Baptism “Sinu Orukọ”
Ẹ̀KỌ́ iwadii ti a ṣe nipa ẹgbẹẹgbẹrun awọn akọsilẹ ti a fi papyrus ṣe ni ayé igbaani ti a rí ninu awọn erupẹ Egipti ni ibẹrẹ ọrundun yii ti sábà maa ń tanmọlẹ gbigbadunmọni sori Iwe Mimọ Kristian Lede Griki. Bawo? Nipa ṣiṣayẹwo ọ̀nà ti a gbà lo awọn ọ̀rọ̀ pàtó kan, a ṣamọna wa siha ọ̀nà tí ó tubọ tọna nipa awọn ọ̀rọ̀ kan-naa ati bi a ṣe gbé wọn kalẹ ninu Iwe Mimọ.
Apẹẹrẹ kan ni bi Jesu ti lo “ní orukọ” nigba ti o paṣẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ ṣaaju ki o to goke re ọrun: “Nitori naa ẹ lọ, ẹ maa kọ́ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ si maa baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ.” Ki ni ohun ti Jesu ni lọkan?—Matteu 28:19.
Awọn ọmọwe akẹkọọjinlẹ ti ṣawari pe ninu awọn ikọwe ayé gbolohun naa “ni orukọ,” tabi “sinu orukọ” (Kingdom Interlinear), ni a lò ni isopọ pẹlu sisanwo “sinu akọsilẹ owó ẹnikẹni.” Ọjọgbọn ẹlẹkọọ isin naa Dokita G. Adolf Deissmann gbagbọ pe lójú-ìwòye awọn ẹ̀rí lati inu awọn iwe papyrus naa, “ero ti o wà labẹ . . . awọn gbolohun naa lati baptisi sinu orukọ Oluwa, tabi lati gbagbọ sinu orukọ Ọmọkunrin Ọlọrun, ni pe baptism tabi igbagbọ ni o parapọ jẹ́ jíjẹ́ ti Ọlọrun tabi ti Ọmọkunrin Ọlọrun.”—Ikọwe winni-winni jẹ́ ti Deissmann.
Lọna ti o fanilọkanmọra, gbolohun tí ó jọ eyi ni awọn Ju ọjọ ayé Jesu lò, gẹgẹ bi a ti ṣalaye ninu Theological Dictionary of the New Testament pe: “Ìkọlà aláwọ̀ṣe kan ni a ń ṣe . . . ‘ni orukọ aláwọ̀ṣe naa,’ lati gbà á sinu eto isin Ju. Ikọla yii ń ṣẹlẹ . . . ‘ni orukọ majẹmu naa,’ lati gbà á sinu majẹmu naa.” Ipo-ibatan kan nipa bayii ni a filelẹ ti ẹni ti kìí ṣe Ju naa si di aláwọ̀ṣe kan labẹ àṣẹ majẹmu naa.
Nitori naa fun awọn Kristian, baptism ti o tẹle iyasimimọ fidi ibatan timọtimọ pẹlu Jehofa Ọlọrun, Ọmọkunrin rẹ̀ Jesu Kristi, ati ẹmi mimọ mulẹ. Ẹni ti a yí lọ́kàn pada naa mọ ọla-aṣẹ tí ọkọọkan wọn ní ninu ọ̀nà igbesi-aye rẹ̀ titun. Ṣagbeyẹwo bi eyi ṣe jẹ otitọ fun ọkọọkan ninu awọn mẹta ti a darukọ naa.
Nipa mimọ ọla-aṣẹ Ọlọrun daju, awa sunmọ ọn pẹkipẹki a si wọnu ipo-ibatan kan pẹlu rẹ̀. (Heberu 12:9; Jakọbu 4:7, 8) A di dúkìá Ọlọrun gẹgẹ bi ẹrú rẹ̀, ti a rà pẹlu iye-owó ẹbọ irapada Jesu Kristi. (1 Korinti 3:23; 6:20) Aposteli Paulu bakan naa sọ fun awọn Kristian ọrundun kìn-ín-ní pe wọn jẹ ti Jesu Kristi, kìí ṣe ti ẹnikẹni yoowu ti o mu otitọ tọ̀ wọn lọ. (1 Korinti 1:12, 13; 7:23; fiwe Matteu 16:24.) Baptism ni orukọ Ọmọkunrin dọgbọn tumọsi mimọ otitọ yii daju, titẹwọgba Jesu gẹgẹ bi “ọ̀nà, ati otitọ, ati iye.”—Johannu 14:6.
Ẹmi mimọ pẹlu ṣe pataki si ipo-ibatan wa titọna pẹlu Jehofa ati Jesu Kristi. Baptism ni orukọ ẹmi mimọ fihàn pe awa mọ ila-iṣẹ ẹmi naa ninu ibalo Ọlọrun pẹlu wa. A nitẹsi lati tẹle itọsọna rẹ̀, a kò ṣàìkà á si tabi ki a huwa lodi sii, ni dídínà mọ́ iṣiṣẹ rẹ̀ nipasẹ wa. (Efesu 4:30; 1 Tessalonika 5:19) Animọ ti alaijẹ ẹni gidi kan tí ẹmi naa ní kò da iṣoro kankan silẹ nipa ìlò tabi itumọ, bi ìlò “ni orukọ majẹmu naa” kò ti ṣe ninu isin Ju.
Nitori naa, ni akoko iyasimimọ ati baptism, a nilati ronu taduratadura lori ohun ti ipo-ibatan wa titun ni ninu. Ó beere fun titẹriba fun ifẹ-inu Ọlọrun, ti a ṣàṣefihàn rẹ̀ ninu apẹẹrẹ ati ipese irapada Jesu Kristi, ti a nilati muṣẹ nipasẹ ẹmi mimọ bi o ti ń dari gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun ninu ifẹ ati iṣọkan kari-aye.