ORÍ KẸTÀLÉLÓGÚN
Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìdáríjì Lọ́dọ̀ Ọ̀gá Rẹ̀
1. Ìgbà wo ló jọ pé ọkàn Pétérù bà jẹ́ jù?
PÉTÉRÙ ò jẹ́ gbàgbé ìgbà tójú òun àti Jésù ṣe mẹ́rin lóru ọjọ́ yẹn. Nígbà tí Jésù wo Pétérù, ṣé Pétérù rí i lójú rẹ̀ pé òun ti já a kulẹ̀ tàbí pé òun ti dójú tì í? A kò lè sọ. Ohun tí Bíbélì kàn sọ ni pé: “Olúwa sì yí padà, ó sì bojú wo Pétérù.” (Lúùkù 22:61) Ṣùgbọ́n wíwò tí Jésù wo Pétérù mú kí Pétérù rí i pé òun ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Ó wá rántí pé ohun tí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ ni òun ṣe yìí, òun sẹ́ Ọ̀gá òun àtàtà. Bẹ́ẹ̀, òun ti lérí pé òun kò ní sẹ́ ẹ láéláé. Ìyẹn ni ìbànújẹ́ fi bá Pétérù. Ọkàn rẹ̀ kò tíì bà jẹ́ tó bẹ́ẹ̀ rí láyé rẹ̀.
2. Ẹ̀kọ́ wo ni Pétérù ní láti kọ́, báwo la sì ṣe lè jàǹfààní nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i?
2 Àmọ́ ṣá o, ó bà ni, kò tíì bà jẹ́. Ìdí ni pé Pétérù nígbàgbọ́ gan-an. Torí náà, àǹfààní ṣì wà fún un láti ṣàtúnṣe, kó sì kọ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù kọ́ni. Ìyẹn ẹ̀kọ́ nípa ìdáríjì. Ó pọn dandan kí gbogbo wa kọ́ ẹ̀kọ́ yìí, nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo bí Pétérù ṣe kọ́ ẹ̀kọ́ náà.
Pétérù Ṣì Ní Ọ̀pọ̀ Ẹ̀kọ́ Láti Kọ́
3, 4. (a) Ìbéèrè wo ni Pétérù bi Jésù, kí ni Pétérù sì lè máa rò? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ìwà àìláàánú àti ẹ̀mí àìní ìdáríjì tó gbòde kan nígbà yẹn ló ran Pétérù?
3 Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà ṣáájú ìgbà yẹn, nígbà tí Pétérù wà ní ìlú Kápánáúmù tó jẹ́ ibùgbé rẹ̀, ó lọ bá Jésù, ó sì bi í pé: “Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mí, tí èmi yóò sì dárí jì í? Títí dé ìgbà méje ni bí?” Pétérù lè máa rò pé òun láàánú bí òun ṣe sọ pé títí dé ìgbà méje. Ó ṣe tán, ohun táwọn aṣáájú ìsìn ń kọ́ni nígbà yẹn ni pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré ni kéèyàn máa dárí jini! Jésù wá dáhùn pé: “Kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.”—Mát. 18:21, 22.
4 Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kí Pétérù máa ka iye ìgbà táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ ẹ́? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tó sọ fún Pétérù pé kó má fi mọ sí ìgbà méje bí kò ṣe ìgbà àádọ́rin lé méje, ohun tó ń sọ ni pé kò sí bí iye ìgbà téèyàn ṣẹ̀ wá ṣe lè pọ̀ tó, ìfẹ́ máa jẹ́ ká dárí jì í. (1 Kọ́r. 13:4, 5) Jésù tipa báyìí jẹ́ kó hàn pé ìwà àìláàánú àti ẹ̀mí àìní ìdáríjì tó gbòde kan nígbà yẹn ló ran Pétérù tó fi sọ bẹ́ẹ̀, ìyẹn bí wọ́n ṣe máa ń ka iye ìgbà tí ẹnì kan ṣẹ̀ wọ́n láti fi mọ̀ bóyá wọ́n á dárí jì í. Ṣe ni àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run máa ń dárí jini láìmọye ìgbà!—Ka 1 Jòhánù 1:7-9.
5. Ìgbà wo ló ṣeé ṣe ká mọyì ìdáríjì jù?
5 Pétérù kò bá Jésù jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ ọ nípa ìdáríjì yìí wọ̀ ọ́ lọ́kàn? Nígbà míì, ìgbà tí àwa fúnra wa bá nílò ìdáríjì lójú méjèèjì la máa ń mọyì ìdáríjì jù. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pa dà wo àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láti alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n mú Jésù títí dé ìgbà tí wọ́n pa á. Ní àsìkò tí kò rọgbọ yẹn, Pétérù ṣẹ Ọ̀gá rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, ó sì ń fẹ́ kó dárí jí òun.
Jésù Dárí Ji Pétérù Lọ́pọ̀ Ìgbà
6. Kí ni Pétérù ṣe nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn àpọ́sítélì ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀, síbẹ̀ ọwọ́ wo ni Jésù fi mú Pétérù?
6 Jésù ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó fẹ́ kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní alẹ́ pàtàkì yẹn, torí ìyẹn ni alẹ́ tó lò kẹ́yìn láyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn. Ara ohun tó fẹ́ kọ́ wọn ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Jésù fi àpẹẹrẹ èyí lélẹ̀ bó ṣe wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ìránṣẹ́ tí ipò rẹ̀ kéré jù ló sì sábà máa ń ṣe iṣẹ́ yìí. Pétérù kọ́kọ́ ta ko ohun tí Jésù fẹ́ ṣe yẹn. Lẹ́yìn náà, kò fẹ́ gbà kí Jésù wẹ ẹsẹ̀ òun. Nígbà tó yá, ó ní ẹsẹ̀ òun nìkan kọ́ ló máa wẹ̀, pé á tún wẹ ọwọ́ àti orí òun pẹ̀lú! Àmọ́ Jésù kò bínú. Ńṣe ló rọra ṣàlàyé ìdí tí òun fi ń ṣe ohun tí òun ń ṣe àti bó ti ṣe pàtàkì tó.—Jòh. 13:1-17.
7, 8. (a) Àwọn ọ̀nà míì wo ni Pétérù tún gbà ṣẹ Jésù? (b) Kí ni Jésù ń ṣe tó fi hàn pé ó ní inúure àti ẹ̀mí ìdáríjì?
7 Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Pétérù tún ṣẹ Jésù. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn àpọ́sítélì ń bára wọn du ẹni tí wọ́n lè kà sí ọ̀gá láàárín ara wọn. Ó sì dájú pé Pétérù náà lọ́wọ́ sí àríyànjiyàn tó tini lójú yẹn. Síbẹ̀, Jésù fi sùúrù tọ́ wọn sọ́nà, ó sì yìn wọ́n nítorí pé wọ́n dúró gbágbáágbá ti òun tó jẹ́ Ọ̀gá wọn. Ó wá sọ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo wọn ṣì máa sá tí wọ́n á fi òun sílẹ̀. Àmọ́, Pétérù tún bá a jiyàn pé òun á dúró tì í gbágbáágbá, àní títí dójú ikú. Jésù wá sọ pé lóru ọjọ́ yẹn gan-an, kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, Pétérù máa sẹ́ òun lẹ́ẹ̀mẹ́ta. Pétérù ta ko Jésù pé òun kò ní sẹ́ ẹ, ó sì tún fọ́nnu pé òun á jẹ́ olóòótọ́ sí i ju àwọn àpọ́sítélì yòókù lọ!—Mát. 26:31-35; Máàkù 14:27-31; Lúùkù 22:24-28; Jòh. 13:36-38.
8 Ǹjẹ́ Jésù wá bínú sí Pétérù? Ó tì o. Kódà, ní gbogbo àkókò tí kò rọgbọ yẹn, ibi tí àwọn àpọ́sítélì aláìpé yìí dáa sí ni Jésù ń wò. Ó mọ̀ pé Pétérù máa ṣẹ òun, síbẹ̀ ó sọ pé: “Èmi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí rẹ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa yẹ̀; àti ìwọ, ní gbàrà tí o bá ti padà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.” (Lúùkù 22:32) Jésù tipa báyìí fi hàn pé òun mọ̀ dájú pé Pétérù máa borí àṣìṣe rẹ̀, á sì máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó láì yẹsẹ̀. Ẹ ò rí i pé inúure àti ẹ̀mí ìdáríjì rẹ̀ pọ̀ jọjọ!
9, 10. (a) Kí nìdí tí ìbáwí fi tọ́ sí Pétérù nínú ọgbà Gẹtisémánì? (b) Kí ni àwọn àṣìṣe Pétérù ń rán wa létí rẹ̀?
9 Lẹ́yìn náà, nínú ọgbà Gẹtisémánì, ó ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ tí Jésù ní láti bá Pétérù wí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Jésù sọ fún Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù pé kí wọ́n máa ṣọ́nà nígbà tó lọ gbàdúrà. Ẹ̀dùn ọkàn bá Jésù, ó sì nílò olùtùnú, àmọ́ Pétérù àtàwọn yòókù ń tòògbé, wọ́n sì ń sùn ṣáá. Jésù fi hàn pé òun mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, òun sì ti dárí jì wọ́n. Ìyẹn ló fi sọ pé: “Ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”—Máàkù 14:32-41.
10 Láìpẹ́, àwọn jàǹdùkú dé, tàwọn ti ètùfù, idà àti kóńdó. Lákòókò yẹn, ọ̀rọ̀ náà gba ọgbọ́n àti ìṣọ́ra. Síbẹ̀, Pétérù fi ìwàǹwára yọ idà sí Málíkọ́sì, ẹrú olórí àlùfáà, ó sì gé ọ̀kan lára etí rẹ̀ dà nù. Jésù rọra bá Pétérù wí, ó wo ọgbẹ́ Málíkọ́sì sàn, ó sì ṣàlàyé pé ìwà ipá lòdì. Ohun tó sọ yìí ni ìlànà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé títí dòní. (Mát. 26:47-55; Lúùkù 22:47-51; Jòh. 18:10, 11) Pétérù ti wá ṣẹ Jésù Ọ̀gá rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà wàyí, àmọ́ ó ń dárí jì í. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí rán wa létí pé gbogbo wa la máa ń ṣẹ̀ látìgbàdégbà. (Ka Jákọ́bù 3:2.) Àbí, èwo nínú wa ni kì í nílò ìdáríjì Ọlọ́run lójoojúmọ́? Àmọ́ o, Pétérù ṣì tún dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú ju gbogbo ìwọ̀nyí lọ lóru ọjọ́ yẹn.
Ẹ̀ṣẹ̀ Pétérù Tó Burú Jù
11, 12. (a) Kí ni Pétérù ṣe lẹ́yìn tí wọ́n mú Jésù tó fi hàn pé kì í ṣe ojo? (b) Kí ló fi hàn pé Pétérù kò tíì ṣe ohun tó sọ pé òun máa ṣe?
11 Jésù wá bá àwọn jàǹdùkú náà sọ̀rọ̀ pé tó bá jẹ́ pé òun ni wọ́n ń wá kí wọ́n jẹ́ kí àwọn àpọ́sítélì òun máa lọ. Ńṣe ni Pétérù kàn ń wò, láìlè ṣe nǹkan kan nígbà tí àwọn jàǹdùkú náà ń de Jésù. Lẹ́yìn náà, Pétérù wá sá lọ bíi tàwọn àpọ́sítélì yòókù.
12 Nígbà tó yá, Pétérù àti Jòhánù dúró, wọn kò sá mọ́. Ó ṣeé ṣe kí ibi tí wọ́n ti dúró jẹ́ ìtòsí ilé Àlùfáà Àgbà tẹ́lẹ̀ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ánásì, níbi tí wọ́n kọ́kọ́ mú Jésù lọ láti gbọ́ tẹnu rẹ̀. Bí wọ́n ṣe mú Jésù kúrò níbẹ̀, Pétérù àti Jòhánù ń tẹ̀ lé wọn àmọ́ “ní òkèèrè réré.” (Mát. 26:58; Jòh. 18:12, 13) Pétérù kì í ṣe ojo rárá. Torí pé ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè tẹ̀ lé irú wọn. Ohun ìjà ń bẹ lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú yẹn, Pétérù sì ti ṣe ọ̀kan lára wọn léṣe tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n o, bó ṣe ń yọ́ tẹ̀ lé wọn yìí kò tíì fi hàn pé ó ní ẹ̀mí ìdúróṣinṣin tó sọ pé òun ní, ìyẹn bó ṣe lérí pé òun àti Ọ̀gá òun jọ máa kú pa pọ̀ ni bí ọ̀rọ̀ bá gbà bẹ́ẹ̀.—Máàkù 14:31.
13. Kí ni ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà tẹ̀ lé Kristi bó ṣe yẹ?
13 Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ máa tẹ̀ lé Kristi “ní òkèèrè réré” bíi ti Pétérù, kí àwọn èèyàn má bàa rí wọn. Ṣùgbọ́n Pétérù fúnra rẹ̀ kọ̀wé nígbà tó yá pé, ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà tẹ̀ lé Kristi bó ṣe yẹ ni pé ká máa tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí, ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ohun gbogbo, láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí.—Ka 1 Pétérù 2:21.
14. Ibo ni Pétérù wà nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ Jésù lóru yẹn?
14 Níkẹyìn, Pétérù yọ́ tẹ̀ lé wọn dé ẹnubodè ọ̀kan lára ilé tó tóbi jù ní Jerúsálẹ́mù. Ilé Káyáfà, àlùfáà àgbà tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ àti alágbára ni. Àgbàlá sábà máa ń wà láàárín irú ilé bẹ́ẹ̀, ó sì máa ń ní ẹnubodè níwájú. Nígbà tí Pétérù dé ẹnubodè náà wọn kò jẹ́ kó wọlé. Jòhánù tó ti wọlé tẹ́lẹ̀ torí pé ó jẹ́ ẹni mímọ̀ àlùfáà àgbà, sì jáde wá bá aṣọ́bodè náà pé kó jẹ́ kí Pétérù wọlé. Ó jọ pé Pétérù kò dúró ti Jòhánù, kò sì gbìyànjú láti wọnú ilé lọ kó lè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọ̀gá rẹ̀. Ṣe ló dúró sí àgbàlá níbi tí díẹ̀ lára àwọn ẹrú àtàwọn ìránṣẹ́ dúró sí, nídìí iná tó mọ́lẹ̀, tí wọ́n ń yáná nínú òtútù lóru yẹn. Ó ń wo bí àwọn tó ń jẹ́rìí èké lòdì sí Jésù ṣe ń wọlé lọ síbi ìgbẹ́jọ́ náà, tí wọ́n sì ń jáde.—Máàkù 14:54-57; Jòh. 18:15, 16, 18.
15, 16. Ṣàlàyé bí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù pé Pétérù máa sẹ́ òun lẹ́ẹ̀mẹta ṣe ní ìmúṣẹ.
15 Ìmọ́lẹ̀ iná yẹn jẹ́ kí ọmọbìnrin tó ṣí ìlẹ̀kùn fún Pétérù ní ẹnubodè wá rí Pétérù dáadáa. Ó sì dá a mọ̀. Ló bá fẹ̀sùn kàn án pé: “Ìwọ, náà, wà pẹ̀lú Jésù ará Gálílì!” Ọ̀ràn náà bá Pétérù lábo, ló bá sẹ́ pé òun kò mọ Jésù, pé òun kò tiẹ̀ mọ ohun tí ọmọbìnrin náà ń sọ rárá. Ó wá lọ dúró sí ìtòsí ẹnubodè náà, ó ń fojú pa mọ́. Àmọ́ ọmọbìnrin míì rí i, ó sì tún sọ irú ohun kan náà, pé: “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ará Násárétì.” Pétérù wá búra, ó ní: “Èmi kò mọ ọkùnrin náà!” (Mát. 26:69-72; Máàkù 14:66-68) Bóyá ẹ̀yìn tí Pétérù sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì yìí ló gbọ́ tí àkùkọ kọ, àmọ́ àwọn nǹkan tó gbà á lọ́kàn kò jẹ́ kó rántí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù ti sọ ṣáájú lọ́jọ́ yẹn.
16 Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, bí Pétérù ṣì ṣe ń dá gbogbo ọgbọ́n kí wọ́n má bàa dá a mọ̀, àwọn kan tí wọ́n dúró nínú àgbàlá náà sún mọ́ ọn. Ọkùnrin kan lára wọn jẹ́ ìbátan Málíkọ́sì, ẹrú tí Pétérù ṣe léṣe. Ó sọ fún Pétérù pé: “Mo rí ọ nínú ọgbà pẹ̀lú rẹ̀, àbí èmi kò rí ọ?” Pétérù fẹ́ fi yé wọn pé irọ́ ni wọ́n ń pa mọ́ òun, ló bá búra, bóyá ó sọ pé kí èpè ja òun tó bá jẹ́ pé irọ́ lòun pa. Ìyẹn jẹ́ ìgbà kẹta tí Pétérù sẹ́. Kò pẹ́ tó sọ̀rọ̀ tán ni àkùkọ kọ, ìyẹn sì ni ẹ̀ẹ̀kejì tí Pétérù gbọ́ tí àkùkọ kọ lóru ọjọ́ yẹn.—Jòh. 18:26, 27; Máàkù 14:71, 72.
17, 18. (a) Kí ni Pétérù ṣe nígbà tó rí i pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lòun ṣẹ̀ sí Ọ̀gá òun? (b) Kí ni Pétérù lè máa rò nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?
17 Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde wá sí ọ̀dẹ̀dẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì tó dojú kọ àgbàlá náà ni. Ìgbà yẹn ni ojú òun àti Pétérù ṣe mẹ́rin bí a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ orí tí a wà yìí. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Pétérù sì rí i pé ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lòun ṣẹ̀ sí Ọ̀gá òun yìí. Ìbànújẹ́ ńlá wá bá a, ló bá jáde ní àgbàlá náà. Ó sì kọrí sí ìgboro, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ òṣùpá àrànmọ́jú tó ti ń pajú dé rìn lọ. Omijé kún ojú rẹ̀ bó ṣe ń lọ. Ó wá bú sẹ́kún, ó sì sunkún kíkorò.—Máàkù 14:72; Lúùkù 22:61, 62.
18 Téèyàn bá ti ṣẹ̀ ní irú ọ̀nà yìí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé ẹ̀ṣẹ̀ òun ti burú kọjá ìdáríjì. Pétérù náà lè rò bẹ́ẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣé yóò wá rí ìdáríjì gbà?
Ǹjẹ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Pétérù Kọjá Ìdáríjì?
19. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ Pétérù ṣe máa rí lára rẹ̀, ṣùgbọ́n báwo la ṣe mọ̀ pé kò sọ̀rètí nù?
19 Ó ṣòro láti mọ bí ìrora Pétérù ṣe pọ̀ tó nígbà tí ilẹ̀ mọ́ lọ́jọ́ yẹn, tó wá ń rí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí Jésù. Ẹ wo bó ṣe máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi tó nígbà tí Jésù kú lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí tó ti ń jẹ̀rora! Ìbànújẹ́ á máa bá Pétérù tó bá tún ronú kan bí òun ṣe dá kún ìrora Ọ̀gá òun lọ́jọ́ tó gbé ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn kẹ́yìn. Ṣùgbọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Pétérù bà jẹ́ kọjá àfẹnusọ, kò sọ̀rètí nù. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé kíá ló pa dà dára pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù. (Lúùkù 24:33) Ó dájú pé gbogbo àwọn àpọ́sítélì ló máa kábàámọ̀ ìwà tí wọ́n hù lálẹ́ ọjọ́ tí nǹkan kò rọgbọ yẹn, àmọ́ wọ́n tu ara wọn nínú dé ìwọ̀n àyè kan.
20. Kí la rí kọ́ lára Pétérù ní ọ̀kan lára àwọn ìgbà tó ṣe ohun tó dára gan-an?
20 Tá a bá wò ó dáadáa, èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbà tí Pétérù ṣe ohun tó dára gan-an. Bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan bá ṣubú, kì í ṣe bí ìṣubú rẹ̀ ṣe pọ̀ tó ló jà jù, bí kò ṣe bó ṣe ń sapá tó láti dìde pa dà, ìyẹn ni pé kó ṣàtúnṣe kí àárín òun àti Ọlọ́run lè pa dà gún. (Ka Òwe 24:16.) Pétérù fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ bó ṣe lọ bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an. Tí ìbànújẹ́ bá báni tàbí téèyàn ń kábàámọ̀ ohun kan, ó lè ṣe é bíi kó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, àmọ́ ìyẹn léwu gan-an. (Òwe 18:1) Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn má jìnnà sí àwọn ará kó bàa lè pa dà bọ̀ sípò, kó sì máa bá ìjọsìn rẹ̀ nìṣó.—Héb. 10:24, 25.
21. Ìròyìn wo ni Pétérù gbọ́ nítorí pé ó wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù?
21 Torí pé Pétérù wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù, ó gbọ́ ìròyìn tó ṣeni ní kàyéfì náà pé òkú Jésù kò sí nínú ibojì mọ́. Ni Pétérù àti Jòhánù bá sáré lọ wo ibojì Jésù tí wọ́n ti ẹnu ọ̀nà rẹ̀ pa yìí. Jòhánù tó ṣeé ṣe kó kéré sí Pétérù lọ́jọ́ orí ló kọ́kọ́ débẹ̀. Bó ṣe rí ẹnu ọ̀nà ibojì náà ni ṣíṣí sílẹ̀, ó dúró kò wọlé. Àmọ́ nígbà tí Pétérù dé, ńṣe ló kàn já wọ ibojì náà pẹ̀lú bó ṣe ń mí hẹlẹhẹlẹ. Ó wá bá ibẹ̀ lófo!—Jòh. 20:3-9.
22. Kí ló jẹ́ kí gbogbo ìbànújẹ́ ọkàn Pétérù àti iyè méjì rẹ̀ fò lọ?
22 Ǹjẹ́ Pétérù gbà pé Jésù ti jíǹde? Kò kọ́kọ́ gbà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin olóòótọ́ ti ròyìn fún un pé àwọn áńgẹ́lì fara han àwọn láti kéde pé Jésù ti jíǹde. (Lúùkù 23:55–24:11) Àmọ́ nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà fi máa ṣú, gbogbo ìbànújẹ́ ọkàn Pétérù àti iyè méjì rẹ̀ ti fò lọ. Ìdí ni pé Jésù ti jíǹde, àmọ́ ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni báyìí! Ó fara han gbogbo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Àmọ́ kí Jésù tó fara hàn wọ́n, ó ti kọ́kọ́ fara han Pétérù nígbà tó dá wà. Lọ́jọ́ yẹn, àwọn àpọ́sítélì sọ pé: “Ní ti tòótọ́ ni a gbé Olúwa dìde, ó sì fara han Símónì!” (Lúùkù 24:34) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ọjọ́ àrà ọ̀tọ̀ yẹn nígbà tó yá, ó ní Jésù “fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà.” (1 Kọ́r. 15:5) Kéfà àti Símónì jẹ́ ara orúkọ Pétérù. Jésù fara hàn Pétérù lọ́jọ́ yẹn, ẹ̀rí sì fi hàn pé ìgbà tí Pétérù dá wà ló fara hàn án.
Pétérù ṣẹ Jésù Ọ̀gá rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ó sì ń dárí jì í. Èwo nínú wa ni kì í nílò ìdáríjì lójoojúmọ́?
23. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn Kristẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lóde òní máa rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn ti Pétérù?
23 Bíbélì kò sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jésù àti Pétérù nígbà aláyọ̀ tí wọ́n pa dà ríra. Àárín àwọn méjèèjì nìyẹn wà. Àmọ́ a lè fojú inú wo bí inú Pétérù á ṣe dùn tó pé ó tún rí Olúwa rẹ̀ ọ̀wọ́n láàyè, àti pé ó láǹfààní láti jẹ́ kí Jésù mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ tóun ṣẹ̀ ṣe dun òun tó, tó sì tọrọ àforíjì. Ohun tó jẹ Pétérù lógún jù ni pé kí Jésù dárí ji òun. Ó sì dájú pé Jésù dárí ji Pétérù pátápátá. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni tó dẹ́ṣẹ̀ lóde òní náà máa rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn ti Pétérù. Ká má ṣe rò pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti kọjá èyí tí Ọlọ́run fi máa dárí jì wá o. Torí ṣe ni Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀, tó jẹ́ pé ó máa ń “dárí jini lọ́nà títóbi.”—Aísá. 55:7.
Ẹ̀rí Míì Tó Fi Hàn Pé Jésù Darí Ji Pétérù Lóòótọ́
24, 25. (a) Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pétérù lọ pa ẹja ní Òkun Gálílì lóru. (b) Kí ni Pétérù ṣe nígbà tí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu fún wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì?
24 Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n lọ sí Gálílì, níbi tí wọ́n á ti pàdé òun. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Pétérù sọ pé òun fẹ́ lọ pẹja ní Òkun Gálílì. Àwọn míì lára wọn náà bá a lọ. Ni Pétérù bá tún gbé ọkọ̀ ojú omi, ó dorí agbami níbi tó ti ń pẹja tẹ́lẹ̀ kó tó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bí ọkọ̀ yìí ṣe ń rọ́ kẹ̀kẹ̀ lọ lórí omi, bí ìgbì omi ṣe ń bì lu ọkọ̀ náà àti bí àwọ̀n náà ṣe rí lọ́wọ́ rẹ̀ mú kí ara tù ú kó sì tún rántí àwọn ìgbà ìṣáájú. Àmọ́ wọn kò rí ẹja pa ní gbogbo òru.—Mát. 26:32; Jòh. 21:1-3.
25 Nígbà tó di àfẹ̀mọ́jú, ẹnì kan pè wọ́n láti etíkun, ó ní kí wọ́n ju àwọ̀n wọn sí ẹ̀gbẹ́ kejì ọkọ̀ náà. Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì fa àwọ̀n wọn sínú ọkọ̀, ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja tí iye rẹ̀ jẹ́ àádọ́jọ lé mẹ́ta [153]! Pétérù ti mọ ẹni náà. Ó wá bẹ́ sínú omi láti inú ọkọ̀, ó sì wẹ̀ lọ sí etíkun. Jésù tó ti wà ní etíkun sì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ yìí lóúnjẹ, ìyẹn ẹja tó yan lórí ẹyín iná. Ó wá yíjú sí Pétérù.—Jòh. 21:4-14.
26, 27. (a) Àǹfààní wo ni Jésù fún Pétérù lẹ́ẹ̀mẹ́ta? (b) Kí ni Jésù fi ṣe ẹ̀rí fún Pétérù pé òun ti dárí jì í pátápátá?
26 Jésù bi Pétérù bóyá ó nífẹ̀ẹ́ Olúwa rẹ̀ “ju ìwọ̀nyí lọ,” bóyá tó nawọ́ sí ẹja rẹpẹtẹ tí wọ́n pa. Ìyẹn ni pé, ṣé Pétérù máa jẹ́ kí bó ṣe fẹ́ràn iṣẹ́ ẹja pípa ju bó ṣe fẹ́ràn Jésù lọ lọ́kàn rẹ̀? Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni Pétérù sẹ́ Olúwa rẹ̀, torí náà, Jésù fún un láǹfààní lẹ́ẹ̀mẹ́ta láti fi hàn níwájú àwọn àpọ́sítélì tó wà níbẹ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ òun. Bí Pétérù sì ṣe ń dá Jésù lóhùn ni Jésù ń sọ bó ṣe máa fi ìfẹ́ yẹn hàn, ìyẹn ni pé kó fi iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ṣááju gbogbo nǹkan yòókù láyé yìí, kó máa bọ́ agbo àgùntàn Kristi, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́. Kó máa fún wọn lókun, kó sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn.—Lúùkù 22:32; Jòh. 21:15-17.
27 Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí Pétérù mọ̀ pé ó ṣì wúlò fún òun àti Baba òun. Ìyẹn ni pé Pétérù yóò kó ipa pàtàkì nínú ìjọ lábẹ́ ìdarí Kristi. Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí tó lágbára nìyẹn jẹ́ fún Pétérù pé Jésù ti dárí jì í pátápátá! Ó dájú pé Pétérù mọyì àánú tí Jésù fi hàn sí i, ó sì kọ́gbọ́n nínú àṣìṣe rẹ̀.
28. Ọ̀nà wo ni orúkọ gbà ro Pétérù?
28 Pétérù ń fi ìṣòtítọ́ bá iṣẹ́ tí Jésù gbé lé e lọ́wọ́ nìṣó fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó ń fún àwọn arákùnrin rẹ lókun bí Jésù ṣe pàṣẹ fún un lálẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa á. Ó ń fi àánú àti sùúrù ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, ó sì ń bọ́ wọn. Orúkọ tí Jésù fún Símónì rò ó, ìyẹn Pétérù tàbí Àpáta, nítorí ó di ẹni tó dúró digbí, tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in, tó sì nípa rere lórí àwọn tó wà nínú ìjọ. A rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi èyí hàn nínú lẹ́tà méjì tó wúni lórí tí Pétérù dìídì kọ sí olúkúlùkù Kristẹni, tó wá di ara àwọn ìwé iyebíye inú Bíbélì. Àwọn ìwé tó kọ yẹn sì fi hàn pé kò gbàgbé ẹ̀kọ́ tó kọ́ lọ́dọ̀ Jésù nípa ìdáríjì.—Ka 1 Pétérù 3:8, 9; 4:8.
29. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Pétérù àti àánú Jésù Ọ̀gá rẹ̀?
29 Ẹ jẹ́ kí àwa náà kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì yẹn. Ǹjẹ́ a máa ń tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa? Ǹjẹ́ a máa ń gbà lóòótọ́ pé ó ti dárí jì wá, àti pé ìdáríjì yẹn ń mú ká dẹni tó mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa? Ṣé àwa náà sì ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé a ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Pétérù àti àánú Jésù Ọ̀gá rẹ̀.