Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu
Ijẹrora Lori Òpó-igi
AWỌN ọlọṣa meji ni a dari jade lọ lati fiya iku jẹ wọn papọ pẹlu Jesu. Nibi ti ko jinna si ilu naa, itolọwọọwọ naa dẹsẹ duro ni ibikan ti a npe ni Golgotha, tabi Ibi Agbárí.
Awọn ẹlẹwọn naa ni a bọ́ laṣọ. Lẹhin naa ni a pese waini ti a po pẹlu òjíá. O jọ pe a ṣe e lati ọwọ awọn obinrin Jerusalẹmu, awọn ara Romu naa ko si ṣai yọnda àpòpọ̀ aparora yii fun awọn wọnni ti a ńkàn mọ́gi. Bi o ti wu ki o ri, nigbati Jesu tọ́ ọ wo, oun kọ̀ lati mú un. Eeṣe? Lọna ti o han gbangba oun fẹ lati ṣakoso gbogbo agbara ero ori rẹ lẹkun-unrẹrẹ nigba idanwo igbagbọ rẹ gigajulọ yii.
Jesu ni a nà sori opó igi nisinsinyi ti a si ka awọn ọwọ rẹ sókè ori rẹ. Lẹhin naa awọn ọmo-ogun kàn ìṣó titobi wọ inu awọn ọwọ ati ẹsẹ rẹ. Oun jà pẹlu irora gẹgẹbi awọn ìṣó naa ti gun ẹran ati iṣan wọnu. Nigbati a gbe opo igi naa nàró, irora naa burujai, nitori ọ̀rìn ara fa oju ọgbẹ́ ìṣó naa ya. Sibẹ, dipo hihalẹ, Jesu gbadura fun awọn ọmọ ogun Romu naa: “Baba, dari ji wọn; nitoriti wọn ko mọ ohun ti wọn nṣe.”
Pilatu mu ki a kàn àmì kan sara opó igi ti o ka pe: “Jesu ti Nasarẹti Ọba awọn Júù.” O jọ pe, oun kọ eyi kiiṣe kiki nitori pe oun bọwọ fun Jesu nikan ni ṣugbọn nitoripe oun korira awọn alufaa Júù fun fifipa gba idajọ iku Jesu lọwọ rẹ. Ki gbogbo eniyan ba le ka ami naa, Pilatu kọ ọ ni ede mẹta—ni Heberu, ni Latin ti a fi aṣẹ yàn, ati ni Giriiki ti o wọpọ.
Awọn olori alufa, papọ pẹlu Kaifa ati Anasi, ni a múrẹ̀wẹ̀sì. Ipokiki olojurere pato yii ba wakati ayọ iṣẹgun wọn jẹ. Nitori naa wọn ṣatako: “Maṣe kọ ọ́ pe Ọba awọn Júù; ṣugbọn pe oun wipe, emi ni Ọba awọn Júù.” Ni fifi ibinu han fun ṣiṣiṣẹ gẹgẹbi ẹni ti a lo lati mu ete awọn alufaa ṣẹ, Pilatu dahun pada pẹlu ọ̀rọ̀ àìkanisí ti o fidimulẹgbọnyin: “Ohun ti mo ti kọ tan, mo ti kọ ọ na.”
Awọn alufaa, papọ pẹlu ọpọlọpọ ero, korajọ si ọgangan ibi ifiya iku jẹni naa, awọn alufaa si gbiyanju lati tako gbolohun ẹ̀rí àmì naa. Wọn ṣatunsọ ẹri eke ti wọn sọ ni iṣaaju nibi ìgbẹ́jọ́ Sanhendrin. Nitori naa ko yanilẹnu pe awọn olurekọjalọ bẹrẹ sii sọ ọrọ eebu, ti wọn nmi ori wọn ni ṣiṣẹlẹya wipe: “Óò iwọ ti yoo di oluwo tẹmpili palẹ ti yoo si kọ́ ọ ni ọjọ mẹta, gba ara rẹ la! Bi iwọ ba jẹ ọmọkunrin Ọlọrun, sọkalẹ kuro lori opo-igi idaloro!”
“Awọn miiran ni oun gbala; oun ko le gba araarẹ la!” Awọn olori alufa ati awọn ọrẹ timọtimọ wọn onisin jalu ọrọ naa. “Ọba Israẹli ni oun; ẹ jẹ ki o sọkalẹ kuro lori opo-igi idaloro nisinsinyi awa yoo si ni igbagbọ ninu rẹ. Oun ti fi igbẹkẹle rẹ̀ sinu Ọlọrun; ẹ jẹ ki O gbà á silẹ nisinsinyi bi Oun ba fẹ ẹ, nitori oun wipe, ‘Ọmọkunrin Ọlọrun ni emi.’”
Bi ẹmi naa ti ràn wọn, awọn ọmọ-ogun naa darapọ ninu fifi Jesu ṣe yẹyẹ. Wọn pese ọtí kíkan fun un lọna ifiniṣẹlẹya, ti o jọ pe wọn gbe e soke rekọja awọn ètè rẹ ti o ti gbẹ. Wọn ṣáátá pe, “Bi iwọ ba jẹ ọba awọn Júù, gba ara rẹ la.” Ani awọn ọlọṣa paapaa—ọkan ti a kan mọgi sapa ọtun Jesu ati ekeji si apa osi—pẹgan rẹ. Rò ó wò na! Ẹni titobijulọ ti o tíì gbe laye ri, bẹẹni, ẹni ti o ṣajọpin pẹlu Jehofa Ọlọrun ninu dida ohun gbogbo, jiya gbogbo eebu yii pẹlu iṣotitọ!
Awọn ọmọ-ogun mu awọn ẹwu awọleke Jesu wọn si pin si apa mẹrin. Wọn ṣẹ́ kèké lati mọ ti tani awọn wọnyi yoo jẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹwu awọtẹlẹ rẹ ko ni oju rírán, ni jijẹ ojulowo didaraju. Nitori naa awọn ọmọ-ogun wi fun ara wọn pe: “Ẹ maṣe jẹ ki a fa a ya, ṣugbọn ki a ṣẹ́ kèké nitori rẹ ti ẹni ti yoo jẹ.” Nipa bayi, laimọọmọ, wọn mu iwe mimọ ṣẹ ti o wipe: “Wọn pin aṣọ mi laaarin ara wọn, wọn si ṣẹ́ kèké le aṣọ ileke mi.”
Laipẹ ọkan lara awọn ọlọṣa wa mọriri pe Jesu nitootọ gbọdọ jẹ ọba kan. Nitorinaa, ni bíbá ẹlẹgbẹ rẹ wi, oun wipe: “Iwọ ko bẹru Ọlọrun, ti iwọ wa ninu ẹbi kannaa? Niti wa, wọn jare nitori ere ohun ti awa ṣe ni awa njẹ: ṣugbọn ọkunrin yi ko ṣe ohun buburu kan.” Lẹhin naa oun sọrọ si Jesu ni taarata, ni bibẹbẹ pe: “Ranti mi nigbati iwọ ba de ijọba rẹ.”
Jesu fesi pada, ‘Loootọ ni mo wi fun ọ lonii, iwọ yoo wa pẹlu mi ni Paradise.’ Ileri yii ni a o muṣẹ nigbati Jesu ba nṣakoso gẹgẹbi Ọba ni ọrun ti o si ji oluṣebuburu aronúpìwàdà yii dide si iye lori ilẹ-aye ninu Paradise ti awọn olùla Armageddon ja ati awọn alabaakẹgbẹ wọn yoo ni anfaani lati mú gbilẹ̀. Matiu 27:33-44, New World Translation; Maaku 15:22-32; Luku 23:27, 32-43; Johanu 19:17-24.
◆ Eeṣe ti Jesu fi kọ̀ lati mu waini ti a po pẹlu òjíá?
◆ Kinni o jọ pe o jẹ idi ti a fi gbe àmì sori opo igi Jesu, ifọrọwerọ siwaju sii wo ni eyi si tun muwa laaarin Pilatu ati awọn olori alufaa?
◆ Eebu siwaju si wo ni Jesu gba lori opo igi, kinni o si fa a lọna hihan gbangba?
◆ Bawo ni asọtẹlẹ ṣe ni imuṣẹ nipa ohun ti a ṣe pẹlu awọn ẹwu Jesu?
◆ Iyipada wo ni ọkan lara awọn ọlọṣa naa ṣe, bawo si ni Jesu yoo ṣe mu ibeere rẹ̀ ṣẹ?