“Ọ̀rẹ́ Mi Ni Yín”
“Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.”—JÒH. 15:14.
1, 2. (a) Báwo ni ipò ìgbésí ayé àwọn ọ̀rẹ́ Jésù ṣe yàtọ̀ síra tẹ́lẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù?
JÉSÙ àtàwọn ọkùnrin kan jókòó sí yàrà kan ní òkè ilé kan báyìí. Ipò ìgbésí ayé àwọn ọkùnrin yẹn tẹ́lẹ̀ yàtọ̀ síra. Pétérù àti Áńdérù tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò wà lára wọn, apẹja ni wọ́n tẹ́lẹ̀. Mátíù náà wà níbẹ̀, agbowó orí ni tẹ́lẹ̀, àwọn Júù sì kórìíra iṣẹ́ yìí bí nǹkan míì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtikékeré làwọn kan lára wọn, bíi Jákọ́bù àti Jòhánù, ti mọ Jésù. Ó sì lè jẹ́ pé kò tíì ju ọdún mélòó kan lọ táwọn míì lára wọn, bíi Nàtáníẹ́lì ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ ọ́n. (Jòh. 1:43-50) Síbẹ̀, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé tí wọ́n ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù yẹn ló dá lójú pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí àti pé òun ni Ọmọ Ọlọ́run alààyè. (Jòh. 6:68, 69) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ Jésù ní láti mú kí wọ́n mọ̀ pé ó fẹ́ràn àwọn gan-an bó ṣe sọ fún wọn pé: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.”—Jòh. 15:15.
2 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ yẹn kan gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lónìí, ó sì tún kan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn.” (Jòh. 10:16) Gbogbo wa la lè ní àǹfààní láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù láìka ipò ìgbésí ayé wa sí. Jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù ṣe pàtàkì gan-an, torí pé tá a bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù, a ti di ọ̀rẹ́ Jèhófà nìyẹn. Ká sòótọ́, kò sí bá a ṣe lè sún mọ́ Jèhófà, láìjẹ́ pé a kọ́kọ́ sún mọ́ Kristi. (Ka Jòhánù 14:6, 21.) Kí wá la lè ṣe tá a fi lè di ọ̀rẹ́ Jésù, tí ọ̀rẹ́ yẹn ò sí ní bà jẹ́? Ká tó jíròrò kókó pàtàkì yẹn, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ bí Jésù fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà, ká sì wo ohun tá a lè rí kọ́ nínú ọ̀nà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Bí Jésù Ṣe Jẹ́ Àpẹẹrẹ Ọ̀rẹ́ Àtàtà
3. Irú ẹni wo làwọn èèyàn mọ Jésù sí?
3 Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba sọ pé: “Púpọ̀ ni ọ̀rẹ́ ọlọ́rọ̀.” (Òwe 14:20) Ọ̀rọ̀ tí ọba yìí sọ ṣàkópọ̀ ohun tó jẹ́ ìṣe àwọn èèyàn aláìpé. Wọ́n máa ń bá àwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́ torí ohun tí wọ́n máa rí gbà lọ́wọ́ wọn, kì í ṣe torí ohun tí wọ́n máa fún àwọn èèyàn. Jésù kò ní irú àbùkù yìí ní tiẹ̀. Kì í torí owó tí ẹnì kan ní tàbí ipò rẹ̀ láwùjọ bá onítọ̀hún ṣọ̀rẹ́. Lóòótọ́ Jésù fìfẹ́ hàn sí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan, ó sì ní kó wá di ọmọ ẹ̀yìn òun. Àmọ́, Jésù sọ fún ọkùnrin náà pé kó ta gbogbo ohun tó ní kó sì kó owó náà fún àwọn tálákà. (Máàkù 10:17-22; Lúùkù 18:18, 23) Àwọn èèyàn kò mọ Jésù sí ọ̀rẹ́ àwọn ọlọ́rọ̀ tàbí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn láwùjọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ọ̀rẹ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ táwọn èèyàn sì ń tẹ́ńbẹ́lú ni wọ́n mọ̀ ọ́n sí.—Mát. 11:19.
4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé aláìpé tó máa ń ṣàṣìṣe làwọn ọ̀rẹ́ Jésù?
4 Ó dájú pé àwọn èèyàn aláìpé ni ọ̀rẹ́ Jésù, wọ́n sì máa ń ṣàṣìṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Pétérù kò ronú lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Mát. 16:21-23) Bákan náà, ìgbà kan wà tí Jákọ́bù àti Jòhánù ń wá ipò ọlá, wọ́n ń fẹ́ kí Jésù fi àwọn sí ipò ńlá nínú Ìjọba rẹ̀. Ohun tí wọ́n ń fẹ́ yẹn múnú bí àwọn àpọ́sítélì yòókù. Ọ̀ràn wíwá ipò ọlá sì máa ń fa àríyànjiyàn láàárín wọn. Àmọ́ Jésù máa ń fi sùúrù tọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí sọ́nà, kì í sì í jẹ́ kí ohun tí wọ́n ṣe bí òun nínú.—Mát. 20:20-28.
5, 6. (a) Kí nìdí tí Jésù fi ń bá èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣọ̀rẹ́ nìṣó? (b) Kí nìdí tí Jésù fi dẹ́kun bíbá Júdásì ṣọ̀rẹ́?
5 Kì í ṣe pé Jésù fàyè gbàgbàkugbà tàbí pé kò ríran rí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ aláìpé yìí ló fi ń bá wọn ṣọ̀rẹ́ nìṣó. Kàkà bẹ́ẹ̀, èrò rere tó wà lọ́kàn wọn àtàwọn ànímọ́ rere wọn ni Jésù ń wò. Bí àpẹẹrẹ, ńṣe ni Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù ń sùn dípò kí wọ́n máa bá Jésù ṣọ́nà lákòókò tó dojú kọ ìṣòro tó le jù lọ. Ó dájú pé ọ̀ràn náà dun Jésù. Síbẹ̀, ó mọ̀ pé wọ́n kò ní èrò burúkú lọ́kàn, ó ní: “Ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”—Mát. 26:41.
6 Àmọ́ Jésù dẹ́kun bíbá Júdásì Ísíkáríótù ṣọ̀rẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Júdásì fojú jọ ọ̀rẹ́, Jésù mọ̀ pé ó ti jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ dìdàkudà. Nítorí pé Júdásì ti di ọ̀rẹ́ ayé, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run. (Ják. 4:4) Nítorí náà, Jésù ti lé Júdásì jáde kó tó sọ fáwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá yòókù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ pé àwọn ni ọ̀rẹ́ òun.—Jòh. 13:21-35.
7, 8. Báwo ni Jésù ṣe fi ìfẹ́ tó ní sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ hàn?
7 Jésù máa ń gbójú fo àṣìṣe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin, ó sì máa ń ṣohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, ó gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ pé kó dáàbò bò wọ́n nígbà tí àdánwò bá dojú kọ wọ́n. (Ka Jòhánù 17:11.) Jésù rí ibi tí agbára wọn mọ, ó sì lo ìgbatẹnirò. (Máàkù 6:30-32) Kì í ṣe èrò tiẹ̀ tó fẹ́ sọ fún wọn nìkan ló jẹ ẹ́ lógún, ó tún fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹnu tiwọn náà, kó sì lóye ohun tí wọ́n ń rò àti bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn.—Mát. 16:13-16; 17:24-26.
8 Jésù lo ìgbésí ayé rẹ̀ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sì kú fún wọn. Lóòótọ́, ó mọ̀ pé ìlànà ìdájọ́ òdodo Baba òun béèrè pé kí òun fi ẹ̀mí òun lélẹ̀. (Mát. 26:27, 28; Héb. 9:22, 28) Àmọ́ ìfẹ́ tó ní fún wọn ló jẹ́ kó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀. Ó sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”—Jòh. 15:13.
Irú Ọ̀rẹ́ Wo Ni Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù Jẹ́ fún Un?
9, 10. Kí làwọn èèyàn ṣe látàrí bí Jésù ṣe yọ̀ǹda àkókò rẹ̀ àtàwọn ohun tó ní fún wọn?
9 Jésù yọ̀ǹda àkókò rẹ̀ àtàwọn ohun tó ní fáwọn èèyàn fàlàlà, ó sì fi ìfẹ́ bá wọn lò. Látàrí èyí, àwọn èèyàn sún mọ́ Jésù, tìdùnnú-tìdùnnú ni wọ́n sì fi ń ṣe nǹkan fún un. (Lúùkù 8:1-3) Nítorí ohun tí Jésù ti rí fúnra rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín. Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín. Nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.”—Lúùkù 6:38.
10 Àmọ́ ṣá o, àwọn kan wà tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n máa rí gbà lọ́dọ̀ Jésù ló ń mú kí wọ́n máa bá a rìn. Àwọn aríre-bani-jẹ ọ̀rẹ́ yìí pa Jésù tì nígbà tí wọ́n ṣi ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan lóye. Dípò kí wọ́n kọ́kọ́ gba ohun tó sọ yẹn gbọ́, bí wọn ò tiẹ̀ lóye rẹ̀, ńṣe ni wọ́n ronú lọ́nà tí kò tọ́ tí wọ́n sì pa dà lẹ́yìn Jésù. Àmọ́ ti àwọn àpọ́sítélì yàtọ̀, wọ́n dúró ṣinṣin. Àwọn náà rí ohun tó lè fẹ́ mú kí wọ́n ṣíwọ́ bíbá Kristi ṣọ̀rẹ́, àmọ́ wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dúró tì í nígbà dídùn àti nígbà kíkan. (Ka Jòhánù 6:26, 56, 60, 66-68.) Lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn kó tó kú, Jésù sọ ohun tó fi hàn pé ó mọrírì àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó ní: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi.”—Lúùkù 22:28.
11, 12. Kí ni Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú, kí lèyí sì mú kí wọ́n ṣe?
11 Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù gbóríyìn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan náà yìí pa á tì. Wọ́n fàyè gba ìbẹ̀rù èèyàn fúngbà díẹ̀ láti borí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Kristi. Àmọ́ Jésù tún dárí jì wọ́n. Lẹ́yìn tó kú tó sì jíǹde, ó fi ara rẹ̀ hàn wọ́n, ó sì fi dá wọn lójú pé ọ̀rẹ́ òun ṣì ni wọ́n jẹ́. Síwájú sí i, ó gbé iṣẹ́ mímọ́ kan lé wọn lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ sísọ “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè” di ọmọ ẹ̀yìn, ó sì tún sọ pé kí wọ́n máa ṣe ẹlẹ́rìí òun “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Mát. 28:19; Ìṣe 1:8) Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe ṣe iṣẹ́ náà?
12 Tọkàntara làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, kò pẹ́ tí wọ́n fi fi ẹ̀kọ́ wọn kún Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 5:27-29) Kódà wọ́n fi ikú halẹ̀ mọ́ wọn, àmọ́ ìyẹn kò ní kí wọ́n ṣíwọ́ ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn òun. Láàárín ọgbọ̀n ọdún péré lẹ́yìn tí Jésù pa àṣẹ náà fún wọn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ti wàásù ìhìn rere náà “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:23) Ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí mọyì ìdè ọ̀rẹ́ tó wà láàárín àwọn àti Jésù!
13. Àwọn ọ̀nà wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbà jẹ́ kí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa lórí àwọn?
13 Àwọn tó dọmọ ẹ̀yìn Jésù tún jẹ́ kí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa lórí ìgbésí ayé àwọn. Èyí gba pé kí ọ̀pọ̀ lára wọn ṣe àwọn àyípadà tó kàmàmà nínú ìwà àti ìṣe wọn. Lára àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dọmọ ẹ̀yìn, a rí àwọn tó jẹ́ abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, panṣágà, ọ̀mùtípara tàbí olè nígbà kan rí. (1 Kọ́r. 6:9-11) Àwọn kan ní láti yí èrò tí wọ́n ní nípa àwọn ẹ̀yà míì pa dà. (Ìṣe 10:25-28) Síbẹ̀, wọ́n ṣègbọràn sí Jésù. Wọ́n bọ́ ògbólógbòó ìwà wọn sílẹ̀, wọ́n sì gbé tuntun wọ̀. (Éfé. 4:20-24) Wọ́n dẹni tó mọ “èrò inú Kristi,” ìyẹn ni pé wọ́n lóye bó ṣe ń ronú àti bó ṣe ń hùwà, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—1 Kọ́r. 2:16.
Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Kristi Lóde Òní
14. Kí ni Jésù ṣèlérí pé òun máa ṣe nígbà “ìparí ètò àwọn nǹkan”?
14 Ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti mọ Jésù tó kó kú tàbí kí wọ́n ti rí i lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀. Ó ṣe kedere pé àwa kò ní irú àǹfààní yẹn. Báwo wá la ṣe lè di ọ̀rẹ́ Kristi? Ọ̀nà kan tá a lè gbà di ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni pé ká máa ṣègbọràn sí ìtọ́ni ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ arákùnrin Jésù tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. Jésù ṣèlérí pé nígbà “ìparí ètò àwọn nǹkan,” òun yóò yan ẹrú yìí sípò “lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní [òun].” (Mát. 24:3, 45-47) Lónìí, ọ̀pọ̀ jaburata lára àwọn tó ń fẹ́ di ọ̀rẹ́ Kristi kì í ṣe ara ẹgbẹ́ ẹrú yìí. Báwo ni ojú tí wọ́n fi ń wo ìtọ́ni ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ ṣe ń nípa lórí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àárín àwọn àti Kristi?
15. Kí ló máa pinnu bóyá ẹnì kan yóò jẹ́ àgùntàn tàbí ewúrẹ́?
15 Ka Mátíù 25:31-40. Jésù pe àwọn tó máa di ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ ní arákùnrin òun. Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa yíya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́, ó sọ ọ́ kedere pé ohunkóhun tá a bá ṣe fáwọn arákùnrin òun, òun alára là ń ṣe é fún. Ní tòdodo, ó sọ pé ohun tó máa fìyàtọ̀ sáàárín àgùntàn àti ewúrẹ́ ni ọ̀nà tí olúkúlùkù bá gbà ń hùwà sí “ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin [òun] wọ̀nyí.” Nítorí náà, ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ni ọ̀nà pàtàkì táwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé máa ń gbà fi hàn pé àwọn fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Kristi.
16, 17. Ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn arákùnrin Kristi?
16 Tó o bá nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ọ̀nà wo lo máa gbà fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn arákùnrin Kristi? Jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́ ni pé ká máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tọkàntọkàn. Kristi pàṣẹ fáwọn arákùnrin rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù ìhìn rere náà kárí ayé. (Mát. 24:14) Àmọ́, iṣẹ́ náà yóò nira fún àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn arákùnrin Kristi lórí ilẹ̀ ayé tí kò bá sí ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Ká sòótọ́, gbogbo ìgbà tí ẹnì kan lára àwọn àgùntàn mìíràn bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, àwọn arákùnrin Kristi ló ń ràn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ mímọ́ tí Jésù gbé fún wọn. Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye mọrírì irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yìí, Kristi pàápàá mọrírì rẹ̀.
17 Ọ̀nà kejì táwọn tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn gbà ń ran àwọn arákùnrin Kristi lọ́wọ́ ni fifi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n yan ọ̀rẹ́ fún ara wọn nípasẹ̀ “ọrọ̀ àìṣòdodo.” (Lúùkù 16:9) Èyí ò túmọ̀ sí pé a lè fowó fa ojú Jèhófà àti Jésù mọ́ra o. Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá ń lo ohun ìní wa láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú, ńṣe là ń fi hàn pé ọ̀rẹ́ wọn la jẹ́ àti pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í ṣe lọ́rọ̀ ẹnu lásán àmọ́ “ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòh. 3:16-18) A máa ń ṣe irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, nígbà tá a bá dáwó fún iṣẹ́ ìkọ́lé àti fún títọ́jú àwọn ibi tá a ti ń pé jọ àti nígbà tá a bá fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Bóyá owó tá a dá kéré tàbí ó pọ̀, ó dájú pé Jèhófà àti Jésù mọrírì bá a ṣe jẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.—2 Kọ́r. 9:7.
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà táwọn alàgbà bá fún wa látinú Bíbélì?
18 Ọ̀nà kẹta tí gbogbo wa lè gbà fi hàn pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Kristi ni pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn alàgbà ìjọ. Ẹ̀mí mímọ́ ló yan àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lábẹ́ ìdarí Kristi. (Éfé. 5:23) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.” (Héb. 13:17) Nígbà míì, ó lè ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà táwọn alàgbà ìjọ fún wa látinú Bíbélì. Ó ṣeé ṣe ká máa rí ibi tí àìpé ẹ̀dá ti máa ń mú kí wọ́n ṣàṣìṣe, èyí sì lè mú ká máa fojú tí kò tọ́ wo àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún wa. Síbẹ̀, ó tẹ́ Kristi Orí ìjọ lọ́rùn láti lo àwọn èèyàn aláìpé wọ̀nyí. Torí náà, ọ̀nà tá a ń gbà tẹ̀ lé ìtọ́ni wọn yóò nípa lórí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àwa àti Kristi. Nígbà tá a bá gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn alàgbà tá a sì ń fàyọ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọn, a ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Kristi.
Ibi Tá A Ti Lè Rí Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́
19, 20. Kí la lè rí láàárín ìjọ, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé èyí?
19 Bí Jésù ṣe ń lo àwọn olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ láti máa bójú tó wa, ó tún pèsè àwọn ìyá, arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí fún wa nínú ìjọ. (Ka Máàkù 10:29, 30.) Báwo làwọn ẹbí rẹ ṣe ṣe sí ọ nígbà tó o kọ́kọ́ dé inú ètò Jèhófà? Ó ṣeé ṣé kí wọ́n tì ọ́ lẹ́yìn láti sún mọ́ Ọlọ́run àti Kristi. Àmọ́ Jésù sọ pé nígbà míì, “àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.” (Mát. 10:36) Ẹ ò rí i pé ohun ìtùnú gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé a lè rí àwọn tó sún mọ́ wa tímọ́tímọ́ ju ọmọ ìyá wa lọ nínú ìjọ!—Òwe 18:24.
20 Ìkíni tí Pọ́ọ̀lù fi parí lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Róòmù fi hàn pé ó ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. (Róòmù 16:8-16) Bákan náà, ní ìparí lẹ́tà kẹta tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ, ó sọ pé: “Bá mi kí àwọn ọ̀rẹ́ ní orúkọ-orúkọ.” (3 Jòh. 14) Ó hàn kedere pé Jòhánù pẹ̀lú ní àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ti ń bá ara wọn bọ̀ tipẹ́. Tó bá di ọ̀ràn yíyan ọ̀rẹ́ àtàtà láàárín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kí àárín wa sì máa gún régé, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àti tàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? Àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé èyí yóò jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa jíjẹ́ ọ̀rẹ́ àtàtà?
• Irú ọ̀rẹ́ wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù jẹ́ fún un?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Kristi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Jésù máa ń fẹ́ láti mọ ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń rò àti bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wọn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Kristi?