Jèhófà—Orísun Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
“Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀.”—DIUTARÓNÓMÌ 32:4.
1. Èé ṣe tí ìfẹ́ wa fún ìdájọ́ òdodo fi jẹ́ àbínibí?
GAN-AN gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ àdámọ́ni pé kí olúkúlùkù nímọ̀lára pé a nífẹ̀ẹ́ òun, bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ àdámọ́ni pé kí gbogbo wa máa yán hànhàn fún ìdájọ́ òdodo. Gẹ́gẹ́ bí òṣèlú ará Amẹ́ríkà náà, Thomas Jefferson, ti kọ̀wé, “[ìdájọ́ òdodo] jẹ́ àdámọ́ni àti àbùdá, . . . ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀lára, ìríran, tàbí ìgbọ́ràn ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ wa.” Kò yani lẹ́nu, nítorí pé àwòrán ara rẹ̀ ni Jèhófà dá wa. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Àní, ó fi àwọn ànímọ́ tó ṣàgbéyọ àkópọ̀ ìwà tirẹ̀ jíǹkí wa, ọ̀kan lára ànímọ́ wọ̀nyí sì ni ìdájọ́ òdodo. Ìdí nìyẹn tí ìfẹ́ wa fún ìdájọ́ òdodo fi jẹ́ àbínibí, ìdí sì nìyẹn tí a fi ń hára gàgà láti gbé nínú ayé òdodo àti ti ìdájọ́ òdodo.
2. Báwo ni ìdájọ́ òdodo ti ṣe pàtàkì tó lójú Jèhófà, èé sì ti ṣe tó fi yẹ kí a mọ ìtumọ̀ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run?
2 Nípa Jèhófà, Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Diutarónómì 32:4) Ṣùgbọ́n nínú ayé tí àìṣèdájọ́ òdodo ti jàrábà yìí, kò rọrùn láti mòye ìtumọ̀ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, nípasẹ̀ ohun tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè mòye bí Ọlọ́run ti ń ṣe ìdájọ́ òdodo, kódà a lè wá túbọ̀ mọyì àwọn ọ̀nà àgbàyanu Ọlọ́run. (Róòmù 11:33) Lílóye ìtumọ̀ tí Bíbélì fún ìdájọ́ òdodo ṣe pàtàkì, nítorí pé èròǹgbà ẹ̀dá ènìyàn lè ti nípa lórí èrò wa nípa ìdájọ́ òdodo. Lójú ìwòye ènìyàn, a lè ronú pé ṣíṣe ìdájọ́ òdodo kò ju pé kí a kàn máa tẹ̀ lé òfin tí a là sílẹ̀. Tàbí gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ọgbọ́n orí náà, Francis Bacon, ti kọ̀wé, “ìdájọ́ òdodo wé mọ́ fífún olúkúlùkù ní ohun tó tọ́ sí i.” Ṣùgbọ́n o, ìdájọ́ òdodo Jèhófà tún nasẹ̀ ré kọjá ìyẹn.
Ìdájọ́ Òdodo Jèhófà Ń Mọ́kàn Yọ̀
3. Ẹ̀kọ́ wo ni a lè rí kọ́ bí a bá ṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a lò nínú Bíbélì fún òdodo àti ìdájọ́ òdodo?
3 A lè túbọ̀ lóye ibi tí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run nasẹ̀ dé nípa ṣíṣàgbéyẹ̀wò bí a ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ inú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ nínú Bíbélì.a Ó yẹ fún àfiyèsí pé, nínú Ìwé Mímọ́, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìyàtọ̀ láàárín òdodo àti ìdájọ́ òdodo. Àní, nígbà mìíràn a máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù náà bí ọ̀rọ̀ tó bára dọ́gba, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú Ámósì 5:24, níbi tí Jèhófà ti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ níyànjú pé: “Jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo tú jáde gan-an gẹ́gẹ́ bí omi, àti òdodo bí ọ̀gbàrá tí ń ṣàn nígbà gbogbo.” Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni gbólóhùn náà, “òdodo àti ìdájọ́ òdodo” fara hàn pa pọ̀ fún ìtẹnumọ́.—Sáàmù 33:5; Aísáyà 33:5; Jeremáyà 33:15; Ìsíkíẹ́lì 18:21; 45:9.
4. Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe ìdájọ́ òdodo, kí sì ni ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga jù lọ fún ìdájọ́ òdodo?
4 Èrò wo ni ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì wọ̀nyí gbìn síni lọ́kàn? Láti ṣe ìdájọ́ òdodo, nínú èrò tó bá Ìwé Mímọ́ mu, túmọ̀ sí láti ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Jèhófà ni ó fi àwọn òfin àti ìlànà ìwà híhù, tàbí ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ lélẹ̀, bí Jèhófà ṣe ń ṣe nǹkan ni ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga jù lọ fún ìdájọ́ òdodo. Ìwé náà, Theological Wordbook of the Old Testament, ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí a tú sí òdodo (tseʹdheq) “tọ́ka sí ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù, ó sì dájú pé nínú M[ájẹ̀mú] L[áéláé] ànímọ́ Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ni ọ̀pá ìdiwọ̀n yẹn.” Nípa báyìí, bí Ọlọ́run ṣe ń lo àwọn ìlànà rẹ̀, pàápàá jù lọ bí ó ṣe ń bá àwọn ènìyàn aláìpé lò, fi ohun tí òdodo àti ìdájọ́ òdodo jẹ́ gan-an hàn.
5. Àwọn ànímọ́ wo ló wé mọ́ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run?
5 Ìwé Mímọ́ fi hàn kedere pé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ń mọ́kàn yọ̀, kì í ṣe èyí tí ń léni sá, tí kì í sì í gba tẹni rò. Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.” (Sáàmù 37:28) Ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ń sún un láti dúró ti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí ó sì yọ́nú sí wọn. Ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run máa ń mú un wà lójúfò sí àìní wa, ó sì máa ń mú un ṣíjú àánú wò wá nítorí àìpé wa. (Sáàmù 103:14) Ìyẹn kò wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ń gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ìwà ibi, nítorí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ fífàyè gba àìṣèdájọ́ òdodo. (1 Sámúẹ́lì 3:12, 13; Oníwàásù 8:11) Jèhófà ṣàlàyé fún Mósè pé Òun jẹ́ ‘aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ẹni tí ń lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run múra tán láti dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá jini, síbẹ̀ kì í jẹ́ kí àwọn tí ìyà tọ́ sí lọ lọ́fẹ̀ẹ́.—Ẹ́kísódù 34:6, 7.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lò?
6 Nígbà tí a bá ṣe àṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe ń ṣe ìdájọ́ òdodo, kò yẹ kí a fojú òṣónú onídàájọ́, tí kò mọ̀ ju kí ó kàn máa pàṣẹ fífìyàjẹ àwọn oníwà àìtọ́ wò ó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ó yẹ kí a máa fojú baba onífẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n tí kò gbàgbàkugbà wò ó, ẹni tí ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ lò lọ́nà dídára jù lọ. Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Jèhófà, ìwọ ni Baba wa.” (Aísáyà 64:8) Gẹ́gẹ́ bí Baba olódodo tí ó mẹ̀tọ́, bí Jèhófà ti jẹ́ adúróṣinṣin ti ohun tí ó tọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló tún jẹ́ oníyọ̀ọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ tàbí ìdáríjì nítorí àwọn ipò lílékoko tàbí ti àìlera ti ẹran ara.—Sáàmù 103:6, 10, 13.
Mímú Ohun Tí Ìdájọ́ Òdodo Jẹ́ Ṣe Kedere
7. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ nípa ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run láti inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà? (b) Ipa wo ni Jésù kó nínú kíkọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nípa ìdájọ́ òdodo?
7 Bí ìdájọ́ òdodo Jèhófà ti kún fún ìyọ́nú tó ni wíwá Mèsáyà gbé yọ lákànṣe. Jésù kọ́ni ní ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, ó sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀. Ní kedere, ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run wé mọ́ fífi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn ènìyàn tí a ń fojú wọn gbolẹ̀. Nípa báyìí, wọn kò ní di ẹni tí a tẹ̀ rẹ́. Jésù, “ìránṣẹ́” Jèhófà, wá sí ilẹ̀ ayé láti “mú” apá yìí nípa ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run “ṣe kedere fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀, lékè gbogbo rẹ̀, nípa fífún wa ní àpẹẹrẹ tó jíire ní ti ohun tí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run túmọ̀ sí. Gẹ́gẹ́ bí “èéhù òdodo” ti Dáfídì Ọba, Jésù hára gàgà láti ‘wá ìdájọ́ òdodo, kí ó sì ṣe kánmọ́kánmọ́ nínú òdodo.’—Aísáyà 16:5; 42:1-4; Mátíù 12:18-21; Jeremáyà 33:14, 15.
8. Èé ṣe tí òdodo àti ìdájọ́ òdodo fi fara sin ní ọ̀rúndún kìíní?
8 Ó pọndandan ní pàtàkì láti mú ọ̀nà ìdájọ́ òdodo Jèhófà ṣe kedere ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Àwọn alàgbà àti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù—àwọn akọ̀wé, Farisí, àti àwọn mìíràn—pòkìkí ojú ìwòye òdì nípa òdodo àti ìdájọ́ òdodo ó sì hàn nínú wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, àwọn gbáàtúù, tí kò ṣeé ṣe fún láti dójú ìlà ohun tí àwọn akọ̀wé àti Farisí là sílẹ̀, wá lérò pé kò sí àrà tí àwọn lè dá tí àwọn fi lè kúnjú ìwọ̀n ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọ́run. (Mátíù 23:4; Lúùkù 11:46) Jésù fi hàn pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Lára àwọn gbáàtúù ni ó ti yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì kọ́ wọn ní ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọ́run.—Mátíù 9:36; 11:28-30.
9, 10. (a) Báwo ni àwọn akọ̀wé àti Farisí ṣe fi òdodo wọn hàn? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òtúbáńtẹ́ ni àṣà àwọn akọ̀wé àti Farisí, èé sì ti ṣe tí òun fi ṣe bẹ́ẹ̀?
9 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn Farisí ń wá ọ̀nà láti fi “òdodo” wọn ṣe ṣekárími nípa gbígbàdúrà tàbí ṣíṣe ìtọrẹ ní gbangba. (Mátíù 6:1-6) Wọ́n tún gbìyànjú láti ṣàṣehàn òdodo wọn nípa rírọ̀mọ́ àìlóǹkà òfin àti ìlànà—púpọ̀ nínú òfin wọ̀nyí sì jẹ́ àdábọwọ́ tiwọn. Gbogbo irú kùkùfẹ̀fẹ̀ bẹ́ẹ̀ sún wọn láti “gbójú fo ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 11:42) Lóde ara, wọ́n lè ti fara hàn bí olódodo, ṣùgbọ́n nínú lọ́hùn-ún, wọ́n ‘kún fún ìwà-àìlófin,’ tàbí àìṣòdodo. (Mátíù 23:28) Kí a sọ ọ́ ní ṣàkó, òye òdodo Ọlọ́run kò yé wọn.
10 Fún ìdí yìí, Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí òdodo yín kò bá pọ̀ gidigidi ju ti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí, lọ́nàkọnà ẹ kì yóò wọ ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 5:20) Ìyàtọ̀ tó hàn kedere láàárín ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run tí Jésù fi hàn nínú ìwà rẹ̀ àti ẹ̀mí ìṣòdodo lójú ara ẹni ti àwọn akọ̀wé àti Farisí aláìgbatẹnirò, ló ń fa awuyewuye ṣáá láàárín wọn.
Ìdájọ́ Òdodo Ọlọ́run àti Ìdájọ́ Tí A Gbé Gbòdì
11. (a) Èé ṣe tí àwọn Farisí fi béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù nípa wíwonisàn lọ́jọ́ Sábáàtì? (b) Kí ni ìdáhùn Jésù fi hàn?
11 Nígbà tí Jésù wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì ní ìgbà ìrúwé ọdún 31 Sànmánì Tiwa, ó tajú kán rí ọkùnrin kan nínú sínágọ́gù tí ọwọ́ rẹ̀ rọ. Níwọ̀n bí ọjọ́ yẹn ti jẹ́ ọjọ́ Sábáàtì, àwọn Farisí béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ó ha bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní sábáàtì bí?” Kàkà tí wọn ì bá fi káàánú ẹni ẹlẹ́ni tí ń jìyà yìí, ohun tí wọ́n máa fi kẹ́wọ́ kí wọ́n lè rí Jésù dá lẹ́bi ni wọ́n ń wá kiri, gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè wọn ti fi hàn. Abájọ tí ẹ̀dùn ọkàn fi bá Jésù nítorí yíyigbì ọkàn-àyà wọn! Nígbà náà ni òun náà wá béèrè irú ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ àwọn Farisí náà, ó ní: “Ó ha bófin mu ní sábáàtì láti ṣe iṣẹ́ rere?” Nígbà tí ẹnu wọ́n wọ̀ ṣin, Jésù wá dáhùn ìbéèrè tí òun alára gbé dìde nípa bíbéèrè lọ́wọ́ wọn bí wọn kò bá ní yọ àgùntàn tó jìn sínú kòtò ní ọjọ́ Sábáàtì.b Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí kò ṣeé já ní koro, ó ní: “Mélòómélòó ni ènìyàn fi ṣeyebíye ju àgùntàn lọ!” Ó kádìí rẹ̀ nípa sísọ pé: “Nítorí náà, ó bófin mu [tàbí, ó tọ̀nà] láti ṣe ohun tí ó dára púpọ̀ ní sábáàtì.” Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn kò gbọ́dọ̀ gbé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run dè. Lẹ́yìn tí Jésù ti la kókó yẹn yé wọn, ó wá tẹ̀ síwájú láti wo ọwọ́ ọkùnrin náà sàn.—Mátíù 12:9-13; Máàkù 3:1-5.
12, 13. (a) Yàtọ̀ pátápátá sí àwọn akọ̀wé àti Farisí, báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sí àtiṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run àti ìṣòdodo lójú ara ẹni?
12 Bí àwọn Farisí kò bá fi bẹ́ẹ̀ bìkítà fún àwọn aláàbọ̀ ara, wọn kò tilẹ̀ bìkítà rárá fún àwọn òtòṣì nípa tẹ̀mí. Ojú ìwòye òdì tí wọ́n ní nípa òdodo sún wọn láti fojú pa àwọn agbowó orí àti ẹlẹ́ṣẹ̀ rẹ́, wọ́n sì tẹ́ńbẹ́lú wọn. (Jòhánù 7:49) Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó dáhùn padà sí ẹ̀kọ́ Jésù, láìsí àní-àní nítorí pé wọ́n rí ìfẹ́ tó ní láti ranni lọ́wọ́ dípò dídánilẹ́jọ́. (Mátíù 21:31; Lúùkù 15:1) Àmọ́ ṣá o, ṣe ni àwọn Farisí bẹnu àtẹ́ lu gbogbo akitiyan tí Jésù ṣe láti wo àwọn tí ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí sàn. Wọ́n ń kùn lábẹ́lẹ̀ tẹ̀gàntẹ̀gàn pé: “Ọkùnrin yìí fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.” (Lúùkù 15:2) Nígbà tí Jésù máa dáhùn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, àpèjúwe olùṣọ́ àgùntàn ló tún lò. Gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń yọ̀ nígbà tó bá rí àgùntàn kan tó sọnù, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn áńgẹ́lì tí ń bẹ ní ọ̀run ń yọ̀ nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. (Lúùkù 15:3-7) Jésù alára yọ̀ nígbà tó ṣeé ṣe fún un láti ran Sákéù lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà kúrò ní ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ tó ń tọ̀ tẹ́lẹ̀. Ó ní: “Ọmọ ènìyàn wá láti wá kiri àti láti gba ohun tí ó sọnù là.”—Lúùkù 19:8-10.
13 Ìforígbárí wọ̀nyí fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, èyí tí ń wá ọ̀nà láti woni sàn, kí ó sì gbani là, àti ìṣòdodo lójú ara ẹni, èyí tí ń wá ọ̀nà láti gbé ìwọ̀nba àwọn kéréje ga, kí ó sì ka ọ̀pọ̀ èèyàn sí aláìwúlò hàn ní kedere. Ààtò asán àti àṣà àtọwọ́dá ènìyàn ti sọ àwọn akọ̀wé àti Farisí di agbéraga àti ajọra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n Jésù sọ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú pé wọ́n ti “ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́.” (Mátíù 23:23) Ǹjẹ́ kí a fara wé Jésù ní ṣíṣe ìdájọ́ òdodo nínú ohun gbogbo tí a bá ń ṣe, kí a sì tún yẹra fún ọ̀fìn jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni.
14. Báwo ni ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù ṣe fi hàn pé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ń gba ti ipò ẹni rò?
14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ko ka àwọn ìlànà àdábọwọ́ ara ẹni ti àwọn Farisí sí, síbẹ̀ ó pa Òfin Mósè mọ́. (Mátíù 5:17, 18) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kò wonkoko mọ́ títúmọ̀ Òfin òdodo yẹn lóréfèé, láìbìkítà fún àwọn ìlànà tó yí i ká. Nígbà tí obìnrin kan tí ìsun ẹ̀jẹ̀ fojú rẹ̀ rí nǹkan fún ọdún 12 fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, tó sì ríwòsàn, Jésù wí fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá; máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní àlàáfíà.” (Lúùkù 8:43-48) Ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn tí Jésù sọ fi hàn pé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run gba ti ipò obìnrin náà rò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ aláìmọ́, gẹ́gẹ́ bí ìlànà, tó sì jẹ́ pé bí a bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe òfíntótó, a lè sọ pé ó ti rú Òfin Mósè ní ti pé ó wà láàárín ọ̀pọ̀ èrò, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó gba èrè ìgbàgbọ́ rẹ̀.—Léfítíkù 15:25-27; fi wé Róòmù 9:30-33.
Òdodo Kò Yọ Ẹnikẹ́ni Sílẹ̀
15, 16. (a) Kí ni àkàwé Jésù nípa ará Samáríà aládùúgbò rere kọ́ wa nípa ìdájọ́ òdodo? (b) Èé ṣe tó fi yẹ kí a yẹra fún jíjẹ́ “olódodo àṣelékè”?
15 Ní àfikún sí títẹnumọ́ ọn pé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run kún fún ìyọ́nú, Jésù tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ó yẹ kí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn. Ète Jèhófà fún un ni láti ‘mú ìdájọ́ òdodo wá fún àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Aísáyà 42:1) Èyí ni kókó inú ọ̀kan lára àkàwé Jésù tó gbajúmọ̀ jù lọ, èyíinì ni àkàwé ará Samáríà aládùúgbò rere. Àkàwé náà jẹ́ èsì sí ìbéèrè tí ọkùnrin kan tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin gbé dìde, ọkùnrin yìí fẹ́ láti “fi ara rẹ̀ hàn ní olódodo.” Nítorí tí ó dájú pé ó fẹ́ láti fi ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aládùúgbò rere mọ sáàárín àwọn Júù, ó béèrè pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Ará Samáríà tí a mẹ́nu kàn nínú àkàwé Jésù jẹ́ olódodo lọ́nà ti Ọlọ́run, nítorí pé ó ṣe tán láti fi àkókò rẹ̀ àti owó rẹ̀ ṣèrànwọ́ fún àjèjì kan tó wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn. Jésù parí àkàwé rẹ̀ nípa gbígba oníbèéèrè náà nímọ̀ràn pé: “Kí ìwọ alára . . . máa ṣe bákan náà.” (Lúùkù 10:25-37) Bí àwa náà bá ń ṣe gbogbo èèyàn lóore, láìka ìran àti ẹ̀yà wọn sí, a óò máa ṣàfarawé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run.—Ìṣe 10:34, 35.
16 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àpẹẹrẹ àwọn akọ̀wé àti Farisí rán wa létí pé bí a óò bá ṣe ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, kò yẹ kí a jẹ́ “olódodo àṣelékè.” (Oníwàásù 7:16) Ṣíṣe ojú ayé, nípa fífi ara ẹni hàn bí olódodo lọ́nà ṣekárími tàbí wíwonkoko mọ́ àwọn òfin àtọwọ́dá ènìyàn kò ní mú ojú rere Ọlọ́run wá.—Mátíù 6:1.
17. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ pé kí a fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣèwà hù?
17 Ọ̀kan lára ìdí tí Jésù fi mú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣe kedere fún àwọn orílẹ̀-èdè ni kí gbogbo ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè mọ bí a ṣe ń fi ànímọ́ yìí ṣèwà hù. Èé ṣe tí èyí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé kí a “di aláfarawé Ọlọ́run,” gbogbo ọ̀nà Ọlọ́run sì jẹ́ ìdájọ́ òdodo. (Éfésù 5:1) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Míkà 6:8 ṣàlàyé pé ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà béèrè fún ni pé kí a máa “ṣe ìdájọ́ òdodo” bí a ti ń bá Ọlọ́run wa rìn. Síwájú sí i, Sefanáyà 2:2, 3, rán wa létí pé bí a bá fẹ́ kí a pa wá mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà, a ní láti “wá òdodo” kí ọjọ́ náà tó dé.
18. Àwọn ìbéèrè wo ni a óò dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
18 Nítorí náà, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko wọ̀nyí “gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà” láti máa ṣe ìdájọ́ òdodo. (2 Kọ́ríńtì 6:2) A lè ní ìdánilójú pé, gẹ́gẹ́ bí Jóòbù, bí a bá ‘fi òdodo wọ ara wa,’ tí a sì ‘fi ìdájọ́ òdodo ṣe aṣọ àwọ̀lékè wa tí kò lápá,’ Jèhófà yóò bù kún wa. (Jóòbù 29:14) Báwo ni ìgbàgbọ́ nínú ìdájọ́ òdodo Jèhófà yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ọjọ́ iwájú yóò dára? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí a ti ń dúró de “ilẹ̀ ayé tuntun” òdodo, báwo ni ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣe ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí? (2 Pétérù 3:13) Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ mẹ́ta pàtàkì ni a lò. Ọ̀kan lára wọn (mish·patʹ) ni a sábà máa ń tú sí “ìdájọ́ òdodo.” Méjì yòókù (tseʹdheq àti tsedha·qahʹ tí ó bá a tan) ni a tú sí “òdodo” lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “òdodo” (di·kai·o·syʹne) ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “jíjẹ́ ẹni tí ó tọ̀nà tàbí tí ó mẹ̀tọ́.”
b Ó dara gan-an tí a lo àpẹẹrẹ Jésù nítorí tí òfin àtẹnudẹ́nu àwọn Júù sọ ní pàtó pé kò sóhun tó burú níbẹ̀ bí wọ́n bá ṣèrànwọ́ fún ẹranko tó kó síṣòro lọ́jọ́ Sábáàtì. Ọ̀pọ̀ ìgbà mìíràn ni ìforígbárí wà lórí kókó kan náà yìí, èyíinì ni, bóyá ó bófin mu láti ṣèwòsàn lọ́jọ́ Sábáàtì.—Lúùkù 13:10-17; 14:1-6; Jòhánù 9:13-16.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ni ìtumọ̀ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run?
◻ Báwo ni Jésù ṣe kọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ní ìdájọ́ òdodo?
◻ Èé ṣe tí òdodo àwọn Farisí fi di èyí tí a gbé gbòdì?
◻ Èé ṣe tó fi pọndandan pé kí a máa ṣe ìdájọ́ òdodo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Jésù mú kí ibi tí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run nasẹ̀ dé ṣe kedere