-
‘Ẹ Kọ́ Wọn Láti Pa Gbogbo Ohun Tí Mo Ti Pa Láṣẹ Fún Yín Mọ́’Ilé Ìṣọ́—2004 | July 1
-
-
‘Ẹ Kọ́ Wọn Láti Pa Gbogbo Ohun Tí Mo Ti Pa Láṣẹ Fún Yín Mọ́’
“Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—MÁTÍÙ 28:19, 20.
1. Ìjíròrò wo ló wáyé láàárín Fílípì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn àti ọkùnrin kan tó wá láti Etiópíà?
ỌKÙNRIN kan tó wá láti Etiópíà rin ìrìn àjò tó jìn gan-an wá sí Jerúsálẹ́mù. Ó wá síbẹ̀ láti wá sin Ọlọ́run tó fẹ́ràn, ìyẹn Jèhófà. Ó hàn gbangba pé ó tún nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Bó ṣe ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ padà lọ sílé tó ń ka ọ̀kan lára àwọn ìwé tí wòlíì Aísáyà kọ ni Fílípì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi lọ bá a. Fílípì béèrè lọ́wọ́ ará Etiópíà náà pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Ọkùnrin náà fèsì pé: “Báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Fílípì wá ran akẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ yìí lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi.—Ìṣe 8:26-39.
2. (a) Ọ̀nà wo ni ìdáhùn ará Etiópíà gbà nítumọ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo la óò gbé yẹ̀ wò tó ní í ṣe pẹ̀lú àṣẹ tí Kristi pa pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn?
2 Ìdáhùn ará Etiópíà yìí gba àfiyèsí gidi. Ó ní: “Báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ó nílò afinimọ̀nà, ìyẹn ẹnì kan tó máa fi ọ̀nà hàn án. Gbólóhùn yìí jẹ́ ká mọ ìjẹ́pàtàkì ìtọ́ni pàtó kan tó wà nínú àṣẹ tí Jésù pa pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Kí ni ìtọ́ni náà? Láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká máa bá àgbéyẹ̀wò wa lọ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù orí kejìdínlọ́gbọ̀n. Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú dá lórí àwọn ìbéèrè tó sọ pé kí nìdí? àti ibo ni? A óò wá gbé àwọn ìbéèrè méjì mìíràn yẹ̀ wò, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú àṣẹ tí Jésù pa pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àwọn ìbéèrè náà ni: kí ni? àti ìgbà wo?
“Ẹ Máa Kọ́ Wọn Láti Máa Pa Gbogbo Ohun . . . Mọ́”
3. (a) Báwo ni ẹnì kan ṣe ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi? (b) Sísọni di ọmọ ẹ̀yìn kan kíkọ́ni ní ohun wo?
3 Kí ni ó yẹ ká fi kọ́ni ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi? Àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, ohun tí Kristi pa láṣẹ la ní láti máa fi kọ́ni.a Àmọ́, kí la lè ṣe láti rí i dájú pé ẹni tá a kọ́ ní àwọn ohun tí Jésù pa láṣẹ yóò di ọmọ ẹ̀yìn, yóò sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀? A rí kókó kan nínú ọ̀nà tí Jésù gbà fara balẹ̀ yan àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lò. Ṣàkíyèsí pé, kò kàn sọ pé: ‘Ẹ máa kọ́ wọn ní gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 19:17) Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?
4. (a) Kí ni pípa àṣẹ kan mọ́ túmọ̀ sí? (b) Ṣàpèjúwe bá a ṣe ń kọ́ ẹnì kan láti pa àwọn àṣẹ Kristi mọ́.
4 Pípa àṣẹ kan mọ́ túmọ̀ sí pé “kéèyàn jẹ́ kí ìṣe òun” bá àṣẹ kan mu, kó ṣègbọràn sí i, tàbí kó pa á mọ́. Báwo la ṣe ń kọ́ ẹnì kan láti pa ohun tí Kristi pa láṣẹ mọ́ tàbí láti ṣègbọràn sí i? Tóò, ronú nípa ọ̀nà tí ẹni tí ń kọ́ni ní ọkọ̀ wíwà yóò gbà kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti pa àwọn òfin ìrìnnà mọ́. Olùkọ́ náà lè kọ́ àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní àwọn òfin ojú ọ̀nà nígbà tí wọ́n bá wà nínú kíláàsì. Àmọ́, tó bá wá fẹ́ kọ́ àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe máa pa àwọn òfin wọ̀nyẹn mọ́, ó ní láti máa tọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ́nà nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀ níbi tí mọ́tò pọ̀ sí kí àwọn náà sì máa sapá láti fi ohun tí wọ́n ti kọ́ sílò. Bákan náà, nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn àṣẹ Kristi la fi ń kọ́ wọn yẹn. Àmọ́, a tún ní láti máa tọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ́nà bí wọ́n ṣe ń sapá láti fi àwọn ìtọ́ni Kristi sílò nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́ àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. (Jòhánù 14:15; 1 Jòhánù 2:3) Nítorí náà, pípa àṣẹ Kristi tó sọ pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn mọ́ dáadáa, gba pé ká jẹ́ olùkọ́ àti afinimọ̀nà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò túmọ̀ sí pé à ń fara wé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ àti èyí tí Jèhófà fúnra rẹ̀ fi lélẹ̀.—Sáàmù 48:14; Ìṣípayá 7:17.
5. Kí nìdí tí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi lè máa lọ́ tìkọ̀ láti ṣègbọràn sí àṣẹ tí Kristi pa pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn?
5 Kíkọ́ àwọn èèyàn láti pa àwọn àṣẹ Jésù mọ́ kan ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa àṣẹ tó sọ pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn mọ́. Ìyẹn lè má rọrùn fún àwọn kan lára àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ akíkanjú nínú ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń lọ tẹ́lẹ̀, kò dájú pé àwọn tó jẹ́ olùkọ́ nínú àwọn ìsìn wọ̀nyẹn kọ́ wọn rí pé kí wọ́n lọ máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì kan jẹ́wọ́ pé tó bá kan ọ̀rọ̀ ti kíkọ́ agbo wọn láti di ajíhìnrere, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kùnà pátápátá nínú ìyẹn. Nígbà tí John R. W. Stott tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lórí àṣẹ tí Jésù pa pé ká lọ sínú ayé ká sì lọ ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn, ó sọ pé: “Kíkùnà tá a kùnà láti ṣègbọràn sí ohun tó wé mọ́ àṣẹ yìí ni olórí àìlera tí ẹ̀sìn Kristẹni ajíhìnrere ní nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìjíhìnrere tòde òní.” Ó fi kún un pé: “Ńṣe ló dà bíi pé à ń polongo ìhìn rere wa láti ọ̀nà jíjìn wá. Nígbà mìíràn, a máa ń ṣe bí àwọn tó tàdí mẹ́yìn sí etíkun tí wọ́n ń kígbe ìkìlọ̀ sí ẹni tí òkun ń gbé lọ. A ò bọ́ sínú omi náà ká lọ gbà wọ́n là. Ẹ̀rù ń bà wá pé kí aṣọ wa má lọ tutù.”
6. (a) Ọ̀nà wo la lè gbà fara wé àpẹẹrẹ Fílípì nígbà tá a bá ń ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bìkítà nígbà tí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù?
6 Tó bá jẹ́ pé inú ìsìn tí wọ́n ti “ń bẹ̀rù pé kí aṣọ àwọn má tútù” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ni ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà tẹ́lẹ̀, ó lè jẹ́ ìṣòro fún un láti borí ẹ̀rù omi tó ń bà á, kó lè ṣègbọràn sí àṣẹ tí Kristi pa pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò nílò ìrànlọ́wọ́. Nítorí náà, a ní láti ní sùúrù bá a ṣe ń fún un ní irú ìtọ́ni àti ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ kí òye rẹ̀ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, tó sì máa sún un ṣiṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ Fílípì ṣe la ará Etiópíà lóye tó sì sún un láti ṣe batisí. (Jòhánù 16:13; Ìṣe 8:35-38) Láfikún sí i, fífẹ́ tá a fẹ́ kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa àṣẹ láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn mọ́ yóò sún àwa náà láti máa bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ká lè tọ́ wọn sọ́nà nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Ìjọba Ọlọ́run.—Oníwàásù 4:9, 10; Lúùkù 6:40.
“Gbogbo Ohun”
7. Kíkọ́ àwọn èèyàn láti ‘pa gbogbo ohun tó pa láṣẹ mọ́’ kan kíkọ́ wọn ní àwọn àṣẹ wo?
7 Kì í ṣe bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun ṣe máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn nìkan la fi ń kọ́ wọn. Jésù sọ fún wa pé ká kọ́ àwọn èèyàn láti “pa gbogbo ohun” tó pa láṣẹ “mọ́.” Ó sì dájú pé àwọn àṣẹ títóbi jù lọ méjì wà lára wọn, ìyẹn ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn aládùúgbò wa. (Mátíù 22:37-39) Báwo la ṣe lè kọ́ ọmọ ẹ̀yìn tuntun pé kó pa àwọn àṣẹ wọ̀nyẹn mọ́?
8. Ṣàpèjúwe ọ̀nà tá a lè gbà fi àṣẹ tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ kọ́ ọmọ ẹ̀yìn tuntun kan.
8 Tún ronú nípa àpèjúwe ẹni tó ń kọ́ bá a ṣe ń wakọ̀. Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń wakọ̀ lójú ọ̀nà táwọn mọ́tọ̀ tí ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ tí ọ̀gá rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni akẹ́kọ̀ọ́ náà ń mọ béèyàn ṣe ń wakọ̀. Kì í ṣe pé yóò máa fetí sí ọ̀gá rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ á tún máa kíyè sí bí àwọn awakọ̀ yòókù ṣe ń wà á. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gá rẹ̀ lè tọ́ka sí awakọ̀ kan tó fi sùúrù jẹ́ kí awakọ̀ mìíràn wọlé síwájú òun níbi táwọn mọ́tò ti tẹ̀ léra wọn; tàbí awakọ̀ kan tó rọra dín iná ọkọ̀ rẹ̀ kù kó má bàa wọ àwọn awakọ̀ tó ń bọ̀ lójú; tàbí awakọ̀ kan tó ṣèrànwọ́ fún ojúlùmọ̀ rẹ̀ kan tí ọkọ̀ rẹ̀ bà jẹ́. Ńṣe ni irú àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyẹn ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà ní àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò tó lè lò nígbà tó bá ń wakọ̀. Bákan náà, ọmọ ẹ̀yìn tuntun kan tó ń rìnrìn àjò ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè kì í kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ olùkọ́ rẹ̀ nìkan, àmọ́ ó tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ rere tó ń rí nínú ìjọ.—Mátíù 7:13, 14.
9. Báwo ni ẹni tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn tuntun ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó túmọ̀ sí láti pa àṣẹ tó sọ pe ká máa fi ìfẹ́ hàn mọ́?
9 Bí àpẹẹrẹ, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lè ṣàkíyèsí òbí anìkàntọ́mọ kan tó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti kó àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó lè rí ẹnì kan tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò, síbẹ̀ tó ń wá sí gbogbo ìpàdé láìfi ìdààmú ọkàn rẹ̀ pè, ó tún lè rí àgbàlagbà kan tó jẹ́ opó tó sì ń gbé àwọn arúgbó bíi tirẹ̀ wá sí gbogbo ìpàdé ìjọ, tàbí ọ̀dọ́langba kan tó ń kópa nínú mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lè rí alàgbà ìjọ kan tó ń fi gbogbo ara mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù láìka ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ tó wà lọ́rùn rẹ̀ nínú ìjọ sí. Ó lè rí Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ aláàbọ̀ ara tí kò sì lè jáde nílé, àmọ́ tó jẹ́ orísun ìṣírí nípa tẹ̀mí fún gbogbo ẹni tó bá wá kí i nílé. Akẹ́kọ̀ọ́ náà lè kíyè sí tọkọtaya kan tí wọ́n ń ṣe àyípadà ńlá nínú ìgbésí ayé wọn kí wọ́n lè máa ṣètọ́jú àwọn òbí wọn tó ti di arúgbó. Nípa kíkíyèsí irú àwọn Kristẹni tó jẹ́ onínúure, tí wọ́n ń ranni lọ́wọ́, tí wọ́n sì ṣeé gbára lé bẹ́ẹ̀, ọmọ ẹ̀yìn tuntun yìí yóò tinú àpẹẹrẹ wọn mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣègbọràn sí àṣẹ Kristi pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò ẹni, àgàgà àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. (Òwe 24:32; Jòhánù 13:35; Gálátíà 6:10; 1 Tímótì 5:4, 8; 1 Pétérù 5:2, 3) Ní ọ̀nà yìí, ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìjọ Kristẹni lè jẹ́ olùkọ́ àti afinimọ̀nà, ohun tó sì yẹ kí wọ́n jẹ́ nìyẹn.—Mátíù 5:16.
“Títí Dé Ìparí Ètò Àwọn Nǹkan”
10. (a) Báwo ni àkókò tí a ó máa bá iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lọ yóò ti pẹ́ tó? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa irú ọwọ́ tó yẹ ká fi mú iṣẹ́ wa?
10 Títí di ìgbà wo ni a ó máa bá iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lọ? Títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan ni. (Mátíù 28:20) Ǹjẹ́ yóò ṣeé ṣe fún wa láti mú apá yìí ṣẹ nínú àṣẹ tí Jésù pa? Gẹ́gẹ́ bí ìjọ kan tó kárí ayé, a ti pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ní àwọn ọdún tó ti kọjá, a ti fi ayọ̀ lo àkókò wa, agbára wa, àti àwọn ohun ìní wa láti fi wá àwọn tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, lójoojúmọ́ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo ìpíndọ́gba ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jákèjádò ayé. A ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé. Òun ló sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 4:34) Ohun tó sì jẹ́ ìfẹ́ ọkàn àwa náà nìyẹn. (Jòhánù 20:21) Kì í ṣe pé a kàn fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tá a gbé lé wà lọ́wọ́ nìkan; àmọ́ a fẹ́ parí rẹ̀ pẹ̀lú.—Mátíù 24:13; Jòhánù 17:4.
11. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa bíi mélòó kan, ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
11 Àmọ́, inú wa máa ń bà jẹ́ tá a bá rí i pé àwọn kan lára àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ti rẹ̀wẹ̀sì nípa tẹ̀mí, tí ìyẹn sì sọ wọn di ẹni tó fà sẹ́yìn tàbí ẹni tí kò ṣègbọràn mọ́ sí àṣẹ Kristi pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè padà wá dara pọ̀ mọ́ ìjọ kí wọ́n sì tún máa kópa nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn? (Róòmù 15:1; Hébérù 12:12) Ọ̀nà tí Jésù gbà ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì fún àkókò díẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe lónìí.
Fìfẹ́ Hàn sí Wọn
12. (a) Kété ṣáájú kí Jésù tó kú, kí ni àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe? (b) Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ ṣe ohun tó fi wọ́n hàn bí aláìlera nípa tẹ̀mí?
12 Ní òpin ìgbà tí Jésù ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n fẹ́ pa á, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ “pa á tì, wọ́n sì sá lọ.” Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n “tú . . . ká, olúkúlùkù sí ilé tirẹ̀.” (Máàkù 14:50; Jòhánù 16:32) Kí ni Jésù ṣe sí ọ̀ràn àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tó ti di aláìlera nípa tẹ̀mí yìí? Kété lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ fún àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ, ẹ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi, kí wọ́n lè lọ sí Gálílì; wọn yóò sì rí mi níbẹ̀.” (Mátíù 28:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn àpọ́sítélì ṣe ti fi hàn pé wọ́n jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí, síbẹ̀ Jésù ṣì ń pè wọ́n ní “arákùnrin mi.” (Mátíù 12:49) Ó ṣì fọkàn tán wọn. Ní ọ̀nà yìí, a rí i pé Jésù jẹ́ aláàánú, ó sì ń dárí jini, bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú tó sì ń dárí jini. (2 Àwọn Ọba 13:23) Báwo la ṣe lè fara wé Jésù?
13. Ojú wo ló yẹ ká fi wo àwọn tó ti rẹ̀wẹ̀sì nípa tẹ̀mí?
13 Ó yẹ ká fi ìyọ́nú tó jinlẹ̀ hàn sí àwọn tó ti rẹ̀wẹ̀sì tàbí tí wọn ò kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù mọ́. A ṣì ń rántí àwọn iṣẹ́ onífẹ̀ẹ́ tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa wọ̀nyẹn ti ṣe sẹ́yìn, kódà àwọn kan ti ṣe iṣẹ́ yìí fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún pàápàá. (Hébérù 6:10) Àárò wọn sọ wá gan-an ni. (Lúùkù 15:4-7; 1 Tẹsalóníkà 2:17) Báwo ni ká ṣe wá fi hàn pé à ń ṣàníyàn nípa wọn?
14. Ní ṣíṣe àfarawé Jésù, báwo la ṣe lè ran àwọn aláìlera lọ́wọ́?
14 Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò pé kí wọ́n lọ sí Gálílì, wọ́n á sì rí òun níbẹ̀. Lẹ́nu kan, ńṣe ni Jésù pè wọ́n sí ìpàdé pàtàkì kan. (Mátíù 28:10) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, a máa ń pe àwọn tó ti rẹ̀wẹ̀sì nípa tẹ̀mí pé kí wọ́n wá sí àwọn ìpàdé ìjọ Kristẹni, ó sì lè ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ tá a máa gbà wọ́n níyànjú láti wá. Ní ti àwọn àpọ́sítélì, ìkésíni náà so èso rere, nítorí pé “àwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ́kànlá lọ sí Gálílì sí òkè ńlá níbi tí Jésù ti ṣètò fún wọn.” (Mátíù 28:16) Inú wa máa ń dùn gan-an nígbà tí àwọn aláìlera bá ṣe bẹ́ẹ̀ dáhùn ìpè wa tí wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni!—Lúùkù 15:6.
15. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa kíkí àwọn aláìlera nípa tẹ̀mí káàbọ̀ sí ibi ìpàdé wa?
15 Kí la máa ṣe nígbà tí Kristẹni kan tó ti di aláìlera bá tún padà wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba? Tóò, kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí i pé àwọn àpọ́sítélì òun tí ìgbàgbọ́ wọn ti jó rẹ̀yìn fúngbà díẹ̀ wá síbi tó sọ pé kí wọ́n ti wá pàdé òun? “Jésù sì sún mọ́ tòsí, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.” (Mátíù 28:18) Kò dúró sọ́ọ̀ọ́kán kó máa wò wọ́n, ńṣe ló lọ bá wọn. Fojú inú wo bí ọkàn àwọn àpọ́sítélì yẹn á ṣe balẹ̀ tó nígbà tí Jésù lo ìdánúṣe yẹn! Ẹ jẹ́ kí àwa náà lo irú ìdánúṣe bẹ́ẹ̀, ká kí àwọn tó ti rẹ̀wẹ̀sì nípa tẹ̀mí tọ̀yàyàtọ̀yàyà nígbà tí wọ́n bá sapá láti padà sínú ìjọ Kristẹni.
16. (a) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ irú ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn aláìlera? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
16 Kí ni Jésù tún ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, ó kéde pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi.” Èkejì, ó gbé iṣẹ́ kan lé wọn lọ́wọ́ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.” Ìkẹta, ó ṣe ìlérí kan fún wọn pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́.” Àmọ́, ǹjẹ́ o kíyè sí ohun tí Jésù kò ṣe? Kò bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà wí nítorí ìkùnà wọn àti nítorí pé wọ́n ṣiyèméjì. (Mátíù 28:17) Ǹjẹ́ ọ̀nà tó gbé ọ̀ràn náà gbà yìí gbéṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni o. Kò pẹ́ sí àkókò yẹn tí àwọn àpọ́sítélì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ “kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere” náà lẹ́ẹ̀kan sí i. (Ìṣe 5:42) Tá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa èrò tó yẹ ká ní sí àwọn aláìlera àti irú ọwọ́ tó yẹ ká fi mú wọn, àwa náà lè rí àbájáde tó dùn mọ́ni bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìjọ wa.b—Ìṣe 20:35.
“Mo Wà Pẹ̀lú Yín Ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”
17, 18. Okun wo la rí gbà látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún wa pé, “mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́”?
17 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kẹ́yìn yẹn pé, “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́,” jẹ́ okun fún gbogbo àwọn tó ń sapá láti mú àṣẹ tí Kristi pa pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣẹ. Àtakò èyíkéyìí táwọn ọ̀tá lè gbé dìde sí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe, ọ̀nà yòówù tí wọ́n lè fi bà wá lórúkọ jẹ́, kò sídìí tó fi yẹ ká bẹ̀rù. Nítorí kí ni? Jésù, Aṣáájú wa, tó ní ‘gbogbo ọlá àṣẹ ní ọ̀run òun ayé,’ wà pẹ̀lú wa láti tì wá lẹ́yìn!
18 Ìlérí tí Jésù ṣe pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́” tún jẹ́ orísun ìtùnú ńlá fún wa. Bá a ṣe ń sapá láti pa àṣẹ Jésù pé ká sọni di ọmọ ẹ̀yìn mọ́, kì í ṣe gbogbo ọjọ́ ni inú wa máa ń dùn, inú wa máa ń bà jẹ́ nígbà mìíràn. (2 Kíróníkà 6:29) Ìbànújẹ́ máa ń dorí àwọn kan lára wa kodò gan-an nígbà tí wọ́n bá ń ṣọ̀fọ̀ ikú èèyàn wọn kan. (Jẹ́nẹ́sísì 23:2; Jòhánù 11:33-36) Ọjọ́ ogbó ń bá àwọn kan fínra, nítorí pé okun àti agbára wọn ń dín kù. (Oníwàásù 12:1-6) Àwọn mìíràn sì wà tó jẹ́ pé ìdààmú ọkàn máa ń bá wọn fúngbà pípẹ́. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Àwọn tó sì pọ̀ lára wa ni awọ ò kájú ìlù fún rárá. Síbẹ̀síbẹ̀, à ń kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, nítorí pé Jésù wà pẹ̀lú wa “ní gbogbo àwọn ọjọ́,” títí kan àwọn ọjọ́ tí ìṣòro mù wá dọ́rùn pàápàá.—Mátíù 11:28-30.
-
-
‘Ẹ Kọ́ Wọn Láti Pa Gbogbo Ohun Tí Mo Ti Pa Láṣẹ Fún Yín Mọ́’Ilé Ìṣọ́—2004 | July 1
-
-
a Ìwé kan tọ́ka sí kókó tí Jésù sọ pé, “ẹ máa batisí wọn . . . ẹ máa kọ́ wọn,” kò sọ pé ‘ẹ máa batisí wọn, ẹ sì máa kọ́ wọn.’ Nítorí náà, àṣẹ láti batisí àti láti kọ́ni “kì í ṣe ohun méjì tó pọn dandan pé a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe ọ̀kan ká tó ṣe ìkejì.” Kàkà bẹ́ẹ̀, “kíkọ́ni jẹ́ ohun tí kì í dáwọ́ dúró, èyí tá a máa ń bá débì kan ṣáájú batisí . . . tá a sì máa ń ṣe lára rẹ̀ lẹ́yìn batisí.”
-