Ohun Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
JÈHÓFÀ, “Ọlọ́run aláyọ̀,” àti Jésù Kristi, “aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà,” mọ ohun náà gan-an tó ń mú kéèyàn láyọ̀ ju bí ẹnikẹ́ni mìíràn ṣe mọ́ ọn lọ. (1 Tímótì 1:11; 6:15) Abájọ tí kò fi yà wá lẹ́nu pé inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti lè rí ohun tó ń fún èèyàn láyọ̀.—Ìṣípayá 1:3; 22:7.
Jésù mẹ́nu kan ohun tó ń mú kéèyàn láyọ̀ nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí tó ṣe lórí Òkè. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni” (1) àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, (2) àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, (3) àwọn onínú tútù, (4) àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, (5) àwọn aláàánú, (6) àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, (7) àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, (8) àwọn tí a ti ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, àti (9) àwọn tí àwọn ènìyàn gàn, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí nítorí rẹ̀.—Mátíù 5:3-11.a
Ṣé Òótọ́ Ni Ohun Tí Jésù Sọ Yìí?
Ó yẹ ká túbọ̀ ṣàlàyé ọ̀nà táwọn kan lára ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn fi jóòótọ́. Tá ló lè sọ pé ẹni tí ọkàn mímọ́ gaara sún láti jẹ́ onínú tútù, tó jẹ́ aláàánú, tó sì tún jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà kò ní láyọ̀ ju ẹni tó máa ń bínú, tó jẹ́ aríjàgbá, tí kò sì láàánú?
Àmọ́, a lè wá ṣe kàyéfì nípa ọ̀nà tí àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ nítorí òdodo tàbí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ fi lè jẹ́ aláyọ̀. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé. Wọ́n ‘ń mí ìmí ẹ̀dùn, wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí táwọn èèyàn ń ṣe’ lákòókò wa yìí. (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Ìyẹn fúnra rẹ̀ kò mú wọn láyọ̀. Àmọ́, inú wọn wá dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Ọlọ́run ti ní i lọ́kàn láti mú ipò ayé padà bọ̀ sí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ àti pé yóò gbèjà àwọn tí à ń pọ́n lójú.—Aísáyà 11:4.
Ìfẹ́ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní fún òdodo tún jẹ́ kí wọ́n máa ṣọ̀fọ̀ lórí bí àwọn fúnra wọn ṣe sábà máa ń kùnà láti ṣe ohun tí ó tọ́. Wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ múra tán láti wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, nítorí wọ́n mọ̀ pé òun nìkan ṣoṣo ló lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti borí ìkùdíẹ̀-káàtó wọn.—Òwe 16:3, 9; 20:24.
Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ nítorí òdodo, tí àìní wọn nípa tẹ̀mí sì ń jẹ lọ́kàn mọ ìjẹ́pàtàkì níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn. Àjọṣe rere láàárín àwa àtàwọn èèyàn bíi tiwa ń fúnni láyọ̀, àmọ́ àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run tún ń fúnni láyọ̀ tó ju ìyẹn lọ. Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó fi gbogbo ọkàn wọn nífẹ̀ẹ́ ohun tí ó tọ́, tí wọ́n sì fẹ́ kí Ọlọ́run máa tọ́ àwọn sọ́nà, lè jẹ́ aláyọ̀ ní ti tòótọ́.
Àmọ́ o, ó lè ṣòro fún ọ láti gbà pé ẹni tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí tí wọ́n sì ń gàn lè jẹ́ aláyọ̀. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ yẹn ní láti jóòótọ́, nítorí pé Jésù fúnra rẹ̀ ló sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, báwo ló ṣe yẹ ká lóye àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀?
A Ń Ṣe Inúnibíni sí Wọn Ṣùgbọ́n Wọ́n Láyọ̀—Báwo Nìyẹn Ṣe Lè Jẹ́ Bẹ́ẹ̀?
A fẹ́ kó o mọ̀ pé Jésù ò sọ pé ẹ̀gàn àti inúnibíni ló ń múni láyọ̀. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, . . . nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, . . . nítorí mi.” (Mátíù 5:10, 11) Nítorí náà, kìkì ohun tó ń fún ẹnì kan láyọ̀ ni pé wọ́n ń pẹ̀gàn rẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi àti nítorí pé ó ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìlànà òdodo tí Jésù fi kọ́ni.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ti ilé ẹjọ́ gíga ti àwọn Júù, “fi ọlá àṣẹ pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pa àṣẹ fún wọn pé kí wọ́n dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.” Kí làwọn àpọ́sítélì náà wá ṣe? “Nítorí náà, àwọn wọ̀nyí bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀. Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.”—Ìṣe 5:40-42; 13:50-52.
Àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ká túbọ̀ lóye ọ̀nà tí ẹ̀gàn àti ayọ̀ gbà so pọ̀ mọ́ra. Ó kọ̀wé pé: “Bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀, nítorí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.” (1 Pétérù 4:14) Bẹ́ẹ̀ ni o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà kì í ṣomi ọbẹ̀, síbẹ̀ jíjìyà gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni nítorí pé à ń ṣe ohun tí ó tọ́, ń fúnni láyọ̀ tó máa ń wá látinú mímọ̀ pé a gba ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe tan mọ́ ayọ̀?
Ṣé Àwọn Iṣẹ́ Tara Ló Ń Fúnni Láyọ̀ àbí Èso Tẹ̀mí?
Kìkì àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso ni Ọlọ́run máa ń fún ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Ìṣe 5:32) Jèhófà kì í fi ẹ̀mí rẹ̀ fún àwọn tó bá ń fi “àwọn iṣẹ́ ti ara” ṣèwà hù. Àwọn iṣẹ́ wọ̀nyẹn ni “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.” (Gálátíà 5:19-21) Lóòótọ́, “àwọn iṣẹ́ ti ara” gbòde kan láyé òde òní. Àmọ́, ayọ̀ àwọn tó ń fi wọ́n ṣèwà hù kì í tọ́jọ́, wọn kì í sì í ní ojúlówó ayọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni fífi irú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ṣèwà hù máa ń ba àjọṣe àárín ẹbí, ọ̀rẹ́, àti ojúlùmọ̀ jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé àwọn tó ń “fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”
Àmọ́, Ọlọ́run máa ń fi ẹ̀mí rẹ̀ fún àwọn tó ní “èso ti ẹ̀mí.” Àwọn ànímọ́ tó para pọ̀ di èso yìí ni “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Nígbà tá a bá ń fi àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn, à ń ṣe ohun tí àjọṣe àárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn yóò fi dán mọ́rán, a óò tún ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí sì ń yọrí sí ayọ̀ tòótọ́. (Wo àpótí.) Lékè gbogbo rẹ̀, tá a bá ń lo ìfẹ́, inú rere, ìwà rere, àtàwọn ànímọ́ mìíràn tó jẹ́ ti Ọlọ́run, a óò máa múnú Jèhófà dùn, a óò sì ní ìrètí aláyọ̀ ti níní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.
Èèyàn Fúnra Rẹ̀ Ló Ń Wá Bóun Ṣe Máa Láyọ̀
Nígbà tí tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Wolfgang àti Brigitte, tí wọ́n ń gbé nílẹ̀ Jámánì, bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn, wọ́n ní ọ̀pọ̀ ohun ìní táwọn èèyàn gbà pé ó ń fúnni láyọ̀. Wọ́n kéré lọ́jọ́ orí, ara wọn sì le. Aṣọ olówó ńlá ni wọ́n máa ń wọ̀, wọ́n sì ń gbé nínú ilé mèremère kan tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, wọ́n tún ń ṣòwò tó ń mówó gidi wọlé. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò wọn ni wọ́n fi ń wá báwọn ṣe máa túbọ̀ kó nǹkan ìní jọ, àmọ́ ìyẹn ò fún wọn ní ojúlówó ayọ̀. Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, Wolfgang àti Brigitte ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò púpọ̀ láti lépa nǹkan tẹ̀mí, wọ́n tún wá ọ̀nà táwọn a fi túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Kò pẹ́ tí ohun tí wọ́n pinnu láti ṣe yìí fi yí èrò wọn padà, wọ́n si dẹni tí kò walé ayé mọ́yà mọ́, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn ni iṣẹ́ fífi àkókò púpọ̀ wàásù Ìjọba náà. Ní báyìí, wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n sì ń sìn ni ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ń kọ́ èdè Éṣíà kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ tọkọtaya yìí rí ayọ̀ tòótọ́? Wolfgang sọ pé: “Àtìgbà tá a ti túbọ̀ ń lépa nǹkan tẹ̀mí ni inú wa ti ń dùn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ọkàn wa sì ti balẹ̀ sí i. Sísin Jèhófà tọkàntọkàn tún ti mú kí ìdè ìgbéyàwó wa lágbára sí i. Kì í ṣe pé àjọgbé wa ò dán mọ́ràn tẹ́lẹ̀ o, àmọ́ àwọn ohun tá à ń ṣe àtàwọn nǹkan tá a nífẹ̀ẹ́ sí ló yàtọ̀ síra. Àmọ́ ohun kan náà la wá jọ ń lépa báyìí.”
Kí Lohun Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀?
Ní ṣókí: Yẹra fún “àwọn iṣẹ́ ti ara,” kó o sì ní “èso ti ẹ̀mí [Ọlọ́run].” Kéèyàn tó lè jẹ́ aláyọ̀, ó ní láti wá bóun ṣe máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹni tó bá sapá láti ṣe èyí yóò bá ohun tí Jésù sọ nípa ẹni tó jẹ́ aláyọ̀ mu.
Nítorí náà, má ṣe rò pé o ò lè láyọ̀. Lóòótọ́, o lè máa ṣàìsàn báyìí, tàbí kó o tiẹ̀ níṣòro nínú ìgbéyàwó rẹ. Ó sì lè jẹ́ pé o ti dàgbà kọjá ẹni tó tún lè bímọ, tàbí kó o máa sa gbogbo ipá rẹ láti ríṣẹ́ tó máa mówó gidi wọlé fun ọ. Bóyá o ò lówó lọ́wọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, fọkàn balẹ̀, kó sídìí tó fi yẹ kó o bọ́hùn! Ìjọba Ọlọ́run yóò yanjú àwọn ìṣòro wọ̀nyí àti àìmọye ìṣòro mìíràn. Láìsí àní-àní, Jèhófà Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí onísáàmù mẹ́nu kàn yẹn ṣẹ láìpẹ́, èyí tó sọ pé: “Ipò ọba rẹ jẹ́ ipò ọba tí ó wà fún gbogbo àkókò tí ó lọ kánrin . . . Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sáàmù 145:13, 16) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jákèjádò ayé lè jẹ́rìí sí i pé fífi ìlérí dídájú tí Jèhófà ṣe yìí sọ́kàn yóò jẹ́ kí ayọ̀ rẹ túbọ̀ pọ̀ sí i lóde òní.—Ìṣípayá 21:3.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀kọ̀ọ̀kan ohun tí Jésù mẹ́nu kàn yìí ló bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ma·kaʹri·oi. Dípò pípe ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ yìí ní “ìbùkún,” bí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan ti ṣe, ọ̀rọ̀ náà “aláyọ̀” tó bá ọ̀rọ̀ yẹn mu jù lọ ni Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àti àwọn ìtumọ̀ mìíràn bíi The Jerusalem Bible àti Today’s English Version, pè é.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Nǹkan Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
Ìfẹ́ á jẹ́ káwọn ẹlòmíràn nífẹ̀ẹ́ rẹ bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn.
Ìdùnnú á fún ọ ní okun inú tí wàá fi fara da àwọn ìṣòro.
Àlàáfíà á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe bá ẹnikẹ́ni ṣọ̀tá.
Ìpamọ́ra á jẹ́ kó o láyọ̀ bó o tilẹ̀ wà nínú àdánwò.
Inú rere á jẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ ọ.
Ìwà rere rẹ á jẹ́ káwọn èèyàn ṣàánú rẹ nígbà tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́.
Ìgbàgbọ́ á jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ darí rẹ.
Ìwà tútù yóò jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀, kí ara sì tù ọ́.
Ìkóra-ẹni-níjàánu kò ní jẹ́ kó o máa ṣe àṣìṣe tó pọ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Tó o bá fẹ́ jẹ́ aláyọ̀, o ní láti fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan tẹ̀mí