“Kí ẹ Má Bàa Bọ́ Sínú Ìdẹwò”
“Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.”—MÁTÍÙ 26:41.
Ọ̀RÀN náà ò rọrùn fún Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run rárá, ó le ju ohunkóhun tí ojú rẹ̀ ti rí ṣáájú ìgbà yẹn lọ. Jésù ti sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Jésù mọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun, wọ́n á dájọ́ ikú fún òun, wọ́n á sì kan òun mọ́ igi oró. Ó mọ̀ pé ìpinnu èyíkéyìí tí òun bá ṣe tàbí ìgbésẹ̀ èyíkéyìí tí òun bá gbé yóò nípa lórí orúkọ Bàbá òun. Jésù tún mọ̀ pé ọrùn òun ni ìrètí ìwàláàyè ọjọ́ iwájú aráyé wà. Pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀ wàhálà ṣe dojú kọ ọ́ yìí, kí ló ṣe?
2 Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ọgbà Gẹtisémánì. Ibì kan tí Jésù fẹ́ràn gan-an láti máa lọ ni. Nígbà tó débẹ̀, ó rìn jìnnà díẹ̀ sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Nígbà tó wá ku òun nìkan, ó yíjú sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, ó gbàdúrà fún okun, ó sì sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un nínú àdúrà tó gbà taratara—kì í ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo o, nígbà mẹ́ta ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, kò ronú pé òun lè dá kójú wàhálà náà fúnra òun.—Mátíù 26:36-44.
3 Lónìí, wàhálà ń kojú àwa náà. Lápá ìbẹ̀rẹ̀ ìwé pẹlẹbẹ yìí, a gbé ẹ̀rí tó fi hàn pé a ti ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú yìí yẹ̀ wò. Ńṣe làwọn ìdẹwò àti àìfararọ ayé Sátánì ń le sí i. Àwọn ìpinnu tí gbogbo àwa tá a sọ pé à ń sin Ọlọ́run tòótọ́ ń ṣe àti àwọn ìgbésẹ̀ tí à ń gbé kan orúkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló sì tún kan ìrètí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti wà láàyè nínú ayé tuntun rẹ̀ gidigidi. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. A fẹ́ láti “fara dà á dé òpin”—yálà òpin ìgbésí ayé wa tàbí òpin ètò àwọn nǹkan yìí, èyíkéyìí tó bá kọ́kọ́ dé nínú rẹ̀. (Mátíù 24:13) Àmọ́ báwo la ṣe lè máa bá a lọ ní rírántí pé àkókò kánjúkánjú là ń gbé ká sì máa bá a lọ láti máa ṣọ́nà?
4 Níwọ̀n bí Jésù ti mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun—láyé ìgbà yẹn àti lóde òní—náà yóò rí wàhálà, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.” (Mátíù 26:41) Kí làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí fún wa lónìí? Ìdẹwò wo ló dojú kọ ọ́? Báwo lo sì ṣe lè “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà?”
Ìdẹwò Láti Ṣe Kí Ni?
5 Lójoojúmọ́, gbogbo wa pátá là ń rí ìdẹwò tó lè múni kó sínú “ìdẹkùn Èṣù.” (2 Tímótì 2:26) Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà gan-an ni Èṣù dájú sọ. (1 Pétérù 5:8; Ìṣípayá 12:12, 17) Fún ìdí wo? Kì í kúkú ṣe pé ẹ̀mí wa gan-an ló fẹ́ gbà. Bá a bá kú gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run, ìyẹn ò da nǹkan kan fún Sátánì. Sátánì mọ̀ pé nígbà tí àkókò bá tó lójú Jèhófà, yóò jí wa dìde, ikú kò sì ní sí mọ́.—Lúùkù 20:37, 38.
6 Ohun kan tó ṣeyebíye gan-an ju ìgbésí ayé wa ìsinsìnyí lọ ni Sátánì fẹ́ bà jẹ́ ìyẹn ni ìṣòtítọ́ wa sí Ọlọ́run. Kò sóhun tí Sátánì ò lè ṣe láti fi hàn pé òun lè yí wa padà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ohunkóhun bá lè sún wa di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run, ìyẹn ni pé ká dáwọ́ wíwàásù ìhìn rere náà dúró tàbí ká pa àwọn ìlànà Kristẹni tì, Sátánì ṣẹ́gun nìyẹn o! (Éfésù 6:11-13) Nípa bẹ́ẹ̀ ńṣe ni “Adẹniwò náà” máa ń gbé ìdẹwò síwájú wa.—Mátíù 4:3.
7 Oríṣiríṣi ọ̀nà ni “ètekéte” Sátánì máa ń gbà wá. (Éfésù 6:11) Ó lè fi ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ìbẹ̀rù, ṣíṣe iyèméjì tàbí ìlépa adùn dẹ wá wò. Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó ń ṣiṣẹ́ jù lọ tó máa ń lò ni ìrẹ̀wẹ̀sì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo ọgbọ́n tó máa fi mú wa ló ń wá, ó mọ̀ dáadáa pé àìnírètí lè sọ wá di aláìlágbára, èyí sì lè mú ká juwọ́ sílẹ̀. (Òwe 24:10) Àgàgà tí ìbànújẹ́ ọkàn bá sọ wá di “ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀,” ìgbà yẹn gan-an ló máa ń dẹ wá wò ká lè juwọ́ sílẹ̀.—Sáàmù 38:8.
8 Bá a ti túbọ̀ ń sún mọ́ òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó dà bíi pé ńṣe làwọn ohun tó ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì ń pọ̀ sí i, ó sì ń kan àwa náà. (Wo àpótí náà, “Díẹ̀ Lára Àwọn Ohun Tó Máa Ń Fa Ìrẹ̀wẹ̀sì.”) Ìrẹ̀wẹ̀sì lè tán wa lókun láìka ohun yòówù kó fà á. “Ríra àkókò tí ó rọgbọ padà” fún àwọn nǹkan tẹ̀mí, títí kan kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni àti kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, lè dìṣòro bó bá rẹ̀ ọ́ gan-an, tí èrò rẹ kò pa pọ̀ sọ́nà kan, tí ìdààmú ọkàn sì bá ọ. (Éfésù 5:15, 16) Rántí pé ńṣe ni Adẹniwò náà fẹ́ kó o jáwọ́. Àmọ́ kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ kó o dẹwọ́ tàbí kó o gbàgbé pé àkókò kánjúkánjú là ń gbé yìí! (Lúùkù 21:34-36) Báwo lo ṣe lè dènà ìdẹwò kó o sì máa bá a lọ láti máa ṣọ́nà? Gbé ìdámọ̀ràn mẹ́rin tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ yìí yẹ̀ wò.
“Máa Gbàdúrà Nígbà Gbogbo”
9 Gbára lé Jèhófà nípa gbígbàdúrà. Rántí ohun tí Jésù ṣe nínú ọgbà Gẹtisémánì. Nígbà tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò, kí ló ṣe? Ó ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, ó gbàdúrà kíkankíkan débi pé ‘òógùn rẹ̀ dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.’ (Lúùkù 22:44) Ronú ná. Jésù ṣáà mọ Sátánì dáadáa. Látọ̀run, Jésù ti rí gbogbo ìdẹwò tí Sátánì ń lò bó ti ń forí ṣe fọrùn ṣe láti dẹkùn mú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Síbẹ̀, Jésù kò ronú pé òun lè borí ohunkóhun tí Adẹniwò náà lè gbé síwájú òun tìrọ̀rùntìrọ̀rùn. Bí Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípe bá gbà pé ó pọn dandan fún òun láti gbàdúrà fún ìrànwọ́ àti òkun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, mélòómélòó wá làwa o!—1 Pétérù 2:21.
10 Tún rántí pé lẹ́yìn tí Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa “gbàdúrà nígbà gbogbo,” ó sọ pé: “Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.” (Mátíù 26:41) Ẹran ara ta ni Jésù ń tọ́ka sí? Ó dájú pé kì í ṣe tirẹ̀; kò sí nǹkan kan tó ṣàìlera nípa ẹran ara èèyàn pípé tó ní. (1 Pétérù 2:22) Àmọ́ ipò tàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yàtọ̀. Nítorí pé wọ́n ti jogún àìpé àti ìtẹ̀sí láti dẹ́ṣẹ̀, wọn yóò nílò ìrànwọ́ gan-an láti lè yẹra fún ìdẹwò. (Róòmù 7:21-24) Ìdí nìyẹn tó fi rọ̀ wọ́n—pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ tó ń bọ̀ lẹ́yìn wọn—láti máa gbàdúrà fún ìrànwọ́ láti borí ìdẹwò. (Mátíù 6:13) Jèhófà máa ń dáhùn irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 65:2) Lọ́nà wo? Lọ́nà méjì ó kéré tán.
11 Àkọ́kọ́, Ọlọ́run máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn ohun tó jẹ́ ìdẹwò mọ̀. Ńṣe làwọn ìdẹwò Sátánì dà bí ìdẹkùn tó wà káàkiri ojú ọ̀nà tó ṣókùnkùn. Bó ò bá rí wọn, o lè kó sínú wọn. Nípasẹ̀ Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì, Jèhófà ń tànmọ́lẹ̀, ó ń jẹ́ ká rí àwọn ìdẹkùn Sátánì, èyí sì ń jẹ́ ká lè borí ìdẹwò. Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá làwọn ìwé tí à ń tẹ̀ jáde àtàwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ láwọn ìpàdé àgbègbè àti ìpàdé àyíká ti ń pe àfiyèsí wa léraléra sáwọn ewu bí ìbẹ̀rù èèyàn, ìwà pálapàla, ìfẹ́ ọrọ̀ àtàwọn ìdẹwò mìíràn tí Sátánì ń gbé kò wá lójú. (Òwe 29:25; 1 Kọ́ríńtì 10:8-11; 1 Tímótì 6:9, 10) Ǹjẹ́ o ò dúpẹ́ pé Jèhófà ń kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ètekéte Sátánì? (2 Kọ́ríńtì 2:11) Rántí pé ìdáhùn sáwọn àdúrà rẹ fún ìrànwọ́ láti borí ìdẹwò ni gbogbo irú àwọn ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́.
12 Èkejì, Jèhófà ń dáhùn àwọn àdúrà wa nípa fífún wa ní okun láti lè fara da ìdẹwò. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: ‘Ọlọ́run kì yóò jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde.’ (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìdẹwò kan le débi pé a ò ní lókun tó pọ̀ tó nípa tẹ̀mí láti dènà rẹ̀—bá a bá ti ń gbára lé e. Báwo ló ṣe ń “ṣe ọ̀nà àbájáde” fún wa? Ó ń “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí yẹn lè mú ká rántí àwọn ìlànà Bíbélì tó lè fún ìpinnu wa láti ṣe ohun tó tọ́ lókun kó sì mú ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. (Jòhánù 14:26; Jákọ́bù 1:5, 6) Ó lè mú ká ní àwọn ànímọ́ tá a nílò láti lè ṣẹ́pá àwọn èrò tí kò tọ́. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ̀mí Ọlọ́run tiẹ̀ tún lè mú kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ‘di àrànṣe afúnnilókun fún wa.’ (Kólósè 4:11) Ǹjẹ́ o ò kún fún ọpẹ́ pé Jèhófà ń dáhùn àdúrà tó o gbà fún ìrànwọ́ lọ́nà onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀?
Má Retí Ohun Tí Kò Lè Ṣeé Ṣe
13 Láti lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, a ò gbọ́dọ̀ máa retí ohun tí kò lè ṣeé ṣe. Gbogbo wa ni àwọn wàhálà ìgbésí ayé máa ń dá lágara lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ká rántí pé Ọlọ́run kò fìgbà kankan ṣèlérí fún wa pé a ò ní níṣòro rárá nínú ètò àwọn nǹkan ògbólógbòó yìí o. Kódà lákòókò tí à ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn Ọlọ́run rí ìpọ́njú, títí kan inúnibíni, ìṣẹ́, ìdààmú ọkàn àti àìsàn.—Ìṣe 8:1; 2 Kọ́ríńtì 8:1, 2; 1 Tẹsalóníkà 5:14; 1 Tímótì 5:23.
14 Lónìí, àwa náà láwọn ìṣòro tá à ń bá yí. A lè dojú kọ inúnibíni, ìṣòro àìrówóná, ìdààmú ọkàn, àìsàn tàbí ká máa rí ìnira láwọn ọ̀nà míì. Tí Jèhófà bá lọ ń dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní jẹ́ kí Sátánì lẹ́nu ọ̀rọ̀ láti gan Jèhófà? (Òwe 27:11) Àmọ́ Jèhófà máa ń fàyè sílẹ̀ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rí ìdẹwò ká sì dán wọn wò, àní débi pé kí àwọn alátakò tiẹ̀ pa wọ́n láìtọ́jọ́ nígbà míì.—Jòhánù 16:2.
15 Nígbà náà, kí wá lohun tí Jèhófà ṣèlérí rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bá a ti mẹ́nu kàn án níṣàájú, ó ṣèlérí pé òun á jẹ́ ká lè borí ìdẹwò èyíkéyìí tó bá kò wá lójú, bá a bá ṣáà ti fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé òun. (Òwe 3:5, 6) Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀, ó ń dàábò bò wá nípa tẹ̀mí, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti pa àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ mọ́. Bí àjọṣe yẹn ò bá ṣáà ti bà jẹ́, kódà bá a tiẹ̀ kú, a ṣì borí. Kò sí ohun tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ láti san èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó dúró ṣinṣin, kódà ikú pàápàá ò lè dí i lọ́wọ́. (Hébérù 11:6) Nínú ayé tuntun èyí tó ti sún mọ́lé gan-an báyìí, Jèhófà kò ní ṣàìmú gbogbo ìlérí ìbùkún dídára yòókù tó ṣe fún àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ ṣẹ.—Sáàmù 145:16.
Rántí Àwọn Ọ̀ràn Tó Wà Nílẹ̀
16 Ká tó lè fara dà á dé òpin, a gbọ́dọ̀ rántí àwọn ọ̀ràn pàtàkì tó so mọ́ gbígbà tí Ọlọ́run fàyè gba ìwà burúkú. Báwọn ìṣòro wa bá fẹ́ dà bí ohun tó kọjá agbára wa láti fara dà nígbà míì tó sì ń dà bíi pé ká jáwọ́, yóò dára ká rán ara wa létí pé Sátánì ti pe ẹ̀tọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ níjà. Atannijẹ yìí tún ti sọ pé ìfọkànsìn àti ìwà títọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run kò wá látinú ọkàn wọn. (Jóòbù 1:8-11; 2:3, 4) Àwọn ọ̀ràn yìí àti ọ̀nà tí Jèhófà ti yàn láti fi yanjú wọn ṣe pàtàkì ju ẹ̀mí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ. Lọ́nà wo?
17 Gbígbà tí Ọlọ́run fàyè gba ìnira fúngbà díẹ̀ ti jẹ́ kí àyè wà fún àwọn mìíràn láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Ronú nípa èyí ná: Jésù jìyà kó lè ṣeé ṣe fún wa láti ní ìyè. (Jòhánù 3:16) Ǹjẹ́ a ò dúpẹ́ pé ó ṣe ìyẹn? Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ àwa náà múra tán láti fára da ìnira fúngbà díẹ̀ sí i kí àwọn mìíràn náà lè jèrè ìyè? Láti fara dà á títí dópin, a gbọ́dọ̀ gbà pé ọgbọ́n Jèhófà ju tiwa lọ fíìfíì. (Aísáyà 55:9) Yóò fòpin sí ìwà ibi ní àkókò tó dára jù lọ láti yanjú àwọn ọ̀ràn náà títí ayé àti fún ire wa ayérayé. Àbí, ká sòótọ́, ọ̀nà wo ló tún lè dára jùyẹn lọ? Kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ Ọlọ́run o!—Róòmù 9:14-24.
“Sún Mọ́ Ọlọ́run”
18 Láti lè máa bá a nìṣó láti máa rántí pé àkókò kánjúkánjú là ń gbé, a gbọ́dọ̀ sún mọ́ Jèhófà gan-an. Má ṣe gbàgbé rárá pé gbogbo agbára tí Sátánì ní ló ń sà láti ba àjọṣe dáadáa tó wà láàárín àwa àti Jèhófà jẹ́. Sátánì á fẹ́ ká gbà gbọ́ pé òpin kò ní dé rárá, àti pé kò sí ìdí láti máa wàásù ìhìn rere náà tàbí láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nígbèésí ayé. Àmọ́ “òpùrọ́ ni àti baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) A gbọ́dọ̀ pinnu lọ́kàn wa láti “kọ ojú ìjà sí Èṣù.” Àjọṣe tó wà láàárín àwa àti Jèhófà kì í ṣe ohun tá à ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá o. Bíbélì rọ̀ wá tìfẹ́tìfẹ́ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:7, 8) Báwo lo ṣe wá lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
19 Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò tàdúràtàdúrà. Tó bá dà bíi pé àwọn nǹkan fẹ́ nira jù fún ọ ní ìgbésí ayé, sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Jèhófà. Bí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣe ṣe pàtó sí, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe tètè mọ ìgbà tó bá dáhùn àwọn ẹ̀bẹ̀ rẹ. Nígbà mìíràn, ó lè máà dáhùn àdúrà rẹ gẹ́lẹ́ bó o ṣe rò, àmọ́ bó bá jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ ni láti bọ̀wọ̀ fún un tó o sì fẹ́ máa pa ìwà títọ́ rẹ mọ́ nìṣó, yóò pèsè ìrànlọ́wọ́ tó o nílò láti lè fara dà á fún ọ. (1 Jòhánù 5:14) Bó o ti ń rí ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ, wàá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn. Ó tún ṣe pàtàkì pé kó máa kà nípa àwọn ànímọ́ àtàwọn ọ̀nà Jèhófà èyí tó wà nínú Bíbélì kó o sì máa fara balẹ̀ ṣàṣàrò lórí wọn. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kó o túbọ̀ mọ̀ ọ́n sí i, yóò mú kí ọkàn rẹ kún fún ìmọrírì bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mú kí ìfẹ́ tó o ní fún un máa pọ̀ sí i. (Sáàmù 19:14) Ìfẹ́ yìí gan-an ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ju ohunkóhun mìíràn lọ láti borí ìdẹwò, táá sì jẹ́ kó o máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.—1 Jòhánù 5:3.
20 Láti lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó tún ṣe pàtàkì pé ká sún mọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Èyí la ó jíròrò nínú apá tó kẹ́yìn nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.
ÌBÉÈRÈ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
• Kí ni Jésù ṣe nígbà tí wàhálà ńlá dojú kọ ọ́ bó ti ń sún mọ́ òpin ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, kí ló sì rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣe? (Ìpínrọ̀ 1 sí 4)
• Kí nìdí tí Sátánì fi dájú sọ àwọn olùjọ́sìn Jèhófà, àwọn ọ̀nà wo ló sì ń gbà dẹ wá wò? (Ìpínrọ̀ 5 sí 8)
• Láti borí ìdẹwò, kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo (Ìpínrọ̀ 9 sí 12), tí kò fi yẹ ka máa retí ohun tí kò lè ṣeé ṣe (Ìpínrọ̀ 13 sí 15), tó fi yẹ ká máa rántí àwọn ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ (Ìpínrọ̀ 16 sí 17), tó sì fi yẹ ká “sún mọ́ Ọlọ́run” (Ìpínrọ̀ 18 sí 20)?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
Díẹ̀ Lára Àwọn Ohun Tó Máa Ń Fa Ìrẹ̀wẹ̀sì
Àìlera tàbí ọjọ́ ogbó. Bí àìsàn tí ò lọ bọ̀rọ̀ bá ń ṣe wá tàbí bí ọjọ́ ogbó ò bá jẹ́ ká lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, a lè máa ní ẹ̀dùn ọkàn nítorí pé a ò lè ṣe púpọ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Hébérù 6:10.
Ìjákulẹ̀. Ọkàn wa lè bà jẹ́ bá ò bá fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn tó fìfẹ́ hàn bá a ti ń sa gbogbo ipá wa láti wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Òwe 13:12.
Kíka ara ẹni sí aláìjámọ́-nǹkankan. Bí wọ́n bá ti fìyà jẹ ẹnì kan fún ọ̀pọ̀ ọdún, ẹni náà lè gbà lọ́kàn rẹ̀ pé kò sẹ́ni tó fẹ́ràn òun, kódà títí kan Jèhófà pàápàá.—1 Jòhánù 3:19, 20.
Bí wọ́n bá ṣẹ ẹnì kan. Ní ti àwọn kan, bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn bá ṣe ohun tó dùn wọ́n wọra, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn débi pé wọ́n á fẹ́rẹ̀ẹ́ láwọn ò lọ sí ìpàdé Kristẹni mọ́ tàbí pé àwọn ò kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mọ́.—Lúùkù 17:1.
Inúnibíni. Àwọn tí ẹ kò jọ ṣe ẹ̀sìn kan náà lè máa ṣàtakò rẹ, kí wọ́n máa ṣe inúnibíni sí ọ tàbí kí wọ́n máa fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.—2 Tímótì 3:12; 2 Pétérù 3:3, 4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Jésù rọ̀ wá pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo” fún ìrànlọ́wọ́ láti kojú ìdẹwò