-
Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?Jí!—2012 | April
-
-
Jésù sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú. Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní; kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa. Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’”—Mátíù 6:9-13.
-
-
Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?Jí!—2012 | April
-
-
“Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.” Ọ̀rọ̀ náà “àwọn gbèsè,” tí Jésù lò níbí yìí túmọ̀ sí “àwọn ẹ̀ṣẹ̀.”c Ó yẹ kí gbogbo wa máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Torí náà, nígbà tá a bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tàbí tá a dẹ́ṣẹ̀ sí i, ńṣe ni ó dà bíi pé a di ajigbèsè. Àmọ́, Jèhófà ṣe tán láti dárí gbèsè wa jì wá nígbà tí àwa náà bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá tìfẹ́tìfẹ́.—Mátíù 18:21-35.
-