Àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí Tí Wọ́n Ní Ẹ̀tọ́ Gẹ́gẹ́ Bí Aráàlú Ní Ọ̀run
“Ní tiwa, ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́ bí aráàlú ń bẹ ní awọn ọ̀run.”—FILIPPI 3:20.
1. Ète àgbàyanu wo ni Jehofa ní níti àwọn ẹ̀dá ènìyàn kan?
ÀWỌN ẹnìkọ̀ọ̀kan tí a bí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà ní ọ̀run, àní lórí àwọn áńgẹ́lì pàápàá. (1 Korinti 6:2, 3; Ìṣípayá 20:6) Ẹ wo irú òtítọ́ àgbàyanu tí ìyẹn jẹ́! Síbẹ̀, Jehofa pète rẹ̀, ó sì ṣàṣeparí rẹ̀ nípasẹ̀ Jesu Kristi, Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo. Èéṣe tí Ẹlẹ́dàá wa fi ṣe irú nǹkan báyìí? Báwo sì ni ìmọ̀ nípa rẹ̀ ṣe yẹ kí ó nípa lórí Kristian lónìí? Ẹ jẹ́ kí á wo bí Bibeli ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
2. Ohun titun wo ni Johannu Oníbatisí kéde pé Jesu yóò ṣe, kí sì ni ohun titun yìí tan mọ́?
2 Nígbà tí Johannu Oníbatisí ń palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jesu, ó kéde pé Jesu yóò ṣe ohun titun. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “[Johannu] . . . a máa wàásù, wí pé: ‘Lẹ́yìn mi ẹni kan tí ó lókunlágbára jù mí lọ ń bọ̀; emi kò yẹ lati bẹ̀rẹ̀ tú awọn okùn sálúbàtà rẹ̀. Emi fi omi batisí yín, ṣugbọn oun yoo fi ẹ̀mí mímọ́ batisí yín.’” (Marku 1:7, 8) Ṣáájú àkókò yẹn, a kò tíì fi ẹ̀mí mímọ́ batisí ẹnikẹ́ni. Èyí jẹ́ ìṣètò titun kan tí ó ní ẹ̀mí mímọ́ nínú, ó sì ní ín ṣe pẹ̀lú ète tí Jehofa ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣípayá láti múra àwọn ẹ̀dá ènìyàn sílẹ̀ fún ìṣàkóso ti ọ̀run.
‘Àtúnbí’
3. Ohun titun wo nípa Ìjọba ọ̀run ni Jesu ṣàlàyé fún Nikodemu?
3 Nínú ìpàdé bòókẹ́lẹ́ pẹ̀lú Farisi kan tí ó yọrí ọlá, Jesu ṣí púpọ̀ síi payá nípa ète àtọ̀runwá yìí. Farisi náà, Nikodemu, tọ Jesu wá ní òru, Jesu sì sọ fún un pé: “Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, oun kò lè rí ìjọba Ọlọrun.” (Johannu 3:3) Nikodemu, ẹni tí ó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí Farisi ó ti níláti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, ti mọ ohun kan nípa òtítọ́ kíkàmàmà ti Ìjọba Ọlọrun. Ìwé Danieli sọtẹ́lẹ̀ pé Ìjọba náà ni a óò fi fún “ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn” àti fún “ènìyàn àwọn ènìyàn-mímọ́ ti Ọ̀gá Ògo.” (Danieli 7:13, 14, 27) Ìjọba náà níláti “fọ́ túútú kí ó sì pa” gbogbo àwọn ìjọba mìíràn run kí ó sì dúró títí láé. (Danieli 2:44) Ó ṣeé ṣe, kí Nikodemu rò pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí yóò ní ìmúṣẹ sára orílẹ̀-èdè Júù; ṣùgbọ́n Jesu sọ pé láti rí Ìjọba náà, a níláti tún ènìyàn bí. Kò yé Nikodemu, nítorí náà Jesu ń bá a lọ ní sísọ pé: “Láìjẹ́ pé a bí ẹnikẹ́ni lati inú omi ati ẹ̀mí oun kò lè wọ inú ìjọba Ọlọrun.”—Johannu 3:5.
4. Níti àwọn tí a bí láti inú ẹ̀mí mímọ́, báwo ni ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Jehofa yóò ṣe yípadà?
4 Johannu Oníbatisí ti sọ̀rọ̀ nípa batisí pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́. Nísinsìnyí, Jesu fi kún un pé ẹnì kan ni a níláti bí láti inú ẹ̀mí mímọ́ bí ó bá níláti wọ Ìjọba Ọlọrun. Nípasẹ̀ ìbí aláìlẹ́gbẹ́ yìí, àwọn ọkùnrin àti obìnrin aláìpé wọ inú ipò ìbátan tí ó jẹ́ àkànṣe gan-an pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun. Wọn di àwọn ọmọ tí ó sọ dọmọ rẹ̀. A kà pé: “Gbogbo awọn tí wọ́n gbà [Jesu], awọn ni oun fún ní ọlá-àṣẹ lati di ọmọ Ọlọrun, nitori pé wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ ninu orúkọ rẹ̀; a sì bí wọn, kì í ṣe lati inú ẹ̀jẹ̀ tabi lati inú ìfẹ́-inú ti ẹran-ara tabi lati inú ìfẹ́-inú ènìyàn bíkòṣe lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.”—Johannu 1:12, 13; Romu 8:15.
Àwọn Ọmọ Ọlọrun
5. Nígbà wo ni a kọ́kọ́ fi ẹ̀mí mímọ́ batisí àwọn olùṣòtítọ́ ọmọ-ẹ̀yìn, ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́ tí ó fara jọ èyí wo ni ó sì ṣẹlẹ̀ ní àkókò kan náà?
5 Nígbà tí Jesu bá Nikodemu sọ̀rọ̀, a ti fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jesu, a yàn án fún ipò ọba rẹ̀ ní ọjọ́-iwájú nínú Ìjọba Ọlọrun, Ọlọrun sì ti jẹ́wọ́ Jesu ní gbangba gẹ́gẹ́ bí Ọmọkùnrin Rẹ̀. (Matteu 3:16, 17) Jehofa bí àwọn ọmọ ẹ̀mí púpọ̀ síi ní Pentekosti 33 C.E. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn olùṣòtítọ́ tí wọ́n kórajọpọ̀ sí yàrá òkè ní Jerusalemu ni a fi ẹ̀mí mímọ́ batisí. Ní àkókò kan náà, a tún wọn bí láti inú ẹ̀mí mímọ́ láti di àwọn ọmọkùnrin ẹ̀mí Ọlọrun. (Ìṣe 2:2-4, 38; Romu 8:15) Síwájú síi, a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n pẹ̀lú ète ọjọ́-iwájú ti àjògún ní ọ̀rún, a sì fi èdídí dí wọn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìtọ́wò ìjótìítọ́ ìrètí náà ní ọ̀run.—2 Korinti 1:21, 22.
6. Kí ni ète Jehofa nípa Ìjọba ti ọ̀run, èésìtiṣe tí ó fi bá a mu pé kí ẹ̀dá ènìyàn ní ìpín nínú èyí?
6 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé àkọ́kọ́ tí Ọlọrun yàn láti wọ inú Ìjọba náà. Ìyẹn ni pé, lẹ́yìn ikú àti àjíǹde wọn, wọ́n níláti di apákan ètò-àjọ Ìjọba ọ̀rún tí yóò ṣàkóso lórí àwọn ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn áńgẹ́lì. Jehofa pète pé nípasẹ̀ Ìjọba yìí, orúkọ ńlá òun ni a óò sọ di mímọ́ tí a óò sì dá ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ láre níṣojú gbogbo ẹ̀dá. (Matteu 6:9, 10; Johannu 12:28) Ẹ wo bí ó ti bá a mu tó pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn nípìn-ín nínú Ìjọba yẹn! Satani lo ẹ̀dá ènìyàn nígbà tí ó ń gbé ìpèníjà rẹ̀ àkọ́kọ́ dìde sí ipò ọba-aláṣẹ Jehofa nígbà yẹn lọ́hùn-ún nínú ọgbà Edeni, nísinsìnyí Jehofa sì ti pète pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn ni a óò mú wọ inú dídáhùn ìpèníjà náà. (Genesisi 3:1-6; Johannu 8:44) Aposteli Peteru kọ̀wé sí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí a yàn láti ṣàkóso nínú Ìjọba yẹn pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, nitori ní ìbámu pẹlu àánú ńlá rẹ̀ ó fún wa ní ìbí titun kan sí ìrètí tí ó wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde Jesu Kristi kúrò ninu òkú, sí ogún kan tí ó jẹ́ aláìlèdíbàjẹ́ ati aláìlẹ́gbin ati aláìlèṣá. A fi í pamọ́ ní awọn ọ̀run de ẹ̀yin.”—1 Peteru 1:3, 4.
7. Ipò ìbátan aláìlẹ́gbẹ́ wo ni àwọn tí a fi ẹ̀mí mímọ́ batisí gbádùn pẹ̀lú Jesu?
7 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọrun sọ dọmọ, àwọn Kristian tí a yàn wọ̀nyí di arákùnrin fún Jesu Kristi. (Romu 8:16, 17; 9:4, 26; Heberu 2:11) Níwọ̀n bí Jesu ti fi ẹ̀rí hàn pé òun ni Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí fún Abrahamu, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́, tàbí onípò kejì, apákan Irú-Ọmọ yẹn, tí yóò fi ìbùkún dá àwọn aráyé tí ó gbàgbọ́ lọ́lá. (Genesisi 22:17, 18; Galatia 3:16, 26, 29) Ìbùkún wo? Àǹfààní ti dídi ẹni tí a rà padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí a sì mú bá Ọlọrun rẹ́ àti ti ṣíṣiṣẹ́sìn ín nísinsìnyí àti títí ayérayé. (Matteu 4:23; 20:28; Johannu 3:16, 36; 1 Johannu 2:1, 2) Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró tí wọ́n wà lórí ilẹ̀-ayé ń darí àwọn ọlọ́kàn-títọ́ sí ìbùkún yìí nípa jíjẹ́rìí nípa Jesu Kristi arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí àti nípa Jehofa Ọlọrun, Bàbá tí ó gbà wọ́n ṣọmọ.—Ìṣe 1:8; Heberu 13:15.
8. Kí ni “ṣíṣí” àwọn ọmọkùnrin Ọlọrun tí a fẹ̀mí bí “payá” jẹ́?
8 Bibeli sọ̀rọ̀ nípa “ṣíṣí” àwọn ọmọkùnrin Ọlọrun tí a fi ẹ̀mí bí yìí “payá.” (Romu 8:19) Ní wíwọnú Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ọba olùkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jesu, wọ́n nípìn-ín nínú pípa ayé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti Satani run. Lẹ́yìn náà, fún ẹgbẹ̀rún ọdún, wọ́n ṣèrànwọ́ láti darí àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà sí aráyé wọ́n sì tipa báyìí gbé ìran ẹ̀dá ènìyàn ga sí ìjẹ́pípé tí Adamu sọnù. (2 Tessalonika 1:8-10; Ìṣípayá 2:26, 27; 20:6; 22:1, 2) Ìṣípayá wọn ní gbogbo èyí nínú. Ó jẹ́ ohun tí ẹ̀dá ènìyàn tí ó gbàgbọ́ ń fi ìháragàgà dúró dè.
9. Báwo ni Bibeli ṣe tọ́ka sí ẹgbẹ́ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró kárí-ayé?
9 Ẹgbẹ́ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró kárí-ayé ni “ìjọ awọn àkọ́bí tí a ti kọrúkọ wọn sílẹ̀ ní awọn ọ̀run.” (Heberu 12:23) Àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó jàǹfààní láti inú ẹbọ ìràpadà Jesu. Àwọn náà ni “ara Kristi,” èyí tí ó fi ìbáṣepọ̀ wọn tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ara wọn àti pẹ̀lú Jesu hàn. (1 Korinti 12:27) Paulu kọ̀wé pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ara ti jẹ́ ọ̀kan ṣugbọn tí ó ní awọn ẹ̀yà-ara púpọ̀, tí gbogbo ẹ̀yà-ara tí ó jẹ́ ti ara yẹn, bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀, sì jẹ́ ara kanṣoṣo, bẹ́ẹ̀ naa ni Kristi. Nitori ní òótọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan ni a batisí gbogbo wa sínú ara kanṣoṣo, yálà Júù tabi Griki, yálà ẹrú tabi òmìnira, a sì mú gbogbo wa mu ẹ̀mí kan.”—1 Korinti 12:12, 13; Romu 12:5; Efesu 1:22, 23; 3:6.
“Israeli Ọlọrun”
10, 11. Ní ọ̀rúndún kìn-ínní, èéṣe tí a fi nílò Israeli titun, àwọn wo sì ni wọ́n parapọ̀ di orílẹ̀-èdè titun yìí?
10 Fún nǹkan tí ó ju 1,500 ọdún ṣáájú wíwá Jesu gẹ́gẹ́ bí Messia tí a ṣèlérí náà, orílẹ̀-èdè Israeli nípa ti ara jẹ́ àwọn ènìyàn àkànṣe fún Jehofa. Láìka ìránnilétí ìgbà gbogbo sí, orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ fi ẹ̀rí jíjẹ́ aláìṣòótọ́ hàn. Nígbà tí Jesu fara hàn, orílẹ̀-èdè náà kọ̀ ọ́. (Johannu 1:11) Nípa báyìí, Jesu sọ fún àwọn aṣáájú ìsìn Júù pé: “A óò gba ìjọba Ọlọrun kúrò lọ́wọ́ yín a óò sì fi fún orílẹ̀-èdè kan tí yoo máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Matteu 21:43) Mímọ “orílẹ̀-èdè” yẹn “tí yoo máa mú èso [Ìjọba náà] jáde” ṣe pàtàkì gidi fún ìgbàlà.
11 Orílẹ̀-èdè titun náà ni ìjọ Kristian tí a fòróró yàn, tí a bí ní Pentekosti 33 C.E. Àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ àkọ́kọ́ ni àwọn Júù ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí wọ́n tẹ́wọ́gbà á gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn ọ̀run. (Ìṣe 2:5, 32-36) Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà orílẹ̀-èdè titun Ọlọrun, kì í ṣe lórí ìpìlẹ̀ pé wọ́n wá láti ìran Júù, ṣùgbọ́n lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jesu. Nípa báyìí, Israeli titun ti Ọlọrun yìí jẹ́ ohun aláìlẹ́gbẹ́ kan—orílẹ̀-èdè tẹ̀mí. Nígbà tí èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn Júù kọ̀ láti gba Jesu, ìkésíni náà láti di apákan orílẹ̀-èdè titun náà ni a nawọ́ rẹ̀ sí àwọn ará Samaria àti lẹ́yìn náà sí àwọn Kèfèrí. Orílẹ̀-èdè titun náà ni a pè ní “Israeli Ọlọrun.”—Galatia 6:16.
12, 13. Báwo ni ó ṣe hàn kedere pé Israeli titun náà kì í ṣe ẹ̀yà ìsìn àwọn Júù?
12 Ní Israeli ìgbàanì, nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Júù di aláwọ̀ṣe, wọ́n níláti juwọ́sílẹ̀ fún Òfin Mose, àwọn ọkùnrin sì níláti fi àpẹẹrẹ èyí hàn nípa kíkọlà. (Eksodu 12:48, 49) Àwọn Kristian kan tí wọ́n jẹ́ Júù rò pé ohun kan náà níláti ṣẹlẹ̀ níti ọ̀ràn àwọn tí kì í ṣe Júù tí wọ́n jẹ́ ara Israeli Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, Jehofa ní ohun tí ó yàtọ̀ lọ́kàn. Ẹ̀mí mímọ́ darí aposteli Peteru sí ilé Korneliu Kèfèrí. Nígbà tí Korneliu àti ìdílé rẹ̀ dáhùnpadà sí ìwàásù Peteru, wọn gba ẹ̀mí mímọ́—àní ṣáájú kí wọ́n tó ṣèrìbọmi nínú omi pàápàá. Èyí fi hàn kedere pé Jehofa ti tẹ́wọ́gba àwọn Kèfèrí wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí mẹ́ḿbà Israeli Ọlọrun láì béèrè pé kí wọ́n juwọ́sílẹ̀ fún Òfin Mose.—Ìṣe 10:21-48.
13 Ó ṣòro gidigidi fún àwọn kan lára àwọn onígbàgbọ́ láti faramọ́ èyí, láìpẹ́ gbogbo ọ̀ràn náà ni àwọn aposteli àti àwọn alàgbà sì níláti jíròrò ní Jerusalemu. Ẹgbẹ́ náà tí ó ní ọlá-àṣẹ tẹ́tísílẹ̀ sí ìkéde ẹ̀rí tí ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe gbékánkán ṣiṣẹ́ lórí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ ṣùgbọ́n tí wọn kì í ṣe Júù. Ìwádìí Bibeli fi hàn pé èyí jẹ́ ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mí sí. (Isaiah 55:5; Amosi 9:11, 12) Wọ́n dórí ìpinnu kan tí ó tọ̀nà pé: Àwọn Kristian tí kì í ṣe Júù kò níláti juwọ́sílẹ̀ fún Òfin Mose. (Ìṣe 15:1, 6-29) Nípa báyìí, nítòótọ́ Israeli tẹ̀mí jẹ́ orílẹ̀-èdè titun kì í kàn ṣe ẹ̀yà ìsìn àwọn Júù.
14. Kí ni pípè tí Jakọbu pe ìjọ àwọn Kristian ní “awọn ẹ̀yà méjìlá tí a túká káàkiri” dọ́gbọ́n túmọ̀ sí?
14 Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, nígbà tí ó ń kọ̀wé sí àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ní ọ̀rúndún kìn-ínní, ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu kọ lẹ́tà rẹ̀ sí “awọn ẹ̀yà méjìlá tí ó túká káàkiri.” (Jakọbu 1:1; Ìṣípayá 7:3-8) Àmọ́ ṣáá o, àwọn aráàlú Israeli titun náà ni a kò yàn sí ẹ̀yà gidi pàtó kan. Kò sí ìpín sí ẹ̀yà 12 tí ó hàn gbangba nínú Israeli ti ẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní Israeli ti ara. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Jakọbu tí a mí sí fi hàn pé lójú Jehofa Israeli Ọlọrun ti dípò ẹ̀yà 12 ti Israeli àbínibí pátápátá. Bí ọmọ Israeli àbínibí kan bá di apákan orílẹ̀-èdè titun náà, ìran rẹ̀ nípa ti ara—àní bí ó bá tilẹ̀ wá láti ẹ̀ya Juda tàbí ti Lefi—kò ní ìjẹ́pàtàkì kankan mọ́.—Galatia 3:28; Filippi 3:5, 6.
Májẹ̀mú Titun
15, 16. (a) Ojú wo ni Jehofa fi ń wo àwọn tí kìí ṣe Júù tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà Israeli Ọlọrun? (b) Lórí ìpìlẹ̀ tí ó bófinmu wo ni a fi dá Israeli titun náà sílẹ̀?
15 Ní ojú Jehofa, àwọn mẹ́ḿbà orílẹ̀-èdè titun yìí tí wọn kì í ṣe ọmọ Israeli ti di Júù tẹ̀mí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́! Aposteli Paulu ṣàlàyé pé: “Oun kì í ṣe Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní òde ara, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe èyí tí ó wà ní òde lára ẹran-ara. Ṣugbọn oun jẹ́ Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní inú, ìkọlà rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn-àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí, kì í sì í ṣe nípasẹ̀ àkójọ òfin kan tí a kọsílẹ̀. Ìyìn ẹni yẹn kò wá lati ọ̀dọ̀ awọn ènìyàn, bíkòṣe lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.” (Romu 2:28, 29) Ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí dáhùnpadà sí ìkésíni náà láti jẹ́ apákan Israeli Ọlọrun, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ yìí sì mú àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ṣẹ. Fún àpẹẹrẹ, wòlíì Hosea kọ̀wé pé: “Èmi óò . . . ṣàánú fún ẹni tí kò ti rí àánú gbà; èmi óò sì wí fún àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi pé, Ìwọ ni ènìyàn mi; òun óò sì wí pé, Ìwọ ni Ọlọrun mi.”—Hosea 2:23; Romu 11:25, 26.
16 Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ Israeli nípa tẹ̀mí kò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin Mose, lórí ìpìlẹ̀ wo ni wọ́n fi jẹ́ apákan orílẹ̀-èdè titun náà? Jehofa dá májẹ̀mú titun kan pẹ̀lú orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí nípasẹ̀ Jesu. (Heberu 9:15) Nígbà tí Jesu pilẹ̀ṣẹ̀ Ìṣe-Ìrántí ikú rẹ̀, ní Nisan 14, 33 C.E., ó gbé búrẹ́dì àti wáìnì fún àwọn aposteli olùṣòtítọ́ 11 ó sì sọ pé wáìnì náà ń ṣàpẹẹrẹ “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú.” (Matteu 26:28; Jeremiah 31:31-34) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú àkọsílẹ̀ Luku, Jesu sọ pé ife wáìnì náà dúró fún “májẹ̀mú titun.” (Luku 22:20) Ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Jesu, nígbà tí a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde ní Pentekosti tí a sì bí Israeli Ọlọrun, Ìjọba náà ni a gbà kúrò lọ́wọ́ Israeli ti ara tí a sì fi fún orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, titun náà. Ní ipò Israeli ti ara, orílẹ̀-èdè titun yìí nísinsìnyí jẹ́ ìránṣẹ́ Jehofa, tí ó jẹ́ àpapọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀.—Isaiah 43:10, 11.
“Jerusalemu Titun”
17, 18. Àpèjúwe wo ni a fúnni nínú ìwé Ìṣípayá nípa ògo tí ń dúró de àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró?
17 Ẹ wo irú ògo tí ń dúró de àwọn wọnnì tí wọ́n ní àǹfààní láti nípìn-ín nínú ìpè ti ọ̀run! Ẹ sì tún wo bí ó ti gbádùn mọ́ni tó láti kọ́ nípa àwọn ohun àgbàyanu tí ń dúró dè wọ́n! Ìwé Ìṣípayá fún wa ní ìmọ́lẹ̀-fìrí amóríyá nípa ogún wọn ní ọ̀run. Fún àpẹẹrẹ, nínú Ìṣípayá 4:4, a kà pé: “Yíká ìtẹ́ [Jehofa] ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún wà, mo sì rí awọn alàgbà mẹ́rìnlélógún tí wọ́n wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun tí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọnyi, adé oníwúrà sì ń bẹ ní orí wọn.” Àwọn alàgbà 24 wọ̀nyí jẹ́ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró, tí a jí dìde tí wọ́n sì ń di ipò tí Jehofa ti ṣèlérí fún wọn mú ní ọ̀run nísinsìnyí. Adé àti ìtẹ́ wọn rán wa létí agbára ipò-ọba wọn. Ronú, bákan náà, nípa àǹfààní àgbàyanu ńláǹlà ti ṣíṣiṣẹ́sìn yíká ìtẹ́ Jehofa tí wọ́n ní!
18 Nínú Ìṣípayá 14:1, a tún rí ìmọ́lẹ̀-fìrí mìíràn nípa wọn: “Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa dúró lórí Òkè-Ńlá Sioni, ati pẹlu rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn.” Níhìn-ín a rí iye àwọn ẹni àmì òróró tí a fòtélé—144,000. Ipò-ìdúró wọn gẹ́gẹ́ bí aládé ni a fòyemọ̀ níti pé wọ́n dúró ti Jesu, “Ọ̀dọ́ Àgùtàn náà,” Ọba tí Jehofa gbé sórí ìtẹ́. Wọ́n sì wà ní Òkè-Ńlá Sioni ní ọ̀run. Òkè-Ńlá Sioni ti orí ilẹ-ayé ni ibi tí Jerusalemu wà, ìlú-ńlá aládé ní Israeli. Òkè-Ńlá Sioni ní ọ̀run dúró fún ipò Jesu àti ti àwọn àjùmọ̀jogún rẹ̀ tí a gbé ga, àwọn tí wọ́n parapọ̀ di Jerusalemu ti ọ̀run.—2 Kronika 5:2; Orin Dafidi 2:6.
19, 20. (a) Ètò-àjọ ti ọ̀run wo ni àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró yóò jẹ́ apákan rẹ̀? (b) Láàárín àkókò wo ni Jehofa yan àwọn wọnnì tí ẹ̀tọ́ aráàlú wọn yóò wà ní ọ̀run?
19 Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn ẹni-àmì-òróró nínú ogo wọn ní ọ̀run ni a sọ̀rọ̀ wọn bákan náà gẹ́gẹ́ bí “Jerusalemu Titun.” (Ìṣípayá 21:2) Jerusalemu ti orí ilẹ̀-ayé ni “ìlú-ńlá ti Ọba ńlá naa” ó sì tún jẹ́ ọgangan ibi ti tẹmpili wà. (Matteu 5:35) Jerusalemu Titun ní ọ̀run ni ètò-àjọ Ìjọba aládé nípasẹ̀ èyí tí Ọba-Aláṣẹ ńlá náà, Jehofa, àti Ọba rẹ̀ tí ó yàn sípò, Jesu, ti ń jọba nísinsìnyí tí a sì ti ń ṣe iṣẹ́-ìsìn àlùfáà bí ìbùkún dídọ́sọ̀ tí ń ṣàn láti orí ìtẹ́ Jehofa fún ìmúláradá aráyé. (Ìṣípayá 21:10, 11; 22:1-5) Nínú ìran mìíràn Johannu gbọ́ pé àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró olùṣòtítọ́, tí a jí dìde, ni a tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ‘ìyàwó Ọ̀dọ́ Àgùtàn.’ Ẹ wo àwòrán tí ó mọ́kàn yọ̀ tí èyí fi síni lọ́kàn nípa àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ tí wọn yóò gbádùn pẹ̀lú Jesu àti ìmúratán wọn láti juwọ́sílẹ̀ fún un! Ronúwòye ìdùnnú-ayọ̀ tí yóò wà ní ọ̀run nígbà tí a bá fún èyí tí ó gbẹ̀yìn nínú wọn ni èrè tirẹ̀ ní ọ̀run. Nísinsìnyí, nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa” lè wáyé! Ètò-àjọ aládé ní ọ̀run náà ni a óò ṣe ní àṣepé nígbà náà.—Ìṣípayá 19:6-8.
20 Bẹ́ẹ̀ni, ìbùkún àgbàyanu wà ní ìpamọ́ fún àwọn wọnnì tí aposteli Paulu sọ nípa wọn pé: “Ní tiwa, ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́ bí aráàlú ń bẹ ní awọn ọ̀run.” (Filippi 3:20) Fún èyí tí ó ti fẹ́rẹ̀ tó ẹgbàá ọdún, Jehofa ti ń yan àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí ó sì ń múra wọn sílẹ̀ fún ogún ti ọ̀run. Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tí ó wà, iṣẹ́ yíyàn yìí àti mímúra sílẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ dópin. Ṣùgbọ́n púpọ̀ síi ṣì wà, gẹ́gẹ́ bí a ti fi han Johannu nínú ìran rẹ̀ tí a kọsílẹ̀ nínú Ìṣípayá orí 7. Nítorí náà nísinsìnyí, ẹgbẹ́ àwùjọ Kristian mìíràn yẹ fún àfiyèsí wa, a óò sì gbé ẹgbẹ́ àwùjọ yìí yẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni ìṣiṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ẹ̀mí mímọ́ lórí àwọn wọnnì tí wọ́n ni ogún ti ọ̀run?
◻ Ipò ìbátan tímọ́tímọ́ wo ni àwọn ẹni-àmì-òróró ń gbádùn pẹ̀lú Jehofa? pẹ̀lú Jesu?
◻ Báwo ni a ṣe ṣàpèjúwe ìjọ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró nínú Bibeli?
◻ Lórí ìpìlẹ̀ tí ó bófinmu wo ni a fi dá Israeli Ọlọrun sílẹ̀?
◻ Àwọn àǹfààní wo ní ọ̀run ni ó ń dúró de àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Láàárín àkókò tí ó fẹ́rẹ̀ tó ẹgbàá ọdún, Jehofa yan àwọn tí yóò ṣàkóso nínú Ìjọba ti ọ̀run