Ṣọọṣi Ijimiji Ha Kọni Pe Ọlọrun Jẹ Mẹtalọkan Bi?
Apa Kì-ín-ní—Jesu ati Awọn Ọmọ-ẹhin Rẹ̀ Ha Fi Ẹkọ Mẹtalọkan Kọni Bi?
Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ha fi ẹkọ Mẹtalọkan kọni bi? Awọn aṣaaju ṣọọṣi ti ọgọrun-un ọdun melookan tẹle e ha fi kọni bi? Bawo ni o ṣe pilẹṣẹ? Eesitiṣe ti o fi ṣe pataki lati mọ otitọ nipa igbagbọ yii? Bẹrẹ pẹlu Apa Kìn-ín-ní ninu itẹjade yii, Ilé-ìṣọ̀ná yoo jiroro awọn ibeere wọnyi ninu ọ̀wọ́ awọn ọrọ-ẹkọ. Awọn ọrọ-ẹkọ miiran ninu ọ̀wọ́ naa yoo farahan lati ìgbà dé ìgbà ninu awọn itẹjade ti yoo tẹle e.
AWỌN wọnni ti wọn gba Bibeli gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun mọ daju pe awọn ní ẹrù iṣẹ lati kọ́ awọn ẹlomiran nipa Ẹlẹdaa. Wọn tun mọ pe pataki ohun ti wọn fi nkọni nipa Ọlọrun gbọdọ jẹ otitọ.
Ọlọrun bá ‘awọn onitunu’ Joobu wí nitori aiṣe bẹẹ. “Oluwa [“Jehofa,” NW] sì wí fun Elifasi, ara Tema pe, Mo binu sí ọ ati sí, awọn ọrẹ rẹ mejeeji, nitori pe ẹyin kò sọrọ, niti emi, ohun ti ó tọ́, bi Joobu iranṣẹ mi ti sọ.”—Joobu 42:7.
Apọsiteli Pọọlu, nigba ti ó njiroro ajinde, sọ pe a o “mu wa ni ẹlẹrii èké fun Ọlọrun” bi awa ba nilati kọni ni ohun kan nipa awọn igbokegbodo Ọlọrun ti kii ṣe otitọ. (1 Kọrinti 15:15) Nigba ti eyi rí bẹẹ pẹlu ẹkọ ajinde, bawo ni o ṣe yẹ ki awa ṣọra tó nigba ti a ba fẹ gbé ẹkọ wa nipa ẹni ti Ọlọrun jẹ́ yẹ̀wò!
Ẹkọ Mẹtalọkan
Ó fẹrẹẹ jẹ pe gbogbo ṣọọṣi Kristẹndọmu ni o nkọni pe Ọlọrun jẹ Mẹtalọkan. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa The Catholic Encyclopedia pe ẹkọ Mẹtalọkan ni “olori ẹkọ isin Kristẹni,” ni titumọ rẹ̀ ni ọna yii:
“Ninu iṣọkan Ọlọrun ẹlẹni mẹta awọn Ẹni Mẹta ni nbẹ, Baba, Ọmọkunrin, ati Ẹmi Mimọ, awọn Ẹni Mẹta wọnyi ti ọkan jẹ eyi ti o yatọ gedegede si omiran. Nipa bayii, ninu awọn ọrọ ìjẹ́wọ́ igbagbọ Athanasia: ‘Baba jẹ Ọlọrun, Ọmọkunrin jẹ Ọlọrun, Ẹmi Mimọ sì jẹ Ọlọrun, ati pe sibẹ Ọlọrun mẹta kọ́ ni ńbẹ ṣugbọn Ọlọrun kanṣoṣo.’ . . . Awọn Ẹni naa jọ jẹ́ ayeraye ati abaradọgba: gbogbo wọn rí bakan naa a kò dá wọn wọ́n sì jẹ alagbara giga julọ.”1
Iwe gbédègbẹ́yọ̀ The Baptist Encyclopædia funni ni itumọ ti o farajọra. O wi pe:
“[Jesu] jẹ . . . Jehofa ayeraye naa . . . Ẹmi Mimọ jẹ Jehofa . . . Ọmọkunrin ati Ẹmi ni a gbé kari ibaradọgba rẹgi pẹlu Baba. Bi oun ba jẹ Jehofa awọn pẹlu jẹ bẹẹ.”2
A Fi Awọn Alatako Bú
Ni 325 C.E., igbimọ awọn biṣọọbu ni Nicea ni Asia Kekere gbé ìjẹ́wọ́ igbagbọ kan kalẹ ti ó polongo Ọmọkunrin Ọlọrun lati jẹ “Ọlọrun tootọ” gan-an gẹgẹ bi Baba ti jẹ “Ọlọrun tootọ.” Apakan ìjẹ́wọ́ igbagbọ yẹn wi pe:
“Ṣugbọn awọn wọnni ti wọn wi pe, [akoko kan] nbẹ nigba ti [Ọmọkunrin naa] kò sí, ati Ṣaaju ki a tó bí i Oun kò sí, ati pe oun wá si ààyè lati inu ohun ti kò sí, tabi ti wọn tẹnumọ ọn pe Ọmọkunrin Ọlọrun jẹ ẹni tabi ohun kan ti o yatọ, tabi pe oun ni a dá, tabi pe oun ni a lè tunṣe tabi yipada—awọn wọnyi ni Ṣọọṣi Katoliki fibu.”3
Nipa bayii, olukuluku ẹni ti o gbagbọ pe Ọmọkunrin Ọlọrun kii ṣe ajumọ jẹ ẹni ayeraye pẹlu Baba tabi pe Ọmọkunrin naa ni a ṣẹ̀dá ni a fi le ìdálẹ́bi ainipẹkun lọwọ. Ẹnikan le ronu ikimọlẹ lati fohunṣọkan ti eyi gbékarí ọpọlọpọ awọn gbáàtúù onigbagbọ.
Ni ọdun 381 C.E., igbimọ miiran pade pọ ni Constantinople wọn sì polongo pe ẹmi mimọ ni a nilati jọsin ki a sì fogo fun gan-an gẹgẹ bi a ti ṣe fun Baba ati Ọmọkunrin. Ọdun kan lẹhin naa, ni 382 C.E, awujọ awọn mẹmba ṣọọṣi miiran padepọ ni Constantinople wọn sì polongo pe ẹmi mimọ jẹ Ọlọrun ni kikun.4 Ni ọdun yẹn kan naa, niwaju igbimọ kan ni Roomu, Pope Damasus gbé akojọpọ awọn ẹkọ ti ṣọọṣi nilati patì kalẹ. Iwe aṣẹ naa, ti a pe ni Tome of Damasus [Iwe-nla ti Damasus], ni awọn gbolohun ti ó tẹle yii ninu:
“Bi ẹnikẹni ba sẹ́ pe Baba jẹ ẹni ayeraye, pe Ọmọkunrin jẹ ẹni ayeraye, ati pe Ẹmi Mimọ jẹ ẹni ayeraye: oun jẹ aládàámọ̀.”
“Bi ẹnikẹni ba sẹ́ pe Ọmọkunrin Ọlọrun jẹ Ọlọrun tootọ, gan-an gẹgẹ bi Baba ti jẹ Ọlọrun tootọ, ti o ni gbogbo agbara, ti o mọ ohun gbogbo, ti o sì baradọgba pẹlu Baba: oun jẹ aládàámọ̀.”
“Bi ẹnikẹni ba sẹ́ pe Ẹmi mimọ . . . jẹ Ọlọrun tootọ ti o ni gbogbo agbara ti o sì mọ ohun gbogbo, . . . oun jẹ́ aládàámọ̀.”
“Bi ẹnikẹni ba sẹ́ pe awọn ẹni mẹtẹẹta naa, Baba, Ọmọkunrin, ati Ẹmi Mimọ jẹ awọn ẹni gidi, abaradọgba, ayeraye, ti o ni ohun gbogbo ti o ṣee fojuri ati eyi ti kò ṣee fojuri ninu, pe wọn jẹ́ alagbara julọ, . . . oun jẹ aládàámọ̀.”
“Bi ẹnikẹni ba wi pe [Ọmọkunrin ẹni ti a] ṣe ni ẹran ara kò sí ninu ọrun pẹlu Baba nigba ti oun wà lori ilẹ-aye: oun jẹ́ aládàámọ̀.”
“Bi ẹnikẹni, nigba ti o nwi pe Baba jẹ́ Ọlọrun Ọmọkunrin jẹ́ Ọlọrun ti Ẹmi Mimọ sì jẹ́ Ọlọrun, . . . kò ba wi pe wọn jẹ Ọlọrun kan, . . . oun jẹ aládàámọ̀.”5
Awọn ọmọwe Jesuit ti wọn tumọ eyi ti a ṣẹṣẹ mẹnukan tan yii fi ọrọ naa kun pe: “Pope St. Celestine Kìn-ín-ní (422 si 432) ni kedere gbe awọn ofin iwe akọsilẹ wọnyi yẹwo; a lè kà wọn si awọn itumọ igbagbọ.”6 Ọmọwe Edmund J. Fortman sì tẹnumọ ọn pe iwe-nla naa duro fun “ẹkọ mẹtalọkan ti ó yè kooro ti o sì ṣe pataki.”7
Bi iwọ ba jẹ mẹmba ṣọọṣi kan ti o tẹwọgba ẹkọ Mẹtalọkan, njẹ awọn gbolohun wọnyi tumọ igbagbọ rẹ bi? Njẹ iwọ sì mọ pe lati gbagbọ ninu ẹkọ Mẹtalọkan gẹgẹ bi a ti fi kọni ninu awọn ṣọọṣi beere lọwọ rẹ lati gbagbọ pe Jesu wà ni ọrun nigba ti oun wa ni ori ilẹ-aye? Ẹkọ yii farajọra pẹlu oun ti Athanasius alufaa ṣọọṣi ọgọrun-un ọdun kẹrin wí ninu iwe rẹ̀ On the Incarnation:
“Ọ̀rọ̀ naa [Jesu] ni a kò fi ara Rẹ̀ dí, bẹẹ ni wíwà nihin-in Rẹ̀ ninu ara kò dín wíwà nibomiran Rẹ̀ lọwọ bakan naa. Nigba ti Ó ṣi ara Rẹ̀ nipo Oun kò dawọ duro pẹlu lati dari agbaye nipasẹ Ero inu ati agbara Rẹ̀. . . . Oun ṣì jẹ́ Orisun iye fun gbogbo agbaye sibẹ, ó wà ni gbogbo apa rẹ̀, sibẹ lẹhin ode gbogbo rẹ̀.”8
Ohun Ti Ẹkọ Mẹtalọkan Tumọsi
Awọn kan ti pari ero pe wiwulẹ ka Jesu sí Ọlọrun ni gbogbo ohun ti ẹkọ Mẹtalọkan tumọsi. Fun awọn miiran, igbagbọ ninu Mẹtalọkan wulẹ tumọsi igbagbọ ninu Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ.
Bi o ti wu ki o ri, ayẹwo kinnikinni ti awọn ìjẹ́wọ́ igbagbọ Kristẹndọmu tudii bi iru ero bẹẹ kò ti kun oju oṣunwọn tó lọna ti o banininujẹ ni itanmọra pẹlu ẹkọ ti a fi aṣẹ tìlẹ́hìn. Awọn itumọ ti a fọwọsi mu un ṣe kedere pe ẹkọ Mẹtalọkan kii ṣe ero ti o rọrun kan. Kaka bẹẹ, o jẹ ọ̀wọ́ awọn ero ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ó lọjupọ ti a ti mu papọ la sáà akoko gigun ti a sì lọ́pọ̀ mọ́ araawọn.
Lati inu aworan ẹkọ Mẹtalọkan ti o farahan lẹhin Igbimọ Constantinople ni 381 C.E, lati inu Iwe-nla ti Damasus ni 382 C.E, lati inu Ìjẹ́wọ́ igbagbọ Athanasia ti ó de laipẹ lẹhin naa ati lati inu awọn iwe ẹ̀rí miiran, a lè pinnu ni kedere ohun ti Kristẹndọmu ni lọkan nipa ẹkọ Mẹtalọkan. O ni awọn ero pato ti wọn tẹle e yi ninu:
1. Awọn ẹni atọrunwa mẹta ni a sọ pe wọn wà—Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ ninu Ọlọrun ẹlẹni mẹta.
2. Ọkọọkan awọn ẹni ọtọọtọ wọnyi ni a sọ pe o jẹ ẹni ayeraye, ko si eyi ti o wá ṣaaju tabi ti ó de lẹhin ekeji ninu akoko.
3. Ọkọọkan ni a sọ pe ó jẹ olodumare, laisi eyi ti o tobiju tabi kere si ekeji.
4. Ọkọọkan ni a sọ pe ó jẹ onímọ̀-gbogbo, ti o mọ ohun gbogbo.
5. Ọkọọkan ni a sọ pe ó jẹ Ọlọrun tootọ.
6. Bi o ti wu ki o ri, a sọ pe ko si awọn Ọlọrun mẹta ṣugbọn kiki Ọlọrun kanṣoṣo
Ni kedere ẹkọ Mẹtalọkan jẹ ọ̀wọ́ awọn ero dídíjúlù ti ó ni o keretan awọn ohun ṣiṣekoko ti wọn wà loke yii ninu ti o si wemọ ohun ti ó tilẹ pọ sii, gẹgẹ bi a ti ṣipaya rẹ nigba ti a ṣayẹwo awọn kulẹkulẹ. Ṣugbọn bi a ba gbe kiki awọn ero ipilẹ ti o wà loke yii yẹwo, o ṣe kedere pe ti a ba mu eyikeyii kuro, ohun ti o ṣẹku kii ṣe Mẹtalọkan ti Kristẹndọmu mọ. Lati ni aworan pipe, gbogbo awọn ẹla wọnyi gbọdọ wà nibẹ.
Pẹlu oye didara ju yii nipa ọrọ naa “Mẹtalọkan”, a lè beere nisinsinyi pe: Ó ha jẹ́ ẹkọ Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi? Bi o ba ri bẹẹ, iba ti farahan gẹgẹ bi eyi ti a ti gbekalẹ ni kikun ninu ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní ti Sanmani Tiwa. Ati niwọn igba ti o jẹ pe ohun ti wọn fi kọni ni a rí ninu Bibeli, nigba naa ẹkọ Mẹtalọkan jẹ yala ẹkọ Bibeli tabi ki o ma jẹ bẹẹ. Bi o ba jẹ bẹẹ oun ni a gbọdọ ti fi kọni ni kedere ninu Bibeli.
Ko ba ọgbọn mu lati ronu pe Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ yoo kọ́ awọn eniyan nipa Ọlọrun sibẹ ki wọn maa sì sọ fun wọn ẹni ti Ọlọrun jẹ́, paapaa nigba ti yoo beere ki awọn onigbagbọ diẹ fi ẹmi wọn lélẹ̀ fun Ọlọrun paapaa. Fun idi yii, Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ iba ti fun kikọ awọn ẹlomiran nipa ẹkọ ṣiṣekoko yii ni ipo kìn-ín-ní.
Ṣayẹwo Awọn Iwe Mimọ
Ni Iṣe ori 17, ẹsẹ 11, awọn eniyan ni a pè ni ‘ọmọluwabi’ nitori pe wọn “nṣayẹwo Iwe mimọ tiṣọratiṣọra lojoojumọ boya awọn nnkan wọnyi rí bẹẹ,” awọn nǹkan ti apọsiteli Pọọlu fi kọni. A fun wọn niṣiiri lati lo Iwe mimọ lati jẹrii si awọn ẹkọ ẹnikan ti ó jẹ́ apọsiteli paapaa. Iwọ gbọdọ ṣe bakan naa.
Ranti pe awọn Iwe mimọ ni “imisi Ọlọrun” a sì nilati lò wọn fun “itọni, fun ikọni ti o wà ninu ododo: ki eniyan Ọlọrun ki o le pe, ti a ti murasilẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.” (2 Timoti 3:16, 17) Nitori naa Bibeli jẹ pipe ninu awọn ọran ti ẹkọ igbagbọ. Bi ẹkọ Mẹtalọkan ba jẹ otitọ, o gbọdọ wà nibẹ.
A kesi ọ lati wá inu Bibeli, ni pataki awọn iwe 27 ti o wà ninu Iwe mimọ ti Kristẹni lede Giriiki, lati ri i funraarẹ bi Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ba fi Mẹtalọkan kọni. Gẹgẹ bi o ti nṣe iwakiri, beere lọwọ araarẹ pe:
1. Mo ha lè rí iwe mimọ eyikeyii ti ó mẹnukan “Mẹtalọkan” bi?
2. Mo ha lè rí iwe mimọ eyikeyii ti o sọ pe Ọlọrun ni ó papọ jẹ ẹni mẹta gédégédé, Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ, ṣugbọn pe awọn mẹtẹẹta wulẹ jẹ Ọlọrun kan?
3. Mo ha lè rí iwe mimọ eyikeyii ti ó sọ pe Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ báradọ́gba ni gbogbo ọna, iru bii ni ayeraye, agbara, ipò, ati ọgbọn?
Bi o ti wu ki o ṣe iwakiri to, iwọ ki yoo rí iwe mimọ kan ti ó lo ọrọ naa Mẹtalọkan, bẹẹ ni iwọ ki yoo rí eyikeyii ti ó sọ pe Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ báradọ́gba ni gbogbo ọna, iru bii ni ayeraye, agbara, ipò, ati ọgbọn. Kò tilẹ sí iwe mimọ kanṣoṣo ti ó sọ pe Ọmọkunrin báradọ́gba pẹlu Baba ni awọn ọna wọnyẹn—bi iru iwe mimọ kan bẹẹ bá sì wà, patapata yoo fidii “mejilọkan” mulẹ kii ṣe Mẹtalọkan. Kò sí ibi ti Bibeli ti fi ẹmi mimọ wé ohun ti ó dọgba pẹlu Baba.
Ohun Ti Ọpọ Awọn Ọmọwe Sọ
Ọpọ awọn ọmọwe, papọ pẹlu awọn onigbagbọ Mẹtalọkan gbà pe Bibeli kò ní ẹkọ Mẹtalọkan nínú niti gidi. Fun apẹẹrẹ, iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa The Encyclopedia of Religion wi pe:
“Awọn alálàyé ati awọn ẹlẹkọọ isin lonii fohunṣọkan pe Bibeli lede Heberu kò ni ẹkọ Mẹtalọkan ninu . . . Bi o tilẹ jẹ pe Bibeli lede Heberu yaworan Ọlọrun gẹgẹ bi Baba Isirẹli ti ó sì lo awọn ọrọ ti a sọ di orukọ ẹni gidi fun Ọlọrun iru bii Ọrọ (davar), Ẹmi (ruah), Ọgbọn (hokhmah), ati Wíwà nihin-in (shekhinah), yoo lọ rekọja ete ati ẹmi Majẹmu Laelae lati mu awọn ero wọnyi baratan pẹlu ẹkọ Mẹtalọkan ẹhin naa.
“Siwaju sii, awọn alálàyé ati awọn ẹlẹkọọ isin fohunṣọkan pe Majẹmu Laelae pẹlu kò ni ẹkọ Mẹtalọkan ti a ṣalaye daradara kan ninu. Ọlọrun Baba ni orisun gbogbo nǹkan ti ó wà (Pantokrator) oun sì tun ni Baba Jesu Kristi; ‘Baba’ kii ṣe orukọ oyè fun ẹni akọkọ ninu Mẹtalọkan ṣugbọn ọrọ ti ó nitumọ kan naa pẹlu Ọlọrun. . . .
“Ninu Majẹmu Titun kò sí ero iru ẹni ti Ọlọrun jẹ́ ti ó ṣoro lati mọ ti a lè ronukan (‘Mẹtalọkan ti ó wà ni ibi gbogbo ni agbaye’), bẹẹ ni Majẹmu Titun kò sì ní ede ti ó nilo imọ akanṣe lati loye ẹkọ igbagbọ ti o kẹhin (hupostasis, ousia, substantia, subsistentia, prosōpon, persona). . . . Kò ṣee jà níyàn pe ẹkọ naa ni a kò le fidii rẹ̀ mulẹ lori ẹ̀rí ti iwe mimọ nikan.”9
Niti otitọ itan lori ọran yii, iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa The New Encyclopædia Britannica wi pe:
“Ọrọ naa Mẹtalọkan tabi alaye kedere ẹkọ naa kò farahan ninu Majẹmu Titun . . .
“Ẹkọ naa gbèrú ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ lati ọpọlọpọ ọgọrun-un ọdun wá ti o sì la ọpọlọpọ ariyanjiyan já. . . .
“Kii ṣe titi di ọgọrun-un ọdun kẹrin ni a tó mu iyatọ gédégédé awọn mẹtẹẹta ati iṣọkan wọn papọ ninu ẹkọ kanṣoṣo ti gbogbo eniyan tẹwọgba ti ipilẹ kan ati ẹni mẹta.”10
Iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa New Catholic Encyclopedia ṣe alaye ti o farajọra niti ipilẹṣẹ Mẹtalọkan pe:
“Ni apa ọdọ awọn alálàyé ati awọn ẹlẹkọọ isin Bibeli papọ pẹlu iye awọn Roman Katoliki ti npọ sii, mímọ̀ naa wà pe ẹni kan kò gbọdọ sọrọ nipa igbagbọ Mẹtalọkan ninu Majẹmu Titun laini ẹ̀rí ìtóótun pataki. Mímọ̀ ti o báradọ́gba pẹkipẹki naa wà pẹlu ni apa ọdọ awọn opitan ẹlẹkọọ gbà á bẹẹ ati awọn ẹlẹkọọ isin oníṣísẹ̀-ntẹ̀lé pe nigba ti ẹnikan ba sọrọ nipa ẹkọ Mẹtalọkan alaini ẹ̀rí títóótun, ẹni naa ti ṣí lọ kuro ni sáà akoko ipilẹṣẹ Kristẹni, ki a sọ pe si ọdun mẹẹdọgbọn ti ó kẹhin ọgọrun-un ọdun kẹrin. O jẹ nigba naa nikan ni ohun ti a lè pe ni ẹkọ gbà á bẹẹ ti Mẹtalọkan pato naa ‘Ọlọrun kan ninu Ẹni mẹta’ di eyi ti a gbà wọnu igbesi-aye ati ironu Kristẹni daradara. . . .
“Ìhùmọ̀ naa funraarẹ ko ṣagbeyọ ero oju ẹsẹ ti sáà akoko ipilẹṣẹ naa; ó jẹ eso imugberu ẹkọ ọlọgọrun-un ọdun mẹta.”11
O Ha Jẹ “Àpẹ́sọ” Bi?
Awọn onigbagbọ Mẹtalọkan lè sọ pe Bibeli “pẹ́” Mẹtalọkan “sọ”. Ṣugbọn ọrọ idaloju yii ni a ṣe ni akoko gigun lẹhin ti a ti kọ Bibeli. O jẹ igbidanwo lati fa ohun ti awọn alufaa ṣọọṣi ti akoko pipẹ fi agbara pinnu pe ó jẹ ẹkọ igbagbọ yọ lati inu Bibeli.
Beere lọwọ araarẹ: Eeṣe ti Bibeli yoo wulẹ fi “pẹ́” ẹkọ rẹ̀ ti ó ṣe pataki julọ “sọ”—ẹni ti Ọlọrun jẹ́? Bibeli ṣe kedere lori awọn ẹkọ pataki miiran; eeṣe ti kò fi jẹ lori eyi, ọ̀kan ti ó ṣe pataki julọ? Ẹlẹdaa agbaye naa kò ha ni ṣe iwe kan ti o ṣe kedere lori jijẹ ti oun jẹ Mẹtalọkan bi iyẹn bá jẹ́ bẹẹ bi?
Idi ti Bibeli kò fi kọni ni ẹkọ Mẹtalọkan ni kedere rọrun: Kii ṣe ẹkọ Bibeli. Bi Ọlọrun bá ti jẹ́ Mẹtalọkan ni, oun iba ti mu un ṣe kedere ki Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ baa le fi kọ awọn ẹlomiran. Isọfunni ṣiṣekoko yẹn ni à bá sì ti fikun Ọrọ onimiisi ti Ọlọrun. A kì bá tí fi i silẹ fun awọn eniyan alaipe lati maa bá a wọ̀dìmú ni ọpọlọpọ ọdun lẹhin naa.
Nigba ti a ba ṣayẹwo awọn ẹsẹ iwe tí awọn ẹlẹkọọ Mẹtalọkan pese gẹgẹ bi ẹ̀rí pe Bibeli “pẹ́” Mẹtalọkan “sọ”, ki ni a rí? Iṣayẹwo alailabosi kan ṣipaya pe iwe mimọ ti a fifunni kò sọrọ nipa Mẹtalọkan ti Kristẹndọmu. Kaka bẹẹ, awọn ẹlẹkọọ igbagbọ gbiyanju lati fi ipa mu awọn ero Mẹtalọkan wọn ti wọn ti ní lọkan tẹlẹ wọnu iwe mimọ ni. Ṣugbọn awọn ero wọnni kò si ninu awọn ẹsẹ iwe mimọ. Nitootọ, awọn ero onigbagbọ Mẹtalọkan wọnni forigbari pẹlu ẹ̀rí ṣiṣe kedere ti Bibeli lodindi.
Apẹẹrẹ kan ti iru awọn ẹsẹ-iwe bẹẹ ni a rí ni Matiu 28:19, 20. Nibẹ Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ ni a mẹnukan papọ. Awọn kan fidaniloju sọ pe eyi dọgbọn tọkasi Mẹtalọkan. Ṣugbọn ka awọn ẹsẹ naa funraarẹ. Ohunkohun ha wà ninu awọn ẹsẹ-iwe wọnni ti o sọ pe awọn mẹtẹẹta jẹ Ọlọrun kan ti ó baradọgba ni ayeraye, agbara, ipo ati ọgbọn? Bẹẹkọ, kò sí ohun ti ó jọ bẹẹ. Bakan naa ni ó rí pẹlu awọn ẹsẹ-iwe miiran ti ó mẹnukan awọn mẹtẹẹta papọ.
Niti awọn wọnni ti wọn rí ìpẹ́sọ Mẹtalọkan ni Matiu 28:19, 20 ninu ìlò “orukọ” ni ẹlẹnikan fun Baba, Ọmọkunrin, ati ẹmi mimọ, jọwọ fiwe ìlò “orukọ,” ẹlẹnikan fun Aburahamu ni Jẹnẹsisi 48:16.—King James Version; New World Translation of the Holy Scriptures.
Awọn ẹlẹkọọ Mẹtalọkan tun tọka si Johanu 1:1 ninu awọn itumọ kan, nibi ti a ti sọrọ nipa “Ọrọ naa” gẹgẹ bi eyi ti ó wà “pẹlu Ọlọrun” ati gẹgẹ bi eyi ti ó jẹ́ “Ọlọrun.” Ṣugbọn awọn itumọ Bibeli miiran sọ pe Ọrọ naa jẹ́ “ọlọrun kan” tabi “ẹni bi Ọlọrun,” ti kò fi dandan tumọsi Ọlọrun ṣugbọn ẹnikan ti o lagbara. Siwaju sii, pe ẹsẹ Bibeli yẹn sọ pe “Ọrọ naa” wà “pẹlu” Ọlọrun. Lọna ti o bọgbọnmu iyẹn yoo yà á sọtọ kuro lara jíjẹ́ Ọlọrun yẹn kan naa. Ati laika ohun ti a pari ero sí nipa “Ọrọ naa,” otitọ naa ni pe kìkì awọn meji ni a mẹnukan ninu Joahnu 1:1, kii ṣe mẹta. Leralera, gbogbo awọn ẹsẹ-iwe ti a lò lati gbiyanju lati ti ẹkọ Mẹtalọkan lẹhin ni ó kùnà patapata lati ṣe bẹẹ nigba ti a ba fi ailabosi ṣayẹwo rẹ̀.a
Koko miiran lati gbeyẹwo ni eyi: Bi ẹkọ Mẹtalọkan ba jẹ́ eyi ti Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi kọni, nigba naa dajudaju awọn alufaa ṣọọṣi ti wọn gba ipo iwaju ti wọn dé kété lẹhin wọn ìbá tun ti fi kọni. Ṣugbọn awọn ọkunrin wọnni, ti a npe ni awọn Onkọwe lẹhin akoko awọn Apọsiteli, ha kọni ni ẹkọ Mẹtalọkan bi? Ibeere yii ni a o jiroro ninu Apá Keji ọ̀wọ́ yii ninu itẹjade Ilé-ìṣọ́nà ti yoo jade ni ọjọ iwaju
Awọn ìtọ́ka
1. The Catholic Encyclopedia, 1912, Ìdìpọ̀ Kẹẹdogun, oju-iwe 47.
2. The Baptist Encyclopædia, ti a tẹ̀ lati ọwọ William Cathcart, 1883, oju-iwe 1168, 1169.
3. A Short History of Christian Doctrine, lati ọwọ Bernhard Lohse, Itẹjade 1980, oju-iwe 53.
4. Ibid., oju-iwe 64, 65.
5. The Church Teaches, ti a tumọ ti a sì tẹ̀ lati ọwọ John F. Clarkson, S.J., John H. Edwards, S.J., William J. Kelly, S.J., ati John J. Welch, S.J., 1955, oju-iwe 125-127.
6. Ibid., oju-iwe 125.
7. The Triune God, lati ọwọ Edmund J. Fortman, Itẹjade 1982, oju-iwe 126.
8. On the Incarnation, ti a tumọ lati ọwọ Penelope Lawson, Itẹjade 1981, oju-iwe 27, 28.
9. The Encyclopedia of Religion, Mircea Eliade, ọ̀gá olutẹwe, 1987, Ìdìpọ̀ 15, oju-iwe 54.
10. The New Encyclopædia Britannica, Itẹjade Kẹẹdogun, 1985, Ìdìpọ̀ 11, Micropædia, oju-iwe 928.
11. New Catholic Encyclopedia, 1967, Ìdìpọ̀ Kẹrinla, oju-iwe 295.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun ijiroro ti o tubọ kúnrẹ́rẹ́ sii nipa iru awọn ẹsẹ iwe mimọ bẹẹ, wo iwe pẹlẹbẹ naa Should You Believe in the Trinity?, ti a tẹ̀ jade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Church at Tagnon, France