Ohun Tí Àwọn Ẹ̀dá “Tí Wọ́n Gbọ́n Lọ́nà Ìtẹ̀sí Ìwà Àdánidá” Lè Kọ́ Wa
ÌMÚLÉTUTÙ, máà-jẹ́-nǹkan-ó-dì, ìmúyọ̀kúrò, ìfìró-mọ-bi-ǹkan-gbé-wà jẹ́ ìhùmọ̀ tí aráyé ti mọ̀ bí ẹní mowó ní ọ̀rúndún ogún yìí. Síbẹ̀, wọ́n ti wà ní àwùjọ àwọn ẹranko láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú. Bẹ́ẹ̀ ni, aráyé ń jàǹfààní nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa irú àwọn ẹ̀dá “tí wọ́n gbọ́n lọ́nà ìtẹ̀sí àdánidá” bẹ́ẹ̀. (Òwe 30:24-28, NW; Jóòbù 12:7-9) Ó dà bíi pé àwọn ẹranko kan ti di olùkọ́ tí kì í fẹnu sọ̀rọ̀ fún aráyé, ó sì lè fà wá lọ́kàn mọ́ra bí a bá gbé wọn yẹ̀ wò.
A ha lè jàǹfààní nínú gbígbé àbùdá àwọn ẹranko kan yẹ̀ wò bí? Tóò, Jésù Kristi fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wé àgùntàn, ejò, àdàbà, àti eéṣú pàápàá. Kí ni ó ní lọ́kàn nígbà ti ó fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wéra pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí? Ẹ jẹ́ kí a wò ó ná.
“Àwọn Àgùntàn Mi Ń Fetí Sílẹ̀ sí Ohùn Mi”
Ó lé ní ìgba 200 tí a mẹ́nu kan àgùntàn nínú Bíbélì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, Smith’s Bible Dictionary, ṣe ṣàlàyé, “àgùntàn jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ fún ìwà tútù, sùúrù, àti ìjuwọ́sílẹ̀.” Nínú Aísáyà orí 53, a fi Jésù fúnra rẹ̀ wé àgùntàn lọ́nà alásọtẹ́lẹ̀. Ẹ wo bí ó ti bá a mu wẹ́kú tó pé a lè fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wé ẹran kan náà! Ṣùgbọ́n irú ànímọ́ wo ní pàtàkì tí àgùntàn ní, ni Jésù ní lọ́kàn?
Jésù wí pé: “Àwọn àgùntàn mi ń fetí sílẹ̀ sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.” (Jòhánù 10:27) Ó tipa bẹ́ẹ̀ tẹnu mọ́ ìwà tútù àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àti ìháragàgà wọn láti tẹ̀ lé e. Àwọn àgùntàn ní ti gidi máa ń fetí sílẹ̀ sí olùṣọ́ àgùntàn wọn, wọ́n sì máa ń fínnúfíndọ̀ tẹ̀ lé e. Olùṣọ́ àgùntàn náà pẹ̀lú ní ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ fún agbo àgùntàn náà.
Agbo àgùntàn kan lè fọ́n káàkiri orí pápá nígbà tí wọ́n bá ń jẹko, ṣùgbọ́n àgùntàn kọ̀ọ̀kan kì í fi agbo náà sílẹ̀. Ìwé náà, Alles für das Schaf (Ohun Gbogbo fún Àgùntàn), sọ pé, nípa báyìí, nígbà tí àwọn ẹran náà bá nímọ̀lára àìláàbò tàbí tí a bá dáyà fò wọ́n, “wọ́n lè tètè kóra jọ.” Bí àgùntàn bá sá fún ewu, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbo, ní dídẹ́sẹ̀ dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti tún ipò náà gbé yẹ̀ wò. “Sísá kúṣẹ́kúṣẹ́ ń mú kí àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn àti àwọn aláìlera ẹran lè máa wà pẹ̀lú agbo náà. Agbo náà pàápàá ń pèsè ààbò àrà ọ̀tọ̀.” Kí ni a lè rí kọ́ nínú ìṣarasíhùwà yìí?
Àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí kò fọ́n káàkiri láàárín àwọn ẹ̀yà ìsìn àti ẹ̀ya ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n para pọ̀ sínú agbo kan. Kristẹni kọ̀ọ̀kan ń nímọ̀lára ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ fún agbo Ọlọ́run, èyí sì ń fi kún ìṣọ̀kan ètò àjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbàkigbà tí yánpọnyánrin bá ṣẹlẹ̀—ì bá à jẹ́ àìsàn líle koko, ogun, tàbí ìjàm̀bá ti ìṣẹ̀dá—ibo ni olùjọsìn kọ̀ọ̀kan ń yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà àti ààbò? Nínú ètò àjọ Jèhófà ni, èyí tí ń pèsè ààbò nípa tẹ̀mí.
Báwo ni a ṣe ń mú ìmọ̀ràn Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó? Nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde bí Ilé Ìṣọ́ àti ìwé ìròyìn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Jí! Àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí àti àwọn ìpàdé Kristẹni ń pèsè ìrànwọ́ àkànṣe fún àwọn tí wọ́n nílò ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀, bíi ti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn àti aláìlera àgùntàn inú agbo. Fún àpẹẹrẹ, a ń fún àwọn òbí anìkàntọ́mọ àti àwọn tí wọ́n sorí kọ́ ní àfiyèsí. Nítorí náà, ẹ wo bí ó ti lọ́gbọ́n nínú tó, láti ka ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan, láti lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ, kí a sì fi ohun tí a kọ́ sílò! A ń tipa báyìí fi ìwà tútù àti ìfẹ́ni lílágbára hàn fún agbo Ọlọ́run.—Pétérù Kìíní 5:2.
“Ẹ Jẹ́ Oníṣọ̀ọ́ra Gẹ́gẹ́ Bí Ejò Síbẹ̀ Kí Ẹ Jẹ́ Ọlọ́rùn Mímọ́ Gẹ́gẹ́ Bí Àdàbà”
Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Smith’s Bible Dictionary, sọ pé: “Jákèjádò Ìlà Oòrùn ejò ń ṣàpẹẹrẹ ìlànà ibi, ẹ̀mí àìgbọràn.” Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, “àdàbà mi” jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń fi bí ẹnì kan ṣe ṣọ̀wọ́n tó hàn. (Orin Sólómọ́nì 5:2) Kí ni Jésù ní lọ́kàn, nígbà náà, nígbà tí ó fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níṣìírí láti ‘jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò síbẹ̀ kí wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà’?—Mátíù 10:16.
Jésù ń fúnni ní ìtọ́ni lórí ìwàásù àti ìkọ́ni. Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè retí ìdáhùnpadà bíbára dé àti aláìbára dé. Àwọn díẹ̀ yóò fi ọkàn ìfẹ́ hàn, nígbà tí àwọn mìíràn yóò kọ ìhìn rere náà. Àwọn kan yóò tilẹ̀ ṣenúnibíni sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. (Mátíù 10:17-23) Báwo ni àwọn ọmọlẹ́yìn yóò ṣe hùwà padà sí inúnibíni?
Nínú ìwe Das Evangelium des Matthäus (Ìhìn Rere Mátíù), Fritz Rienecker sọ nípa Mátíù 10:16 pé: “Ọgbọ́n inú . . . gbọ́dọ̀ wà papọ̀ pẹ̀lú ìwà títọ́, òtítọ́ inú, àti nínà tán, aìíbaàámọ̀ tí ohunkóhun yóò bá ṣẹlẹ̀ tí yóò fùn àwọn ọ̀tá lẹ́nu ọ̀rọ̀ fún ṣíṣàròyé. Àwọn ikọ̀ Jésù wà lára àwọn akọjúùjà síni oníwà ìkà, tí wọn kò bìkítà, tí wọ́n gbógun ti àwọn àpọ́sítélì láìfi àánú hàn nígbàkugbà tí wọ́n ní àǹfààní rẹ̀. Nítorí náà, ó pọn dandan—gan-an gẹ́gẹ́ bí ejò ti ń ṣe—láti ṣọ́ra fún àwọn akọjúùjàsíni, àti láti fi ojú àti òye ìwàlójúfò yẹ ipò náà wò; láti káwọ́ ipò náà láìlo ọgbọ́n àrékérekè tàbí ẹ̀tàn, láti jẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ tí í sì í ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí àdàbà.”
Kí ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní kọ́ láti inú ọ̀rọ̀ Jésù tí a rí nínú Mátíù 10:16? Lónìí, àwọn ènìyàn ń hùwà padà sí ìhìn rere náà lọ́nà kan náà gẹ́lẹ́ tí wọ́n gbà hùwà ní ọ̀rúndún kìíní. Nígbà tí a bá dojú kọ inúnibíni, àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti pa ọgbọ́n inú ejò pọ̀ mọ́ ìjẹ́mímọ́ àdàbà. Àwọn Kristẹni kì í lo ẹ̀tàn tàbí àbòsí ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ aláìníwààbàjẹ́, olóòótọ́, àti aláìlábòsí nínú pípolongo ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn.
Láti ṣàkàwé: Àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹni níbi iṣẹ́, àwọn ọ̀dọ́ ní ilé ẹ̀kọ́, tàbí kódà àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ lè sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa èrò ìgbàgbọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà. Ìhùwàpadà ojú ẹsẹ̀ lè jẹ́ láti dáhùn padà nípa bíbu ẹnu àtẹ́ lu ìgbàgbọ́ tiwọn pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ìyẹ́n ha bójú mu bí? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀. Bí o bá fi han àwọn tí ń ṣe lámèyítọ́ rẹ pé ọ̀rọ̀ wọn kò ní ipa kankan lórí ìṣarasíhùwà gbígbádùn mọ́ni rẹ, wọ́n lè yí padà sí rere. Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ ọlọgbọ́n inú àti aláìlárìíwísí—‘tí ó ṣọ́ra bí ejò, síbẹ̀ tí ó jẹ́ ọlọ́rùn mímọ́ bí àdàbà.’
“Ìrí Àwọn Eéṣú Náà Sì Jọ Àwọn Ẹṣin Tí A Múra Sílẹ̀ fún Ìjà Ogun”
Ìwé ìròyin GEO sọ pé ní 1784, “ọ̀wọ́ [eéṣú] tí ó pọ̀ jù lọ tí a tí ì kọ sílẹ̀ rí nínú ìtàn” bo Gúúsù Áfíríkà ṣíbáṣíbá. Eéṣú náà bo agbègbè 5,200 kìlómítà níbùú lóòró, èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po márùn-ún Hong Kong. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Smith’s Bible Dictionary, sọ pé eéṣú “a máa jẹ koríko orílẹ̀-èdè tí ó bá bẹ̀ wò ní àjẹbàjẹ́.”
Nínú ohun tí Ọlọ́run ṣí payá fún un nípa àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́ Olúwa,” Jésù lo ìran àwọn eéṣú. Ó sọ nípa wọn pé: “Ìrí àwọn eéṣú náà sì jọ àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ìjà ogun.” (Ìṣípayá 1:1, 10; 9:3-7) Kí ni ìjẹ́pàtàkì ìṣàpẹẹrẹ yìí?
Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mọ̀ pé àwọn eéṣú Ìṣípayá orí 9 ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni-àmì-òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀rúndún yìí.a A ti yan iṣẹ́ kan pàtó fún àwọn Kristẹni wọ̀nyí—láti wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé, kí wọ́n sì sọni di ọmọlẹ́yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Èyí ń béèrè pé kí wọ́n borí ìdènà, kí wọ́n sì rọ̀ mọ́ iṣẹ́ wọn. Kí ni ó tún lè ṣàkàwé èyí ju eéṣú àkòtagìrì lọ?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ni ó fi gùn ju sẹ̀ǹtímítà márùn-ún lọ, eéṣú máa ń rìnrìn àjo 100 sí 200 kìlómítà lójúmọ́. Eéṣú aṣálẹ̀ tilẹ̀ lè lọ jìnnà dé 1,000 kìlómítà. Ìwé ìròyìn GEO ṣàlàyé pé “àwọn ìyẹ́ rẹ̀ ń jù síwá sẹ́yìn nígbà 18 ní ìṣẹ́jú àáyá kan àti fún nǹkan bíi wákàtí 17 lójúmọ́—ohun kan tí kòkòrò mìíràn kò lè dágbá lé.” Ẹ wo irú iṣẹ́ kíkàmàmà tí èyí jẹ́ fún irú ẹ̀dá bíńtín bẹ́ẹ̀!
Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ adúrógbọn-ingbọn-in nínú títan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀. Wọ́n ń wàásù ní iye tí ó lé ní 230 ilẹ̀ nísinsìnyí. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí ń borí ọ̀pọ̀ ìṣòro láti baà lè ṣàjọpín nínú ṣíṣe iṣẹ́ wọn. Irú ìṣòro wo ni wọ́n ń dojú kọ? Ẹ̀tanú, ìkálọ́wọ́kò òfin, àìsàn, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti àtakò láti ọ̀dọ̀ ìbátan, kí á wulẹ̀ mẹ́nu kan díẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ohun kan tí ó tí ì dá ìtẹ̀síwájú wọn dúró. Wọ́n rọ̀ mọ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn.
Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Fífi Ànímọ́ Kristẹni Hàn
Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wé àgùntàn, ejò, àdàbà, àti eéṣú. Èyí bá ọjọ́ wa mu ní tòótọ́. Èé ṣe? Nítorí pé òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti sún mọ́lé, ìṣòro sì ń gorí ìṣòro sí i.
Ní fífi àwọn ọ̀rọ̀ àkàwé Jésù sọ́kàn, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ agbo Ọlọ́run, wọ́n sì ń fi ìwà tútù tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn láti ọwọ́ ètò àjọ Jèhófà. Wọ́n ń ṣọ́nà, wọ́n sì wà lójúfò sí àwọn ipò tí ó lè ké ìgbòkègbodò Kristẹni wọn nígbèrí, nígbà tí wọ́n sì ń wà láìní àríwísí nínú ohun gbogbo. Ní àfikún sí i, wọ́n ń lo ìforítì nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lójú àwọn ìṣòro. Wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn ẹ̀dá “tí wọ́n gbọ́n lọ́nà ìtẹ̀sí àdánidá.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé Revelation—Its Grand Climax At Hand!, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., orí 22.