ORÍ 9
Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere
AKÍKANJÚ oníwàásù ìhìn rere ni Jésù, ó sì fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó máa ń lọ bá àwọn èèyàn láti wàásù fún wọn, ó sì máa ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nínú ilé wọn àti láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí. (Mát. 9:35; 13:36; Lúùkù 8:1) Jésù bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ ní ìdákọ́ńkọ́, ó sì bá àwùjọ àwọn èèyàn tó lé lẹ́gbẹ̀rún sọ̀rọ̀. (Máàkù 4:10-13; 6:35-44; Jòh. 3:2-21) Ó máa ń lo àyè tó bá yọ láti fún àwọn èèyàn ní ìṣírí, ó sì máa ń sọ̀rọ̀ tó ń mú káwọn èèyàn nírètí. (Lúùkù 4:16-19) Kódà, tó bá fẹ́ sinmi tàbí tó fẹ́ jẹun, tí àwọn èèyàn sì dé, á pa gbogbo ẹ̀ tì kó lè wàásù fún wọn. (Máàkù 6:30-34; Jòh. 4:4-34) Tí a bá kà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù nínú Bíbélì, ǹjẹ́ kì í wù wá pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Ó dájú pé ó máa ń wù wá, bó ṣe wu àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.—Mát. 4:19, 20; Lúùkù 5:27, 28; Jòh. 1:43-45.
2 Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀nà tí àwa Kristẹni òde òní lè gbà máa wàásù ìhìn rere tí Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn.
À Ń WÀÁSÙ LÁTI ILÉ DÉ ILÉ
3 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láti ilé dé ilé lọ́nà tó wà létòlétò. Ọ̀pọ̀ ibi la ti ń wàásù lọ́nà yìí débi pé àwọn èèyàn ti mọ̀ wá mọ́ ọn. Àṣeyọrí tó ń múnú ẹni dùn yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa wàásù láti ilé dé ilé torí pé ó ti jẹ́ ká lè wàásù fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn láwọn ọdún díẹ̀. (Mát. 11:19; 24:14) Iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ti mú ká fi hàn pé òótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn tó wà ládùúgbò wa.—Mát. 22:34-40.
4 Kì í ṣe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní la bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ń kọ́ àwọn èèyàn nínú ilé wọn. Nígbà tó ń ṣàlàyé iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ fún àwọn alábòójútó ní ìlú Éfésù, ó ní: “Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo ti dé sí ìpínlẹ̀ Éṣíà, . . . mi ò . . . fà sẹ́yìn nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tó lérè fún yín tàbí nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” Lọ́nà yìí àti láwọn ọ̀nà míì, Pọ́ọ̀lù “jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.” (Ìṣe 20:18, 20, 21) Nígbà yẹn, àwọn olú ọba Róòmù gbé ìbọ̀rìṣà lárugẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn sì wà ń “bẹ̀rù àwọn ọlọ́run.” Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn èèyàn wá “Ọlọ́run tó dá ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀,” ìyẹn Ẹni tó “ń sọ fún gbogbo èèyàn níbi gbogbo pé kí wọ́n ronú pìwà dà.”—Ìṣe 17:22-31.
5 Lónìí, ó ti wá túbọ̀ ṣe pàtàkì pé kí ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. Òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí ti sún mọ́lé gan-an. Nígbà tọ́rọ̀ sì ti wá rí báyìí, ó yẹ ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ yìí. Títí di báyìí, ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà rí àwọn tí ebi òtítọ́ ń pa ni pé ká máa wá wọn láti ilé dé ilé, ọ̀nà yìí la sì ti rí pé ó dára jù lọ. Ìyẹn ló ń mú ká lè máa bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ bó ṣe rí láwọn ọjọ́ Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀.—Máàkù 13:10.
6 Ṣé ìwọ náà máa ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé dé ilé? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé inú Jèhófà dùn sí ẹ. (Ìsík. 9:11; Ìṣe 20:35) Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti wàásù láti ilé dé ilé. Ó lè jẹ́ nítorí ìṣòro ara, tàbí pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ fetí sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó o wà. Ó sì lè jẹ́ torí pé ìjọba fi òfin de iṣẹ́ ìwàásù. Ìwọ alára lè jẹ́ onítìjú èèyàn tó sì nira fún ẹ láti bá ẹni tí o kò mọ̀ rí sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìyẹn ni kì í jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀ nígbà tó o bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Ohun yòówù kó jẹ́, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. (Ẹ́kís. 4:10-12) Ohun tó ń ṣe ẹ́ yìí ń ṣe àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ láwọn ibòmíì.
7 Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó! Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Ìlérí yìí ń mú ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Àwa náà lè sọ bíi ti Pọ́ọ̀lù pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.” (Fílí. 4:13) Torí náà sa gbogbo ipá rẹ láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tí ìjọ ṣètò. Tó o bá ń bá àwọn míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, wàá máa rí ìṣírí àti ìrànlọ́wọ́ gbà. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè borí ìṣòro èyíkéyìí tó o bá ní, kó o sì máa fi gbogbo okun rẹ ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà.—1 Jòh. 5:14.
8 Bó o ṣe ń wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn, wàá jẹ́ kí wọ́n mọ ‘ìdí tó o fi ní ìrètí yìí.’ (1 Pét. 3:15) Á jẹ́ kó o túbọ̀ rí i pé àwọn tó ń retí Ìjọba Ọlọ́run yàtọ̀ gan-an sí àwọn tí kò ní ìrètí. (Àìsá. 65:13, 14) Ọkàn rẹ máa balẹ̀ pé ò ń pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ‘kí ìmọ́lẹ̀ rẹ máa tàn,’ á sì ṣeé ṣe fún ẹ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kí wọ́n sì mọ òtítọ́ táá jẹ́ kí wọ́n rí ìyè àìnípẹ̀kun.—Mát. 5:16; Jòh. 17:3; 1 Tím. 4:16.
9 A máa ń ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ní òpin ọ̀sẹ̀ àti ní àárín ọ̀sẹ̀. Ní àwọn ibi tó bá ti ṣòro láti bá àwọn èèyàn nílé ní àárọ̀ tàbí ọ̀sán, àwọn ìjọ kan máa ń ṣètò ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́. Ó lè túbọ̀ rọ àwọn èèyàn lọ́rùn láti gbàlejò ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ju àárọ̀ lọ.
BÁ A ṢE Ń WÁ ÀWỌN ẸNI YÍYẸ KÀN
10 Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun “wá ẹni yíyẹ kàn.” (Mát. 10:11) Kì í ṣe ìgbà tí Jésù bá ń wàásù láti ilé dé ilé nìkan ló máa ń wá àwọn tó lọ́kàn rere. Kódà, ó wàásù fáwọn èèyàn láwọn ìgbà tó yàtọ̀, yálà nígbà tó dìídì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tàbí nígbà tó ń ṣe nǹkan míì lọ́wọ́, àmọ́ tí àǹfààní àtiwàásù yọ. (Lúùkù 8:1; Jòh. 4:7-15) Àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú wàásù fún àwọn èèyàn láwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.—Ìṣe 17:17; 28:16, 23, 30, 31.
Àfojúsùn wa ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí fún àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan
11 Bó ṣe rí lóde òní náà nìyẹn, àfojúsùn wa ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí fún àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Èyí gba pé ká máa ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn bí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti ṣe é, ká máa fiyè sí bí nǹkan ṣe ń yí pa dà àti bí ipò àwọn èèyàn ṣe yàtọ̀ síra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. (1 Kọ́r. 7:31) Bí àpẹẹrẹ, àwọn akéde ń rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ láwọn àdúgbò táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ìjẹ́rìí òpópónà ti mú ká lè wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn, bákan náà ni ìwàásù láwọn ibi ìgbafẹ́, ibi ìgbọ́kọ̀sí àti láwọn ibòmíì táwọn èèyàn máa ń wà. Àwọn ìjọ kan ṣètò láti máa pàtẹ àwọn ìwé wa sórí tábìlì àti sórí àwọn ohun tó ṣeé tì kiri ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń ṣètò àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí, níbi táwọn èèyàn ti ń lọ tí wọ́n ń bọ̀, wọ́n sì máa ń yan àwọn akéde láti ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ náà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn tí kò sí nílé nígbà tí àwọn akéde wàásù dé ilé wọn á lè gbọ́ ìhìn rere náà níbòmíràn.
12 Tá a bá pàdé àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá à ń wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí, a lè fún wọn ní ìwé tó bá ipò wọn mu. Láti mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú, a lè fún wọn ní ìsọfúnni nípa bí wọ́n ṣe lè kàn sí wa, ká sì ṣètò láti pa dà bẹ̀ wọ́n wò. A lè darí wọn sorí ìkànnì jw.org tàbí ká sọ àdírẹ́sì ilé ìpàdé wa tó sún mọ́ ọ̀dọ̀ wọn. Wàá rí i pé iṣẹ́ ìwàásù níbi tí èrò pọ̀ sí máa ń gbádùn mọ́ni àti pé á jẹ́ kó o túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjiṣẹ́ rẹ.
13 Àmọ́, ìwàásù ìhìn rere nìkan kọ́ ni iṣẹ́ tá a yàn fún àwa Kristẹni lóde òní. Tó o bá fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ tó máa mú kí wọ́n rí ìyè àìnípẹ̀kun, ó gba pé kó o máa lọ sọ́dọ̀ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn.
BÁ A ṢE Ń ṢE ÌPADÀBẸ̀WÒ
14 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:8) Àmọ́, ó tún sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mát. 28:19, 20) Ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò máa ń mú kéèyàn láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kí inú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere nígbà tó o kọ́kọ́ wàásù fún wọn dùn nígbà tó o bá pa dà lọ sọ́dọ̀ wọn. Tó o bá bá wọn jíròrò síwájú sí i nínú Bíbélì, wàá lè mú kí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run lágbára, kí wọ́n sì fẹ́ láti sìn ín. (Mát. 5:3) Tó o bá múra sílẹ̀ dáadáa, tó o sì ṣètò láti pa dà bẹ̀ wọ́n wò lásìkò tó o máa bá wọn nílé, wàá lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni kó o máa rò ní gbogbo ìgbà tó o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ní máa gbin èso òtítọ́ nìkan, àmọ́ àá tún máa bomi rin ín.—1 Kọ́r. 3:6.
15 Ó lè ṣòro fún àwọn kan láti máa ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ó ṣeé ṣe kó o mọ béèyàn ṣe ń wàásù ìhìn rere dáadáa lọ́nà tó ṣe ṣókí, tó o sì máa ń gbádùn apá yìí nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ṣùgbọ́n tó bá di pé kó o pa dà lọ bá ẹni tó o wàásù fún kẹ́ ẹ lè jọ jíròrò Bíbélì sí i, ó lè dà bí òkè ìṣòro. Ìmúrasílẹ̀ máa jẹ́ kó o túbọ̀ nígboyà. Rí i pé ò ń lo àwọn àbá tí wọ́n ń fún wa nínú ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀. O lè ní kí akéde kan tó mọ bí a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ lé ẹ lọ.
BÓ O ṢE LÈ MÁA DARÍ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
16 Nígbà tí Fílípì tó jẹ́ ajíhìnrere ń bá Júù aláwọ̀ṣe kan tó ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ó bi í pé: “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ lóye ohun tí ò ń kà?” Ọkùnrin náà fèsì pé: “Báwo ni mo ṣe lè lóye, láìjẹ́ pé ẹnì kan tọ́ mi sọ́nà?” Ìwé Ìṣe orí 8 wá sọ pé látinú Ìwé Mímọ́ tí ọkùnrin yẹn ń kà ni Fílípì ti bẹ̀rẹ̀ sí í “kéde ìhìn rere nípa Jésù fún un.” (Ìṣe 8:26-36) A ò mọ bí Fílípì ṣe pẹ́ tó lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n àlàyé nípa ìhìn rere tó ṣe fún ọkùnrin náà yé e dáadáa débi tó fi gba Jésù gbọ́ tó sì sọ pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi. Ó sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi.
17 Ọ̀pọ̀ lónìí ni kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Bíbélì. Torí náà, ó lè gba pé ká ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn lọ́pọ̀ ìgbà ká sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa ní ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, ọ̀pọ̀ oṣù, ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kí wọ́n tó lè ní ìgbàgbọ́, kí wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, èrè wà nínú kéèyàn máa fi sùúrù àti ìfẹ́ ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn, torí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
18 Ó dájú pé wàá fẹ́ láti lo ọ̀kan lára àwọn ìwé tá a dìídì ṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tá à ń rí gbà nípàdé àárín ọ̀sẹ̀, tó o sì ń bá àwọn tó mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, wàá lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú, wàá sì lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi.
19 Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti bó o ṣe lè máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, sọ fún ọ̀kan lára àwọn alábòójútó tàbí akéde kan tó mọ bá a ṣe ń kọ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn àbá tó wà nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tá a sì ń ṣe àṣefihàn wọn nípàdé tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Gbára lé Jèhófà, kó o sì máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (1 Jòh. 3:22) Torí náà, ní in lọ́kàn pé wàá máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bó bá ṣeé ṣe ní àfikún sí ìkẹ́kọ̀ọ́ yòówù tó o bá ń ṣe pẹ̀lú ìdílé rẹ. Tó o bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá túbọ̀ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
BÁ A ṢE Ń DARÍ ÀWỌN OLÙFÌFẸ́HÀN SÍNÚ ÈTÒ JÈHÓFÀ
20 Tá a bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà Ọlọ́run tí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, àwọn náà á di ara ìjọ. Tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ti mọ ètò Jèhófà tí wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò náà, àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run á máa dára sí i, òtítọ́ á sì jinlẹ̀ nínú wọn. Ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. A dìídì ṣe ìwé Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? àtàwọn fídíò kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Díẹ̀ lára ohun tó wà ní Orí 4 nínú ìwé yìí tún máa ràn wọ́n lọ́wọ́.
21 Gbàrà tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò Bíbélì pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ni kó o ti jẹ́ kó mọ̀ pé ètò kan wà tí Jèhófà ń lò kí iṣẹ́ ìwàásù lè kárí ayé lónìí. Ṣàlàyé fún un bí àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe wúlò tó àti bí àwọn òjíṣẹ́ tí wọ́n ya ara wọ́n sí mímọ́ fún Ọlọ́run ṣe yọ̀ǹda ara wọn láti máa tẹ àwọn ìwé náà tí wọ́n sì ń pín wọn fún àwọn èèyàn kárí ayé. Sọ fún ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé kẹ́ ẹ jọ lọ sí àwọn ìpàdé tá à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe àwọn ìpàdé náà fún un, kó o sì fi àwọn ará hàn án. Tún ràn án lọ́wọ́ láti di ojúlùmọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. Láwọn àpéjọ yìí àti láwọn ibòmíì, jẹ́ kí ẹni tuntun náà fojú ara rẹ̀ rí bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ hàn, ìyẹn àmì tá a fi ń dá àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀. (Jòh. 13:35) Bí ẹni náà bá ṣe ń mọyì ètò Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ lá ṣe túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà.
BÍ A ṢE Ń LO ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
22 Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ń fi ìtara wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ṣe ẹ̀dà àwọn Ìwé Mímọ́ tí àwọn fúnra wọn ń kà, tí wọ́n sì tún ń lò nínú ìjọ. Wọ́n tún máa ń gba àwọn èèyàn níyànjú láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ẹ̀dà tí wọ́n fọwọ́ kọ náà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, wọ́n sì mọyì rẹ̀ gan-an. (Kól. 4:16; 2 Tím. 2:15; 3:14-17; 4:13; 1 Pét. 1:1) Lóde òní, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo àwọn ẹ̀rọ ìgbàlóde láti tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù Bíbélì àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lára wọn ni ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ńlá àti àwọn ìwé ìròyìn ní èdè ọgọ́rùn-ún mélòó kan.
23 Bó o ṣe ń wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn, máa rí i dájú pé ò ń lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ètò Jèhófà tẹ̀ jáde. Torí pé ìwọ fúnra rẹ ti jàǹfààní gan-an nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn á mú kó yá ẹ lára láti sọ ohun tó o kọ́ fáwọn èèyàn.—Héb. 13:15, 16.
24 Àwọn èèyàn tó ń gba ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Torí náà, yàtọ̀ sí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a tún ń lo ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn jw.org láti wàásù ìhìn rere fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn èèyàn káàkiri ayé lè lo kọ̀ǹpútà láti ka Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè tàbí kí wọ́n tẹ́tí sí àwọn ohùn tá a ti gbà sílẹ̀. Àwọn tí kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tàbí tí wọ́n ń gbé láwọn ibi tí wọn ò ti lè rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá sọ̀rọ̀ lè ṣèwádìí nípa ohun tá a gbà gbọ́ tí wọ́n bá lọ sórí ìkànnì jw.org nínú ilé wọn.
25 Torí náà, nígbàkigbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ, a máa ń sọ fún àwọn èèyàn nípa ìkànnì jw.org. Tí ẹnì kan tá a wàásù fún bá béèrè ohun tá a gbà gbọ́, a lè fi ìdáhùn hàn án lójú ẹsẹ̀ lórí fóònù alágbèéká tàbí lórí kọ̀ǹpútà. Tá a bá bá ẹnì kan tó ń sọ èdè míì pà dé, títí kan èdè àwọn adití, a lè sọ fún un pé kó wo ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì níbi tó ti máa rí Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè rẹ̀. Ọ̀pọ̀ akéde ti lo àwọn fídíò tó wà lórí ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
ÌJẸ́RÌÍ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ
26 Jésù sọ fún àwọn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. . . . Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.” (Mát. 5:14-16) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, tó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni torí pé ó mú kí “ìmọ́lẹ̀ ìyè” máa tàn fún gbogbo àwọn tó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Jòh. 8:12.
27 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa. (1 Kọ́r. 4:16; 11:1) Nígbà tó wà nílùú Áténì, ojoojúmọ́ ló ń wàásù nínú ọjà fún àwọn tó bá wà ní àrọ́wọ́tó. (Ìṣe 17:17) Àwọn Kristẹni tó wà nílùú Fílípì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ nínú ìwé tó kọ sí wọn pé wọ́n ń gbé “láàárín ìran onímàgòmágó àti oníwà ìbàjẹ́” àti pé wọ́n ń “tàn bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé.” (Fílí. 2:15) Lónìí, àwa pẹ̀lú lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tàn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa nígbàkigbà tí àǹfààní bá yọ láti wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn. Òótọ́ ni pé jíjẹ́ tá a jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin máa jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé a yàtọ̀ sí àwọn èèyàn ayé. Àmọ́, tá a bá wàásù ìhìn rere fún wọn, wọ́n á mọ ìdí tá a fi yàtọ̀.
28 Ọ̀pọ̀ lára àwa èèyàn Jèhófà máa ń wàásù ìhìn rere fún àwọn tá à ń bá pàdé lẹ́nu ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́, ìyẹn níbi iṣẹ́ wa, níléèwé, nínú ọkọ̀ èrò tàbí níbòmíràn. Tá a bá ń rìnrìn-àjò, a máa ń lo àǹfààní tó bá yọ láti wàásù fún àwọn tá a jọ ń rìnrìn àjò. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti máa wá ọ̀nà tá a lè gbà mú ọ̀rọ̀ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run wọnú ìjíròrò wa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ ká máa múra sílẹ̀ ká lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà tí àyè ẹ̀ bá yọ.
29 Ó máa yá wa lára láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a bá ń fi sọ́kàn pé ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ yin Ẹlẹ́dàá wa lógo tá a sì ń bọlá fún orúkọ rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àá lè ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà, kí àwọn náà lè sìn ín kí wọ́n sì rí ìyè torí pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. Àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ máa ń mú inú Jèhófà dùn, ó sì gbà pé òun là ń ṣiṣẹ́ sìn.—Héb. 12:28; Ìfi. 7:9, 10.
ÌPÍNLẸ̀ ÌWÀÁSÙ
30 Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé, títí dé àwọn ìlú àtàwọn àrọko. Ìdí nìyẹn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì fi máa ń yan ìpínlẹ̀ ìwàásù fún àwọn ìjọ àtàwọn ará tó ń sìn ní agbègbè àdádó. (1 Kọ́r. 14:40) Èyí bá ètò tí Ọlọ́run ní kí àwọn Kristẹni ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mu. (2 Kọ́r. 10:13; Gál. 2:9) Torí pé iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run túbọ̀ ń gbòòrò sí i láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan la máa gbé ṣe tí ìjọ kọ̀ọ̀kan bá ṣètò tó dáa nípa bí wọ́n á ṣe máa ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn.
31 Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ló máa ń bójú tó ìṣètò yìí. A lè ní kí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan máa pín ìpínlẹ̀ ìwàásù. Oríṣi ìpínlẹ̀ ìwàásù méjì ló wà, ti àwùjọ àti ti ara ẹni. Tí ìjọ ò bá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó pọ̀, a máa ń fún àwọn alábòójútó àwùjọ ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí àwọn akéde tó wà ní àwùjọ wọn á ti máa wàásù. Àmọ́ tí ìpínlẹ̀ ìwàásù tí ìjọ ní bá pọ̀, akéde kọ̀ọ̀kan lè gba ìpínlẹ̀ ìwàásù tirẹ̀.
32 Bí akéde kan bá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tirẹ̀, á ní ibi tó ti lè wàásù láwọn ìgbà tí ìjọ ò bá ṣètò ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí nígbà tí kò bá ṣeé ṣe fún un láti dara pọ̀ mọ́ àwùjọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn akéde kan gba ìpínlẹ̀ ìwàásù tó wà nítòsí ibiṣẹ́ wọn, wọ́n sì máa ń wàásù níbẹ̀ ní àkókò ìsinmi ọ̀sán tàbí lẹ́yìn tí iṣẹ́ bá parí. Àwọn ìdílé kan gba ìpínlẹ̀ ìwàásù sí àdúgbò tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì máa ń wàásù níbẹ̀ láwọn ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Tí akéde kan bá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ní ibi tó rọrùn fún un, ìyẹn á jẹ́ kó lè túbọ̀ lo ọ̀pọ̀ àkókò nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́, ìjọ lápapọ̀ tún lè wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tá a fún ẹnì kan. Tó o bá fẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tìrẹ, sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù.
33 Tá a bá fún alábòójútó àwùjọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí àwọn tó wà ní àwùjọ rẹ̀ á ti máa wàásù tàbí a fún akéde kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tirẹ̀, ó yẹ kí wọ́n sapá láti wàásù ní ilé kọ̀ọ̀kan tó wà níbẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n rí i dájú pé àwọn tẹ̀ lé àwọn òfin tó jẹ mọ́ ààbò lórí ìsọfúnni ara ẹni. Kí àwọn alábòójútó àwùjọ tàbí akéde tá a fún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù rí i pé àwọn parí rẹ̀ lóṣù mẹ́rin, ó pẹ́ tán. Tí wọ́n bá ti parí rẹ̀, kí wọ́n sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù. Alábòójútó àwùjọ tàbí akéde tá a fún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù lè máa ṣe ìpínlẹ̀ náà nìṣó tàbí kí wọ́n dá a pa dà fún ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù.
34 Bí gbogbo wa tá a wà nínú ìjọ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, àá lè wàásù dáadáa ní gbogbo ibi tí ìpínlẹ̀ ìjọ wa dé. Kò tún ní sí pé àwọn akéde míì tún lọ wàásù ní ibì kan náà tí àwọn akéde kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, torí pé ìyẹn lè múnú bí àwọn tá a lọ wàásù fún. Nípa bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a gba ti àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa rò, títí kan àwọn ará wa.
BÍ ÀWỌN ÌJỌ ṢE LÈ FỌWỌ́ SOWỌ́ PỌ̀ LÁTI WÀÁSÙ FÚN ÀWỌN ÈÈYÀN TÍ ÈDÈ WỌN YÀTỌ̀ SÍRA
35 Gbogbo èèyàn pátá ló yẹ kó mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀ àti Ìjọba Rẹ̀. (Ìfi. 14:6, 7) A fẹ́ ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́ láìka èdè tí wọ́n ń sọ sí, kí wọ́n máa pe orúkọ Jèhófà kí wọ́n lè rí ìgbàlà, kí wọ́n sì máa hùwà tó yẹ Kristẹni. (Róòmù 10:12, 13; Kól. 3:10, 11) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó máa ń wáyé tá a bá ń wàásù ìhìn rere láwọn ibi tí àwọn èèyàn ti ń sọ èdè tó yàtọ̀ síra? Kí la lè ṣe táá mú kí èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ní àǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní èdè tó yé wọn jù lọ?—Róòmù 10:14.
36 Èdè tí wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan la fi máa ń pinnu ìjọ tó máa ṣe ìpínlẹ̀ ìwàásù náà. Torí náà, àwọn akéde láti ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè wàásù ní àdúgbò kan náà tó bá jẹ́ pé èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń sọ ládùúgbò náà. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó dára jù ni pé kí àwọn akéde ìjọ kọ̀ọ̀kan gbájú mọ́ bí wọ́n á ṣe wàásù fún àwọn èèyàn lédè wọn. Ohun kan náà lẹ máa ṣe nígbà tẹ́ ẹ bá ń pín àwọn ìwé ìkésíni lọ́dọọdún. Àmọ́, tí àwọn akéde bá ń wàásù níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí àti láìjẹ́ bí àṣà, wọ́n lè bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì fún wọn ní ìwé ní èdè èyíkéyìí.
37 Nígbà míì ó lè ṣòro fún àwọn ìjọ tó ń sọ èdè míì láti máa ṣiṣẹ́ déédéé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn tó jìnnà gan-an. Kí àwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ìjọ tó ń ṣe àwọn ìpínlẹ̀ náà jọ jíròrò láti mọ bí wọ́n á ṣe jọ máa kárí àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù náà déédéé. Èyí á jẹ́ kí àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, kò sì ní sí pé àwọn ará tún lọ wàásù níbi tí àwọn ará ìjọ míì ṣẹ̀ṣẹ̀ wàásù dé.—Òwe 15:22.
38 Kí ló yẹ ká ṣe tí ẹni tó dá wa lóhùn lẹ́nu ọ̀nà bá ń sọ èdè míì? Kò yẹ ká rò pé àwọn akéde tó ń sọ èdè rẹ̀ máa wá bá a sọ̀rọ̀. Àwọn akéde kan ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè wàásù ní ṣókí ní èdè tí àwọn kan ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. A lè ṣàlàyé fún ẹnì kan nípa bó ṣe lè ka ìwé wa tàbí bó ṣe lè wà á jáde lórí ìkànnì jw.org. A sì lè sọ fún un pé a máa mú ìwé wá fún un ní èdè rẹ̀.
39 Tí onítọ̀hún bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóòótọ́, ká sapá láti wá ẹni tó lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ lédè rẹ̀. A tún lè júwe ibi tí kò jìnnà sí i tá a ti ń ṣèpàdé lédè rẹ̀. Tó bá fẹ́ kí ẹnì kan tó gbọ́ èdè rẹ̀ kàn sí i, a lè kọ́ ọ bó ṣe máa kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà lórí ìkànnì jw.org. Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa wá sọ fún àwọn tí kò jìnnà sí onítọ̀hùn láti lọ bá a, ó lè jẹ́ ìjọ, àwùjọ tàbí akéde tó lè túbọ̀ ran onítọ̀hún lọ́wọ́.
40 A ó máa lọ sọ́dọ̀ ẹni náà títí tó fi máa sọ fún wa pé ẹni tó gbọ́ èdè òun ti wá bá òun. Nígbà míì, ẹ̀ka ọ́fíìsì á sọ fún àwọn alàgbà pé wọn ò rí ẹni tó gbọ́ èdè onítọ̀hún. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa kọ́ onítọ̀hún lẹ́kọ̀ọ́. Tó bá ṣeé ṣe, a lè máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká máa lo ìwé tá a ṣe ní èdè rẹ̀. Tá a bá ń fi àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀ ṣàlàyé ẹ̀kọ́ náà, tá a sì ń ní kó ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, onítọ̀hún á ní òye díẹ̀ nípa Bíbélì. Tí ọ̀kan lára àwọn ará ilé rẹ̀ bá gbọ́ èdè wọn tó sì gbọ́ èdè yín, ó lè máa bá yín túmọ̀ ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ.
41 Kí ẹni tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà lè dara pọ̀ mọ́ ètò Ọlọ́run, ẹ pè é wá sí àwọn ìpàdé wa, tí kò bá tiẹ̀ lóye gbogbo ohun tá à ń sọ níbẹ̀. Nígbà tá a bá ń ka ẹsẹ Bíbélì, ká bá ẹni náà ṣí i nínú Bíbélì èdè rẹ̀, tó bá wà. Tó bá ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn míì nínú ìjọ, á mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, á sì jẹ́ kó túbọ̀ tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run.
42 Àwọn Tó Fẹ́ Di Àwùjọ: Àwọn tó fẹ́ di àwùjọ máa ń ní àwọn akéde tó ń wàásù ní èdè tó yàtọ̀ sí èdè tí ìjọ fi ń ṣèpàdé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó kúnjú ìwọ̀n tó lè máa darí ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lédè yẹn. Ẹ̀ka ọ́fíìsì lè fọwọ́ sí ìjọ kan gẹ́gẹ́ bí ìjọ tó ń bójú tó àwọn tó fẹ́ di àwùjọ bí wọ́n bá dójú ìlà àwọn ohun tí a béèrè yìí:
(1) Àwọn èèyàn tó pọ̀ díẹ̀ ní agbègbè yẹn ń sọ èdè tí kì í ṣe ti ìjọ.
(2) Ó kéré tán, àwọn akéde mélòó kan gbọ́ èdè yẹn tàbí wọ́n múra tán láti kọ́ èdè yẹn.
(3) Ìgbìmọ̀ alàgbà ṣe tán láti múpò iwájú nínú ṣíṣètò iṣẹ́ ìwàásù lédè yẹn.
Bí ó bá wu ìgbìmọ̀ alàgbà láti bójú tó àwọn tó fẹ́ di àwùjọ, kí wọ́n kàn sí alábòójútó àyíká. Alábòójútó àyíká lè mọ àwọn ìjọ míì tó ń gbìyànjú láti wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè yẹn, ó sì lè pèsè ìsọfúnni tó wúlò tó máa jẹ́ kí a lè pinnu ìjọ tó máa dáa jù lọ láti bójú tó àwọn tó fẹ́ di àwùjọ. Gbàrà tí a bá ti pinnu ìjọ yẹn, kí àwọn alàgbà fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì kí wọ́n lè fọwọ́ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìjọ tó ń bójú tó àwọn tó fẹ́ di àwùjọ.
43 Àwọn Àwùjọ: Ẹ̀ka ọ́fíìsì lè fọwọ́ sí ìjọ kan gẹ́gẹ́ bí ìjọ tó ń bójú tó àwùjọ tó ń sọ èdè míì bí wọ́n bá dójú ìlà àwọn ohun tí a béèrè yìí:
(1) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lédè yẹn pọ̀ tó, ẹ̀rí sì wà pé àwọn tó wà nínú àwùjọ náà á máa pọ̀ sí i.
(2) Àwọn akéde bíi mélòó kan wà tó gbọ́ èdè yẹn tàbí tí wọ́n ń kọ́ èdè yẹn.
(3) Alàgbà kan tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó kúnjú ìwọ̀n wà tí yóò máa múpò iwájú tí yóò sì máa darí, ó kéré tán ìpàdé kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀—tàbí apá kan lára ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, irú bí àsọyé fún gbogbo èèyàn tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́—lédè yẹn.
Nígbà tí wọ́n bá dójú ìlà àwọn ohun tí a béèrè yìí débi tó lápẹẹrẹ, kí ìgbìmọ̀ alàgbà fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé kí wọ́n fọwọ́ sí ìjọ wọn gẹ́gẹ́ bí ìjọ tó ń bójú tó àwùjọ, kí ìwé náà sì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nínú. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń múpò iwájú ni a ó kà sí “alábòójútó àwùjọ” tàbí “ìránṣẹ́ àwùjọ.”
44 Tí a bá ti fọwọ́ sí àwùjọ náà, ìgbìmọ̀ alàgbà ìjọ tó ń ṣe àbójútó máa pinnu bóyá kí wọ́n fi apá míì nínú àwọn ìpàdé ìjọ kún ìpàdé tí wọ́n ń ṣe àti iye ìgbà tí wọ́n á máa ṣe é láàárín oṣù. Wọ́n tún lè ṣètò ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá fún àwùjọ náà. Gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ náà á máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tó ń bójú tó àwùjọ náà. Àwọn alàgbà á máa fún wọn ní ìtọ́ni táá jẹ́ kí wọ́n máa tẹ̀ síwájú, wọ́n á sì máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwùjọ náà. Tí alábòójútó àyíká bá ṣèbẹ̀wò sí ìjọ tó ń bójú tó àwùjọ náà, á bá àwọn ará tó wà ní àwùjọ náà ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀ yẹn, á sì kọ ìròyìn ṣókí sí ẹ̀ka ọ́fíísì nípa bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú sí àti ohun tí wọ́n nílò. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe kí àwùjọ náà di ìjọ. Tí gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni ètò Ọlọ́run, wọ́n á rí ojúure Jèhófà.—1 Kọ́r. 1:10; 3:5, 6.
ÌJẸ́RÌÍ ÀJẸ́PỌ̀
45 Ojúṣe àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ni láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe é, àmọ́ ọ̀pọ̀ wa la mọyì bá a ṣe ń bá àwọn míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. (Lúùkù 10:1) Torí náà, àwọn ìjọ máa ń pàdé pọ̀ láti lọ wàásù láwọn òpin ọ̀sẹ̀ àti láàárín ọ̀sẹ̀. Àsìkò ọlidé tún máa ń fún wa láǹfààní láti lọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ nítorí pé ọ̀pọ̀ ará ni kì í lọ síbi iṣẹ́ lásìkò yẹn. Kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ṣètò ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá láwọn àkókò tó rọrùn àti níbi tó rọrùn, lọ́wọ́ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́.
46 Ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ máa ń mú kí àwọn akéde jọ ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì ‘jọ fún ara wọn ní ìṣírí.’ (Róòmù 1:12) Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde máa ń bá àwọn ọ̀jáfáfá akéde tí wọ́n nírìírí ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́. Láwọn àdúgbò kan, ó máa ń dáa kí akéde méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣiṣẹ́ pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù torí ọ̀rọ̀ ààbò. Ká tiẹ̀ ló o fẹ́ dá ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù náà, á dára kó o wá sí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá torí pé ìyẹn máa fún gbogbo yín níṣìírí. Bó o ṣe mọ̀ pé àwọn ará wà nítòsí, tí gbogbo yín sì ń wàásù lágbègbè kan náà máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. Kò pọn dandan kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn míì wà ní gbogbo ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá tí ìjọ ṣètò, pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ pé ojoojúmọ́ nirú ìpàdé bẹ́ẹ̀ ń wáyé. Àmọ́, á ṣeé ṣe fún wọn láti wà ní àwọn kan lára ìpàdé náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
47 Torí náà, kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀! Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa bù kún ìsapá wa bá a ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ pàtàkì yìí, ìyẹn wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Lúùkù 9:57-62.