Máa Tẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jésù Nínú Ìwà àti Ìṣe Rẹ
“Ẹni tí Ọlọ́run rán jáde ń sọ àwọn àsọjáde Ọlọ́run.”—JÒH. 3:34.
1, 2. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè ti ṣeyebíye tó, kí sì nìdí tá a fi lè sọ pé inú “àwọn àsọjáde Ọlọ́run” ló ti wá?
Ọ̀KAN lára òkúta dáyámọ́ńdì táwọn èèyàn tíì rí pé ó níye lórí jù lọ lóde òní ni èyí tí wọ́n pè ní Star of Africa. Àmọ́ ohun kan wà tó ṣeyebíye ju òkúta yẹn lọ. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Lórí Òkè. Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu, nítorí ọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ ti wá! Ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù ni pé: “Ẹni tí Ọlọ́run rán jáde ń sọ àwọn àsọjáde Ọlọ́run.”—Jòh. 3:34-36.
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má gbà tó ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tí Jésù fi ṣe Ìwàásù Lórí Òkè yẹn, síbẹ̀ ìgbà mọ́kànlélógún ló fa ọ̀rọ̀ yọ nínú ìwé mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Jésù kò wá láti ibòmíì bí kò ṣe inú “àwọn àsọjáde Ọlọ́run.” Ẹ jẹ́ ká wá wo bá a ṣe lè lo díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó ṣeyebíye tí ààyò Ọmọ Ọlọ́run sọ nínú ìwàásù tó fakíki yìí.
‘Kọ́kọ́ Wá Àlàáfíà Pẹ̀lú Arákùnrin Rẹ’
3. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn tó ti kìlọ̀ fún wọn nípa ohun tí ìbínú lè ṣe fúnni?
3 Àwa Kristẹni ní ayọ̀, a tún jẹ́ èèyàn àlàáfíà nítorí pé a ní ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ìdùnnú àti àlàáfíà sì wà nínú èso ẹ̀mí yìí. (Gál. 5:22, 23) Jésù ò fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pàdánù àlàáfíà àti ayọ̀ wọn, ìdí nìyẹn tó fi kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ìbínú pẹ́ lọ́kàn wọn nítorí ó lè yọrí sí ikú. (Ka Mátíù 5:21, 22.) Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mát. 5:23, 24.
4, 5. (a) Kí ni “ẹ̀bùn” tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Mátíù 5:23, 24? (b) Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tó sọ pé a ṣẹ òun?
4 “Ẹ̀bùn” tí Jésù sọ yìí jẹ́ ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ fi rú ẹbọ ní tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Bí àpẹẹrẹ, fífi ẹran rúbọ sí Jèhófà ṣe pàtàkì nítorí pé ó jẹ́ ara ìjọsìn táwọn èèyàn rẹ̀ ń ṣe fún un nígbà yẹn. Àmọ́, Jésù sọ pé ohun kan wà tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìyẹn ni pé kí ẹni tó fẹ́ rúbọ náà kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ tó fẹ̀sùn kàn án pé ó ṣẹ òun, kó tó lọ fi ẹ̀bùn rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run.
5 Gbólóhùn náà, “wá àlàáfíà” níhìn-ín, túmọ̀ sí pé kéèyàn yanjú ọ̀ràn tó wà láàárín òun àti ẹnì kan. Kí la wá lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí? Ẹ̀kọ́ náà ni pé ọ̀nà tá à ń gbà hùwà sáwọn èèyàn wà lára ohun tó máa pinnu bí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa rí. (1 Jòh. 4:20) Ká sòótọ́, ọrẹ ẹbọ tí wọ́n ń rú sí Ọlọ́run nígbà àtijọ́ kò ní já mọ́ nǹkan kan tẹ́ni tó ń rúbọ kò bá hùwà tó dára sí ọmọnìkejì rẹ̀.—Ka Míkà 6:6-8.
A Gbọ́dọ̀ Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀
6, 7. Kí nìdí tá a fi nílò ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tá a bá ń wá bí àlàáfíà ṣe máa wà láàárín àwa àti arákùnrin tó sọ pé a ṣẹ òun?
6 Tá ò bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó lè ṣòro láti lọ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tó sọ pé a ṣẹ òun. Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn kì í tìtorí káwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ lè gbà pé orí ẹ̀tọ́ lòun wà, kó máa bá wọn fa ọ̀rọ̀. Fífa nǹkan lọ́nà yẹn á jẹ́ kí ọ̀ràn di iṣu ata yán-an yàn-an bí irú èyí tó wáyé nígbà kan láàárín àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì àtijọ́. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀, ó sọ kókó kan tó ń múni ronú jinlẹ̀, ó ní: “Gbogbo-ẹ̀ gbògbò-ẹ̀, ó túmọ̀ sí ìpaláyò fún yín pé ẹ ń pe ara yín lẹ́jọ́. Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a ṣe àìtọ́ sí ẹ̀yin fúnra yín? Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a lu ẹ̀yin fúnra yín ní jìbìtì?”—1 Kọ́r. 6:7.
7 Jésù kò sọ pé ká lọ sọ́dọ̀ arákùnrin wa láti lọ fi yé e pé òun ló jẹ̀bi wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó yẹ ká tìtorí rẹ̀ lọ bá a ni bí àlàáfíà ṣe máa wà. Kó tó lè ṣeé ṣe fún wa láti wá àlàáfíà, a óò ní láti sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wa gan-an. Kò sì yẹ ká ṣàìka ọ̀rọ̀ tí onítọ̀hún sọ pé ó ń dun òun sí. Tó bá sì wá jẹ́ pé àwa la ṣàṣìṣe, ó yẹ ká tọrọ àforíjì tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀.
‘Bí Ojú Ọ̀tún Rẹ Bá Ń Mú Ọ Kọsẹ̀’
8. Sọ kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ Jésù ní Mátíù 5:29, 30.
8 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù fúnni ní ìlànà tó múná dóko lórí ìwà rere. Ó mọ̀ pé ẹ̀yà ara àwa èèyàn aláìpé lè ṣàkóbá fún wa. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Nítorí ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún ọ kí o pàdánù ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara rẹ ju kí a gbé gbogbo ara rẹ sọ sínú Gẹ̀hẹ́nà. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, ké e kúrò, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Nítorí ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún ọ kí o pàdánù ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara rẹ ju kí gbogbo ara rẹ balẹ̀ sínú Gẹ̀hẹ́nà.”—Mát. 5:29, 30.
9. Kí la lè ṣe tí “ojú” tàbí “ọwọ́” wa kò fi ní mú wa “kọsẹ̀”?
9 “Ojú” tí Jésù ń sọ níbí yìí ṣàpẹẹrẹ bá a ṣe ń pọkàn pọ̀ sórí ohun kan, “ọwọ́” tó ń sọ sì jẹ mọ́ ohun tí à ń fi ọwọ́ wa ṣe. Bá ò bá ṣọ́ra, àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí lè mú wa “kọsẹ̀,” ká sì ṣíwọ́ ‘bíbá Ọlọ́run rìn.’ (Jẹ́n. 5:22; 6:9) Nígbà tí ìdẹwò tó lè mú wa ṣàìgbọràn sí Jèhófà bá dojú kọ wá, a ní láti gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára lórí ara wa, bí ìgbà téèyàn yọ ojú ara rẹ̀ tàbí tó gé ọwọ́ ara rẹ̀ dà nù.
10, 11. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní dẹni tó ṣèṣekúṣe?
10 Kí la lè ṣe tá a ò fi ní máa wo ìwòkuwò? Jóòbù tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?” (Jóòbù 31:1) Jóòbù tó ti ní aya sílé, pinnu pé òun ò ní rú òfin tí Ọlọ́run ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìwà mímọ́. Ohun tó yẹ kó jẹ́ ìpinnu tiwa náà nìyẹn, yálà a ti ṣègbéyàwó tàbí a ò tíì ṣègbéyàwó. Láti yẹra fún ìṣekúṣe a ní láti jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí wa. Ẹ̀mí yìí máa ń mú káwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní ìkóra-ẹni-níjàánu.—Gál. 5:22-25.
11 Ká má bàa dẹni tó ń ṣèṣekúṣe, á dára ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń gbà kí ojú mi máa mú kí ọkàn mi fà sí ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tí wọ́n sábà máa ń gbé jáde nínú ìwé, lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?’ Bákan náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ, pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀wẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti ṣàṣeparí rẹ̀, a mú ikú wá.” (Ják. 1:14, 15) Àní sẹ́, bí ẹnì kan tó ti ṣe ìyàsímímọ́ sí Ọlọ́run bá “ń bá a nìṣó ní wíwo” ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan pẹ̀lú èrò ìṣekúṣe lọ́kàn, ó yẹ kó ṣe ìyípadà tó lágbára, tó dà bí ìgbà téèyàn bá yọ ojú rẹ̀ jáde tó sì sọ ọ́ nù.—Ka Mátíù 5:27, 28.
12. Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti gbógun ti ìfẹ́ ìṣekúṣe?
12 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lílo ọwọ́ wa lọ́nà tí kò tọ́, lè mú ká tẹ ìlànà Jèhófà lójú, a gbọ́dọ̀ ṣèpinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba ìwà mímọ́ wa jẹ́. Nítorí náà, ó yẹ ká ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.” (Kól. 3:5) Gbólóhùn náà, ‘ẹ sọ ẹ̀ya ara yín dòkú’ jẹ́ ká rí i pé ìgbésẹ̀ tó lágbára lèèyàn gbọ́dọ̀ gbé láti gbógun ti ìfẹ́ ìṣekúṣe.
13, 14. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká yẹra fún èròkerò àti ìṣekúṣe?
13 Ẹnì kan lè gbà kí wọ́n gé ẹ̀ya ara òun kan dà nù torí kó má bàa kú. Láti lè yẹra fún èròkerò àti ìṣekúṣe tó lè mú ká kú nípa tẹ̀mí, ó ṣe pàtàkì pé ká ṣe ohun tó lágbára lórí ara wa, èyí tó máa dà bí ìgbà téèyàn yọ ojú rẹ̀ tàbí tó gé ọwọ́ rẹ̀ tó sì sọ ọ́ nù. Ohun tó lè mú ká bọ́ lọ́wọ́ Gẹ̀hẹ́nà tó ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé ni pé ká jẹ́ mímọ́ lọ́rọ̀, lérò àti níṣe, ká sì jẹ́ kí ìjọsìn wa mọ́ lójú Ọlọ́run.
14 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a ti jogún, ó gba ìsapá gan-an kéèyàn tó lè máa jẹ́ oníwà mímọ́ nìṣó. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.” (1 Kọ́r. 9:27) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà, àti pé a kò ní máa ṣe ohun táá fi hàn pé a kò mọrírì ẹbọ ìràpadà rẹ̀.—Mát. 20:28; Héb. 6:4-6.
“Sọ Fífúnni Dáṣà”
15, 16. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú jíjẹ́ ọ̀làwọ́? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Lúùkù 6:38 túmọ̀ sí?
15 Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù àtàwọn àpẹẹrẹ rẹ̀ tó ta yọ ń gbin ẹ̀mí ọ̀làwọ́ síni lọ́kàn. Jésù fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó ga hàn ní ti bó ṣe wá sáyé nítorí tàwa ẹ̀dá aláìpé. (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:9.) Jésù fínnúfíndọ̀ bọ́ ògo ti ọ̀run sílẹ̀ ó sì di èèyàn, kó bàa lè fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí máa di ọlọ́rọ̀ ní ọ̀run nígbà tí wọ́n bá di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba ọ̀run. (Róòmù 8:16, 17) Ó sì dájú pé Jésù ń fẹ́ ká jẹ́ ọ̀làwọ́ nígbà tó sọ pé:
16 “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín. Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín. Nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.” (Lúùkù 6:38) Dída ohun tó wà nínú òṣùwọ̀n sórí itan tí Jésù ń sọ níbí yìí jẹ́ ohun táwọn òǹtajà kan sábà máa ń ṣe, ìyẹn ni pé wọ́n máa ń da oúnjẹ sínú ibi tí òǹrajà ṣẹ́ po lápá iwájú lára ẹ̀wù tó wọ̀. Tá a bá jẹ́ ẹni tó ń lawọ́ sí onírúurú èèyàn, ó lè jẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà ọ̀làwọ́ sáwa náà, bóyá nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro.—Oníw. 11:2.
17. Báwo ni Jèhófà ṣe fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ lórí ọ̀ràn fífúnni, irú fífúnni wo ló sì máa mú ká láyọ̀?
17 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó máa ń fúnni ní nǹkan tọ̀yàyàtọ̀yàyà, ó sì máa ń san èrè fún wọn. Òun fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀, ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni “kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹni tí ó bá . . . ń fúnrúgbìn yanturu yóò ká yanturu pẹ̀lú. Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́r. 9:6, 7) Ó dájú pé lílo àkókò wa, okun wa, àti ohun ìní wa láti fi ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn mímọ́ yóò fún wa láyọ̀ àti ọ̀pọ̀ ìbùkún.—Ka Òwe 19:17; Lúùkù 16:9.
“Má Ṣe Fun Kàkàkí Níwájú Rẹ”
18. Àwọn ohun wo ni kò ní jẹ́ ká “ní èrè kankan” lọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run?
18 “Ẹ ṣọ́ra gidigidi láti má ṣe fi òdodo yín ṣe ìwà hù níwájú àwọn ènìyàn kí wọ́n bàa lè ṣàkíyèsí rẹ̀; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ kì yóò ní èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 6:1) “Òdodo” tí Jésù ń sọ níbí yìí ni ìwà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Jésù ò sọ pé ó burú láti máa ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí ní gbangba o, nítorí ó ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ “kí ìmọ́lẹ̀ [wọn] máa tàn níwájú àwọn ènìyàn.” (Mát. 5:14-16) Ṣùgbọ́n a “kì yóò ní èrè kankan” lọ́dọ̀ Baba wa ọ̀run tá a bá ń ṣe nǹkan torí káwọn èèyàn “bàa lè ṣàkíyèsí rẹ̀” kí wọ́n sì kan sáárá sí wa, bíi tẹni tó ń ṣe eré orí ìtàgé. Tó bá jẹ́ pé irú ẹ̀mí yẹn la fi ń ṣe nǹkan, a ò ní ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run a ò sì ní gbádùn ìbùkún ayérayé tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá.
19, 20. (a) Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ká má ṣe máa “fun kàkàkí” nígbà tá a bá ń fúnni ní “ẹ̀bùn àánú”? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì wa mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún ń ṣe?
19 Tá a bá ní ẹ̀mí tó dáa, a ó máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù yìí, ó ní: “Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà tí o bá ń lọ fi àwọn ẹ̀bùn àánú fúnni, má ṣe fun kàkàkí níwájú rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn alágàbàgebè ti ń ṣe nínú sínágọ́gù àti ní àwọn ojú pópó, kí àwọn ènìyàn lè yìn wọ́n lógo. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Wọ́n ń gba èrè wọn ní kíkún.” (Mát. 6:2) “Ẹ̀bùn àánú” yìí ni ohun tí wọ́n fi ń ta àwọn aláìní lọ́rẹ. (Ka Aísáyà 58:6, 7.) Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní àpótí tí wọ́n ń kówó sí, tí wọ́n á lè máa mú nínú rẹ̀ láti fi ran àwọn tálákà lọ́wọ́. (Jòh. 12:5-8; 13:29) Níwọ̀n bí àwọn èèyàn kì í ti í fun kàkàkí láti kéde pé àwọn ń ta àwọn tálákà lọ́rẹ, ó ṣe kedere pé èdè àbùmọ́ ni Jésù lò bó ṣe sọ pé ká má ṣe “fun kàkàkí” níwájú wa tá a bá fẹ́ fi “ẹ̀bùn àánú” fúnni. A ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ìtọrẹ àánú wa láṣehàn, bíi tàwọn Farisí Júù. Jésù pè wọ́n ní alágàbàgebè nítorí wọ́n ń polongo ọrẹ àánú wọn “nínú sínágọ́gù àti ní àwọn ojú pópó.” Àwọn alágàbàgebè wọ̀nyẹn ti “ń gba èrè wọn ní kíkún.” Gbogbo èrè tí wọ́n máa rí gbà ni ògo èèyàn àti bóyá jíjókòó lọ́wọ́ iwájú pẹ̀lú àwọn rábì olókìkí nínú sínágọ́gù, nítorí Jèhófà ò ní fún wọn ní nǹkan kan. (Mát. 23:6) Àmọ́, báwo ló ṣe yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi máa ṣe ìtọrẹ tiwọn? Ohun tí Jésù sọ fún wọn kan àwa náà, ó sọ pé:
20 “Ṣùgbọ́n ìwọ, nígbà tí o bá ń fi àwọn ẹ̀bùn àánú fúnni, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe, kí àwọn ẹ̀bùn àánú rẹ lè wà ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.” (Mát. 6:3, 4) Ọwọ́ wa méjèèjì la máa ń lò pa pọ̀. Nítorí náà, nígbà tí Jésù sọ pé ká má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì wa mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún wa ń ṣe, ohun tó túmọ̀ sí ni pé a kò ní máa polongo iṣẹ́ àánú tá à ń ṣe. Kódà kó yẹ ká sọ ọ́ fáwọn tá a jọ sún mọ́ra bí ọwọ́ ọ̀tún ṣe rí sí ọwọ́ òsì.
21. Àwọn nǹkan wo ló wà lára ohun tí Ẹni “tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀” yóò san fún wa?
21 Tá a kì í bá fi ọrẹ tá à ń fáwọn èèyàn fọ́nnu, “ẹ̀bùn àánú” wa yóò wà ní àṣírí. Nígbà náà, Baba wa “tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀” yóò san án pa dà fún wa. Lójú àwa èèyàn, Baba wa ti ń bẹ lọ́run wà “ní ìkọ̀kọ̀” ní ti pé, ọ̀run ló ń gbé, ojú ẹ̀dá èèyàn kò sì lè rí i. (Jòh. 1:18) Ara ohun tí Jèhófà, ẹni “tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀” ń san fún wa pa dà ni àjọṣe tímọ́tímọ́ tó ń jẹ́ ká ní pẹ̀lú rẹ̀, bó ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá àti bó ṣe máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Òwe 3:32; Jòh. 17:3; Éfé. 1:7) Gbogbo ìyẹn sì dára fíìfíì ju gbígba ìyìn lọ́dọ̀ èèyàn lọ!
Ọ̀rọ̀ Iyebíye Tó Yẹ Ká Mọrírì Ni
22, 23. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọrírì àwọn ọ̀rọ̀ Jésù?
22 Dájúdájú, Ìwàásù Lórí Òkè kún fún onírúurú ẹ̀kọ́ iyebíye tó dùn mọ́ni. Láìsí àní-àní, àwọn ọ̀rọ̀ iyebíye tó lè mú wa láyọ̀, àní nínú ayé onídààmú yìí, wà nínú rẹ̀. Ní tòótọ́, a óò láyọ̀ tá a bá mọrírì àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tá a sì ń tẹ̀ lé e nínú ìwà àti ìṣe wa.
23 Gbogbo ẹni tó “ń gbọ́” tó sì “ń ṣe” ohun tí Jésù kọ́ni yóò rí ìbùkún gbà. (Ka Mátíù 7:24, 25.) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa fi ìmọ̀ràn Jésù sílò. Nínú àpilẹ̀kọ́ kẹta tó parí ọ̀wọ́ yìí, a óò jíròrò díẹ̀ sí i lára ọ̀rọ̀ Jésù nínú Ìwàásù Lórí Òkè.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tó sọ pé a ṣẹ òun?
• Kí la lè ṣe kí “ojú ọ̀tún” wa má bàa mú wa kọsẹ̀?
• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní tó bá dọ̀ràn fífúnni?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ẹ ò rí bó ṣe dára tó pé ká “wá àlàáfíà pẹ̀lú” ẹni tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tó sọ pé a ṣẹ òun!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó ń fúnni ní nǹkan tọ̀yàyàtọ̀yàyà