“Ẹ Máa Bá a Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”!
“Ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—MÁÀKÙ 13:37.
1, 2. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni ọkùnrin kan kọ́ nípa ṣíṣọ́ ohun ìní rẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ wo lá rí kọ́ nípa wíwà lójúfò látinú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa olè?
JUAN tọ́jú àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ sínú ilé. Ó tọ́jú wọn sábẹ́ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀—lójú tirẹ̀, èèrà kankan ò lè rà á níbẹ̀. Àmọ́ lóru ọjọ́ kan, tóun àti ìyàwó rẹ̀ ti sùn, olè wọ iyàrá náà. Ó hàn gbangba pé olè náà mọ ibi gan-an tó yẹ kóun lọ. Ó rọra kó gbogbo nǹkan olówó iyebíye tó wà lábẹ́ bẹ́ẹ̀dì náà àti owó tí Juan fi pa mọ́ sínú dúrọ́ọ̀ tó wà lára tábìlì tó gbé sẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀. Àárọ̀ ọjọ́ kejì ni Juan tó mọ̀ pé olè ti ja òun. Kò lè gbàgbé ẹ̀kọ́ bíbaninínújẹ́ tó kọ́ pé: Ẹni tó ń sùn ò lè ṣọ́ ohun ìní rẹ̀.
2 Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn ṣe rí nípa tẹ̀mí. A ò lè ṣọ́ ìrètí àti ìgbàgbọ́ wa tá a bá ń sùn. Ìdí rèé tí Pọ́ọ̀lù fi rọ̀ wá pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù ti ń ṣe, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò, kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:6) Ká bà a lè mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká wà lójúfò, Jésù lo àpèjúwe olè. Ó sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tóun fi máa wá gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́, ẹ̀yìn náà ló kìlọ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ mọ ohun kan, pé ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, ì bá wà lójúfò, kì bá sì ti yọ̀ǹda kí a fọ́ ilé rẹ̀. Ní tìtorí èyí, ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Mátíù 24:42-44) Olè kì í sọ fúnni pé ìgbà báyìí lòun ń bọ̀ wá fọ́lé. Ìgbà tí ẹnikẹ́ni ò retí rẹ̀ ló máa wá. Lọ́nà kan náà, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, òpin ètò àwọn nǹkan yìí á dé ní ‘wákàtí tí a kò ronú pé yóò dé.’
“Ẹ Wà Lójúfò, Ẹ Dúró Gbọn-in Gbọn-in Nínú Ìgbàgbọ́”
3. Báwo ni Jésù ṣe fi àpèjúwe àwọn ẹrú tó ń dúró de ọ̀gá wọn tó lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ṣàkàwé bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká wà lójúfò?
3 Nínú àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù, Jésù fi àwọn Kristẹni wé àwọn ẹrú tó ń dúró de ìgbà tí ọ̀gá wọn máa ti ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó tó lọ dé. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọpọlọ wọ́n jí pépé, kí wọ́n lè wà lójúfò láti yẹ́ ọ̀gá wọn sí nígbà tó bá dé. Bákan náà, Jésù sọ pé: “Ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.” (Lúùkù 12:40) Àwọn kan tí wọ́n ti ń sin Jèhófà láti ọdún pípẹ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ kí iná ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú wọn bẹ̀rẹ̀ sí jó àjórẹ̀yìn níbi tójú ọjọ́ dé yìí. Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ó ṣì máa pẹ́ gan-an kí òpin tó dé. Àmọ́ irú èrò yìí lè máà jẹ́ ká fiyè sáwọn ohun tẹ̀mí mọ́, ká bẹ̀rẹ̀ sí lé ohun tara, èyí sì lè mú ká máa tòògbé nípa tẹ̀mí.—Lúùkù 8:14; 21:34, 35.
4. Irú ìdánilójú wo ló lè mú ká máa ṣọ́nà, báwo sì ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ èyí?
4 A lè rí ẹ̀kọ́ mìíràn kọ́ látinú àkàwé Jésù. Òótọ́ ni pé àwọn ẹrú náà kò mọ wákàtí tí ọ̀gá wọn á dé, àmọ́ wọ́n mọ òru ọjọ́ tó máa dé. Ì bá ṣòro fún wọn láti wà lójúfò ní gbogbo òru ọjọ́ náà ká ní wọ́n ronú pé òru ọjọ́ mìíràn lọ̀gá wọn á dé. Àmọ́ wọn ò ronú lọ́nà yìí, wọ́n mọ òru ọjọ́ tó máa dé gan-an, ìyẹn sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà lójúfò. Lọ́nà kan náà, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi yé wa kedere pé àkókò òpin la wà yìí; àmọ́ wọn ò sọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí òpin náà á dé fún wa. (Mátíù 24:36) Ìgbàgbọ́ tá a ní pé òpin náà á dé ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò, àmọ́ tó bá dá wa lójú pé lóòótọ́ ni ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé, èyí á túbọ̀ mú ká máa ṣọ́nà.—Sefanáyà 1:14.
5. Báwo la ṣe ṣàmúlò ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù pé ká “wà lójúfò”?
5 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ wà lójúfò, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 16:13) Dájúdájú, wíwà lójúfò wa tan mọ́ dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ Kristẹni. Báwo la ṣe lè wà lójúfò? Nípa níní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ sí i nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:14, 15) Ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti lílọ sípàdé déédéé ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun, bẹ́ẹ̀ sì ni fífi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn jẹ́ apá kan tó ṣe pàtàkì nínú ìgbàgbọ́ wa. Nítorí náà, tá a bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé a ti sún mọ́ òpin ètò yìí látìgbàdégbà, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gbàgbé àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì nípa òpin tó ti sún mọ́lé náà.a Ó tún dára ká máa kíyè sí bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ṣe ń mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Arákùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì kọ̀wé pé: “Gbogbo ìgbà tí mo bá ń gbọ́ ìròyìn—ogun, ilẹ̀ ríri, ìwà ipá àti bí ilẹ̀ ayé wa ṣe ń di eléèérí—ló túbọ̀ ń sọ sí mi lọ́kàn pé òpin ti sún mọ́lé.”
6. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣàlàyé pé èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí dẹwọ́ wíwà lójúfò bí àkókò ṣe ń lọ?
6 A rí àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ ìyànjú mìíràn tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wà lójúfò nínú Máàkù orí kẹtàlá. Nínú orí yìí, Jésù fi ipò táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà wé ti olùṣọ́nà tó ń dúró de ìgbà tí ọ̀gá rẹ̀ á ti ìrìn àjò rẹ̀ sí ilẹ̀ òkèèrè dé. Olùṣọ́nà yìí kò mọ wákàtí tí ọ̀gá rẹ̀ máa dé. Ó gbọ́dọ̀ máa ṣọ́nà ṣáá ni. Jésù tọ́ka sí ìṣọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ọ̀gá rẹ̀ lè dé ní èyíkéyìí lára wọn. Ìṣọ́ kẹrin máa ń bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí aago mẹ́ta ìdájí títí dìgbà tí oòrùn á yọ. Láàárín ìṣọ́ tó gbẹ̀yìn yìí, olùṣọ́nà náà lè bẹ̀rẹ̀ sí tòògbé. A tiẹ̀ gbọ́ pé àwọn jagunjagun gbà pé ìgbà tó bá kù díẹ̀ kí ilẹ̀ mọ́ ni àkókò tó dára jù lọ láti lọ mú ọ̀tá tíyẹn ò sì ní fura. Bákan náà, lákòókò òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, táráyé ti sùn fọnfọn nípa tẹ̀mí, ó lè di dandan ká jà fitafita láti wà lójúfò. (Róòmù 13:11, 12) Abájọ tí Jésù fi sọ ọ́ tó tún tún un sọ nínú àkàwé rẹ̀ pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò . . . Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà . . . Ohun tí mo sọ fún yín ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn, Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—Máàkù 13:32-37.
7. Ewu ńlá wo ló ń bẹ, ìṣírí wo la sì ń rí gbà nínú Bíbélì látìgbàdégbà?
7 Lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló gbani níyànjú láti wà lójúfò. Kódà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìgbà tí Ìwé Mímọ́ bá mẹ́nu kan òpin ètò àwọn nǹkan yìí la máa ń rí ìkìlọ̀ náà láti wà lójúfò tàbí láti máa ṣọ́nà.b (Lúùkù 12:38, 40; Ìṣípayá 3:2; 16:14-16) Ó ṣe kedere pé ewu ńláǹlà ni kéèyàn máa tòògbé nípa tẹ̀mí. Gbogbo wa pátá lá nílò ìkìlọ̀ yìí!—1 Kọ́ríńtì 10:12; 1 Tẹsalóníkà 5:2, 6.
Àwọn Àpọ́sítélì Mẹ́ta Tí Kò Wà Lójúfò
8. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù sọ pé káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mẹ́ta máa ṣọ́nà nínú ọgbà Gẹtisémánì?
8 Ohun tó túmọ̀ sí láti wà lójúfò ju kéèyàn máa gbèrò ohun rere lọ́kàn lọ, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù ṣe fi hàn. Èèyàn tẹ̀mí làwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí, wọ́n fi òótọ́ inú tẹ̀ lé Jésù wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Àmọ́ wọn ò wà lójúfò ní òru Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Nígbà tí wọ́n kúrò ní yàrá òkè tí wọ́n ti ṣe àjọ̀dún Ìrékọjá, àwọn àpọ́sítélì mẹ́ta yìí tẹ̀ lé Jésù lọ sínú ọgbà Gẹtisémánì. Ibẹ̀ ni Jésù ti sọ fún wọn pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi, àní títí dé ikú. Ẹ dúró síhìn-ín, kí ẹ sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà pẹ̀lú mi.” (Mátíù 26:38) Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù gbàdúrà tìtaratìtara sí Baba rẹ̀ ọ̀run, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ló sì lọ wo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí àmọ́ wọ́n ti sùn fọnfọn.—Mátíù 26:40, 43, 45.
9. Kí ni nǹkan tó lè fà á táwọn àpọ́sítélì fi ń sùn?
9 Kí nìdí táwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí fi já Jésù kulẹ̀ lóru ọjọ́ náà? Ìdí kan ni pé ó ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu. Ilẹ̀ ti ṣú gan-an, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀gànjọ́ òru ni àkókò náà, ‘ojú wọn sì ti wúwo’ fún oorun. (Mátíù 26:43) Síbẹ̀, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò. Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”—Mátíù 26:41.
10, 11. (a) Pẹ̀lú pé ó ti rẹ Jésù gan-an, kí ló ràn án lọ́wọ́ láti wà lójúfò nínú ọgbà Gẹtisémánì? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì mẹ́ta nígbà tí Jésù ní kí wọ́n máa ṣọ́nà?
10 Kò sí àní-àní pé ó ti rẹ Jésù fúnra rẹ̀ gan-an lóru ọjọ́ mánigbàgbé yẹn. Àmọ́ dípò tí ì bá fi máa sùn, ńṣe ló fi ìwọ̀nba àkókò tó kù yìí gba àdúrà tìtaratìtara. Ní ọjọ́ mélòó kan ṣáájú, ó ti rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà. Ó sọ pé: “Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró níwájú Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 21:36; Éfésù 6:18) Tá a bá ṣègbọràn si ìmọ̀ràn Jésù tá a sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ dídára rẹ̀ nínú ọ̀ràn àdúrà, ẹ̀bẹ̀ tá à ń bẹ Jèhófà látọkànwá á ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí.
11 Lóòótọ́, Jésù mọ̀—bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ò mọ̀ lákòókò yẹn—pé wọ́n máa tó fàṣẹ ọba mú òun wọ́n á sì dájọ́ ikú fóun. Orí òpó igi oró ni ìrora àdánwò rẹ̀ yìí á ti wá ga lágajù. Jésù ti sọ gbogbo èyí fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀, àmọ́ òye rẹ̀ kò yé wọn. Ìdí rèé tí wọ́n fi sùn lọ nígbà tóun wà lójúfò tó ń gbàdúrà. (Máàkù 14:27-31; Lúùkù 22:15-18) Ẹran ara ti àwa náà ṣe aláìlera bíi tàwọn àpọ́sítélì, àwọn ohun kan sì wà tá ò tíì lóye. Àmọ́, tá ò bá fi sọ́kàn pé kì í ṣe àkókò téèyàn ń ṣe sùẹ̀sùẹ̀ la wà yìí, a lè bẹ̀rẹ̀ sí sùn nípa tẹ̀mí. Kìkì ìgbà tá ò bá jókòó gẹlẹtẹ nìkan la lè wà lójúfò.
Ànímọ́ Pàtàkì Mẹ́ta
12. Ànímọ́ mẹ́ta wo ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó ṣe pàtàkì fún pípa agbára ìmòye wa mọ́?
12 Báwo la ṣe lè ní ẹ̀mí kánjúkánjú? A ti mọ bí àdúrà ṣe ṣe pàtàkì tó a sì ti rí i pé ó yẹ ká máa fi ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn. Kò wá tán síbẹ̀ o, Pọ́ọ̀lù tún sọ àwọn ànímọ́ pàtàkì mẹ́ta tá a gbọ́dọ̀ ní. Ó sọ pé: “Ní ti àwa tí a jẹ́ ti ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a pa agbára ìmòye wa mọ́, kí a sì gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀ àti ìrètí ìgbàlà gẹ́gẹ́ bí àṣíborí.” (1 Tẹsalóníkà 5:8) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ní ṣókí, ipa tí ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ ń kó nínú wíwà lójúfò wa nípa tẹ̀mí.
13. Ipa wo ni ìgbàgbọ́ ń kó nínú wíwà lójúfò wa?
13 A gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in pé Jèhófà wà àti pé “òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ìmúṣẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa àkókò òpin kọ́kọ́ ní ní ọ̀rúndún kìíní jẹ́ ká túbọ̀ nígbàgbọ́ pé ó máa nímùúṣẹ títóbi jù lọ ní àkókò tiwa. Ìgbàgbọ́ wa tún ń mú ká máa fi ìháragàgà retí dídé ọjọ́ Jèhófà, a sì ní ìdánilójú pé “[ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà] yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.
14. Tá a bá fẹ́ wà lójúfò, báwo ni ìrètí ti ṣe pàtàkì tó?
14 Ńṣe ni ìgbàgbọ́ wa tó dájú dà bí “ìdákọ̀ró fún ọkàn,” tó ń mú ká fara da ìṣòro, kódà bó tiẹ̀ túmọ̀ sí pé a ní láti dúró dìgbà táwọn ìlérí kan pàtó tí Ọlọ́run ṣe á nímùúṣẹ. (Hébérù 6:18, 19) Arábìnrin Margaret tó jẹ́ ẹni àmì òróró, tó ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún, tó sì ti ṣèrìbọmi ní ohun tó lé láàádọ́rin ọdún sẹ́yìn sọ pé: “Nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ kọlu ọkọ mi lọ́dún 1963, ńṣe ló ń ṣe mí bí ẹni pé kí òpin dé ní kíákíá. Àmọ́ mo ti wá rí i báyìí pé àǹfààní tara mi nìkan ni mò ń rò nígbà yẹn. A ò mọ ibi tí iṣẹ́ náà máa gbòòrò dé kárí ayé nígbà yẹn. Kódà ní báyìí pàápàá, ọ̀pọ̀ ibi ni iṣẹ́ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dé. Inú mi dùn gan-an pé Jèhófà mú sùúrù.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú un dá wa lójú pé: ‘Ìfaradà [ń mú] ipò ìtẹ́wọ́gbà [wá]; ipò ìtẹ́wọ́gbà, ní tirẹ̀, ìrètí, ìrètí náà kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀.”—Róòmù 5:3-5.
15. Báwo ni ìfẹ́ á ṣe mú ká máà tẹ̀ síwájú kódà nígbà tó bá dà bí ẹni pé ó ti pẹ́ tá a ti ń retí kí òpin dé àmọ́ tí kò dé?
15 Ìfẹ́ Kristẹni jẹ́ ànímọ́ tó ta yọ nítorí pé òun gan-an ló ń mú wa ṣe ohunkóhun tá a bá ń ṣe. Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà la ṣe ń jọ́sìn rẹ̀, láìfi àkókò yòówù kó yàn kalẹ̀ pè. Ìfẹ́ fún aládùúgbò wa ló ń mú ká wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, bó ti wu kí àkókò tí Ọlọ́run fẹ́ ká fi ṣe é gùn tó àti bó ti wù kí iye ìgbà tá a máa padà lọ wàásù nínú ilé kan náà ti pọ̀ tó. Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé, “àwọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àwọn mẹ́ta wọ̀nyí; ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:13) Ìfẹ́ ń mú ká ní ìfaradà ó sì ń mú ká wà lójúfò. “[Ìfẹ́] a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”—1 Kọ́ríńtì 13:7, 8.
“Máa Bá A Nìṣó Ní Dídi Ohun Tí Ìwọ Ní Mú Ṣinṣin”
16. Dípò ká dẹwọ́, irú ànímọ́ wo ló yẹ ká ní?
16 Àkókò pàtàkì la wà yìí táwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ń rán wa létí pé a ti wà ní apá òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (2 Tímótì 3:1-5) Àkókò yìí kì í ṣe èyí tó yẹ kéèyàn máa ṣe sùẹ̀sùẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ ká ‘máa bá a nìṣó ní dídi ohun tí a ti ní mú ṣinṣin.’ (Ìṣípayá 3:11) Tá a bá ‘wà lójúfò ní jíjẹ́ kí àdúrà jẹ wá lọ́kàn,’ tá a sì ní ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́, àá lè gbára dì de àkókò ìdánwò. (1 Pétérù 4:7) Iṣẹ́ ń bẹ jabíjabí fún wa láti ṣe nínú Olúwa. Tá a bá sì jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, àá lè wà lójúfò dáadáa.—2 Pétérù 3:11.
17. (a) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí ìjákulẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 21.) (b) Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà, ìrètí wo ló sì ń dúró de àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Jeremáyà kọ̀wé pé: “Jèhófà ni ìpín mi, . . . ìdí nìyẹn tí èmi yóò ṣe fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí i. Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí ẹni tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí ọkàn tí ń wá a. Ó dára kí ènìyàn dúró, àní ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, de ìgbàlà Jèhófà.” (Ìdárò 3:24-26) Àwọn kan lára wa ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí dúró láti rí ìgbàlà Jèhófà ni. Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn mìíràn ti ń bá a bọ̀. Àmọ́ àkókò tá a fi dúró yìí kò tó nǹkan kan tá a bá fi wéra pẹ̀lú ayérayé tó ń bẹ níwájú! (2 Kọ́ríńtì 4:16-18) Bá a sì ṣe ń dúró de àkókò tí Jèhófà yàn, a lè fìgbà yẹn mú àwọn ànímọ́ pàtàkì Kristẹni dàgbà ká sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti fi àkókò tí Jèhófà ń mú sùúrù yìí kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Nígbà náà, ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà. Ẹ jẹ́ ká fara wé Jèhófà ká ní sùúrù, ká sì máa ṣọpẹ́ fún ìrètí tó fún wa. Bá a sì ṣe wà lójúfò náà, ká má ṣe fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tá a ní. Ìgbà náà ni ìlérí alásọtẹ́lẹ̀ yìí á jẹ́ tiwa, èyí tó sọ pé: “[Jèhófà] yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.”—Sáàmù 37:34.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Á dára ká ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí, nínú Ilé Ìṣọ́ January 15, 2000, ojú ìwé 12 àti 13.—2 Tímótì 3:1.
b Nígbà tí W. E. Vine, tó jẹ́ atúmọ̀ èdè ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tá a tú sí “wà lójúfò,” ó ṣàlàyé pé ní ṣáńgílítí, ó túmọ̀ sí ‘kéèyàn lé oorun lọ,’ kì í sì í “ṣe kéèyàn kàn wà lójúfò lásán là ń sọ̀, bí kò ṣe pé kéèyàn ṣe bí àwọn tí ohun kan ń jẹ lọ́kàn ṣe ń fi gbogbo ara ṣọ́nà.”
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo la ṣe lè túbọ̀ mú un dá ara wa lójú pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí ti sún mọ́lé?
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù?
• Àwọn ànímọ́ mẹ́ta wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
• Èé ṣe tó fi jẹ́ àkókò yìí ló yẹ ká ‘máa bá a nìṣó ní dídi ohun tí a ti ní mú ṣinṣin’?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
“Aláyọ̀ Ni Ẹni Tí Ń Bá A Nìṣó Ní Fífojúsọ́nà”—Dáníẹ́lì 12:12.
Ká sọ pé olùṣọ́ kan fura pé olè fẹ́ wá fọ́lé ní àdúgbò tó ń ṣọ́. Tí ilẹ̀ bá ti ṣú, ńṣe ni olùṣọ́ náà á máa tẹ́tí léko láti gbọ́ ìró èyíkéyìí tó lè tú olè náà fó. Gbogbo ìgbà lá á máa kẹ́tí tá á sì lajú sílẹ̀ kedere. Kódà, ìró tí ò tó nǹkan pàápàá lè gbé e lọ́kàn sókè—àwọn nǹkan bí ìró afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ igi sọ́tùn-ún sósì tàbí ti ológbò tó ń da nǹkan rú.—Lúùkù 12:39, 40.
Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń “fi ìháragàgà dúró de ìṣípayá Olúwa wa Jésù Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 1:7) Ohun táwọn àpọ́sítélì rò ni pé kété lẹ́yìn àjíǹde Jésù ló máa ‘mú ìjọba padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì. (Ìṣe 1:6) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, a rán àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà létí pé wíwàníhìn-ín Jésù ṣì di ọjọ́ iwájú. (2 Tẹsalóníkà 2:3, 8) Síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí yìí kò sọ pé ọjọ́ Jèhófà táwọn ń wọ̀nà fún ò tètè dé kí wọ́n wá tìtorí ìyẹn fi ọ̀nà ìyè sílẹ̀.—Mátíù 7:13.
Ní àkókò tá a wà yìí, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìjákulẹ̀ nítorí pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí tá à ń retí ò tètè dé mú ká dẹra sílẹ̀ ká máà wà lójúfò mọ́. Ìró àwọn nǹkan tí kò tó nǹkan lè tètè gbé olùṣọ́ tó wà lójúfò lọ́kàn sókè, síbẹ̀ ó gbọ́dọ̀ wà lójúfò! Kò níṣẹ́ méjì jùyẹn lọ. Bọ́ràn àwọn Kristẹni náà ṣe rí nìyẹn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ ó dá ọ lójú pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ìpàdé, àdúrà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní ṣíṣọ́nà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Gẹ́gẹ́ bíi ti Margaret, ẹ jẹ́ ká ní sùúrù ká sì máa ṣọ́nà nígbà gbogbo