ORÍ KARÙN-ÚN
“Gbogbo Ìṣúra Ọgbọ́n”
1-3. Báwo ni nǹkan ṣe lọ lọ́jọ́ kan báyìí ní ìgbà ìrúwé ọdún 31 Sànmánì Kristẹni tí Jésù ṣe ìwàásù kan, kí sì nìdí tẹ́nu fi ya àwọn olùgbọ́ rẹ̀?
ÌGBÀ ìrúwé ọdún 31 Sànmánì Kristẹni ni. Jésù Kristi ti sún mọ́ ìlú Kápánáúmù, ìyẹn ìlú kan tó kún fún ọ̀pọ̀ èrò tó ń ṣe káràkátà. Ó wà ní àríwá ìwọ̀ oòrùn létí Òkun Gálílì. Lórí òkè kan láyìíká ibẹ̀, Jésù gbàdúrà ní gbogbo òru yẹn lóun nìkan. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ó pe àwọn ọmọ ẹyìn rẹ̀ jọ, lára wọn ló sì ti yan àwọn méjìlá, tó pè ní àpọ́sítélì. Síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà yẹn, ogunlọ́gọ̀ èèyàn ti tẹ̀ lé Jésù débí yìí. Ọ̀nà tó jìn púpọ̀ làwọn kan nínú wọn ti wá, wọ́n sì pé jọ síbi tó tẹ́ju lórí òkè náà. Wọ́n ti ń fojú sọ́nà láti gbọ́ ohun tí Jésù fẹ́ bá wọn sọ, wọ́n tún fẹ́ kó wo àìsàn wọn sàn. Gbogbo ohun tí wọ́n ń retí ni Jésù sì ṣe fún wọn.—Lúùkù 6:12-19.
2 Jésù sún mọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà, ó sì wo gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn láàárín wọn sàn. Lẹ́yìn tó rí i pé kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn mọ́ tó ní àìsàn líle kankan lára, ó jókòó ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.a Ọ̀rọ̀ tó sọ lọ́jọ́ tí afẹ́fẹ́ ìtùra ń fẹ́ yẹ́ẹ́ yẹn ní láti yà wọ́n lẹ́nu. Wọn ò ṣáà tíì rí kí ẹnikẹ́ni kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ báyẹn rí. Kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bàa lè rinlẹ̀ létí àwọn olùgbọ́ rẹ̀, kò mú lára ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ tàbí látinú ọ̀rọ̀ àwọn rábì Júù tí wọ́n jẹ́ gbajúmọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, látinú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ló ti ń fa ọ̀rọ̀ yọ léraléra. Ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣe tààràtà, ọ̀rọ̀ tó ń sọ ò lọ́jú pọ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣe kedere. Nígbà tó sì kọ́ wọn tán, ẹnu ya àwọn èèyàn náà. Ẹnù ò lè má yà wọ́n, torí pé ọkùnrin tó tíì gbọ́n jù láyè yìí ló ṣẹ̀ṣẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀ tán!—Mátíù 7:28, 29.
3 Ìwàásù yẹn àtàwọn nǹkan míì tí Jésù sọ àtèyí tó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ohun tó máa dáa ni pé ká yànàná ohun tí Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí sọ nípa Jésù, nítorí pé nínú Jésù ni “gbogbo ìṣúra ọgbọ́n” wà. (Kólósè 2:3) Ibo ló ti rí irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀, ìyẹn ọgbọ́n tó jẹ́ kó lè lo ìmọ̀ àti òye? Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe fa ọgbọ́n yọ, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
“Ibo Ni Ọkùnrin Yìí Ti Rí Ọgbọ́n Yìí?”
4. Ìbéèrè wo làwọn olùgbọ́ Jésù ní Násárétì ń béèrè, kí sì nìdí?
4 Lọ́jọ́ kan, bí Jésù ṣe ń wàásù kiri, ó dé sí Násárétì tí í ṣe ìlú tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni nínú sínágọ́gù. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́nu ń yà tí wọ́n sì ń ṣe kàyééfì, wọ́n béèrè pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí?” Wọ́n mọ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, ìyẹn àwọn òbí àtàwọn ọmọ ìyá rẹ̀, wọ́n mọ̀ pé kò-là-kò-ṣagbe ni wọ́n nínú ìdílé tó ti jáde. (Mátíù 13:54-56; Máàkù 6:1-3) Ó sì dá wọn lójú ṣáká pé ọ̀gbẹ́ni gbẹ́nàgbẹ́nà, tọ́rọ̀ yọ̀ mọ́ lẹ́nu yìí ò lọ sí èyíkéyìí lára ìlé ìwé àwọn rábì tó gbayì. (Jòhánù 7:15) Torí náá, ó dà bíi pé ìbéèrè wọn mọ́gbọ́n dání.
5. Ibo ni Jésù sọ pé òun ti rí ọgbọ́n tóun ń lò?
5 Ẹni pípé ni Jésù lóòótọ́, àmọ́ ọgbọ́n rẹ̀ ò tinú èrò tiẹ̀ fúnra rẹ̀ wá. Nígbà tó yá, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó parí, lákòókò kan tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní gbangba nínú tẹ́ńpìlì, Jésù fi hàn pé ọgbọ́n tó wá láti òkè ni ọgbọ́n tòun. Ó ní: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Bẹ́ẹ̀ ni, Baba Jésù tó rán an wá sáyé gan-an ni orísun ọgbọ́n rẹ̀. (Jòhánù 12:49) Báwo ni Jésù ṣe wá gba ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Jèhófà?
6, 7. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà rí ọgbọ́n gbà látọ̀dọ̀ Bàbá rẹ̀?
6 Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń darí ọkàn àti èrò Jésù. Aísàyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù tó máa jẹ́ Mèsáyà pé: “Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Aísáyà 11:2) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀mí Jèhófà ló bà lé e tó sì ń tọ́ ìrònú rẹ̀ àti ìpinnu tó ń ṣe, ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù ń sọ àtohun tó ń ṣe ń fi ọgbọ́n tó ju ọgbọ́n lọ hàn?
7 Ọ̀nà pàtàkì míì tún wà tí Jésù gbà rí ọgbọ̀n gbà látọ̀dọ̀ Bàbá rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i ní Orí 2, láti àìmọye ọdún kí Jésù tó wá sáyé, ó ní àǹfààní láti mọ èrò Bàbá rẹ̀ lórí àwọn ọ̀ràn. Kò sí bá a ṣe lè máa sọ ìwọ̀n ọgbọ́n tí Ọmọ yìí á ti kó jọ látìgbà tó ti wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀ nígbà tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” Ọlọ́run lákòókò ìṣẹ̀dá gbogbo nǹkan abẹ̀mí àti aláìlẹ́mìí. Ó tọ́ nígbà náà pé kí Bíbélì pe Ọmọ yìí tó wá sáyé bí èèyàn ní ọgbọ́n. (Òwe 8:22-31; Kólósè 1:15, 16) Ní gbogbo ìgbà tó sì fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó lo ọgbọ́n tó ti kó jọ nígbà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀ lọ́run.b (Jòhánù 8:26, 28, 38) Nítorí náà, ká má ṣe jẹ́ kó yà wá lẹ́nu jù bá a ṣe ń rí ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti òye táwọn ọ̀rọ̀ Jésù ń fi hàn àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ làákàyè tó ń yọ nínú gbogbo ìṣe rẹ̀.
8. Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù, báwo la ṣe lè ní ọgbọ́n?
8 Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù, ó pọn dandan káwa náà wá ọgbọ́n lọ sọ́dọ̀ Jèhófà. (Òwe 2:6) Òótọ́ kan ni pé Jèhófà kì í fún wa ní ọgbọ́n lọ́nà ìyanu. Àmọ́, tá a bá fi taratara bẹ̀ ẹ́ nígbà tá a bá ń gbàdúrà pé kó fún wa ní ọgbọ́n láti fi yanjú àwọn ìṣòro kan nígbèésí ayé, ó máa ń fún wa. (Jákọ́bù 1:5) Ká tó lè ní irú ọgbọ́n yẹn, ó ń béèrè pé ká sapá gan-an. A ní láti máa wá a “bí àwọn ìṣúra fífarasin.” (Òwe 2:1-6) Bẹ́ẹ̀ ni o, ńṣe la ní láti máa walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, níbi tí ọgbọ́n rẹ̀ wà, ká sì jẹ́ kí ìgbésí ayé wa bá ohun tá à ń kọ́ mu. Àpẹẹrẹ Ọmọ Jèhófà máa wúlò fún wa láti lè mọ bá a ṣe lè ní ọgbọ́n. Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà mélòó kan tí Jésù gbà fi ọgbọ́n hàn ká sì kọ́ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n
9. Kí ló mú káwọn ẹ̀kọ́ Jésù fọgbọ́n yọ tó bẹ́ẹ̀?
9 Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ló ń wọ́ tọ Jésù wá torí àtilè gbọ́rọ̀ rẹ̀. (Máàkù 6:31-34; Lúùkù 5:1-3) Ìyẹn ò sì yẹ kó yà wá lẹ́nu tórí a mọ̀ pé tí Jésù bá lanu kòtó báyìí, ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ju ọgbọ́n lọ ló máa ń bọ́ lẹ́nu rẹ̀! Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ máa ń fi hàn pé ó ní òye tó jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì mọ bó ṣe lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ tànmọ́lẹ̀ sí gbogbo ohun tó ṣókùnkùn. Kò síbi tí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ò ti fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra, kò sì sígbà tí wọn ò wúlò. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára ọgbọ́n tá a rí nínú ọ̀rọ̀ Jésù, ẹni tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pè ní “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn.”—Aísáyà 9:6.
10. Àwọn ànímọ́ rere wo ni Jésù rọ̀ wá pé ká kọ́, kí sì nìdí?
10 Ìwàásù Lórí Òkè tá a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ Orí yìí ni èyí tó tíì pọ̀ jù lára àwọn àkọsílẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀kọ́ Jésù pọ́ńbélé, tí ọ̀rọ̀ ẹlòmíì kò wọ̀ ọ́. Nínú ìwàásù yìí, kì í ṣe pé Jésù kàn ń gbà wá níyànjú nípa bó ṣe yẹ ká máa sọ̀rọ̀ àti bó ṣe yẹ ká máa hùwà nìkan ni. Ìmọ̀ràn tó gbà wá jù bẹ́ẹ̀ lọ. Jésù mọ̀ pé ohun tó wà lọ́kàn wa àti bí nǹkan bá ṣe rí lára wa ló máa ń mú ká sọ̀rọ̀ tàbí ká hùwà, torí rẹ̀ ló ṣe rọ̀ wá pé ká ní àwọn ànímọ́ rere nínú ọkàn wa, ìyẹn àwọn ànímọ́ bí inú tútù, ìfẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́, fífẹ́ láti jẹ́ aláàánú àti ẹni àlàáfíà àti nínífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. (Mátíù 5:5-9, 43-48) Bá a ṣe ń gbin irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí sínú ọkàn wa, ohun tó máa tìdí rẹ̀ yọ ni pé ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa á jẹ́ èyí tó ṣàǹfààní. Kì í ṣe pé á máa múnú Jèhófà dùn nìkan ni, ṣùgbọ́n á tún máa jẹ́ kí àárín àwa àtàwọn ẹlòmíì dán mọ́rán.—Mátíù 5:16.
11. Bí Jésù bá ń fúnni nímọ̀ràn nípa ìwà tó lè múni dẹ́ṣẹ̀, báwo ló ṣe máa ń túṣu ọ̀rọ̀ désàlẹ̀ ìkòkò?
11 Jésù máa ń túṣu ọ̀rọ̀ désàlẹ̀ ìkòkò nígbà tó bá ń fúnni nímọ̀ràn nípa àwọn ìwà tó lè múni dẹ́ṣẹ̀. Kò kàn sọ fún wa pé ká yàgò fún ìwà ipá, àmọ́ ó kílọ̀ fún wa láti má ṣe gba ìbínú láyè nínú ọkàn wa. (Mátíù 5:21, 22; 1 Jòhánù 3:15) Dípò kó kàn sọ pé ká má ṣe panṣágà, ṣe ló kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó máa ń bẹ̀rẹ̀ látinú ọkàn láyè kó tó sún wa ṣe panṣágà. Ó gbà wá níyànjú pé ká má ṣe jẹ́ kí ojú wa rí ohun tó máa mú ká ní èròkerò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. (Mátíù 5:27-30) Èrò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó máa ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ ni Jésù tẹnu mọ́ kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fúnra rẹ̀.—Sáàmù 7:14.
12. Ojú wo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi ń wo àwọn àmọ̀ràn rẹ̀, kí sì nìdí?
12 Kékeré mà kọ́ ni ọgbọ́n tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù o! Àbájọ tó fi jẹ́ pé “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:28) Ńṣe làwa ọmọlẹ́yìn Jésù ń jẹ́ kí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n rẹ̀ máa tọ́ wa sọ́nà nígbèésí ayé wa. A máa ń wá bá a ṣe máa ní àwọn ànímọ́ rere tó dámọ́ràn, ìyẹn àwọn ànímọ́ bí àánú, àlàáfíà, àti ìfẹ́, níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé èyí á jẹ́ ká lè máa ṣe ohun tó máa wu Jèhófà. A máa ń sapá láti fa àwọn ìwàkiwà, bí ìbínú kíkorò àti ìfẹ́ ìṣekúṣe, tí Jésù kì wá nílọ̀ nípa rẹ̀ tu kúrò nínú ọkàn wa. Torí a mọ̀ pé ìyẹn ló máa mú kó rọrùn fún wa láti yàgò fún àwọn ìwà tó lè sún wa dẹ́ṣẹ̀.—Jákọ́bù 1:14, 15.
Ọgbọ́n Darí Gbogbo Ìgbé Ayé Rẹ̀
13, 14. Kí ló fi hàn pé Jésù lo làákàyé nígbà tó fẹ́ yan ohun tó máa fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe?
13 Bí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ṣe ń fa ọgbọ́n yọ náà ni àwọn ìwà rẹ̀ ṣe ń fi ìmọ̀ hàn. Gbogbo ìgbé ayé rẹ̀ pátá lọgbọ́n ti hàn lónírúurú ọ̀nà tó wúni lórí. Ṣé ti àwọn ìpinnu tó ṣe ni ká sọ ni, àbí ti ojú tó fi ń wo ara rẹ̀, títí kan ọwọ́ tó fi mú àwọn ẹlòmíì. Wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yìí tó jẹ́ ká mọ̀ gbangba pé “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú” ló ń darí Jésù.—Òwe 3:21.
14 Ọgbọ́n tún ní nínú lílo làákàyè. Jésù fi làákàyè yan ohun tó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Ronú lórí irú ìgbé ayé tí ì bá gbé ná, irú ilé tí ì bá kọ́, bí òwò rẹ̀ ì bá ti búrẹ́kẹ́ tó àti bí ì bá ṣe níyì tó? Jésù mọ̀ pé “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù” ni ẹni tó bá fi ìgbésí ayé rẹ̀ lé irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Oníwàásù 4:4; 5:10) Ìwà òmùgọ̀ ló jẹ́, òdìkejì ọgbọ́n sì nìyẹn. Jésù yàn láti gbé ìgbésí ayé tó mọ níwọ̀n. Kò lépa àtikówó jọ tàbí àtiní dúkìá rẹpẹtẹ. (Mátíù 8:20) Ohun tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn lòun náà ń ṣe, ohun kan ṣoṣo ló fi ṣe àfojúsùn, ìyẹn ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mátíù 6:22) Ọgbọ́n Jésù mú kó pinnu láti fi gbogbo àkókò àti agbára rẹ̀ ṣe àwọn nǹkan tó máa mú kí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tẹ̀ síwájú. Àwọn nǹkan yìí sì ṣe pàtàkì fíìfíì ju nǹkan tara lọ̀, kódà ó ṣàǹfààní. (Mátíù 6:19-21) Nípa báyìí, ó fi àpẹẹrẹ tó yẹ ká tẹ̀ lé lélẹ̀ fún wa.
15. Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe lè fi hàn pé ọ̀nà kan lojú àwọn mú, kí sì nìdí tí gbígbé ìgbésí ayé ẹni lọ́nà bẹ́ẹ̀ fi bọ́gbọ́n mu?
15 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù òde òní náà mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu láti máa lépa ohun tọ́wọ́ wọn ò lè tẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọn kì í fi í tọrùn bọ gbèsè, tí wọn kì í sì í lé ohun tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní gidi kan, èyí tó lè gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ àkókò àti okun. (1 Tímótì 6:9, 10) Ọ̀pọ̀ ló ti gbé ìgbésẹ̀ láti jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn mọ níwọ̀n kí wọ́n bàa lè rí àkókò tó túbọ̀ pọ̀ sí i fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, bóyá kí wọ́n tiẹ̀ máa sìn bí oníwàásù alákòókò kíkún. Kò sí nǹkan míì téèyàn tún lè ṣe nígbèésí ayé tó lérè tó fífi ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sípò tó tọ́, nítorí pé òun ló máa ń fún èèyàn ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn jù lọ.—Mátíù 6:33.
16, 17. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun àti pé òun ò retí kóun ṣe kọjá agbára òun? (b) Báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa àti pé a ò retí láti ṣe kọjá agbára wa?
16 Bíbélì fi hàn pé ọgbọ́n tan mọ́ ìmẹ̀tọ́mọ̀wà, èyí tó jẹ mọ́ ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni. (Òwe 11:2) Jésù mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, kò sì retí pé òun á ṣe kọjá agbára òun. Ó mọ̀ pé gbogbo ẹni tó gbọ́rọ̀ òun ò lè di ọmọlẹ́yìn òun. (Mátíù 10:32-39) Ó sì tún mọ̀ pé ìwọ̀nba niye èèyàn tóun fúnra òun máa lè ráyè wàásù dé ọ̀dọ̀ wọn. Ìdí nìyẹn tó fi bọ́gbọ́n mu pé ó gbé iṣẹ́ sísọni-di-ọmọ-ẹ̀yìn lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́. (Mátíù 28:18-20) Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni ló jẹ́ kó sọ pé wọ́n á “ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju” èyí tóun ṣe lọ, torí wọ́n á ní láti wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn láwọn ibi tó pọ̀ gan-an àti fún àkókò tó gùn gan-an. (Jòhánù 14:12) Jésù sì mọ̀ pé òun ò kọjá ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́. Ó gba ìrànlọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n wá ṣèrànṣẹ́ fún un nígbà tó wà nínú aginjù, ó sì gba okun tí áńgẹ́lì kan fún un nínú ọgbà Gẹ́tisémánì. Nígbà kan tí nǹkan le tán, Ọmọ Ọlọ́run kígbe sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́.—Mátíù 4:11; Lúùkù 22:43; Hébérù 5:7.
17 Àwa náà ní láti mọ̀wọ̀n ara wa, ká sì má máa rò pé a lè ṣe kọjá ibi tí agbára wa mọ. Ó máa ń wù wá láti fi gbogbo ọkàn wa àti gbogbo okun wa ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọni-di-ọmọ-ẹ̀yin. (Lúùkù 13:24; Kólósè 3:23) Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà kì í fi wá wé àwọn ẹlòmíràn, àwa náà ò sì gbọ́dọ̀ máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì. (Gálátíà 6:4) Bá a bá ní ọgbọ́n, ohun tágbára wa ká, tí ipò wa sì máa gbà wá láyè láti ṣe la ó fi ṣe àfojúsùn. Láfikún sí i, ọgbọ́n á tọ́ àwọn tó ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn sọ́nà débi tí wọ́n á fi máa rántí pé àwọn náà ní àwọ̀n kùdìẹ̀ kudiẹ kan, wọ́n á sì lè mọ̀ pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí lóòrèkóòrè. Bí wọ́n bá mọ̀wọ̀n ara wọn, wọ́n á lè máa mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá rí gbà, wọ́n á sì máa rántí pé Jèhófà lè fi onígbàgbọ́ bíi tiwọn ṣe “àrànṣe afúnnilókun” fún wọn.—Kólósè 4:11.
18, 19. (a) Kí ló fi hàn pé Jésù fi òye bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò, báwo ló sì ṣe ń mára tù wọ́n? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ní èrò rere nípa àwọn ará wa lẹ́nì kìíní-kejì ká sì máa fòye bá wọn lò, báwo la sì ṣe lè ṣe é?
18 Jákọ́bù 3:17 sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè . . . ń fòye báni lò.” Jésù máa ń fòye báni lò, ó sì jẹ́ onínúure sáwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ó mọ àléébù wọn, síbẹ̀ ànímọ́ rere tí wọ́n ní ló máa ń wò. (Jòhánù 1:47) Ó mọ̀ pé wọ́n á pa òun tì lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n máa mú òun, síbẹ̀ ó gbà pé ẹ̀yìn òun ni wọ́n ṣì wà. (Mátíù 26:31-35; Lúùkù 22:28-30) Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sẹ́ pé òun ò tiẹ̀ mọ Jésù rí. Pẹ̀lú ìyẹn náà, Jésù gbàdúrà nítorí Pétérù, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun ṣì fọkàn tán an. (Lúùkù 22:31-34) Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, kò mẹ́nu ba àṣìṣe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó ń gbàdúrà sí Bàbá. Dípò ìyẹn, dáadáa tí wọ́n ti ń ṣe bọ̀ títí di alẹ́ ọjọ́ yẹn ló ń sọ, ó ní: “Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.” (Jòhanù 17:6) Láìfi ti àìpé wọn ṣe, ìkáwọ́ wọn ló fi gbogbo àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé sí. (Mátíù 25:14, 15; Lúùkù 12:42-44) Kò síyè méjì pé sísọ tó sọ ìgbọ́kànlé àti ìgbàgbọ́ tó ní nínú wọn jáde jẹ́ kóríyá fún wọn láti ṣe iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́.
19 Kò sóhun tó gbọ́dọ̀ mú káwa ọmọlẹ́yìn Jésù kùnà láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ láwọn ọ̀nà yìí. Bí Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípé bá lè ní sùúrù láti bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìpé lò nírú ọ̀nà bẹ́ẹ̀, mélòó mélòó ló wá yẹ kí àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ máa fòye bá ara wa lò! (Fílípì 4:5) Dípò tí a ó fi máa ránnu mọ́ àṣìṣe àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, ńṣe ni ká máa wo ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Ọgbọ́n tá a bá ní ò ní jẹ́ ká gbàgbé pé Jèhófà ló pè wọ́n. (Jòhánù 6:44) Kó sì tó lè pè wọ́n, ó gbọ́dọ̀ ti rí ànímọ́ rere kan lára wọn, ó sì yẹ káwa náà rí i. Bá a bá ní èrò rere nípa wọn, á jẹ́ ká lè máa “gbójú fo” àṣìṣe wọn, ká sì máa wá ohun rere tá a lè tìtorí rẹ̀ yìn wọ́n. (Òwe 19:11) Bá a bá jẹ́ káwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin mọ̀ pé a ní ìgbọ́nkànlé nínú wọn, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti sin Jèhófà kí wọ́n sì máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn.—1 Tẹsalóníkà 5:11.
20. Kí ló yẹ ká fi ibú ọgbọ̀n tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe, kí sì nìdí?
20 Ká sòótọ́, ibú ọgbọ́n ni àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere! Kí ló yẹ ká fi ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ yìí ṣe? Nígbà tí Jésù fẹ́ parí Ìwàásù Lórí Òkè, ó rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kì í ṣe kí wọ́n kàn gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tóun sọ lásán ló jà jù o, àmọ́ kí wọ́n rí i pé àwọn ṣe ohun tí òun sọ, lédè míì, pé kí wọ́n mú ohun tí wọ́n gbọ́ lò. (Mátíù 7:24-27) Bá a bá ń jẹ́ kí ìrònú wa bá àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí Jésù sọ àtàwọn ohun tó ṣe mu, tó sì jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ náà ló ń sún wa ṣe ohun tá à ń ṣe, tá a sì ń hùwà tó bá àwọn ọ̀rọ̀ náà mu, ó máa mú ká lè gbé ìgbésí ayé tó dáa jù lọ nísinsìnyí, a ó sì lè wà lójú ọ̀nà tá a máa tọ̀ dé ìyè àìnípẹ̀kun. (Mátíù 7:13, 14) Ó dájú pé kò sí ọ̀nà ọlọgbọ́n míì tá a lè gbà gbé ìgbésí ayé wa jùyẹn lọ!
a Àsọyé tí Jésù sọ lọ́jọ́ yẹn ló di èyí tá a mọ̀ sí Ìwàásù Lórí Òkè. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Mátíù 5:3–7:27, ẹsẹ mẹ́tàdínláàádọ́fa [107] ló ní, ó sì ṣeé ṣe kó má gba Jésù ju nǹkan bí ogún ìṣẹ́jú lọ láti sọ ọ́.
b Ó dájú pé, nígbà tí “ọ̀run ṣí sílẹ̀” lọ́jọ́ tó ṣèrìbọmi, òye wíwà Jésù kó tó wá sáyé padà sọ sí i nínú.—Mátíù 3:13-17.