-
Nígbà Tí Àwọn Adigunjalè Bá Ṣọṣẹ́Ilé Ìṣọ́—1998 | December 15
-
-
Nígbà Tí Àwọn Adigunjalè Bá Dé
Ṣùgbọ́n o, kí ni ṣíṣe bí àwọn olè bá rọ́nà bá wọ ilé rẹ, tí wọ́n sì kò ọ́ lójú? Rántí pé ẹ̀mí rẹ ṣe pàtàkì ju nǹkan ìní. Kristi Jésù sọ pé: “Má ṣe dúró tiiri lòdì sí ẹni burúkú; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí èkejì sí i pẹ̀lú. Bí ẹnì kan bá sì fẹ́ . . . gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ pẹ̀lú lọ sọ́wọ́ rẹ̀.”—Mátíù 5:39, 40.
Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n nìyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe dandan fún àwọn Kristẹni láti fún àwọn ọ̀daràn ní ìsọfúnni nípa dúkìá, ó jọ pé àwọn olè tètè máa ń yọwọ́ ìjà bí wọ́n bá rí i pé ẹnì kan ń ṣagídí, tí kò gbọ́rọ̀ sáwọn lẹ́nu, tàbí tó ń tàn wọ́n. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló tètè máa ń fìbínú hanni léèmọ̀, “níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.”—Éfésù 4:19.
Ilé fúláàtì ni Samuel ń gbé. Àwọn olè dí gbogbo ọ̀nà àbáwọ ilé náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti fúláàtì dé fúláàtì, wọ́n ń kẹ́rù. Samuel gbọ́ ìró ìbọn, ó gbọ́ ìró fífọ́ ilẹ̀kùn, ó sì gbọ́ tí àwọn èèyàn ń kígbe, tí wọ́n ń sunkún, tí wọ́n sì ń pohùnréré ẹkún. Ọ̀nà àjàbọ́ ò sí. Samuel sọ fún ìyàwó àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé kí wọ́n kúnlẹ̀, kí wọ́n káwọ́ sókè, kí wọ́n dijú, kí wọ́n sì máa retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Nígbà tí àwọn olè náà já wọlé, Samuel doríkodò bá wọn sọ̀rọ̀, ó mọ̀ pé bí òun bá wò wọ́n lójú, wọ́n lè rò pé òun yóò dá wọn mọ̀ lẹ́yìn náà. Ó sọ pé: “Ẹ wọlé. Ẹ kó gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́. Ẹ lè kó ohun tó bá wù yín. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a ò ní ṣagídí.” Ó ya àwọn olè náà lẹ́nu. Fún nǹkan bí wákàtí kan ni àwọn ọkùnrin méjìlá tó dira fi wọlé wá ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti owó àti àwọn ohun abánáṣiṣẹ́, wọn kò lu ìdílé náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ṣá wọn ládàá, bí wọ́n ti ṣe fún àwọn yòókù nínú ilé náà. Ìdílé Samuel dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀mí wọn.
Èyí fi hàn pé tó bá ti dọ̀ràn owó àti àwọn nǹkan ti ara, àwọn tí kò bá ṣagídí nígbà tí olè ń jà wọ́n lè dín èṣe tó lè wáyé kù.a
-
-
Nígbà Tí Àwọn Adigunjalè Bá Ṣọṣẹ́Ilé Ìṣọ́—1998 | December 15
-
-
a Ṣùgbọ́n o, ó ní ibi tí a lè gbọ́rọ̀ sí wọn lẹ́nu mọ. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kì í bá ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó bá rú òfin Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, Kristẹni kan kò kàn ní fínnúfíndọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún ìfipábánilòpọ̀.
-