Jésù Kọ́ Wa Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
“Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” —JÒH. 13:15.
1, 2. Kí ni Jésù ṣe ní alẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí èèyàn lórí ilẹ̀ ayé? Ẹ̀kọ́ wo ló fi kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
NÍ ALẸ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ó wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nínú yàrá òkè ilé kan ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ alẹ́ lọ́wọ́, Jésù dìde ó sì bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. Ó fi aṣọ ìnura di ara rẹ̀ lámùrè. Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú bàsíà kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì ń fi aṣọ ìnura nù wọ́n gbẹ. Lẹ́yìn náà, ó wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. Kí nìdí tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ rírẹlẹ̀ yẹn?—Jòh. 13:3-5.
2 Jésù fúnra rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe fún yín? . . . Bí èmi, tí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nítorí mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” (Jòh. 13:12-15) Jésù fi iṣẹ́ rírẹlẹ̀ tó fínnú fíndọ̀ ṣe yẹn kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ kan tí wọn kò ní gbàgbé, táá mú kí àwọn náà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.
3. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàkì? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Kì í ṣe ìgbà tí Jésù wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì ló kọ́kọ́ kọ́ wọn pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàkì. Kó tó dìgbà yẹn, nígbà táwọn àpọ́sítélì kan ń bára wọn jiyàn nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láàárín wọn, Jésù mú ọmọdé kan wá síwájú wọn, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gbà mí pẹ̀lú, ẹnì yòówù tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó rán mi jáde pẹ̀lú. Nítorí ẹni tí ó bá hùwà bí ẹni tí ó kéré jù láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.” (Lúùkù 9:46-48) Níwọ̀n bí Jésù ti mọ̀ pé àwọn Farisí máa ń wá ipò ọlá, ó sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ àti ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.” (Lúùkù 14:11) Ó ṣe kedere pé Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kò fẹ́ kí wọ́n máa gbéra ga tàbí kí wọ́n jọra wọn lójú. Ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ bí Jésù ṣe fìrẹ̀lẹ̀ hàn kí àwa náà lè fìwà jọ ọ́. A tún máa rí bí ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè ṣàǹfààní fún ẹni tó bá ní in àti àwọn mìíràn pẹ̀lú.
“ÈMI KÒ YÍ PADÀ SÍ ÒDÌ-KEJÌ”
4. Báwo ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ṣe fìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn kó tó wá sáyé?
4 Kó tiẹ̀ tó di pé ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run wá sáyé ló ti ń fìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Jésù lo àìmọye ọdún lókè ọ̀run pẹ̀lú Baba rẹ̀. Ìwé Aísáyà sọ nípa àjọṣe tímọ́tímọ́ tí Jésù ní pẹ̀lú Ọlọ́run, ó ní: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́, kí n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn. Ó ń jí mi ní òròòwúrọ̀; ó ń jí etí mi láti gbọ́, bí àwọn tí a kọ́. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti ṣí etí mi, èmi, ní tèmi, kò sì ya ọlọ̀tẹ̀. Èmi kò yí padà sí òdì-kejì.” (Aísá. 50:4, 5) Jésù fìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn ó sì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí Jèhófà kọ́ ọ. Ó máa ń wù ú nígbà gbogbo láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run òtítọ́. Torí náà, ó ti ní láti fara balẹ̀ kíyè sí bí Jèhófà ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi àánú hàn sí aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀.
5. Báwo ni ohun tí Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì ṣe nígbà tó ní aáwọ̀ pẹ̀lú Èṣù ṣe fi hàn pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀?
5 Gbogbo ẹ̀dá tó wà lọ́run kọ́ ló fìwà jọ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run. Dípò tí áńgẹ́lì tó di Sátánì Èṣù ì bá fi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kó sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, ńṣe ló ń hùwà ìgbéraga, ó jọra rẹ̀ lójú, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Àmọ́, ipò tí Jèhófà fi Jésù sí gẹ́gẹ́ bíi Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì tẹ́ ẹ lọ́rùn. Kò ṣi àṣẹ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ lò nígbà tó ní ‘aáwọ̀ pẹ̀lú Èṣù nípa òkú Mósè.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Ọmọ Ọlọ́run ṣe fi hàn pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Ó fẹ́ kí Jèhófà, Onídàájọ́ Gíga Jù Lọ láyé àtọ̀run bójú tó ọ̀ràn náà bó ṣe fẹ́, kó sì ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá tọ́ lójú rẹ̀.—Ka Júúdà 9.
6. Báwo ni Jésù ṣe fìrẹ̀lẹ̀ hàn nígbà tí Ọlọ́run yàn án láti jẹ́ Mèsáyà?
6 Láìsí àní-àní, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jésù nígbà tó bá wá sáyé gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà wà lára àwọn nǹkan tó kọ́ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó ti mọ̀ pé àwọn ohun tí kò bára dé máa ṣẹlẹ̀ sí òun. Síbẹ̀, Jésù gbà láti wá sáyé, ó sì ṣe tán láti kú gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Kí nìdí? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, ó ní: “Ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.”—Fílí. 2:6, 7.
JÉSÙ “RẸ ARA RẸ̀ SÍLẸ̀” NÍGBÀ TÓ WÀ LÁYÉ
7, 8. Báwo ni Jésù ṣe fìrẹ̀lẹ̀ hàn nígbà tó wà lọ́mọdé àti nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
7 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí [Jésù] rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” (Fílí. 2:8) Láti kékeré ni Jésù ti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni Jósẹ́fù àti Màríà tó tọ́ Jésù dàgbà, “ó . . . ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.” (Lúùkù 2:51) Àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn jẹ́ fún àwọn ọmọdé. Ọlọ́run máa bù kún wọn bí wọ́n bá ń fínnú fíndọ̀ tẹrí ba fún àwọn òbí wọn.
8 Nígbà tí Jésù dàgbà ó ṣì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ síbẹ̀, bó sì ṣe máa ṣe ohun tó wu Jèhófà ló jẹ ẹ́ lógún jù lọ. (Jòh. 4:34) Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó lo orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an. Ó ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ohun tó ti pinnu pé òun máa ṣe fún aráyé. Ohun tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà lòun náà ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nínú àdúrà àwòkọ́ṣe, ohun tí Jésù kọ́kọ́ sọ ni pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n lógún jù lọ ni bí wọ́n ṣe máa sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. Ohun tó sì jẹ òun náà lógún jù lọ nìyẹn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tó kù díẹ̀ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ parí lórí ilẹ̀ ayé, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn [àwọn àpọ́sítélì], ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀.” (Jòh. 17:26) Bákan náà, Jésù máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ò lè dá nǹkan kan ṣe láìsí ìtìlẹ́yìn Jèhófà.—Jòh. 5:19.
9. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Sekaráyà sọ nípa Mèsáyà, báwo sì ni Jésù ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ?
9 Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà pé: “Kún fún ìdùnnú gidigidi, ìwọ ọmọbìnrin Síónì. Kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù. Wò ó! Ọba rẹ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá. Ó jẹ́ olódodo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni ìgbàlà; onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ẹran tí ó ti dàgbà tán, ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” (Sek. 9:9) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ nígbà tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù, kí Ìrékọjá tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. Ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn tẹ́ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà, àwọn mìíràn sì kó àwọn ẹ̀ka igi sí ojú ọ̀nà. Kódà, nígbà tó wọ ibẹ̀, arukutu sọ kárí ìlú náà. Pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe ń kan sáárá sí i gẹ́gẹ́ bí ọba, kò gbéra ga.—Mát. 21:4-11.
10. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà títí tó fi kú?
10 Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run títí tó fi kú lórí igi oró. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi hàn kedere pé àwọn èèyàn lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nígbà tí wọ́n bá wà nínú àdánwò tó le gan-an. Jésù tún fi hàn pé irọ́ ni Sátánì pa pé torí káwọn èèyàn lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ Jèhófà nìkan ni wọ́n ṣe ń sìn ín. (Jóòbù 1:9-11; 2:4) Bí Kristi ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí tó fi kú tún fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ àgbáyé àti pé ìṣàkóso Jèhófà ló dára jù lọ. Ó dájú pé inú Jèhófà dùn bó ṣe ń wo ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti adúróṣinṣin.—Ka Òwe 27:11.
11. Kí ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi máa mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?
11 Jésù kú lórí igi oró, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ra aráyé pa dà. (Mát. 20:28) Lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, ó sì máa mú ká lè wà láàyè títí láé. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè.” (Róòmù 5:18) Ikú Jésù mú kó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró láti jogún àìleèkú ní ọ̀run, ó sì mú kó ṣeé ṣe fún “àwọn àgùntàn mìíràn” láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.—Jòh. 10:16; Róòmù 8:16, 17.
MO JẸ́ “ẸNI RÍRẸLẸ̀ NÍ ỌKÀN-ÀYÀ”
12. Báwo ni Jésù ṣe fi ìwà tútù àti ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn aláìpé?
12 Jésù ní kí gbogbo àwọn tó “ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn” wá sọ́dọ̀ òun. Ó sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” (Mát. 11:28, 29) Torí pé Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníwà-tútù, ó máa ń fi inúure bá àwọn èèyàn aláìpé lò, kì í sì í ṣe ojúsàájú. Kò sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣe ohun tí agbára wọn kò gbé. Jésù máa ń gbóríyìn fún wọn ó sì máa ń fún wọn níṣìírí. Kì í mú kí wọ́n rí ara wọn bí aláìmọ̀kan tàbí aláìníláárí. Ó dájú pé Jésù kì í ṣe ẹni líle koko tàbí aninilára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mú kó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé bí wọ́n bá wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun tí wọ́n sì ń ṣe àwọn nǹkan tí òun kọ́ wọn, wọn yóò rí ìtura torí pé àjàgà òun jẹ́ ti inú rere, ẹrù òun sì fúyẹ́. Ara máa ń tu tọmọdé tàgbà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin bí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀.—Mát. 11:30.
13. Báwo ni Jésù ṣe fi àánú hàn sí àwọn tí ìyà ń jẹ?
13 Jésù tún fi àánú hàn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ìyà ń jẹ, ó sì fìfẹ́ ṣe ohun tí wọ́n nílò fún wọn. Nítòsí Jẹ́ríkò, ó rí ọkùnrin afọ́jú oníbáárà kan tó ń jẹ́ Báátíméù àti èkejì rẹ̀ tí Bíbélì kò sọ orúkọ rẹ̀. Wọ́n bẹ Jésù léraléra pé kó ran àwọn lọ́wọ́, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn bá wọn wí kíkankíkan pé kí wọ́n panu mọ́. Bí Jésù bá fẹ́ fi gbígbọ́ ṣe aláìgbọ́, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, dípò kó ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ní kí wọ́n mú wọn wá sọ́dọ̀ òun, àánú ṣe é, ó sì la ojú wọn. Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀, Jèhófà, torí pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ó sì máa ń fi àánú hàn sí àwọn òtòṣì ẹlẹ́ṣẹ̀.—Mát. 20:29-34; Máàkù 10:46-52.
‘ẸNÌ YÒÓWÙ TÍ Ó BÁ RẸ ARA RẸ̀ SÍLẸ̀ NI A ÓÒ GBÉ GA’
14. Àwọn àǹfààní wo ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jésù mú wa?
14 Bí Jésù Kristi ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn láyọ̀, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. Inú Jèhófà dùn pé Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n fìrẹ̀lẹ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí òun rán an. Bí Jésù ṣe jẹ́ onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ máa ń mú kí ara tu àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn. Àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ fún wọn, ẹ̀kọ́ tó kọ́ wọn àti bó ṣe máa ń gbóríyìn fún wọn máa ń mú kí wọ́n fẹ́ tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí. Àwọn èèyàn tí wọn ò kà sí láwùjọ jàǹfààní látinú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jésù torí pé ó ràn wọ́n lọ́wọ́, ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó sì fún wọn ní ìṣírí. Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù máa jàǹfààní títí láé nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀.
15. Àǹfààní wo ni Jésù rí nínú bó ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
15 Jésù náà ńkọ́? Ǹjẹ́ ó jàǹfààní nínú bó ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, torí ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹnì yòówù tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.’ (Mát. 23:12) Bí ọ̀rọ̀ Jésù ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: ‘Ọlọ́run gbé Jésù sí ipò gíga, ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Baba.’ Torí pé Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti olóòótọ́ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, Jèhófà Ọlọ́run gbé e ga, ó sí fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹ̀dá tó wà lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé.—Fílí. 2:9-11.
JÉSÙ MÁA “GẸṢIN LỌ NÍTORÍ ÒTÍTỌ́ ÀTI ÌRẸ̀LẸ̀”
16. Kí ló fi hàn pé Ọmọ Ọlọ́run á ṣì máa fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe?
16 Ọmọ Ọlọ́run á ṣì máa fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Nígbà tí onísáàmù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí Jésù ṣe máa bá àwọn ọ̀tá Rẹ̀ jà láti ipò gíga tó wà lókè ọ̀run, ó sọ pé: “Nínú ọlá ńlá rẹ, kí o tẹ̀ síwájú dé àṣeyọrí sí rere; máa gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo.” (Sm. 45:4) Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jésù Kristi máa gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n fẹ́ràn òtítọ́ tí wọ́n sì ń hùwà òdodo. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, lẹ́yìn tí Mèsáyà Ọba “bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán”? Ṣé Jésù ṣì máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, torí pé ó máa ‘fi ìjọba lé Ọlọ́run tó jẹ́ Baba rẹ̀ lọ́wọ́.’—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:24-28.
17, 18. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jọ Jésù? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Àwa náà ńkọ́? Ṣé a máa fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jọ Jésù tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa? Ipò wo ni Jésù Kristi Ọba máa bá wa nígbà tó bá wá mú ìdájọ́ ṣẹ ní Amágẹ́dọ́nì? Bí Jésù ṣe ń gẹṣin lọ nítorí ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo fi hàn pé àwọn tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti olódodo nìkan ló máa gbà là. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a bá fẹ́ là á já. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti àwọn míì ṣe jàǹfààní nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ fi hàn pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló máa jẹ́ tiwa tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.
18 Kí ló máa mú ká fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ jọ Jésù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, báwo la ṣe lè sapá ká bàa lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? A máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.