ni ó fihàn pé àwọn púpọ̀ síi yóò darapọ̀ ní jíjọ́sìn pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli tẹ̀mí?
5 Nínú Ìṣípayá 7:3-8, àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ̀síwájú lọ́nà yíyọrísírere síhà góńgó ti ọ̀run ni a tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí “awọn ẹrú Ọlọrun wa.” (Wo 1 Peteru 2:9, 16.) Àwọn 144,000 tí a mẹ́nukàn níbẹ̀ ha jẹ́ kìkì àwọn Júù àbínibí bí? Kìkì àwọn Júù ni wọ́n ha wà nínú agbo àgùtàn ìṣàpẹẹrẹ ti inú àkàwé Jesu bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́; wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà Israeli tẹ̀mí ti Ọlọrun, gbogbo wọn jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi gẹ́gẹ́ bí irú-ọmọ tẹ̀mí ti Abrahamu. (Galatia 3:28, 29; 6:16; Ìṣípayá 14:1, 3) Àmọ́ ṣáá o, àkókò náà yóò dé níkẹyìn, nígbà tí iye tí a ti fòtélé náà yóò pé. Nígbà náà kí ni yóò ṣẹlẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ṣe sọtẹ́lẹ̀, àwọn mìíràn—tí wọ́n jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá—yóò darapọ̀ mọ́ àwọn Israeli tẹ̀mí wọ̀nyí ní jíjọ́sìn Jehofa.—Sekariah 8:23.
“Awọn Àgùtàn Mìíràn”—Kèfèrí Tí Ó Di Kristian Ni Wọ́n Bí?
6. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni Johannu 10:16 tọ́ka sí?
6 Lẹ́yìn mímẹ́nukan agbo àgùtàn kan ní Johannu 10:7-15, Jesu mú ẹgbẹ́ àwùjọ mìíràn wá sí ojútáyé, ní sísọ pé: “Emi sì ní awọn àgùtàn mìíràn, tí kì í ṣe ti ọ̀wọ́ agbo yii; awọn wọnnì pẹlu ni mo gbọ́dọ̀ mú wá, wọn yoo sì fetísílẹ̀ sí ohùn mi, wọn yoo sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùtàn kan.” (Johannu 10:16, NW) Àwọn wo ni “awọn àgùtàn mìíràn” wọ̀nyẹn?
7, 8. (a) Èéṣe tí ó fi jẹ́ pé orí ìpìlẹ̀ tí kò tọ̀nà ni a gbé èrò náà kà pé àwọn Kèfèrí tí wọ́n di Kristian ni àwọn àgùtàn mìíràn? (b) Àwọn òkodoro wo nípa ète Ọlọrun fún ilẹ̀-ayé ni o níláti nípa lórí òye wa nípa àwọn tí wọ́n jẹ́ àgùtàn mìíràn?
7 Àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Kristẹndọm ní gbogbogbòò ní ojú ìwòye náà pé àwọn àgùtàn mìíràn wọ̀nyí jẹ́ àwọn Keferi tí wọ́n di Kristian àti pé àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú agbo àgùtàn náà tí a tọ́ka sí níṣàájú jẹ́ àwọn Júù, àwọn wọnnì tí wọ́n wà lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, àti pé ọ̀run ni àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ méjèèjì ń lọ. Ṣùgbọ́n Júù àbínibí ni Jesu jẹ́ ó sì wà lábẹ́ májẹ̀mú Òfin. (Galatia 4:4) Síwájú síi, àwọn wọnnì tí ń wo àwọn àgùtàn mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwọn Kèfèrí tí wọ́n di Kristian tí a óò fi ìwàláàyè ti ọ̀run san èrè fún ń kùnà láti gbé apá tí ó ṣe pàtàkì nínú ète Ọlọrun yẹ̀wò. Nígbà tí Jehofa dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ tí ó sì fi wọ́n sínú ọgbà Edeni, ó mú un ṣe kedere pé ète òun ni pé kí ilẹ̀-ayé kún fún àwọn olùgbé, pé kí gbogbo rẹ̀ di paradise, àti pé kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ń mójútó o gbádùn ìwàláàyè títí láé—kìkì bí wọn yóò bá bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn kí wọ́n sì ṣègbọràn sí i.—Genesisi 1:26-28; 2:15-17; Isaiah 45:18.
8 Nígbà tí Adamu dẹ́ṣẹ̀, a kò ké ète Jehofa nígbèrí. Ọlọrun fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣètò fún àwọn àtọmọdọ́mọ Adamu láti ní àǹfààní láti gbádùn ohun tí Adamu ti kùnà láti mọrírì. Jehofa sọtẹ́lẹ̀ pé òun yóò gbé olùdáǹdè kan dìde, irú-ọmọ kan, nípasẹ̀ ẹni tí ìbùkún yóò fi tó gbogbo orílẹ̀-èdè lọ́wọ́. (Genesisi 3:15; 22:18) Ìlérí yẹn kò túmọ̀ sí pé gbogbo ènìyàn rere tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé ni a óò kó lọ sí ọ̀run. Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́-inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀-ayé pẹlu.” (Matteu 6:9, 10, NW) Kò pẹ́ púpọ̀ ṣáájú kí ó tó sọ àkàwé tí a kọsílẹ̀ nínú Johannu 10:1-16, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé “agbo kékeré” nìkan ni Bàbá òun fọwọ́sí láti fún ní Ìjọba ti ọ̀run. (Luku 12:32, 33) Nítorí náà nígbà tí a kà nípa àkàwé Jesu fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùtàn Àtàtà tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ nítorí àwọn àgùtàn rẹ̀, yóò jẹ́ àṣìṣe láti máṣe gba ti àwọn tí ó pọ̀ jù lára àwọn tí Jesu mú wá sábẹ́ ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yẹ̀wò, àwọn wọnnì tí wọ́n di ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run lórí ilẹ̀-ayé.—Johannu 3:16.
9. Bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bíi 1884, kí ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lóye pé àwọn àgùtàn mìíràn jẹ́?
9 Láti nǹkan bíi 1884, Ilé-Ìṣọ́nà ti fi àwọn àgùtàn mìíràn hàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí a óò fún ní àǹfààní láti gbé lórí ilẹ̀-ayé yìí lábẹ́ àwọn ipò tí yóò mú ète Ọlọrun ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìjímìjí wọ̀nyẹn mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn àgùtàn mìíràn wọ̀nyí yóò jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti wàláàyè rí tí wọ́n sì ti kù ṣáájú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jesu lórí ilẹ̀-ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan wà tí wọn kò lóye dáradára. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n lérò pé kíkó àwọn àgùtàn mìíràn jọ yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró bá ti gba èrè wọn ti ọ̀run tán. Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ ní pàtó pé àwọn àgùtàn mìíràn kì í wulẹ̀ ṣe àwọn Kèfèrí tí wọ́n di Kristian. Àǹfààní láti di ọ̀kan lára àwọn àgùtàn mìíràn ṣí sílẹ̀ fún àwọn Júù àti Kèfèrí lápapọ̀, fún gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà.—Fiwé Iṣe 10:34, 35.
10. Kí a baà lè jẹ́ àwọn wọnnì tí Jesu ń wò gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùtàn mìíràn tirẹ̀ nítòótọ́, kí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ òtítọ́ nípa wa?
10 Láti bá àpèjúwe tí Jesu fúnni mu, àwọn àgùtàn mìíràn gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ka Jesu Kristi sí Olùṣọ́ Àgùtàn Àtàtà, láìka ẹ̀yà-ìran tàbí àwùjọ ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ sí. Kí ni ohun tí ìyẹn ní nínú? Wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìwàtútù àti ìmúratán láti jẹ́ ẹni tí ó ṣe é darí hàn, àwọn ànímọ́ tí ó jẹ́ ìwà àgùtàn. (Orin Dafidi 37:11) Bí ó ṣe jẹ́ òtítọ́ níti agbo kékeré, wọ́n gbọ́dọ̀ “mọ ohùn [olùṣọ́ àgùtàn àtàtà náà]” kí wọ́n má sì ṣe yọ̀ọ̀da kí àwọn tí wọ́n lè máa wá ọ̀nà láti nípa ìdarí lórí àwọn mú àwọn ṣáko lọ. (Johannu 10:4, NW; 2 Johannu 9, 10) Wọ́n gbọ́dọ̀ mọrírì ìjẹ́pàtàkì ohun tí Jesu ṣe níti jíjọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ nítorí àwọn àgùtàn rẹ̀ kí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ kíkúnrẹ́rẹ́ nínú ìpèsè yẹn. (Iṣe 4:12) Wọ́n gbọ́dọ̀ “tẹ́tísílẹ̀” sí ohùn Olùṣọ́ Àgùtàn Àtàtà náà nígbà tí ó bá ń rọ̀ wọ́n láti ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Jehofa nìkan ṣoṣo, láti máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́, láti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, àti láti máa fi ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ hàn fún ẹnìkínní kejì. (Matteu 4:10; 6:31-33; Johannu 15:12, 13, 19) Ìwọ ha bá àpèjúwe yẹn nípa àwọn wọnnì tí Jesu ń wò gẹ́gẹ́ bí àwọn àgùtàn mìíràn tirẹ̀ mu bí? Ìwọ ha fẹ́ bẹ́ẹ̀ bí? Ẹ wo irú ipò-ìbátan ṣíṣeyebíye tí ó ṣí sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tí wọ́n di àgùtàn mìíràn ti Jesu níti tòótọ́!
Ọ̀wọ̀ fún Ọlá-Àṣẹ Ìjọba
11. (a) Nínú àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀, kí ni Jesu sọ nípa àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́? (b) Àwọn wo ni àwọn arákùnrin tí Jesu tọ́ka sí?
11 Ní oṣù mélòókan lẹ́yìn tí ó ti fúnni ní àkàwé tí ó wà lókè yìí, Jesu tún ti padà sí Jerusalemu. Nígbà tí ó jókòó lórí Òkè Olifi tí ó ń wo agbègbè tẹ́ḿpìlì nísàlẹ̀, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní kúlẹ̀kúlẹ̀ ‘àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ ati ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.’ (Matteu 24:3, NW) Ó tún sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn àgùtàn jọ. Lára àwọn nǹkan tí ó sọ ni pé: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn áńgẹ́lì pẹlu rẹ̀, nígbà naa ni oun yoo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ni a óò sì kó jọ níwájú rẹ̀, oun yoo sì ya awọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùtàn kan tí ń ya awọn àgùtàn sọ́tọ̀ kúrò lára awọn ewúrẹ́. Oun yoo sì fi awọn àgùtàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.” Nínú òwe àkàwé yìí, Jesu fihàn pé àwọn wọnnì tí Ọba náà fún ní àfiyèsí lọ́nà yìí ni a óò ṣe ìdájọ́ wọn lórí ìpìlẹ̀ bí wọ́n ṣe hùwà sí “àwọn arákùnrin” rẹ̀. (Matteu 25:31-46, NW) Àwọn wo ni àwọn arákùnrin wọ̀nyí? Wọ́n jẹ́ àwọn Kristian tí a fi ẹ̀mí yàn tí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ di “ọmọ Ọlọrun.” Jesu ni Ọmọkùnrin àkọ́bí ti Ọlọrun. Nítorí ìdí èyí, wọ́n jẹ́ arákùnrin Kristi. Wọ́n jẹ́ “awọn ẹrú Ọlọrun wa” tí a mẹ́nukàn ní Ìṣípayá 7:3, àwọn tí a yàn láti inú aráyé láti nípìn-ín pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run.—Romu 8:14-17, NW.
12. Èéṣe tí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn gbà ń hùwà sí àwọn arákùnrin Kristi fi ṣe pàtàkì púpọ̀?
12 Ọ̀nà tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn mìíràn gbà ń hùwà sí àwọn àjògún Ìjọba wọ̀nyí ní ìjẹ́pàtàkì ṣíṣekókó. Ìwọ ha ń wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí Jesu Kristi àti Jehofa ṣe ń wò wọ́n bí? (Matteu 24:45-47; 2 Tessalonika 2:13) Ìwà ẹnì kan sí àwọn ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí ń fi ìwà rẹ̀ sí Jesu Kristi fúnra rẹ̀ àti sí Bàbá rẹ̀, Ọba Aláṣẹ Àgbáyé hàn.—Matteu 10:40; 25:34-46.
13. Dé àyè wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní 1884 lóye òwe àkàwé nípa àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́?
13 Nínú ìtẹ̀jáde rẹ̀ ti August 1884, Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹ̀ẹ́sì) tọ́ka sí i lọ́nà tí ó tọ́ pé “awọn àgùtàn” nínú òwe àkàwé yìí ni àwọn wọnnì tí wọn yóò ti gbé ìrètí ìwàláàyè pípé lórí ilẹ̀-ayé ka iwájú ara wọn. A tún lóye rẹ̀ pé òwe àkàwé náà gbọ́dọ̀ ní ìmúṣẹ nígbà tí Kristi bá ń ṣàkóso láti orí ìtẹ́ ògo rẹ̀ ní ọ̀run. Síbẹ̀, ní àkókò yẹn wọn kò tí ì lóye àkókò tí yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ náà tí a ṣàpèjúwe níbẹ̀ tàbí bí yóò ṣe pẹ́ tó ní kedere.
14. Báwo ni ọ̀rọ̀-àwíyé àpéjọpọ̀ kan ní 1923 ṣe ran àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ́wọ́ láti mọrírì ìgbà tí òwe àkàwé alásọtẹ́lẹ̀ Jesu yóò ní ìmúṣẹ?
14 Bí ó ti wù kí ó rí, ní 1923, nínú ọ̀rọ̀-àwíyé àpéjọpọ̀ kan, J. F. Rutherford, tí ó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, mú kí àkókò ìmúṣẹ òwe àkàwé àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́ ṣe kedere. Èéṣe? Lọ́nà kan, nítorí pé òwe àkàwé náà fihàn pé àwọn arákùnrin Ọba náà—ó kéré tán díẹ̀ lára wọn—yóò ṣì wà lórí ilẹ̀-ayé. Láàárín àwọn ẹ̀dá ènìyàn, kìkì àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí a fi ẹ̀mí bí ni a lè fi tòótọ́-tòótọ́ pé ní arákùnrin rẹ̀. (Heberu 2:10-12) Àwọn wọ̀nyí kì yóò sí lórí ilẹ̀-ayé jálẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà, láti fún àwọn ènìyàn ní àǹfààní láti ṣe rere sí wọn ní àwọn ọ̀nà tí Jesu ṣàpèjúwe.—Ìṣípayá 20:6.
15. (a) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó ran àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ́wọ́ láti dá àwọn àgùtàn inú òwe àkàwé Jesu mọ̀ lọ́nà títọ́? (b) Báwo ni àwọn àgùtàn ti ṣe fi ẹ̀rí ìmọrírì wọn hàn fún Ìjọba náà?
15 Nínú ọ̀rọ̀-àwíyé yẹn ní 1923, a sapá láti mú kí a mọ́ àwọn wọnnì tí wọ́n bá àpèjúwe Oluwa nípa àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́ mu, ṣùgbọ́n ó yẹ kí a lóye àwọn ọ̀ràn mìíràn ṣáájú kí òye kíkúnrẹ́rẹ́ nípa òwe àkàwé náà tó lè ṣe kedere. Láàárín àwọn ọdún tí ó tẹ̀lé e, Jehofa pé àfiyèsí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì wọ̀nyí ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Èyí ní nínú lílóye lọ́nà ṣíṣe kedere ní 1927, pé “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ni gbogbo ẹgbẹ́ àwọn Kristian tí a fi ẹ̀mí yàn tí wọ́n wà lórí ilẹ̀-ayé; àti mímọrírì ní 1932, àìní náà láti darapọ̀ mọ́ àwọn ẹni-àmì-òróró ìránṣẹ́ Jehofa láìbẹ̀rù, gẹ́gẹ́ bí Jonadabu ti ṣe sí Jehu. (Matteu 24:45, NW; 2 Ọba 10:15) Ní àkókò yẹn, lórí ìpìlẹ̀ Ìṣípayá 22:17, àwọn ẹni-bí-àgùtàn wọ̀nyí ni a fún ní ìṣírí lọ́nà tí ó ṣe pàtó láti nípìn-ín nínú mímú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà tọ àwọn ẹlòmíràn lọ. Ìmọrírì wọn fún Ìjọba Messia náà yóò sún wọn kì í wulẹ̀ ṣe kìkì nínawọ́ inúrere afẹ́dàáfẹ́re sí àwọn ẹni-àmì-òróró Oluwa nìkan bíkòṣe láti ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ fún Jehofa nípasẹ̀ Kristi àti láti darapọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹni-àmì-òróró rẹ̀, kí wọ́n sì fi tìtara-tìtara nípìn-ín nínú iṣẹ́ náà tí wọ́n ń ṣe pẹ̀lú. Ìwọ ha ń ṣe ìyẹn bí? Ọba náà yóò sọ fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín lati ìgbà pípilẹ̀ ayé.” Ìrètí títóbilọ́lá ti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ìjẹ́pípé nínú ilẹ̀ àkóso Ìjọba náà lórí ilẹ̀-ayé yóò wà ní iwájú wọn.—Matteu 25:34, 46, NW.
Àwọn “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá”—Níbo Ni Wọ́n Ń Lọ?
16. (a) Èrò òdì wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìjímìjí ní nípa àwọn tí ó jẹ́ ògìdìgbó ńlá náà, tàbí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ti inú Ìṣípayá 7:9? (b) Nígbà wo àti lórí ìpìlẹ̀ wo ni a fi tún ojú-ìwòye wọn ṣe?
16 Fún àkókò kan àwọn ìránṣẹ́ Jehofa gbàgbọ́ pé ògìdìgbó ńlá (tàbí, ogunlọ́gọ̀ ńlá) ti inú Ìṣípayá 7:9, 10 yàtọ̀ sí àwọn àgùtàn mìíràn ti inú Johannu 10:16 àti àwọn àgùtàn inú Matteu 25:33. Nítorí Bibeli sọ pé “wọn dúró níwájú ìtẹ́,” a ronú pé wọn yóò wà ní ọ̀run, kì í ṣe lórí ìtẹ́, ní ṣíṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, bíkòṣe ní ipò kejì ní iwájú ìtẹ́. A kà wọ́n sí àwọn Kristian tí ìṣòtítọ́ wọn kò kún tó, àwọn tí wọn kò fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tòótọ́ hàn. Ní 1935 a tún ojú-ìwòye yẹn ṣe.b Àyẹ̀wò Ìṣípayá 7:9 ní gbígbé àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ bíi Matteu 25:31, 32 yẹ̀wò mú kí ó ṣe kedere pé àwọn ènìyàn tí wọ́n wà níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé lè wà “níwájú ìtẹ́.” A tún tọka sí i pẹ̀lú pé Ọlọrun kò ní ọ̀pá ìdiwọ̀n ìṣòtítọ́ méjì. Gbogbo àwọn tí wọn yóò bá rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ gbọ́dọ̀ di ìwàtítọ́ wọn mú sí i.—Matteu 22:37, 38; Luku 16:10.
17, 18. (a) Láti 1935, àwọn kókó abájọ wo ni ó fa ìbísí ńláǹlà nínú iye àwọn tí ń fojúsọ́nà fún ìyè ayérayé lórí ilẹ̀-ayé? (b) Nínú iṣẹ́ ṣíṣekókó wo ni àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá ti ń fi tìtara-tìtara kópa?
17 Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni àwọn ènìyàn Jehofa ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlérí Ọlọrun nípa ilẹ̀-ayé. Nítorí ohun tí wọ́n ń retí pé kí ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọdún 1920 lọ́hùn-ún, wọ́n polongo pé “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tí Ó Wàláàyè Nísinsìnyí Kì Yóò Kú Láé.” Ṣùgbọ́n kò sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n tẹ́wọ́gba ìpèsè Ọlọrun fún ìyè nígbà yẹn. Nínú àwọn tí ó pọ̀ jù tí wọ́n tẹ́wọ́gba òtítọ́, ẹ̀mí mímọ́ pèsè ìrètí ìyè ti ọ̀run. Ṣùgbọ́n, ní pàtàkì lẹ́yìn 1935, ìyípadà pípẹtẹrí kan wáyé. Kì í ṣe pé Ilé-Ìṣọ́nà ti pa ìrètí ìyè ayérayé lórí ilẹ̀-ayé tì. Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ti sọ̀rọ̀ nípa èyí wọ́n sì ti fojúsọ́nà fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá àpèjúwe tí Bibeli fúnni mu. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó tó àkókò lójú Jehofa, ó rí sí i pé àwọn wọ̀nyí fi ara wọn hàn.
18 Àwọn àkọsílẹ̀ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fihàn pé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ọ̀pọ̀ jùlọ lára àwọn tí ń wá síbi Ìṣe-Ìrántí ń ṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ. Ṣùgbọ́n láàárín ọdún 25 lẹ́yìn 1935, iye àwọn tí ń wá síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi ní ọdọọdun fò sókè dé ìlọ́po ọgọ́rùn-ún àwọn wọnnì tí ń ṣàjọpín. Àwọn wo ni àwọn mìíràn wọ̀nyí? Àwọn tí ń fojúsọ́nà láti jẹ́ mẹ́ḿbà ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ni. Lọ́nà tí ó ṣe kedere, àkókò Jehofa ti tó láti kó wọn jọ kí ó sì múra wọn sílẹ̀ fún líla ìpọ́njú ńlá náà tí ń bọ̀ wá já. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọtẹ́lẹ̀, wọ́n ti jáde wá “lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9, NW) Wọ́n ń fi tìtara-tìtara nípìn-ín nínú iṣẹ́ náà tí Jesu sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ó sọ pé: “A óò sì wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.”—Matteu 24:14, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, tí ó bá ìgbà mu nípa àwọn àgùtàn ti Johannu orí 10, wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1984, ojú-ìwé 10 sí 20, àti 31.
b Ilé-Ìṣọ́nà, August 1 àti 15, 1935 (Gẹ̀ẹ́sì).
Kí Ni O Rí Sọ Sí I?
◻ Èéṣe tí ìran inú Ìṣípayá orí 7 fi jẹ́ ohun tí a ní ọkàn-ìfẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ sí?
◻ Èéṣe tí a kò fi fi àwọn àgùtàn inú Johannu 10:16 mọ sórí àwọn Keferi tí wọ́n di Kristian?
◻ Kí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn wọnnì tí wọ́n bá àpèjúwe Bibeli nípa àwọn àgùtàn mìíràn mu?
◻ Báwo ni òwe àkàwé àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́ ṣe pe àfiyèsí sí ọ̀wọ̀ fún ọlá-àṣẹ Ìjọba?
◻ Kí ni ó jẹ́ kí a mọ ìgbà tí ó tó àkókò fún Jehofa láti kó àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti Ìṣípayá 7:9 jọ?