Ǹjẹ́ o Ti Rí “Ẹ̀mí Òtítọ́ Náà” Gbà?
“Baba . . . yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé, ẹ̀mí òtítọ́ náà.”—JÒHÁNÙ 14:16, 17.
1. Ìsọfúnni pàtàkì wo ni Jésù fi tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ létí ní àwọn wákàtí tó fi wà pẹ̀lú wọn kẹ́yìn ní yàrá òkè?
“OLÚWA ibo ni ìwọ ń lọ?” Ọ̀kan lára ìbéèrè táwọn àpọ́sítélì Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nìyẹn láàárín àwọn wákàtí tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn nínú yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù. (Jòhánù 13:36) Bí ìpàdé náà ti ń lọ lọ́wọ́ ni Jésù fi tó wọn létí pé ó ti tó àkókò wàyí fún òun láti padà sọ́dọ̀ Baba òun. (Jòhánù 14:28; 16:28) Kò ní sí lọ́dọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara mọ́, láti máa fún wọn nítọ̀ọ́ni àti láti máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Àmọ́, ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nípa sísọ pé: “Èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ [tàbí olùtùnú] mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé.”—Jòhánù 14:16, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
2. Kí ni Jésù ṣèlérí pé òun yóò rán sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn lẹ́yìn tí òun bá lọ?
2 Jésù sọ ohun tí olùrànlọ́wọ́ náà jẹ́, ó sì ṣàlàyé ọ̀nà tó máa gbà ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ́wọ́. Ó sọ fún wọn pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan wọ̀nyí ni èmi kò sọ fún yín ní àkọ́kọ́, nítorí pé mo wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi . . . Fún àǹfààní yín ni mo fi ń lọ. Nítorí bí èmi kò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà kì yóò wá sọ́dọ̀ yín lọ́nàkọnà; ṣùgbọ́n bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, èmi yóò rán an sí yín dájúdájú. . . . Nígbà tí èyíinì bá dé, ẹ̀mí òtítọ́ náà, yóò ṣamọ̀nà yín sínú òtítọ́ gbogbo.”—Jòhánù 16:4, 5, 7, 13.
3. (a) Ìgbà wo la rán “ẹ̀mí òtítọ́ náà” sí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? (b) Ọ̀nà pàtàkì wo ni ẹ̀mí náà gbà jẹ́ “olùrànlọ́wọ́” fún wọn?
3 Ìlérí yìí nímùúṣẹ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, bí àpọ́sítélì Pétérù ṣe jẹ́rìí sí i pé: “Jésù yìí ni Ọlọ́run jí dìde, òtítọ́ tí gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún. Nítorí náà, nítorí pé a gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tí ó sì gba ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tú èyí tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ jáde.” (Ìṣe 2:32, 33) Gẹ́gẹ́ bí a ó ṣe rí i níwájú, ẹ̀mí mímọ́ tí a tú jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù ṣèlérí pé “ẹ̀mí òtítọ́ náà” yóò ‘mú gbogbo ohun tí òun ti sọ fún wọn padà wá sí ìrántí wọn.’ (Jòhánù 14:26) Yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rántí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti ẹ̀kọ́ rẹ̀, kódà yóò rán wọn létí àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ́nu rẹ̀ jáde gan-an, wọn ó sì kọ wọ́n sílẹ̀. Èyí ti ní láti ran àpọ́sítélì Jòhánù arúgbó nì lọ́wọ́ gan-an ní òpin ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, nígbà tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ìwé Ìhìn Rere tí ó kọ. Àkọsílẹ̀ yẹn ní àwọn ìmọ̀ràn ṣíṣeyebíye tí Jésù fúnni ní alẹ́ ọjọ́ tó dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ nínú.—Jòhánù, orí 13 sí 17.
4. Báwo ni “ẹ̀mí òtítọ́ náà” ṣe ran àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́?
4 Jésù tún ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn pé ẹ̀mí náà yóò ‘kọ́ wọn ní ohun gbogbo,’ yóò sì ‘ṣamọ̀nà wọn sínú òtítọ́ gbogbo.’ Ẹ̀mí náà yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn ohun ìjìnlẹ̀ inú Ìwé Mímọ́, yóò sì jẹ́ kí èrò, òye, àti ète wọn ṣọ̀kan. (1 Kọ́ríńtì 2:10; Éfésù 4:3) Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn lágbára láti jùmọ̀ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tó ń fún Kristẹni ẹni àmì òróró kọ̀ọ̀kan ní “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—Mátíù 24:45.
Ẹ̀mí Náà Ń Jẹ́rìí
5. (a) Kí ni ohun tuntun tí Jésù sọ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní alẹ́ Nísàn 14 ọdún 33 Sànmánì Tiwa? (b) Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ yóò kó nínú ìmúṣẹ ìlérí Jésù?
5 Ní alẹ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù fi tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ létí pé wọn yóò wá sọ́dọ̀ òun nígbà tó bá yá, wọn ó sì máa gbé lọ́dọ̀ òun àti Baba òun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ó sọ fún wọn pé: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi ì bá ti sọ fún yín, nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.” (Jòhánù 13:36; 14:2, 3) Wọn óò bá a jọba nínú Ìjọba rẹ̀. (Lúùkù 22:28-30) Kí ọwọ́ wọn tó lè tẹ ìrètí ti ọ̀run yìí, wọ́n ní láti di ẹni tá a “bí láti inú ẹ̀mí,” gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí, kí a sì fòróró yàn wọ́n láti sìn gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi ní òkè ọ̀run.—Jòhánù 3:5-8; 2 Kọ́ríńtì 1:21, 22; Títù 3:5-7; 1 Pétérù 1:3, 4; Ìṣípayá 20:6.
6. (a) Ìgbà wo ni ìpè ti ọ̀run bẹ̀rẹ̀, àwọn mélòó ló sì gba ìpè yìí? (b) Inú kí la batisí àwọn tá a pè sí?
6 “Ìpè ti ọ̀run” yìí bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó sì dà bíi pé ó parí ní àárín àwọn ọdún 1930. (Hébérù 3:1) Iye àwọn tí ẹ̀mí mímọ́ fi èdìdì dì láti jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí a “rà lára aráyé.” (Ìṣípayá 7:4; 14:1-4) Àwọn wọ̀nyí la batisí sínú ara Kristi nípa tẹ̀mí, tá a batisí sínú ìjọ rẹ̀, àti sínú ikú rẹ̀. (Róòmù 6:3; 1 Kọ́ríńtì 12:12, 13, 27; Éfésù 1:22, 23) Lẹ́yìn tá a ti fi omi batisí wọn tán, tá a sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, ni wọ́n wá wọnú ipa ọ̀nà ìfara-ẹni-rúbọ, tó túmọ̀ sí pé wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé ìwà títọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn.—Róòmù 6:4, 5.
7. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kìkì àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló ń jẹ tó sì ń mu àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí?
7 Gẹ́gẹ́ bí Ísírẹ́lì tẹ̀mí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí wà nínú májẹ̀mú tuntun tó wà láàárín Jèhófà àti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16; Jeremáyà 31:31-34) A fẹsẹ̀ májẹ̀mú tuntun yìí múlẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi tí a ta sílẹ̀. Jésù mẹ́nu kan èyí nígbà tó dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀. Àkọsílẹ̀ Lúùkù sọ pé: “Ó mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’ Àti ife pẹ̀lú, lọ́nà kan náà lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó wí pé: ‘Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.’” (Lúùkù 22:19, 20) Àwọn àṣẹ́kù, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù sórí ilẹ̀ ayé lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà ló ń jẹ búrẹ́dì, tí wọ́n sì ń mu wáìnì ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi.
8. Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń mọ̀ pé àwọn ti gba ìpè ti ọ̀run?
8 Báwo làwọn ẹni àmì òróró ṣe ń mọ̀ pé àwọn ti gba ìpè ti ọ̀run? Ẹ̀mí mímọ́ ló ń fún wọn ní ẹ̀rí láìsí iyèméjì kankan rárá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Gbogbo àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń ṣamọ̀nà, àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Ọlọ́run. . . . Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, kìkì bí a bá jọ jìyà pa pọ̀, kí a lè ṣe wá lógo pa pọ̀ pẹ̀lú.” (Róòmù 8:14-17) Ẹ̀rí tí ẹ̀mí mímọ́ ń jẹ́ yìí lágbára débi pé àwọn tó bá ń ṣiyèméjì nípa bóyá àwọn ti rí i gbà tàbí àwọn kò rí i gbà máa ń parí èrò sí pé àwọn kò rí i gbà, wọn kì í sì í jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí.
Ẹ̀mí Náà àti Àwọn Àgùntàn Mìíràn
9. Àwọn ẹgbẹ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo la mẹ́nu kàn nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere àti nínú ìwé Ìṣípayá?
9 Nítorí pé àwọn Kristẹni tó para pọ̀ jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí kéré níye ni Jésù ṣe pè wọ́n ní “agbo kékeré.” A gbà wọ́n wọlé sínú “ọ̀wọ́” májẹ̀mú tuntun náà, ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn “àgùntàn mìíràn” tí kò lóǹkà, tí Jésù sọ pé àwọn pẹ̀lú ni òun yóò kó jọ. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Àwọn àgùntàn mìíràn tí a ń kó jọ ní àkókò ìkẹyìn yìí ló máa di “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí yóò la “ìpọ́njú ńlá” já, pẹ̀lú ìrètí gbígbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé títí láé. Ó dùn mọ́ni pé, ìran tí Jòhánù rí ní òpin ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa fi ìyàtọ̀ sáàárín ogunlọ́gọ̀ ńlá àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ mẹ́ńbà Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Ìṣípayá 7:4, 9, 14) Ṣé àwọn àgùntàn mìíràn pẹ̀lú máa rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ni, bí wọ́n bá máa rí i gbà, ipa wo ló máa ní lórí ìgbésí ayé wọn?
10. Báwo la ṣe batisí àwọn àgùntàn mìíràn “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́”?
10 Láìsí àní-àní, ẹ̀mí mímọ́ ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn àgùntàn mìíràn. Wọ́n fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣe batisí “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Mátíù 28:19) Wọ́n gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ, wọ́n ń tẹrí ba fún Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Olùtúnniràpadà wọn, wọ́n sì ń tọ ipa ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run, ìyẹn agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀, ń darí wọn sí nínú ìgbésí ayé. Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń gbìyànjú láti mú “èso ti ẹ̀mí” dàgbà nínú ìgbésí ayé wọn, ìyẹn “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gálátíà 5:22, 23.
11, 12. (a) Báwo la ṣe sọ àwọn ẹni àmì òróró di mímọ́ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀? (b) Ọ̀nà wo la gbà sọ àwọn àgùntàn mìíràn di mímọ́?
11 Àwọn àgùntàn mìíràn tún ní láti jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sọ wọ́n di mímọ́. A ti sọ àwọn ẹni àmì òróró di mímọ́ lọ́nà àkànṣe, ní ti pé a ti polongo wọn ní olódodo àti ẹni mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Kristi. (Jòhánù 17:17; 1 Kọ́ríńtì 6:11; Éfésù 5:23-27) Wòlíì Dáníẹ́lì pè wọ́n ní “àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ,” tí yóò gba ìjọba lábẹ́ “ọmọ ènìyàn” náà, Kristi Jésù. (Dáníẹ́lì 7:13, 14, 18, 27) Ṣáájú àkókò yẹn, Jèhófà tipasẹ̀ Mósè àti Áárónì polongo fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín; kí ẹ sì sọ ara yín di mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.”—Léfítíkù 11:44.
12 Ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ìsọdimímọ́” túmọ̀ sí gan-an ni “sísọni di mímọ́, yíyanisọ́tọ̀, tàbí yíyọ̀ǹda ẹni fún iṣẹ́ ìsìn tàbí fún ìlò Jèhófà Ọlọ́run; ipò jíjẹ́ ẹni mímọ́, tàbí tí a wẹ̀ mọ́.” Láti ọdún 1938 ni Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì ti sọ pé ẹgbẹ́ Jónádábù, ìyẹn àwọn àgùntàn mìíràn, “gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìyàsímímọ́ àti ìsọdimímọ́ pọn dandan fún ẹnikẹ́ni tí yóò di ara ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí yóò sì máa gbé orí ilẹ̀ ayé títí lọ fáàbàdà.” Nínú ìran ogunlọ́gọ̀ ńlá tá a kọ sínú ìwé Ìṣípayá, a sọ pé wọ́n ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” àti pé wọ́n “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún” Jèhófà “tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Ìṣípayá 7:9, 14, 15) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, àwọn àgùntàn mìíràn ń sa gbogbo ipá wọn láti dé ojú ìlà àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè nínú ọ̀ràn ìjẹ́mímọ́.—2 Kọ́ríńtì 7:1.
Ṣíṣoore fún Àwọn Arákùnrin Kristi
13, 14. (a) Ní ìbámu pẹ̀lú àkàwé Jésù nípa àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́, kí ni ìgbàlà àwọn àgùntàn sinmi lé? (b) Ọ̀nà wo làwọn àgùntàn mìíràn ń gba ṣoore fáwọn arákùnrin Kristi ní àkókò òpin yìí?
13 Jésù tẹnu mọ́ àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwọn àgùntàn mìíràn àti agbo kékeré nínú òwe tó pa nípa àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́, èyí tó mẹ́nu kàn nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “òpin ètò àwọn nǹkan.” Nínú àkàwé yẹn, Kristi fi hàn kedere pé ohun tí yóò mú kí àwọn àgùntàn mìíràn rí ìgbàlà ni irú ìwà tí wọ́n bá hù sí àwọn ẹni àmì òróró, tó pè ní “àwọn arákùnrin mi.” Ó sọ pé: “Ọba yóò wí fún àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé. . . . Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹ ti ṣe é fún mi.’”—Mátíù 24:3; 25:31-34, 40.
14 Gbólóhùn náà “dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é” tọ́ka sí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n fún àwọn arákùnrin Kristi tí a fi ẹ̀mí bí, àwọn tí ayé Sátánì ń wò bí àjèjì, tí wọ́n tiẹ̀ ń ju àwọn kan lára wọn sẹ́wọ̀n pàápàá. Wọ́n ti ṣe aláìní oúnjẹ, aṣọ, àti ìtọ́jú ìlera. (Mátíù 25:35, 36, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ní àkókò òpin yìí, láti ọdún 1914 ni ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àmì òróró ti bá ara wọn nínú irú ipò bẹ́ẹ̀. Ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní fi hàn pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó jẹ́ adúróṣinṣin, ìyẹn àwọn àgùntàn mìíràn ń tì wọ́n lẹ́yìn, bí ẹ̀mí ṣe ń darí àwọn wọ̀nyí.
15, 16. (a) Inú ìgbòkègbodò wo làwọn àgùntàn mìíràn ti dìídì ń ran àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ́wọ́? (b) Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe fi ìmọrírì wọn hàn fún àwọn àgùntàn mìíràn?
15 Àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi tó wà lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò òpin yìí ní pàtàkì ń gbádùn ìtìlẹ́yìn gbígbámúṣé tí àwọn àgùntàn mìíràn ń fún wọn nínú ọ̀ràn pípa àṣẹ tí Ọlọ́run fún wọn mọ́, èyíinì ni láti “wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14; Jòhánù 14:12) Bí iye àwọn ẹni àmì òróró ti ń dín kù sí i bí ọdún ti ń gorí ọdún ni iye àwọn àgùntàn mìíràn ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ti di àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn wọ̀nyí ló ń sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún—àwọn aṣáájú ọ̀nà àti míṣọ́nnárì—tí wọ́n ń mú ìhìn rere ìjọba náà lọ sí “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Àwọn tó kù ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà dé ibi tí wọ́n lè ṣe é dé, wọ́n sì ń fi tayọ̀tayọ̀ lo owó wọn fún iṣẹ́ pàtàkì yìí.
16 Àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi mọrírì ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ táwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń fún wọn yìí gan-an ni! Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn la ṣàlàyé nínú ìwé Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” tí ẹgbẹ́ ẹrú náà tẹ̀ jáde ní ọdún 1986. Ìwé náà sọ pé: “Lati igba Ogun Agbaye II, imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu fun ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan’ ni eyi ti ó pọ julọ jẹ́ nitori ipa ti ‘ogunlọgọ nla’ ti ‘awọn aguntan miiran’ ń sà. . . . Ọpẹ gidigidi ni, nigba naa, fun ‘ogunlọgọ nla’ elédè ahọn pupọ naa jakejado awọn orilẹ-ede fun ipa ribiribi ti wọn ti sà ní mimu asọtẹlẹ [Jesu] ninu Matteu 24:14 ṣẹ!”
‘A Kò Sọ Wọ́n Di Pípé Láìsí Àwa’
17. Ní ọ̀nà wo ni àwọn olóòótọ́ ìgbàanì tí a óò jí dìde sórí ilẹ̀ ayé ‘kò fi ní di pípé láìsí’ àwọn ẹni àmì òróró?
17 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró, tó sì ń tọ́ka sí àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àtobìnrin tó gbé ayé ṣáájú Kristi, ó kọ̀wé pé: “Bí wọ́n tilẹ̀ ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí wọn nípa ìgbàgbọ́ wọn, gbogbo àwọn wọ̀nyí kò rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti rí ohun tí ó dára jù tẹ́lẹ̀ fún wa [àwọn ẹni àmì òróró], kí a má bàa sọ wọ́n di pípé láìsí àwa.” (Hébérù 11:35, 39, 40) Láàárín Ẹgbẹ̀rúndún náà, Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀ ní ọ̀run yóò jẹ́ ọba àti àlùfáà, wọn ó sì rí sí i pé àwọn èèyàn jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn àgùntàn mìíràn yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ “di pípé” ní ara àti ní èrò inú.—Ìṣípayá 22:1, 2.
18. (a) Kí ló yẹ kí àwọn ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì jẹ́ kí àwọn àgùntàn mìíràn mọrírì rẹ̀? (b) Kí ni àwọn àgùntàn mìíràn ń retí bí wọ́n ti ń dúró de “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run”?
18 Ó yẹ kí gbogbo èyí jẹ́ kí àwọn àgùntàn mìíràn mọ ìdí tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì fi darí àfiyèsí tó pọ̀ sórí Kristi àtàwọn ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀ àti ipa pàtàkì tí wọ́n kó nínú mímú ète Jèhófà ṣẹ. Àwọn àgùntàn mìíràn wá tipa bẹ́ẹ̀ kà á sí àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ ẹrú náà ní gbogbo ọ̀nà tó bá ṣeé ṣe, bí wọ́n ti ń dúró de “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run” nígbà Amágẹ́dọ́nì àti ní àárín Ẹgbẹ̀rúndún náà. Wọ́n lè máa fojú sọ́nà fún dídi ẹni tí ‘a dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, kí wọ́n sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.’—Róòmù 8:19-21.
Wíwà Ní Ìṣọ̀kan Nínú Ẹ̀mí Nígbà Ìṣe Ìrántí
19. Kí ni “ẹ̀mí òtítọ́ náà” ti ṣe fún àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, báwo ni wọn ó sì ṣe wà ní ìṣọ̀kan lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ March 28?
19 Nínú àdúrà tí Jésù gbà kẹ́yìn ní alẹ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó sọ pé: ‘Mo ṣe ìbéèrè kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi jáde.’ (Jòhánù 17:20, 21) Ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ láti wá fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ìgbàlà àwọn ẹni àmì òróró àti ti aráyé onígbọràn. (1 Jòhánù 2:2) “Ẹ̀mí òtítọ́ náà” ti so àwọn arákùnrin Kristi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn pọ̀ ṣọ̀kan. Ní ìrọ̀lẹ́ March 28, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì yóò kóra jọ pọ̀ láti ṣayẹyẹ ìrántí ikú Kristi àti láti rántí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀, Kristi Jésù. Ǹjẹ́ kí wíwà níbi ayẹyẹ pàtàkì yìí fún ìṣọ̀kan wọn lókun, kó sì sọ ìpinnu wọn láti máa bá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó dọ̀tun, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀rí hàn pé inú àwọn dùn láti wà lára àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́.
Àtúnyẹ̀wò
• Ìgbà wo la rán “ẹ̀mí òtítọ́” sí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, báwo ló sì ṣe jẹ́ “olùrànlọ́wọ́”?
• Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró ṣe ń mọ̀ pé àwọn ti rí ìpè ti ọ̀run gbà?
• Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ń ṣiṣẹ́ lára àwọn àgùntàn mìíràn?
• Báwo làwọn àgùntàn mìíràn ṣe ṣoore fún àwọn arákùnrin Kristi, kí sì nìdí tí wọn ò fi lè “di pípé láìsí” àwọn ẹni àmì òróró?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
A tú “ẹ̀mí òtítọ́ náà” sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn àgùntàn mìíràn ti ṣoore fún àwọn arákùnrin Kristi nípa títì wọ́n lẹ́yìn nínú mímú àṣẹ Ọlọ́run láti wàásù ṣẹ