“Ìjọba Mi Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé Yìí”
‘Nítorí èyí ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.’—JÒH. 18:37.
1, 2. (a) Kí nìdí táwọn èèyàn ayé ò fi wà níṣọ̀kan lónìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ARÁBÌNRIN kan láti gúúsù ilẹ̀ Yúróòpù sọ bí nǹkan ṣe rí fún un nígbà kan rí, ó ní: “Àtikékeré ni mo ti rí báwọn olóṣèlú ṣe ń hùwà ìrẹ́jẹ. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í tako ìjọba, mo wá ṣagbátẹrù ẹgbẹ́ àwọn oníjàgídíjàgan tó ń wá ìyípadà. Kódà, ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi fẹ́ ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ afẹ̀míṣòfò.” Arákùnrin kan láti gúúsù Áfíríkà tóun náà ti fìgbà kan rí jẹ́ oníjàgídíjàgan sọ pé: “Mo gbà pé ẹ̀yà mi ló dáa jù, torí náà mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kan. Wọ́n kọ́ wa pé ká máa fi ọ̀kọ̀ gún àwọn alátakò wa pa, kódà wọ́n ní ká máa pa àwọn tá a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà àmọ́ tí wọn ò sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú wa.” Arábìnrin kan tó ń gbé ní Yúróòpù sọ pé: “Mo kórìíra ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ ìlú mi àtàwọn tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ sí tèmi.”
2 Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ń hùwà bíi tàwọn mẹ́ta tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí. Onírúurú ẹgbẹ́ ajìjàgbara ló ń jà fún òmìnira. Rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo òṣèlú kì í ṣe kékeré. Lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè sì rèé, ọkàn àwọn àjèjì kì í balẹ̀ torí pé àwọn ọmọ ìbílẹ̀ kórìíra wọn. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn èèyàn máa jẹ́ “aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan,” bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ sì rí lóòótọ́. (2 Tím. 3:1, 3) Kí láá jẹ́ káwa Kristẹni wà níṣọ̀kan láìka bí àwọn èèyàn ayé ṣe túbọ̀ ń yapa síra wọn? Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Jésù ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nígbà tí rògbòdìyàn òṣèlú gbilẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta yìí: Kí nìdí tí Jésù ò fi dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn tó ń jà fún òmìnira? Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé kò yẹ kí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú? Báwo sì ni Jésù ṣe fi hàn pé a ò gbọ́dọ̀ jà, kódà táwọn èèyàn bá ṣàìdáa sí wa?
ÌDÍ TÍ JÉSÙ Ò FI DÁ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÀWỌN TÓ Ń JÀ FÚN ÒMÌNIRA
3, 4. (a) Nígbà ayé Jésù, kí ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù ń fẹ́? (b) Kí làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù náà rò nípa Mèsáyà?
3 Ọjọ́ pẹ́ táwọn Júù ìgbà ayé Jésù ti ń wá bí wọ́n ṣe máa gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba Róòmù. Àwọn Júù kan tó jẹ́ alákatakítí dá àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara sílẹ̀, wọ́n sì ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n já ara wọn gbà lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù. Ọ̀pọ̀ àwọn alákatakítí yẹn ló di ọmọ ẹ̀yìn ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Júdásì ará Gálílì. Ọ̀gbẹ́ni yìí pe ara ẹ̀ ní mèsáyà, ó sì tan ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Òpìtàn Júù kan tó ń jẹ́ Josephus sọ pé Júdásì yìí “máa ń rọ àwọn Júù pé kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀, ó ní sùẹ̀gbẹ̀ ni wọ́n torí pé wọ́n ń san ìṣákọ́lẹ̀ fáwọn ará Róòmù.” Nígbà tó yá, ọwọ́ ìjọba Róòmù tẹ Júdásì, wọ́n sì pa á. (Ìṣe 5:37) Àwọn alákatakítí kan tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dá wàhálà sílẹ̀ torí kí wọ́n lè gbòmìnira.
4 Yàtọ̀ sáwọn alákatakítí yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ń retí Mèsáyà náà torí wọ́n gbà pé òun ló máa gbà wọ́n sílẹ̀ lábẹ́ àjàgà ìjọba Róòmù, á sì sọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè alágbára. (Lúùkù 2:38; 3:15) Wọ́n rò pé Mèsáyà máa gbé ìjọba kan kalẹ̀ ní Ísírẹ́lì, ìyẹn á sì mú káwọn Júù tó ti fọ́n káàkiri pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jòhánù Oníbatisí bi Jésù pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tí Ń Bọ̀, tàbí kí a máa fojú sọ́nà fún ẹnì kan tí ó yàtọ̀?” (Mát. 11:2, 3) Ó ṣeé ṣe kí Jòhánù fẹ́ mọ̀ bóyá Jésù ló máa gba àwọn Júù sílẹ̀ tàbí ẹlòmíì ṣì ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. Bákan náà lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó pàdé méjì nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú ọ̀nà Ẹ́máọ́sì, àwọn ọmọlẹ́yìn náà rò pé Jésù ni Mèsáyà tó máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù. (Ka Lúùkù 24:21.) Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn làwọn àpọ́sítélì Jésù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba padà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?”—Ìṣe 1:6.
5. (a) Kí nìdí táwọn ará Gálílì fi pinnu láti fi Jésù jọba? (b) Báwo ni Jésù ṣe tún èrò wọn ṣe?
5 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò táwọn Júù ní ló mú káwọn ará Gálílì pinnu láti fi Jésù jọba. Wọ́n rí i pé sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ ni Jésù, ó lè mú àwọn aláìsàn lára dá, ó sì lè bọ́ àwọn tébi ń pa. Kódà ìgbà kan wà tó bọ́ àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000], torí náà wọ́n lè máa ronú pé táwọn bá fi Jésù jọba, ayé àwọn ti dáa nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Jésù, ní mímọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, tún fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí òkè ńlá ní òun nìkan.” (Jòh. 6:10-15) Nígbà tí ara àwọn èèyàn náà balẹ̀ díẹ̀ lọ́jọ́ kejì, Jésù lọ sí òdì kejì Òkun Gálílì, ó sì ṣàlàyé ìdí tóun fi wá sáyé fún wọn. Ó sọ pé kì í ṣe nǹkan tara ni òun wá pèsè fún wọn, bí kò ṣe láti kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó ní: “Ẹ ṣiṣẹ́, kì í ṣe fún oúnjẹ tí ń ṣègbé, bí kò ṣe fún oúnjẹ tí ó wà títí ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 6:25-27.
6. Báwo ni Jésù ṣe mú kó ṣe kedere pé òun ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú ayé yìí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
6 Nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ kí Jésù kú, ó kíyè sí i pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ń retí pé kí òun gbé ìjọba kan kalẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ó wá sọ àkàwé kan nípa mínà kó lè tún èrò wọn ṣe. Nínú àkàwé náà, Jésù fi ara rẹ̀ wé “ọkùnrin kan tí a bí ní ilé ọlá” tó rìnrìn-àjò, tó sì máa pẹ́ kó tó pa dà wálé. (Lúùkù 19:11-13, 15) Jésù tún jẹ́ káwọn aláṣẹ Róòmù mọ̀ pé òun ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ńtíù Pílátù bi Jésù pé: “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù bí?” (Jòh. 18:33) Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba Pílátù pé Jésù lè dá rògbòdìyàn sílẹ̀, kó sì mú káwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Róòmù. Àmọ́ Jésù dá a lóhùn pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòh. 18:36) Jésù ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú rárá torí pé ọ̀run ni Ìjọba rẹ̀ ti máa ṣàkóso. Ó tún sọ fún Pílátù pé torí kóun “lè jẹ́rìí sí òtítọ́” lòun ṣe wá sáyé.—Ka Jòhánù 18:37.
7. Ǹjẹ́ ó yẹ ká ti ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí lẹ́yìn kódà nínú ọkàn wa? Kí nìdí tí èyí ò fi rọrùn?
7 Iṣẹ́ tí Jèhófà rán Jésù ló gbájú mọ́, táwa náà bá gbájú mọ́ iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wa, a ò ní gbè sẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí, kódà a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ọkàn wa. Ká sòótọ́, èyí ò rọrùn. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn lágbègbè wa ló túbọ̀ ń hùwà jàgídíjàgan, ṣe ni wọ́n ń gbé orílẹ̀-èdè wọn lárugẹ, wọ́n sì gbà pé nǹkan máa sàn tó bá jẹ́ pé ẹni tó jẹ́ ẹ̀yà wọn ló ń ṣàkóso. Àmọ́ a dúpẹ́ pé àwọn ará gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ kí wọ́n wà níṣọ̀kan. Wọ́n gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ, kó sì yanjú gbogbo àwọn ìṣòro míì tá à ń kojú.”
JÉSÙ Ò DÁ SÍ ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ TÓ Ń FA AWUYEWUYE LÁGBO ÒṢÈLÚ
8. Ìwà ìrẹ́jẹ wo ló wọ́pọ̀ nígbà ayé Jésù?
8 Ìwà ìrẹ́jẹ ló sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Nígbà ayé Jésù, ọ̀rọ̀ sísan owó orí máa ń dá wàhálà sílẹ̀ lágbo òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, ìjọba Róòmù ní káwọn èèyàn forúkọ sílẹ̀ kí wọ́n lè rí i dájú pé wọ́n ń san owó orí. Èyí ló mú kí Júdásì ará Gálílì tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan làwọn tó wà lábẹ́ àkóso Róòmù ń san owó orí fún nígbà yẹn tó fi mọ́ ẹrù, ilé àti ilẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, oníjẹkújẹ làwọn agbowó orí torí pé owó gegere ni wọ́n ń bù lé àwọn èèyàn. Ìwà wọn burú débi pé ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lówó kí wọ́n lè fi wọ́n sí ipò kan tí wọ́n á ti rówó rẹpẹtẹ. Àpẹẹrẹ kan ni Sákéù tó jẹ́ olórí agbowó orí ní Jẹ́ríkò, owó tó ń fipá gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn ló sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀. (Lúùkù 19:2, 8) Ohun tí ọ̀pọ̀ wọn sì máa ń ṣe nìyẹn.
9, 10. (a) Báwo làwọn ọ̀tá Jésù ṣe wá ọ̀nà láti dẹkùn mú un kó lè dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú? (b) Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Jésù sọ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
9 Àwọn ọ̀tá Jésù ń wá ọ̀nà láti dẹkùn mú un, wọ́n bi í bóyá ó yẹ káwọn Júù máa san “owó orí,” ìyẹn dínárì kan tí ìjọba Róòmù ń béèrè. (Ka Mátíù 22:16-18.) Àwọn Júù kì í fẹ́ san owó orí yìí torí ó máa ń rán wọn létí pé abẹ́ ìjọba Róòmù ni wọ́n wà. Torí náà, nígbà tí “àwọn ọmọlẹ́yìn àjọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù” bi Jésù ní ìbéèrè yìí, wọ́n ronú pé tí Jésù bá sọ pé kò yẹ kí wọ́n máa san owó orí, wọ́n á fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Tí Jésù bá sì sọ pé ó yẹ kí wọ́n máa san án, inú lè bí àwọn tó ń tẹ̀ lé Jésù kí wọ́n sì pa dà lẹ́yìn rẹ̀. Kí ni Jésù wá ṣe?
10 Jésù rí i dájú pé òun ò dá sí ọ̀rọ̀ náà, kò sọ bóyá ó yẹ kí wọ́n san án àbí kò yẹ. Ohun tó sọ ni pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mát. 22:21) Lóòótọ́, Jésù mọ̀ pé oníjẹkújẹ làwọn agbowó orí, síbẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ló ṣe pàtàkì jù sí i, ohun tó sì gbájú mọ́ nìyẹn. Jésù mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé. Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Torí náà, kò yẹ ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú èyíkéyìí kódà tó bá jọ pé ohun tó tọ́ làwọn èèyàn ń jà fún. Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ làwa Kristẹni gbájú mọ́, a kì í sọ̀rọ̀ burúkú nípa ìjọba tàbí ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn ká wa lára ju bó ṣe yẹ lọ.—Mát. 6:33.
11. Ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ?
11 Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti fìgbà kan rí jẹ́ abẹnugan lágbo òṣèlú àmọ́ ní báyìí wọ́n ti jáwọ́. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní Yunifásítì, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àjọṣe ẹ̀dá ìyẹn social studies. Ẹ̀kọ́ yẹn jẹ́ kí n kórìíra àwọn aláwọ̀ funfun torí ìyà tí wọ́n ti fi jẹ àwọn aláwọ̀ dúdú sẹ́yìn. Mo wá pinnu pé màá jà fún ẹ̀tọ́ àwa èèyàn dúdú. Lóòótọ́ tó bá di pé ká jiyàn, èmi ni mo máa ń borí, síbẹ̀ gbogbo nǹkan máa ń tojú sú mi. Mi ò mọ̀ pé ó dìgbà téèyàn bá fa ẹ̀tanú tu lọ́kàn kí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó lè dópin. Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mo wá rí i pé ó yẹ kémi gan-an fa ẹ̀mí burúkú yìí tu lọ́kàn mi. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, arábìnrin kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun ló ràn mí lọ́wọ́ tí mo fi ṣàtúnṣe. Ní báyìí, aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni mí ní ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití, mo sì ń wàásù fún onírúurú èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá sí.”
“DÁ IDÀ RẸ PADÀ SÍ ÀYÈ RẸ̀”
12. “Ìwúkàrà” wo ni Jésù kìlọ̀ fáwọn àpọ́sítélì pé kí wọ́n ṣọ́ra fún?
12 Nígbà ayé Jésù, àwọn tó jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn náà ló jẹ́ abẹnugan lágbo òṣèlú. Ìwé náà Daily Life in Palestine at the Time of Christ sọ pé: “Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín ẹgbẹ́ ìsìn àtàwọn ẹgbẹ́ òṣèlú torí àwọn ẹlẹ́sìn náà ló wà nídìí òṣèlú.” Abájọ tí Jésù fi kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti Hẹ́rọ́dù.” (Máàkù 8:15) Ó jọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn àjọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó mẹ́nu kan ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù. Ẹgbẹ́ kejì ni àwọn Farisí. Àwọn Farisí ń ti àwọn Júù lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń jà fún òmìnira kúrò lábẹ́ ìjọba Róòmù. Nínú ìwé Mátíù, Jésù tún kìlọ̀ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n ṣọ́ra fún àwọn Sadusí. Ìdí ni pé àwọn Sadusí ń ṣagbátẹrù ìjọba Róòmù torí pé wọ́n ń rí jẹ lábẹ́ àkóso wọn. Abájọ tí Jésù fi kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣọ́ra fún ìwúkàrà tàbí ẹ̀kọ́ táwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ń gbé lárugẹ. (Mát. 16:6, 12) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí máa wọ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lọ́kàn torí kò pẹ́ lẹ́yìn táwọn èèyàn fẹ́ fi jọba ló fún wọn ní ìkìlọ̀ yìí.
13, 14. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn èèyàn da ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ òṣèlú nígbà yẹn? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jà kódà tó bá hàn gbangba pé wọ́n rẹ́ wa jẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
13 Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú bó ti wù kó kéré mọ. Torí pé táwọn èèyàn bá da ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ òṣèlú, wàhálà àti ìjà ló sábà máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. Dída ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ òṣèlú wà lára ohun tó mú káwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí máa wọ́nà láti pa Jésù. Àyà wọn ń já bí wọ́n ṣe rí i pé àwọn èèyàn gba ti Jésù, wọ́n ń ronú pé àwọn èèyàn lè sọ ọ́ di olórí kó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbapò mọ́ àwọn lọ́wọ́. Wọ́n sọ pé: “Bí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ lọ́nà yìí, gbogbo wọn yóò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ará Róòmù yóò wá, wọn yóò sì gba àyè wa àti orílẹ̀-èdè wa.” (Jòh. 11:48) Kódà, Káyáfà tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ló ṣètò bí wọ́n ṣe máa pa Jésù.—Jòh. 11:49-53; 18:14.
14 Káyáfà rán àwọn sójà pé kí wọ́n lọ mú Jésù ní òru. Ṣùgbọ́n Jésù mọ gbogbo ètekéte wọn. Nígbà tóun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń jẹun lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó ní kí wọ́n kó idà dání kó lè kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Wọ́n sì kó idà méjì dání. (Lúùkù 22:36-38) Nígbà táwọn tó fẹ́ mú Jésù dé, Pétérù rí i pé òru ni wọ́n fi bojú wá mú un. Èyí múnú bí i débi pé ó fi idà ṣá ọ̀kan lára wọn. (Jòh. 18:10) Àmọ́ Jésù sọ fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mát. 26:52, 53) Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ àtàtà ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé! Ohun tí Jésù sì gbàdúrà fún lálẹ́ ọjọ́ yẹn nìyẹn. (Ka Jòhánù 17:16.) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé a ò gbọ́dọ̀ jà kódà tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, àfi ká fìjà fún Ọlọ́run jà.
15, 16. (a) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran àwọn Kristẹni kan lọ́wọ́? (b) Kí ló ń múnú Jèhófà dùn láìka ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé?
15 Arábìnrin tó ń gbé ní gúúsù ilẹ̀ Yúróòpù tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé “Mo ti wá rí i pé jàgídíjàgan kò lè yanjú ìṣòro kankan. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń jà torí ìwà ìrẹ́jẹ ló máa ń kú sẹ́nu ẹ̀. Ìbànújẹ́ ló sì máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀ fáwọn míì. Inú mi dùn pé mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì wá mọ̀ pé Ọlọ́run nìkan ló lè fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ. Ní báyìí, ó ti lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tí mo ti ń wàásù nípa èyí.” Arákùnrin tó wá láti gúúsù Áfíríkà náà ti kọ́ bó ṣe lè máa lo “idà ẹ̀mí” ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dípò ọ̀kọ̀ tó ń lò tẹ́lẹ̀, ó sì ti ń wàásù ìhìn rere àlàáfíà fáwọn míì láìka ẹ̀yà tí wọ́n ti wá sí. (Éfé. 6:17) Lẹ́yìn tí arábìnrin tó ń gbé ní Yúróòpù di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó fẹ́ arákùnrin kan tó wá láti ẹ̀yà míì tó kórìíra tẹ́lẹ̀. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣàtúnṣe torí pé wọ́n fẹ́ dà bíi Kristi.
16 Irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Bíbélì fi aráyé wé omi òkun tó ń ru gùdù, tí kò sì ní àlàáfíà. (Aísá. 17:12; 57:20, 21; Ìṣí. 13:1) Ọ̀rọ̀ òṣèlú máa ń dá ìjà sílẹ̀, ó máa ń kọ ẹ̀yìn àwọn èèyàn sí ara wọn, wàhálà tó sì máa ń fà kì í tán bọ̀rọ̀, síbẹ̀ àwa èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn àlàáfíà, a sì wà níṣọ̀kan. Ó dájú pé inú Jèhófà á máa dùn bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn rẹ̀ wà níṣọ̀kan láìka ìyapa tó wà nínú ayé.—Ka Sefanáyà 3:17.
17. (a) Àwọn nǹkan mẹ́ta wo la lè ṣe ká lè túbọ̀ wà níṣọ̀kan? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti rí àwọn nǹkan mẹ́ta tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ wà níṣọ̀kan: (1) A gbà pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa yanjú gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ, (2) a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú rárá àti (3) a kì í jà kódà tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ. Àmọ́ nígbà míì, ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lè yọ́ wọnú ìjọ kó sì dá ìyapa sílẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, a sì máa rí ohun tá a lè ṣe ká má bàa fàyè gba ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láàárín wa.