-
Ta Ni Pọ́ńtíù Pílátù?Ilé Ìṣọ́—2005 | September 15
-
-
Pílátù lè fẹ́ ṣe ohun tó tọ́ o, àmọ́ ó ń du orí ara rẹ̀ ó sì tún fẹ́ ṣe ohun tó dùn mọ́ àwọn èèyàn náà. Níkẹyìn, torí pé kò fẹ́ kúrò nípò tó wà, ó ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ àti ìdájọ́ òdodo. Ó ní kí wọ́n bu omi wá, ó sì ṣan ọwọ́ rẹ̀, ó ní ọwọ́ òun mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ ikú Jésù, ìyẹn lẹ́yìn tó ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa á.a Pílátù mọ̀ pé Jésù ò jẹ̀bi, síbẹ̀ ó ní kí wọ́n fi bílálà oníkókó nà án, ó sì tún gbà káwọn ọmọ ogun fi í ṣẹlẹ́yà, kí wọ́n lù ú, kí wọ́n sì tutọ́ sí i lára.—Mátíù 27:24-31.
-
-
Ta Ni Pọ́ńtíù Pílátù?Ilé Ìṣọ́—2005 | September 15
-
-
a Àwọn Júù ló sábà máa ń ṣanwọ́ láti fi hàn pé ọwọ́ àwọn mọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ ẹni tí àwọn kan pa, kì í ṣe àṣà àwọn ará Róòmù rárá.—Diutarónómì 21:6, 7.
-