Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Mèsáyà
TIPẸ́TIPẸ́ ṣáájú kí Mèsáyà tó dé làwọn Júù ti ń retí ẹ̀, ohun tó sì fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ti mọ ohun tí Aísáyà àtàwọn wòlíì míì sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Kódà nígbà tí Jésù fi máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ti “ń fojú sọ́nà” fún Mèsáyà tí wọ́n gbà pé ó máa tó fara hàn. (Lúùkù 3:15) Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó jọni lójú nípa ìgbésí ayé Mèsáyà wà lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Kò séèyàn kankan tó lè sọ tẹ́lẹ̀ nípa irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí tó lè mú káwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jésù wáyé.
Nípa Ìbí Mèsáyà. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wúńdíá lẹni tó máa bí Mèsáyà, ìyẹn Kristi náà. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Mátíù ṣàlàyé ọ̀nà ìyanu tí wọ́n gbà bí Jésù tán, ó fi kún un pé: “Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, kí a lè mú èyíinì tí Jèhófà sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ ṣẹ, pé: ‘Wò ó! Wúńdíá náà yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan.’” (Mátíù 1:22, 23; Aísáyà 7:14) Aísáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àtọmọdọ́mọ Dáfídì ni Kristi máa jẹ́, kódà ó dárúkọ Jésè bàbá Dáfídì. Bó sì ṣe sọ gẹ́lẹ́, ìlà ìdílé Dáfídì ní tààràtà ni wọ́n ti bí Jésù. (Mátíù 1:6, 16; Lúùkù 3:23, 31, 32) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kí Màríà tó bí Jésù, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé: “Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un.”—Lúùkù 1:32, 33; Aísáyà 11:1-5, 10; Róòmù 15:12.
Nípa Ìgbésí Ayé Mèsáyà. Nígbà tí Jésù dàgbà, ó wá sí sínágọ́gù tó wà ní ìlú Násárétì, ó ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sókè ketekete, ohun tó kà níbẹ̀ rèé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.” Láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa òun ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń sọ, Jésù sọ fún wọn pé: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ.” (Lúùkù 4:17-21; Aísáyà 61:1, 2) Aísáyà tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Jésù ṣe máa ṣe àwọn tó nílò ìwòsàn pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tí kò sì ní máa gbé ara rẹ̀ ga. Mátíù kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tẹ̀ lé e pẹ̀lú, ó sì wo gbogbo wọn sàn, ṣùgbọ́n ó fi àìyẹhùn pàṣẹ fún wọn láti má ṣe fi òun hàn kedere; kí a bàa lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì ṣẹ . . . ‘Kì yóò ṣàríyànjiyàn aláriwo, tàbí kí ó ké sókè . . . Kò sí esùsú kankan tí a ti pa lára tí yóò tẹ̀ fọ́.’”—Mátíù 8:16, 17; 12:10-21; Aísáyà 42:1-4; 53:4, 5.
Nípa Bí Mèsáyà Ṣe Máa Jìyà. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní gba Mèsáyà gbọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni Mèsáyà máa di “òkúta ìkọ̀sẹ̀” fún wọn. (1 Pétérù 2:6-8; Aísáyà 8:14, 15) Lóòótọ́, pẹ̀lú adúrú iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, àwọn èèyàn wọ̀nyẹn “kì í ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ Aísáyà wòlíì fi ṣẹ tí ó wí pé: ‘Jèhófà, ta ni ó ti lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí a gbọ́?’” (Jòhánù 12:37, 38; Aísáyà 53:1) Ara ohun tí kò jẹ́ kí wọ́n gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà ni èrò kan tí kò tọ̀nà tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn Júù, pé gbàrà tí Mèsáyà bá ti dé ló máa jẹ́ kí orílẹ̀-èdè àwọn gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn ará Róòmù tó ń ṣàkóso wọn, tó sì máa dá ìjọba tiwọn tó jẹ́ ti Dáfídì pa dà. Nítorí pé Jésù jìyà tó sì kú, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ò gbà pé òun ni Mèsáyà. Ṣùgbọ́n ohun tí Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ ni pé Mèsáyà máa jìyà kó tó jọba.
Aísáyà kọ ọ́ sínú ìwé rẹ̀ bíi pé Mèsáyà fúnra rẹ̀ ló ń sàsọtẹ́lẹ̀, ó ní: “Ẹ̀yìn mi ni mo fi fún àwọn akọluni . . . Ojú mi ni èmi kò fi pa mọ́ fún àwọn ohun tí ń tẹ́ni lógo àti itọ́.” Mátíù sì wá ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìgbẹ́jọ́ Jésú, ó ní: “Wọ́n tutọ́ sí ojú rẹ̀ wọ́n sì lù ú ní ẹ̀ṣẹ́. Àwọn mìíràn gbá a lójú.” (Aísáyà 50:6; Mátíù 26:67) Aísáyà kọ̀wé pé: “Ó sì jẹ́ kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́; síbẹ̀síbẹ̀, kò jẹ́ la ẹnu rẹ̀.” Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí wá máa ṣẹ, Pílátù tó ń gbẹ́jọ́ Jésù bi í léèrè nípa ẹ̀sùn táwọn Júù fi kàn án, àmọ́ Jésù “kò dá a lóhùn rárá, àní kì í tilẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ kan, tó bẹ́ẹ̀ tí gómìnà fi ṣe kàyéfì gidigidi.”—Aísáyà 53:7; Mátíù 27:12-14; Ìṣe 8:28, 32-35.
Nípa Ikú Mèsáyà. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísàyà ṣì ń ṣẹ nìṣó sára Jésù títí dìgbà tó fi kú àti lẹ́yìn ìgbà náà pàápàá. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Òun yóò sì ṣe ibi ìsìnkú rẹ̀ àní pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú, àti pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ikú rẹ̀.” (Aísáyà 53:9) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó dà bíi pé ó ta kora yìí ṣe lè nímùúṣẹ? Nígbà tí wọ́n fẹ́ pa Jésù, wọ́n kàn án mọ́gi láàárín àwọn ọlọ́ṣà méjì. (Mátíù 27:38) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, Jósẹ́fù ara Arimatíà tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ lọ tẹ́ òkú Jésù sínú ibojì tara rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́ sínú àpáta. (Mátíù 27:57-60) Lákòótán, ikú Jésù mú ohun pàtàkì kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ. Bí Aísáyà ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà, ó sọ pé: “Ìránṣẹ́ mi, olódodo, yóò . . . mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn; àwọn ìṣìnà wọn ni òun fúnra rẹ̀ yóò sì rù.” Ká sòótọ́, ikú Jésù ni ìràpadà tó máa mú ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lórí gbogbo àwọn olóòótọ́ èèyàn.—Aísáyà 53:8, 11; Róòmù 4:25.
Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Ìmúṣẹ Wọn Dájú
Láti lè mú káwọn èèyàn rí i látinú Ìwé Mímọ́ pé Jésù ni Mèsáyà, àwọn àpọ́sítélì àti Jésù fúnra rẹ̀ lo ọ̀rọ̀ inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ju bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ inú ìwé èyíkéyìí míì lọ nínú Bíbélì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìwé Aísáyà nìkan kọ́ ni ìwé inú Bíbélì tó sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ wà nínú àwọn ìwé míì lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó ṣẹ sára Jésù, Ìjọba rẹ̀ àti àwọn nǹkan rere tí Ìjọba náà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.a (Ìṣe 28:23; Ìṣípayá 19:10) Báwo ló ṣe dájú tó pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa nímùúṣẹ? Jésù sọ fáwọn Júù tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe rò pé mo wá láti pa Òfin tàbí àwọn Wòlíì [ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù] run. Èmi kò wá láti pa run, bí kò ṣe láti mú ṣẹ; nítorí lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò tètè kọjá lọ jù kí lẹ́tà kan tí ó kéré jù lọ tàbí kí gínńgín kan lára lẹ́tà kan kọjá lọ kúrò nínú Òfin lọ́nàkọnà kí ohun gbogbo má sì ṣẹlẹ̀.”—Mátíù 5:17, 18.
Jésù tún tọ́ka sí báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nígbà ayé rẹ̀ àtàwọn tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá kú ṣe máa mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. (Dáníẹ́lì 9:27; Mátíù 15:7-9; 24:15) Yàtọ̀ síyẹn, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò láyé, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì wọ̀nyí àtàwọn èyí tó máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ ka àlàyé púpọ̀ sí i nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára, wo ojú ìwé 200 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe e.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
“Wúńdíá náà yóò . . . bí ọmọkùnrin kan”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
“Ojú mi ni èmi kò fi pa mọ́ fún àwọn ohun tí ń tẹ́ni lógo”