Ojú Ọ̀nà Gbayawu Tí Ó Ní Òmìnira Kékeré
Ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́ta—bàbá, ìyá, àti ọmọbìnrin kékeré—wà ní ilé ní Sydney, Australia, nígbà tí ilé gbiná. Wọ́n gbìyànjú láti bẹ́ láti ojú fèrèsé, ṣùgbọ́n a ti fi irin dábùú àwọn fèrèsé náà. Nítorí àwọn irin tí ó wà fún ààbò wọ̀nyí, àwọn panápaná kò lè gbà wọ́n là. Ìyá àti bàbá ṣègbé sínú èéfín àti iná náà. Ọmọbìnrin náà kú lẹ́yìn náà ní ilé ìwòsàn.
ẸWO bí ó ti bani nínú jẹ́ tó pé ìdílé yìí kú nítorí kíkọ́ ohun tí wọ́n lérò pé yóò dáàbò bò wọ́n! Ó jẹ́ àkíyèsí kan nípa àkókò tiwa pé kì í ṣe ìdílé yìí nìkan ni ń lo àwọn irin ìdábùú àti àwọn kọ́kọ́rọ́ ààbò láti dáàbò bo ilé wọn. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn aládùúgbò ní ilé àti dúkìá tí ó dàbí odi agbára. Èé ṣe? Wọ́n ń wá ààbò àti ìbalẹ̀-ọkàn. Ẹ wo irú ìjákulẹ̀ tí èyí jẹ́ fún ẹgbẹ́ àwùjọ “olómìnira” nígbà tí àwọn ènìyàn ń nímọ̀lára àìséwu kìkì nígbà tí a bá há wọn mọ́ bí ẹlẹ́wọ̀n nínú ilé ara wọn! Ní iye àwọn àdúgbò tí ń pọ̀ sí i, àwọn ọmọdé kò lè ṣeré kiri láìséwu nínú ọgbà tí kò jìnnà wọn kò sì lè rìn lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ láìjẹ́ pé òbí kan tàbí àgbàlagbà kan tẹ̀ lé wọn. Nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ìgbésí ayé, òmìnira ń pòórá bí ìrì òwúrọ̀.
Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ó Yí Padà
Ìgbà àwọn òbí wa àgbà yàtọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, wọ́n sábà máa ń ṣeré níbikíbi tí wọ́n bá fẹ́ láìsí ìbẹ̀rù. Gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà, wọn kò fi àwọn kọ́kọ́rọ́ àti irin ìdábùú kankan da ara wọn láàmú. Wọ́n nímọ̀lára òmìnira, dé ìwọ̀n ààyè kan, wọ́n sì ní òmìnira. Ṣùgbọ́n àwọn òbí wa àgbà ti rí ìyípadà nínú ẹ̀mí àwùjọ nígbà ayé wọn. Ó ti túbọ̀ di aláìníwà-bí-ọ̀rẹ́ àti onímọtara-ẹni-nìkan; ní àwọn ibi púpọ̀, ìbẹ̀rù aládùúgbò ti rọ́pò ìfẹ́ fún aládùúgbò, èyí tí ó dákún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ tí a mẹ́nu kàn lókè. Ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwàrere tí ó túbọ̀ ń lọ sílẹ̀ síi ń lọ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àìsí òmìnira tí ń pọ̀ sí i. Ẹgbẹ́ àwùjọ ni “ọ̀nà ìwàrere tuntun” ti kó sí lórí, ṣùgbọ́n ní ti gidi, a ti dé àyè kan nísinsìnyí níbi tí ó ti ṣòro láti rí ọ̀nà ìwàrere kankan rárá.
Ọ̀mọ̀wé Rupert Goodman, olùkọ́ni ètò-ẹ̀kọ́ tẹ́lẹ̀ rí kan ní University of Queensland, kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀dọ́ ni a ti ṣí payá sí ọ̀nà ìgbésí ayé jadùnjadùn nísinsìnyí . . . èyí tí ó yàtọ̀, níbi tí ‘ara-ẹni’ ti jẹ́ kókó àfiyèsí: ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́, ìkara-ẹni-sí-pàtàkì, ìtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn, ìfẹ́-ọkàn fún ire ara-ẹni.” Ó tún sọ pé: “Àwọn ìlànà bí ìkóra-ẹni-níjàánu, ìsẹ́ra-ẹni, iṣẹ́ àṣekára, mímọ nǹkan lò, ọ̀wọ̀ fún aláṣẹ, ìfẹ́ àti ọlá fún àwọn òbí . . . jẹ́ ìpìlẹ̀-èrò tí ó ṣàjèjì sí ọ̀pọ̀lọpọ̀.”
Ojú Ọ̀nà Fífẹ̀ Ni Ní ti Gidi
Ìdánìkànjọpọ́n tí ó gbalé-gbòde yìí kò ya àwọn tí wọ́n mọ àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli lẹ́nu, nítorí Jesu Kristi kìlọ̀ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Fífẹ̀ ati aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà naa tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni awọn ẹni tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé tóóró ni ẹnubodè naa ati híhá ni ojú ọ̀nà naa tí ó lọ sínú ìyè, ìwọ̀nba díẹ̀ sì ni awọn ẹni tí ń rí i.” (Matteu 7:13‚ 14) Ojú ọ̀nà àkọ́kọ́, tí ó ní àyè tí ó pọ̀ tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ arìnrìn-àjò, jẹ́ “fífẹ̀” nítorí pé níní àwọn ìlànà Bibeli tí ó ṣàkóso ìwàrere àti ìgbésí-ayé ojoojúmọ́ kò dí i lọ́wọ́. Ó fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ láti ronú bí ó ti wù wọ́n kí wọ́n sì ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ mọ́ra—láìsí òfin kankan, láìsí ẹ̀jẹ́-àdéhùn kankan.
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti yan ọ̀nà fífẹ́ náà ń sọ pé àwọn ń gbádùn òmìnira ara wọn. Ṣùgbọ́n èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú wọn ni ẹmí ìmọtara-ẹni-nìkan tí ó wọ́pọ̀ ń sún ṣiṣẹ́. Bibeli sọ pé a ń darí wọn nípasẹ̀ “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí ninu awọn ọmọ àìgbọ́ràn.” Ẹ̀mí yìí ń sún wọn láti gbé “ní ìbámu pẹlu . . . ẹran-ara . . . , ní ṣíṣe awọn ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́-inú ti ẹran-ara,” ì bá à jẹ́ ti ìwà pálapàla, ìlo oògùn ní ìlòkulò, ìlépa ọrọ̀ láìkọ ohun tí yóò náni, ipò iyì, tàbí àgbára.—Efesu 2:2, 3.
Ọ̀nà Fífẹ̀ náà Ń Lọ sí Ìjábá
Ṣàkíyèsí pé àwọn tí ń rìn ní ojú ọ̀nà fífẹ̀ náà ni a ń sún láti ṣe “awọn ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́-inú ti ẹran-ara.” Èyí fi hàn pé wọn kò lómìnira rárá—wọ́n ní ọ̀gá. Wọ́n jẹ́ ẹrú ẹran-ara. Ṣíṣiṣẹ́sin ọ̀gá yìí sì lè yọrí sí ìṣòro púpọ̀—àrùn àjàkáyé tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, ìdílé tí ó yapa, ara àti èrò-inú tí oògùn àti ọtí àmujù ń mú kí ó ṣàìsàn, láti wulẹ̀ mẹ́nu kan kìkì díẹ̀. Àwọn ìgbésẹ̀ ìwà ipá, ìkólé, àti ìfipábánilòpọ̀ pàápàá ni wọ́n pilẹ̀ láti inú ìrònú anìkànjọpọ́n tí ojú ọ̀nà fífẹ́ onígbọ̀jẹ̀gẹ́ yìí ń mú dàgbà. Àti pé, níwọ̀n bí “ojú ọ̀nà . . . tí ó lọ sínú ìparun” yìí bá ṣì ń bá a lọ láti máa wà, àwọn èso rẹ̀ yóò tilẹ̀ túbọ̀ di èyí tí ó ṣeni lọ́ṣẹ́ sí i.—Owe 1:22, 23; Galatia 5:19-21; 6:7.
Gbé àwọn àpẹẹrẹ tí ó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi láti Australia yẹ̀wò. Mary juwọ́ sílẹ̀ fún ìdánwò, nípa lílo oògùn tí ń di bárakú nílòkulò bákan náà sì ni nípa lílọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla.a Ṣùgbọ́n ayọ̀ tí ó ń wá kiri di àléèbá fún un. Lẹ́yìn tí ó ti ní ọmọ méjì pàápàá, ìgbésí-ayé rẹ̀ dàbí èyí tí ó ṣófo. Ó dé ipò rẹ̀ tí ó rẹlẹ̀ jù lọ nígbà tí ó mọ̀ pé òun ti kó àrùn AIDS.
Ìṣelọ́ṣẹ́ ti Tom jẹ́ ní ọ̀nà mìíràn. Ó kọ̀wé pé: “Mo dàgbà ní ilé míṣọ́nnárì ní àríwá Queensland. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún 16, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọtí ní àmuyíràá. Bàbá mi, àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, àti àwọn ọ̀rẹ́ mi jẹ́ alámuyíràá, nítorí náà, ó dàbí ohun tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti ṣe. Mo bá a dé ipò kan tí ó jẹ́ pé mo lè mu ohunkóhun, bẹ̀rẹ̀ láti orí bíà títí dé orí methylated spirit. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí i gẹṣin ta tẹ́tẹ́, nígbà mìíràn mo máa ń pàdánù ọ̀pọ̀ jù lọ nínú owó oṣù tí mo fi òógùn ojú wá. Èyí kì í ṣe owó kékeré, nítorí iṣẹ́ ìrèké gígé tí mo ń ṣe ń mú owó wọlé gan-an.
“Lẹ́yìn náà, mo gbéyàwó a sì ní àwọn ọmọ. Kàkà kí ń kọjú mọ́ ẹrù iṣẹ́ mi, mo ń ṣe ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ mi ń ṣe—ọtí, tẹ́tẹ́, àti ìjà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń tì mí mọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n àdúgbò. Ṣùgbọ́n èyí pàápàá kò ní ipa kankan lórí mi. Ìgbésí ayé mi ń lọ sílẹ̀. Ó kún fún ìṣòro.”
Bẹ́ẹ̀ ni, nípa fífàyè gba ìfẹ́-ọkàn tí kò tọ̀nà, kì í ṣe ara wọn nìkan ni Tom àti Mary ṣe lọ́ṣẹ́ ṣùgbọ́n àwọn ìdílé wọn pẹ̀lú. Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni ìtẹ̀sí dídi ẹni tí ẹ̀mí òmìnira àìníjàánu, tí ń ṣini lọ́nà tí a fifúnni ní ojú ọ̀nà fífẹ̀ ń tàn jẹ. Ì bá ṣe pé àwọn ọ̀dọ́ lè ríran ré kọjá ìbòjú náà ni, kí wọ́n wòye ẹ̀tàn tí òmìnira yìí ní. Ká ní wọ́n lè rí ìjóòótọ́ ojú ọ̀nà fífẹ̀ náà—owó-orí líle koko tí gbogbo àwọn tí ń rìn ín yóò san nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Lóòótọ́, ó fẹ̀ ó sì rọrùn láti tọ̀. Ṣùgbọ́n fífẹ̀ rẹ̀ gan-an ni ó fa wàhálà. Ipa ọ̀nà ọgbọ́n ni láti fi òkodoro òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro náà sọ́kàn pé “ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹlu níní ẹran-ara rẹ̀ lọ́kàn yoo ká ìdíbàjẹ́ lati inú ẹran-ara rẹ̀.”—Galatia 6:8.
Bí ó ti wù kí ó rí, yíyàn tí ó sàn jù wà. Òun ni ojú ọ̀nà tóóró náà. Ṣùgbọ́n báwo ni ojú ọ̀nà yìí ti ń káni lọ́wọ́ kò tó, báwo ni ó ṣe há tí ó sì tóóró tó? Níbo ni ó sì ń lọ?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ padà.