O Lè La Àwọn Ìṣòro Tó Dà Bí Ìjì Já
LÁWỌN àkókò líle koko tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ ló ń fojú winá àwọn ìṣòro tó dà bí ìjì líle. Síbẹ̀, ìfẹ́ táwọn Kristẹni ní fún Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe ń fi gbogbo ọkàn wọn tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Lọ́nà wo? A lè rí ìdáhùn nínú àkàwé kan tí Jésù Kristi sọ. Ó fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onígbọràn wé “ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.” Jésù sọ pé: “Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ṣùgbọ́n kò ya lulẹ̀, nítorí a ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.”—Mátíù 7:24, 25.
Kíyè sí i pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin inú àkàwé Jésù yìí jẹ́ olóye, síbẹ̀ ó ṣì rí ìpọ́njú, èyí tí Jésù fi wé ọ̀yamùúmùú òjò, àkúnya omi, àti ìjì tó ń ba nǹkan jẹ́. Nípa báyìí, Jésù kò sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò ní níṣòro rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé wọ́n á máa ní àlááfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn nígbà gbogbo. (Sáàmù 34:19; Jákọ́bù 4:13-15) Síbẹ̀, ó ní yóò ṣeé ṣe fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ láti múra sílẹ̀ de irú àwọn ìpọ́njú àti ìṣòro tó dà bí ìjì líle bẹ́ẹ̀, àti pé á ṣeé ṣe fún wọn láti fara dà á.
Jésù bẹ̀rẹ̀ àkàwé náà nípa sísọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí ó sì ń ṣe wọ́n ni a ó fi wé ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.” Àmọ́ o, kì í ṣe ọ̀rọ̀ kíkọ́ ilé ni Jésù ń sọ bí kò ṣe níní àwọn ànímọ́ tó yẹ kí Kristẹni ní. Àwọn tó bá ń fi ọ̀rọ̀ Jésù sílò máa ń lo ọgbọ́n inú àti làákàyè nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Orí àwọn ẹ̀kọ́ Kristi tó dà bí àpáta ràbàtà, èyí tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in-gbọn-in, ni wọ́n máa ń gbé èrò ọkàn wọn àti ìṣe wọn kà. Ọ̀nà tí wọ́n sì ń gbà ṣe èyí ni nípa fífi àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ sílò. Ó yẹ ká kíyè sí i pé, abẹ́ ilẹ̀ ni àpáta ràbàtà ìṣàpẹẹrẹ yìí wà. Ọkùnrin olóye inú àkàwé náà ní láti “walẹ̀ jìn” kó tó lè kan àpáta náà. (Lúùkù 6:48) Bákan náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa ń sa gbogbo ipá wọn láti ní àwọn ànímọ́ tó máa sọ wọ́n di Kristẹni tó jinná dénú tí yóò túbọ̀ mú wọn sún mọ́ Ọlọ́run.—Mátíù 5:5-7; 6:33.
Kí làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa ń ṣe nígbà táwọn ìṣòro tó dà bí ìjì líle bá fẹ́ bi ìgbàgbọ́ wọn ṣubú? Àwọn ẹ̀kọ́ Kristi tí wọ́n ń fi sílò tinútinú àtàwọn ànímọ́ Kristẹni tí wọ́n ní ń fún wọn lókun nírú àwọn àkókò ìpọ́njú bẹ́ẹ̀. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, àwọn ànímọ́ wọ̀nyí yóò fún wọn lókun lákòókò ìjì Amágẹ́dọ́nì tó máa tó jà. (Mátíù 5:10-12; Ìṣípayá 16:15, 16) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀ ló ń borí àwọn ìṣòro tó dà bí ìjì lónìí nípa fífi àwọn ẹ̀kọ́ Kristi sílò. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Pétérù 2:21-23.