Orí 5
Ìjọsìn Ta Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́gbà?
1. Kí ni ohun tí obìnrin ará Samaria kan fẹ́ láti mọ̀ nípa ìjọsìn?
ÌWỌ ha ti ṣe kàyéfì rí pé, ‘Ìjọsìn ta ni Ọlọrun tẹ́wọ́gbà?’ Irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ti níláti wá sọ́kàn obìnrin kan nígbà tí ó bá Jesu Kristi sọ̀rọ̀ nítòsí Òkè Gerisimu ní Samaria. Ní dídarí àfiyèsí sí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ìjọsìn àwọn ara Samaria àti ti àwọn Júù, ó sọ pé: “Awọn baba-ńlá wa jọ́sìn ní òkè-ńlá yii; ṣugbọn ẹ̀yin wí pé ní Jerusalemu ni ibi tí ó yẹ kí awọn ènìyàn ti jọ́sìn.” (Johannu 4:20) Jesu ha sọ fún obìnrin ará Samaria yìí pé Ọlọrun tẹ́wọ́gba gbogbo ìjọsìn bí? Tàbí ó ha sọ pé àwọn ohun kan ní pàtó ní a béèrè láti wu Ọlọrun?
2. Ní dídá obìnrin ará Samaria náà lóhùn, kí ni Jesu sọ?
2 Èsì amúnitagìrì Jesu ni pé: “Wákàtí naa ń bọ̀ nígbà tí kì í ṣe ní òkè-ńlá yii tabi ní Jerusalemu ni ẹ óò ti máa jọ́sìn Baba.” (Johannu 4:21) Fún ìgbà pípẹ́ ni àwọn ará Samaria ti ní ìbẹ̀rù fún Jehofa tí wọ́n sì jọ́sìn àwọn ọlọrun mìíràn lórí Òkè Gerisimu. (2 Awọn Ọba 17:33) Wàyí o Jesu Kristi sọ pé ibẹ̀ yẹn tàbí Jerusalemu kò tún ní ṣe pàtàkì mọ́ nínú ìjọsìn tòótọ́.
JỌ́SÌN NÍ Ẹ̀MÍ ÀTI ÒTÍTỌ́
3. (a) Èéṣe tí àwọn ará Samaria kò fi mọ Ọlọrun níti gidi? (b) Báwo ni àwọn Júù olùṣòtítọ́ àti àwọn mìíràn ṣe lè mọ Ọlọrun?
3 Jesu tẹ̀síwájú láti sọ fún obìnrin ará Samaria náà pé: “Ẹ̀yin ń jọ́sìn ohun tí ẹ kò mọ̀; awa ń jọ́sìn ohun tí awa mọ̀, nitori pé ìgbàlà pilẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ awọn Júù.” (Johannu 4:22) Awọn ará Samaria ní àwọn èrò èké nípa ìsìn wọ́n sì tẹ́wọ́gba kìkì ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ní ìmísí—ìyẹn sì jẹ́ kìkì nínú àtúntẹ̀ tiwọn tí a mọ̀ sí Ìwé Márùn-ún Àkọ́kọ́ ti Àwọn Ará Samaria. Nítorí èyí, wọn kò mọ Ọlọrun níti gidi. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Júù ni a ti fi ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ sí ní ìkáwọ́. (Romu 3:1, 2) Ìwé Mímọ́ fún àwọn Júù olùṣòtítọ́ àti àwọn mìíràn tí wọ́n fẹ́ láti gbọ́ ní ohun tí wọ́n nílò láti lè mọ Ọlọrun.
4. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jesu sọ, kí ni àwọn Júù àti àwọn ará Samaria níláti ṣe bí ìjọsìn wọn yóò bá ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun?
4 Níti gidi, Jesu fi hàn pé àwọn Júù àti àwọn ará Samaria yóò níláti tún ọ̀nà ìjọsìn ṣe bọ̀sípò láti lè wu Ọlọrun. Ó sọ pé: “Wákàtí naa ń bọ̀, nísinsìnyí sì ni, nígbà tí awọn olùjọsìn tòótọ́ yoo máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí ati òtítọ́, nitori pé, nítòótọ́, irúfẹ́ awọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá lati máa jọ́sìn oun. Ọlọrun jẹ́ Ẹ̀mí, awọn wọnnì tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí ati òtítọ́.” (Johannu 4:23, 24) A níláti jọ́sìn Ọlọrun “ní ẹ̀mí,” tí ọkàn-àyà tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ sún ṣiṣẹ́. Ó ṣeé ṣe láti jọ́sìn Ọlọrun ‘ní òtítọ́’ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti nípa jíjọ́sìn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ rẹ̀ tí a ṣí payá. Ìwọ ha ń háragàgà láti ṣe ìyẹn bí?
5. (a) Kí ni “ìjọsìn” túmọ̀ sí? (b) Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe bí a bá fẹ́ kí Ọlọrun tẹ́wọ́gba ìjọsìn wa?
5 Jesu tẹnumọ́ ọn pé Ọlọrun ń fẹ́ ìjọsìn tòótọ́. Èyí fi hàn pé àwọn ọ̀nà ìjọsìn kan wà tí Jehofa kò tẹ́wọ́gbà. Láti jọ́sìn Ọlọrun túmọ̀ sí láti fún un ní ọlá tí ó ní ọ̀wọ̀ ńlá kí a sì fi iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ fún un. Bí o bá fẹ́ láti bọlá fún alákòóso kan tí ó jẹ́ alágbára, ó ṣeé ṣe pé ìwọ yóò máa háragàgà láti ṣiṣẹ́sìn ín kí o sì ṣe ohun tí yóò wù ú. Dájúdájú, nígbà náà, a fẹ́ láti wu Ọlọrun. Dípò kí a wulẹ̀ sọ pé, ‘Ìsìn mi tẹ́ mi lọ́rùn,’ ó yẹ kí a rí àrídájú nígbà náà pé ìjọsìn wa kájú àwọn ohun tí Ọlọrun béèrè.
ṢÍṢE ÌFẸ́-INÚ BÀBÁ
6, 7. Èéṣe tí Jesu kò fi gba àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?
6 Jẹ́ kí a ka Matteu 7:21-23 kí a sì ríi bí a bá lè yọ kókó pàtàkì kan sọ́tọ̀ tí ń pinnu bóyá gbogbo ìjọsìn ni ó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun. Jesu sọ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Oluwa, Oluwa,’ ni yoo wọ inú ìjọba awọn ọ̀run, bíkòṣe ẹni naa tí ń ṣe ìfẹ́-inú Baba mi tí ń bẹ ní awọn ọ̀run ni yoo wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yoo wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Oluwa, Oluwa, awa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé awọn ẹ̀mí-èṣù [àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú] jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀ emi yoo wá jẹ́wọ́ fún wọn dájúdájú pé: Emi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà-àìlófin.”
7 Gbígba Jesu Kristi bí Oluwa ṣe kókó nínú ìjọsìn tòótọ́. Ṣùgbọ́n ohun kan yóò sọnù nínú ìjọsìn ọ̀pọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ń sọ pé ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ni àwọn jẹ́. Ó sọ pé àwọn kan yóò ṣe “ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára,” irú àwọn tí a rò pé ó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu ìmúláradá. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n yóò kùnà láti ṣe ohun tí Jesu sọ pé ó ṣekókó. Wọn kì yóò “ṣe ìfẹ́-inú Baba [rẹ̀].” Bí àwa bá fẹ́ láti wu Ọlọrun, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ìfẹ́-inú Baba jẹ́ kí a sì ṣe é.
ÌMỌ̀ PÍPÉYE—ÀÀBÒ KAN
8. Bí a bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun kí ni ohun tí a béèrè, ojú-ìwòye tí ó láṣìṣe wo sì ni a gbọ́dọ̀ yẹra fún?
8 Ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun béèrè ìmọ̀ pípéye nípa Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Dájúdájú, nígbà náà, gbogbo wa yóò fẹ́ láti fi ọwọ́ dan-in dan-in mú ọ̀ràn jíjèrè ìmọ̀ pípéye láti inú Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn kan sọ pé kò sí ìdí fún bíbìkítà níwọ̀n ìgbà tí a bá ti jẹ́ olóòótọ́-inú tí a sì ní ìtara nínú ìjọsìn wa. Àwọn mìíràn sọ pé, ‘Bí ohun tí o mọ̀ bá ti kéré tó, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí a retí lọ́wọ́ rẹ yóò ṣe kéré tó.’ Síbẹ̀, Bibeli fún wa ní ìṣírí láti pọ̀ síi nínú ìmọ̀ Ọlọrun àti àwọn ète rẹ̀.—Efesu 4:13; Filippi 1:9; Kolosse 1:9.
9. Báwo ni ìmọ̀ pípéye ṣe ń dáàbòbò wa, èésìtiṣe tí a fi nílò irú ààbò bẹ́ẹ̀?
9 Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ààbò kúrò lọ́wọ́ kíkó èérí bá ìjọsìn wa. Aposteli Paulu sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀dá ẹ̀mí kan báyìí tí ń díbọ́n jíjẹ́ “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Korinti 11:14) Bí ó ti dọ́gbọ́n paradà, ẹ̀dá ẹ̀mí yìí—Satani—ń gbìyànjú láti ṣì wá lọ́nà láti ṣe àwọn ohun tí ó lòdì sí ìfẹ́-inú Ọlọrun. Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn tí wọ́n ní ìsopọ̀ mọ́ Satani pẹ̀lú ti ń sọ ìjọsìn àwọn ènìyàn di eléèérí, nítorí Paulu sọ pé: “Awọn nǹkan tí awọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ wọ́n fi ń rúbọ sí awọn ẹ̀mí-èṣù, kì í sì í ṣe sí Ọlọrun.” (1 Korinti 10:20) Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ti ronú pé àwọn ń jọ́sìn ní ọ̀nà tí ó tọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ohun tí Ọlọrun fẹ́ ni wọ́n ń ṣe. A ti ṣì wọ́n lọ́nà sínú ìjọsìn èké aláìmọ́. Níwájú a óò kọ́ púpọ̀ síi nípa Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù, ṣùgbọ́n dájúdájú àwọn ọ̀tá Ọlọrun wọ̀nyí ti ń sọ ìjọsìn aráyé di eléèérí.
10. Kí ni ìwọ yóò ṣe bí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ fi májèlé sínú ìpèsè omi rẹ, kí sì ni ìmọ̀ pípéye Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mú wa gbaradì láti ṣe?
10 Bí o bá mọ̀ pé ẹnì kan ti mọ̀ọ́mọ̀ fi májèlé sínú ìpèsè omi rẹ, ìwọ yóò ha ṣì máa mu omi ibẹ̀ bí? Dájúdájú, ìwọ yóò gbé ìgbésẹ̀ ojú-ẹsẹ̀ láti wá orísun omi tí ó mọ́ gaara tí ó sì láàbò. Ó dára, ìmọ̀ pípéye ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń mú wa gbaradì láti mọ ìsìn tòótọ́ yàtọ̀ kí a sì kọ àwọn èérí tí ń sọ ìjọsìn di aláìní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọrun.
ÀṢẸ ÈNÌYÀN BÍ Ẹ̀KỌ́ ÌGBÀGBỌ́
11. Kí ni ohun tí kò tọ̀nà nínú ìjọsìn ọ̀pọ̀ àwọn Júù?
11 Nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀-ayé, ọ̀pọ̀ àwọn Júù kò gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye ti Ọlọrun. Wọ́n tipa báyìí pàdánù àǹfààní láti ní ìdúró mímọ́ tónítóní níwájú Jehofa. Paulu kọ̀wé nípa wọn pé: “Mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọrun; ṣugbọn kì í ṣe ní ìbámu pẹlu ìmọ̀ pípéye.” (Romu 10:2) Wọ́n pinnu fúnra wọn bí wọ́n ṣe fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọrun dípò kí wọ́n tẹ́tísílẹ̀ sí ohun tí ó sọ.
12. Kí ní kó èérí bá ìjọsìn àwọn ọmọ Israeli, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
12 Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọmọ Israeli ṣe ìsìn mímọ́ gaara tí Ọlọrun fún wọn, ṣùgbọ́n ó di èyí tí àwọn ẹ̀kọ́ àti àwọn ọgbọ́n èrò-orí àwọn ènìyàn kó èérí bá pẹ̀lú. (Jeremiah 8:8, 9; Malaki 2:8, 9; Luku 11:52) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù tí a mọ̀ sí àwọn Farisi lérò pé ìjọsìn wọn ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun, Jesu sọ fún wọn pé: “Isaiah sọtẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nipa ẹ̀yin alágàbàgebè, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Awọn ènìyàn yii ń fi ètè wọn bọlá fún mi, ṣugbọn ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nitori pé wọ́n ń fi awọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.’”—Marku 7:6, 7.
13. Báwo ni a ṣe lè ṣe bí àwọn Farisi ti ṣe?
13 Ó ha ṣeé ṣe pé a lè ṣe bí àwọn Farisi náà ti ṣe bí? Èyí lè ṣẹlẹ̀ bí a bá tẹ̀lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn tí a jogún dípò kí a ṣàyẹ̀wò ohun tí Ọlọrun ti sọ nípa ìjọsìn. Ní kíkìlọ̀ nípa ewu yìí gan-an níti gidi, Paulu kọ̀wé pé: “Gbólóhùn àsọjáde onímìísí wí ní pàtó pé ní ìkẹyìn awọn sáà àkókò awọn kan yoo yẹsẹ̀ kúrò ninu ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí awọn gbólóhùn àsọjáde onímìísí tí ń ṣinilọ́nà ati awọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí-èṣù.” (1 Timoteu 4:1) Nítorí náà, láti wulẹ̀ rò pé ìjọsìn wa wu Ọlọrun kò tó. Bíi ti obìnrin ará Samaria náà tí ó pàdé Jesu, a lè ti jogún ọ̀nà ìjọsìn wa láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wa. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí a jẹ́ kí ó dá wa lójú pé a ń ṣe àwọn ohun tí ó kájú ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun.
ṢỌ́RA FÚN MÍMÚ ỌLỌRUN BÍNÚ
14, 15. Àní bí a bá tilẹ̀ ní ìmọ̀ ìfẹ́-inú Ọlọrun díẹ̀, èéṣe tí a fi níláti ṣọ́ra?
14 Àyàfi bí a bá ṣọ́ra, a lè ṣe ohun tí Ọlọrun kò tẹ́wọ́gbà. Fún àpẹẹrẹ, aposteli Johannu wólẹ̀ sí ẹsẹ̀ áńgẹ́lì kan “lati jọ́sìn rẹ̀.” Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà kìlọ̀ pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ ati ti awọn arákùnrin rẹ tí wọ́n ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jesu. Jọ́sìn Ọlọrun.” (Ìṣípayá 19:10) Nípa báyìí ìwọ ha rí àìní náà láti ríi dájú pé irú oríṣi ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí kò kó èérí bá ìjọsìn rẹ?—1 Korinti 10:14.
15 Nígbà tí àwọn Kristian kan bẹ̀rẹ̀ síí ṣe àwọn àṣà ìsìn tí kò wu Ọlọrun, Paulu béèrè pé: “Èétirí tí ẹ tún ń padà sẹ́yìn sí awọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ aláìlera ati akúrẹtẹ̀ tí ẹ sì ń fẹ́ lati tún padà sìnrú fún wọn? Ẹ̀yin ń pa awọn ọjọ́ ati oṣù ati àsìkò ati ọdún mọ́ fínnífínní dórí bín-ń-tín. Ẹ̀rù bà mí fún yín, pé lọ́nà kan ṣáá mo ti ṣe làálàá lásán nipa yín.” (Galatia 4:8-11) Àwọn ẹni wọ̀nyẹn ti jèrè ìmọ̀ Ọlọrun ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà wọ́n ṣìnà nípa kíkíyèsí àwọn àṣà ìsìn àti àwọn ọjọ́ mímọ́ tí Jehofa kò tẹ́wọ́gbà. Bí Paulu ti sọ, a níláti máa “bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Oluwa dájú.”—Efesu 5:10.
16. Báwo ni Johannu 17:16 àti 1 Peteru 4:3 ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu bí àwọn họlidé àti àwọn àṣà kan bá wu Ọlọrun?
16 A gbọ́dọ̀ ríi dájú pé a yẹra fún àwọn họlidé ìsìn àti àwọn àṣà mìíràn tí ń tẹ àwọn ìlànà Ọlọrun lójú. (1 Tessalonika 5:21) Fún àpẹẹrẹ, Jesu sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apákan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí emi kì í ti í ṣe apákan ayé.” (Johannu 17:16) Ìsìn rẹ ha ń lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ àti àwọn họlidé tí ń tẹ ìlànà àìdásí tọ̀tún tòsì níti àwọn àlámọ̀rí ayé lójú bí? Tàbí àwọn tí ẹ jọ wà nínú ìsìn kan náà nígbà mìíràn ha máa ń kópa nínú àwọn àṣà àti àwọn àjọyọ̀ tí ó lè ní nínú ìwà tí ó dọ́gba pẹ̀lú èyí tí aposteli Peteru ṣàpèjúwe bí? Ó kọ̀wé pé: “Àkókò tí ó ti kọjá lọ ti tó fún yín lati fi ṣe ìfẹ́-inú awọn orílẹ̀-èdè nígbà tí ẹ ń tẹ̀síwájú ninu awọn ìṣe ìwà àìníjàánu, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àṣejù nídìí ọtí wáìnì, awọn àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí-mímu, ati awọn ìbọ̀rìṣà tí ó lòdì sí òfin.”—1 Peteru 4:3.
17. Kí ni ìdí tí a fi níláti yẹra fún ohunkóhun tí ó bá gbé ẹ̀mí ayé yọ?
17 Aposteli Johannu tẹnumọ́ àìní náà láti yẹra fún àwọn àṣà tí ó yí wa ká tí ó gbé ẹ̀mí ayé aláìwà-bí-Ọlọ́run yọ. Johannu kọ̀wé pé: “Ẹ máṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tabi awọn ohun tí ń bẹ ninu ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí ninu rẹ̀; nitori ohun gbogbo tí ń bẹ ninu ayé—ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara ati ìfẹ́-ọkàn ti ojú ati fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí-ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Baba, ṣugbọn ó pilẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ni yoo dúró títí láé.” (1 Johannu 2:15-17) Ìwọ ha ṣàkíyèsí pé àwọn wọnnì tí wọ́n “ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun” ní yóò dúró títí láé? Bẹ́ẹ̀ni, bí a bá ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun tí a sì yẹra fún àwọn ìgbòkègbodò tí ń fi ẹ̀mí ayé yìí hàn, a lè ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun!
PA ÀWỌN Ọ̀PÁ-ÌDIWỌ̀N GÍGA ỌLỌRUN MỌ́
18. Báwo ni àwọn ará Korinti kan ṣe ṣàṣìṣe níti ìwà wọn, kí sì ni ó yẹ kí a kọ́ láti inú èyí?
18 Ọlọrun fẹ́ kí àwọn wọnnì tí wọn ń mú ara wọn bá ọ̀pá-ìdiwọ̀n gíga rẹ̀ níti ìwàrere mu jẹ́ olùjọsìn òun. Àwọn kan ní Korinti ìgbàanì fi àṣìṣe lérò pé Ọlọrun yóò fàyègba ìwà pálapàla. A lè rí bí wọ́n ti kùnà tó nípa kíka 1 Korinti 6:9, 10. Bí a bá níláti jọ́sìn Ọlọrun lọ́nà tí òun tẹ́wọ́gbà, a gbọ́dọ̀ wù ú nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe. Irú ọ̀nà-ètò ìjọsìn rẹ ha ń mú kí o ṣe bẹ́ẹ̀ bí?—Matteu 15:8; 23:1-3.
19. Báwo ni ìjọsìn tòótọ́ ṣe nípa lórí bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò?
19 Bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò pẹ̀lú níláti gbé àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun yọ. Jesu Kristi fún wa níṣìírí láti bá àwọn ẹlòmíràn lò bí a óò ti fẹ́ kí wọ́n bá wa lò, nítorí èyí jẹ́ apákan ìjọsìn tòótọ́. (Matteu 7:12) Ṣàkíyèsí ohun tí ó tún sọ nípa fífi ìfẹ́ ará hàn: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Johannu 13:35) Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọn sì ṣe ohun tí ó dára fún àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn àti àwọn mìíràn.—Galatia 6:10.
ÌJỌSÌN TỌKÀNTỌKÀN
20, 21. (a) Irú ìjọsìn wo ni Ọlọrun béèrè fún? (b) Èéṣe tí Jehofa fi ṣá ìjọsìn Israeli tì ní ọjọ́ Malaki?
20 Lọ́kàn rẹ, o lè fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọrun lọ́nà tí ó ṣètẹ́wọ́gbà. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ ní ojú-ìwòye Jehofa nípa ìjọsìn. Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu tẹnumọ́ ọn pé ojú-ìwòye Ọlọrun ni ó ṣe pàtàkì, kì í ṣe tiwa. Jakọbu wí pé: “Irú ọ̀nà-ètò ìjọsìn tí ó mọ́ tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú-ìwòye Ọlọrun ati Baba wa ni èyí: lati máa bójútó awọn ọmọ òrukàn ati awọn opó ninu ìpọ́njú wọn, ati lati pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò ninu ayé.” (Jakọbu 1:27) Pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn láti wu Ọlọrun, gbogbo wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan yẹ kí a yẹ ìjọsìn wa wò láti ríi dájú pé àwọn àṣà aláìwà-bí-Ọlọ́run kò kó èérí bá a tàbí pé a kò gbójúfo ohun kan tí ó kà sí pàtàkì dá.—Jakọbu 1:26.
21 Kìkì ìjọsìn tí ó mọ́ tónítóní, tí ó sì jẹ́ láti ọkàn wá ni ó wu Jehofa. (Matteu 22:37; Kolosse 3:23) Nígbà tí orílẹ̀-èdè Israeli fún Ọlọrun ní ohun tí ó dínkù sí ìyẹn, ó sọ pé: “Ọmọ a máa bọlá fún baba, àti ọmọ-ọ̀dọ̀ fún olúwa rẹ̀: ǹjẹ́ bí èmí bá ṣe baba, ọlá mi ha dà? bí èmí bá sì ṣe olúwa, ẹ̀rù mi ha dà?” Wọ́n mú Ọlọrun bínú nípa fífi àwọn ẹran afọ́jú, arọ, àti aláìsàn ṣe ìrúbọ, ó sì ṣá irú àwọn ìṣe ìjọsìn bẹ́ẹ̀ tì. (Malaki 1:6-8) Jehofa yẹ fún irú ọ̀nà-ètò ìjọsìn tí ó mọ́ gaara jùlọ kò sì gba ohun kan tí ó dínkù sí ìfọkànsìn tí a yàsọ́tọ̀ gédégbé.—Eksodu 20:5; Owe 3:9; Ìṣípayá 4:11.
22. Bí a bá fẹ́ kí Ọlọrun tẹ́wọ́gba ìjọsìn wa, kí ni a óò yẹra fún, kí ni a óò sì ṣe?
22 Ó jọ pé obìnrin ará Samaria tí ó bá Jesu sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́-ọkàn nínú jíjọ́sìn Ọlọrun ní ọ̀nà tí Ọlọrun tẹ́wọ́gbà. Bí ìyẹn bá jẹ́ ìfẹ́-ọkàn wa, a óò yẹra fún gbogbo ẹ̀kọ́ àti àṣà tí ń kó èérí báni. (2 Korinti 6:14-18) Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò tiraka láti gba ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọrun a óò sì ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. A óò tòròpinpin mọ́ àwọn ohun tí ó béèrè fún ìjọsìn tí òun tẹ́wọ́gbà. (1 Timoteu 2:3, 4) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń làkàkà láti ṣe ìyẹn gẹ́lẹ́, wọn sì fi tọ̀yàyà tọ̀yàyà rọ̀ ọ́ láti ṣàjọpín pẹ̀lú wọn nínú jíjọ́sìn Ọlọrun “ní ẹ̀mí ati òtítọ́.” (Johannu 4:24) Jesu sọ pé: “Irúfẹ́ awọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá lati máa jọ́sìn oun.” (Johannu 4:23) A nírètí pé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ ni ìwọ́ jẹ́. Bí obìnrin ará Samaria yẹn, láìṣiyèméjì ìwọ yóò fẹ́ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Johannu 4:13-15) Ṣùgbọ́n o ń rí i tí àwọn ènìyàn ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú. Orí tí ó tẹ̀lé e ṣàlàyé ohun tí ó fa sábàbí.
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Bí Johannu 4:23, 24 ti fi hàn, irú ìjọsìn wo ni Ọlọrun tẹ́wọ́gbà?
Báwo ni a ṣe lè pinnu bóyá irú àwọn àṣà àti àjọyọ̀ kan wu Ọlọrun?
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí a béèrè fún ìjọsìn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 44]