Òpin Sí Ìkórìíra Jákèjádò Ayé
NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, ẹgbẹ́ àwùjọ tí ó kéré jùlọ kan jìyà ìkórìíra. Tertullian ṣàlàyé ìwà tí ó wọ́pọ̀ tí àwọn ará Romu hù sí àwọn Kristian ìjímìjí: “Bí ọ̀run kò bá rọ̀jò, bí ìmìtìtì-ilẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, bí ìyàn bá mú tàbí bí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, ìbòsí náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni pé, ‘Ẹ kó àwọn Kristian lọ fún àwọn kìnnìún láti pajẹ!’”
Láìka pé wọ́n jẹ́ ẹni tí a dójúsùn fún ìkórìíra sí, àwọn Kristian ìjímìjí gbéjàko ìdánwò náà láti gbẹ̀san àìṣèdájọ́ òdodo. Nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí Lórí Òkè, Jesu Kristi sọ pé: “Ẹ̀yin gbọ́ pé a wí i pé, ‘Iwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún ẹ̀yin pé: Ẹ máa bá a lọ lati máa nífẹ̀ẹ́ awọn ọ̀tá yín ati lati máa gbàdúrà fún awọn wọnnì tí ń ṣe inúnibíni sí yín.”—Matteu 5:43, 44.
Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù gbà pé ‘kíkórìíra ọ̀tá’ jẹ́ ohun tí ó tọ́ láti ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu sọ pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọ̀tá wa, kì í ṣe kìkì àwọn ọ̀rẹ́ wa. Èyí ṣòro ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe. Nínífẹ̀ẹ́ ọ̀tá kò túmọ̀ sí fífẹ́ràn gbogbo ọ̀nà rẹ̀ tàbí ìṣe rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a rí nínú àkọsílẹ̀ Matteu ni a fà yọ láti inú a·gaʹpe, tí ó ṣàpèjúwe ìfẹ́ tí ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà. Ẹni tí ń fi a·gaʹpe, ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà hàn, ń ṣe rere kódà sí ọ̀tá tí ó kórìíra rẹ̀ tí ó sì ń bá a lò lọ́nà àìtọ́. Èéṣe? Nítorí tí ó jẹ́ ọ̀nà láti ṣàfarawé Kristi, ó sì tún jẹ́ ọ̀nà láti ṣẹ́gun ìkórìíra. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Griki kan ṣàkíyèsí pé: “[A·gaʹpe] ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun ìtẹ̀sí àdánidá tí a ní fún ìbínú àti ìwà-kíkorò.” Ṣùgbọ́n èyí yóò ha gbéṣẹ́ nínú ayé òde-òní tí ó kún fún ìkórìíra bí?
A gbà pé, kì í ṣe gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ Kristian ni wọ́n pinnu láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi. Ìwà ìkà òǹrorò tí ó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí ní Rwanda ni a hù láti ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀yà-ìbílẹ̀ kan, tí ọ̀pọ̀ nínú mẹ́ḿbà rẹ̀ jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ Kristian. Pilar Díez Espelosín, obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti ìsìn Roman Katoliki tí ó ti ṣiṣẹ́ ní Rwanda fún 20 ọdún, sọ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ní ìyọrísí ńláǹlà. Ọkùnrin kan tí ó ń fi aṣóró kan tí ó dájú pé ó ń lò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀. Obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé náà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni o ń ṣe yìí tí o ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn láti pa àwọn ènìyàn? Ṣe o kò ronú nípa Kristi ni?” Ó jẹ́wọ́ pé òun ronú nípa rẹ̀ ó sì wọnú ṣọ́ọ̀ṣì, ó kúnlẹ̀, ó sì fi ìgbóná-ọkàn ka Àdúrà Mímọ́ Katoliki. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣetán, ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ láti máa bá ìpànìyàn nìṣó. Obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé náà jẹ́wọ́ pé: “Ó fi hàn pé a kò fi ìhìnrere kọ́ni dáradára.” Bí ó ti wù kí ó rí, irú ìkùnà bẹ́ẹ̀ kò fi hàn pé ìhìn-iṣẹ́ Jesu lábùkù. Àwọn tí wọ́n ń ṣe ìsìn Kristian tòótọ́ lè ṣẹ́gun ìkórìíra.
Ṣíṣẹ́gun Ìkórìíra Nínú Ibùdó Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́
Max Liebster jẹ́ Júù àbínibí tí ó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ àpèlé rẹ̀ túmọ̀ sí “àyànfẹ́,” ó ti rí ìkórìíra tirẹ̀ lọ́nà tí ó bùáyà. Ó ṣàpèjúwe ohun tí ó kọ́ nípa ìfẹ́ àti ìkórìíra ní Germany lábẹ́ ìṣàkòso Nazi.
“A tọ́ mí dàgbà nítòsí Mannheim, Germany, ní àwọn ọdún 1930. Hitler jẹ́wọ́ pé gbogbo àwọn Júù jẹ́ ọlọ́rọ̀ tí ń jèrè àjẹpajúdé tí ń kó àwọn ará Germany nífà. Ṣùgbọ́n òtítọ́ náà ni pé aṣebàtà lásán làsàn kan ni bàbá mi. Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí ipa ìdarí tí ìgbékèéyíde Nazi ní, àwọn aládùúgbò bẹ̀rẹ̀ síí lòdì sí wa. Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba, ará abúlé kan fi tipátipá kun ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ sí iwájú orí mi. Àbùkù ńláǹlà yìí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ ni. Ní 1939 àwọn Gestapo fàṣẹ ọba mú mi, wọ́n sì gba gbogbo ohun-ìní mi.
“Láti January 1940 títí di May 1945, mo tiraka láti là á já nínú ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Sachsenhausen, Neuengamme, Auschwitz, Buna, àti Buchenwald. Bàbá mi, tí a rán òun pẹ̀lú lọ sí Sachsenhausen, kú ní ìgbà òtútù líle koko ti 1940. Mo fúnra mi gbé òkú rẹ̀ lọ sí ibi tí wọ́n ti ń dáná sun òkú, níbi tí òkìtì òkú wà tí a tòjọ fún sísun. Ní àpapọ̀, mẹ́jọ lára àwọn ìdílé mi kú sí àwọn ibùdó.
“A tilẹ̀ kórìíra àwọn kapos láàárín àwọn ẹlẹ́wọ̀n ju àwọn ẹ̀ṣọ́ SS pàápàá lọ. Àwọn kapos jẹ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn SS tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbádùn àwọn ojúrere kan. A fi wọ́n sí àbójútó pípín oúnjẹ, wọ́n sì tún máa ń na àwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn. Lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n hùwà lọ́nà ìṣègbè àti ti ewèlè. Mo lérò pé mo ní ìdí tí ó pọ̀ tó láti kórìíra àwọn SS àti àwọn kapos, ṣùgbọ́n ní àkókò tí mo fi wà lẹ́wọ̀n, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ìfẹ́ lágbára ju ìkórìíra lọ.
“Okun ìfàyàrán nǹkan tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa ní mú kí n gbàgbọ́ dájú pé wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn karí Ìwé Mímọ́—èmi fúnra mi sì di Ẹlẹ́rìí. Ernst Wauer, Ẹlẹ́rìí kan tí mo bá pàdé ní ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Neuengamme, rọ̀ mí láti mú ìṣarasíhùwà èrò-orí Kristi dàgbà. Bibeli sọ pé ‘nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, oun kò bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, oun kò bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀mọ́ni, ṣugbọn ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni naa tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.’ (1 Peteru 2:23) Mo gbìyànjú láti ṣe ohun kan náà, láti fi ẹ̀san lé Ọlọrun lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ Onídàájọ́ gbogbo ènìyàn.
“Àwọn ọdún tí mo lò nínú àwọn ibùdó kọ́ mi pé àwọn ènìyàn sábà máa ń ṣe àwọn nǹkan búburú láti inú àìmọ̀kan. Kì í ṣe gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ SS pàápàá ni ó burú—ọ̀kan wà tí ó gba ẹ̀mí mi là. Àrunṣu tí ó le kọlù mí nígbà kan tí n kò sì lágbára rárá láti rìn láti ibi iṣẹ́ mi padà sínú ibùdó. À bá ti rán mi lọ sínú ìyẹ̀wù onígáàsì olóró aṣekúpani ní Auschwitz ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ṣùgbọ́n ẹ̀ṣọ́ SS kan, tí ó wá láti ẹkùn kan náà tí mo ti wá ní Germany, dá sí ọ̀ràn náà nítorí tèmi. Ó jẹ́ kí n ṣiṣẹ́ ní ilé oúnjẹ àwọn SS, níbi tí ó ti ṣeé ṣe fún mi láti sinmi díẹ̀ títí mo fi kọ́fẹ padà. Ní ọjọ́ kan ó jẹ́wọ́ fún mi pé: ‘Max, ó dàbí ẹni pé mo wà nínú ọkọ̀ ojú-irin tí ń sáré àsápajúdé tí kò sì ṣeé ṣàkóso. Bí mo bá bẹ́ jáde, n óò kú. Bí mo bá dúró sínú rẹ̀, n óò fọ́ yángá!’
“Àwọn ènìyàn wọ̀nyí nílò ìfẹ́ gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nílò rẹ̀. Níti gidi, ìfẹ́ àti ìyọ́nú, àti ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọrun, ni ó mú kí ó ṣeé ṣe fún mi láti kojú ipò òṣì àti ìfikú halẹ̀mọ́ni ojoojúmọ́. N kò lè sọ pé mo là á já láìfarapa, ṣùgbọ́n àwọn àpá tí mo ní níti èrò-ìmọ̀lára kéré jọjọ.”
Ọ̀yàyà àti inúrere tí Max ṣì ń fi hàn ní 50 ọdún lẹ́yìn náà jẹ́ ẹ̀rí kedere sí òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀ràn ti Max kì í ṣe ọ̀kan tí ó ṣàrà-ọ̀tọ̀. Ó ní ìdí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ láti borí ìkórìíra—ó fẹ́ láti farawé Kristi. Àwọn mìíràn tí Ìwé Mímọ́ ti ṣamọ̀nà ìgbésí-ayé wọn ti hùwà ní irú ọ̀nà kan náà. Simone, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti France, ṣàlàyé bí ó ṣe kọ́ ohun tí ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan túmọ̀ sí níti gidi.
“Màmá mi, Emma, tí ó di Ẹlẹ́rìí kété ṣáájú ogun àgbáyé kejì, kọ́ mi pé àwọn ènìyàn sábà máa ń ṣe àwọn ohun búburú nítorí wọn kò mọ ohun tí ó sàn ju ìyẹn lọ. Ó ṣàlàyé pé bí a bá kórìíra wọn bí wọ́n tí kórìíra wa, a kì í ṣe Kristian tòótọ́, níwọ̀n bí Jesu tí sọ pé kí a nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa kí a sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí wa.—Matteu 5:44.
“Mo rántí ipò kan tí ó le koko gan-an tí ó fi ìdálójú ìgbàgbọ́ yìí sábẹ́ ìdánwò. Nígbà tí Nazi gba France, Màmá jìyà púpọ̀ lọ́wọ́ aládùúgbò kan tí ń gbé ilé wa. Ó fi Màmá sun àwọn Gestapo, àti nítorí èyí, màmá mi lo ọdún méjì ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Germany, níbi tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Lẹ́yìn ogun náà, àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ France fẹ́ kí Màmá fi ọwọ́ sí ìwé kan tí ń fi ẹ̀rí hàn pé obìnrin yìí lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Germany. Ṣùgbọ́n màmá mi kọ̀, ó sọ pé ‘Ọlọrun ni Onídàájọ́ àti Olùsẹ̀san ire àti ibi.’ Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, aládùúgbò yìí kan náà ní àrùn jẹjẹrẹ tí yóò yọrí sí ikú ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Dípò yíyọ̀ ọ́, màmá mi lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí láti mú kí àwọn oṣù tí ó kẹ́yìn ìgbésí-ayé rẹ̀ rọrùn bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Èmi kì yóò gbàgbé bí ìfẹ́ ṣe borí ìkórìíra yìí láé.”
Àwọn àpẹẹrẹ méjì wọ̀nyí ṣàpèjúwe agbára ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà lójú àìṣèdájọ́ òdodo. Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli fúnra rẹ̀ sọ pé “ìgbà fífẹ́, àti ìgbà kíkórìíra” wà. (Oniwasu 3:1, 8) Báwo ni ìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?
Àkókò Láti Kórìíra
Ọlọrun kò dá gbogbo ìkórìíra lẹ́bi. Nípa Jesu Kristi, Bibeli sọ pé: “Iwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà-àìlófin.” (Heberu 1:9) Bí ó ti wù kí ó rí, ìyàtọ̀ wà láàárín kíkórìíra ìwà àìtọ́ àti kíkórìíra ẹni náà tí ó hùwà àìtọ́.
Jesu fi àpẹẹrẹ ìwàdéédéé tí ó tọ́ láàárín ìfẹ́ àti ìkórìíra hàn. Ó kórìíra àgàbàgebè, ṣùgbọ́n ó gbìyànjú láti ran àwọn alágàbàgebè lọ́wọ́ láti yí ọ̀nà ìrònú wọn padà. (Matteu 23:27, 28; Luku 7:36-50) Ó dá ìwà-ipá lẹ́bi, ṣùgbọ́n ó gbàdúrà fún àwọn tí wọ́n pa á. (Matteu 26:52; Luku 23:34) Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé ayé kórìíra rẹ̀ láìní ìdí, ó fi ìwàláàyè tirẹ̀ rúbọ láti baà lè fún aráyé ní ìyè. (Johannu 6:33, 51; 15:18, 25) Ó fi àpẹẹrẹ pípé ti ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà àti ìkórìíra tí Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ sí lélẹ̀ fún wa.
Àìṣèdájọ́ òdodo lè gbé ìkannú tí ó tọ́ dìde nínú wa, bí ó ti rí fún Jesu. (Luku 19:45, 46) Bí ó ti wù kí ó rí, a kò fún àwọn Kristian ní àṣẹ láti fúnra wọn gbẹ̀san. “Ẹ máṣe fi ibi san ibi fún ẹni kankan,” ní ìmọ̀ràn tí Paulu fún àwọn Kristian tí ó wà ní Romu. “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí-àlàáfíà pẹlu gbogbo ènìyàn. Ẹ máṣe gbẹ̀san ara yín . . . Máṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣugbọn máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Romu 12:17-21) Nígbà tí àwa fúnra wa bá kọ̀ láti gbin ìkórìíra sínú tàbí láti gbẹ̀san ìwà àìtọ́, ìfẹ́ yóò jagunmólú.
Ayé kan Láìsí Ìkórìíra
Fún ìkórìíra láti pòórá jákèjádò ayé, ìwà tí ó ti wọ ọ̀pọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn lẹ́wù gbọ́dọ̀ yípadà. Báwo ni èyí ṣe lè ṣeé ṣe? Ọ̀jọ̀gbọ́n Ervin Staub dámọ̀ràn tí ó tẹ̀lé e yìí: “A máa ń fojú kéré àwọn tí a ń pa lára, a sì máa ń fojú pàtàkì wo àwọn tí a ń ṣèrànwọ́ fún. Bí a ti túbọ̀ ń fojú pàtàkì wo àwọn ènìyàn tí a ń ràn lọ́wọ́ tí a sì ń ní ìrírí ìtẹ́lọ́rùn tí ó wà nínú ríranni lọ́wọ́, a óò túbọ̀ wá rí ara wa gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó bìkítà tí ó sì wúlò. Ọ̀kan lára àwọn góńgó wa gbọ́dọ̀ jẹ́ láti ṣe ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́-àwùjọ tí lílọ́wọ́ nínú ṣíṣe nǹkan fún ẹlòmíràn wà lọ́nà gbígbòòrò bí ó bá ti ṣeé ṣe tó.”—The Roots of Evil.
Ní èdè mìíràn, mímú ìkórìíra kúrò béèrè fún ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́-àwùjọ kan nínú èyí tí àwọn ènìyàn ti ń kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ ríran ẹnìkínní-kejì lọ́wọ́, ẹgbẹ́-àwùjọ kan nínú èyí tí àwọn ènìyàn ń gbàgbé gbogbo kèéta tí ẹ̀tanú, ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni, ẹ̀yà-tèmi-lọ̀gá, àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà fà. Irú ẹgbẹ́-àwùjọ bẹ́ẹ̀ ha wà bí? Gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tí ó fúnra rẹ̀ dojúkọ ìkórìíra nígbà Ìyípadà Àṣà Ìbílẹ̀ ní China yẹ̀wò.
“Nígbà tí Ìyípadà Àṣà Ìbílẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a kọ́ wa pé kò sí àyè fún jíjuwọ́sílẹ̀ nínú ‘ìjàkadì ẹlẹ́gbẹ́mẹgbẹ́.’ Ìkórìíra ní ìtẹ̀sí tí ó gbalé gbòde. Mo di ọmọ ẹgbẹ́ Red Guard, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ‘àwọn ọ̀tá ẹgbẹ́’ kiri—àní láàárín àwọn ìdílé tèmi pàápàá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́langba ni mí nígbà náà, mo lọ́wọ́ nínú yíyẹ ilé wò kiri nínú èyí tí a tí ń wá ẹ̀rí ‘ìtẹ̀sí jíjẹ́ alátakò.’ Mo tún darí ìpàdé ìtagbangba kan tí ó bu ẹnu àtẹ́ lu ‘àwọn alátakò ìyípìlẹ̀padà.’ Àmọ́ ṣáá o, àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí nígbà mìíràn ni a sábà máa ń gbé karí kèéta ara ẹni dípò ìgbéyẹ̀wò olóṣèlú.
“Mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn—ọmọdé àti àgbà, ọkùnrin àti obìnrin,—tí a nà lẹ́gba lọ́na tí ó túbọ̀ ń burú síi. Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ mi—tí ó jẹ́ ọkùnrin rere—ni a mú la ìgboro já bí ẹni pé ó jẹ́ ọ̀daràn. Oṣù méjì lẹ́yìn náà olùkọ́ mìíràn tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi ní ilé-ẹ̀kọ́ mi ni a rí tí ó kú sí Odò Suzhou, a sì fi ipá mú olùkọ́ Gẹ̀ẹ́sì mi láti pokùnso. Jìnnìjìnnì bò mí ọkàn mi sì pòrúurùu. Onínúure ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́. Bíbá wọn lò lọ́nà yìí kò tọ́! Nípa bẹ́ẹ̀ mo já gbogbo ìdè àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Red Guard.
“N kò rò pé sáà ìkórìíra yìí tí ó bo China mọ́lẹ̀ fún àkókò díẹ̀ jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ṣàrà-ọ̀tọ̀. Ọ̀rúndún yìí ti rí ọ̀pọ̀ ìbújáde ìkórìíra. Bí ó ti wù kí ó rí, ó dá mi lójú pé ìfẹ́ lè ṣẹ́gun ìkórìíra. Ohun tí mo ti rí fúnra mi ni. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí darapọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ojúlówó ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí àwọn ènìyàn onírúurú ẹ̀yà-ìran àti ipò àtilẹ̀wá wú mi lórí. Mo ń fojú sọ́nà fún àkókò náà nígbà tí, gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti ṣèlérí, gbogbo ènìyàn yóò kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ẹnìkínní-kejì.”
Bẹ́ẹ̀ni, ẹgbẹ́-àwùjọ ará kárí-ayé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ẹ̀rí tí ó ṣeé fojúrí pé ìkórìíra ṣeé fòpin sí. Ohun yòówù kí ipò àtilẹ̀wá wọn jẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí ń gbìyànjú láti fi ọ̀wọ̀ fún tọ̀túntòsì rọ́pò ẹ̀tanú àti láti mú ipa-àmì kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀yà-tèmi-lọ̀gá, tàbí ìfẹ́-orílẹ̀-èdè-ẹni kúrò. Ìdí kan fún àṣeyọrí wọn ni ìpinnu wọn láti farawé Jesu Kristi nínú fífi ìfẹ́ tí ìlànà ń darí hàn. Ìdí mìíràn ni pé wọ́n ń wo Ìjọba Ọlọrun láti mú òpin débá àìṣèdájọ́ òdodo èyíkéyìí tí wọ́n lè máa jìyà rẹ̀.
Ìjọba Ọlọrun ni ojútùú tí ó dájú sí níní ayé kan láìsí ìkórìíra, ayé kan tí kì yóò tilẹ̀ sí ìwà ibi láti kórìíra. A ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọ̀run titun,” àkóso ti ọ̀run yìí yóò mú ayé kan tí ó bọ́ lọ́wọ́ àìṣèdájọ́ òdodo dáni lójú. Yóò ṣàkóso lórí “ilẹ̀-ayé titun,” tàbí ẹgbẹ́-àwùjọ àwọn ènìyàn titun tí a óò ti kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ẹnìkínní-kejì. (2 Peteru 3:13; Isaiah 54:13) Ẹ̀kọ́ yìí ń lọ lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bí ìrírí Max, Simone, àti àwọn mìíràn ti jẹ́rìí sí i. Ó jẹ́ àpẹẹrẹ ráńpẹ́ ti ètò kárí-ayé láti mú ìkórìíra àti àwọn okùnfà rẹ̀ kúrò.
Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Isaiah, Jehofa ṣàpèjúwe àbájáde rẹ̀: “Wọ́n kì yóò panilára, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò panirun ní gbogbo òkè mímọ́ mi: nítorí ayé yóò kún fún ìmọ̀ Oluwa gẹ́gẹ́ bí omi ti bo òkun.” (Isaiah 11:9) Ọlọrun fúnra rẹ̀ yóò ti dáwọ́ ìkórìíra dúró. Yóò jẹ́ àkókò láti nífẹ̀ẹ́ ní tòótọ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Nazi kọ nọ́ḿbà ẹ̀wọ̀n sí apá òsì Max Liebster
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìkórìíra yóò di ohun àtijọ́ láìpẹ́