-
Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso MèsáyàÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
4, 5. Kí ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa dídé Mèsáyà, ọ̀nà wo ló sì jọ pé Mátíù gbà lo ọ̀rọ̀ Aísáyà?
4 Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà ayé Aísáyà, àwọn Hébérù mìíràn tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì ti sọ ọ́ pé Mèsáyà, Aṣáájú tòótọ́ tí Jèhófà yóò rán sí Ísírẹ́lì, ń bọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 49:10; Diutarónómì 18:18; Sáàmù 118:22, 26) Wàyí o, Jèhófà lo Aísáyà láti ṣe àlàyé síwájú sí i. Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ̀ka igi kan yóò sì yọ láti ara kùkùté Jésè; àti láti ara gbòǹgbò rẹ̀, èéhù kan yóò máa so èso.” (Aísáyà 11:1; fi wé Sáàmù 132:11.) “Ẹ̀ka igi” àti “èéhù” pa pọ̀ fi hàn pé Mèsáyà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jésè nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ Dáfídì, ẹni tí wọ́n fòróró yàn gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 16:13; Jeremáyà 23:5; Ìṣípayá 22:16) Nígbà tí Mèsáyà tòótọ́ bá dé, ìyẹn “èéhù” láti ilé Dáfídì yìí, èso rere ni yóò so.
5 Jésù ni Mèsáyà táa ṣèlérí yẹn. Ọ̀rọ̀ Aísáyà 11:1 ni Mátíù òǹkọ̀wé ìhìn rere ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé pípè tí wọ́n ń pe Jésù ní “ará Násárétì” mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì ṣẹ. Ìlú Násárétì ni wọ́n ti tọ́ Jésù dàgbà, ìyẹn ni wọ́n fi ń pè é ní ará Násárétì, ó sì jọ pé orúkọ yìí tan mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “èéhù” nínú Aísáyà 11:1.b—Mátíù 2:23, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; Lúùkù 2:39, 40.
-
-
Ìgbàlà àti Ayọ̀ Lábẹ́ Àkóso MèsáyàÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
b Lédè Hébérù, neʹtser ni wọ́n ń pe “èéhù,” Nots·riʹ ni wọ́n sì ń pe “ará Násárétì.”
-