Báwo Ni Ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ Nínú Ọlọ́run Ṣe Lágbára Tó?
‘Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.’—MÁTÍÙ 6:33.
1, 2. Kí ni ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
Ọ̀DỌ́KÙNRIN kan ń fẹ́ dẹni tó wúlò nínú ìjọ rẹ̀. Àmọ́ ìṣòro rẹ̀ ni pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀ ń dí i lọ́wọ́, kò jẹ́ kó lè wá sípàdé déédéé. Báwo ló ṣe yanjú ìṣòro yìí? Ó mójú rẹ̀ kúrò nínú àwọn nǹkan kan, ó sì kọ̀wé fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Nígbà tó yá, ó rí iṣẹ́ kan tó fún un láyè láti bójú tó àwọn ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Ní báyìí, owó tó ń gbà kéré sí ti tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó ń bójú tó ìdílé rẹ̀ bó ṣe yẹ, ó sì wúlò nínú ìjọ tó wà.
2 Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí ọ̀dọ́kùnrin yìí fi ṣe àyípadà yẹn? Ǹjẹ́ o lè ṣe irú ohun tó ṣe yẹn tó bá jẹ́ pé ìwọ lo wà nírú ipò yẹn? Ó wúni lórí pé ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ṣe yìí sì fi hàn pé wọ́n nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí tí Jésù ṣe pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Jèhófà ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé pé á bójú tó àwọn, wọn kò gbẹ́kẹ̀ lé ayé yìí.—Òwe 3:23, 26.
3. Kí nìdí táwọn kan fi ń rò pé bóyá ló bọ́gbọ́n mu láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ lónìí?
3 Àwọn kan lè máa rò pé bóyá lohun tí ọ̀dọ́kùnrin yìí ṣe bọ́gbọ́n mu pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣe le gan-an lákòókò tá a wà yìí. Lóde òní, inú òṣì paraku làwọn èèyàn kan wà nígbà táwọn kan wà nínú ọrọ̀ rẹpẹtẹ tá ò rírú rẹ̀ rí. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn láwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì ni yóò lo àǹfààní èyíkéyìí tí wọ́n bá rí láti mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fáwọn. Àmọ́ ní tàwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀, ńṣe làwọn ń ṣàníyàn nípa bí wọn ò ṣe ní dẹni tí kò lọ́rọ̀ mọ́, nítorí ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè wọn tó ń jó àjórẹ̀yìn, táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ ríṣẹ́ ṣe mọ́, táwọn agbaniṣíṣẹ́ sì fẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ máa lo gbogbo agbára wọn àti àkókò rẹpẹtẹ níbi iṣẹ́. Pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣe le koko yìí, àwọn kan lè máa rò pé, ‘Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́?’ Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn ni pé ká kọ́kọ́ ronú nípa àwùjọ kan tí Jésù bá sọ̀rọ̀.
“Ẹ Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn”
4, 5. Àpèjúwe Jésù wo ló fi hàn pé kò bọ́gbọ́n mu káwọn èèyàn Ọlọ́run máa ṣàníyàn jù bó ṣe yẹ lọ nípa ohun tí wọ́n nílò lójoojúmọ́?
4 Gálílì ni Jésù wà nígbà tó ń bá àwùjọ àwọn èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n wá láti ibi púpọ̀ sọ̀rọ̀. (Mátíù 4:25) Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn èèyàn yẹn ló jẹ́ ọlọ́rọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló jẹ́ tálákà. Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe fi wíwá ọrọ̀ nípa tara sípò àkọ́kọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ọrọ̀ tó ṣeyebíye jù lọ ló sọ pé kí wọ́n máa tò jọ, ìyẹn ọrọ̀ nípa tẹ̀mí. (Mátíù 6:19-21, 24) Jésù sọ pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀. Ọkàn kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ àti ara ju aṣọ lọ?”—Mátíù 6:25.
5 Ọ̀rọ̀ Jésù lè dà bí ohun tí kò bọ́gbọ́n mu lójú ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé báwọn ò bá ṣiṣẹ́ kára, ìyà yóò jẹ ìdílé àwọn. Àmọ́, Jésù ní kí wọ́n rántí àwọn ẹyẹ. Ojoojúmọ́ làwọn ẹyẹ wọ̀nyí máa ń wá oúnjẹ àti ibi tí wọ́n máa wọ̀ sí, síbẹ̀ Jèhófà ń bójú tó wọn. Jésù tún rán wọn létí bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn òdòdó inú igbó tí ẹwà wọn sì tayọ ẹwà Sólómọ́nì pẹ̀lú gbogbo ògo tó ní. Bí Jèhófà bá ń bójú tó àwọn ẹyẹ àtàwọn òdòdó wọ̀nyí, ṣe kò wá ní bójú tó wa ni? (Mátíù 6:26-30) Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ, ẹ̀mí wa àti ara wa ṣe pàtàkì ju oúnjẹ tá à ń rà láti fi gbé ẹ̀mí wa ró àti aṣọ tá à ń wọ̀ láti fi bo ara wa lọ. Bó bá jẹ́ àtijẹ-àtimu àti ká lè ráṣọ wọ̀ sọ́rùn là ń lo gbogbo okun wa fún láìṣe nǹkan gidi kan nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, á jẹ́ pé a kàn wà láàyè lásán ni.—Oníwàásù 12:13.
Èrò Títọ́ Tó Yẹ Ká Ní
6. (a) Ohun wo làwọn Kristẹni ní láti fúnra wọn bójú tó? (b) Ta làwọn Kristẹni gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá?
6 Àmọ́ o, Jésù kò rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe ṣiṣẹ́, pé kí wọ́n dúró kí Ọlọ́run wá máa pèsè ohun tí ìdílé wọn nílò. Kódà àwọn ẹyẹ pàápàá ní láti wá oúnjẹ kiri fún ara wọn àti fún ọmọ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní láti ṣiṣẹ́ bí wọ́n bá fẹ́ jẹun. Wọ́n ní láti bójú tó ìdílé wọn. Àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ àtàwọn tó jẹ́ ẹrú ní láti ṣiṣẹ́ kára fún ọ̀gá wọn. (2 Tẹsalóníkà 3:10-12; 1 Tímótì 5:8; 1 Pétérù 2:18) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ àgọ́ pípa láti fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. (Ìṣe 18:1-4; 1 Tẹsalóníkà 2:9) Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni wọ̀nyí kò fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn. Jèhófà ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ní ìbàlẹ̀ ọkàn táwọn ẹlòmíràn kò ní. Onísáàmù náà sọ pé: “Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dà bí Òkè Ńlá Síónì, tí a kò lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ṣùgbọ́n tí ó ń bẹ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 125:1.
7. Kí ló lè jẹ́ èrò ẹni tí kò bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dáadáa?
7 Èrò ẹni tí kò bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lè yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ onísáàmù yẹn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn máa ń wo ohun ìní tara bíi pé òun gan-an ló ń fini lọ́kàn balẹ̀. Èyí ló mú káwọn òbí máa rọ àwọn ọmọ wọn láti lo ìgbà èwe wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga pẹ̀lú ìrètí pé ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè rí iṣẹ́ olówó ńlá ṣe. Ó ṣeni láàánú pé gbogbo ìsapá yìí ti já sí àdánù ńlá fáwọn ìdílé Kristẹni kan, nítorí pé ńṣe làwọn ọmọ wọn fi nǹkan tẹ̀mí sílẹ̀ pátápátá tí wọ́n ń lé nǹkan tara.
8. Èrò tó tọ́ wo làwọn Kristẹni máa ń ní?
8 Nítorí náà, àwọn Kristẹni tí wọ́n gbọ́n mọ̀ pé ìmọ̀ràn Jésù wúlò gan-an lónìí bó ṣe wúlò ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n sì ń gbìyànjú láti ní èrò tó tọ́. Àní bí wọ́n tilẹ̀ ní láti lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn láti lè bójú tó ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ó yẹ ní ṣíṣe, síbẹ̀ wọn ò jẹ́ kí wíwá owó mú wọn pa ohun tó ṣe pàtàkì jù tì, ìyẹn nǹkan tẹ̀mí.—Oníwàásù 7:12.
“Ẹ Má Ṣàníyàn”
9. Báwo ni Jésù ṣe fọkàn àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá balẹ̀?
9 Nínú ìwàásù Jésù lórí Òkè, ó rọ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” (Mátíù 6:31, 32) Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe múnú ẹni dùn tó! Bá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, yóò máa tì wá lẹ́yìn nígbà gbogbo. Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ Jésù yìí ń múni ronú jinlẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn rán wa létí pé tá a bá ń fi “ìháragàgà” lépa àwọn nǹkan tara, èrò wa kò yàtọ̀ sí ti “àwọn orílẹ̀-èdè” nìyẹn, ìyẹn àwọn èèyàn tí wọn kì í ṣe Kristẹni tóòtọ́.
10. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan lọ bá Jésù láti gbàmọ̀ràn, báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ ohun tí ọ̀dọ́kùnrin náà nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ?
10 Nígbà kan, ọ̀dọ́kùnrin kan tó lọ́rọ̀ gan-an béèrè lọ́wọ́ Jésù pé kí ni òun yóò ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù rán an létí ohun tí Òfin Mósè sọ, èyí táwọn èèyàn ṣì ń tẹ̀ lé nígbà yẹn. Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fún Jésù pé: “Mo ti pa gbogbo ìwọ̀nyí mọ́; kí ni mo ṣaláìní síbẹ̀?” Èsì tí Jésù fún un lè máà bọ́gbọ́n mu lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Ó sọ pé: “Bí ìwọ bá fẹ́ jẹ́ pípé, lọ ta àwọn nǹkan ìní rẹ, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” (Mátíù 19:16-21) Ọ̀dọ́kùnrin náà kúrò níbẹ̀, inú rẹ̀ bà jẹ́ nítorí kò fẹ́ pàdánù ọrọ̀ tó ní. Bó ti wu kó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó, ó ṣì nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ rẹ̀ ju Jèhófà lọ.
11, 12. (a) Gbólóhùn tó ń múni ronú jinlẹ̀ wo ni Jésù sọ nípa ọrọ̀? (b) Báwo ni ohun ìní ṣe lè díni lọ́wọ́ sísin Jèhófà?
11 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kí Jésù sọ ohun kan tó yani lẹ́nu, ó ní: “Yóò jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba ọ̀run. . . . Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run.” (Mátíù 19:23, 24) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kò sí ọlọ́rọ̀ tí yóò jogún Ìjọba Ọlọ́run? Rárá o, nítorí ó sọ síwájú sí i pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.” (Mátíù 19:25, 26) Ní tòdodo, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwọn ọlọ́rọ̀ kan nígbà yẹn di Kristẹni ẹni àmì òróró. (1 Tímótì 6:17) Síbẹ̀síbẹ̀, ó nídìí pàtàkì tí Jésù fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ yíyanilẹ́nu tó sọ yẹn. Ńṣe ló ń kìlọ̀ fún wa.
12 Tó bá jẹ́ pé ohun ìní lẹnì kan gbẹ́kẹ̀ lé bíi ti ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn, ó lè dí i lọ́wọ́ fífi gbogbo ọkàn sin Jèhófà. Ìyẹn sì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó ti lọ́rọ̀ àtẹni tó “pinnu láti di ọlọ́rọ̀.” (1 Tímótì 6:9, 10) Gbígbẹ́kẹ̀lé àwọn nǹkan tara jù lè mú kẹ́nì kan di ẹni tí ohun tó ‘ṣaláìní nípa ti ẹ̀mí kò jẹ lọ́kàn’ tó bó ṣe yẹ mọ́. (Mátíù 5:3) Ohun tó máa wá ṣẹlẹ̀ ni pé, onítọ̀hún lè dẹni tí kò rí ìdí láti gbára lé Jèhófà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. (Diutarónómì 6:10-12) Ó lè máa retí pé káwọn èèyàn máa gbé òun gẹ̀gẹ̀ nínú ìjọ. (Jákọ́bù 2:1-4) Ó sì lè máa lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ̀ fún gbígbádùn ọrọ̀ rẹ̀ dípò kó máa lo àkókò náà láti sin Jèhófà.
Ní Èrò Tó Tọ́
13. Èrò òdì wo làwọn ará Laodíkíà ní?
13 Ìjọ Laodíkíà ti ọ̀rúndún kìíní jẹ́ àwọn èèyàn tí wọ́n ní èrò òdì nípa ohun ìní tara. Jésù sọ fún wọn pé: “Ìwọ wí pé: ‘Ọlọ́rọ̀ ni mí, mo sì ti kó ọrọ̀ jọ, èmi kò sì nílò ohunkóhun rárá,’ ṣùgbọ́n o kò mọ̀ pé akúùṣẹ́ ni ọ́ àti ẹni ìkáàánú fún àti òtòṣì àti afọ́jú àti ẹni ìhòòhò.” Kì í ṣe ọrọ̀ táwọn ará Laodíkíà ní ló gbé wọn dé irú ipò tó sọ wọ́n dẹni ìkáàánú fún nípa tẹ̀mí yẹn. Bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ dípò kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ló fà á. Òun ló mú kí wọ́n lọ́ wọ́ọ́wọ́ọ́ nípa tẹ̀mí, Jésù ò sì ní pẹ́ ‘pọ̀ wọ́n jáde’ kúrò lẹ́nu rẹ̀.—Ìṣípayá 3:14-17.
14. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi gbóríyìn fáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni?
14 Ní ìdà kejì, Pọ́ọ̀lù yin àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni nítorí ìwà wọn nígbà tí inúnibíni kan kọ́kọ́ wáyé. Ó sọ pé: “Ẹ fi ìbánikẹ́dùn hàn fún àwọn tí ń bẹ nínú ẹ̀wọ̀n, ẹ sì fi ìdùnnú gba pípiyẹ́ àwọn nǹkan ìní yín, ní mímọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ní ohun ìní dídárajù àti èyí tí ó wà lọ títí.” (Hébérù 10:34) Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn kò banú jẹ́ nítorí pé wọ́n pàdánù ohun ìní wọn. Wọn ò pàdánù ayọ̀ wọn nítorí pé ohun ìní tó ṣe pàtàkì jù lọ ni wọ́n dì mú ṣinṣin, ìyẹn “ohun ìní dídárajù àti èyí tí ó wà lọ títí.” Bíi ti oníṣòwò inú àpèjúwe Jésù tó yááfì gbogbo ohun tó ní nítorí péálì kan tó níye lórí, wọ́n pinnu láti di ìrètí Ìjọba náà mú ṣinṣin, láìka ohunkóhun tó lè ná wọn sí. (Mátíù 13:45, 46) Ẹ̀mí rere tí wọ́n ní yìí mà dára o!
15. Báwo ni ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni lórílẹ̀-èdè Làìbéríà ṣe fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́?
15 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní irú ẹ̀mí rere tí wọ́n ní yìí lónìí. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Làìbéríà, wọ́n fún ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni láǹfààní láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì. Lórílẹ̀-èdè yẹn, ohun tó máa jẹ́ kí ọkàn ẹni balẹ̀ lọ́jọ́ iwájú làwọn èèyàn ka irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ sí. Àmọ́ aṣáájú-ọ̀nà lòun ní tiẹ̀, ìyẹn ajíhìnrere tó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù, wọ́n sì ti pè é pé kó wá sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe onígbà díẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin náà yàn láti wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, kò sì fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún tó ń ṣe sílẹ̀. Ó lọ síbi tí wọ́n yàn án sí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́kànlélógún láàárín oṣù mẹ́ta. Ọ̀dọ́bìnrin yìí àtàwọn ẹgbàágbèje mìíràn bíi tirẹ̀ ń wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, kódà bí wọ́n tiẹ̀ máa pàdánù àwọn nǹkan tó lè jẹ́ àǹfààní tara. Kí ló mú kí wọ́n nírú ẹ̀mí rere bẹ́ẹ̀ nínú ayé tó kún fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì yìí? Ìdí ni pé, wọ́n ti ní àwọn ànímọ́ rere kan. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára ànímọ́ wọ̀nyẹn yẹ̀ wò.
16, 17. (a) Kí nìdí tí ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni fi ṣe pàtàkì bá a bá fẹ́ nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run?
16 Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni: Bíbélì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́. Má ṣe di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ.” (Òwe 3:5-7) Nígbà mìíràn, ipa ọ̀nà kan lè dà bíi pé ó dára tá a bá fojú tí ayé fi ń wo nǹkan wò ó. (Jeremáyà 17:9) Síbẹ̀, Jèhófà ni Kristẹni kan tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn máa ń wò fún ìtọ́sọ́nà. (Sáàmù 48:14) Ó máa ń fi ìrẹ̀lẹ̀ wá ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ Jèhófà ‘nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣe,’ ì báà jẹ́ nínú ìjọ, nínú ẹ̀kọ́ ìwé, níbi iṣẹ́, nínú eré ìnàjú tàbí ohunkóhun mìíràn.—Sáàmù 73:24.
17 Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí Jèhófà: Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Bá a bá ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ńṣe ló máa dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu láti ‘lo ayé yìí dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.’ (1 Kọ́ríńtì 7:31) Àmọ́ ṣá o, bí ìgbàgbọ́ wa bá lágbára, a ó pinnu lọ́kàn wa pé a ó máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Báwo la ṣe lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára? Nípa sísúnmọ́ Jèhófà nínú àdúrà àtọkànwá àti nípa ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé ni. (Sáàmù 1:1-3; Fílípì 4:6, 7; Jákọ́bù 4:8) Àwa náà lè gbàdúrà bíi ti Dáfídì Ọba pé: “Ìwọ Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé. Mo ti wí pé: ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ Oore rẹ mà pọ̀ yanturu o!”—Sáàmù 31:14, 19.
18, 19. (a) Báwo ni fífi aápọn ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe ń mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú rẹ̀ lágbára sí i? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni kan múra tán láti yááfì àwọn ohun kan?
18 Jíjẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà: Nínú ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ńṣe ni níní ìgbẹ́kẹ̀lé pé àwọn ìlérí Jèhófà yóò ṣẹ àti jíjẹ́ aláápọn jọ ń rìn pọ̀, ó sọ pé: “A fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin.” (Hébérù 6:11) Bọ́wọ́ wa bá ń dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó dájú pé yóò tì wá lẹ́yìn. Gbogbo ìgbà tá a bá sì rí ìtìlẹ́yìn náà gbà ni ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú rẹ̀ á máa lágbára sí i, a ó dẹni tó “fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,” a ó sì “di aláìṣeéṣínípò.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) A ó máa tipa báyìí sọ ìgbàgbọ́ wa dọ̀tun, ìrètí wa á sì fìdí múlẹ̀ ṣinṣin.—Éfésù 3:16-19.
19 Mímúratán láti yááfì àwọn ohun kan: Pọ́ọ̀lù yááfì iṣẹ́ tó máa ń mówó wọlé kó bàa lè tẹ̀ lé Jésù. Ó ṣe kedere pé ohun tó dára ló ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbà mìíràn wà tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún un nípa tara. (1 Kọ́ríńtì 4:11-13) Jèhófà kò ṣèlérí fún wa pé a ó máa gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ, ìgbà mìíràn sì wà tí nǹkan kì í rọgbọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Mímúra tá a múra tán láti mú àwọn ohun ìdíwọ́ kúrò nígbèésí ayé wa, tá a sì ń yááfì àwọn nǹkan kan, fi bí ìpinnu wa láti sin Jèhófà ṣe lágbára tó hàn.—1 Tímótì 6:6-8.
20. Kí nìdí tí sùúrù fi ṣe pàtàkì fáwọn tó fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́?
20 Sùúrù: Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Nítorí náà, ẹ mú sùúrù, ẹ̀yin ará, títí di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa.” (Jákọ́bù 5:7) Nínu ayé kòókòó jàn-ánjàn-án yìí, ó ṣòro láti jẹ́ onísùúrù. A máa ń fẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ nǹkan ní kíákíá. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá láti máa fara wé àwọn tí wọ́n “tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Hébérù 6:12) Múra tán láti dúró de Jèhófà. Ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ohun téèyàn ń dúró dè!
21. (a) Kí là ń fi hàn nígbà tá a bá fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́? (b) Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé èyí?
21 Dájúdájú, ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa pé ká máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ wúlò gan-an. Tá a bá ṣe ohun tó sọ yìí, à ń fi hàn pé lóòótọ́ la gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí a sì yan ọ̀nà kan ṣoṣo tó lè mú àwọn Kristẹni bọ́ lọ́wọ́ ewu. Àmọ́ Jésù tún gbà wá nímọ̀ràn láti máa ‘wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò rí ìdí tó fi jẹ́ pé òde òní gan-an la nílò ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí jù lọ.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Èrò wo ni Jésù gbà wá níyànjú pé ká ní nípa ohun ìní tara?
• Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ràkúnmí àti ojú abẹ́rẹ́?
• Àwọn ànímọ́ Kristẹni wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Tálákà ni ọ̀pọ̀ àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ náà nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ rẹ̀ ju Ọlọ́run lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Oníṣòwò inú àpèjúwe Jésù yááfì gbogbo ohun tó ní nítorí péálì kan tó níye lórí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bọ́wọ́ wa bá dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó dájú pé Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́