-
Kí Ló Ń Mú Káyé YẹniIlé Ìṣọ́—2012 | December 15
-
-
13. Kí ni Jésù sọ nípa títo ìṣúra pa mọ́?
13 Jésù sọ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. Nítorí pé ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.”—Mát. 6:19-21.
-
-
Kí Ló Ń Mú Káyé YẹniIlé Ìṣọ́—2012 | December 15
-
-
15. Tá a bá fẹ́ káyé yẹ wá, kí ló yẹ ká máa fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún?
15 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan máa ń wàásù fún àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kì í ṣe ohun tó dáa kéèyàn máa sapá láti wá bí nǹkan á ṣe ṣẹnuure fúnni. Àmọ́ Jésù kò sọ pé ó burú láti wá bí nǹkan á ṣe ṣẹnuure fúnni o! Ohun tó ń sọ ni pé ohun tó máa jẹ́ kí Ọlọ́run rí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun bí ẹni táyé yẹ ló yẹ kí wọ́n máa fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé kí wọ́n to “ìṣúra” tí kì í bà jẹ́ “jọ pa mọ́ fún ara [wọn] ní ọ̀run.” Ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún ni pé kí Jèhófà kà wá sí ẹni táyé yẹ. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ rán wa létí pé ọwọ́ wa ló kù sí láti pinnu ohun tá a máa fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún. Òótọ́ tó sì wà níbẹ̀ ni pé ohun tó bá wà lọ́kàn wa tàbí ohun tá a bá kà sí pàtàkì, la sábà máa ń fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún.
16. Kí ló yẹ kó dá wa lójú?
16 Tá a bá fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ ká lè ṣe ohun tó wu Jèhófà, ó yẹ kó dá wa lójú pé ó máa fún wa ní àwọn ohun tá a bá ṣaláìní. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìgbà míì wà tí ebi lè pa wá tàbí kí òùngbẹ gbẹ wá. (1 Kọ́r. 4:11) Síbẹ̀, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé: “Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mát. 6:31-33.
-