Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn” Kẹ́ Ẹ Lè Fògo fún Jèhófà
“Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè . . . fi ògo fún Baba yín.”—MÁT. 5:16.
1. Kí ló ń múnú àwa èèyàn Ọlọ́run dùn?
INÚ wa ń dùn bá a ṣe ń rí i tí iye àwa èèyàn Jèhófà túbọ̀ ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé ìmọ́lẹ̀ wa ń tàn kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún tó kọjá, ohun tó jú mílíọ̀nù mẹ́wàá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la darí. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe. Gbogbo àwọn tó wá ló kẹ́kọ̀ọ́ pé ìfẹ́ ló mú kí Ọlọ́run pèsè ìràpadà náà.—1 Jòh. 4:9.
2, 3. (a) Kí ni kò dí wa lọ́wọ́ láti máa “tàn bí atànmọ́lẹ̀”? (b) Bí Jésù ṣe sọ nínú Mátíù 5:14-16, kí la máa jíròrò?
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwa èèyàn Jèhófà ń sọ kárí ayé, síbẹ̀ a wà níṣọ̀kan, a sì jùmọ̀ ń yin Jèhófà Baba wa ọ̀run. (Ìṣí. 7:9) Èdè yòówù ká máa sọ tàbí ibi yòówù ká máa gbé, a lè máa “tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé.”—Fílí. 2:15.
3 Bá a ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tá a wà níṣọ̀kan, tá a sì ń wà lójúfò nípa tẹ̀mí ń fògo fún Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn láwọn ọ̀nà mẹ́ta yìí.—Ka Mátíù 5:14-16.
Ẹ RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ WÁ SIN JÈHÓFÀ
4, 5. (a) Yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìwàásù, báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn? (b) Tá a bá ń fọ̀yàyà kí àwọn èèyàn, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
4 Àpilẹ̀kọ náà, “Ìmọ́lẹ̀ nínú Òkùnkùn” tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 1925 sọ pé: “Kò sí bí èèyàn ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ sí Olúwa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí . . . àyàfi tó bá ń lo àwọn àǹfààní tó ní láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn.” Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Ó gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ nípa wíwàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn, kó sì tún máa ṣe ohun tó bá ọ̀nà ìmọ́lẹ̀ náà mu.” Ó dájú pé ọ̀nà kan tá a lè gbà jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn ni pé ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Yàtọ̀ síyẹn, a tún lè fi ìwà wa yin Jèhófà torí pé àwọn tá à ń wàásù fún àtàwọn tó ń rí wa ń kíyè sí ìwà wa. Bá a ṣe ń rẹ́rìn-ín sí wọn, tá a sì ń fọ̀yàyà kí wọn máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ púpọ̀ nípa wa àti Ọlọ́run tá à ń sìn.
5 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá ń wọ ilé, ẹ kí agbo ilé náà.” (Mát. 10:12) Àwọn èèyàn lágbègbè tí Jésù ti wàásù sábà máa ń gba àwọn àjèjì sílé wọn. Àmọ́, torí bí nǹkan ṣe rí lónìí, àwọn èèyàn kì í fẹ́ gba àjèjì sílé mọ́. Síbẹ̀, tá a bá fọ̀yàyà kí àwọn tá a fẹ́ wàásù fún, tá a ṣe bí ọ̀rẹ́ sí wọn, tá a sì fohùn tútù ṣàlàyé ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ wọn, ọkàn wọn á balẹ̀, ara á sì tù wọ́n. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀rín músẹ́ nìkan ti tó láti fa àwọn èèyàn mọ́ra. Àwọn tó ń wàásù níbi térò pọ̀ sí ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Tó o bá ń wàásù níbi térò pọ̀ sí, wàá kíyè sí i pé ó máa ń yá àwọn èèyàn lára láti mú àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a bá rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn, tá a sì fọ̀yàyà kí wọn. A ò ní gbàgbé pé ìwà ọmọlúwàbí wa lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti wàásù.
6. Kí ni tọkọtaya àgbàlagbà kan ṣe kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
6 Àìlera ò jẹ́ kí tọkọtaya àgbàlagbà kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lè wàásù láti ilé dé ilé. Wọ́n wá pinnu pé àwọn lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láìka àìlera àwọn sí. Ilé ìwé kan wà nítòsí ilé wọn, wọ́n wá gbé tábìlì kan sí ìta, wọ́n sì kó àwọn ìtẹ̀jáde sórí ẹ̀ kí àwọn òbí tó fẹ́ wá mú àwọn ọmọ wọn nílé ìwé lè rí i. Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ló mú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní àti Apá Kejì àtàwọn ìtẹ̀jáde míì. Nígbà tó yá, arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan níjọ wọn wá dara pọ̀ mọ́ wọn. Àwọn òbí náà kíyè sí i pé arábìnrin náà lọ́yàyà àti pé tọkọtaya àgbàlagbà yẹn nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Èyí mú kí ọ̀kan lára àwọn òbí náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
7. Báwo ló ṣe lè ran àwọn tó ṣí wá sí àdúgbò yín lọ́wọ́?
7 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ló ti ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì torí pé wọ́n ń wá ibi ìsádi. Báwo la ṣe lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà, kí wọ́n sì mọ ohun tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú? Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè lo ètò ìṣiṣẹ́ JW Language láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń kí àwọn èèyàn lédè wọn. Yàtọ̀ síyẹn, o lè kọ́ díẹ̀ nínú èdè wọn kó o lè sọ ohun táá fà wọ́n lọ́kàn mọ́ra. O lè tipa bẹ́ẹ̀ darí wọn lọ sí ìkànnì jw.org, kí wọ́n lè wo àwọn fídíò àtàwọn ìtẹ̀jáde tó wà lédè wọn.—Diu. 10:19.
8, 9. (a) Kí là ń kọ́ láwọn ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀? (b) Báwo làwọn obí ṣe lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ àwọn ọmọ wọn máa tàn?
8 Ká lè túbọ̀ já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, Jèhófà ti ṣètò Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ fún wa. Àwọn nǹkan tá à ń kọ́ nípàdé yìí máa ń jẹ́ ká túbọ̀ nígboyà láti ṣe ìpadàbẹ̀wò ká sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
9 Táwọn ẹni tuntun bá wá sípàdé wa, wọ́n sábà máa ń kíyè sí bí àwọn ọmọ wa ṣe máa ń dáhùn nípàdé. Ẹ̀yin òbí, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa dáhùn lọ́rọ̀ ara wọn, ìyẹn á jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látàrí ìdáhùn àtọkànwá tí wọ́n gbọ́ lẹ́nu àwọn ọmọ wa.—1 Kọ́r. 14:25.
ṢE IPA TÌRẸ KÍ ÌJỌ LÈ WÀ NÍṢỌ̀KAN
10. Báwo ni ìjọsìn ìdílé ṣe ń mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan?
10 Ọ̀nà míì tá a lè gbà mú kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn ni pé, ká máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ìdílé wà níṣọ̀kan, ká sì jẹ́ kí àlááfíà gbilẹ̀ nínú ìjọ. Ọ̀nà kan táwọn òbí lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé. Àwọn ìdílé kan máa ń wo Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW nígbà ìjọsìn ìdílé wọn. Ẹ̀yin náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá wò ó tán, ẹ jíròrò àwọn ohun tẹ́ ẹ gbádùn nínú ètò náà. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé, ẹ fi sọ́kàn pé ẹ̀kọ́ tó máa ṣàǹfààní fún ọmọdé lè yàtọ̀ sí èyí tó máa ṣàǹfààní fún ọ̀dọ́. Torí náà, ẹ ṣètò rẹ̀ lọ́nà tí ẹnì kọ̀ọ̀kàn tó wà nínú ìdílé máa rí ẹ̀kọ́ kọ́.—Sm. 148:12, 13.
11-13. Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè ṣe ipa tìrẹ kí ìjọ lè túbọ̀ wà níṣọ̀kan?
11 Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú kí ìjọ túbọ̀ wà níṣọ̀kan? Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, oò ṣe sún mọ́ àwọn àgbàlagbà, wọ́n ní ọmọdé tó bá mọ ọwọ́ wẹ̀ á bá àgbà jẹun. O lè ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fún ẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìrírí wọn máa fún ẹ lókun, àwọn náà á sì jàǹfààní lára ẹ. Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa kí àwọn ẹni tuntun tó bá wá sípàdé káàbọ̀, èyí lè mú kí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó máa dáa ká máa kí àwọn ẹni tuntun tẹ̀rín-tọ̀yàyà, ká mú wọn lọ kí àwọn ará, ká sì fi ibi tí wọ́n máa jókòó hàn wọ́n. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kára tù wọ́n.
12 Tó o bá darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ó lè ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó rọrùn fún wọn lo pín wọn sí? Láwọn ìgbà míì, á dáa kó o pín àwọn ọ̀dọ́ mọ́ wọn kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lóde ẹ̀rí. Bákan náà, ó yẹ kó o fi ìgbatẹnirò hàn sí àwọn aláìlera àtàwọn tí ipò wọn ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kí tèwetàgbà máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Léf. 19:32.
13 Onísáàmù náà sọ pé: “Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” (Ka Sáàmù 133:1, 2.) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe wà níṣọ̀kan mú kí wọ́n lè máa gbé ara wọn ró, kí wọ́n sì máa sin Jèhófà pa pọ̀. Ńṣe ni ìṣọ̀kan yẹn dà bí òróró olóòórùn dídùn tó ń mára tuni. Torí náà, pinnu pé wàá máa gbé àwọn míì ró, wàá sì máa ṣe ipa tìrẹ kí ìṣọ̀kan lè gbilẹ̀ láàárín àwọn ará. A gbóríyìn fún ẹ tó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ǹjẹ́ o lè “gbòòrò síwájú,” ìyẹn ni pé, kó o túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará ìjọ yín?—2 Kọ́r. 6:11-13.
14. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ máa tàn ládùúgbò rẹ?
14 Ǹjẹ́ o lè fi kún ìsapá rẹ ládùúgbò tó ò ń gbé kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ lè túbọ̀ máa tàn? Táwọn aládùúgbò wa bá kíyè sí i pé a kì í sọ̀rọ̀kọ́rọ̀, a sì máa ń hùwà ọmọlúàbí, ìyẹn lè mú kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí náà, bi ara rẹ pé: ‘Ojú wo làwọn ará àdúgbò fi ń wò mí? Ṣé mo máa ń ran àwọn aládùúgbò mi lọ́wọ́? Ṣé ilé mi máa ń wà ní mímọ́ tónítóní, ṣé mo sì máa ń tún àyíká mi ṣe?’ Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àdúgbò wa máa túbọ̀ wà ní mímọ́. Tíwọ àtàwọn ará míì bá ń sọ̀rọ̀, o lè béèrè nípa bí ìwà àti ìṣe wọn ṣe mú kí àwọn míì nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ irú bí àwọn mọ̀lẹ́bí, aládùúgbò, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ọmọléèwé wọn. Ó ṣeé ṣe kó o gbọ́ àwọn ìrírí tó máa fún ẹ lókun.—Éfé. 5:9.
Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká wà lójúfò?
15 Tá a bá fẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa túbọ̀ máa tàn, a gbọ́dọ̀ máa fi àkókò tá à ń gbé yìí sọ́kàn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Mát. 24:42; 25:13; 26:41) Tá a bá ń ronú pé ó máa pẹ́ kí “ìpọ́njú ńlá” tó dé, tàbí pé kì í ṣe ìgbà tiwa yìí ló máa ṣẹlẹ̀, a lè má wà lójúfò mọ́, kí ìtara tá a fi ń wàásù sì dín kù. (Mát. 24:21) Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, dípò ká máa tàn yanran lágbègbè tá à ń gbé, ìmọ́lẹ̀ wa máa bẹ̀rẹ̀ sí í kú díẹ̀díẹ̀, ó sì lè kú pátápátá.
16, 17. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè wà lójúfò?
16 Ó yẹ ká túbọ̀ wà lójúfò pàápàá láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí torí pé nǹkan túbọ̀ ń burú sí i. Ọkàn wa balẹ̀ pé àkókó tí Jèhófà ti pinnu ló máa gbé ìgbésẹ̀. (Mát. 24:42-44) Àmọ́, bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ náà, ẹ jẹ́ ká ní sùúrù, ká sì túbọ̀ wà lójúfò. Ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa gbàdúrà láìdabọ̀. (1 Pét. 4:7) A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti ń ṣọ́nà fún ọ̀pọ̀ ọdún, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn máa tàn bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ sin Jèhófà. Àpẹẹrẹ kan ni ìrírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2012, ojú ìwé 18 sí 21, àkòrí rẹ̀ ni, “Àádọ́rin Ọdún Rèé Tí Mo Ti Ń Di Ibi Gbígbárìyẹ̀ Lára Aṣọ Ẹni Tí Í Ṣe Júù Mú.”
17 Tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tá a sì ń bá àwọn ará kẹ́gbẹ́, àá túbọ̀ máa láyọ̀, a ò tiẹ̀ ní mọ̀gbà tí àkókò máa lọ. (Éfé. 5:16) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ àṣeyọrí làwọn ará wa ṣe torí pé ọwọ́ wọn dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ ní báyìí, a túbọ̀ ń rí ọwọ́ Jèhófà lára wa, àṣeyọrí tá a sì ń ṣe lónìí ju tiwọn lọ fíìfíì. Ká sòótọ́, ìmọ́lẹ̀ wa túbọ̀ ń tàn sí i, kódà ó ti mọ́lẹ̀ kọjá bá a ṣe rò.
18, 19. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò, kí ìtara wa má sì jó rẹ̀yìn? Sọ àpẹẹrẹ kan.
18 Inú wa dùn pé Jèhófà ò pa wá tì bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, a sì máa ń ṣàṣìṣe. Bákan náà, ó fún wa láwọn alàgbà tí Bíbélì pè ní “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn.” (Ka Éfésù 4:8, 11, 12.) Torí náà, nígbàkigbà táwọn alàgbà bá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ, mọyì wọn kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọgbọ́n àti ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹ.
19 Bí àpẹẹrẹ, àwọn tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè England ní ìṣòro nínú ìdílé wọn, wọ́n sì ní kí àwọn alàgbà ran àwọn lọ́wọ́. Àwọn alàgbà méjì wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. Ìyàwó sọ pé ọkọ òun kì í múpò iwájú tó bá kan ìjọsìn Jèhófà. Ọkọ rẹ̀ gbà pé òun ò mọ bí wọ́n ṣe ń kọ́ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, òun ò sì ṣètò ìjọsìn ìdílé déédéé. Àwọn alàgbà náà wá jẹ́ kí ọkọ yẹn rí bó ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Wọ́n sì rọ ìyàwó náà pé kó túbọ̀ mú sùúrù fún ọkọ rẹ̀. Wọ́n wá fún tọkọtaya yẹn láwọn àbá tó máa jẹ́ kí wọ́n lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí wọ́n sì ṣètò ìjọsìn ìdílé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn méjèèjì. (Éfé. 5:21-29) Ọkọ yẹn ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ràn náà, àwọn alàgbà sì gbóríyìn fún un. Wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó má jẹ́ kó sú u, kó sì gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà kó lè túbọ̀ máa múpò iwájú nínú ìdílé rẹ̀. Ìfẹ́ táwọn alàgbà yẹn fi hàn sí ìdílé yẹn àti bí wọn ò ṣe dá wọn dá ìṣòro wọn mú kí ìmọ́lẹ̀ ìdílé náà túbọ̀ máa tàn.
20. Kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ tó o bá ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ máa tàn?
20 Onísáàmù náà kọrin pé: “Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.” (Sm. 128:1) Torí náà, tá a bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá sin Jèhófà, tá à ń mú kí ìjọ túbọ̀ wà níṣọ̀kan, tá a sì ń ṣọ́nà, ìmọ́lẹ̀ wa á túbọ̀ máa tàn, àá sì láyọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn míì á kíyè sí àwọn iṣẹ́ àtàtà wa, wọ́n á sì fògo fún Baba wa ọ̀run.—Mát. 5:16.