Máa Wá Ìjọba Ọlọ́run, Má Ṣe Wá Àwọn Nǹkan
“Ẹ máa wá ìjọba [Ọlọ́run] nígbà gbogbo, a ó sì fi nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín.”—LÚÙKÙ 12:31.
1. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn ohun tá a nílò àtàwọn ohun tá a fẹ́?
ÀWỌN ohun tí ẹ̀dá nílò kò pọ̀, àwọn ohun tó wu ẹ̀dá ni ò lópin. Ó jọ pé ọ̀pọ̀ ò mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn nǹkan tó wù wọ́n àtàwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn? Àwọn ohun tá a “nílò” ni àwọn nǹkan kòṣeémáàní tá a gbọ́dọ̀ ní nígbèésí ayé. Bí àpẹẹrẹ, a nílò oúnjẹ, aṣọ àti ilé. Àwọn nǹkan tó “wù” wá làwọn nǹkan tá a kàn fẹ́, àmọ́ tí kò pọn dandan pé ká ní wọn.
2. Kí ni díẹ̀ lára ohun táwọn èèyàn máa ń fẹ́?
2 Ohun táwọn èèyàn fẹ́ máa ń yàtọ̀ síra, ibi táwọn èèyàn ń gbé ló sì máa ń pinnu ohun tí wọ́n fẹ́. Ní àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ohun táwọn èèyàn fẹ́ lè máà kọjá owó tí wọ́n fẹ́ fi ra fóònù, ọ̀kadà tàbí ilẹ̀ tí wọ́n lè fi kọ́lé. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, ó lè jẹ́ pé aṣọ olówó gọbọi ni wọ́n máa fẹ́ rà kún inú kọ́ńbọ̀dù wọn, wọ́n lè fẹ́ ilé tó tóbi ju èyí tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀ lọ tàbí mọ́tò bọ̀gìnnì. Àmọ́, láìka ibi tá à ń gbé sí tàbí bá a ṣe lówó lọ́wọ́ tó, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í wá bá a ṣe máa kó àwọn nǹkan jọ, yálà a nílò wọn tàbí a ò nílò wọn, tàbí kẹ̀ bóyá agbára wa ká wọn tàbí agbára wa ò ká wọn.
MÁ ṢE KÓ OHUN ÌNÍ JỌ
3. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá lẹ́nì kan ń kó ohun ìní jọ?
3 Kí ló túmọ̀ sí tá a bá lẹ́nì kan ń kó ohun ìní jọ? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn máa wá bó ṣe máa kó ọrọ̀ jọ pelemọ dípò kó máa wá bó ṣe máa mú kí ìjọsìn rẹ̀ túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Inú ọkàn èèyàn ni ìfẹ́ ọrọ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀, ohun ìní láá máa kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, òun láá sì máa ronú lé lórí ṣáá. Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo nǹkan láá máa wu ẹni náà pé kó ní. Kódà, àwọn tálákà pàápàá lè máa forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè kó dúkìá jọ. Ó lè mú kí wọ́n dín ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run kù.—Héb. 13:5.
4. Báwo ni Sátánì ṣe máa ń lo “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú”?
4 Sátánì máa ń lo ìpolówó ọjà láti mú ká ronú pé ó dìgbà tá a bá kó àwọn nǹkan ìní jọ tìrìgàngàn, títí kan àwọn nǹkan tá ò nílò ká tó lè láyọ̀. Ó mọ bó ṣe lè lo “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” láti dẹkùn mú wa. (1 Jòh. 2:15-17; Jẹ́n. 3:6; Òwe 27:20) Oríṣiríṣi nǹkan ló kún inú ayé, títí kan àwọn nǹkan tó lòde àtèyí tí kò jọjú mọ́, àwọn míì tiẹ̀ máa ń fani mọ́ra gan-an. Ṣé o ti ra ohun tó wọ̀ ẹ́ lójú rí torí pé o rí ìpolówó rẹ̀ tàbí torí pé o rí i lọ́jà, àmọ́ tó o wá rí i nígbà tó yá pé kò wúlò fún ẹ rárá? Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń mú ayé sú ni, ó sì máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n lè fa ìpínyà ọkàn fún wa débi tá ò fi ní máa ka Bíbélì déédéé mọ́, tá ò sì ní máa múra ìpàdé sílẹ̀ mọ́. Ó lè mú ká máa pa ìpàdé jẹ, ká má sì lọ sóde ẹ̀rí déédéé mọ́. Rántí ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù fún wa pé: ‘Ayé àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ń kọjá lọ.”
5. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń fi gbogbo ìgbésí ayé wọn kó ohun ìní jọ?
5 Sátánì ò fẹ́ ká sin Jèhófà, Ọrọ̀ ló fẹ́ ká máa lé. (Mát. 6:24) Àwọn tó ń fi gbogbo ìgbésí ayé wọn kó ohun ìní jọ kì í láyọ̀, ìgbésí ayé wọn kì í sì í nítumọ̀ torí pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀. Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé ìjọsìn Ọlọ́run lè má ṣe pàtàkì sí wọn mọ́, wọ́n sì lè ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìjákulẹ̀. (1 Tím. 6:9, 10; Ìṣí. 3:17) Ohun tí Jésù sọ nínú àkàwé akárúgbìn nìyẹn. Nígbà tí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run bọ́ “sáàárín àwọn ẹ̀gún . . . , ìfẹ́-ọkàn fún àwọn nǹkan yòókù gbógun wọlé, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ó sì di aláìléso.”—Máàkù 4:14, 18, 19.
6. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù?
6 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù, akọ̀wé wòlíì Jeremáyà. Bí ìparun Jerúsálẹ́mù tá a sọ tẹ́lẹ̀ ṣe ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀, Bárúkù bẹ̀rẹ̀ sí í “wá àwọn ohun ńláńlá” fún ara rẹ̀, tó sì jẹ́ pé àwọn nǹkan ọ̀hún ò ní tọ́jọ́. Ohun tí Jèhófà ṣèlérí fún un ló yẹ kó máa ronú lé. Jèhófà sọ fún un pé: “Èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ.” (Jer. 45:1-5) Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní dá ohun ìní ẹnikẹ́ni sí nínú ìlú tó máa tó pa run. (Jer. 20:5) Bí àwa náà ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí, kì í ṣe ìsinsìnyí ló yẹ ká máa to ọrọ̀ jọ pelemọ fún ara wa. Kò yẹ ká máa retí pé èyíkéyìí lára dúkìá wa máa la ìpọ́njú ńlá já bó ti wù kí nǹkan ọ̀hún ṣeyebíye tó.—Òwe 11:4; Mát. 24:21, 22; Lúùkù 12:15.
7. Kí la máa jíròrò báyìí, kí sì nìdí?
7 Jésù fún wa ní ìmọ̀ràn nípa bá a ṣe lè ní àwọn nǹkan tá a nílò síbẹ̀ tọ́kàn wa ò ní pín yà. Tá a bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò, a ò ní máa kó dúkìá jọ, a ò sì ní máa ṣàníyàn. Jésù sọ bá a ṣe lè ṣe é nínú Ìwàásù Lórí Òkè. (Mát. 6:19-21) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ka ohun tó wà nínú Mátíù 6:25-34, ká sì jíròrò rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá rí i pé Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ ká máa wá, kì í ṣe àwọn nǹkan.—Lúùkù 12:31.
JÈHÓFÀ MÁA Ń PÈSÈ ÀWỌN OHUN TÁ A NÍLÒ
8, 9. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣàníyàn jù nípa àwọn nǹkan tá a nílò? (b) Kí ni Jésù mọ̀ nípa àwa èèyàn àtàwọn ohun tá a nílò? What did Jesus know about humans and their needs?
8 Ka Mátíù 6:25. Nígbà tí Jésù sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n “dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn [wọn],” ohun tó ń sọ ni pé kí wọ́n “má da ara wọn láàmú mọ́.” Wọ́n ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n da ara wọn láàmú lé lórí. Ó sì nídìí tí Jésù fi sọ pé kí wọ́n má ṣàníyàn mọ́. Ìdí ni pé téèyàn bá ń ṣàníyàn, kò ní lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé. Ọ̀pọ̀ nǹkan tá a gbà pé ó pọn dandan pàápàá ni ò yẹ ká máa ṣàníyàn lé. Jésù tẹ ọ̀rọ̀ yìí mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn torí pé ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló kìlọ̀ fún wọn nínú ìwàásù náà.—Mát. 6:27, 28, 31, 34.
9 Kí nìdí tí Jésù fi sọ fún wa pé ká má ṣàníyàn nípa ohun tá a máa jẹ, ohun tá a máa mu tàbí aṣọ tá a máa wọ̀? Ṣé àwọn nǹkan yìí ò ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ni? Ó dájú pé wọ́n ṣe pàtàkì. Tá ò bá ní àwọn nǹkan yìí, ó dájú pé a máa ṣàníyàn, Jésù náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó mọ ohun táwọn èèyàn nílò lójoojúmọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó mọ̀ pé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á máa gbé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1) Irú àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn ni àìríṣẹ́ ṣe, owó ọjà tó ń lọ sókè, àìtó oúnjẹ àti ipò òṣì tó ń ni ọ̀pọ̀ lára. Síbẹ̀, Jésù mọ̀ pé ‘ọkàn ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ, ara sì sàn ju aṣọ lọ.’
10. Nígbà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, kí ló sọ pé ó yẹ kó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé wọn?
10 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ fún àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n máa bẹ Baba wọn ọ̀run pé kó pèsè àwọn ohun kòṣeémáàní fún wọn, ó ní kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wọn ní oúnjẹ tí wọ́n nílò fún “ọjọ́ òní.” (Mát. 6:11) Nígbà tó yá, ó tún sọ ọ́ lọ́nà míì pé: “Máa fún wa ní ońjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.” (Lúùkù 11:3, Ìròhìn Ayọ̀) Àmọ́, Jésù ò sọ pé ká jẹ́ kí àwọn ohun tá a nílò gbà wá lọ́kàn jù. Nínú àdúrà yìí kan náà, Ìjọba Ọlọ́run ni Jésù sọ pé ká kọ́kọ́ máa gbàdúrà fún. (Mát. 6:10; Lúùkù 11:2) Kí ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lè balẹ̀, Jésù sọ pé Jèhófà lágbára láti pèsè àwọn ohun tá a nílò.
11, 12. Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe ń tọ́jú àwọn ẹyẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
11 Ka Mátíù 6:26. Ẹ jẹ́ ká “ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.” Bí àwọn ẹyẹ yẹn ṣe kéré tó, wọ́n máa ń jẹun gan-an, wọ́n máa ń jẹ ọ̀pọ̀ kóró, èso, kòkòrò àti ekòló. Ká sọ pé ó ṣeé ṣe láti mú kí ẹyẹ tóbi tó èèyàn ni, àá rí i pé wọ́n ń jẹun ju àwa èèyàn lọ. Síbẹ̀, wọn kì í dáko kí wọ́n tó jẹun. Jèhófà máa ń pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò. (Sm. 147:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ pọ̀ yanturu fún wọn, Ọlọ́run kì í fi oúnjẹ nù wọ́n, wọ́n ṣì ní láti wá oúnjẹ náà lọ.
12 Jésù mọ̀ pé tí Jèhófà bá ń pèsè oúnjẹ fáwọn ẹyẹ, ó dájú pé ó máa pèsè oúnjẹ fún àwa èèyàn náà.[1] (1 Pét. 5:6, 7) Jèhófà ò ní fi oúnjẹ nù wá, àmọ́ ó lè mú kí àwọn ohun tá a gbìn hù tàbí kó pèsè owó tá a máa fi ra ohun tá a nílò. Jèhófà tún lè mú kí àwọn míì fún wa lára ohun tí wọ́n ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò sọ bí Ọlọ́run ṣe ń pèsè ilé fáwọn ẹyẹ, síbẹ̀ Jèhófà ti fún wọn ní ọgbọ́n àti ohun tí wọ́n á fi kọ́ ìtẹ́ tí wọ́n á máa gbé. Jèhófà lè ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè rí ilé tó dáa tí àwa àti ìdílé wa máa gbé.
13. Kí ló fi hàn pé a níye lórí ju àwọn ẹyẹ lọ?
13 Jésù wá bi àwọn tó ń tẹ́tí sí i pé: “Ẹ kò ha níye lórí ju [àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run] lọ bí?” Ó dájú pé Jésù mọ̀ pé òun máa tó fi ẹ̀mí òun rúbọ fún aráyé. (Fi wé Lúùkù 12:6, 7.) Kì í ṣe àwọn ẹyẹ tàbí àwọn ẹranko ni Jésù kú fún. Àwa èèyàn ló kú fún ká lè wà láàyè títí láé.—Mát. 20:28.
14. Kí ni ẹni tó ń ṣàníyàn ò lè ṣe láé?
14 Ka Mátíù 6:27. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé ẹni tó ń ṣàníyàn ò lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún gígùn ìwàláàyè rẹ̀? Ìdí ni pé àníyàn nípa àwọn ohun kòṣeémáàní kò lè fi kún iye ọdún tá a máa lò láyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dín in kù.
15, 16. (a) Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn òdòdó? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa, kí sì nìdí?
15 Ka Mátíù 6:28-30. Kò sẹ́ni tí kò fẹ́ wọ aṣọ tó rẹwà, pàápàá jù lọ téèyàn bá ń lọ sí ìpàdé, òde ẹ̀rí tàbí àwọn àpéjọ wa. Síbẹ̀, ṣó yẹ ká máa ṣàníyàn nípa aṣọ? Jésù pe àfíyèsí wa sí iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà míì. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ lára “àwọn òdòdó lílì pápá.” Ó lè jẹ́ pé àwọn òdòdó kan tó lẹ́wà ni Jésù ní lọ́kàn, bí àwọn òdòdó etí odò àtàwọn òdòdó míì tó láwọ̀ mèremère. Àwọn òdòdó yìí kì í ránṣọ tàbí hun aṣọ fún ara wọn. Síbẹ̀, tí wọ́n bá tanná, wọ́n máa ń dùn ún wò gan-an. Kódà, “Sólómọ́nì pàápàá nínú gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe ní ọ̀ṣọ́ bí ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí
16 Ẹ má gbàgbé ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Bí Ọlọ́run bá wọ ewéko pápá láṣọ báyìí . . . , òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?” Ó dájú pé Jèhófà máa pèsè, àmọ́ ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára. (Mát. 8:26; 14:31; 16:8; 17:20) Torí náà, wọ́n ní láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Àwa ńkọ́? Ṣó dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti pèsè ohun tá a nílò àti pé ó wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀?
17. Kí ló lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́?
17 Ka Mátíù 6:31, 32. Kò yẹ ká máa fara wé àwọn tí kò nígbàgbọ́ pé Jèhófà lè pèsè fún gbogbo àwọn tó bá ń fi Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. Tó bá jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn ń lé kiri làwa náà ń lé, àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà lè bà jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá ṣe ohun tó yẹ ká ṣe, tá à ń fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, Jèhófà máa pèsè ohun rere fún wa. Tá a bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, a máa jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn, ìyẹn oúnjẹ, aṣọ àti ilé.—1 Tím. 6:6-8.
ṢÉ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN LO FI SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́ NÍGBÈÉSÍ AYÉ RẸ?
18. Kí ni Jèhófà mọ̀ nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, kí ló sì máa ṣe nípa rẹ̀?
18 Ka Mátíù 6:33. Àwa ọmọ ẹ̀yìn Kristi gbọ́dọ̀ máa fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé, ‘gbogbo nǹkan mìíràn ni a ó fi kún un fún wa.’ Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí,” ìyẹn àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé. Jèhófà mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nílò, kódà kí àwa fúnra wa tó mọ̀ pé a máa nílò wọn. Jèhófà mọ̀ pé a nílò oúnjẹ, aṣọ àti ilé. (Fílí. 4:19) Ó mọ àwọn aṣọ wa tí kò ní pẹ́ gbó. Ó mọ irú oúnjẹ tá a nílò àti irú ilé tó máa tu àwa àti ìdílé wa lára. Ó dájú pé Jèhófà máa bójú tó gbogbo àwọn nǹkan tá a nílò ní ti gidi.
19. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa da ara wa láàmú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
19 Ka Mátíù 6:34. Jésù tún sọ nígbà kejì pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé.” Kò fẹ́ ká da àníyàn tòní pọ̀ mọ́ tọ̀la, ó fẹ́ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Téèyàn bá ń da ara rẹ̀ láàmú láìnídìí nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ó lè máa gbára lé ara rẹ̀ dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ìyẹn sì lè ba àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.—Òwe 3:5, 6; Fílí. 4:6, 7.
MÁA WÁ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN LÁKỌ̀Ọ́KỌ́, JÈHÓFÀ MÁA PÈSÈ FÚN Ẹ́
20. (a) Kí làwọn nǹkan tó o lè máa lé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? (b) Báwo lo ṣe lè mú kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn?
20 Téèyàn bá ń lé bó ṣe máa kó dúkìá jọ dípò kó máa lé Ìjọba Ọlọ́run, asán ni gbogbo rẹ̀ máa já sí. Àwọn nǹkan tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ló yẹ ká máa lé. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o lè lọ dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i? Ṣé o lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà? Tó bá jẹ́ pé aṣáájú-ọ̀nà ni ẹ́, ṣé o lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run? Ṣé o lè máa tilé wá ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tàbí ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè láwọn ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀? Ṣé o lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó Sì Ń Kọ́ Ọ tàbí kó o lọ bá wọn ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba? Ronú nípa bó o ṣe lè máa ṣọ́wó ná tàbí kó o dín iṣẹ́ tó ò ń ṣe kù, kó o lè túbọ̀ ráyè fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Gbàdúrà, kó o sì ronú nípa ohun tó wà nínú àpótí náà “Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ohun Ìní Díẹ̀ Tẹ́ Ẹ Lọ́rùn,” Bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn ohun tó ò ń lé.
21. Kí ló máa mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
21 Ó nídìí tí Jésù fi sọ pé ká máa wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ dípò àwọn nǹkan. Tá a bá ń wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, a ò ní máa ṣàníyàn nípa àwọn ohun tá a nílò. Àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àá sì fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e tó bá jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun tó wù wá tàbí táyé ń gbé lárugẹ là ń rà, kódà tá a bá ní owó rẹ̀ lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn nísinsìnyí, àá “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”—1 Tím. 6:19.
^ [1] (ìpínrọ̀ 12) Ó máa ń ṣòro fún àwọn Kristẹni kan láti rí oúnjẹ tó tó jẹ. Ká lè mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gbà á, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́, September 15, 2014, ojú ìwé 22.