Ọ̀rọ̀ Tó Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀ Látinú Lẹ́tà Èdè Hébérù Tó Kéré Jù Lọ
Ǹjẹ́ ó lè dá wa lójú pé gbogbo àwọn ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ? Ó dá Jésù lójú, ohun tó sì fi kọ́ àwọn èèyàn jẹ́ kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Wo àpèjúwe tó sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè, tó wà ní Mátíù 5:18: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò tètè kọjá lọ jù kí lẹ́tà kan tí ó kéré jù lọ tàbí kí gínńgín kan lára lẹ́tà kan kọjá lọ kúrò nínú Òfin lọ́nàkọnà kí ohun gbogbo má sì ṣẹlẹ̀.”
Lẹ́tà tó kéré jù lọ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù ni י (yod), òun sì ni lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù, ìyẹn Jèhófà.a Láfikún sí ọ̀rọ̀ àti àwọn lẹ́tà inú Òfin Ọlọ́run, àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí ka “gínńgín kan lára lẹ́tà” náà sí pàtàkì.
Jésù sọ pé ó ṣeé ṣe kí ọ̀run àti ayé kọjá lọ ju kí èyí tó kéré jù lọ nínú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ Òfin lọ láìṣẹ. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó dá wa lójú pé ọ̀run àti ayé tá a lè fi ojú rí yìí máa wà títí láé. (Sáàmù 78:69) Ọ̀rọ̀ ńlá tí Jésù sọ yìí fi hàn pé èyí tó kéré jù lọ nínú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ inú Òfin kò ní lọ láìṣẹ.
Ǹjẹ́ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó kéré gan-an tiẹ̀ ṣe pàtàkì lójú Jèhófà Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ ni. Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé wọn ò gbọ́dọ̀ fọ́ egungun ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá. (Ẹ́kísódù 12:46) Ó jọ pé kúlẹ̀kúlẹ̀ òfin yìí kéré. Ǹjẹ́ wọ́n mọ ìdí tí wọn ò fi gbọ́dọ̀ fọ́ èyíkéyìí lára àwọn egungun náà? Kò dájú pé wọ́n mọ̀ ọ́n. Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ ni àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ inú òfin yìí, èyí tó túmọ̀ sí pé wọn ò ní ṣẹ́ èyíkéyìí lára egungun Mésáyà nígbà tí wọ́n bá pa á lórí igi oró.—Sáàmù 34:20; Jòhánù 19:31-33, 36.
Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kọ́ wa? Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé gbogbo àwọn ìlérí Jèhófà Ọlọ́run ló máa ṣẹ pátá, títí dórí èyí tó kéré jù lọ. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ lèyí jẹ́ látinú lẹ́tà èdè Hébérù tó kéré jù lọ!
a Lẹ́tà tó kéré jù lọ nínú álífábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì ni iota, ẹ̀rí sì fi hàn pé ó jọ lẹ́tà èdè Hébérù náà י (yod). Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́tà èdè Hébérù ni Jésù ń tọ́ka sí torí pé èdè Hébérù ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Òfin Mósè, èdè yẹn náà làwọn míì fi kà á.