Ṣé Ọlọ́run Ń Kíyè Sí Rẹ?
OHUN TÁ A RÍ KỌ́ NÍNÚ ÌṢẸ̀DÁ
Láàárín wákàtí kan tí ọmọ bá jáde nínú ikùn ìyá rẹ̀, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí ìyá fa ọmọ náà mọ́ra tímọ́tímọ́.a Tí àwọn abiyamọ bá fa ọmọ wọn mọ́ra ní àkókò pàtàkì yìí, èyí á jẹ́ kí ọmọ náà dàgbà lọ́nà tó yẹ.
Kí ló máa ń mú kí ìyá tọ́jú ọmọ rẹ̀ jòjòló lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́? Nínú ìwé The Journal of Perinatal Education, ọ̀jọ̀gbọ́n Jeannette Crenshaw ṣàlàyé pé kẹ́míkà kan tí wọ́n ń pè ní oxytocin máa ń pọ̀ nínú ìyá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, “èyí ló máa ń jẹ́ kí ìfẹ́ àti ìmọ̀lára tí ìyá ní sí ọmọ rẹ̀ jòjòló pọ̀ sí i bó ṣe ń wo ojú ọmọ náà, tó ń fọwọ́ kàn án, tó sì ń fún un lọ́mú.” Lákòókó yìí kan náà, kẹ́míkà míì tún máa ń “jẹ́ kí ọkàn ìyá náà máa fà sí ọmọ rẹ̀” tó sì máa ń jẹ́ kí ọmọ àti ìyá sún mọ́ra gan-an. Kí nìdí tí èyí fi gba àfíyèsí?
Àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín ìyá àti ọmọ kò ṣẹ̀yìn Jèhófà Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́.b Abájọ tí Ọba Dáfídì fi yin Ọlọ́run lógo pé ó mú òun “jáde láti inú ikùn,” ó sì mú kí ara tu òun lọ́wọ́ ìyá òun. Ó wá gbàdúrà pé: “Ìwọ ni a gbé mi lé lọ́wọ́ láti inú ilé ọlẹ̀, ìwọ ni Ọlọ́run mi láti inú ikùn ìyá mi wá.”—Sáàmù 22:9, 10.
RÒ Ó WÒ NÁ: Tí Ọlọ́run bá lè ṣe é tí ìyá á fi lè fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ jòjòló, tí á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ṣé kò wá bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run rí tiwa rò lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, àwa tá a jẹ́ ‘ọmọ Ọlọ́run’?—Ìṣe 17:29.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ KỌ́ WA NÍPA BÍ ỌLỌ́RUN ṢE Ń BÓJÚ TÓ WA
Jésù Kristi tó mọ Ẹlẹ́dàá wa ju ẹnikẹ́ni lọ sọ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Mátíù 10:29-31.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í kíyè sí àwọn ẹyẹ kéékèké, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé wọ́n á mọ̀ ‘tí ọ̀kan nínú wọn bá já bọ́ lulẹ̀.’ Àmọ́ Baba wa ọ̀run máa ń kíyè sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sí bí àwọn ẹyẹ ṣe pọ̀ tó tí wọ́n lè níye lórí lójú Ọlọ́run tó àwa èèyàn. Ẹ̀kọ́ tá a fẹ́ fà jáde ni pé: Kò sí ìdí fún ẹnikẹ́ni láti máa bẹ̀rù pé Ọlọ́run kò rí ti òun rò. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run rí tiwa rò, ó sì bìkítà nípa wa!
Ọlọ́run mọ̀ wá dáadáa, ó sì ń fi ìfẹ́ bójú tó wa.
Bíbélì fi dá wa lójú pé
“Ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.”—ÒWE 15:3.
“Ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.”—SÁÀMÙ 34:15.
“Èmi yóò kún fún ìdùnnú, èmi yóò sì máa yọ̀ nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, ní ti pé ìwọ ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́; ìwọ ti mọ̀ nípa àwọn wàhálà ọkàn mi.”—SÁÀMÙ 31:7.
“Ó MÁA Ń ṢE MÍ BÍI PÉ JÈHÓFÀ Ò NÍFẸ̀Ẹ́ MI”
Ṣé ayé wa máa túbọ̀ nítumọ̀ tá a bá mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún, ó sì fẹ́ kí nǹkan dáa fún wa? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ máa rí. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ìrírí Hannahc tó wá láti England:
“Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti rò pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ mi àti pé kò gbọ́ àwọn àdúrà mi, bóyá nítorí pé ìgbàgbọ́ mi kò tó. Mo rò pé mi ò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀ ló ṣe kórìíra mi. Ó ṣe mí bíi pé Ọlọ́run ò bìkítà nípa mi.”
Àmọ́, ní báyìí, Hannah ti wá mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun. Kí ló jẹ́ kó mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Mo rántí pé ẹnì kan fi Bíbélì ṣàlàyé nípa bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa, ìgbà yẹn ni èrò mi bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà díẹ̀díẹ̀, mo wá rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi lóòótọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bú sẹ́kún tí mo bá rí bí Ọlọ́run ṣe dáhùn àdúrà mi, ìyẹn sì jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo sì ń lọ sí ìpàdé Kristẹni ti jẹ́ kí n mọ̀ pé Ọlọ́run ní àwọn ànímọ́ tó dáa, ó sì bìkítà nípa wa. Ní báyìí, mo ti wá rí bí Jèhófà ṣé ń fi ìfẹ́ hàn sí wa, tó ń tì wá lẹ́yìn, tó sì ń bójú tó wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.”
Ohun tí Hannah sọ wúni lórí gan-an. Àmọ́, kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn ìbéèrè yìí.
a Àwọn ìyá kan kò lè fa ọmọ wọn mọ́ra torí pé wọ́n ní postpartum depression, ìyẹn àìsàn ọpọlọ tó máa ń ṣe àwọn obìnrin kan lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ. Àmọ́ kò yẹ kí àwọn ìyá bẹ́ẹ̀ máa dá ara wọn lẹ́bi. Àjọ National Institute of Mental Health ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé “kì í ṣe pé ìyá ọmọ ló fa àìsàn yìí bá ara rẹ̀, àwọn nǹkan míì ló máa ń fà á, kì í ṣe ẹ̀bi ìyá.” Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i lórí kókó yìí, wo àpilẹ̀kọ náà “Understanding Postpartum Depression” nínú Jí! June 8, 2003.
b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú Bíbélì.—Sáàmù 83:18.
c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí.