“Ọ̀fẹ́ Ni Ẹ̀yin Gbà, Ọ̀fẹ́ Ni Kí Ẹ Fúnni”
“Ọ̀FẸ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Ìtọ́ni yẹn ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó rán wọn jáde láti lọ wàásù ìhìn rere náà. Ǹjẹ́ àwọn àpọ́sítélì ṣègbọràn sí ìtọ́ni yìí? Bẹ́ẹ̀ ni o, kódà wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́yìn tí Jésù kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Símónì tó jẹ́ oṣó tẹ́lẹ̀ rí agbára iṣẹ́ ìyanu tí àpọ́sítélì Pétérù àti Jòhánù ní, ó fẹ́ fún wọn lówó kí wọ́n lè fún òun nírú agbára bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Pétérù bá Símónì wí, ó sì sọ fún un pé: “Kí fàdákà rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí ìwọ rò pé o lè tipasẹ̀ owó rí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run gbà.”—Ìṣe 8:18-20.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà fi irú ẹ̀mí tó jọ ti Pétérù hàn. Pọ́ọ̀lù ì bá ti sọ ara rẹ̀ di ẹrù ìnáwó sí ọrùn àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀ tó wà ní Kọ́ríńtì. Àmọ́, ńṣe ló ń fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. (Ìṣe 18:1-3) Abájọ, tó fi lè fi gbogbo ẹnu sọ pé òun ti wàásù ìhìn rere náà fún àwọn ará Kọ́ríńtì “láìgba owó.”—1 Kọ́ríńtì 4:12; 9:18.
Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ tó pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn Kristi ni kò fi ẹ̀mí ìmúratán kan náà láti ‘fúnni lọ́fẹ̀ẹ́’ hàn. Àní, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ló ń “fúnni ní ìtọ́ni kìkì fún iye kan.” (Míkà 3:11) Àwọn kan lára àwọn aṣáájú ìsìn tiẹ̀ ti di ọlọ́rọ̀ látinú owó tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ. Àní lọ́dún 1989, wọ́n fi ajíhìnrere kan sẹ́wọ̀n ọdún márùnlélógójì ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nítorí kí ni? Ó ti “lu àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ní jìbìtì ọ̀kẹ́ àìmọye dọ́là, ó sì ti fi lára owó náà ra ọ̀pọ̀ ilé àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ó ti ná lára rẹ̀ sórí ìrìn àjò afẹ́, kódà ó tún ra ilé kan tí wọ́n kọ́ fún ajá, tí wọ́n sì ṣe ẹ̀rọ amúlétutù sínú rẹ̀.”—Ìwé ìròyìn People’s Daily Graphic, October 7, 1989.
Ní Gánà, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn Ghanaian Times ti March 31, 1990 sọ, ńṣe ni àlùfáà ìjọ Kátólíìkì kan kó owó táwọn ọmọ ìjọ dá lákòókò ìsìn kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì jọ, tó sì da owó náà lu àwọn ọmọ ìjọ. Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, níwọ̀n bí àwọn ará ìjọ náà ti jẹ́ àwọn tó dàgbà, ó retí pé kí wọ́n dá owó ńláńlá.” Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ló ń gbìyànjú láti jẹ́ kí àwọn ọmọ ìjọ wọn ní ẹ̀mí ìwọra nípa gbígbé tẹ́tẹ́ títa àti àwọn ọ̀nà àrékérekè mìíràn lárugẹ kí owó lè wọlé fún wọn.
Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti fara wé Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí. Wọn ò ní àwọn àlùfáà tí wọ́n ń sanwó oṣù fún. Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ló jẹ́ òjíṣẹ́ tá a gbé ẹrù iṣẹ́ wíwàásù “ìhìn rere ìjọba” náà fáwọn ẹlòmíràn lé lọ́wọ́. (Mátíù 24:14) Àwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà lára wọn kárí ayé ló ń mú “omi ìyè” lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́. (Ìṣípayá 22:17) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn tí “kò ní owó” pàápàá lè jàǹfààní látinú ìhìn Bíbélì náà. (Aísáyà 55:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó táwọn èèyàn ń fínnúfíndọ̀ dá ni wọ́n ń ná sórí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe jákèjádò ayé, síbẹ̀ wọn ò tọrọ owó rí. Gẹ́gẹ́ bí àwọn òjíṣẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run, wọn kì í ṣe “akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” àmọ́ wọ́n ń sọ̀rọ̀ ‘pẹ̀lú òtítọ́ inú, bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí a ti rán wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.’—2 Kọ́ríńtì 2:17.
Kí wá nìdí tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń fẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, tí wọ́n á sì ná owó ara wọn? Kí ló ń mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ fífúnni lọ́fẹ̀ẹ́ túmọ̀ sí pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìsí èrè kankan fún ìsapá wọn?
Ìdáhùn sí Ìpèníjà Sátánì
Olórí ohun tó ń sún àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe lónìí ni fífẹ́ tí wọ́n fẹ́ múnú Jèhófà dùn—kì í ṣe láti sọ ara wọn di ọlọ́rọ̀. Ìyẹn sì wá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti pèsè ìdáhùn sí ìpèníjà tí Sátánì Èṣù gbé dìde ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Ìbéèrè tí Sátánì gbé ko Jèhófà lójú nítorí Jóòbù ọkùnrin olódodo nì ni pé, “Lásán ha ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run bí?” Sátánì wá sọ pé Jóòbù ń sin Ọlọ́run kìkì nítorí pé Ó ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká. Sátánì sọ pé tí gbogbo ohun ìní Jóòbù ò bá sí mọ́, ó dájú pé Jóòbù yóò bú Ọlọ́run ní ojú rẹ̀ gan-an!—Jóòbù 1:7-11.
Láti dáhùn ìpèníjà yìí, Ọlọ́run fàyè gba Sátánì láti dán Jóòbù wò, ó sọ pé: “Ohun gbogbo tí ó ní wà ní ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 1:12) Kí ni àbájáde rẹ̀? Jóòbù fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Pẹ̀lú bí ìpọ́njú tó bá a ṣe pọ̀ tó, Jóòbù dúró ṣinṣin. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—Jóòbù 27:5, 6.
Àwọn olùjọsìn tòótọ́ ń fi irú ẹ̀mí tó dà bíi ti Jóòbù hàn lóde òní. Kì í ṣe nítorí àtikó ọrọ̀ jọ ni wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run.
Ẹ̀bùn Ọ̀fẹ́ Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
Ìdí mìíràn táwọn Kristẹni fi múra tán láti “fúnni lọ́fẹ̀ẹ́” ni pé àwọn fúnra wọn ti “gbà lọ́fẹ̀ẹ́” láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìran ènìyàn wà nínú ìdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, baba ńlá wa. (Róòmù 5:12) Ìfẹ́ sún Jèhófà láti ṣètò pé kí Ọmọ òun kú ikú ìrúbọ—ìyẹn sì ká Ọlọ́run lára gan-an. Ó dájú pé ìràn ènìyàn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí èyí rárá. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni.—Róòmù 4:4; 5:8; 6:23.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Róòmù 3:23, 24, Pọ́ọ̀lù wá sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run, a sì ń polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.” Bákan náà làwọn tó ní ìrètí wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń gba “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́.” Ẹ̀bùn yìí wé mọ́ àǹfààní dídi ẹni tí a kà sí olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Jèhófà.—Jákọ́bù 2:23; Ìṣípayá 7:14.
Ẹbọ ìràpadà Kristi tún mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo Kristẹni láti sìn gẹ́gẹ́ bi òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo di òjíṣẹ́ èyí [àṣírí ọlọ́wọ̀] gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (Éfésù 3:4-7) Níwọ̀n bí a ti pè wọ́n sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí nípasẹ̀ ẹ̀bùn kan, wọn ò lè máa gbowó oṣù, àwọn tó jẹ́ òjíṣẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run ò lè retí pé kí a san ohun ìní ti ara fún àwọn nítorí pé àwọn ń sọ ìhìn ẹ̀bùn yìí fáwọn ẹlòmíràn.
Ǹjẹ́ Ìyè Àìnípẹ̀kun Jẹ́ Ọ̀ràn Ìmọtara-Ẹni-Nìkan?
Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ káwọn Kristẹni sin òun láìní fún wọn ní èrè kankan? Rárá o, nítorí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 6:10) Jèhófà kì í sì í ṣe aláìṣèdájọ́ òdodo. (Diutarónómì 32:4) Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, Jèhófà jẹ́ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Àmọ́, ṣé ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè kì í ṣe ọ̀ràn ìmọtara-ẹni-nìkan?—Lúùkù 23:43.
Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ìdí kan ni pé, Ọlọ́run ló fi wíwù tó wu àwọn èèyàn láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé sí wọn lọ́kàn. Òun ló sọ nípa ìfojúsọ́nà yìí fún àwọn tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15-17) Ó tún mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti padà ní ìrètí yìí nígbà tí Ádámù àti Éfà pàdánù rẹ̀ fún àwọn àtọmọdọ́mọ wọn. Ọlọ́run wá tipa bẹ́ẹ̀ ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Nítorí náà, ohun tó tọ́ tó sì yẹ gan-an ni pé káwọn Kristẹni òde òní máa “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà” bíi ti Mósè. (Hébérù 11:26) Kì í ṣe pé Ọlọ́run fẹ́ fi ẹ̀san yìí fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra. Ojúlówó ìfẹ́ tó ní fáwọn tó ń sìn ín ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Tẹsalóníkà 2:16, 17) Látàrí èyí, “àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.”—1 Jòhánù 4:19.
Ète Rere Tá A Fi Ń Sin Ọlọ́run
Gbogbo ìgbà làwọn Kristẹni òde òní gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò ète táwọn fi ń sin Ọlọ́run. A kà á nínú ìwé Jòhánù 6:10-13 pé, Jésù fi iṣẹ́ ìyanu bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún. Àwọn kan wá bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé Jésù nítorí àwọn ìdí kan tó jẹ́ ti ìmọtara-ẹni-nìkan. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ ń wá mi, kì í ṣe nítorí pé ẹ rí àwọn iṣẹ́ àmì, bí kò ṣe nítorí pé ẹ jẹ láti inú àwọn ìṣù búrẹ́dì náà, ẹ sì yó.” (Jòhánù 6:26) Bákan náà làwọn Kristẹni kan ṣe iṣẹ́ ìsìn fún Ọlọ́run ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn ìyẹn, àmọ́ tí “kì í ṣe pẹ̀lú ète mímọ́ gaara.” (Fílípì 1:17) Àwọn kan tí ò ‘fara mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera tó jẹ́ ti Jésù Kristi’ tiẹ̀ wá ọ̀nà láti jèrè ohun ti ara látinú bíbá àwọn Kristẹni kẹ́gbẹ́.—1 Tímótì 6:3-5.
Kristẹni kan tó jẹ́ pé ìdí tó fi ń sin Ọlọ́run lóde òní kò ju pé kóun ṣáà lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè lè máa sìn pẹ̀lú ète ìmọtara-ẹni-nìkan. Èyí sì lè mú kírú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣubú nípa tẹ̀mí ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Pípẹ́ tí ètò Sátánì pẹ́ ju bá a ṣe rò lọ lè mú kírú ẹni bẹ́ẹ̀ “ṣàárẹ̀,” kó máa ronú pé òpin náà kò tètè dé. (Gálátíà 6:9) Ó tiẹ̀ lè di ẹni tínú ń bí nítorí àwọn nǹkan ti ara tó ti fi du ara rẹ̀. Jésù rán wa létí pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹni tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ ni olórí ìdí tó fi ń sin Ọlọ́run kò ní ronú àtisìn ín fún àkókò kan pàtó. Á pinnu láti sin Jèhófà títí láé! (Míkà 4:5) Kò ní kábàámọ̀ ohunkóhun tó bá ti fi du ara rẹ̀ nítorí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run. (Hébérù 13:15, 16) Ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run ló máa sún un láti fi ohun tí Ọlọ́run fẹ́ sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀.—Mátíù 6:33.
Lónìí, àwọn olùjọsìn tòótọ́ tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ló ń ‘yọ̀ǹda ara wọn tinútinú’ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Sáàmù 110:3) Ǹjẹ́ o wà lára wọn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣàṣàrò lórí ohun tí Ọlọ́run nawọ́ rẹ̀ sí wa: ìyẹn ògidì ìmọ̀ òtítọ́; (Jòhánù 17:3) òmìnira kúrò lábẹ́ àjàgà àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké; (Jòhánù 8:32) ìrètí wíwà láàyè títí láé. (Ìṣípayá 21:3, 4) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run—lọ́fẹ̀ẹ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
Fífẹ́ láti ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí ni olórí ohun tó ń sún àwọn Kristẹni ṣe nǹkan lóde òní—kì í ṣe nítorí àtisọ ara wọn di ọlọ́rọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ìràpadà tí Ọlọ́run fúnni ló ń mú káwọn Kristẹni wàásù ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́