-
Àwọn Èèyàn Mọ Òfin Pàtàkì Náà—Kárí AyéIlé Ìṣọ́—2001 | December 1
-
-
Àwọn Èèyàn Mọ Òfin Pàtàkì Náà—Kárí Ayé
“Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.
ÓTI fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì báyìí tí Jésù Kristi ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nínú Ìwàásù rẹ̀ olókìkí lórí Òkè. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tó ti kọjá lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ làwọn èèyàn ti sọ, ìwé ò sì lóǹkà tí wọ́n ti kọ lórí gbólóhùn tó sọ wẹ́rẹ́ yẹn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn ti kókìkí òfin yìí, wọ́n lóun ni “olórí ẹ̀kọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni,” wọ́n lóun ni “àkópọ̀ ojúṣe Kristẹni sí aládùúgbò rẹ̀,” wọ́n tún sọ pé òun ni “olú òfin ìwà híhù.” Àní níbi táwọn èèyàn mọ̀ ọ́n dé, Òfin Pàtàkì ni wọ́n ń pè é.
Kì í tún wáá ṣe àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni nìkan làwọn èèyàn tó mọ Òfin Pàtàkì yìí o. Àwọn ẹlẹ́sìn Júù, ẹlẹ́sìn Búdà àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì pàápàá ń gbé ìlànà yìí lárugẹ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bí ẹní mowó làwọn ará Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé mọ gbólóhùn kan tó jáde lẹ́nu Confucius, ẹni táwọn ará Ìlà Oòrùn ayé kà sí àgbà amòye àti olùkọ́. Nínú ìwé náà The Analects, tí í ṣe apá kẹta Four Books, ìyẹn ìwé àwọn ẹlẹ́sìn Confucius, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la rí ọ̀rọ̀ tó fara pẹ́ Òfin Pàtàkì yìí nínú rẹ̀. Nígbà tí Confucius ń dáhùn ìbéèrè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ bi í, ẹ̀ẹ̀mejì ló sọ pé: “Ohun tí o ò bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ẹ, má ṣe é sí wọn.” Nígbà kan tí ọmọléèwé rẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Zigong fọ́nnu pé, “Ohun tí mi ò bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí mi, èmi náà kì í fẹ́ ṣe é sí wọn,” olùkọ́ náà fèsì lọ́nà tí ń múni ronú jinlẹ̀ pé, “Òótọ́ ni, ṣùgbọ́n o ò tíì lè ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí.”
Béèyàn ṣe ń ka ọ̀rọ̀ yìí, á rí i pé ohun tí Confucius sọ yìí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sóhun tí Jésù sọ lẹ́yìn náà. Ìyàtọ̀ tó kàn wà níbẹ̀ ni pé Òfin Pàtàkì náà tí Jésù gbé kalẹ̀ ń béèrè gbígbé ìgbésẹ̀ pàtó fún ire àwọn ẹlòmíràn. Ká sọ pé àwọn èèyàn ń gbé ìgbésẹ̀ níbàámu pẹ̀lú gbólóhùn àtàtà tó jáde lẹ́nu Jésù yìí, ká sọ pé wọ́n ń bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn, tí wọ́n ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, tí ìwà wọn ojoojúmọ́ sì bá ìlànà yìí mu. Ǹjẹ́ o ò rò pé ayé yìí ì bá túbọ̀ dára sí i? Á túbọ̀ dára mọ̀nà.
Yálà ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ ọ́ tọ́ tàbí kò tọ́, ọ̀nà yòówù kí wọ́n gbà sọ ọ́, ohun tó gbàfiyèsí ni pé láti àtayébáyé ni àwọn èèyàn níbi gbogbo àti ní onírúurú ipò ti gbà pé òfin tó dáa ni Òfin Pàtàkì náà. Ohun tí èyí kàn fi hàn ni pé ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni nínú Ìwàásù Lórí Òkè kan àwọn èèyàn nígbà gbogbo, ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.
Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Ṣé màá fẹ́ káwọn èèyàn fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí, kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ mi dù mí, kí wọ́n má sì rẹ́ mi jẹ? Ṣé màá fẹ́ gbé nínú ayé tí kò ti sí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìwà ọ̀daràn àti ogun? Ṣé màá fẹ́ wà nínú ìdílé tí gbogbo mẹ́ńbà rẹ̀ ti ń bìkítà nípa ìmọ̀lára àti ire ẹnì kìíní kejì?’ Ká sòótọ́, ta ló máa sọ pé òun ò fẹ́ nǹkan dáadáa wọ̀nyẹn? Ohun tó kàn ń báni nínú jẹ́ ni pé bóyá la rí ẹni tó ń gbádùn ipò wọ̀nyí lónìí. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, bí ẹní ń gbéra ẹni gẹṣin aáyán ni ríretí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.
Wọ́n Ti Rú Òfin Pàtàkì Náà
Kì í ṣòní kì í ṣàná làwọn èèyàn ti ń hùwà ibi séèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìkejì wọn lójú. Lára ìwà ibi wọ̀nyí ni òwò ẹrú ní Áfíríkà, àwọn àgọ́ ìfikúpani ti ìjọba Násì, àṣà fífi agbára mú àwọn ògo wẹẹrẹ ṣiṣẹ́ àti ìwà ìkà pípa odindi ẹ̀yà run ní àwọn ibi púpọ̀. Tá a bá ní ká máa ka gbogbo ìwà láabi táwọn èèyàn ń hù, ilẹ̀ á kún.
Ayé anìkànjọpọ́n layé onímọ̀ ẹ̀rọ tí à ń gbé lónìí. Ṣàṣà làwọn tó ń gba ti ẹlòmíì rò, àfi tí kò bá ní í ná wọn ní nǹkan kan, tí kò sì ní tẹ ohun tí wọ́n pè ní ẹ̀tọ́ tiwọn lójú. (2 Tímótì 3:1-5) Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ya onímọtara-ẹni-nìkan, òǹrorò, aláìlójú àánú àti anìkànjọpọ́n? Kì í ha í ṣe nítorí pé àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò ti pa Òfin Pàtàkì náà tì, tí wọ́n kà á sí ìlànà tí kò bóde mu mọ́ ni bí? Ó mà ṣe o, nítorí pé àwọn kan tó sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ pàápàá wà lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Níbi tí nǹkan sì ń bá a lọ yìí, ńṣe làwọn èèyàn á túbọ̀ máa di anìkànjọpọ́n.
Nítorí náà, àwọn ìbéèrè tó ṣe kókó, tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni: Kí ni títẹ̀lé Òfin Pàtàkì yìí wé mọ́? Ǹjẹ́ a ṣì rí àwọn tó ń tẹ̀ lé e? Ǹjẹ́ àkókò kan máa wà tí gbogbo aráyé yóò tẹ̀ lé Òfin Pàtàkì yìí? Tó o bá fẹ́ mọ ìdáhùn tòótọ́ sí ìbéèrè wọ̀nyí, jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Confucius àtàwọn mìíràn fi ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí Òfin Pàtàkì náà kọ́ni
-
-
Òfin Pàtàkì Náà—Ṣì Bóde MuIlé Ìṣọ́—2001 | December 1
-
-
Òfin Pàtàkì Náà—Ṣì Bóde Mu
Lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn, Jésù ló ṣe Òfin Pàtàkì náà kí ó lè fi ìwà rere kọ́ni, àmọ́ ohun tí òun alára sọ ni pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 7:16.
BẸ́Ẹ̀ ni o, ẹni tó rán Jésù, èyíinì ni Jèhófà Ọlọ́run, tí í ṣe Ẹlẹ́dàá, ni Orísun àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni, títí kan èyí tí a wá mọ̀ sí Òfin Pàtàkì.
Ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni pé kí gbogbo èèyàn máa ṣe sáwọn ẹlòmíì bí wọ́n ṣe fẹ́ káwọn ẹlòmíì máa ṣe sáwọn. Bí a bá wo bó ṣe dá ènìyàn, a óò rí i pé ó fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ ní ti bíbìkítà fún ire àwọn ẹlòmíràn. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Èyí túmọ̀ sí pé títí dé àyè kan, Ọlọ́run fi tìfẹ́tìfẹ́ fún àwọn èèyàn ní àwọn ànímọ́ rẹ̀ títayọ, kí wọ́n lè wà ní àlàáfíà, ayọ̀ àti ìṣọ̀kan—ète rẹ̀ sì ni pé kí wọ́n máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí ayé fáàbàdà. Bí wọ́n bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wọn dáadáa, yóò darí wọn láti máa ṣe sí àwọn ẹlòmíràn bí àwọn alára ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí wọn.
Ìmọtara-Ẹni-Nìkan Wá Gbòde Kan
Níwọ̀n bí nǹkan ti dáa tó báyẹn fáráyé níbẹ̀rẹ̀, kí wá ló ṣẹlẹ̀? Tóò, láìfọ̀rọ̀ gùn, ńṣe làwọn èèyàn wá di onímọtara-ẹni-nìkan. Ṣàṣà lẹni tí kò mọ ìtàn Bíbélì nípa ohun tí tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣe, gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta. Sátánì, tó máa ń takò gbogbo ìlànà òdodo Ọlọ́run, sún Ádámù àti Éfà láti fi ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tàpá sí ìṣàkóso Ọlọ́run, kí wọ́n lè di òmìnira, kí wọ́n sì ráyè máa ṣe tinú ara wọn. Ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwà ọ̀tẹ̀ wọn ṣe àkóbá ńláǹlà fún wọn. Àmọ́ kì í wáá ṣe àwọn nìkan, ó tún ṣàkóbá fún gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn ọjọ́ iwájú. Àbájáde yìí fi hàn kedere pé dídágunlá sí ohun tá a wá mọ̀ sí Òfin Pàtàkì lẹ́yìn náà kò lè bímọọre láé. Fún ìdí yìí, “ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aráyé lápapọ̀ pa àwọn ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run là sílẹ̀ tì, síbẹ̀ òun kò pa wọ́n tì. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní Òfin rẹ̀ kí ó lè tọ́ wọn sọ́nà. Òfin yìí kọ́ wọn pé kí wọ́n máa ṣe sí àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí wọn. Òfin náà fún wọn ní ìtọ́ni nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sáwọn ẹrú, àwọn ọmọ aláìníbaba àtàwọn opó. Ó sọ ìgbésẹ̀ tó yẹ ní gbígbé bí ìwà ipá, ìjínigbé àti olè jíjà bá wáyé. Àwọn òfin ìmọ́tótó fi ìjẹ́pàtàkì bíbìkítà nípa ìlera àwọn ẹlòmíràn hàn. Kódà àwọn òfin wà lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo. Jèhófà ṣàkópọ̀ Òfin rẹ̀ nípa sísọ fáwọn èèyàn náà pé: “Kí ìwọ . . . nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,” Jésù sì ṣàyọlò gbólóhùn yìí lẹ́yìn náà. (Léfítíkù 19:18; Mátíù 22:39, 40) Òfin náà tún sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe sáwọn àtìpó tó wà láàárín wọn. Òfin náà pa á láṣẹ pé: “Ìwọ kò . . . gbọ́dọ̀ ni àtìpó lára, níwọ̀n bí ẹ̀yin fúnra yín ti mọ ọkàn àtìpó, nítorí ẹ̀yin jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ Íjíbítì.” Lédè mìíràn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ṣojú àánú sí àwọn tí nǹkan ò ṣẹnuure fún.—Ẹ́kísódù 23:9; Léfítíkù 19:34; Diutarónómì 10:19.
Jèhófà bù kún Ísírẹ́lì nígbà tí orílẹ̀-èdè náà ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé Òfin náà. Lábẹ́ àkóso Dáfídì àti Sólómọ́nì, orílẹ̀-èdè náà láásìkí, inú àwọn èèyàn náà dùn, ọkàn wọn sì balẹ̀. Ìròyìn kan sọ fún wa pé: “Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà lẹ́bàá òkun nítorí tí wọ́n jẹ́ ògìdìgbó, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀. Júdà àti Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ààbò, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 4:20, 25.
Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú pé àlàáfíà àti ààbò tí orílẹ̀-èdè yẹn ní kò bá wọn kalẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Ọlọ́run, wọn ò tẹ̀ lé e; wọ́n jẹ́ kí ìmọtara-ẹni-nìkan paná ìfẹ́ tó yẹ kí wọ́n ní sáwọn ẹlòmíì. Ìwà yìí, àti ìpẹ̀yìndà, kó ìnira bá wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀. Níkẹyìn, lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà jẹ́ kí àwọn ará Bábílónì pa ìjọba Júdà àti ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì gàgàrà náà pàápàá run. Kí nìdí? “‘Nítorí ìdí náà pé ẹ kò ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, kíyè sí i, èmi yóò ránṣẹ́, dájúdájú, èmi yóò mú gbogbo ìdílé àríwá,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní èmi yóò ránṣẹ́ sí Nebukadirésárì ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi, ṣe ni èmi yóò mú wọn wá láti gbéjà ko ilẹ̀ yìí, àti láti gbéjà ko àwọn olùgbé rẹ̀ àti láti gbéjà ko gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí ó yí i ká; dájúdájú, èmi yóò yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun, èmi yóò sì sọ wọ́n di ohun ìyàlẹ́nu àti ohun ìsúfèé sí àti ibi ìparundahoro fún àkókò tí ó lọ kánrin.’” (Jeremáyà 25:8, 9) Ẹ ò rí ohun tójú wọ́n rí nítorí pípa ìjọsìn mímọ́ Jèhófà tì!
Àpẹẹrẹ Kan Tó Yẹ Ní Títẹ̀lé
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kì í ṣe pé Jésù Kristi kọ́ni ní Òfin Pàtàkì náà nìkan ni, àmọ́ ó tún fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ ní títẹ̀lé e. Ó fi tinútinú bìkítà fún ire àwọn ẹlòmíì. (Mátíù 9:36; 14:14; Lúùkù 5:12, 13) Ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan, lẹ́bàá ìlú Náínì, pé Jésù rí opó oníròbìnújẹ́ kan láàárín èrò tí ń lọ sìnkú ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí opó náà bí. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí Olúwa sì tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é.” (Lúùkù 7:11-15) Ìwé Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ pé ìtumọ̀ gbólóhùn náà ‘àánú ṣe é’ ni pé “kéèyàn ní ìmọ̀lára àtinúwá.” Jésù mọ àròdùn ọkàn obìnrin yìí, èyí sì sún un gbégbèésẹ̀ láti lé àròdùn rẹ̀ lọ. Ẹ wo bí inú opó yẹn á ti dùn tó nígbà tí Jésù jí ọ̀dọ́mọkùnrin náà dìde, tí “ó sì fi í fún ìyá rẹ̀”!
Lékè gbogbo rẹ̀, níbàámu pẹ̀lú ète Ọlọ́run, Jésù fínnúfíndọ̀ jìyà, ó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà, kí aráyé lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ ní títẹ̀lé Òfin Pàtàkì náà.—Mátíù 20:28; Jòhánù 15:13; Hébérù 4:15.
Àwọn Èèyàn Tí Ń Fi Òfin Pàtàkì Náà Sílò
Ǹjẹ́ a rí àwọn tó ń tẹ̀ lé Òfin Pàtàkì náà láyé tá a wà yìí? Bẹ́ẹ̀ ni o, kì í sì í ṣe ìgbà tó bá rọ̀ wọ́n lọ́rùn nìkan ni wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, lákòókò tí ìjọba Násì ń ṣàkóso ní Jámánì, ìgbàgbọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nínú Ọlọ́run àti ìfẹ́ tí wọ́n ní fún aládùúgbò wọn kò yẹ̀ rárá. Wọ́n tipa báyìí fi hàn pé àwọn rọ̀ mọ́ Òfin Pàtàkì náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí pọ oró sáwọn èèyàn nínú, pé kí wọ́n kórìíra àwọn Júù, kí wọ́n sì dojúùjà kọ wọ́n, àwọn Ẹlẹ́rìí rọ̀ mọ́ Òfin Pàtàkì náà. Kódà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọ́n ń bá a lọ ní ṣíṣaájò àwọn ẹlòmíì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ wọ́n bí ojú, síbẹ̀ wọ́n ń pín lára ìwọ̀nba tí wọ́n bá rí fáwọn Júù àtàwọn mìíràn tí ebi ń pa. Àní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìjọba pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ohun ìjà láti fi pààyàn, wọ́n kọ̀ jálẹ̀, wọ́n láwọn ò ní pa ẹlòmíì, níwọ̀n bí àwọn ò ti fẹ́ kí ẹlòmíì pa àwọn. Báwo ni wọ́n ṣe lè pa àwọn tó yẹ kí wọ́n fẹ́ràn bí ara wọn? Nítorí tí wọ́n kọ̀, wọn ò wá fi ọ̀ràn wọn mọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nìkan, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni wọ́n pa.—Mátíù 5:43-48.
Bí o ṣe ń ka àpilẹ̀kọ yìí, o ń jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ ọ̀nà mìíràn tá a gbà ń lo Òfin Pàtàkì náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jìyà lónìí, láìní ìrètí, láìní olùrànlọ́wọ́. Fún ìdí yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí ń yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí àti ìtọ́ni tó bóde mu látinú Bíbélì. Ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ aláìlẹ́gbẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́ kárí ayé. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ nínú Aísáyà 2:2-4, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,” àní sẹ́, àwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà kárí ayé, ni a ti ‘fún ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà, tí wọ́n sì ń rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’ Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n ti kọ́ ‘láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn sì ti fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.’ Wọ́n ti rí àlàáfíà àti ààbò láwọn àkókò yánpọnyánrin yìí.
Ìwọ Ńkọ́?
Ronú fún sáà kan lórí ìpọ́njú àti ìjìyà tí àìka Òfin Pàtàkì náà sí ti mú bá aráyé látìgbà ìṣọ̀tẹ̀ tí Sátánì Èṣù dá sílẹ̀ ní Édẹ́nì. Jèhófà ti pinnu láti tún ọ̀ràn náà ṣe láìpẹ́. Lọ́nà wo? “Fún ète yìí ni a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere, èyíinì ni, láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Èyí yóò ṣẹlẹ̀ nínú Ìjọba Ọlọ́run, lábẹ́ Jésù Kristi, tó jẹ́ ọlọgbọ́n tó sì tóótun, ẹni tó kọ́ni ní Òfin Pàtàkì náà, tó sì fi ṣèwà hù.—Sáàmù 37:9-11; Dáníẹ́lì 2:44.
Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri. Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni ó ń fi ojú rere hàn, tí ó sì ń wínni, nítorí náà, àwọn ọmọ rẹ̀ wà ní ìlà fún ìbùkún.” (Sáàmù 37:25, 26) Ǹjẹ́ o ò gbà pé ńṣe ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lónìí ń du ti ara wọn, dípò ‘fífi ojú rere hàn, kí wọ́n sì máa wínni’? Ó ṣe kedere pé títẹ̀lé Òfin Pàtàkì náà lè ṣamọ̀nà sí àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ nítorí pé a lè fojú sọ́nà fún àwọn ìbùkún nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba Ọlọ́run yóò mú gbogbo ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì fi ètò tuntun tí Ọlọ́run yóò gbé kalẹ̀ rọ́pò ìṣàkóso ènìyàn tó kún fún ìwà ìbàjẹ́. Nígbà yẹn, gbogbo èèyàn ló máa fẹ́ láti tẹ̀ lé Òfin Pàtàkì náà.—Sáàmù 29:11; 2 Pétérù 3:13.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Kì í ṣe pé Jésù kọ́ni ní Òfin Pàtàkì náà nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún fi àpẹẹrẹ dídára jù lọ lélẹ̀ ní títẹ̀lé e
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Títẹ̀lé Òfin Pàtàkì náà lè ṣamọ̀nà sí àlàáfíà àti ààbò tòótọ́
-