Rí i Dájú Pé O Fi Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣáájú!
Alẹ́ ọjọ́ ìpàdé ni, ṣùgbọ́n o níṣẹ́ láti ṣe. Èwo ni ìwọ yóò fi ṣáájú?
O JẸ́ ọkọ, o sì tún jẹ́ bàbá. Bí iṣẹ́ òòjọ́ tí ó mú kí àárẹ̀ mú ọ ti ń parí lọ, ọkàn rẹ lọ sí ìpàdé ìjọ tí ẹ óò ṣe ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Bí o bá tètè kúrò ní ibi iṣẹ́, ìwọ yóò ní àkókò tí ó tó láti wẹ̀, kí o pààrọ̀ aṣọ rẹ, kí o sì tètè jẹun kí o tó lọ sí ìpàdé. Lójijì, ọ̀gá rẹ dé, ó sì ní kí o ṣiṣẹ́ díẹ̀ sí i. Ó ṣèlérí pé òun yóò sanwó tí ó jọjú fún ọ. O nílò owó yẹn.
Bóyá ìyàwóolé tàbí ìyálọ́mọ ni ọ́. Bí o ti ń gbọ́únjẹ alẹ́, o tajú kán rí àwọn aṣọ tí a kò tí ì lọ̀, tí a óò sì nílò àwọn kan nínú wọn lọ́la. O bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Bí mo bá lọ sí ìpàdé lálẹ́ yìí, nígbà wo ni màá ráyè lọ aṣọ yìí?’ Nígbà tí ó jẹ́ pé kò tí ì pẹ́ tí o gba iṣẹ́ àṣedalẹ́ yìí, o ń kọ́ bí o ṣe nira tó láti bójú tó àwọn iṣẹ́ ilé àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́.
Bóyá akẹ́kọ̀ọ́ sì ni ọ́. Nínú iyàrá rẹ, orí tábìlì rẹ̀ ga gègèrè fún àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá. Ó ti pẹ́ díẹ̀ tí a ti yan àwọn kan lára rẹ̀ fún ọ, ṣùgbọ́n ò ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ sì ti wá wà nílẹ̀ fún ọ báyìí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ó ń ṣe ọ́ bíi pé kí o sọ fún àwọn òbí rẹ pé kí wọ́n yọ̀ǹda fún ọ láti jókòó sílé kí o bàa lè parí iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ.
Èwo ni ìwọ yóò fi ṣáájú: iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, aṣọ lílọ̀, iṣẹ́ àṣetiléwá, tàbí ìpàdé ìjọ? Nípa tẹ̀mí, kí ló túmọ̀ sí láti fi àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù ṣáájú? Kí ni èrò Jèhófà?
Èwo Ni Ká Fi Ṣáájú?
Kété lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba Òfin Mẹ́wàá, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣa igi jọ ní ọjọ́ Sábáàtì. Òfin ka èyí léèwọ̀ pátápátá. (Númérì 15:32-34; Diutarónómì 5:12-15) Báwo ni ò bá ti dá ẹjọ́ náà? Ṣé ò bá fi ọkùnrin náà sílẹ̀ ni, ní sísọ pé, ó ṣe tán, kì í ṣe pé ó ń ṣiṣẹ́ láti gbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì ṣùgbọ́n láti pèsè ohun kòṣeémánìí fún ìdílé rẹ̀? Ìwọ yóò ha ti sọ pé ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni ó wà nínú ọdún tí a fi lè pa Sábáàtì mọ́ àti pé a lè dárí jì í fún pípàdánù àǹfààní náà ní ọjọ́ kan ṣoṣo, bóyá nítorí pé ọkùnrin náà kùnà láti wéwèé ṣáájú bí?
Jèhófà fojú tí ó ṣe pàtàkì ju ìyẹn wo ọ̀ràn náà. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí ó ṣe, Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Láìṣe àní-àní, ọkùnrin náà ni kí a fi ikú pa.’” (Númérì 15:35) Èé ṣe tí ohun tí ọkùnrin náà ṣe fi ká Jèhófà lára tó bẹ́ẹ̀?
Àwọn èèyàn náà ní ọjọ́ mẹ́fà láti kó igi jọ, kí wọ́n sì bójú tó àìní wọn fún oúnjẹ, aṣọ, àti ilé. Wọ́n gbọ́dọ̀ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún àìní tẹ̀mí. Bí kò tilẹ̀ burú láti kó igi jọ, ó burú láti lo àkókò tí ó yẹ kí a yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn Jèhófà fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Mósè, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò ha kọ́ wa bí a ṣe lè ṣètò àwọn ohun àkọ́múṣe wa lónìí bí?—Fílípì 1:10.
Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lo 40 ọdún nínú aginjù, wọ́n múra láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ó ti sú àwọn kan láti máa jẹ mánà tí Ọlọ́run pèsè nínú aginjù, kò sì sí iyèméjì pé wọ́n ń wọ̀nà fún yíyí oúnjẹ wọn padà. Láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye tí ó yẹ bí wọ́n ti ń wọ ilẹ̀ náà, “tí ń ṣàn fun wàrà àti oyin,” Jèhófà rán wọn létí pé: “Ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni ènìyàn fi ń wà láàyè.”—Ẹ́kísódù 3:8; Diutarónómì 8:3.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ṣiṣẹ́ kára fún “wàrà àti oyin.” Àwọn ọmọ ogun wà tí wọ́n ni láti ṣẹ́gun, ilé wà tí wọn ní láti kọ́, pápá sì wà tí wọn yóò fi ṣọ̀gbìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti ya àkókò kan sọ́tọ̀ lóòjọ́ fún ṣíṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Wọ́n tún ní láti wá àkókò láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ọ̀nà Ọlọ́run. Jèhófà wí pé: “Kí ẹ fi [àwọn òfin mi] kọ́ àwọn ọmọ yín, kí [wọ́n] bàa lè máa sọ̀rọ̀ wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí [wọ́n] bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí [wọ́n] bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí [wọ́n] bá dìde.”—Diutarónómì 11:19.
Ìgbà mẹ́ta lọ́dún ni a pàṣẹ fún ọkùnrin kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì àti aláwọ̀ṣe ní ilẹ̀ náà láti fara hàn níwájú Jèhófà. Nítorí tí ọ̀pọ̀ olórí ìdílé mọ̀ pé gbogbo ìdílé náà ni yóò jàǹfààní nípa tẹ̀mí nínú irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣètò pé kí aya wọn àti àwọn ọmọ wọn bá wọn lọ. Ṣùgbọ́n ta ni yóò máa ṣọ́ ilé àti oko wọn tí àwọn ọ̀tá bá dé nígbà tí ìdílé náà ti rìnrìn àjò? Jèhófà ṣèlérí pé: “Ojú ẹnikẹ́ni kì yóò sì wọ ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ láti rí ojú Jèhófà Ọlọ́run ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún.” (Ẹ́kísódù 34:24) Ó gba ìgbàgbọ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbà pé bí àwọn bá fi ire tẹ̀mí ṣáájú, àwọn kò ní pàdánù ohunkóhun. Jèhófà ha mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ bí? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́!
Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́
Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti fi àwọn góńgó tẹ̀mí ṣáájú ohun gbogbo mìíràn. Nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, ó rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:31, 33) Kété lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn Kristẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn. Ọ̀pọ̀ Júù tàbí aláwọ̀ṣe Júù ni ó rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù fún ayẹyẹ àjọ̀dún Pẹ́ńtíkọ́sì ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀. Wọ́n gbọ́, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìhìn rere nípa Jésù Kristi. Bí wọ́n ti ń hára gàgà láti gbọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa ìgbàgbọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà, wọ́n dúró sí Jerúsálẹ́mù. Ohun tí wọ́n ní lọ́wọ́ kò tó nǹkan mọ́, ṣùgbọ́n ohun ti ara kò fi bẹ́ẹ̀ jọ wọ́n lójú. Wọ́n ti rí Mèsáyà náà! Àwọn Kristẹni arákùnrin wọn ṣàjọpín ohun ti ara tí wọ́n ní pẹ̀lú wọn kí gbogbo wọn bàa lè máa bá a nìṣó ní “bíbá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì àti . . . nínú àdúrà.”—Ìṣe 2:42.
Nígbà tí ó yá, àwọn Kristẹni kan kò ka pípéjọpọ̀ déédéé fún ìkẹ́gbẹ́pọ̀ nínú àwọn ìpàdé sí mọ́. (Hébérù 10:23-25) Bóyá wọ́n ti di onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì, tí wọn kó ka àwọn nǹkan tẹ̀mí sí mọ́ níbi tí wọ́n ti ń gbìyànjú láti rí i pé owó kò wọ́n àwọn àti ìdílé wọn. Lẹ́yìn rírọ àwọn arákùnrin rẹ̀ láti má ṣe máa pa ìpàdé jẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí òun ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’”—Hébérù 13:5.
Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù bọ́ sákòókò gan-an. Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí àwọn Hébérù, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù ti Cestius Gallus yí Jerúsálẹ́mù ká. Àwọn Kristẹni olóòótọ́ rántí ìkìlọ̀ Jésù pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí [èyí] . . . , kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀, tàbí kí ó wọlé lọ mú ohunkóhun jáde kúrò nínú ilé rẹ̀; kí ẹni tí ó wà ní pápá má sì padà sí àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀.” (Máàkù 13:14-16) Wọ́n mọ̀ pé lílà á já wọn sinmi lórí ṣíṣègbọràn sí ìtọ́ni Jésù, kì í ṣe bí iṣẹ́ wọn ti ń lọ déédéé sí tàbí ìníyelórí dúkìá wọn. Kò sí àní-àní pé ó rọrùn fún àwọn tí wọ́n ti dáhùn padà sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n sì ti fi ire tẹ̀mí ṣáájú láti fi ilé, iṣẹ́, aṣọ, àti àwọn ohun ìní ṣíṣeyebíye sílẹ̀, kí wọ́n sì sá lọ sórí òkè ju ẹnikẹ́ni tí kò tí ì ja ara rẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ ìfẹ́ owó.
Bí Àwọn Kan Ṣe Fi Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣáájú Lónìí
Àwọn Kristẹni olóòótọ́ mọyì ìkẹ́gbẹ́pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, ọ̀pọ̀ sì ń fi ọ̀pọ̀ nǹkan rúbọ láti lè wá sí àwọn ìpàdé. Ní àwọn àdúgbò kan, iṣẹ́ àṣegbà nìkan ni ó wà. Arákùnrin kan gbà láti máa gbaṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní alẹ́ Saturday, tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lò ládùúgbò náà láti fi ṣe eré ìnàjú, bí àwọn pẹ̀lú bá lè gba iṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ní àwọn alẹ́ tí ó bọ́ sọ́jọ́ ìpàdé. Àwọn arákùnrin mìíràn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àṣegbà máa ń lọ sí ìpàdé ní ìjọ ìtòsí bí iṣẹ́ wọn bá dí wọn lọ́wọ́ láti lọ sí ìpàdé tiwọn. Lọ́nà yìí, wọn kì í sábà pa ìpàdé jẹ. Olùfìfẹ́hàn tuntun kan ní Kánádà tètè mọ ìjẹ́pàtàkì Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, ṣùgbọ́n ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ forí gbárí pẹ̀lú àkókò ìpàdé. Nítorí náà, ó san owó fún òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan láti kúnjú àkókò iṣẹ́ àṣegbà tirẹ̀ kí ó bàa lè ní àyè láti lọ sí àwọn ìpàdé pàtàkì wọ̀nyí.
Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ní àrùn bárakú pàápàá kì í sábà pa ìpàdé jẹ. Wọ́n ń tẹ́tí sílẹ̀ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ní ilé nípasẹ̀ tẹlifóònù tàbí ohùn tí a gbà sórí téèpù nígbà tí wọn kò bá lè wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n ń fi ìmọrírì tí ó yẹ fún oríyìn hàn fún ìpèsè tẹ̀mí Jèhófà nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”! (Mátíù 24:45) Àwọn Kristẹni tí ń ṣètọ́jú àwọn òbí wọn àgbàlagbà mọrírì rẹ̀ gidigidi nígbà tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá gbà láti dúró ti òbí náà kí olùtọ́jú náà bàa lè lọ sí ìpàdé ìjọ.
Wéwèé Ṣáájú!
Àwọn òbí tí àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ wọ́n lọ́kàn ń ran àwọn ọmọ wọ́n lọ́wọ́ láti mọrírì àwọn ìpàdé Kristẹni. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà gbogbo gbòò, wọ́n retí pé kí àwọn ọmọ wọn ti ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wọn lásìkò tí a yàn án fún wọn dípò tí wọn yóò fi dúró kí ó di gègèrè. Ní alẹ́ ọjọ́ ìpàdé, àwọn ọmọ yóò ti yára ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá wọn ní kété tí wọ́n bá ti ilé ìwé dé. A kò ní fàyè gbà àwọn ohun àyànláàyò àti ìgbòkègbodò mìíràn láti forí gbárí pẹ̀lú ìpàdé ìjọ.
Gẹ́gẹ́ bí ọkọ, tí ó sì tún jẹ́ baba, o ha fi lílọ sí ìpàdé ṣáájú bí? Gẹ́gẹ́ bí aya, tí ó sì tún jẹ́ màmá, o ha ń gbìyànjú láti ṣètò àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè jẹ́ kí o lọ sí ìpàdé bí? Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́langba, o ha ń wéwèé iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀ lọ́nà tí ó fi hàn pé o gbà pé ìpàdé ṣe pàtàkì jù ú lọ àbí ò ń ṣe é lọ́nà tí ó fi hàn pé o gbà pé ó ṣe pàtàkì ju ìpàdé lọ bí?
Ìpàdé ìjọ jẹ́ ìpèsè onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti rí i dájú pé a nípìn-ín nínú ìṣètò náà. Jèhófà yóò bù kún ọ jìngbìnnì, bí o bá fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jù ṣáájú!