Kí Ni Jésù Fi Kọ́ni Nípa Ọ̀run Àpáàdì?
Jésù sọ pé: “Bí ojú rẹ bá ń mú ọ dẹ́ṣẹ̀ yọ ọ́ dà nù. Ó sàn kí o lọ sí ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí o ní ojú méjì kí a sì jù ẹ́ sínú ọ̀run àpáàdì. Àwọn kòkòrò ibẹ̀ kì í kú, iná kì í sì í kú níbẹ̀.”—MÁÀKÙ 9:47, 48, ìtúmọ̀ Contemporary English Version.
Jésù tún sọ̀rọ̀ nípa àkókò ìdájọ́, nígbà tó ń sọ fáwọn èèyàn búburú pé: ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún. Ẹ lọ sínú iná àjóòkú tí a ti pèsè sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.’ Ó tún sọ pé àwọn wọ̀nyí ‘yóò lọ sínú ìyà àìlópin.’—MÁTÍÙ 25:41, 46, Ìròhìn Ayọ̀.
TÓ O bá kọ́kọ́ ka àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà lókè yìí, ó lè dà bíi pé òun náà ń fi ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì kọ́ni. Ó dájú pé Jésù ò ta ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sọ kedere pé: ‘Àwọn òkú kò mọ ohun kan.’—Oníwàásù 9:5, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Kí wá ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé wọ́n máa ju àwọn kan “sínú ọ̀run àpáàdì”? Ṣé iná gidi ni “iná àjóòkú” tí Jésù kìlọ̀ nípa rẹ̀, àbí iná ìṣàpẹẹrẹ? Báwo làwọn èèyàn búburú ṣe máa ‘lọ sínú ìyà àìlópin’? Ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí níkọ̀ọ̀kan.
Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé wọ́n máa ju àwọn kan “sínú ọ̀run àpáàdì”? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ọ̀run àpáàdì” nínú Máàkù 9:47 ni Geʹen·na. Inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà Geh Hin·nomʹ, ni wọ́n ti tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ni “Àfonífojì Hínómù.” Ẹ̀yin odi ìlú Jerúsálẹ́mù ìgbàanì ni Àfonífojì Hínómù wà. Láyé àwọn ọba Ísírẹ́lì, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń fàwọn ọmọ kéékèèké rúbọ, èyí sì jẹ́ ìwà ìríra tínú Ọlọ́run ò dùn sí. Ọlọ́run sọ pé òun máa pa àwọn tó ń ṣe irú ìjọsìn èké bẹ́ẹ̀ run. Àfonífojì Hínómù máa wá di ‘àfonífojì ìpakúpa,’ níbi tí ‘òkú àwọn ènìyàn yìí’ ti máa wà nílẹ̀ láìsin. (Jeremáyà 7:30-34, Bibeli Ajuwe) Jèhófà tipa báyìí sọ tẹ́lẹ̀ pé Àfonífojì Hínómù máa di ibi tí wọ́n á máa ju àwọn òkú sí, kì í ṣe ibi tí wọ́n á ti máa dá àwọn èèyàn lóró.
Nígbà tí Jésù wà láyé, ìdọ̀tí làwọn ará Jerúsálẹ́mù máa ń dà sí Àfonífojì Hínómù. Wọ́n máa ń ju òkú àwọn ọ̀daràn síbẹ̀, iná tó wà níbẹ̀ kì í sì í kú, kó lè máa jó ìdọ̀tí àti òkú àwọn ọ̀daràn tó wà níbẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 66:24 ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ń sọ nípa kòkòrò àti iná tí kì í kú. Nígbà tí Aísáyà sọ̀rọ̀ nípa ‘òkú àwọn tí ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí [Ọlọ́run],’ ó sọ pé, ‘kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná kì yóò sì kú.’ (Bibeli Ajuwe) Jésù àtàwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ mọ̀ pé òkú àwọn ẹni tí kò yẹ kí wọ́n sin ni Aísáyà ń sọ̀rọ̀ nípa wọn.
Nítorí náà, Jésù lo Àfonífojì Hínómù tàbí Gẹ̀hẹ́nà láti ṣàpẹẹrẹ ikú tí kò ní ní àjíǹde. Ó jẹ́ kí ohun tó ní lọ́kàn nípa Gẹ̀hẹ́nà ṣe kedere nígbà tó sọ pé Ọlọ́run ‘lè pa ara àti ọkàn run ní ọ̀run àpáàdì,’ ìyẹn Gẹ̀hẹ́nà. (Mátíù 10:28, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Gẹ̀hẹ́nà ń ṣàpẹẹrẹ ikú ayérayé, kì í ṣe ìdálóró ayérayé.
Ṣé iná gidi ni “iná àjóòkú” tí Jésù kìlọ̀ nípa rẹ̀ àbí iná ìṣàpẹẹrẹ? Kíyè sí i pé “iná àjóòkú” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bó ṣe wà nínú ìwé Mátíù 25:41 wà fún ‘Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.’ Ṣó o rò pé iná lásán lè jó àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí? Àbí Jésù ń fi “iná” ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan ni? Ó dájú pé “àwọn àgùntàn” àti “àwọn ewúrẹ́” tí Jésù mẹ́nu kan nínú ọ̀rọ̀ kan náà yìí kì í ṣe àgùntàn àti ewúrẹ́ lásán, ó fi wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwùjọ àwọn èèyàn méjì kan ni. (Mátíù 25:32, 33) Iná àjóòkú tí Jésù ń sọ máa jó àwọn ẹni ibi run pátápátá lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.
Báwo làwọn èèyàn búburú ṣe máa ‘lọ sínú ìyà àìlópin’? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “ìyà” nínú ìwé Mátíù 25:46, ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà koʹla·sin túmọ̀ sí gan-an ni pé kéèyàn “gé ẹ̀ka igi” tí kò wúlò dà nù. Torí náà, báwọn tó jẹ́ oníwà bí àgùntàn ṣe ń gba ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn oníwà bí ewúrẹ́ tí kò ronú pìwà dà máa jẹ́ ‘ìyà àìlópin,’ ní ti pé Ọlọ́run máa gé wọn dà nù títí láé.
Kí Lèrò Ẹ?
Jésù ò fìgbà kankan kọ́ni pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú. Àmọ́, ó sábà máa ń kọ́ni pé àwọn òkú máa jí dìde. (Lúùkù 14:13, 14; Jòhánù 5:25-29; 11:25) Kí nìdí tí Jésù á fi sọ pé àwọn òkú máa jíǹde tó bá gbà gbọ́ pé ẹ̀mí wọn kì í kú?
Jésù ò kọ́ni pé Ọlọ́run máa dá àwọn ẹni búburú lóró títí ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: ‘Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.’ (Jòhánù 3:16, Ìròhìn Ayọ̀) Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé àwọn tí kò bá gba òun gbọ́ máa kú? Ì bá ti sọ fún wa, tó bá jẹ́ pé wọ́n máa wà láàyè títí láé níbi tí wọ́n á ti máa joró nínú iná ọ̀run àpáàdì.
Bíbélì ò kọ́ni pé ibi tí Ọlọ́run ti máa dá àwọn èèyàn lóró ni ọ̀run àpáàdì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀kọ́ àwọn kèfèrí táwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni fi ń kọ́ni ni. (Wo àpótí náà “Ìtàn Ṣókí Nípa Ọ̀run Àpáàdì,” lójú ìwé 6) Ọlọ́run kì í fìyà jẹ àwọn èèyàn títí ayé nínú ọ̀run àpáàdì. Tó o bá mọ òtítọ́ nípa ọ̀run àpáàdì, báwo nìyẹn ṣe lè nípa lórí irú ẹni tó o rò pé Ọlọ́run jẹ́?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
ÌTÀN ṢÓKÍ NÍPA Ọ̀RUN ÀPÁÀDÌ
Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN KÈFÈRÍ NI: Àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì gbà pé iná wà ní ọ̀run àpáàdì. Ìwé kan tí wọ́n ń pè ní The Book Ȧm-Ṭuat, tí wọ́n kọ ní ọdún 1375 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n “máa fi sọ̀kò sínú kòtò oníná; . . . wọn ò ní lè sá jáde bẹ́ẹ̀ ni . . . wọn ò ní lè yè bọ́ lọ́wọ́ iná náà.” Onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ Plutarch (tó gbé láyé láàárín ọdún 46 sí ọdún 120 Sànmánì Kristẹni) kọ̀wé nípa àwọn ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ilẹ̀, ó sọ pé: “[Wọ́n] ń figbe ta bí wọ́n ṣe ń jìyà tí wọ́n sì ń joró.”
Ẹ̀KỌ́ Ọ̀RUN ÀPÁÀDÌ WỌNÚ ÌSÌN ÀWỌN JÚÙ: Òpìtàn Josephus (tó gbé láyé láàárín ọdún 37 sí ọdún 100 Sànmánì Kristẹni) kọ̀wé pé ẹ̀ya ìsìn àwọn Júù kan tí wọ́n ń pè ní Essenes gbà pé “ọkàn kì í kú, ńṣe ló máa ń wà títí láé.” Ó fi kún un pé: “Ohun táwọn Gíríìkì náà gbà gbọ́ nìyí . . . Wọ́n gbà pé ìyà ayérayé níbi ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan tó ṣókùnkùn ló tọ́ sáwọn ẹni búburú.”
ÀWỌN ALÁFẸNUJẸ́ KRISTẸNI MÚ Ẹ̀KỌ́ YÌÍ WỌNÚ Ẹ̀SÌN WỌN: Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni, ìwé àpókírífà, ìyẹn Apocalypse of Peter sọ nípa àwọn ẹni burúkú pé: “Iná àjóòkú ló ń dúró dè wọ́n.” Ó tún sọ pé: “Áńgẹ́lì ìbínú tó ń jẹ́ Ezrael kó àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tíná ń jó lára wọn, ó sì jù wọ́n sínú ibì kan tó ṣókùnkùn, ìyẹn ọ̀run àpáàdì tó wà fáwọn èèyàn, ẹ̀dá ẹ̀mí kan sì ń fìyà jẹ wọ́n níbẹ̀.” Lákòókò yẹn kan náà, òǹkọ̀wé kan tó ń jẹ́ Theophilus ará Áńtíókù fa ọ̀rọ̀ Sibyl tó jẹ́ wòlíì obìnrin láti ilẹ̀ Gíríìsì yọ, o ní obìnrin náà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìyà tó máa jẹ́ àwọn ẹni ibi, ó sọ pé: “Iná ń bọ̀ wá sórí yín, títí ayé sì ni èéfín iná á máa rú lórí yín.” Àwọn ọ̀rọ̀ yìí wà lára ọ̀rọ̀ tí ọ̀gbẹ́ni Theophilus sọ pé ó jẹ́ “òótọ́, pé ó wúlò, ó bá ìdájọ́ òdodo mu, ó sì ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní.”
TORÍ WỌ́N NÍGBÀGBỌ́ NÍNÚ INÁ Ọ̀RUN ÀPÁÀDÌ NI WỌ́N ṢE MÁA Ń HÙWÀ IPÁ LÁYÉ ÀTIJỌ́: Àwọn èèyàn sọ pé ọbabìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Mary Kìíní, (tó gbé láyé láàárín ọdún 1553 sí 1558), dáná sun àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Pùròtẹ́sítáǹtì tó tó nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] lórí igi, ó sọ pé: “Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti ń dáná sun àwọn tí kò fara mọ́ ìgbàgbọ́ wa nínú ọ̀run àpáàdì báyìí, ohun tó dáa jù témi náà lè máa ṣe báyìí ni pé kí n fara wé Ọlọ́run, kí n sì máa dáná sun wọ́n láyé.”
ÌTÚMỌ̀ TUNTUN: Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ẹ̀sìn kan ti yí ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni nípa ọ̀run àpáàdì pa dà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1995, Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ẹ̀kọ́ Ẹ̀sìn Nínú Ìjọ Áńgílíkà, sọ pé: “Ọ̀run àpáàdì kì í ṣe ibi tí Ọlọ́run ti máa dá àwọn èèyàn lóró títí ayérayé, àmọ́ ohun tó túmọ̀ sí gan-an ni ohun tó máa gbẹ̀yìn àwọn tó bá ń ṣe orí kunkun, tí wọ́n sì kọ̀ láti ṣèfẹ́ Ọlọ́run, wọn ò sì ní sí mọ́ rárá.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
KÍ NI “ADÁGÚN INÁ”?
Ìwé Ìfihàn [Ìṣípayá, Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun] 20:10 jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run á ju Èṣù sínú “adágún iná”, á ‘sì máa dá a lóró tọ̀sán-tòru láé àti láéláé.’ (Bibeli Yoruba Atọ́ka) Tó bá jẹ́ pé títí láé ni Èṣù máa joró, a jẹ́ pé Ọlọ́run dá ẹ̀mí ẹ̀ sí nìyẹn, ohun tí Bíbélì sì sọ ni pé Jésù máa ‘pa á run.’ (Hébérù 2:14, Bibeli Mimọ) Adágún iná náà ṣàpẹẹrẹ “ikú kejì.” (Ìṣípayá 21:8) Ikú tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ kì í ṣe ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà, ìyẹn ikú tó ní àjíǹde tí Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:21, 22) Torí pé Bíbélì ò sọ pé àwọn tó wà nínú “adágún iná” máa jíǹde, ó fi hàn pé “ikú kejì” gbọ́dọ̀ jẹ́ oríṣi ikú míì, tí kò ní àjíǹde.
Báwo làwọn tó wà nínú “adágún iná” ṣe ń joró títí ayérayé? Nígbà míì, “ìdánilóró” lè túmọ̀ sí “láti fi nǹkan kan du” ẹnì kan. Nígbà kan tí Jésù àtàwọn ẹ̀mí èṣù pàdé, wọ́n figbe ta pé: ‘Ìwọ wá láti dá wa lóró [rán wa lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀] kí ó tó tó àkókò?’ (Mátíù 8:29; Lúùkù 8:30, 31; Bibeli Mimọ) Torí náà, gbogbo àwọn tó wà nínú “adágún” náà ló máa ‘joró’ ní ti pé Ọlọ́run máa fi ìwàláàyè dù wọ́n títí láé, èyí sì túmọ̀ sí “ikú kejì.”