Àṣírí Tí Àwọn Kristẹni Kò Jẹ́ Pa mọ́!
“Mo ti bá ayé sọ̀rọ̀ ní gbangba. . . . Èmi kò sì sọ nǹkan kan ní ìkọ̀kọ̀.”—JÒHÁNÙ 18:20.
1, 2. Kí ni ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, my·steʹri·on, gẹ́gẹ́ bí a ti lò ó nínú Ìwé Mímọ́?
Ọ̀RỌ̀ Gíríìkì náà, my·steʹri·on, ni a túmọ̀ sí ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ nínú Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures nígbà 25, àti nígbà mẹ́ta sí “ohun ìjìnlẹ̀.” Ní tòótọ́, àṣírí kan tí a pè ní ọlọ́wọ̀ gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì! Ẹnikẹ́ni tí ó bá láǹfààní láti lóye irú àṣírí bẹ́ẹ̀ yẹ kí ó nímọ̀lára pé a bọlá fún òun gidigidi, níwọ̀n bí a ti kà á kún ẹni yíyẹ tí ó lè ṣàjọpín àṣírí kan pẹ̀lú Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ni àgbáálá ayé.
2 Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Expository Dictionary of Old and New Testament Words ti Vine, jẹ́rìí sí i pé, nínú ọ̀ràn tí ó pọ̀ jù lọ ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ jẹ́ ìtumọ̀ tí ó ṣe wẹ́kú ju “ohun ìjìnlẹ̀” lọ. Ó sọ ní ti my·steʹri·on pé: “Nínú [Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì], kì í ṣe ọ̀rọ̀ náà ohun ìjìnlẹ̀ ni ó túmọ̀ sí (gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ rẹ̀ ti jẹ́ ní èdè [Yorùbá]), bí kò ṣe ohun kan tí ó ré kọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn láti lóye, tí ó jẹ́ pé ìṣípayá Àtọ̀runwá nìkan ni ó lè sọ ọ́ di mímọ̀, a sì sọ ọ́ di mímọ̀ lọ́nà kan àti ní àkókò kan tí Ọlọ́run yàn, àti fún kìkì àwọn tí Ẹ̀mí Rẹ̀ là lóye. Ní bí a ṣe sábà máa ń lò ó, ohun ìjìnlẹ̀ túmọ̀ sí ìmọ̀ tí a sé mọ́wọ́; nígbà tí a bá lò ó nínú Ìwé Mímọ́ ó túmọ̀ sí òtítọ́ tí a ṣí payá. Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó so mọ́ kókó ọ̀rọ̀ yí ni ‘sọ di mímọ̀,’ ‘mú rọrùn láti lóye,’ ‘ṣí payá,’ ‘wàásù,’ ‘lóye,’ ‘ìpínkiri.’”
3. Báwo ni ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní ṣe yàtọ̀ sí àwọn ẹgbẹ́ ìsìn awo kan?
3 Àlàyé yìí ṣàfihàn ìyàtọ̀ pàtàkì tí ó wà láàárín àwọn ẹgbẹ́ ìsìn awo tí ó tàn kálẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní àti ìjọ Kristẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn tí a mú wọnú ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ ni a sábà máa ń fi ẹ̀jẹ́ bòókẹ́lẹ́ ká lọ́wọ́ kò láti dáàbò bo àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn, àwọn Kristẹni kò fìgbà kan rí sí lábẹ́ irú ìkálọ́wọ́kò bẹ́ẹ̀. Òtítọ́ ni pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ‘ọgbọ́n Ọlọ́run nínú àṣírí ọlọ́wọ̀ kan’ ní pípè é ní “ọgbọ́n tí a fi pa mọ́,” ìyẹn ni pé, a fi í pa mọ́ fún “àwọn olùṣàkóso ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí.” A kò fi í pa mọ́ fún àwọn Kristẹni, àwọn tí a ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run ṣí i payá fún, kí wọ́n baà lè sọ ọ́ dì mímọ̀ fáyé gbọ́.—Kọ́ríńtì Kíní 2:7-12; fi wé Òwe 1:20.
‘Àṣírí Ọlọ́wọ̀’ Náà Di Mímọ̀
4. Ọ̀dọ̀ ta ni ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ náà darí àfiyèsí sí, lọ́nà wo sì ni?
4 Ọ̀dọ̀ Jésù Kristi ni ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ Jèhófà darí àfiyèsí sí. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “[Jèhófà] sọ àṣírí [ọlọ́wọ̀] ìfẹ́ inú rẹ̀ di mímọ̀ fún wa. Ó jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere rẹ̀ èyí tí òun pète nínú ara rẹ̀ fún iṣẹ́ àbójútó kan ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀, èyíinì ni, láti tún kó ohun gbogbo jọ pa pọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé. Bẹ́ẹ̀ ni, nínú rẹ̀.” (Éfésù 1:9, 10) Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ túbọ̀ ṣe pàtó nípa ohun tí ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ náà jẹ́, nígbà tí ó tọ́ka sí ìjẹ́pàtàkì ‘ìmọ̀ pípéye nípa àṣírí ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run, èyíinì ni, Kristi.’—Kólósè 2:2.
5. Kí ni ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ náà ní nínú?
5 Ṣùgbọ́n, ó ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan nínú, nítorí ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ jẹ́ àṣírí alápá púpọ̀. Kì í ṣe kìkì dídá Jésù mọ̀ yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí Irú-Ọmọ náà tí a ṣèlérí tàbí Mèsáyà; ó kan ipa tí a yàn fún un láti kó nínú ète Ọlọ́run. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣàkóso ti ọ̀run, Ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ Mèsáyà, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣàlàyé ní kedere nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún láti lóye àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba àwọn ọ̀run, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọnnì ni a kò yọ̀ǹda fún.’—Mátíù 13:11.
6. (a) Èé ṣe tí ó fi tọ̀nà láti sọ pé ‘a ti pa àṣírí ọlọ́wọ̀ mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fún àwọn àkókò pípẹ́ títí’? (b) Báwo ni a ṣe ṣí i pa yá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé?
6 Àkókò gígùn jàn-ànràn jan-anran kan yóò wà láàárín ìgbà tí a kọ́kọ́ mẹ́nu kan ète Ọlọ́run láti pèsè ìpìlẹ̀ fún Ìjọba Mèsáyà àti mímú ‘àṣírí ọlọ́wọ̀ wá sí ìparí.’ (Ìṣípayá 10:7; Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Mímú un wá sí ìparí yóò ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ Ìjọba náà, gẹ́gẹ́ bí fífi Ìṣípayá 10:7 àti 11:15 wéra ti fi hàn. Ní tòótọ́, nǹkan bí 4,000 ọdún kọjá láti ìgbà tí a ti ṣèlérí àkọ́kọ́ nípa Ìjọba náà ní Édẹ́nì sí ìgbà tí Ọba Tí A Yàn náà fara hàn ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Kí a tó gbé Ìjọba náà kalẹ̀ ní ọ̀run ní 1914, 1,885 ọdún mìíràn tún kọjá. Nípa báyìí, a ṣí ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ náà payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé jálẹ̀ àkókò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 6,000 ọdún. (Wo ojú ìwé 16.) Pọ́ọ̀lù tọ̀nà ní tòótọ́ ní sísọ̀rọ̀ nípa ‘ìṣípayá àṣírí ọlọ́wọ̀ tí a ti pa mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fún àwọn àkókò pípẹ́ títí ṣùgbọ́n tí a ti fi hàn kedere nísinsìnyí tí a sì ti sọ di mímọ̀.’—Róòmù 16:25-27; Éfésù 3:4-11.
7. Èé ṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé pátápátá nínú ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú náà?
7 Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀dá ènìyàn, tí sáà ìwàláàyè wọn kò tó nǹkan, ojú kì í kán Jèhófà láti ṣí àṣírí rẹ̀ payá nígbà tí àkókò kò bá tí ì tó. Òkodoro òtítọ́ yìí yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹni tí ń kánjú nígbà tí a kò bá lè ṣàlàyé àwọn ìbéèrè Bíbélì kan lọ́nà tí ó tẹ́ wa lọ́rùn nísinsìnyí. Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà níhà ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú, tí a fàṣẹ yàn láti pèsè oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún agbo ilé Kristẹni, kì í jẹ́ kí ó kù gbù gbé ìgbésẹ̀, kí ó sì fi ìwàǹwára méfò nípa àwọn nǹkan tí kò tí ì ṣe kedere. Ẹgbẹ́ ẹrú náà ń tiraka láti má ṣe jẹ́ ẹni tí ojú ìwòye rẹ̀ kò ṣeé yí pa dà. Kò gbéraga débi tí kò ti ní gbà pé títí di ìsinsìnyí òun kò lè dáhùn gbogbo ìbéèrè, ní fífi Òwe 4:18 sọ́kàn dáadáa. Ṣùgbọ́n, ẹ wo bí ó ṣe múni lórí yá tó láti mọ̀ pé Jèhófà, ní àkókò tirẹ̀ àti ní ọ̀nà tirẹ̀, yóò máa bá a nìṣó láti ṣí àṣírí rẹ̀ payá ní ti àwọn ète rẹ̀! Kí a má ṣe di ẹni tí ń kánjú ní ti àwọn ìṣètò Jèhófà láé, ní fífi ìwà òmùgọ̀ sá síwájú Olùṣí àwọn àṣírí payá. Ẹ wo bí ó ti fini lọ́kàn balẹ̀ tó láti mọ̀ pé ipa ọ̀nà tí Jèhófà ń lò lónìí kì í ṣe bẹ́ẹ̀! Olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ni ní tòótọ́.—Mátíù 24:45; Kọ́ríńtì Kíní 4:6.
A Gbọ́dọ̀ Sọ Àṣírí Tí A Ti Ṣí Payá Náà Síta!
8. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé a óò sọ ‘àṣírí ọlọ́wọ̀ náà’ di mímọ̀?
8 Jèhófà kò ṣí ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ rẹ̀ payá fún àwọn Kristẹni pẹ̀lú ète pé kí wọ́n pa á mọ́. Wọ́n ní láti sọ ọ́ di mímọ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí Jésù là sílẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀—kì í ṣe fún kìkì àwùjọ àlùfáà díẹ̀: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú ńlá kan kò lè fara sin nígbà tí ó bá wà lórí òkè ńlá. Àwọn ènìyàn a tan fìtílà wọ́n a sì gbé e kalẹ̀, kì í ṣe sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, á sì tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín kí wọ́n sì lè fi ògo fún Bàbá yín tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run.”—Mátíù 5:14-16; 28:19, 20.
9. Kí ní fi hàn pé Jésù kì í ṣe aṣèyípadà tegbò tigaga, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ?
9 Jésù kò ní èrò ṣíṣe ìyípadà tegbò tigaga lọ́kàn, ti dídá àjọ abẹ́lẹ̀ ti àwọn ọmọlẹ́yìn tí ń lépa ète bòókẹ́lẹ́ sílẹ̀. Nínú ìwé Early Christianity and Society, Robert M. Grant kọ̀wé nípa ìgbèjà àwọn Kristẹni ìjímìjí tí agbèjà ìgbàgbọ́ ní ọ̀rúndún kejì, Justin Martyr, ṣe: “Bí àwọn Kristẹni bá jẹ́ aṣèyípadà tegbò tigaga, wọn yóò fara pa mọ́ kí ọwọ́ wọn baà lè tẹ góńgó wọn.” Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè “fara pa mọ́,” kí wọ́n sì tún dà bí “ìlú . . . tí ó wà lórí òkè” lọ́wọ́ kan náà? Wọn kò jẹ́ gbé fìtílà wọn pa mọ́ sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n! Nítorí náà, ìjọba kò ní ohunkóhun láti bẹ̀rù nípa ìgbòkègbodò wọn. Òǹkọ̀wé yìí ń bá a nìṣó láti ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí “alájọṣe dídára jù lọ fún olú ọba ní ti lílépa àlàáfíà àti ìwàlétòlétò.”
10. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni kò fi ní láti fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ pa mọ́?
10 Jésù kò fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun fi àṣírí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ẹ̀yà ìsìn kan pa mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sábà máa ń pè é. (Ìṣe 24:14; 28:22) Kíkùnà láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa mọ́lẹ̀ lónìí kì yóò mú inú Kristi àti Bàbá rẹ̀, Olùṣí àṣírí payá, dùn, kò sì ní mú kí a láyọ̀.
11, 12. (a) Èé ṣe tí Jèhófà fi fẹ́ kí a sọ ẹ̀sìn Kristẹni di mímọ̀? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ tí ó tọ́ lélẹ̀?
11 Jèhófà “kò ní ìfẹ́ ọkàn kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó ní ìfẹ́ ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (Pétérù Kejì 3:9; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:23; 33:11; Ìṣe 17:30) Ìpìlẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ronú pìwà dà ni ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, tí ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—kì í ṣe fún àwọn kéréje—kí “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà parun ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ó ṣe pàtàkì pé kí a ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ tí yóò mú kí wọ́n tóótun láti di ẹni tí a kà sí àgùntàn, kì í ṣe ẹni tí a kà sí ewúrẹ́, nígbà ìdájọ́ tí ń bọ̀.—Mátíù 25:31-46.
12 Ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe ẹ̀sìn tí a ń fi pa mọ́; a gbọ́dọ̀ sọ ọ́ di mímọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ó bá ṣeé ṣe. Jésù fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ tí ó yẹ lélẹ̀. Nígbà tí àlùfáà àgbà bi í ní ìbéèrè nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó wí pé: “Mo ti bá ayé sọ̀rọ̀ ní gbangba. Nígbà gbogbo ni mo ń kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì, níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọ pa pọ̀ sí; èmi kò sì sọ nǹkan kan ní ìkọ̀kọ̀.” (Jòhánù 18:19, 20) Lójú ìwòye àpẹẹrẹ ìṣáájú yìí, olùbẹ̀rù Ọlọ́run wo ni ó tó bẹ́ẹ̀ láti pa ohun tí Ọlọ́run sọ pé kí a sọ fáyé gbọ́ mọ́ ní bòókẹ́lẹ́? Ta ni yóò jẹ́ fi “kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀” tí ó ṣí ọ̀nà sí ìyè ayérayé pa mọ́? Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ó dà bí àwọn àgàbàgebè onísìn ní ọ̀rúndún kìíní.—Lúùkù 11:52; Jòhánù 17:3.
13. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a wàásù ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ bá ṣí sílẹ̀?
13 Ǹjẹ́ kí ó má ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láé láti sọ pé àwa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pa ìhìn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run mọ́ ní bòókẹ́lẹ́! Yálà wọ́n tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ náà tàbí wọn kò tẹ́wọ́ gbà á, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ pé a ti wàásù rẹ̀. (Fi wé Ìsíkẹ́ẹ̀lì 2:5; 33:33.) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a lo gbogbo àǹfààní tí a ní láti sọ ìhìn iṣẹ́ òtítọ́ fún gbogbo ènìyàn, níbikíbi tí a bá ti bá wọn pàdé.
Fífi Ìwọ̀ Kọ́ Ẹ̀rẹ̀kẹ́ Sátánì
14. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a lọ́ tìkọ̀ nípa jíjọ́sìn ní gbangba?
14 Ní ọ̀pọ̀ ibi, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ ń di ìfojúsùn fún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn. Ní ìfarajọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni ìjímìjí, a sábà máa ń fi wọ́n hàn lọ́nà òdì, a sì ń fojú tí a fi ń wo àwọn ẹgbẹ́ awo ìsìn àti ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ tí a lè gbé ìbéèrè dìde sí wò wọ́n. (Ìṣe 28:22) Jíjẹ́ ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ìwàásù wa ní gbangba ha lè sọ wa di ẹni tí a túbọ̀ ń ta kò bí? Dájúdájú yóò jẹ́ ìwà òmùgọ̀, kò sì ní bá ìmọ̀ràn Jésù mu, láti ti ara wa sínú awuyewuye láìnídìí. (Òwe 26:17; Mátíù 10:16) Ṣùgbọ́n, a kò gbọdọ̀ fi àǹfààní iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba àti ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i pa mọ́. Ó ń fi ògo fún Jèhófà, ó ń gbé e ga, ó ń darí àfiyèsí sí i àti sí Ìjọba rẹ̀ tí ó gbé kalẹ̀. Ìdáhùnpadà tí ń tẹ́ni lọ́rùn sí òtítọ́ Bíbélì ní Ìlà Oòrùn Europe àti ní àwọn apá ibì kan ní Áfíríkà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, lápá kan ti jẹ́ nítorí títúbọ̀ lè wàásù òtítọ́ náà ní gbangba níbẹ̀.
15, 16. (a) Ète wo ni wíwàásù tí a ń wàásù ní gbangba àti aásìkí tẹ̀mí wa ń ṣiṣẹ́ fún, ṣùgbọ́n ó ha yẹ kí èyí fa ìdààmú bí? (b) Èé ṣe tí Jèhófà fi fi ìwọ̀ kọ́ ẹ̀rẹ̀kẹ́ Sátánì?
15 Òtítọ́ ni pé ìwàásù Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbangba, párádísè tẹ̀mí tí wọ́n ń gbádùn, àti aásìkí wọn—ní ti ìtìlẹ́yìn ẹ̀dá ènìyàn àti ní ti dúkìá ti ara—ni a ń kíyè sí. Bí ó tilẹ̀ ń fa àwọn aláìlábòsí ọkàn mọ́ra, àwọn kókó abájọ wọ̀nyí lè bí àwọn alátakò nínú. (Kọ́ríńtì Kejì 2:14-17) Ní tòótọ́, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, èyí lè sún agbo ọmọ ogun Sátánì láti gbéjà ko àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
16 Ó ha yẹ kí èyí kó àníyàn bá wa bí? Ìyẹn kò ní bá àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà tí a rí nínú Ìsíkẹ́ẹ̀lì orí 38 mu. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé, Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù, tí ó dúró fún Sátánì Èṣù láti ìgbà tí a ti rẹ̀ ẹ́ nípò wálẹ̀ sí sàkání ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìgbékalẹ̀ Ìjọba ní 1914, yóò ṣáájú gbígbéjà ko àwọn ènìyàn Ọlọ́run. (Ìṣípayá 12:7-9) Jèhófà sọ fún Gọ́ọ̀gù pé: “Ìwọ óò sì wí pé, èmi óò gòkè lọ sí ilẹ̀ ìletò tí kò ní odi: èmi óò tọ àwọn tí ó wà ní ìsinmi lọ, tí wọ́n ń gbé láìbẹ̀rù, tí gbogbo wọn ń gbé láìsí odi, tí wọn kò sì ní agbàrà irin tàbí ẹnu odi. Láti lọ kó ìkógun, àti láti lọ mú ohun ọdẹ; láti yí ọwọ́ rẹ sí ibi ahoro wọnnì tí a tẹ̀ dó nísinsìnyí, àti sí ènìyàn tí a kó jọ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè wá, àwọn tí ó ti ní ohun ọ̀sìn àti ẹrù, tí ń gbé òkè ilẹ̀ náà.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:11, 12) Ṣùgbọ́n, ẹsẹ 4 fi hàn pé kò sí ìdí kankan fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run láti bẹ̀rù ìgbéjàkò yí, nítorí pé, iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà ni. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí Ọlọ́run yóò fi yọ̀ǹda—bẹ́ẹ̀ ni, àní tí yóò tilẹ̀ tún súnná sí—sísa gbogbo ipa láti gbéjà ko àwọn ènìyàn rẹ̀? A ka ìdáhùn Jèhófà ní ẹsẹ 23 pé: “Èmi óò sì gbé ara mi lékè, èmi óò sì ya ara mi sí mímọ́; èmi óò sì di mímọ̀ lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè; wọn óò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”
17. Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ìgbéjàkò Gọ́ọ̀gù tí ó sún mọ́lé?
17 Nípa báyìí, kàkà tí wọn yóò fi jẹ́ kí ìgbéjàkò Gọ́ọ̀gù kó jìnnìjìnnì bá wọn, àwọn ènìyàn Jèhófà ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún àfikún ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yí. Ẹ wo bí ó ti múni lọ́kàn yọ̀ tó láti mọ̀ pé nípa mímú aásìkí àti ìbùkún dé bá ètò àjọ rẹ̀ tí a lè fojú rí, Jèhófà ń fi ìwọ̀ kọ́ ẹ̀rẹ̀kẹ́ Sátánì, ó sì ń wọ́ òun pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbo ọmọ ogun rẹ̀ tuurutu lọ sí ibi tí a óò ti ṣẹ́gun wọn!—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 38:4.
Wọ́n Ń Ṣe É Nísinsìnyí Ju Ti Ìgbàkigbà Rí Lọ!
18. (a) Kí ni ohun tí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá mọ̀ nísinsìnyí, èé sì ti ṣe? (b) Báwo ni ìdáhùnpadà sí ìwàásù Ìjọba ṣe wá jẹ́ ìsúnniṣe tí ó lágbára?
18 Ní òde òní, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti sọ ojú ìwòye wọn tí a gbé ka Bíbélì jáde ní gbangba, àní bí ọ̀pọ̀ kò tilẹ̀ fẹ́ ẹ. Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, wọ́n ti kìlọ̀ nípa ewu tí ń bẹ nínú sìgá mímu àti ìjoògùnyó, ojú ìwòye tí ó kúrú ní ti kíkẹ́ ọmọ lákẹ̀ẹ́bàjẹ́, agbára ìdarí búburú ti eré ìnàjú tí ó kún fún ìbálòpọ̀ tí ó lòdì sófin àti ìwà ipá, àti ewu gbígba ẹ̀jẹ̀ sára. Wọ́n tún ti tọ́ka sí àìbáramu tí ó wà nínú àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí i ń sọ nísinsìnyí pé, “Òtítọ́ mà ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ.” Ká ní a kò ti jẹ́ ẹni tí kì í ṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́, ní sísọ ojú ìwòye wa jáde ní gbangba ni, wọn kò ní lè sọ ohun tí wọ́n sọ yìí. Má sì ṣe gbójú fo òtítọ́ náà dá pé ní sísọ irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ jáde, wọ́n ń gbé ìgbésẹ̀ síhà sísọ pé, “Sátánì, òpùrọ́ ni ọ́; àṣé Jèhófà ni ó tọ̀nà.” Ẹ wo irú ìsúnniṣe lílágbára tí èyí jẹ́ fún wa láti máa bá a nìṣó láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ní sísọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní gbangba!—Òwe 27:11.
19, 20. (a) Ìpinnu wo ni àwọn ènìyàn Jèhófà sọ jáde ní 1922, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ha ṣì ṣeé fi sílò lónìí bí? (b) Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ Jèhófà?
19 Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni àwọn ènìyàn Jèhófà ti mọ ẹrù iṣẹ́ wọn níhà yí. Ní àpéjọpọ̀ mánigbàgbé kan ní 1922, J. F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, ru ìmọ̀lára àwùjọ rẹ̀ sókè ní sísọ pé: “Ẹ ṣe gírí, ẹ wà lójúfò, ẹ tara ṣàṣà, ẹ jẹ́ onígboyà. Ẹ jẹ́ ẹlẹ́rìí tòótọ́, tí ó ṣe é gbára lé fún Olúwa. Ẹ máa bá ìjà náà nìṣó títí a óò fi sọ gbogbo àwókù Bábílónì di ahoro. Ẹ polongo ìhìn iṣẹ́ náà jákè jádò. Ayé gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run àti pé, Jésù Kristi ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa. Ọjọ́ gbogbo àwọn ọjọ́ ni èyí. Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń jọba! Ẹ̀yin ni aṣojú tí ń polongo rẹ̀. Nítorí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.”
20 Bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bá ṣe pàtàkì ní 1922, ẹ wo bí yóò ti ṣe pàtàkì tó ní ọdún 75 lẹ́yìn náà, nígbà tí ìṣípayá Kristi gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ àti Olùgbẹ̀san ti túbọ̀ sún mọ́lé! Ìhìn iṣẹ́ Ìjọba Jèhófà tí a gbé kalẹ̀ àti ti párádísè tẹ̀mí tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń gbádùn jẹ́ ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ tí ó kọyọyọ ju ohun tí a lè fi pa mọ́ lọ. Gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ti sọ ní kedere, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́rìí “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé” nípa ipò pàtàkì tí ó dì mú nínú ète ayérayé Jèhófà. (Ìṣe 1:8; Éfésù 3:8-12) Ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run tí ń ṣí àṣírí payá, a kò jẹ́ pa àṣírí yìí mọ́ sọ́dọ̀ ara wa!
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ náà?
◻ Báwo ni a ṣe mọ̀ pé ó yẹ kí a polongo rẹ̀?
◻ Kí ní mú ìgbéjàkò Gọ́ọ̀gù lòdì sí àwọn ènìyàn Jèhófà wá, ojú wo sì ni ó yẹ kí a fi wo èyí?
◻ Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yẹ kí ó pinnu láti ṣe?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
‘Àṣírí Ọlọ́wọ̀’ Tí A Sí Payá ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé
◻ Lẹ́yìn Ọdún 4026 Ṣááju Sànmánì Tiwa: Ọlọ́run ṣèlérí gbígbé Irú-Ọmọ kan dìde láti pa Sátánì run.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15
◻ Ọdún 1943 Ṣááju Sànmánì Tiwa: A fìdí májẹ̀mú Ábúráhámù múlẹ̀, ní ṣíṣèlérí pé Irú-Ọmọ náà yóò tipasẹ̀ Ábúráhámù wá.—Jẹ́nẹ́sísì 12:1-7
◻ Ọdún 1918 Ṣááju Sànmánì Tiwa: Ìbí Aísíìkì gẹ́gẹ́ bí ajogún májẹ̀mú.—Jẹ́nẹ́sísì 17:19; 21:1-5
◻ c. Ọdún 1761 Ṣááju Sànmánì Tiwa: Jèhófà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Irú-Ọmọ náà yóò tipasẹ̀ Jákọ́bù ọmọkùnrin Aísíìkì wá.—Jẹ́nẹ́sísì 28:10-15
◻ Ọdún 1711 Ṣááju Sànmánì Tiwa: Jákọ́bù fi hàn pé Irú-Ọmọ náà yóò tipasẹ̀ ọmọkùnrin rẹ̀, Júdà, wá.—Jẹ́nẹ́sísì 49:10
◻ Ọdún 1070 sí 1038 Ṣááju Sànmánì Tiwa: Ọba Dáfídì gbọ́ pé Irú-Ọmọ náà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ òun, yóò sì ṣàkóso títí láé gẹ́gẹ́ bí Ọba.—Sámúẹ́lì Kejì 7:13-16; Orin Dáfídì 89:35, 36
◻ Ọdún 29 sí 33 Sànmánì Tiwa: A fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí Irú-Ọmọ náà, Mèsáyà, onídàájọ́ ní ọjọ́ ọ̀la, àti Ọba Tí A Yàn.—Jòhánù 1:17; 4:25, 26; Ìṣe 10:42, 43; Kọ́ríńtì Kejì 1:20; Tímótì Kíní 3:16
◻ Jésù ṣí i payá pé òun yóò ní àwọn ajùmọ̀ṣàkóso àti ajùmọ̀ṣèdájọ́, pé Ìjọba ọ̀run yóò ní àwọn ọmọ abẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, àti pé gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwàásù Ìjọba.—Mátíù 5:3-5; 6:10; 28:19, 20; Lúùkù 10:1-9; 12:32; 22:29, 30; Jòhánù 10:16; 14:2, 3
◻ Jésù ṣí i payá pé a óò gbé Ìjọba náà kalẹ̀ ní àkókò kan pàtó, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé ṣe jẹ́rìí sí i.—Mátíù 24:3-22; Lúùkù 21:24
◻ Ọdún 36 Sànmánì Tiwa: Pétérù mọ̀ pé àwọn tí kì í ṣe Júù yóò di ajùmọ̀jogún Ìjọba náà pẹ̀lú.—Ìṣe 10:30-48
◻ Ọdún 55 Sànmánì Tiwa: Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a óò jí àwọn ajùmọ̀jogún Ìjọba ọ̀run náà dìde sí ipò àìleèkú àti àìdíbàjẹ́ nígbà wíwàníhìn-ín Kristi.—Kọ́ríńtì Kíní 15:51-54
◻ Ọdún 96 Sànmánì Tiwa: Jésù, tí ó ti ń ṣàkóso lórí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró, ṣí i payá pé iye wọn pátá yóò jẹ́ 144,000.—Éfésù 5:32; Kólósè 1:13-20; Ìṣípayá 1:1; 14:1-3
◻ Ọdún 1879 Sànmánì Tiwa: Ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower tọ́ka sí 1914 gẹ́gẹ́ bí ọdún tí ó ṣe pàtàkì gidigidi nínú ṣíṣàṣeparí ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ Ọlọ́run
◻ Ọdún 1925 Sànmánì Tiwa: Ile-Iṣọ Na ṣàlàyé pé a bí Ìjọba náà ní 1914; a gbọ́dọ̀ polongo ‘àṣírí ọlọ́wọ̀’ nípa Ìjọba náà.—Ìṣípayá 12:1-5, 10, 17
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wọn, Jésù, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń polongo Ìjọba Jèhófà ní gbangba