Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń wo Àwọn Èèyàn Lo Fi Ń Wò Wọ́n?
“Kí ó má bàa sí ìpínyà kankan nínú ara . . . Kí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ lè ní aájò kan náà fún ara wọn.”—1 KỌ́R. 12:25.
1. Báwo ló ṣe rí lára rẹ nígbà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ dénú Párádísè tẹ̀mí?
NÍGBÀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé búburú yìí tá a sì bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, inú wa dùn pé wọ́n gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ a sì rí ìfẹ́ tó wà láàárín wọn. Ẹ ò rí i pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn ewèlè èèyàn, tí wọ́n kún fún ìkórìíra, àwọn ẹhànnà ẹ̀dá tí Sátánì ń darí! A ti dé inú Párádísè tẹ̀mí níbi tí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ti ń jọba.—Aísá. 48:17, 18; 60:18; 65:25.
2. (a) Kí ló lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í fojú àbùkù wo àwọn èèyàn? (b) Kí ló lè pọn dandan pé ká ṣe?
2 Àmọ́, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àìpé wa lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í fojú àbùkù wo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Àìpé tó ń bá wa fínra lè mú ká sọ kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará wa di ńlá dípò ká máa wo àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Ká kúkú sọ bó ṣe jẹ́ gan-an, a máa ń gbàgbé láti máa wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n. Bí èyí bá ti ṣẹlẹ̀ sí wa, ó ti tó àkókò báyìí láti fiyè sí ojú tá a fi ń wo àwọn ẹlòmíì, ká sì máa wò wọ́n bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n.—Ẹ́kís. 33:13.
Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àwọn Ará Wa
3. Kí ni Bíbélì fi ìjọ Kristẹni wé?
3 Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé 1 Kọ́ríńtì 12:2-26, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wé ara tó ní “ẹ̀yà ara púpọ̀.” Bí àwọn ẹ̀yà ara ṣe yàtọ̀ síra wọn, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe yàtọ̀ síra nínú ìwà àti ẹ̀bùn wọn. Síbẹ̀, Jèhófà fàyè gba àwọn onírúurú ìyàtọ̀ wọ̀nyí nínú ìjọ. Ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ ara ìjọ, ó sì mọyì wọn. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú fi gbà wá nímọ̀ràn pé, ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìjọ ní láti “ní aájò kan náà fún ara wọn.” Èyí lè ṣòro nítorí pé ànímọ́ táwọn kan ní lè yàtọ̀ sí tiwa.
4. Kí nìdí tá a fi ní láti tún èrò wa ṣe lórí ojú tá a fi ń wo àwọn ará wa?
4 Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ńṣe la dájú sọ àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé à ń fi awò wo ohun kan, tó sì jẹ́ pé ibi kékeré ni awò ọ̀hún lè rí. Àmọ́, Jèhófà ní tiẹ̀ máa ń lo awò ńlá tó máa ń rí nǹkan látòkè délẹ̀ àti gbogbo ohun tó wà láyìíká rẹ̀. A lè máa wo ohun kan tí kò tẹ́ wa lọ́rùn lára ẹnì kan, àmọ́ kó jẹ́ pé látòkè délẹ̀ ni Jèhófà ń wo onítọ̀hún, ìyẹn ni pé ó ń rí gbogbo ànímọ́ rere tẹ́ni náà ní. Bá a bá ṣe ń sapá tó láti dà bíi Jèhófà, bẹ́ẹ̀ la ṣe máa túbọ̀ fi kún ẹ̀mí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ.—Éfé. 4:1-3; 5:1, 2.
5. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́?
5 Jésù mọ̀ pé àwa ẹ̀dá aláìpé sábà máa ń dá ọmọnìkejì wa lẹ́jọ́. Ó fún wa nímọ̀ràn pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” (Mát. 7:1) Kíyè sí i pé Jésù kò sọ pé: “Má ṣe dáni lẹ́jọ́”; àmọ́ ó sọ pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́.” Ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ òun ti máa ń dá àwọn ẹlòmíì lẹ́jọ́. Ṣé kò tíì di àṣà wa láti máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́? Tó bá jẹ́ pé a ti máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti sapá láti yí padà, ká má bàa dá wa lẹ́jọ́ lọ́nà tó le jù. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ẹ̀tọ́ wo la ní láti máa ṣèdájọ́ ẹni tí Jèhófà ń lò nípò tó yàn án sí? Àbí ẹ̀tọ́ wo la ní láti sọ pé ẹni náà kì í ṣe ará ìjọ? Arákùnrin kan lè ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, àmọ́ ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa kọ̀ ọ́ nígbà tí Jèhófà ò kọ̀ ọ́? (Jòh. 6:44) Ǹjẹ́ a gbà ní tòótọ́ pé Jèhófà ló ń darí ètò rẹ̀ àti pé bí àwọn àtúnṣe kan bá yẹ, yóò ṣe nǹkan kan sí i nígbà tó bá tó àkókò lójú rẹ̀?—Ka Róòmù 14:1-4.
6. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
6 Ohun kan tó jẹ́ àgbàyanu nípa Jèhófà ni pé ó lè rí ohun tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan máa dà nígbà tí wọ́n bá dẹni pípé nínú ayé tuntun. Ó sì tún mọ ibi tí wọ́n ti tẹ̀ síwájú dé nínú fífi ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì sílò. Nítorí náà, kò sí ìdí kankan tí Jèhófà á fi máa wo kìkì kùdìẹ̀-kudiẹ ẹnì kan. Sáàmù 103:12 sọ pé: “Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa.” Ẹ wo bí ọpẹ́ wa ti pọ̀ tó nítorí èyí!—Sm. 130:3.
7. Kí la rí kọ́ nínú ojú tí Jèhófà fi wo Dáfídì?
7 A rí ẹ̀rí nínú Ìwé Mímọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ta yọ nínú wíwo àwọn ànímọ́ rere tó wà nínú ẹnì kan. Ọlọ́run pe Dáfídì ní “ìránṣẹ́ mi Dáfídì, ẹni tí ó pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ó sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ tọ̀ mí lẹ́yìn nípa ṣíṣe kìkì ohun tí ó tọ́ ní ojú mi.” (1 Ọba 14:8) Láìsí àní-àní, a mọ̀ pé Dáfídì ṣe àwọn ohun kan tí kò tọ́. Síbẹ̀, Jèhófà yàn láti wo àwọn ànímọ́ rere tí Dáfídì ní, nítorí ó mọ̀ pé ọkàn Dáfídì dúró ṣánṣán.—1 Kíró. 29:17.
Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àwọn Ará Ni Kó O Fi Máa Wò Wọ́n
8, 9. (a) Ọ̀nà wo la lè gbà dà bíi Jèhófà? (b) Kí la lè fi ṣàpèjúwe èyí, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́?
8 Jèhófà lè mọ ohun tó ń bẹ lọ́kàn ẹnì kan, ṣùgbọ́n àwa ò lè mọ̀ ọ́n. Èyí gan-an ni ìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn. A kò mọ gbogbo ohun tó ń bẹ lọ́kàn ẹnì kan tó mú kó ṣe àwọn nǹkan tó ṣe. Ó yẹ ká gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, ká má ṣe dájú sọ àìpé ẹ̀dá tí yóò pòórá nígbà tó bá yá. Ǹjẹ́ kò ní dáa gan-an láti máa lépa bí a ó ṣe dà bíi Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, èyí yóò túbọ̀ mú kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn ará wa.—Éfé. 4:23, 24.
9 Àpèjúwe kan rèé: Wo ilé kan tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Àwọn agbòjò rẹ̀ ti yẹ̀, àwọn wíńdò rẹ̀ ti fọ́, omi sì ti ba àjà rẹ̀ jẹ́. Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá wo ilé náà wọ́n lè máa sọ pé kí wọ́n wó o dà nù; nítorí pé àríbojújẹ́ ni. Àmọ́ ẹnì kan lè rí ilé náà kó sì ní èrò tó yàtọ̀ pátápátá. Ó lè rí i pé ilé náà ṣì dúró dáadáa kó sì mọ̀ pé tí ilé náà bá rí àtúnṣe, ó ṣì lè ṣeé gbé. Ó ra ilé náà, ó sì tún àwọn ibi tí kò dára lára rẹ̀ ṣe, ilé náà wá dára gan-an. Nígbà táwọn tó ń kọjá lọ wá rí i, wọ́n ń sọ pé ilé náà dára rèǹtèrente. Ǹjẹ́ a lè ṣe bí ẹni tó sapá láti tún ilé yẹn ṣe? Dípò ká máa wo kìkì kùdìẹ̀-kudiẹ tó wà lára arákùnrin tàbí arábìnrin wa, ǹjẹ́ kò yẹ ká mọ àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní, ká sì mọ̀ pé wọ́n lè ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí lọ́jọ́ iwájú? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó dẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, nítorí ànímọ́ rere tí wọ́n ní.—Ka Hébérù 6:10.
10. Báwo ni ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 2:3, 4 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa lámọ̀ràn tó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ìjọ. Ó gba àwa Kristẹni níyànjú pé: “Láìṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ, kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílí. 2:3, 4) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa fojú tó tọ́ wo àwọn ẹlòmíràn. Mímójútó ire àwọn ẹlòmíràn àti wíwo ànímọ́ rere tí wọ́n ní yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti máa wò wọ́n gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n.
11. Kí làwọn ohun tó ti mú kí àyípadà bá àwọn ìjọ kan?
11 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣí láti ibì kan lọ́ síbòmíràn. Àwọn èèyàn láti onírúurú ilẹ̀ ti wá ń gbé láwọn ìlú ńlá kan nísinsìnyí. Lára àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí wá sí àgbègbè wa ti nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti dára pọ̀ mọ́ wa láti máa jọ́sìn Jèhófà. Wọ́n wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣí. 7:9) Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìjọ wa ti ní àwọn èèyàn tó wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè.
12. Irú ojú wo ló yẹ kí olúkúlùkù wa máa fi wo ara wa, kí sì nìdí tí èyí fi lè ṣòro nígbà míì?
12 Nínú ìjọ wa, ó lè gba pé kí olúkúlùkù wa túbọ̀ máa gbìyànjú láti máa fi ojú tó tọ́ wo ara wa. Ìyẹn sì gba pé ka fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù sọ́kàn pé, ká máa fi “ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè” hàn, ká sì “nífẹ̀ẹ́ ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.” (1 Pét. 1:22) Ó lè má rọrùn láti ní ojúlówó ìfẹ́ tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè ló wà nínú ìjọ wa. Àṣà ìbílẹ̀ àwọn tá a jọ ń jọ́sìn lè yàtọ̀ sí tiwa gan-an. A lè kàwé ju ara wa lọ, a lè lówó ju ara wa lọ, èdè wa sì lè yàtọ̀ síra. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ọ láti lóye èrò tàbí ìṣe àwọn kan nínú ìjọ? Ó lè ṣòro fún àwọn náà láti lóye tìrẹ. Síbẹ̀, Bíbélì gba gbogbo wa nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.”—1 Pét. 2:17.
13. Àtúnṣe wo la lè ní láti ṣe nípa ọ̀nà tá à ń gbà ronú?
13 Ó lè gba pé ká ṣe àwọn àtúnṣe kan nípa ọ̀nà tá à ń gbà ronú, kí ìfẹ́ wa bàa lè gbòòrò, ká sì lè máa fìfẹ́ hàn sí gbogbo àwọn ará wa. (Ka 2 Kọ́ríńtì 6:12, 13.) Ṣé a ti ṣàkíyèsí rí pé a sọ gbólóhùn bíi, “Kì í ṣọ̀rọ̀ ẹ̀tanú o, àmọ́ . . . ” a wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà tí kò dáa tá a gbà pé ó wọ́pọ̀ láàárín ẹ̀yà kan? Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè fi hàn pé a ní láti mú ẹ̀tanú tó ṣì wà nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún kúrò. A lè bi ara wa pé, ‘Ṣé mo máa ń sapá nígbà gbogbo láti dojúlùmọ̀ àwọn èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tèmi?’ Tá a bá ń yẹ ara wa wò lọ́nà yìí, yóò lè mú ká túbọ̀ máa gba àwọn ará wa tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà míì tọwọ́tẹsẹ̀ ká sì máa pọ́n wọn lé.
14, 15. (a) Sọ àpẹẹrẹ àwọn tó tún èrò wọn ṣe nípa ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn ẹlòmíràn. (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?
14 Bíbélì fúnni lápẹẹrẹ àwọn èèyàn tó ṣàtúnṣe nínú èrò wọn, àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Nítorí pé Pétérù jẹ́ Júù, kì í fẹ́ wọ ilé Kèfèrí. Wo bí ọ̀rọ̀ náà ti rí lára rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run ní kó lọ sí ilé Kọ̀nílíù tó jẹ́ Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́! Pétérù tún èrò rẹ̀ ṣe, ó sì wá rí i pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo orílẹ̀-èdè di ara ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 10:9-35) Sọ́ọ̀lù, tó wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà tó ya, tún ní láti tún èrò rẹ̀ ṣe, kó sì mú ẹ̀tanú kúrò lọ́kàn ara rẹ̀. Ó jẹ́wọ́ pé òun ti kórìíra àwọn Kristẹni gan-an “títí dé àyè tí ó pọ̀ lápọ̀jù ni [òun] ń ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run, tí [òun] sì ń pa á run.” Síbẹ̀, nígbà tí Jésù Olúwa tọ́ Pọ́ọ̀lù sọ́nà, ó ṣe àwọn ìyípadà tó kàmàmà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ àwọn tó ti ṣe inúnibíni sí tẹ́lẹ̀.—Gál. 1:13-20.
15 Láìsí àní-àní, ẹ̀mí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe èrò wa. Tá a bá kíyè sí i pé a ṣì ní ẹ̀tanú tó fara sin nínú ọkàn wa, ẹ jẹ́ ká sapá láti fà á tu, ká sì “máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:3-6) Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “fi ìfẹ́ wọ ara [wa] láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kól. 3:14.
Títẹ̀lé Àpẹẹrẹ Jèhófà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
16. Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn?
16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” (Róòmù 2:11) Ìfẹ́ Jèhófà ni pé káwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo jọ máa sìn ín. (Ka 1 Tímótì 2:3, 4.) Nítorí èyí ló ṣe ṣètò pé ká kéde “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” “fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣí. 14:6) Jésù sọ pé: “Pápá náà ni ayé.” (Mát. 13:38) Báwo lèyí ti ṣe pàtàkì tó fún ìwọ àti ìdílé rẹ?
17. Ọ̀nà wo la lè gbà ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́?
17 Gbogbo wa kọ́ ló lè mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ fáwọn èèyàn níbi tó jìnnà jù lọ láyé. Àmọ́, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti mú ìhìn rere lọ fáwọn ará àdúgbò wa tí wọ́n wá láti apá ibi gbogbo lágbàáyé. Ǹjẹ́ a máa ń lo àǹfààní tó bá yọ láti wàásù fún onírúurú èèyàn tí kì í ṣe àwọn tá a ti ń wàásù fún ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn? O ò ṣe pinnu láti lọ wàásù fún àwọn tí kò tíì gbọ́ ìwàásù rí?—Róòmù 15:20, 21.
18. Kí ló wu Jésù látọkànwá pé kó ṣe fáwọn èèyàn?
18 Ó wu Jésù látọkànwá pé kó ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́. Kì í ṣe àgbègbè kan péré ló ti wàásù. Ìtàn kan nínú Bíbélì sọ fún wa pé Jésù “mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n nínú ìrìn àjò ìbẹ̀wò sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé.” Àti pé “nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é,” ó sì sọ pé òun á ràn wọ́n lọ́wọ́.—Mát. 9:35-37.
19, 20. Bíi ti Jèhófà àti Jésù, àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé ọ̀rọ̀ onírúurú èèyàn jẹ wá lógún?
19 Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ ọ́ lógún bíi ti Jésù? Àwọn kan ti sapá láti wàásù láwọn ibì kan ní ìpínlẹ̀ wọn níbi tí wọn kì í sábà wàásù. Ìwọ̀nyí lè jẹ́ àwọn àgbègbè táwọn èèyàn ti ń ṣe káràkátà, àwọn ọgbà ìtura, ibùdókọ̀, tàbí níwájú àwọn ilé gbígbé tí kò rọrùn láti wọ̀. Àwọn mìíràn ti sapá láti kọ́ èdè tuntun kí wọ́n bàa lè wàásù fáwọn ẹ̀yà kan tí wọ́n ń gbé lágbègbè wọn nísinsìnyí, tàbí àwùjọ àwọn èèyàn tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan lọ́gbọ̀n ni wọ́n ń gbọ́ ìwàásù. Kíkọ́ bó o ṣe lè kí àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ní èdè wọn lè fi hàn bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó. Báwa ò bá tiẹ̀ lè kọ́ èdè tuntun, ǹjẹ́ a lè fún àwọn tó ń kọ́ ọ níṣìírí? Kò ní dáa ká máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tó ń kọ́ èdè tuntun tàbí ká máa fimú fínlẹ̀ láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń sapá láti lè wàásù fáwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Ẹ̀mí gbogbo èèyàn ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, bó sì ṣe yẹ kó rí lójú tiwa náà nìyẹn.—Kól. 3:10, 11.
20 Fífi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n tún túmọ̀ sí pé a ní láti wàásù fún gbogbo wọn, láìfi ipò tí wọ́n wà pè. Àwọn kan lè má nílé lórí, ìrísí wọn lè rí wúruwùru tàbí kó hàn kedere pé oníṣekúṣe ni wọ́n. Báwọn èèyàn kan bá tiẹ̀ ṣàìdáa sí wa, kò yẹ kíyẹn mú ká ní èrò burúkú nípa orílẹ̀-èdè wọn tàbí ẹ̀yà wọn. Àwọn èèyàn kan ṣàìdáa sí Pọ́ọ̀lù, àmọ́ kò jẹ́ kíyẹn dí òun lọ́wọ́ láti wàásù fún àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè wọn. (Ìṣe 14:5-7, 19-22) Ó nírètí pé àwọn kan yóò gbọ́ ìwàásù náà wọ́n á sì mọyì rẹ̀.
21. Báwo ni wíwo àwọn èèyàn pẹ̀lú ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́?
21 A ti wá rí i kedere báyìí pé ojú tó tọ́, ìyẹn ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, ló yẹ ká máa fi wo àwọn ará ìjọ wa, àwọn ará wa láti orílẹ̀-èdè míì, àtàwọn èèyàn tá à ń wàásù fún lóde ẹ̀rí. Bá a bá ṣe túbọ̀ ń wo àwọn èèyàn pẹ̀lú ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe túbọ̀ mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà láàárín wa. A ó sì wá kúnjú ìwọ̀n láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tí “kì í ṣe ojúsàájú” ṣùgbọ́n tó nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, “nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn jẹ́.”—Jóòbù 34:19.
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?
• Irú ojú wo ni kò yẹ ká máa fi wo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa?
• Ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nínú ojú tá a fi ń wo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa?
• Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nípa ojú tó yẹ kó o máa fi wo àwọn ará wa tó wá láti orílẹ̀-èdè míì?
• Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nípa ojú tá a fi ń wo àwọn èèyàn nígbà tá a bá ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọ̀nà wo lo lè gbà dojúlùmọ̀ àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tìrẹ?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ èèyàn púpọ̀ sí i?